Ẹksodu 19:3-8; 34:27, 28; Deuteronomi 4:12, 13; 5:2, 3; 11:8, 9

Lesson 158 - Senior

Memory Verse
“Ofin ti jẹ olukọni lati mu ni wá sọdọ Kristi, ki a le da wa lare nipa igbagbọ” (Galatia 3:24).
Notes

Mose si goke tọ Ọlọrun lọ, OLUWA si kọ si i lati oke na wá wipe, Bayi ni ki iwọ ki o sọ fun ile Jakọbu, ki o si wi fun awọn ọmọ Israẹli pe;

Ẹnyin ti ri ohun ti mo ti ṣe si awọn ara Egipti, ati bi mo ti rù nyin li apa-iyẹ idi, ti mo si mú nyin tọ ara mi wá.

Njẹ nisisiyi, bi ẹnyin ba fẹ gbà ohùn mi gbọ nitõtọ, ti ẹ o si pa majẹmu mi mọ, nigbana li ẹnyin o jẹ iṣura fun mi jù gbogbo enia lọ: nitori gbogbo aiye ni ti emi.

Ẹnyin o si ma jẹ ijọba alufa fun mi, ati orilẹ-ède mimọ. Wọnyi li ọrọ ti iwọ o sọ fun awọn ọmọ Israẹli.

Mose si wá o si ranṣẹ pè awọn àgba awọn enia, o si fi gbogbo ọrọ wọnyi lelẹ niwaju wọn ti OLUWA palaṣẹ fun u.

Gbogbo awọn enia na si jùmọ dahùn, nwọn si wipe, Ohun gbogbo ti OLUWA wi li awa o ṣe. Mose si mú ọrọ awọn enia pada tọ Ọlọrun lọ” (Ẹksodu 19:3-8).

Nigba ti Abrahamu ṣe irubọ gẹgẹ bi Oluwa ti pa a laṣẹ, ti o si ṣe ifararubọ ti o jinlẹ ni igbesi-aye rẹ, apẹẹrẹ eyi ti awọn irubọ wọnyii i ṣe, gẹgẹ bi a ti kọ ọ silẹ ninu Gẹnẹsisi 15:9-11, Ọlọrun fẹ fi ohun ti yoo ṣẹlẹ nikẹyin si awọn ọmọ rẹ hàn an, ani iṣudẹdẹ ti o wà niwaju wọn. Nitori bi oòrùn ti n wọ lọ, oorun ijikà kun Abrahamu, “si kiyesi i, ẹru bà a, òkunkun biribiri si bò o.” Oluwa si wi fun un pe: “Mọ nitõtọ pe irú-ọmọ rẹ yio ṣe alejo ni ilẹ ti ki iṣe ti wọn, nwọn o si sìn wọn, nwọn o si jẹ wọn ni iya ni irinwo ọdún (Gẹnẹsisi 15:13). Ṣugbọn ileri ti Ọlọrun fi ti i lẹyin fi oyin si ikoro ti o ti ṣiwaju: “Ati orilẹ-ède na pẹlu, ti nwọn o ma sin, li emi o dá lẹjọ: lẹhin na ni nwọn o si jade ti awọn ti ọrọ pipọ” (Gẹnẹsisi 15:14).

