Deuteronomi 28:29, 43, 48, 65-67; Isaiah 32:10, 13, 14; Hosea 3:4; Luku 21:20-24

Lesson 162 - Senior

Memory Verse
“Nwọn o si ti oju idà ṣubu, a o si di wọn ni igbekun lọ si orilẹ-ède gbogbo: Jerusalẹmu yio si di itẹmọlẹ li ẹsẹ awọn Keferi, titi akoko awọn Keferi yio fi kún” (Luku 21:24).
Notes

Nigbati ẹnyin ba si ri ti a fi ogun yi Jerusalẹmu ká, ẹ mọ nigbana pe, isọdahoro rẹ kù si dẹdẹ.

Nigbana ni ki awọn ti mbẹ ni Judea ki o sa lọ sori oke; ati awọn ti mbẹ lārin rẹ ki nwọn jade kuro; ki awọn ti o si mbẹ ni igberiko ki o máṣe wọ inu rẹ lọ.

Nitori ọjọ ẹsan li ọjọ wọnni, ki a le mu ohun gbogbo ti a ti kọ we rẹ ṣe.

Ṣugbọn egbé ni fun awọn ti o lóyun, ati awọn ti o nfi ọmú fun ọmọ mu ni ijọ wọnni! Nitoriti ipọnju pipọ yio wà lori ati ibinu si awọn enia wọnyi.

Nwọn o si ti oju idà ṣubu, a o si di wọn ni igbekun lọ si orilẹ-ède gbogbo; Jerusalẹmu yio si di itẹmọlẹ li ẹsẹ awọn Keferi, titi akoko awọn Keferi yio fi kún” (Luku 21:20-24).

Kikọ Olugbala Israẹli

Ninu ẹkọ ti a ṣe kọja, a kọ nipa asọtẹlẹ ti o jẹ mọ ituka awọn Ju kaakiri gbogbo orilẹ-ède agbaye. A ri i nibẹ gẹgẹ bi Oluwa ti sọ fun awọn eniyan wọnyi lati ẹnu Mose Woli Rẹ ni nkan bi ẹẹdẹgbẹjọ (1,500) ọdun ṣiwaju ituka ti o wà titi di oni-oloni yi, nipa ohun ti yoo ṣẹlẹ si wọn bi wọn kò ba yọ ọwọ kuro ninu iwà aigbọran. Fun igbà pupọ laarin ẹẹdẹgbẹjọ (1,500) ọdún yi ni wọn fi ṣọtẹ si Ọlọrun. Iṣọtẹ wọn de gongo nigbà ti wọn kọ Olugbala wọn, Ọmọ bibi ka ṣoṣo ti Ọlọrun, ti wọn si kan An mọ agbelebu, nipa eyi ti wọn ṣe idajọ ayéderu ti o buru ju lọ lati igbà ti ayé ti ṣẹ.

Pọntu Pilatu, ti i ṣe aṣoju ijọba Romu ti pinnu tan lati fi ọgbọn gbà ara rẹ silẹ bi alai lẹbi ninu ohun ti awọn eniyan fẹ mu un ṣe. Owu, ilara ati ẹtanu awọn Ju kò mọ niwọn. Kò tilẹ jẹ ki wọn le ronulọna ti o tọ. Ninu aimọkan, wọn wi fun Pilatu ni ohun rara pe, “Ki ẹjẹ rẹ wà lori wa” (Matteu 27:25; I Kọrinti 2:8). Eyi kò tilẹ tẹ wọn lọrun, wọn tẹ siwaju si i pe, “Ati li ori awọn ọmọ wa” pẹlu; lọna bayi wọn daràn ti kò lẹgbẹ silẹ de awọn ọmọ ati atọmọ-dọmọ wọn. Egún buburu ni wọn fà sori ara wọn ati awọn ọmọ wọn!

