Matteu 2:1-23; Luku 2:1-20

Lesson 156 - Junior

Memory Verse
“Má bẹru: sawò o, mo mu ihinrere ayọ nla fun nyin wá, ti yio ṣe ti enia gbogbo” (Luku 2:10).
Notes

Awọn Alejo Ọrun

Ọjọ Keresimesi kin-in-ni, eyi ti a ṣe ariyá rẹ ni ọpọlọpọ ọdún sẹyin ni ilu kekere ti Bẹtlẹhẹmu, mu awọn alejo wá lati Ọrun si ori awọn oke Judea. A gbọ orin awọn angẹli n dún ninu awọsanma; awọn oluṣọ-agutan ti wọn si tẹti silẹ wi pe gbogbo awọn ọrun kún fun ẹgbẹ awọn angẹli ti n kọrin. Ogunlọgọ awọn ogun ọrun ni wọn wá lati kọrin pe, “Ogo ni fun Ọlọrun loke ọrun,” nipa Olugbala arayé ti a bi ni alẹ ọjọ naa ni Bẹtlẹhẹmu.

Awọn angẹli naa ti mọ Jesu ni Ọrun, wọn si ti wolẹ, wọn si ti sin In bi wọn ti n kọrin yi itẹ Rẹ ká. Gbogbo wọn ni wọn n yọ ni Ọrun, kò si si nnkan lati pa wọn lara. Ṣugbọn ni ọjọ kan Ọlọrun boju wo ilẹ O si ri idaamu ati oṣi ti o wà ninu ọkàn eniyan, O si wi pe akoko tó fun Jesu lati sọkalẹ lati wa ran awọn eniyan lọwọ.

Aigbọran ati Ipọnju

Ayé yii ti jẹ ibugbe ayọ ri, pẹlu; nnkan ti o si ṣẹlẹ ni yii. Dipo ki awọn eniyan gbọran si Ọlọrun lẹnu, wọn ti yà kurò lọdọ Rẹ wọn si ti dá oriṣiriṣi ẹṣẹ. Nitori naa, lai ṣe aniani, wahala wá sinu ayé dipo inu didun. Nipa ṣiṣe aigbọran si Ọlọrun, awọn eniyan ti ta ara wọn fun Satani, wọn kò si jẹ ọmọ Ọlọrun mọ. Wọn kò ni nnkan kan ti wọn i bá fi san gbẹsẹ ẹṣẹ wọn. Ẹni kan ṣoṣo ni ó wà ti o le ra wọn padà. Ẹni naa ni Jesu.

Ayọ Nla fun Gbogbo Eniyan

Nitori naa nigba ti Ọlọrun ri ibanujẹ ti o wà ninu ayé ti O si wi pe akoko to fun Jesu lati bọ bi Olurapada, Jesu wá, a si bi I sinu aye, ni ibujẹ-ẹran ni Bẹtlẹhẹmu. Iwọ mọ idi rẹ ti inu awọn angẹli fi dùn? Inu wọn dùn pupọ pe Ọlọrun ṣi ọna yii silẹ fun awọn olugbe inu ayé lati tun le ni ayọ lẹẹkan si i.

Ẹrù ba awọn oluṣọ-agutan nigbà ti wọn ri awọn angẹli naa. Boya wọn rò pe kikú ni awọn yoo kú. Ṣugbọn aṣiwaju awọn angẹli naa wi pe: “Má bẹru: sawò o, mo mu ihinrere ayọ nla fun nyin wá, ti yio ṣe ti enia gbogbo. Nitori a bi Olugbala fun nyin loni ni ilu Dafidi, ti iṣe Kristi Oluwa.” Nigbà naa ni ogunlọgọ awọn angẹli gbé ohùn orin ọpẹ soke pe: “Ogo ni fun Ọlọrun loke ọrun, ati li aiye alafia, ifẹ inu rere si enia.” Abájọ ti awọn angẹli kọrin! Iṣura ti o ṣe iyebiye ju lọ ni Ọrun ni o sọkalẹ wa lati ba eniyan gbé, lati kọ wọn bi o ti yẹ ki wọn gbe ninu aye. Igbagbọ ninu Rẹ yoo mu alaafia wá fun ọkàn ẹnikẹni. Etutu fun ẹṣẹ, ani Ọdọ-agutan Ọlọrun, ni O yọnda ara Rẹ tọkàn-tọkàn fun araye, lati tun rà wọn pada sọdọ Ọlọrun.

