Gẹnẹsisi 13:14-18; 15:18-21; Ẹksodu 6:1-8; Lefitiku 26:3-9

Lesson 160 - Senior

Memory Verse
“Emi o si fi ilẹ ti iwọ ṣe alejo nibẹ fun ọ, ati fun irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ, gbogbo ilẹ Kenaani ni ini titi lailai; emi o si ma ṣe Ọlọrun wọn” (Gẹnẹsisi 17:8).
Notes

Awọn Ju

Itan ati ibẹẹrẹ awọn eniyan ti ogunlọgọ wọn n pada si Israẹli ilu wọn nisinsinyi (Israẹli ti o ṣẹṣẹ di orilẹ-ède ni Palẹstini) lati ọpọlọpọ orilẹ ati ède agbaye, ti bẹrẹ lati akoko patriaki Abrahamu ni nnkan bi ẹgbaa ọdun o le aadoje din mẹrin (2,126) ṣiwaju ibi Jesu Oluwa wa si ori ilẹ aye. Abrahamu ni Ju kinni; Isaaki ọmọ rẹ si ni akọbi Ju. Bi a ba ka Gẹnẹsisi 17:15-17 a o ri i pe ipilẹṣẹ awọn eniyan wọnyi jẹ iyanu, bakan naa ni wọn jẹ iyanu lati igba nì titi di oni-oloni.

Ileri Ọlọrun fun Abrahamu

Awọn ọrọ wọnyi wà ninu Majẹmu ti Ọlọrun ba Abrahamu dá:

OLUWA si wi fun Abramu, lẹhin igbati Lọti yà kuro lọdọ rẹ tan pe, Gbé oju rẹ soke nisisiyi, ki o si wò lati ibiti o gbé wà ni lọ, si iha ariwa, ati si iha gusu, si iha ila-õrùn, ati si iha iwọ-õrun:

Gbogbo ilẹ ti o ri ni, iwọ li emi o sa fi fun ati fun irú ọmọ rẹ lailai.

Emi o si ṣe irú-ọmọ rẹ bi erupẹ ilẹ: tobẹẹ bi o ba ṣepe enia kan ba le kà iye erupẹ ilẹ, on li a o to le kaye irú-ọmọ rẹ pẹlu.

Dide, rin ilẹ na já ni ina rẹ, ati ni ibú rẹ nitori iwọ li emi o fi fun.

Nigbana ni Abramu ṣi agọ rẹ, o si wá o si joko ni igbo Mamre, ti o wà ni Hebroni, o si tẹ pẹpẹ kan nibẹ fun OLUWA” (Gẹnẹsisi 13:14-18).

Majẹmu nla Ọlọrun pẹlu awọn eniyan wọnyi ni a kọkọ ba Abramu da ni Gẹnẹsisi 12:1-7. Awọn ohun ti o jẹ koko ninu Majẹmu naa ni pe: ilẹ kan yoo jẹ ini ti Abramu; orilẹ-ède nla kan yoo ti inu Abramu jade; ibukún Ọlọrun yoo maa ba a gbe; a o fun un ni orukọ nla kan; oun yoo jẹ ẹni ibukun Ọlọrun yoo maa ba awọn ẹni ti o ba sure fun Abramu gbe, ègun Ọlọrun yoo si wà lori ẹni ti o ba fi Abramu bú; ati pẹlu gẹgẹ bi a ti mọ wi pe nipasẹ Abramu ni a o ti bukun fun gbogbo idile aye, lọna bayi pe, ninu iran Abramu ni Jesu, Ẹbọ Pipe naa yoo ti jade wá.

Majẹmu pẹlu Abrahamu jẹ ti Ayeraye

Lẹhin eyi, nigba ti Ọlọrun yoo fi idi Majẹmu ti O ba Abrahamu dá ninu Gẹnẹsisi 17:1-8 mulẹ, Oluwa wi pe Majẹmu naa yoo jẹ Majẹmu ayeraye laarin Oun ati Abrahamu ati irù-ọmọ rẹ. Gbogbo ilẹ Kenaani ni a o fi fun un ati irú ọmọ rẹ ni ini titi laelae.