Wọn kò le gba Pilatu kuro lọwọ idalẹbi, ṣugbọn wọn pinnu tan lati gbà a sori ara wọn ni kikún. Lati igbà ti wọn ti kọ Olugbala yi, bi wọn ti n sa kaakiri gbogbo orilẹ-ède agbaye ni Agbẹsan Ẹjẹ n tọ wọn lẹhin. Kò tii si ilu aabo kan ti o daju fun awọn ọdaràn eniyan wọnyi; tootọ ati igbagbọ ninu Ẹni ti i ṣe orisun gbogbo ire wọn, nipa ti ara ati nipa ti ẹmi (Sekariah 12:10).

Kò pe ogoji ọdun lẹhin ti awọn Ju sọ ọrọ wonyi, lati gbà idalẹbi kikún nipa ikú Jesu ni awọn ara Romu, labẹ akoso Ọgagun kan ti a n pe ni Titu gbogun ti Jerusalẹmu olu ilu awọn Ju ni aadọrin ọdun (70 A.D.) lẹhin ti a bi Jesu. Nigbà ti awọn ara ilu yi jọwọ silẹ lẹhin ogun jija oṣu mẹfa, awọn ara Romu bẹrẹ si kàn wọn mọ agbelebu to bẹẹ ti agbelebu kò pọ to fun awọn ti wọn dá lẹbi ikú, bẹẹ ni àyè kò to fun awọn agbelebu ti o wà nilẹ. Josẹfu opitan sọ fun ni pe akoko Ajọ Irekọja ni wọn bẹrẹ ogun ti a gbe ti wọn. Ogunlọgọ eniyan ni o wá si Jerusalẹmu lati oriṣiṣi ilu fun ajọdun yi; lojiji awọn ọmọ-ogun Romu sé ilẹkun odi ilu mọ wọn bi ẹni ti o wà ninu ile tubu ti o tobi. O ṣe pataki ki a fi fi sọkàn pe kò si ara ilu ajeji miran kan ri ti o ti i wa lati pa awọn Ju run lọna bayi ni akoko ajọdun wọn; lati igbà Mose titi di igba yi. Oluwa ni o n daabo bo wọn ni iru igbà bẹẹ, ṣugbọn ni akoko yi, wọn yapa kuro lọdọ Ọlorun, wọn kò si gbọran si I lẹnu mọ. Nigbà ti ogun yi pari tan, ọkẹ marun-din-lọgọta (1,100,000) ninu awọn Ju ni o ti kú, yala nipa kikàn mọ agbelebu, tabi nipa ajakalẹ àrun ati iyàn, a si kó nkan bi ọkẹ marun-o-din-ẹgbẹẹdogun (97,000) eniyan ni igbèkùn.

Bayi ni ituká awọn Ju kaakiri gbogbo orilẹ-ède agbaye bẹrẹ lati nkan bi ẹdẹgbaa (1900) ọdún sẹhin titi di oni oloni. Lẹhin ti wọn di Olugbala wọn nigbekun, awọn Ju funra wọn paapaa si di igbèkùn laarin orilẹ-ède gbogbo nibi ti ipọnju ati ìṣẹ ti jẹ ipin wọn lati ọpọlọpọ ọdun sẹhin. Nigbà ti Jesu sọ bayi pe, “Nwọn o si ti oju idà ṣubu, a o si di wọn ni igbekùn lọ si orilẹ-ède gbogbo: Jerusalẹmu yio si di itẹmọlẹ li ẹsẹ awọn keferi, titi akoko awọn keferi yio fi kún” (Luku 21:24), a sọ fun ni pe awọn eniyan ti o wà ni Palẹstini nigbà naa to ẹgbẹta ọkẹ (12,000,000); nkan bi aadọjọ ọkẹ (3,000,000) ni o wá ni Galili nikan ṣoṣo. Opitan miran sọ fun ni pe “awọn eniyan ti o wa lori ilẹ mile kan ti o dọgba yika ni ilu Palẹstini pọ ju ti ibikibi lọ ni gbogbo ilẹ Ijọba Romu.” Ṣugbọn ọdun 1160, igba (200) Ju pere ni o wà ni Jerusalẹmu. Ni ọdun 1827, a le ri to nkan bi ẹẹdẹgbẹta (500) Ju lati Dani de Beerṣeba. Ni ọdun 1882, wọn to nkan bi ẹgbaaji (4,000) pere. Nipa bayi a le mọ bi asọtẹlẹ Jesu ti ṣe to lati nkan bi ẹẹdẹgbaa ọdùn yi wa. O fẹrẹ jẹ pe fun gbogbo ẹẹdẹgbaa (1900) ọdún naa ni awọn Ju kò fi wa ninu ilu ti wọn, ti awọn Keferi si n gbe ilẹ naa. Ni akoko yi a ti tú awọn Ju ká saarin gbogbo orilẹ-ède ti o wà labẹ Ọrun, o si yẹ ki a ranti pe ituká yi ti ṣẹlẹ ni ọjọ pipẹ ki a to ni ọkọ oju-omi ati ti oju irin. Ituká yi pọ o si yara to bẹẹ ti kò fi le ni irọrun rara. Eyi fi hàn pe iṣoro nlá nlà ni oju awọn ti a tú kaakiri wọnyi ri.