Wọn Tẹti Silẹ

Awa kò mọ bi ẹlomiran lẹyin awon oluṣọ-agutan naa gbọ orin awọn angẹli naa; ṣugbọn awọn ẹni irẹlẹ wọnyii bẹru Ọlọrun wọn si ni ọkàn ti yoo tẹti silẹ lati gbọ iṣẹ ti a rán wọn lati Ọrun. Fun ẹnikẹni ti o ba n fẹ gbọ, Ọlọrun yoo sọrọ. A lẹ ma gbọ ohùn ọrọ gan an, ṣugbọn ọkàn wa yoo mọ iṣẹ ti Ọlọrun n fẹ rán si wa bi a ba rin pẹlẹpẹlẹ niwaju Rẹ, ti a ba si tẹti silẹ si ohun ti O ba n fẹ ba wa sọ. Nigbà pupọ ti a ba n ka Bibeli ẹsẹ kan le mú wa lọkan ṣinṣin to bẹẹ ti yoo fẹrẹ dabi ẹni pe n ṣe ni Ọlọrun rán ọrọ naa si wa gan an.

A kò mọ boya Maria ati Josẹfu gbọ orin awọn angẹli naa, ṣugbọn awọn oluṣọ-agutan royin ohun gbogbo ti wọn ti gbọ fun wọn. Maria mọ pe Ọmọ oun jẹ Ọmọ Ọlọrun; bi o tilẹ jẹ pe kò sọrọ nipa rẹ, sibẹ o “pa gbogbo nkan wọnyi mọ, o nrò wọn ninu ọkàn rẹ.” Ohun iṣura iyebiye ni fun un lati mọ pe awọn angẹli ti kọrin ologo nipa ti Ọmọ-ọwọ rẹ.

Wọn Ri Alaafia

Ayọ ati alaafia ti o dé ba awọn oluṣọ-agutan ti wọn ri Jesu ti pọ tó! Wọn pada si ẹnu iṣẹ irẹlẹ wọn, ẹrù iṣẹ wọn si di fifuyẹ nitori ayọ ti o wà ninu ọkàn wọn. Wọn ti ri Jesu, Oludande araye! Wọn ti wolẹ sin niwaju Rẹ, wọn si ti lọ pẹlu ibukun.

Awọn oluṣọ-agutan naa wi pe awọn angẹli ni o dari wọn si ibi ti a bi Olugbala si, “ti iṣe Kristi Oluwa.” Olukuluku ẹni ti o gbọ ni o yà lẹnu; ṣugbọn a kò mọ boya pupọ eniyan lọ wò o funra wọn.

Ọpọ awọn eniyan lonii ti n gbọ itan Irapada ni o n jọ loju pe eniyan le ri idariji ẹṣẹ gbà, pe igbesi aye eniyan le di ọtun, ati pe alaafia ati ayọ le dipo ìkorò ati ikorira; ṣugbọn wọn kò gbiyanju lati ri Jesu. Nitori bẹẹ wọn ki i ni alaafia ti Oun maa n fi fun gbogbo awọn ti wọn tọ Ọ lọ lọfẹẹ.

Lati Ilẹ Okeere

Bi o tilẹ jẹ pe iba diẹ ninu ogunlọgọ awọn ti o wà ni Bẹtlẹhẹmu ni oru naa ni wọn wá ri Jesu, awọn amoye eniyan kan ti ilu ti o jinna rére wá ti wọn ti gbọ nipa ọjọ-ibi Rẹ, wọn si rin lati ọna jinjin wá ki wọn ba le ri I. Wọn ki i ṣe ninu awọn Ju ti wọn n reti Messia, ṣugbọn pẹlu ọkàn otitọ ni wọn fi n ṣafẹri ohun kan ti o tayọ ti o si duro pẹ ju eyi ti ọgbọn wọn ti fi fun wọn. Lai ṣe aniani wọn ti kà ninu iwe wọn nipa awọn asọtẹlẹ Balaamu, ẹni ti Ọlọrun mi si lati sọtẹlẹ pe: “Irawọ kan yio ti inu Jakọbu jade wá, ọpa-alade kan yio si ti inu Israẹli dide” (Numeri 24:17).

