Joṣua 5:10-15; 6:1-27

Lesson 155 - Junior

Memory Verse
“Ẹ hó; nitoriti OLUWA ti fun nyin ni ilu na” (Joṣua 6:16).
Notes

A Mú Joṣua Lọkàn Le

Ọlọrun ti mú awọn Ọmọ Israẹli wá si ilẹ ileri nipasẹ Joṣua. Agọ wọn kin-in-ni wa ni Gilgali nibi ti wọn ti ṣe Ajọ Irekọja (Joṣua 5:10). Bayii ni awọn Ọmọ Israẹli gbọran si Ọrọ Oluwa, ti wọn si ṣẹgun idenà nlá nlà ati ohun ti awọn ọta fi ṣe aabo ara wọn. Wọn ti jẹ ninu eso Ilẹ Kenaani (Joṣua 5:12). Bawo ni eyi yoo ti ki wọn layà to! Dajudaju, wọn ni itara lati lọ si oju ogun, ki wọn si ba awọn ọta jà, gẹgẹ bi Ọlọrun ti paṣẹ fun wọn lati ṣe.

Joṣua wà nitosi ilu Jẹriko. Boya o n ṣe aṣaro ninu ọkàn rẹ, o si n ronu nipa iṣẹgun lori Jẹriko ti a n pe ni “ilu ọlọpẹ” (Deuteronomi 34:3). Boya Joṣua n duro de itọsọna ati aṣẹ lati ọdọ Oluwa nipa ilu olódi yii. Bi Joṣua ti gbé oju rẹ soke, o ri ọkunrin kan pẹlu idà ni ọwọ rẹ. Ẹru kò ba Joṣua, nitori Ọlọrun ti wi fun un pe: “Emi ki yio fi ọ silẹ, bẹẹli emi ki yio kọ ọ” (Joṣua 1:5).

Joṣua tọ ọkunrin yii lọ, o si bi i leere bi ó bá wà niha ti wọn tabi bẹẹ kọ. Ọkunrin naa dahun pe oun wá bi Olori-ogun Oluwa. Lẹsẹ kan naa ni Joṣua “wolẹ niwaju rẹ” lati sin in. Joṣua kò wi pe Ọlọrun ti fi oun ṣe aṣaaju awọn Ọmọ Israẹli. Ṣugbọn, pẹlu ọkàn irẹlẹ, o beere itọsọna lọwọ ọkunrin ti o mu idà dani yii. Joṣua bọ salubata rẹ gẹgẹ bi a ti sọ fun un lati ṣe. Ibi ti o wà yii jẹ ibi mimọ nitori Ọlọrun funra Rẹ wà nibẹ.

Ọlọrun n fẹ ki a wá siwaju Oun tọwọtọwọ lọjọ oni pẹlu. Ọlọrun n fẹ ki a dakẹ jẹẹ pẹlu ẹmi isin ninu ile isin ati ni ibikibi nigbà ti awọn miiran ba n gbadura tabi nigbà ti wọn bá n ka Bibeli. Nigba pupọ ni ọmọ Ọlọrun maa n ka ibi ti Ọlọrun ti bukun fun un ti o si ki i laya, si ibi ọwọ ati ibi mimọ, boya ni ile-isin, ni ile rẹ, tabi ni ibomiran pẹlu.

Joṣua fi irẹlẹ wolẹ nibẹ pẹlu ọwọ, bi ifarahàn Ọkunrin yii ti mú igboya ati igbagbọ ọtun wọ inu ọkàn rẹ. Ta ni Ọkunrin yii ti i ṣe Olori ogun Oluwa? Ta ni i ba jẹ Olori ogun bi kò ṣe Jesu tikara Rẹ? Ninu Heberu 2:9, 10, a kà pe Jesu ni Balógun igbalà wa. Oun ni Ẹni ti O n mú wa lọ lati ìṣẹgun de ìṣẹgun, nigbà ti a ba gbé oju wa soke si I ti a si gbọran si gbogbo ọrọ Rẹ.