Ni awọn igba miran lẹhin eyi, ti Ọlọrun tun fi idi Majẹmu kan naa mulẹ pẹlu Abrahamu (Gẹnẹsisi 15:18-20), ati pẹlu Isaaki (Gẹnẹsisi 26:1-5), ati pẹlu Jakọbu (Gẹnẹsisi 28:10-15; 35:10-12), awọn ajogun ileri kan naa pẹlu Abrahamu, O tẹnu mọ ọn pe titi laelae ni Oun fun wọn ni ilẹ naa ti a fi fun wọn ni ini yii, ju bẹẹ lọ O si tun fi òye ye wọn bi ilẹ naa ti tobi to.

Li ọjọ na gan li OLUWA bá Abramu dá majẹmu pe, irú-ọmọ rẹ ni mo fi ilẹ yi fun, lati odò Egipti wá, titi o fi de odò nla nì, odò Euferate:

Awọn enia Keni, ati awọn enia Kenissi, ati awọn enia Kadmoni,

Ati awọn enia Hitti, ati awọn enia Perissi, ati awọn Refaimu,

Ati awọn enia Amori, ati awọn enia Kenaani, ati awọn Girgaṣi, ati awọn Jebusi” (Gẹnẹsisi 15:18-21).

(Fun òye kikún nipa bi ati fi ilẹ naa fun wọn ni ipilẹṣẹ, lọ ka Ẹksodu 23:31; Numeri 34; Deuteronomi 11:24; 34:1-4; Joṣua 1:2-6).

Bi Ilẹ Wọn Yoo ti Pọ Tó

Lati inu awọn ẹsẹ ọrọ Ọlọrun ti a tọka si wọnyi, a là wá lóye yekeyeke nipa aala ilẹ-ini awọn Ọmọ Israẹli. “Irú-ọmọ rẹ ni mo fi ilẹ yi fun, lati odò Egipti wá, titi o de odo nla nì, odò Euferate.” Ninu Ẹksodu 23:31 a ṣe apejuwe aala ilẹ naa fun wa bayii: “Emi o si fi opinlẹ rẹ lelẹ, lati Okun Pupa wá titi yoo fi dé okun awọn ara Filistia, ati lati aṣalẹ nì wá dé odò nì; nitoriti emi o fi awọn olugbe ilẹ na lé nyin lọwọ; iwọ o si lé wọn jade kuro niwaju rẹ.” Awọn Ọmọ Israẹli ni lati lé awọn olugbe ilẹ naa jade ki wọn si gba a. Iṣẹgun wọn lori Ilẹ Kenaani yoo jẹ ti idajọ ati mu ileri ti Ọlọrun ṣe fun Abrahamu, Isaaki ati Jakọbu ṣẹ. A ran Israẹli si ilẹ naa lati pa awọn orilẹ-ède ti kò bikita fun ọpọlọpọ ọdún lai ronupiwada ki wọn si yipada kuro ninu ibọriṣà ati iwa ẹṣẹ wọn.

Ni akotan, eyi ni aala Ilẹ Ileri: Oke Lebanoni ni ihà ariwa; Odo Euferate ni ihà oke ila-oorun; aṣálẹ Arabia ni ihà ila oorun; Okun Pupa ati Odo Egipti ni ihà gusu; ati Okun Filistini; Mẹditerranean ni ihà iwọ-oorun.