Awọn amoye naa n kiyesi awọn irawọ, ni alẹ ọjọ kan wọn ri itanṣan kan ni awọsanma irú eyi ti wọn kò ri ri. O ha le jẹ pe n ṣe ni Ọlọrun fun arayé ni àmi pe Messia Israẹli ti dé? Ọkan wọn gbiná, wọn si dide lati tẹle irawọ Bẹtlẹhẹmu naa.

Titẹjumọ

Boya ẹnikẹni ti o ba wo ọna fun irawọ ajeji yii ni i ba ti ri i, ti i ba si tẹle e wa si ọdọ Olugbala; ṣugbọn kiki awọn amoye diẹ wọnyii ni a mọ ti o n wọna fun nnkan ti iyẹ ainipẹkun, ti wọn si tẹle irawọ naa de ibi ti a bi Ọba Ogo si.

Wọn la awọn aṣalẹ kọja, wọn la odo kọja, wọn gun okẹ, wọn sa n tẹjú mọ irawọ naa, titi wọn fi de ilu Jerusalẹmu, nibi ti ọba n gbé. Ijọba Romu ni o ti yan ọba yii, oun ki i si ṣe ọba Israẹli ni idile Dafidi. Awọn wolii kọwe rẹ pe lati idile Dafidi ni a o ti bi Messia, nitori bẹẹ dajudaju, awọn amoye naa reti pe Messia naa ni lati jẹ ọba, wọn si lọ si olu-ilu awọn Ju lati wa A.

Jerusalẹmu Daamu

Lode oni nigba ti a ba bi ọmọ ti a mọ pe yoo jọba, inu gbogbo ilu ni o maa n dun si i, kiakia ni ọrọ naa maa n tàn kaari. O ni lati jẹ ohun ajeji pupọ fun awọn amoye naa nigbà ti wọn de Jerusalẹmu ti wọn kò si bá ariyá, ti wọn kò tilẹ ri ẹnikẹni ti o dabi ẹni pe o mọ pe a ti bi Ọba. Awọn amoye naa beere pe, “Nibo li ẹniti a bi ti iṣe ọba awọn Ju wà? nitori awa ti ri irawọ rẹ ni ila-õrùn, awa si wá lati foribalẹ fun u.” Dipo ki inu awọn eniyan dùn si iroyin iyanu yii, n ṣe ni wọn daamú. Ọba gbọ ọ, o si bẹrù pe boya ẹni kan ni o n fẹ gba ijọba oun. O gba ọrọ awọn amoye naa gbọ, nitori dajudaju awọn eniyan nlá bayii kò ni rin irin-ajo jijin naa lati wa wo ọmọ titun kan ni ilu ti ki i ṣe ti wọn bi kò ba ṣe pe wọn gbagbọ pe Ọlọrun ni O ti fun wọn ni iṣipayá kan pataki.

Hẹrọdu Ọba pe awọn olori alufaa ati awọn akọwe, awọn ẹni ti o mọ Ofin, o si beere bi akọsilẹ kankan ba wà ninu asọtẹlẹ nipa ọba ti a ni lati bi ni akoko yii; bi o ba si ri bẹẹ, nibo ni a o bi i si. Kò pẹ ki wọn to ri ẹsi. Wọn kà a: “Iwọ Bẹtlẹhẹmu ni ilẹ Judea, iwọ kò kere julọ ninu awọn ọmọ alade Juda, nitori lati inu rẹ ni Bãlẹ kan yio ti jade, ti yio ṣe itọju Israẹli awọn eniyan mi.”

Hẹrọdu dibọn pe oun fẹ lọ juba “Bãlẹ” naa ti awọn amoye n wá, o si pe wọn si ikọkọ o si sọ fun wọn ohun ti awọn wolii ti sọ. O wi pe ki wọn lọ si Bẹtlẹhẹmu ki wọn si wá ọmọ-ọwọ naa ri, ki wọn si tun wa jiṣẹ fun oun ki oun ba le juba Rẹ.