Gbogbo nnkan wọnyii ni o ṣẹ kinnikinni. Isinrú kikorò ti o jẹ ti awọn Ọmọ Israẹli ni ilẹ Egipti, awọn akoni-ṣiṣẹ ti a fi ṣe oluwa wọn, ati ilagbà ti a fi nà wọn ti di ọrọ itàn nisisiyii. Bakan naa nigbà ti o ku diẹ ki irinwo ọdún ti a ti sọtẹlẹ nipa rẹ de opin, Oluwa, ni imuṣẹ ileri Rẹ, fi ara hàn Mose ninu igbẹ ti n jó. O si fi aṣẹ fun oun ati Aarọni arakunrin rẹ lati mu aṣẹ Rẹ ṣẹ, ki Oun ba le dá orilẹ-ède naa lẹjọ, ki O si le mu awọn eniyan Rẹ jade pẹlu ọwọ lile ati ọwọ agbara. Nigba ti Mose ati Aarọni de iwaju Farao, ti wọn si wi fun un pe: “Bayi ni OLUWA Ọlọrun Israẹli wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ”, ọba onigberaga yii dahùn pe “Tali OLUWA, ti emi o fi gbà ohùn rẹ gbọ?” Lati igbà naa lọ, gbogbo Egipti lati Farao lori itẹ rẹ titi de ọdọ awọn iranṣẹ rẹ ti o rẹlẹ ju lọ ninu pápá ni a fun ni anfaani nlá nlà lati mọ ẹni ti “OLUWA Ọlọrun Israẹli” i ṣe. Nitori nipa ọwọ Oluwa ni a gbé sọ oko wọn di aṣálẹ, awọn ohun-ọsin wọn n ṣegbe, lopin gbogbo rẹ, ni ile kọọkan, awọn akọbi kú lọ bẹẹrẹbẹ. Ṣugbọn ni Goṣeni, nibi ti a gbe fi ẹjẹ sara ibugbe wọn gẹgẹ bi aṣẹ Ọlọrun, ẹyọ ọkàn kan kò kú. Ni alẹ ọjọ naa, nigba ti akoko to, “li ọjọ na gan,” awọn Ọmọ Israẹli dide kánkán, wọn kó awọn ohun ini wọn ati awọn dukia ti awọn ara Egipti kó fun wọn jọ, wọn si jade lọ, “ti awọn ti ọrọ pipọ”, ọgbọn ọkẹ (600,000) eniyan lai kà awọn obirin ati awọn ọmọde. Kò si si alailera kan ṣoṣo laaarin wọn. Awọn wọnyii ni awọn ọmọ Abrahamu nipa ileri.

Israẹli: Ohun-èlò Lọwọ Ọlọrun

Ki a kàn ka Bibeli wàràwàrà lasan ṣá, yoo mu ki ẹnu ya awọn ẹlomiran pe ki ni ṣe ti Oluwa fi yọnda ki awọn eniyan wọnyii -- awọn eniyan Rẹ -- jiya pupọ to bẹẹ labẹ isinru ni ilẹ Egipti lai jẹ pe ẹṣẹ wọn ni o kó ba wọn ni akoko naa. Ṣugbọn ọna Ọlọrun yatọ si ti ọmọ eniyan. Niwọn bi o ti jẹ pe lati igbà ti Ọlọrun ti ba Abrahamu dá Majẹmu, ẹni ti O yàn lati ti ipasẹ rẹ “bukun fun gbogbo idile aiye” ni ọwọ Rẹ ti wà lara Israẹli, O yan Egipti ṣe ibi ti yoo gbe yiiri wọn wò fun ọgbọn-le-nirinwo ọdún ki Israẹli ba le jẹ ohun-elo ti a ti danwo “ohun-elo ipakà mimú,” ni ọwọ Rẹ lati mu ileri pataki ti O ti ṣe fun Abrahamu ṣẹ, pe, “ninu rẹ li a o ti bukun fun gbogbo idile aiye”(Gẹnẹsisi 12:3). Pẹlupẹlu, nipa ileri ti Ọlọrun ṣe fun awọn orilẹ-ède ayé, ni a kọ ọ pe, “Nigbati Ọga-ogo pin ini fun awọn orilẹ-ède, nigbati o tu awọn ọmọ enia ká, o pàla awọn enia na gẹgẹ bi iye awọn ọmọ Israẹli. Nitoripe ipin ti OLUWA li awọn enia rẹ; Jakọbu ni ipín iní rẹ” (Deuteronomi 32:8, 9). Oluwa yan Israẹli fun idi kan pataki ti o si logo pẹlu. Ṣugbọn nikẹyin o wa yé awọn eniyan wọnyii, gẹgẹ bi gbogbo awọn iranṣẹ Ọlọrun ti i maa n mọ pe lati sin Ọlọrun Israẹli ki i ṣe isin gbẹfẹ kan lasan.

Ṣugbọn, ohun miiran wà nipa iṣoro ati idanwo kikoro awọn Ọmọ Israẹli, gẹgẹ bi ọna iyanu ti a fi gbà wọn silẹ ni oko-ẹrú ti fi hàn. Ọlọrun dide fun igbala wọn, ki i ṣe nitori wọn fi bẹẹ yatọ si awọn orilẹ-ède miiran, tabi nitori O ri ohun rere kan ninu wọn. “Ẹni rere kan kò si bikoṣe ẹnikan, eyini li Ọlọrun.” Ṣugbọn O ṣaanu fun awọn eniyan ti a tẹ lori ba wọnyii, nitori O ranti Majẹmu Ayeraye ti O dá pẹlu Abrahamu, Isaaki ati Jakọbu. Nitori naa Ọlọrun boju wo ipọnju wọn O gbọ gbingbin wọn, O si fi ọwọ aanu nla Rẹ mu wọn jade kuro ninu inira ati iyà wọn. Bakan naa ni Israẹli gbà ohùn Rẹ gbọ, wọn si fi ẹjẹ sara atẹrigbà ati opo ilẹkun wọn, wọn kò si fara gbá ninu ikú akọbi ti o kọlu Egipti. Bayii ni Israẹli jade ti ẹjẹ naa ṣe aabo wọn. Iṣẹlẹ nlá nlà yii duro fun apẹẹrẹ idalare nipa igbagbọ titi di oni oloni.