Ilẹ yi kò fi igbà kan jẹ ti Israẹli gan an ni ọna ti Ọlọrun pinnu rẹ (Numeri 33:51-56). Wọn kò lé gbogbo olugbe ilẹ naa jade patapata (Joṣua 23:11-13; Awọn Onidajọ 2:1-5; Orin Dafidi 106:34, 35); bẹẹ ni Ọlọrun si ti tẹnu mọ ọn gidigidi pe awọn abọriṣa wọnyi kò gbọdọ ba awọn eniyan Rẹ gbe ilẹ naa (Ẹksodu 23:33). Sọlomọni ọba jọba lori gbogbo ilẹ wọnyi, ṣugbọn a kò gbọdọ gbagbé pe laarin awọn ẹkùn ilẹ wọnyi ijọba pupọ ni o wà. Sọlomọni n jọba lapapọ lori awọn ijọba kekeke wọnyi; awọn ijọba Siria, Damasku, Moabu ati Amoni ti o wà laarin Euferate ati Mediterraneani. O dabi ẹni pe awọn ilu ti a tẹri wọn ba wọnyi ni ijọba ati iṣelu ti wọn gẹgẹ bi wọn ti ni in tẹlẹ, ṣugbọn o ṣe dandan ki wọn mu owó ati awọn nnkan ti o niye lori miran lọ fun Sọlomọni ni ọdọọdún. Ṣugbọn igba n bọ ti Israẹli yoo gba ilẹ ini rẹ patapata. Yoo si to fun ibugbe wọn bi wọn tilẹ pọ bi “erupẹ ilẹ.” Ọrọ aileyipada ti Ọlọrun ti sọ tẹlẹ yoo ṣẹ dandan.

Nipa Igbọran ni Wọn Yoo Gba Ilẹ Naa

A ri i nisinsinyi pe Ẹni ti O ni ilẹ lati ipilẹṣẹ aye ti ṣe iwe ini-ilẹ fun awọn Ju gẹgẹ bi oluwa ilẹ Palẹstini. A le ri iwe ini-ilẹ yi kà ninu ẹgbaagbeje Bibeli ti a ti tẹ ni ailonkà ède jakejado gbogbo agbaye. Kò si orilẹ-ède miran aye ti a ti i fun ni iru iwe ini-ilẹ bayi. Nigba ti a n kà iwe itan awọn eniyan agbaye, a ri i pe, nigba pupọ ni o ṣe pe wọn jagun gba ilẹ-ini wọn ni, ṣugbọn ilẹ Kenaani jẹ ti Israẹli nitori pe Ọlọrun ni o fi i fun wọn. Iwe ini-ilẹ yanju kedere lati nnkan bi ẹgbaaji (4,000) dun ṣehin. “Gbé oju rẹ soke nisisiyi, ki o si wò lati ibi ti o gbé wà ni lọ, si iha ariwa, ati si iha gusu, si iha ila-õrun ati si iha iwọ-õrùn: gbogbo ilẹ ti o ri nì, iwọ li emi o sa fi fun ati fun iru-ọmọ rẹ lailai” (Gẹnẹsisi 13:14, 15).

Awọn iran Abrahamu ni lati wà ni ilẹ wọn ki wọn to le ri awọn ibukun wọnyi gbà ni kikún (Deuteronomi 28:1-14). A ṣeleri fun wọn wi pe wọn yoo wà titi ni Ilẹ Ileri: “Yio si ṣe, bi iwọ ba farabalẹ gbọ ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma kiyesi ati ṣe aṣẹ rẹ gbogbo ti mo pa fun ọ li oni, njẹ OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé ọ ga jù gbogbo orilẹ-ède aiye lọ: Gbogbo ibukun wọnyi yio si ṣẹ sori rẹ, yio si bá ọ, bi iwọ ba fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ.”