Ijọba ati Isin Ọlọrun ni akoko Ituká

Nitori ọjọ pupọ li awọn ọmọ Israẹli yio gbe li aini ọba, ati li aini olori, ati li aini ẹbọ, li aini ere, ati li aini awòaiyà, ati li aini tẹrafimu” (Hosea 3:4).

Gẹgẹ bi awọn ẹkọ wa ti fi ye ni, awọn “ọjọ pupọ” wọnyi ti gbà ọpọlọpọ ọdún. Ibugbe wọn lati igbà naa titi di isinsinyi ni “lati igun kan opin aiye titi de ekeji.” Nipa bayi, a ti dù wọn ni ilẹ wọn; wọn wà laini ọba tabi ijoye.

Ibi kan ṣoṣo ni awọn Ju le rú ẹbọ wọn, eyi ni ibi ti Oluwa ti yàn (Deuteronomi 12:5, 6, 13, 14; 16:1-6). Oluwa paṣẹ pe ni Jerusalẹmu ni ki a kọ Tẹmpili si “nibi ilẹ-ipakà Onani ara Jebusi” (I Kronika 21:18; II Kroniika 3:1). Wọn kò le rubọ nibẹ loni nitori pe nibẹ ni Mọṣalaṣi Omari gbe wà nisisinyi. Wọn a maa jẹ Matsoti – akara alaiwu – ati egungun ojugun ẹsẹ ọdọ-agutan ti a sun. Wọn a maa lọ si sinagọgu, wọn a maa sin gẹgẹ bi eto ati ilana Talmudu (Iwe itan atọwọdọwọ awọn Ju). Ohun gbogbo ti wọn n ṣe yatọ si ohun patakii kan ti Ọlọrun beere leke ohun gbogbo. Oun kò wi pe “Nigbà ti mo ba ri ti ẹ mu iwukara kuro, tabi nigba ti mo ba ri ti ẹ jẹ Matsoti tabi ọdọ-agutan, tabi ri yin ni sinagọgu, Emi o re nyin kọja”, bi kò ṣe pe “Nigbati mo ba ri ẹjẹ na emii o re nyin kọja.” Ẹsìn ti kò ni Ẹjẹ ninu ni ẹsin wọn niwọn bi wọn ti kọ Olugbala wọn ti a kàn mọ igi -- ẹsìn ti kò ba sin ni Ẹjẹ jẹ okú ẹsìn. Fun ọpọlọpọ ọdun ni awọn Ju fi n ba igbesi aye wọn lọ lọna bayi, a si ri i loni pe wọn ti bẹrẹ si gbe iṣisẹ lati mu apa keji ọrọ asọtẹlẹ naa ṣẹ ti o lọ bayi pe: “Lẹhin na awọn ọmọ Israẹli yio padà, nwọn o si wá OLUWA Ọlọrun wọn, ati Dafidi ọba won; nwọn o si bẹru OLUWA, ati ore rẹ li ọjọ ikẹhin” (Hosea 3:5).