Idande mani-gbagbe yii wá di kókó afiyesi pataki ninu itan igbesi aye awọn Ọmọ Israẹli, oun si ni kókó awọn orin iyin wọn si Ọlọrun. Ninu awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun ti o wà loke, a ka a pe “Ẹnyin ti ri ohun ti mo ṣe si awọn ara Egipti, ati bi mo ti rù nyin li apa-iyẹ idì, ti mo si mú nyin tọ ara mi wá” (Ẹksodu 19:4). Bayi Oluwa Jehofa, Ọlọrun oniṣẹ àrà, ṣe Israẹli ni “iṣura” fun ara Rẹ, ti a si wa mọ Ọ ni Ọlọrun Israẹli – nitori majẹmu ti O dá pẹlu Abrahamu.

Ṣugbọn okiki Ọlọrun kò pin si Israẹli. Itàn aanu ati idajọ Rẹ ni a kede fun awọn orilẹ-ède miiran. Wọn mọ ohun ti o ṣẹlẹ si awọn ara Egipti ati ibukun ti o jẹ ti Israẹli. Wọn mọ pẹlu pe Ọlọrun alagbara ni Oun i ṣe, wọn si bẹrù Rẹ ati awọn enian Rẹ. Imọlẹ ti mọ si wọn bi o tilẹ jẹ pe wọn n sin awọn oriṣa wọn sibẹ, wọn kò juba Rẹ, gẹgẹ bi awọn eniyan ti ode-oni ti n ṣe.

Oke Sinai

Awọn Ọmọ Israẹli de Oke Sinai ni oṣu kẹta, lẹyin ti wọn ti rin pupọ ni aginju ti aarẹ si mu wọn. Ṣugbọn Ọlọrun wọn n ṣe itọju wọn ni iṣisẹ kọọkan, O n daabo bo wọn, o si n fi ọwọn awọsanma ṣe amọna wọn ni ọsan ati ọwọn iná ni oru. Ninu aṣalẹ ti kò tilẹ si oko ọka, nigba pupọ, kò si omi, kò si igbó, kò si si igi eleso, ṣugbọn Ọlọrun wọn gbé wọn ró, O si fi manna lati Ọrun bọ wọn, ati omi lati inu apata.

Nisisiyii a paṣẹ fun wọn ki wọn tẹdo si pẹtẹlẹ Sinai, nitori oke yii yoo jẹ ami akoko pataki – igba titun – ninu ibalò Ọlọrun pẹlu Israẹli.

Majẹmu pẹlu Israẹli

Nigba ti Israẹli tẹdo siwaju Oke yii, ohun ti o tẹle e ni pe ki Mose goke tọ Oluwa lọ, ki o le gba itọni nipa awọn eniyan ti a yàn an lati ṣe akoso. “Mose si goke tọ Ọlọrun lọ, OLUWA si kọ si i lati oke na wá wipe, Bayi ni ki iwọ ki o sọ fun ile Jakọbu, ki o si wi fun awọn ọmọ Israẹli pe; Ẹnyin ti ri ohun ti mo ti ṣe si awọn ara Egipti, ati bi mo ti rù nyin li apa-iyẹ idì, ti mo si mú nyin tọ ara mi wá. Njẹ nisisiyi, bi ẹnyin ba fẹ gbà ohùn mi gbọ nitõtọ, ti ẹ o si pa majẹmu mi mọ, nigbana li ẹnyin o jẹ iṣura fun mi jù gbogbo enia lọ: nitori gbogbo aiye ni ti emi.”