Eto Ọlọrun

Awọn ti n gbe Jẹriko ti gbọ ohun ti Ọlọrun ti ṣe fun awọn Ọmọ Israẹli. Ibẹrù wà ninu ọkàn wọn (Joṣua 2:11), wọn si ti ilẹkun ilu ki ẹnikẹni má ba le jade tabi ki o wọle. Eyi kò di awọn Ọmọ Israẹli lọwọ, nitori ki i ṣe ilana Ọlọrun fun wọn lati gba ilu naa nipa rirán awọn ọmọ-ogun ti yoo bá ẹnu ọna wọle.

A sọ fun Joṣua pe Ọlọrun ti fi Jẹriko, ọba ibẹ ati awọn ọmọ-ogun rẹ le e lọwọ, Ṣugbọn wọn kò tọ Joṣua wa lati tuubá. Joṣua ati awọn Ọmọ Israẹli ni lati mú ilana Ọlọrun fun wọn ṣẹ. A fun wọn ni aṣẹ ti o ṣe ajeji, ṣugbọn wọn kò lọra lati mu wọn ṣe.

Wọn yi ilu Jẹriko ká lẹẹkan loojọ fun ọjọ mẹfa. Wọn tò lẹsẹẹsẹ gẹgẹ bi Ọlọrun ti pa a laṣẹ. Awọn ti wọn hamọra ogun ni wọn ṣaaju; lẹyin naa awọn alufaa meje n lọ niwaju Apoti Oluwa, wọn gbe ipẹ meje, ti wọn fi iwo agbo ṣe lọwọ, lẹyin naa ni “ogun-ẹhin,” awọn eniyan. Lai si aniani, eyi jẹ iran ti o ṣe ajeji si awọn ara Jẹriko bi wọn ti n wò wọn lati inu ile wọn lori odi.

Dajudaju awọn ti n gbe Jẹriko ni ireti lati gbọ ariwo ogun. Kiki ohun ti wọn gbọ ni iro ẹsẹ awọn ti n rin lẹsẹẹsẹ, ati iró ipe meje, eyi ti o ṣe e ṣe ki o jẹ ẹrù fun awọn ọtá, ṣugbọn ti o jẹ iwuri fun ogun Israẹli. Lẹyin ti wọn ti yi odi Jẹriko ka bayii, wọn pada si agọ wọn.

Ko si Aabò

Ẹnu le ti ya ọba Jẹriko si iwéwe ogun jija ti o ṣe ajeji yii, ki o si beere pe, “Ki ni eto wọn? Bawo ni yoo ti pẹ to ti wọn yoo maa rin lẹsẹẹsẹ yika odi ilu bẹẹ? Ki ni wọn o ri gbà nipa nnkan ti wọn n ṣe yii?” Boya lẹyin ọjọ mẹfa, awọn ọta wọn ti rò pe wọn wà lai lewu nitori wọn kò ri ewu ninu iwéwe ogun ti o ṣe ajeji yii. Nigba pupọ ti awọn ẹlẹṣẹ ba n rò pe wọn wà lai lewu, nigbà naa ni idajọ wọn yoo de. Ninu 1 Tẹssalonika 5:3, a kà pe: “Nigbati nwọn ba nwipe, alafia ati ailewu; nigbana ni iparun ojiji yio de sori wọn … nwọn ki yio si le sálà.”

Ki ni awọn Ọmọ Israẹli rò nipa gbogbo irin wọn lẹsẹẹsẹ yii? Wọn kò sọ igbẹkẹle wọn ninu Ọlọrun nù, bi o tilẹ jẹ pe kò si abayọri ti a le fi oju ri. Ọlọrun ti ṣeleri pe odi naa yoo wó lulẹ nigbà ti wọn ba yi ilu na ká ni ẹẹkeje ni ọjọ keje. Pẹlu suuru ati igbagbọ ni wọn fi gbọran si aṣẹ Ọlọrun.