Ipo ti Ilẹ naa Wà

Ọpọlọpọ ọjọ, on ọdún, li a o fi ma wahala nyin, ẹnyin alafara obirin: nitori ikore ki yio si, kikojọ rẹ ki yio de.

Ẹgún ọgan on òṣuṣu yio wá sori ilẹ awọn enia mi; nitõtọ, si gbogbo ile ayọ ni ilu alayọ.

nitoripe a o kọ lafin wọnni silẹ; a o fi ilu ariwo na silẹ; odi ati ile-iṣọ ni yioo di ihò titi lai, ayọ fun kẹtẹkẹtẹ igbẹ, pápa-oko fun ọwọ ẹran” (Isaiah 32:10, 13, 14).

Nkan bi ẹgbẹtala (2600) ọdún sẹhin ni a sọ ọrọ wọnyi. A fi bi a ba ṣe ayẹwo awọn ohun ti o ti kọja ni ilẹ Palẹstini lati ọdún mọdún wọnyi wa nikan ni a to le mọ bi awọn asọtẹlẹ wọnyi ti pe perepere to ti a sọ lati ẹnu Woli Isaiah. Iyanu ni o jẹ fun awọn arinrin-ajo ti o kọja lori awọn oke tutu rinrin ni Palẹstini wi pe apejuwe ti a ṣe nipa rẹ ninu Numeri 13:21-27 ati ibomiran gbogbo ninu Iwe Mimọ ti ṣe le jẹ otitọ. A sọ fun ni pe gẹrẹ lẹhin iṣubu Jerusalẹmu, a wọ ohun elo itulẹ kọja lori Oke Sioni lati fi hàn pé kii ṣe ilu mọ. Woli Ọlọrun ti sọ asọtẹlẹ gbangba wi pe Jerusalẹmu yoo di papa oko (Jeremiah 26:18).

Ilẹ ti o ni ọpọlọpọ ileri ibukun fun Israẹli di ahoro -- aṣalẹ ti kò le mu eso wa -- lai si àkọrọ ati àrọkuro ọjọ bi o tilẹ jẹ pe o ti fi igbà kan ṣàn “fun wara ati fun oyin.” Lati inu odo Nile ni awọn eniyan ti n pọn omi lati bomi rin awọn ohun ọgbin ni ilẹ Egipti. Òjo àtọrun wá ni o n fun Israẹli ni omi. Bi Oluwa ba fun wọn ni àkọrọ ati àrọkuro òjo ni akoko rẹ, wọn a ni idaniloju anito ati aniṣẹkù. Bi oun kò ba si fun wọn ni òjo, eyi yoo fa ọdá ati iyàn, awọn eniyan yoo si “run kankan kuro ni ilẹ rere na” ti Oluwa fi fun wọn (Deuteronomi 11:10-17). Aigbọran ki yoo jẹ ki wọn ni àkọrọ ati àrọkuro òjo. Iyanu ni pe awọn Ọmọ Israẹli le ka Iwe Ofin yi, ki wọn kà nipa awọn ègun ti yoo wá sori wọn, ki wọn kà itan igbesi aye wọn – eyi ti o ti kọja, eyi ti wọn n lo lọ lọwọlọwọ ati ọjọ iwaju -- sibẹ ki wọn takú sinu aigbagbọ.