Ọrọ wọnyii ti mu ni lọkan ṣinṣin to! Oṣu mẹta pere ni o ṣi kọja lẹyin ti Ọga-Ogo Julọ, Ọlọrun Abrahamu, Isaaki ati Jakọbu boju wolẹ lati Ọrun wá ti O si gba awọn eniyan ti n jiya wọnyii kuro ni oko-ẹrú Egipti. Iṣẹ agbara Rẹ ki i ṣe eyi ti a le tete gbagbe. Iran mẹrin ti dagba laaarin ibọriṣa, ṣugbọn nisisiyii, Ọlọrun awọn baba wọn ti fi ara Rẹ hàn, awọn ọlọrun Egipti kò si lagbara lati ran awọn ara Egipti lọwọ. Nisisiyii Ọlọrun kan naa yii ni O fẹ bá wọn dá Majẹmu. “Njẹ tani ẹnyin o ha fi mi we, tabi tali emi o ba dọgbà? ni Ẹni-Mimọ wi” (Isaiah 40:25).

Eyi ki i ṣe Majẹmu kan naa ti Ọlọrun bá Abrahamu baba wọn dá. Ohun kan naa ni o dè wọn – “bi ẹnyin ba fẹ gbà ohùn mi gbọ nitõtọ, ti ẹ o si pa majẹmu mi mọ” – ipinnu Ọlọrun sibẹ ni lati mu awọn ileri ti O ṣe fun Abrahamu ṣẹ; ṣugbọn nisisiyii, ninu ibalò Rẹ pẹlu Israẹli, igbesẹ miiran ninu Eto nla Ọlọrun fẹrẹ ṣipaya nipa Majẹmu yii, eyi ti O fi hàn fun Israẹli lọna kan naa ti O gbà sọ Majẹmu Rẹ di mimọ fun Abrahamu ni ṣisẹ n tẹle. Ni akoko yii, o fi ileri iyanu kan ti i lẹyin: “Ẹnyin o jẹ iṣura fun mi jù gbogbo enia lọ: nitori gbogbo aiye ni ti emi. Ẹnyin o si ma jẹ ijọba alufa fun mi, ati orilẹ-ède mimọ.”

O fẹrẹ jẹ pe ninu ọrọ kọọkan ti ó wà ninu ileri yii ni ifẹ Ọlọrun si Israẹli ti fara hàn gẹgẹ bi idande wọn kuro ni oko-ẹru Egipti ti ri pẹlu: “Bi mo ti rù nyin li apa-iyẹ idì, ti mo si mú nyin tọ ara mi wá.” Ati nisisiyii, “Ẹnyin o jẹ iṣura fun mi.” Awọn ọrọ ti o ṣọwọn wọnyii fi iru ibarẹ ati ibalo timọtimọ ti Israẹli yoo ni pẹlu Ọlọrun wọn hàn. Ju bẹẹ lọ, Oun yoo gbé wọn ga “jù gbogbo enia,” ati pe, “ẹnyin o si ma jẹ ijọba alufa fun mi ati orilẹ-ède mimọ.” Awọn ọrọ ti o kẹyin wọnyii fi ipè giga wọn hàn – lori adehùn kan yii pe wọn yoo gbọran si ofin Rẹ, wọn yoo si pa Majẹmu Rẹ mọ. Mose sọ ọrọ wọnyii fun wọn. “Gbogbo awọn enia na si jùmọ dahùn, nwọn si wipe, Ohun gbogbo ti OLUWA wi li awa o ṣe. Mose si mú ọrọ awọn enia pada to OLUWA lọ.” Bayii ni a fi idi Majẹmu Ọlọrun pẹlu Israẹli mulẹ, awọn ohun miiran ni a o si maa fi kun un fun wọn.

Ẹkọ yii kò pari tan patapata, Alufaa Charles R. Rodman ti o n ṣe e, jẹ ọkan ninu awọn ogbogi alufaa, olukọni ati olóòtú ọpọlọpọ awọn ẹkọ ti a ti ṣe kọja ninu Awọn Aṣayan Ẹkọ Bibeli, oun ni o bẹrẹ ti o si ṣe e de ibi ti o pari si yii ni ọsan ọjọ Iṣẹgun kan “Tuesday” ni aipẹ yii, lai si aniani, pẹlu ireti yii pe, oun yoo tun maa ba iṣẹ naa lọ ni owurọ ọjọ keji, bi Oluwa ba fa bibọ Rẹ sẹyin.