Awọn miiran maa n gbọn loju ara wọn. Wọn kò le duro de Oluwa. Wọn le fẹ maa gbòke-gbodò nigbà ti Oluwa n fẹ ki wọn duro jẹẹ. Ọlọrun n fẹ igbọran – boya ni lilọ tabi ni diduro. Ki ni o rò pe yoo ṣẹlẹ bi a ba ri ninu awọn ọkunrin ti o hamọra ogun yii ti ko ni suuru, ki wọn si ti gbiyanju lati ṣẹgun Jẹriko nipa ilana ati agbara wọn? Lai ṣe aniani, wọn i ba ti kuna, boya wọn i ba ti padanu ẹmi wọn ati ti awọn miiran pẹlu. Aṣẹ ti a fi fun wọn ni lati rin lẹsẹẹsẹ, ki i ṣe pe ki wọn jà. Onisaamu wi pe “Duro de OLUWA; ki o si tújuka, yio si mu ọ li aiya le: mo ni, duro de OLUWA” (Orin Dafidi 27:14).

Ki i ṣe igbà gbogbo ni Onigbagbọ le ri esi adura rẹ gbà lẹsẹkẹsẹ tabi abayọrisi aapọn ti o n ṣe fun Oluwa. Pẹlu suuru, iforiti, ati igbagbọ, oun yoo maa tẹ siwaju, niwọn bi o ti mọ pe iṣẹ oun ki i ṣe asan ninu Oluwa (1 Kọrinti 15:58).

Hihó ti Igbagbọ

Bi ilẹ ọjọ keje ti mọ, akoko iparun Jẹriko sun mọ itosi. Awọn Ọmọ Israẹli dide ni kutukutu owurọ lọjọ naa lati yi ilu na ká ni igbà meje. A kò mọ bi wọn ti rin lẹsẹẹsẹ jinna to tabi iye akoko ti o gbà wọn, ṣugbọn awọn Ọmọ Israẹli gbọran, wọn si lọ ninu agbara Oluwa. Wolii Daniẹli wi pe, “Awọn enia ti o mọ Ọlọrun yio mu ọkàn le, nwọn o si ma ṣe iṣẹ agbara” (Daniẹli 11:32). Wọn ti gba aṣẹ nipa irin wọn lẹsẹẹsẹ yii pe, kò gbọdọ si ọrọ sisọ tabi ariwo titi a o fi fun wọn ni àmi. Boya eyi ni lati mu idaamu ba awọn ọta wọn tabi lati fun awọn Ọmọ Israẹli ni ayẹ lati ṣe aṣarò ohun ti Ọlọrun n ṣe fun wọn. Nigbà miiran awọn eniyan, yala àgbalagba tabi awọn ọmọde pẹlu maa n fi ara wọn sinu wahala nipa sisọ ọrọ pupọ. Ọrọ sisọ naa ti gba akoko ati erò wọn. Nigbà pupọ ni o maa n yọri si were ati ohun miiran ti kò gbeni ró.

Awọn Ọmọ Israẹli ti rin lẹsẹẹsẹ fun igbà mẹfa ṣaaju; ni ọjọ keje, wọn tò lọwọọwọ ni igbà meje. Boya awọn ọtá wọn n wò wọn lati oju ferese wọn, awọn miiran si le ti fi iwéwe ogun jija ti o ṣe ajeji yii ṣẹfẹ. Ṣugbọn ti awọn Ọmọ Israẹli ni lati gbọran si Ọlọrun.

Nikẹyin, irin wọn lẹsẹẹsẹ fẹrẹ dopin. Joṣua wi pe, “Ẹ hó; nitoriti OLUWA ti fun nyin ni ilu na.” Awọn oniyemeji miiran le wi pe: “Ki ni a o hó fun? Odi ṣi wà ni ipo rẹ sibẹ. Nigbà ti odi ba wó lulẹ, nigba naa ni a o hó.”