Fun nkan bi ẹgbaa (2000) ọdún ni ilẹ na ti wà ni ipo idahoro. Ọlajú ati itẹsiwaju wọn kò duro pẹ, ilẹ naa si ti wà lasan fun ẹgbẹrun (1,000) ọdún. Nitori pe awọn eniyan yi kò le san owo ori ti ijọba Tatambulu (Turkey) fẹ gbà lọwọ wọn lori igi kọọkan, o kan dandan fun wọn lati ge awọn igi naa lulẹ, eyi si mu ki ilẹ Palẹstini di ilu ti kò ni igi mọ. Niwọn igbà ti ilẹ Palẹstini wà labẹ ijọba Tatambulu (Turkey) ati Larubawa, a fẹrẹ má si igi nibẹ rara nitori pe ilẹ naa di ahoro. Eyi jẹ ẹri kan pataki pe ilẹ naa ki i ṣe ti awọn Larubawa bi kò ṣe ti awọn Ju. Ọlọrun kò sọ fun Abrahamu pe ninu Iṣmaẹli li a o ti pe iru-ọmọ rẹ,” ṣugbọn O wi pe “Ninu Isaaki.” Nitori naa awọn Ju ni oni ilẹ naa ki i ṣe awọn Larubawa.

Bi Ọlọrun ti ṣe pa awọn Ju mọ ni ọna iyanu lati fi ilẹ yi fun wọn ni ini, bẹẹ ni O ṣe pa ilẹ naa mọ ni ọna iyanu fun awọn Ju. Nipa didawọ àkọrọ ati àrọkuro òjo duro, ilẹ ti o ti n ṣàn fun wara ati fun oyi nigbà kan ri di aṣalẹ patapata. A ti sọ asọtẹlẹ nipa eyi ṣiwaju ninu Isaiah 32:9-17. Ohun ti a sọ ninu Ọrọ Ọlọrun yi nipa Palẹstini ti ṣẹ lati ọpọlọpọ ọdún sẹhin. Ajara kò mu eso wa mọ; a kò tu ilẹ naa; ẹgun gbà gbogbo ilẹ naa kan; gbogbo ọna parẹ. Awọn Tatambulu (Turkey) kò ṣe ohunkohun lati mu iṣoro ti airọ òjo mu wa kuro. Lọna bayi ni Ọlọrun fi daabo bo ilẹ naa fun awọn eniyan yi.

Ni ọpọlọpọ ọdún wọnyi ti awọn Ju fi tú kaakiri gbogbo orilẹ-ède ti wọn si n jiya, ilẹ wọn di ahoro, iwọn iba eniyan diẹ kinun ni wọn wà nibẹ gẹgẹ bi Iwe Mimọ ti a tọka si loke yi ti fi hàn. A sọ fun ni pe lati ọdún-mọdun ni, bi ohun gbogbo ti n lọ mu ki ilẹ Israẹli maa ṣe Isinmi Ọsẹ lọ titi. Fun ọpọlọpọ ọdún ni ilẹ yi fi wà lọwọ awọn eniyan ti o mu ki o wà ni idahoro sibẹ. Awọn diẹ gbagbọ pe bi o ba ṣe pe orilẹ-ède ti o jafafa ni o wà ni Palẹstini nkan ki ba ri bi o ti ri ni ilu naa. Ọpọlọpọ orilẹ-ède Onigbagbọ ni igba pupọ ni won ti fi itara ṣafẹri ilẹ yi, ti wọn si fẹ gba a pẹlu agbara, ṣugbọn ti wọn ti kunà. Ṣugbọn akoko ti Ọlọrun to ti Oun yoo gba a kuro lọwọ awọn Tatambulu (Turkey) ti o ti takú sibẹ fun bi ẹgbẹfa (1200) ọdún. Ni opin Ogun Ajakaye Kinni, Ilẹ Palẹstini bọ kuro lọwọ akoso awon Musulumi eyi si fi opin si akoko iṣudẹdẹ ninu ita igbesi aye awọn Ọmọ Israeli.