Arakunrin wa Rodman sunmọ Ọlọrun timọtimọ nigba ti o n kọ ẹkọ yii; eyi ti o ṣiwaju eyi ti a n pe ni “Majẹmu Ọlọrun pẹlu Abrahamu.” O mọ bi ẹkọ naa ti jinlẹ to o si gbadura gidigidi nipa awọn ẹkọ wọnyii. O n gbe igbesi-aye awọn ẹkọ wọnyii titi wọn fi di ara fun un. O fi n ṣe ọrọ sọ fun gbogbo awọn ti o wà yi i ká. O waasu nipa awọn ẹkọ wọnyii pẹlu. O sọrọ nipa rẹ fun awọn akẹkọọ Bibeli ti o wà labẹ rẹ. Fifi ara mọ ọn timọtimọ mu ki igbesi-aye rẹ ati iṣẹ iranṣẹ rẹ larinrin lọpọlọpọ. O mu un lọkan gidigidi to bẹẹ gẹẹ -- awọn ilana ati anfaani rẹ -- ti o fi rin sun mọ Ọlọrun pẹkipẹki ni awọn ọsẹ diẹ ti o kẹyin ọjọ aye rẹ.

Ni owurọ ọjọ keji, bi arakunrin wa Rodman ti n lọ si ibi iṣẹ, o ni lati jẹ pe Ọlọrun boju wolẹ lati Ọrun wá, O si wi pe, “ṣiwọ iṣẹ!” Pẹlu iru ẹmi kan naa, o tilẹ fẹrẹ jẹ lọna kan naa gẹgẹ bi ti ọkan ninu awọn eniyan mimọ ti igbà nì, ni eniyan Ọlọrun yii fi fi ayé yii silẹ lati lọ wà pẹlu Ọlọrun. O jẹ itunu ati iwuri fun wa pe nisisiyii o n sọrọ nipa Majẹmu Ayeraye pẹlu awọn eniyan mimọ ati awọn patriaki o si n fi iyin fun Ọdọ-Agutan Ọlọrun ti O fi ẹmi Rẹ lelẹ ki ẹlẹṣẹ le là.

Iwaasu ti a tẹ si isalẹ yii ni iwaasu ti eniyan Ọlọrun yii ṣe kẹyin ni iya Ijọ wa ni Amẹrika, ni iwọn iba ọjọ diẹ ṣiwaju iku rẹ. Iwaasu yii ati Ẹkọ 159 ni o ṣe aṣepari àlaye ti ẹkọ yii kò mẹnu kàn.”

MAJẸMU AYERAYE

Ẹ tẹtilelẹ, ki ẹ si wá sọdọ mi: ẹ gbọ, ọkan nyin yio si yè: emi o si ba nyin dá majẹmu ainipẹkun, ānu Dafidi ti o daju.

Kiye si i, emi ti fi on fun awọn enia fun ẹlẹri, olori ati alaṣẹ fun awọn enia.

Kiyesi i, iwọ o pe orilẹ-ède ti iwọ kò mọ, ati orilẹ-ède ti kò mọ ọ yio sare wá sọdọ rẹ, nitori Oluwa Ọlọrun rẹ, ati nitori Ẹni-Mimọ Israẹli; nitori on ti ṣe ọ li ogo” (Isaiah 55:3-5).

Kò ṣoro fun ni rara lati mọ ẹni ti Woli Isaiah n kọwe nipa Rẹ nihin yi. Ki i ṣe ẹlomiran bi kò ṣe Jesu Kristi Oluwa.

Ni iwọn nkan bi ẹẹdẹgbẹrin (700) ọdun ṣiwaju ibi Jesu ni eyi, ṣugbọn kaakiri ninu Majẹmu Laelae yi ni asọtẹlẹ wa nipa Jesu. Awọn Ju mọ Ọn ni Messia ti o n bọ wa; awa mọ Ọn ni Ẹni Ami Ororo Oluwa, ani Kristi.

Nigba kan Jesu sọ fun awọn Ju ti o wà lọdọ Rẹ wi pe: “Ẹnyin nwá inu Iwe-mimọ, nitori ẹnyin rò pe ninu wọn li ẹnyin ni iye ti kò nipẹkun; wọnyi si li awọn ti njẹri mi” (Johannu 5:39). Koko Ofin ati awọn woli ni Jesu Kristi.

Nihin a fun wa ni apejuwe ti o peye nipa akoko ti wa yi. “Iwọ o pe orilẹ-ède ti iwọ kò mọ, ati orilẹ-ède ti kò mọ ọ yio sare wá sọdọ rẹ, nitori Oluwa Ọlọrun rẹ, ati nitori Ẹni-Mimọ Israẹli.” Awọn Keferi ni eyi n tọka si.