Aigbọran yoo fa Ijiya Ikolọ

Ninu Deuteronomi 28 ati Lefitiku 26 a ri i pe Oluwa fi ègun lé ilẹ ati awọn olugbe rẹ lori bi wọn ba ṣaigbọran. Deuteronomi 28:15 sọ fun ni pe: “Yio si ṣe bi iwọ kò ba fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati mā kiyesi ati ṣe gbogbo aṣẹ rẹ ati ilana rẹ ti mo filelẹ fun ọ li oni; njẹ gbogbo ègún wọnyi yio ṣẹ lori rẹ, yio si bá ọ.” Ni kukuru, awọn egun ti o wà fun aigbọran ni iwọnyi: awọn ọmọ ọmọ wọn yoo di alailagbara, arun ati ọta wọn yoo pa wọn ni ipakupa, ọdá yoo da ilẹ ki yoo si mu eso pupọ jade wa; arun ati lukuluku yoo kọlu awọn ẹran ọsin wọn. Ṣiwaju si i, dipo ti wọn i ba fi jẹ eniyan mimọ fun JEHOFA Alaaye, Onifẹ ati Oloore, a o kò wọn kuro ni ilẹ wọn, wọn o si di abọriṣa ti yoo maa foribalẹ ni isin asan fun ọlọrun igi ati okuta ti kò riran ti kò si le gbọran. Awọn egun wọnyi wa dipo ibukún ti a tò lẹsẹẹsẹ ni apa kinni Deuteronomi ori 28. Bi awọn eniyan ba takú sinu aigbọran wọn, a o lé wọn kuro ni ilẹ naa.

Atipo Israẹli ni Ilẹ Ajeji

Oluwa ti sọ fun Abramu pe, “Mọ nitotọ pe irú-ọmọ rẹ yio ṣe alejo ni ilẹ ti ki iṣe ti wọn, nwọn o si sin wọn, nwọn o si jẹ wọn ni iya ni irinwo ọdùn; ati orilẹ-ède na pẹlu ti wọn o mā sin, li emi o dá lẹjọ: lẹhin na ni wọn o si jade ti awọn ti ọrọ pipọ” (Gẹnẹsisi 15:13,14). Nihin ni a sọ asọtẹlẹ atipo awọn Ọmọ Israẹli ni Egitpi. A pe aropọ iye ọdún ti wọn yoo gbe nibẹ ni irinwo (400) ọdún. A kà ninu Ẹksodu 12:40 pe, “Njẹ igbà atipo awọn ọmọ Israẹli ti nwọn ṣe ni ilẹ Egipti o jẹ irinwo ọdún o le ọgbọn.” Ọgbọnle-ni-rinwo (430) ọdún yii bẹrẹ lati igbà ti Ọlọrun ti pe Abrahamu lati kuro ni Harani ni Mẹsopotamia ki o si lọ si ilẹ Kenaani. A ka ọdún ti awọn baba nla Israẹli, Abrahamu, Isaaki ati Jakọbu “ṣe atipo ni ilẹ-ileri bi ẹnipe ni ilẹ ajeji” pọ mọ iye ọdún ti awọn iran wọn ti ṣe atipo ni Egipti. Paulu sọ fun ni pe ọgbọn-le-nirinwo (430) ọdún yii bẹrẹ lati igbà ti Ọlọrun ti ba Abramu dá Majẹmu (Galatia 3:17). A gbagbọ pe lati igba ti Ọlọrun ti pe Abramu titi di igbà ti awọn iran rẹ sọkalẹ lọ si Egipti jẹ okoo-le-nigba ọdún o din marun (215), lati igbà ti wọn sọkalẹ lọ si Egipti titi di igbà ti wọn jade nibẹ jẹ okoo-le-nigba o din marun (215) ọdún, apapọ gbogbo rẹ jẹ ọgbọn-le-nirinwo (430) ọdún.

Idahun JEHOFA Si Adura Mose

Bi akoko ti a o dá awọn Ọmọ Israẹli ni ide kuro ninu isinru kikoro ni Egipti ti n sun mọ etile, Oluwa ba Mose ti o n da agbo ẹran Jetro ana rẹ ni ilẹ Midiani sọrọ wi pe: “Nitorina wá nisisiyi, emi o si rán ọ si Farao, ki o le mú awọn enia mi, awọn ọmọ Israẹli, lati Egipti jade wá” (Ẹksodu 3:10). Mose pada si Egipti; ni igba ekinni ti oun ati Aarọni lọ sọdọ Farao ọba, nwọn beere wipe, “Bayi li OLUWA, Ọlọrun Israẹli wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le ṣe ajọ fun mi ni ijù.” Eyi ni iṣisẹ kinni lati dá awọn Ọmọ Israẹli ni idè kuro ninu isinru ni Egipti. Gẹgẹ bi Oluwa ti sọ tẹlẹ, wọn ni ijatilẹ. A tubọ fi kún ipọnju awọn eniyan ti a n pọn loju wọnyi. Mose pada tọ Ọlọrun lọ ninu adura nitori ọran yi, Oluwa si da a lohun wi pe:

Nigbayi ni iwọ o ri ohun ti emi o ṣe si Farao: nitori ọwọ agbara li on o ṣe jọwọ wọn lọwọ lọ, ati pẹlu ọwọ agbara li on fi ti wọn jade kuro ni ilẹ rẹ.

Ọlọrun si sọ fun Mose, o si wi fun u pe, Emi ni JEHOFA:

Emi si farahàn Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu, li Ọlọrun Olodumare, ṣugbọn orukọ mi JEHOFA ni nwọn kò fi mọ mi.

Emi si ti bá wọn da majẹmu mi pẹlu, lati fun wọn ni ilẹ Kenaani, ilẹ atipo wọn, nibiti nwọn gbé ṣe atipo.

Emi si ti gbọ irora awọn ọmọ Israẹli pẹlu, ti awọn ara Egipti nmu sin; emi si ti ranti majẹmu mi.

Nitorina wi fun awọn ọmọ Israẹli pe, Emi li OLUWA, emi o si mú nyin jade kuro labẹ ẹrù awọn ara Egipti, emi o si yọ nyin kuro li oko-ẹrú wọn, emi o si fi apa ninà ati idajọ nla da nyin ni ide:

Emi o si gbà nyin ṣe enia fun ara mi, emi o si jẹ Ọlọrun fun nyin: ẹnyin o si mọ pe emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin jade kuro labẹ ẹrù awọn ara Egipti:

Emi o si mú nyin lọ sinu ilẹ na, ti mo ti bura lati fi fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakọbu; emi o si fi i fun nyin ni ini: Emi li OLUWA” (Ẹksodu 6:1-8).

Ọlọrun fi ara Rẹ hàn fun awọn eniyan Rẹ ni Jehofa nigbà ti Oun tikara Rẹ dide lati dá wọn ni ide pẹlu ọwọ lile ati ọwọ agbara kuro ninu isinru Egipti, ati lati tun fi idi ileri Rẹ mulẹ pe awọn ni a fi ilẹ Kenaani fun. Lẹhin iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu pupọ ni Egipti, ninu eyi ti a sọ ọ di ahoro, Farao yọọda ni akoko yi pe ki awọn Ọmọ Israẹli maa lọ si ilẹ ileri wọn. Oludande wọn wà pẹlu wọn ni gbogbo akoko ti wọn fi n rin kiri ni aginju. Ipinnu Oluwa ni lati mu wọn wọ ilẹ naa lai pẹ jọjọ, ani ilẹ ti kò si ibomiran ti a le fi ṣe akawe rẹ ni aye yii, ṣugbọn nitori aigbagbọ, iṣọtẹ ati aigbọran awọn eniyan yii, a kò gbà iran naa layè de opin irin-ajo naa (Ka Numeri 14:22-35).

Ilẹ Ileri Naa

Laarin ogoji (40) ọdún ti awọn Ọmọ Israẹli fi rin kiri ni aginju, Oluwa n pese awọn iran keji silẹ lati re Jọrdani kọja lọ si Kenaani. O ṣe eyi nipa fifun wọn ni ofin ti yoo maa tọ wọn sọna ninu sisin Ọlọrun otitọ ati alaaye ni ilẹ ti wọn n lọ. O fun wọn ni ofin iṣakoso ilu, ati itọju ohun ini wọn. Gbogbo ofin wọnyi ni a fi fun wọn fun ire wọn. Igbọran pipe yoo mu ki wọn ri ọpọ ibukun gbà ni ilẹ ti wọn n lọ gba.