Wiwa Laaye Lakoko Ituka ati Inunibini

Òjo àrọkuro ti kò si mọ ni o mu ki ilẹ yi jẹ ti awọn Ju sibẹ. Lọna miran ẹwẹ, a ti ri bi a ti dá awọn Ju si lọna iyanu ki ilẹ yi ba le jẹ ti wọn. Bi o tilẹ jẹ pe o fẹrẹ to ẹẹdẹgbaa (1900) ọdun ti a fi tú wọn kaakiri gbogbo agbaye ati pe a ti ṣẹ wọn niṣẹ gidigidi, wọn kú ikú oro, sibẹ lọjọ oni awọn Ju ti o wà laaye kaakiri agbaye to nkan bi ẹgbẹta ọkẹ (12,000,000), lẹhin ti a tilẹ ti ṣe inunibini si wọn lai pẹ yi ni akoko Ogun Ajakaye Keji. Ọpọlọpọ ọkẹ aimoye awọn eniyan yi ni a ti jẹ niya kikoro lọna ailaanu, eyi si gba ẹmi nkan bi ọọdunrun ọkẹ (6,000,000) eniyan wọn.

Bi a ba boju wo ẹhin ti a si lọ ka itan wọn, a o ri i pe awọn ọba Farao ti o jẹ ni Egipti ni nkan bi ẹgbẹjọ (1600) ọdún ṣiwaju igbà ti a bi Jesu oluwa wa, fẹ fi gbigbé sọ sinu odò run wọn ṣugbọn kò ṣe e ṣe. Awọn Assiria pẹlu gbiyanju lati run wọn ni nkan bi ọrin-le-lẹẹdẹgbẹrin ọdún o din marun (775) ṣiwaju akoko ti a bi Jesu Oluwa; Nebukadnessari ni nkan bi ẹgbeta ọdun o din mejila (588) ati Hamani ni nkan bi ẹẹgbẹta o le mẹwa ọdun (510) ṣiwaju akoko ti a bi Jesu Oluwa; Antiokusi Epifanesi ni nkan bi aadọsan (170) ọdun ṣiwaju akoko ti a bi Jesu Oluwa ati Titu ni nkan bi aadọrin (70 A.D.) ọdun lẹhin ibi Jesu Oluwa wa.

Oluwa wa ti sọ tẹlẹ lati ẹnu Mose Olufunni loin Rẹ pe iya kikoro ni a o fi jẹ wọn bi wọn ba ṣaigbọran si Oluwa.

Iwọ o si ma fi ọwọ talẹ li ọsán gangan, bi afọju ti ifi ọwọ talẹ ninu òkunkun, iwọ ki yio si ri rere ninu ọna rẹ: ẹni inilara ṣá ati ẹni kikó li ọjọ gbogbo ni iwọ o jẹ, ki o si si ẹniti o gbà ọ.

Alejò ti mbẹ lārin rẹ, yio mā ga jù ọ lọ siwaju ati siwaju, iwọ o si ma di ẹni irẹsilẹ, siwaju ati siwaju.

Nitorina ni iwọ o ṣe ma sin awọn ọtá rẹ ti Oluwa yio rán si ọ, ninu ebi ati ninu ongbẹ, ati ninu ihoho, ati ninu aini ohun gbogbo: on o si fi àjaga irin bọ ọ li ọrùn, titi yio fi run ọ.”

Ati lārin orilẹ-ède wọnyi ni iwọ ki yio ri irọrun, bẹẹli atẹlẹsẹ rẹ ki yio ri isimi, ṣugbọn OLUWA yio fi iwariri àiya ati oju jijoro, ati ibanujẹ ọkàn fun ọ.”

Ẹmi rẹ yio sorọ ni iyemeji li oju rẹ; iwọ o si mā bẹru li oru ati li ọsán, iwọ ki yio si ni idaniloju ẹmi rẹ.”

Li owurọ iwọ o wipe, Alẹ ibajẹ lẹ! ati li alẹ iwọ o wipe, Ilẹ iba jẹ mọ! nitori ibẹru àiya rẹ ti iwọ o mā bẹru, ati nitori iran oju rẹ ti iwọ o mā ri” Deuteronomi 28:29, 43, 48, 65-67).