Irawọ Amọna

Awọn amoye naa tẹ siwaju lẹsẹ kan naa. Si kiyesi i, irawọ naa tun wà niwaju wọn. Bawo ni inu wọn ti dùn to lati mọ pe Ọlọrun wà pẹlu wọn, O si n ṣamọnà wọn sibẹ lọ si ọdọ Olugbala! Ọlọrun ko jẹ fi ẹnikẹni ti o ba fẹ ri Jesu silẹ lati maa nikan rin kiri ninu okunkun. Oun yoo rán imọlẹ lati tọ ẹni naa si otitọ.

Bẹtlẹhẹmu jẹ ilu kekere ti kò jinna si Jerusalẹmu, kò si pẹ ki awọn amoye naa to de ibẹ. Nibẹ ni wọn si ri imọlẹ lati ọdọ irawọ iyanu naa, o tàn sori ile ti Jesu wà pẹlu awọn obi Rẹ. Awọn amoye naa ti i ṣe eniyan pataki ninu ayé, wọ ibugbé irẹlẹ naa, wọn si ba búrúbúrú niwaju Ọmọde kekere naa. Wọn tú awọn iṣura iyebiye ti wọn mu wá, wọn si fi tifẹtifẹ ọkàn wọn ta A lọrẹ. Awọn ọkunrin ilẹ ajeji wọnyii gbà ibukun Ọlọrun ṣiwaju awọn alufaa ati akọwe, ti kò mọ Ọba wọn.

Gbigbe Jesu Sa Lọ

Ọlọrun kilọ ninu alá fun awọn amoye naa ki wọn má ṣe pada sọdọ Hẹrọdu; wọn si gbà ọnà miran lọ si ilu wọn. Hẹrọdu reti ipadabọ won titi, lati wa sọ fun un ibi ti o ti le ri Jesu, Ẹni ti o n fẹ lati parun. Nikẹhin o ri i pe wọn kò fẹ lat pada. O binu, o si rgo wi pe yoo ṣe e ṣe sibẹsibẹ fun oun lati ṣe Jesu ni jamba. O paṣẹ pe ki awọn iranṣẹ rẹ lọ pa gbogbo awọn ọmọ wẹwẹ, lati ọmọ ọdun meji si isalẹ, o n rò pe dajudaju Jesu kò ni ṣai pẹlu. Ṣugbọn Ọlọrun ti ṣe itọju Ọmọ Rẹ daradara, O si wà ni Egipti pẹlu baba ati iya Rẹ, Josẹfu ati Maria, nigbà ti iwà ika buburu jai yii n ṣẹlẹ ni Jerusalẹmu.

Ọlọrun ti kilọ fun Josẹfu pe Hẹrọdu yoo ṣe jamba; nitori naa ni ọjọ kan Josẹfu yọ lọ pẹlu ẹbi rẹ kekere yii, o si mu wọn lọ jinnà si ewu. Wọn jẹ talaka, lai ṣe aniani ẹbun awọn amoye naa ràn wọn lọwọ ninu irin-ajo wọn si Egipti. Nibẹ ni wọn wà titi Hẹrọdu ọba fi kú. Nigbà gbogbo ti Ọlọrun ba sọrọ ni Josẹfu n tẹti silẹ, o si ṣe ohun ti o ba gbọ. Nigbà ti ọba naa kú, Ọlọrun sọ fun Josẹfu pe ki o pada si Judea, ki o si maa gbé ni ilu Nasarẹti, ni imuṣẹ Iwe Mimọ ti o sọ pe a o maa pe Jesu ni ara Nasarẹti. Nibẹ ni Ọmọ naa ti dagba. A kò gbọ nipa Rẹ mọ titi O fi pe ọmọ ọdun mejila, nigbà ti a ba A ni Tẹmpili ti O n kọ awọn amòfin.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Nibo ni a ti bi Jesu?
  2. Ta ni kede ibi Rẹ?
  3. Ta ni gbọ ikede naa?
  4. Ki ni wọn ṣe lẹyin ti wọn gbọ ikede naa?
  5. Awọn wo ni Ọlọrun tun fi hàn pe a ti bi Jesu? Bawo?
  6. Ki ni wọn ṣe nigbà ti wọn gbọ nipa rẹ?
  7. Nibo ni awọn amoye ti beere Jesu?
  8. Bawo ni wọn ṣe mọ ibi ti wọn yoo lọ lati Jerusalẹmu?
  9. Ki ni Hẹrọdu fẹ ṣe si Jesu?
  10. Bawo ni Jesu ṣe bọ?