Bi ẹnyin ba nrin ninu ilana mi, ti ẹ si npa ofin mi mọ, ti ẹ si nṣe wọn;

Nigbana li emi o fun nyin li òjò li àkokò rẹ, ilẹ yio si ma mú ibisi rẹ wá, igi oko yio si ma so eso wọn.

Ipakà nyin yio si dé igba ikore àjàrà, igba ìkórè àjàrà yio si dé igba ifunrugbin: ẹnyin o si ma jẹ onjẹ nyin li ajẹyo, ẹ o si ma gbé ilẹ nyin li ailewu.

Emi o si fi alaafia si ilẹ na, ẹnyin o si dubulẹ, kò si si ẹniti yio dẹruba nyin: emi o si mu ki ẹranko buburu ki o dasẹ kuro ni ilẹ na, bẹẹni idà ki yio la ilẹ nyin já.

Ẹnyin o si lé awọn ọtá nyin, nwọn o si ti ipa idà ṣubu niwaju nyin.

Marun ninu nyin yio si lé ọgọrun, ọgọrun ninu nyin yio si lé ẹgbarun: awọn ọtá nyin yio si ti ipa idà ṣubu niwaju nyin.

Nitori emi o fi ojurere wò nyin, emi o si mu nyin bisi i, emi o si sọ nyin di pupọ, emi o si gbé majẹmu mi kalẹ pẹlu nyin” (Lefitiku 26:3-9).

Kin ni Oluwa i bá tun ṣe fun ire awọn eniyan yi? A o fun wọn ni òjo lakoko rẹ. Ilẹ naa yoo mu eso wá lọpọlọpọ. Igi ilẹ naa yoo so eso nigba gbogbo. Ikore yoo pọ to bẹẹ ti o ṣe wi pe oṣu mẹfa ni wọn yoo fi maa ru ìtí ilẹ naa sinu àka lati idaji oṣu Nisani (April) de idaji oṣu Tiṣiri (October).

A sọ fun ni wi pe ni oṣu kẹwa (October) ni ọdún ni a n tulẹ ni ilẹ ọlọra yii ati pe ni oṣu kọkanla (November) ni a n funrugbin. Ikore ọka barli ati alikama kò pari titi di oṣu kẹrin (April) ati oṣu karun (May) ọdún ti o fi hàn pe akoko ikore gùn rekọja aalà, ati pe o pọ tayọ. Ikore ajara bẹrẹ ni oṣu kẹjọ (August) ọdun, kò si ni pari titi di nnkan bi oṣu kẹwa (October) ọdun. Iṣẹ yii gba akoko ti o gùn rekọja aala, eyi si fi hàn pẹlu pe ilẹ mu eso jade rẹpẹtẹ. Ipaka bẹrẹ lẹhin ikore ọka, ṣiwaju ikore àjara. Ileri Ọlọrun ni pe ilẹ yoo mu ọpọlọpọ eso wá to bẹẹ ti igba ipaka yoo de igba ikore ajara – akoko ikore àjara ati ifunti – ti o bẹrẹ ni oṣu kẹjọ (August) ọdun. Lẹhin naa akoko ikore ajara ati ifunti ki yoo dopin titi di akoko itulẹ ati ifunrugbin ni nnkan bi i oṣu kẹwa ọdun. Dajudaju ikore àjara yoo pọ to bẹẹ ti ki yoo pari titi akoko itulẹ ati ifunrugbin yoo fi tun bẹrẹ.

Lẹhin awọn ibukun ti eso ilẹ wọnyi, Ọlọrun tun ṣeleri alaafia pẹlu. Kò si ẹnikẹni ni orilẹ-ède miran ti yoo le dayafo wọn, nitori ti Oluwa ti ṣeleri pe idà ki yoo là ile wọn kọja. Wọn o jẹ akọni ati ajagun-ṣẹgun, wọn o lé gbogbo awọn ọtá wọn kuro ni ilẹ naa ti a o fi fun wọn.