Awọn orilẹ-ède miran, laarin ẹni ti wọn wà, kàn gbà wọn bẹẹ bẹẹ ṣá ni. Sibẹsibẹ wọn jẹ ẹri pataki nipa agbara awamaridi Ọlọrun. Wọn jẹ ẹri ti kò le ṣe e jiyàn rẹ wi pe, nipa imisi Ọlọrun ni a fi kọ Bibeli. Ọba kan beere lọwọ ọgbẹni John Knọx, Onigbagbọ tootọ wi pe, “Njẹ iwọ le fun mi ni ẹri ni kukuru, pe Ọrọ Ọlọrun ni Bibeli i ṣe”? Oniwaasu pataki yi dahùn wi pe, “Bẹẹ ni, awọn Ju.”

Awọn ti o Súre ati awọn ti o fi awọn Ju Ré

Oluwa sọ fun Abrahamu pe: “Emi o bukun fun awọn ti nsúre fun ọ, ẹniti o nfi ọ ré li emi o si fi ré” (Gẹnẹsisi 12:3). Kin ni ha ṣẹlẹ si awọn orilẹ-ède diẹ wọnni ti o ti fi awọn Ju ṣọrẹ bi o tilẹ pe fun iwọn igbà diẹ ni? Awọn eniyan gbà pe orilẹ-ède Amẹrika ni o lọrọ jù, ti wọn si lagbara jù ni gbogbo aye. Awọn Ju ti wà nibẹ lati nkan bi ọdunrun (300) ọdún ni alaafia. Wọn gbilẹ nibẹ ju ibikibi ni gbogbo agbaye to bẹẹ ti wọn fi pọ to ọtalerugba ọkẹ (5,200,000) ni Amẹrika. Wọn ti di ọlọrọ nibẹ, Ọlọrun si ti bukun orilẹ-ède yi pẹlu wọn. A kà ninu Iwe Mimọ pe, “Gbadura fun alafia Jerusalẹmu: awọn ti o fẹ ọ yio ṣe rere” (Orin Dafidi 122:6). O ṣe ni laanu ṣá, wi pe, wọn kò ṣe alai ni idojukọ ati iyọṣuti si, paapaa ju lọ, lati nkan bi ọdún diẹ wa yi.

Orilẹ-ède Gẹẹsi di alagbara labẹ akoso ọgbẹni Disraẹli ti i ṣe Ju. O di olokiki ati alagbara. Ọgbẹni yi jẹ ọkan ni awọn òṣelu pataki ti a ti i ri ri ni ilẹ Gẹẹsi. Ṣugbọn lẹhin ti awon Gẹẹsi di alabojuto lori ilẹ Palẹstini, ojurere ti awọn Gẹẹsi ti ni si awọn Ju ri wa yi pada. Iwe eto ohun ti Ijọba yoo ṣe ti a gbe jade ni May 17, 1939 kọ pe ki a yọọda fun awọn Ju lati lọ si ilẹ Palẹstini lẹhin ọdun marun ti iwe yi jade, laarin ọdun marun yi ẹgbafa (12,000) eniyan pere ni a le yọọda fun larin ọdun kan lati pada lọ si Palẹstini. Ni akoko Ogun Ajakaye Keji, awọn Gẹẹsi tẹ ipá bọ eto ti wọn ṣe yi, wọn kò si jẹ ki awọn Ju pada si ilẹ wọn. Ọpọlọpọ ọkọ ti o kó awọn Ju ti o n sá lọ lati wa ibi aabo kuro lọwọ awọn ara Jamani ti wọn n dá wọn loro ti wọn si n pa wọn ni ipakupa, ni awon atukọ oju-omi Gẹẹsi ni agbami dá duro, a si kó awọn ọkunrin, obinrin ati ọmọde ti o wà nibẹ lọ si agọ-idani-loro ni ilu Kipru.