Iṣẹgun

Awọn Ọmọ Israẹli kò ṣiyemeji. Wọn gbàgbọ, wọn si ṣe bi Joṣua ti paṣẹ fun wọn. Nigbà ti awọn alufaa meje naa fun ipẹ, awọn eniyan naa hó, “odi na wó lulẹ bẹrẹ.”Bibeli kò sọ pe odi naa wó lulẹ nitori isẹlẹ tabi gẹgẹ bi abayọrisi iro ẹsẹ awọn ti n rin lẹsẹẹsẹ. O wi pe, “Nipa igbagbọ li awọn odi Jẹriko wó lulẹ, lẹhin igbati a yi wọn ká ni ijọ meje” (Heberu 11:30). Odi naa kò wó lulẹ diẹdiẹ ni igbà kan tabi ni ojoojumọ, tabi ki afo wà nihin ati lọhun; “odi wó lulẹ bẹrẹ” nigbà ti awọn eniyan naa hó.

Kò si ohun ija ogun tabi agbara miiran ti awọn Ọmọ Israẹli lò si i; ṣugbọn gẹgẹ bi igbagbọ wọn, odi naa wó lulẹ, eyi si fun wọn ni ayẹ lati wọ ilú naa.

Idasilẹ

Joṣua rán awọn ami meji naa (Ẹkọ 153) lati lọ yọ Rahabu ati awọn ẹbi rẹ ti wọn wà ninu ilé ti a so owú ododó mọ oju ferese rẹ (Joṣua 2:18). Rahabu, ẹbi rẹ ati gbogbo ohun ti o ni, ni a gbalà; ṣugbọn iyoku Jẹriko ni a parun. Bayii ni Rahabu n gbe ni Israẹli lati igbà naa wá.

Gbogbo awọn ohun elò idẹ ati irin, gbogbo fadaka ati wúrà ni a fi sinu ile iṣura Oluwa ti a si yà wọn sọtọ fun Un. Ṣugbọn awọn eniyan naa kò fi ohun kan pamọ fun ara wọn, ki o ma ba jẹ pe ki i ṣe awọn nikan bi kò ṣe gbogbo agọ ni a o fi bú pẹlú. Eyi ni aṣẹ Oluwa – ki wọn pa awọn ọta wọn run patapata nitori iwà buburu wọn.

Awọn Onigbagbọ lonii kò ni odi nla bi ti Jẹriko lati wó lulẹ, ṣugbọn ọpọ ni o ni iṣoro ti o dabi ẹni pe o nira lati bori. Nigbà pupọ ni awọn ọmọde maa n ni wahala ninu iṣẹ ile-ẹkọ wọn tabi laaarin awọn ẹlẹgbẹ wọn. Awọn ọmọde miiran ni awọn obi ti kò ri igbalà ti wọn kò si bá wọn so ọwọ pọ lati sin Ọlọrun. Oluwa maa n mú iṣoro wọnyii kurò bi ọmọ Ọlọrun naa ba le fi igbagbọ ati suurù mu awọn iṣoro yii lọ sọdọ Rẹ ninu adura. Boya a le ṣe alai dahun adura wọn ni igbà kin-in-ni ṣugbọn nipa igbọran ati igbẹkẹle ninu Oluwa, awọn eniyan rẹ maa n jẹ aṣẹgun.

Nigba ti o bá ni iṣoro ninu igbesi aye rẹ, ranti pe igbagbọ rẹ ninu Ọlọrun le mú ki “odi” na wó lulẹ. Ẹri rẹ yoo dabi ti Abijah, ọba Juda. Ki o to lọ si ogun o wi pe “Si kiyesi i, Ọlọrun tikararẹ si wà pẹlu wa li Olori wa.” Nitori naa ni awọn ọmọ Juda “si bori, nitori ti nwọn gbẹkẹle OLUWA Ọlọrun awọn baba wọn” (2 Kronika 13:12, 18).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti Olori ogun Oluwa fi ara han Joṣua?
  2. Ki ni ṣe ti a “há” Jẹriko “mọ”?
  3. Ki ni ṣe ti awọn Ọmọ Israẹli rin lẹsẹẹsẹ yi Jẹriko ká nigbà pupọ bẹẹ?
  4. Ki ni awọn eniyan naa ni lati hó fun?
  5. Ki ni mu odi Jẹriko wó lulẹ?
  6. Ki ni ṣe ti a gba Rahabu ati ẹbi rẹ là?
  7. Ki ni ohun miiran ti a kò parun?