A ti fi hàn fun awọn Ọmọ Israẹli ohun ti ilẹ Ileri naa yoo mu jade wa. Awọn ami mejila ti Mose rán mu diẹ ninu eso ilẹ naa pada wá. Ẹka idi eso ajara Eṣkolu kan tobi to bẹẹ ti o fi ṣe wi pe eniyan meji ni wọn fi ọpa ru u. Wọn mu eso ọpọtọ ati pomegranate bọ pẹlu. Ihin ti wọn mu wa ni pe “nitõtọ li o nṣàn fun wara ati fun oyin; eyi si li eso rẹ” (Numeri 13:27). Eyi fi idi ohun ti Ọlọrun ti sọ fun wọn tẹlẹ nipa eso ilẹ naa mulẹ. Eyi ati awọn ohun rere miran pẹlu ni yoo fun wọn bi wọn ba gbọran. Ijiya aigbọran ni pe, a ki yoo fun wọn ni òjo, eyi yoo mu ki ilẹ di aṣalẹ, ki yoo si mu eso jade wá. Lẹhin eyi, a o tú wọn kaakiri gbogbo orilẹ-ède agbaye nitori aigbọran.

Wọn ṣaigbọran si Oluwa, nitori idi eyi, Oluwa ti tú wọn kaakiri gbogbo orilẹ-ède agbaye lati nnkan bi ẹgbaa (2,000) ọdún. Ṣugbọn akoko n sun mọ etile ti Ọlọrun yoo lọ awọn ẹka-iyẹka (awọn Ju) pada sara Ajara – Jesu Kristi Oluwa (Johannu 15:1-6; Romu 11:15-26). Òjo ti tun bẹrẹ si rọ ni ilẹ Palẹstini. O ti bẹrẹ si rudi bi òdòdó. Ilẹ ti o ti wà lasan fun ọpọlọpọ ọdún ni a ti bẹrẹ si ro, ti a si funrugbin si, o si ti bẹrẹ si so eso lọpọlọpọ. Akoko ti a o mu ileri asọtẹlẹ nipa ilẹ naa ṣẹ patapata n sun mo tosi. “Kiyesi i, ọjọ na de, li OLUWA wi, ti ẹniti ntulẹ yio le ẹniti nkore bá, ati ẹniti o ntẹ eso ajara yio le ẹniti o nfunrugbin bá; awọn oke-nla yio si kán ọti-waini didùn silẹ, gbogbo oko kékèké yio si di yiyọ” (Amosi 9:13).

Ọjọgbọn kan sọ fun ni pe, “Ilẹ naa lọra pupọ, oju ọjọ si dara to bẹẹ gẹẹ ti a fi le wi pe bi nnkan ba lọ deedee, bi awọn eniyan ti n pọ to, ni ilẹ naa yoo maa gba wọn. Bi a ti n tu ilẹ ibẹ to ni yoo maa mu eso wa si i titi awọn olugbe ibẹ yoo fi to nnkan bi aadọta-le-lẹẹ-dẹgbẹrin ọkẹ (15,000,000) eniyan.” Aadọjọ ọkẹ (3,000,000) ni eyi fi pọ ju awọn Ju ti o wà ni gbogbo agbaye loni. Awọn Israẹli nipa lilo ọgbọn ati ilana ẹkọ ijinlẹ (Science) ninu iṣẹ agbẹ wọn, mu ki ilẹ naa mu eso pupọ jade fun wọn ju bi o ti mu wa fun awọn Larubawa. Nipa aanu Ọlọrun ti O n pa Majẹmu mọ, ilẹ naa ti bẹrẹ si fi apẹrẹ “ṣiṣan fun wara ati fun oyin” hàn; ọgọọrọ awọn onilẹ naa gan an si ti bẹrẹ si pada si ori ilẹ wọn. Ni igba ijọba ẹgbẹrun ọdun, “Wọn o joko olukuluku labẹ ajara rẹ ati labẹ igi ọpọtọ rẹ; ẹnikan ki yio si daiyà fò wọn: nitori ẹnu OLUWA awọn ọmọ-ogun li o ti sọ ọ” (Mika 4:4; Sekariah 3:10).