Eyi ni o ṣi ọna fun awọn Keferi, nigba ti a bi Jesu ni Bẹtlẹhẹmu, nipasẹ Ẹni ti a le mu wọn wọ Ijọba Ọlọrun. Eyi nì ni Eto nla ti Ọlọrun ti ṣe lati igba Majẹmu Laelae. Nigba naa, awọn Ju nikan ni O ba lò; ṣugbọn akoko n bọ ti kò ni si idabu mọ, gbogbo ohun idabu ni a o mu kuro, oore-ọfẹ Ọlọrun yoo kari gbogbo agbaye.

O n sọ nipa Majẹmu Ayeraye nihin yi. Ki i ṣe Majẹmu ti a ba awọn Ọmọ Israẹli dá ni Oke Sinai ni Isaiah n sọrọ ba nihin; a kò pe e ni Majẹmu Ayeraye. Majẹmu naa ni awọn Ju kunà lati pamọ, a si pa a tì. Ṣugbọn a kò ni pa Majẹmu yi tì; yoo wa titi ayeraye. A fi ẹjẹ malu ati ewurẹ ṣe edidi Majẹmu ti igba nì ti a dá pẹlu awọn Ọmọ Israẹli nigba ti a fun wọn ni Ofin ni Oke Sinai; ṣugbọn Ẹjẹ Jesu ni a fi ṣe edidi Majẹmu Ayeraye. Ẹjẹ Rẹ ti a ta silẹ ni a fi fi idi Majẹmu naa mulẹ.

Ọlọrun ti ṣe eto Majẹmu yi lati ibẹrẹ, ṣugbọn a ni lati mu ki awọn Ọmọ Israẹli kẹkọ fun ọdún pupọ ninu irinkiri wọn ni aginju ati ni Ilẹ Ileri pẹlu. Olukọni ni i ṣe lati mu wọn wa sọdọ Kristi. Eredi naa ni eyi. Kristi ni imuṣẹ Majẹmu Laelae; Oun ni imuṣe Ofin. O pa a mọ perepere; O si rin ninu gbogbo rẹ. Lati igba ti aye ti ṣẹ, Oun nikan ṣoṣo ni O ṣe bẹẹ. Bi o ti wu ki eniyan le ṣogo to ninu iwa rere, inu rere, ati itọrẹ aanu rẹ, oun kò mu gbogbo ohun ti Ọlọrun bere ṣẹ. Ṣugbọn Jesu Oluwa mu un ṣẹ. Awọn ọta-iyọta Rẹ tilẹ sọ pe wọn kò ri buburu kan ninu Rẹ. Pilatu wẹ ọwọ rẹ, o gbiyanju lati wẹ ẹbi kuro lori ara rẹ nitori pe o fi Jesu Kristi Oluwa le wọn lọwọ lati pa A.

Nitori naa, a le ri i pe, lati ayebaye ni a kò ti le ri ohun buburu kan ninu Rẹ. O duro gedegede lati ayebaye bi Ẹni ti a kò ri ẹsùn kan si; bẹẹ ni ẹsùn kankan kò si le fẹsẹ mulẹ nipa Rẹ.

A ni Majẹmu kan ti Ọlọrun tikara Rẹ gbé kalẹ, ohun iyebiye ni O san lati gbe e kalẹ. Eyi ni o mu Jesu Oluwa lọ sori oke Kalfari ti a si kan An Mọ agbelebu nibẹ, nitori pe nia Ẹjẹ ti a ta silẹ, nipa Ẹmi Rẹ ti O fi lelẹ, ki a le dá Majẹmu kan – ki i ṣe pẹlu awọn Ju nikan ṣugbọn pẹlu gbogbo araye, nipasẹ eyi ti wọn le fi ba Ọlọrun laja.

Majẹmu yi ni lati dí ọgbun ti o wà laarin Ọlọrun ati eniyan, eyi ti ẹṣẹ mu wá, ti o ya eniyan ya Ọlọrun. Ọna kan ṣoṣo ti a le fi mu iyapa yi kuro ni nipa gbese ti Jesu san, Ẹjẹ ti O ta silẹ, ẹbọ ti O fi ara Rẹ ru, Etutu ti O ṣe nipasẹ eyi ti iwọ ati emi fi le ba Ọlọrun laja.

Ohun pataki ni lati ba Ọlọrun laja. Ẹṣẹ ni o n ya eniyan ya Ọlọrun, awọn ẹṣẹ pupọ ti o wà ni igbesi aye wa. Ẹni kọọkan wa, ohunkohun ti o wu ki a jẹ ni ti ipo, a o maa boju wo ẹhin wo igbesi aye wa atẹhinwa bi alakala. Bẹẹ ni o si ri. A jẹ alejo si ọlọtọ Israẹli, alejo si Majẹmu ti ileri, lai ni ireti ati lai ni Ọlọrun ni ayeyi.