Gẹrẹ ti awọn Gẹẹsi bẹrẹ si hu irú iwa bayi ni ogo ijọba ati orilẹ-ède wọn n wọmi diẹdiẹ. Nigba ti a n kọ iwe yi, a kò le sọ pe awọn ni o lagbara ju lọ ni aye. Wọn ti wọ gbese. Ki i ṣe alakoso okun mọ. O ha le jẹ pe ọrọ ti Ọlọrun sọ fun Abrahamu ni nkan bi ẹẹdẹgbaaji (3,900) ọdún sẹhin wi pe, “Ẹniti o n fi ọ ré li emi o si fi ré” ni nkan kan pẹlu ogo ilẹ Gẹẹsi ti o n wọmi yi? A tun rii ti Ọlọrun ti ẹnu woli Rẹ Sekariah sọ wi pe, “Ẹniti o tọ nyin, o tọ ọmọ oju rẹ” (Sekariah 2:8).

Ogo awọn orilẹ-ède miran ti wọn dá awọn Ju loro, ti wọn jẹ wọn niyà, ti wọn ṣe inunibini si wọn, ti wọn si pa wọn ni ipakupa ti wọmi, awọn orilẹ-ède bi Egipti, Babiloni, Persia, Griki, Romu, ati ni igbà ti wa yi, orilẹ-ède Jamani. Farao gbiyanju lati ri awọn Ọmọ Israẹli ninu okun. Oun ati awọn ogun rẹ rì si Okun Pupa. Hamani fẹ fi wọn kọ sori igi. A fi oun funra rẹ kọ sori igi naa ti o rì fun ọkan ninu awọn aṣiwaju Ju nigba naa, Mordekai. Ipinnu buburu ti Hitler, aṣeyi-t’o-wu-u, ni lọkàn lati pa awọn Ju run kuro lori ilẹ aye. Igbẹhin rẹ kò dara, o si kó wahala, irora ati iṣẹ ba ẹgbẹẹgbẹrun awọn Jamani.

Wiwa Laaye Awọn Ju

Eredi wiwà laaye ti awon Ju wà laaye di oni-oloni? Eeṣe ti wọn kò parẹ si aarin awọn orilẹ-ède ti wọn n gbé? Eyi ti ṣẹlẹ si awọn ara ilẹ iwọ-orun ti wọn ṣilọ lati gbe ni ilẹ miran. Nigba ti yoo fi to iran kẹta, a kò le mọ wọn yatọ mọ, won ti di ara awon orilẹ-ède ti wọn wà. Ṣugbọn kò ri bẹẹ fun awọn Ju, won yatọ patapata si awọn orilẹ-ède gbogbo nibi ti wọn n gbé. Awọn Ju wà sibẹ, awọn ọta wọn ni wọn ṣegbe. Eyi ran wa leti asọtẹlẹ Balaamu pe: “Nitoripe lati ori apata wọnni ni mo ri i, ati lati òke wọnni ni mo wò o: kiyesi, awon enia yi yio dagbe, a ki yio si kà wọn kún awọn orilẹ-ède” (Numeri 23:9). Wo Jeremiah 30:10,11 pẹlu.

Fun iwọn bi ẹgbẹẹdogun (3,000) ọdun ti wọn fi wà bi orilẹ-ède, igbà pupọ ni o n dabi ẹni pe wọn yoo parun patapata, ṣugbọn sibẹ wọn a tun gberú. Eeṣe? Nitori Ọlọrun dá wọn si. Dajudaju Ọlọrun dá wọn si lọna iyanu fun idi pataki kan ti o jẹ mọ itẹsiwaju awọn orilẹ-ède ni ọjọ ọla. Ọba alai-wa-bi Ọlọrun kan kọwe nigbà kan si alaṣẹ igberiko rẹ kan bayi pe: “Maṣe tọ awọn Ju; kò si ẹni ti o tọ wọn ti o ṣe rere.”

Bi a ti n tẹ siwaju ninu ẹkọ yi, a o maa ri iṣipaya eto Ọlọrun fun awọn ẹni iyanu wọnyi ti wọn wà kaakiri gbogbo orilẹ-ède agbaye. Ọrọ asọtẹlẹ Ọlọrun ti ki i tase n bọwa ṣẹ, yoo si maa ṣẹ titi a o fi mu gbogbo rẹ ṣẹ.