Ohun iyanu ni pe Ọlọrun ti lana silẹ, nipasẹ eyi ti ọmọ eniyan le fi bọ lọwọ ẹṣẹ ki o si ba Ọlọrun laja, jù gbogbo rẹ lọ, ki a si fi ifẹ Rẹ sinu ọkàn -- ifẹ si Ọlọrun ati ifẹ si eniyan. Ofin ifẹ ni ofin titun ti igba oore-ọfẹ.

Oun yoo jẹ Ẹlẹri, Alakoso, ati Balogun. A le sọ pe ogun jijà ni eyi jasi nipasẹ eyi ti Oun yoo ṣiwaju awọn eniyan Rẹ lati ja ija rere ti igbagbọ ki O si ṣẹgun. Nigba ti O ba si ti gbe Majẹmu yi kalẹ, ohun ti o tẹle e ni lati ro ọna ti a le fi ni ipin ninu Majẹmu naa. A kò ṣalai sọ eyi ninu Ọrọ Ọlọrun. Ninu ori iwe yi kan naa a kà a pe:

Jẹ ki enia buburu kọ ọna rẹ silẹ, ki ẹlẹṣẹ si kọ ironu rẹ silẹ: si jẹ ki o yipada si OLUWA, on o si ṣānu fun u, ati si Ọlọrun wa, yio si fi jì ĩ li ọpọlọpọ.”

Ohun ti kò ṣoro ni eyi jẹ. Oye rẹ le yé ọmọ ọdún mẹrin. Itumọ rẹ ni pe ki a jẹwọ gbogbo ẹṣẹ wa ki a si kọ wọn silẹ, ki a si yi pada si Oluwa. Nipa bayi ni ẹni naa yoo fi ba Oluwa da Majẹmu, Majẹmu ayeraye ti yoo gbe e de ibode Ọrun. Eyi ni ileri ti a ṣe: “Eleyi li emi o wò, ani òtoṣi ati oníròbinujẹ ọkàn, ti o so nwariri si ọrọ mi” (Isaiah 66:2). Ọlọrun yoo gbọ adura ẹni naa. Ki adura naa to jade ni ẹnu rẹ tan ni idahùn yoo ti de wi pe, “A dari ẹṣẹ rẹ ti o pọ ji ọ.” A nu irekọja rẹ nù! Akọsilẹ rẹpẹtẹ ti a ti kọ nipa rẹ ni Ọrun – nitori pe Ọlọrun ni akọsilẹ -- a ti nù wọn kuro patapata, ko kù nkan kan rara. Gbogbo rẹ ti parẹ patapata! A da ẹni naa lare niwaju Ọlọrun Ọga-ogo Julọ bi ẹni pe kò tilẹ da ẹṣẹ ri rara.

Awọn ẹlomiran ro pe ohun ṣeréṣeré kan ṣa ni lati ba olọrun laja, wọn ro pe kò ju pe ki wọn kan yi ero wọn pada. A dupẹ lọwọ Ọlọrun pe bẹẹ ni o ri, o si tun ju bẹẹ lọ. O tumọ si pe Ọlọrun ti ṣiṣẹ iyanu ti iyipada ninu ọkàn rẹ. Kò ṣẹṣẹ di igba ti o ba gbọ ẹri pupọ ki eyi to ye ọ. Fun apẹẹrẹ, jẹ ki a wo ọkunrin kan ti o mookun ninu ẹṣẹ ti o si n mu ẹṣẹ bi ẹni mu omi, ti o buru jayi, ṣugbọn ki a wa ri i, ki o si maa gbe igbesi aye ọtun, ohun atijọ ti kọja lọ, ẹṣẹ kò si mọ rara. Iṣẹ iyanu ni eyi jẹ!

Mo jẹ ọkan ninu awọn, oniwaasu ti Ọlọrun yi pada. Mo kọ iṣẹ oniwaasu, ṣugbọn n kò mọ Ọlọrun. Mo jẹ ajeji si majẹmu ileri. N kò ni gbagbe alẹ ọjọ ti mo ke pe Ọlọrun lori eekun mi pe, “Ọlọrun ṣānu fun emi ẹlẹṣẹ.” Idahun si de. Iṣẹ naa ṣe! Mo jade kuro ninu agọ ti a ti nṣe ipade Ajọ-Agọ, ni aṣaalẹ ọjọ naa, mo si n lọ sile; ha, mo bọ si ayé titun! Ayọ Ọrun ti wọ inu ọkan mi, alaafia bi idakẹ rọrọ lẹhin iji. Iji ti rekọja. Alaafia yi wà nibẹ sibẹsibẹ. Ayọ Oluwa wa ninu ọkàn mi sibẹ. Lati ọdun mẹrindinlogoji. Mo wà labẹ Majẹmu Ayeraye, a ra mi pada nipa itoue Ẹjẹ Jesu Kristi. Nibẹ ni n o si wà, nipa oore-ọfẹ Ọlọrun, niwọn igba ti mo ba n rin ninu imọlẹ.

Nibo miran a ka a pe, “Iwọ má bẹru; nitori mo wà pẹlu rẹ; má foyà; nitori emi ni Ọlọrun rẹ: emi o fun ọ ni okun; nitõtọ, emi o ràn ọ lọwọ; nitõtọ, emi o fi ọwọ ọtun ododo mi gbé ọ sokè” (Isaiah 41:10). Eyi ni ileri ti a ṣe fun ẹni ti a ti ra pada, pe Ọlọrun yoo fun un ni okun, yoo di i mu, yoo si pa a mọ. Ohun iyanu ni, ani afo ti Jesu Oluwa di ni igbesi aye ẹni ti a ti ra pada.

A sọ fun ni ninu Iwe Mimọ pe a fi ṣe “ọgbọn ati ododo, ati isọdimimọ, ati idande fun wa” (I Kọrinti 1:30). Jesu Kristi di ohun gbogbo ninu ohun gbogbo. A si ni anfaani iyebiye lati sinmi le apa ayeraye Rẹ, ki a si mọ agbara Rẹ ti o n fun ni lokun ati ọwọ Rẹ ti o n gbé ni ro.

Wò iranṣẹ mi, ẹni ti mo gbéro: ayànfẹ mi, ẹniti inu mi dùn si; mo ti fi ẹmi mi fun u: on o mu idajọ wá fun awọn Keferi.

On ki yio kigbé, bẹẹni ki yio gbé ohùn soke, bẹẹni ki yio jẹ ki a gbọ ohun rẹ ni igboro.

Iye fifọ ni on ki yio ṣẹ, owú ti nrú ẹẹfin ni on ki yio pa: yio mu idajọ wá si otitọ.

“rẹ ki yio mú u, a ki yio si daiyà fò o, titi yio fi gbé idajọ kalẹ li aiye: awọn erekùṣu yio duro de ofin rẹ” (Isaiah 42:1-4).

Akoko okunkun ni a wà yi. Nigba ti wọn n ba Jesu ṣẹjọ, O wi fun awọn olufisun Rẹ pe: “Akokò ti nyin li eyi, ati agbara òkunkun.” Igbà ti Jesu gbadura ni Gẹtsemane pẹlu jẹ akoko iṣudẹdẹ. Irú iṣudẹdẹ bẹẹ n bọ lori aye loni. Agbara okunkun fẹ bori aye paapaa julọ awọn ọmọ Ọlọrun. Ṣugbọn a ni Ẹni kan ẹni ti i ṣe ilu olodi wa, Odi Agbara wa, ati Asa wa. A si o daju pe ni akoko ikẹhin yi, ti ọta n gbogun, ti o si n ta ọfa gbigbona rẹ si awọn ọmọ Ọlọrun, Oun ni Ẹni ti awa gbagbọ pe O le mu wa la a ja.

Iwe Mimọ sọ fun ni pe iyè fifọ ni Oun kì yoo ṣẹ, owu ti n rú eefin ni Oun ki yoo pa. O pẹ ni, o ya ni, olukuluku yoo di iyè fifọ. Akoko n bọ ti oun yoo de opin ipa ọna rẹ, nihin gan an ni Jesu Oluwa gbe ṣetan lati dide fun iranlọwọ rẹ, lati gbe e dide, lati gba a kuro ninu ẹṣẹ ati iaṣe deedee rẹ, ki O si fi iṣẹgun ati alaafia fun un.

Bi akoko kan ba wà lati igba ti aye ti ṣẹ ti a ni lati ni in, akoko yi gan an ni. Bi iwọ ba jẹ ọkan ninu awọn ti kò ti ni in, jẹ ki o da ọ loju pe bi iwọ ba tọ Ọlọrun wa, ti o si ṣe ohun ti O ba wi fun ọ nipa Majẹmu Ayeraye yi, Oun yoo gbọ adura rẹ, yoo si da ọ lohun.