Isaiah 60:8-10; 61:4; Jeremiah 16:14-18; 32:42-44; Esekiẹli 37:1-14; Amosi 9:11-15; Matteu 24:32-35

Lesson 163 - Senior

Memory Verse
“Njẹ ẹ kọ owe lara igi ọpọtọ; nigbati ẹká rẹ ba yọ titun, ti o ba si ru ewé, ẹnyin mọ pe igba ẹẹrùn sunmọ etile: Gẹgẹ bẹẹ li ẹnyin, nigbati ẹnyin ba ri gbogbo nkan wọnyi, ki ẹ mọ pe o sunmọ etile tan lẹhin ilẹkun” (Matteu 24:32,33).
Notes

Njẹ ẹ kọ owe lara igi ọpọtọ; nigbati ẹka rẹ ba yọ titun, ti o ba si ru ewé, ẹnyin mọ pe igba ẹẹrùn sunmọ etile;

Gẹgẹ bẹẹ li ẹnyin, nigbati ẹnyinn ba ri gbogbo nkan wọnyi, ki ẹ mọ pe o sunmọ etile tan lẹhin ilẹkun.

Lõtọ ni mo wi fun nyin, iran yi ki yio rekọja, titi gbogbo nkan wọnyi yio fi ṣẹ.

Ọrun on aiye yio rekọja, ṣugbọn ọrọ mi ki yio rekọja” (Matteu 24:32-35).

Owe Igi Ọpọtọ

Jesu sọ fun ni lati kọ ẹkọ, tabi ki oye ki o ye wa, nipa owe ti igi ọpọtọ. Iwe Mimọ fi ye ni pe igi ọpọtọ yi duro fun orilẹ-ède awọn Ju (Jeremiah 24:1-10; Hosea 9:10; Mika 7:1; Luku 13:6-9). Lati nkan bi aadọta ọdún tabi ni nkan bi opin aadọta ọdún sẹhin, igi ọpọtọ yi ti bẹrẹ si rudi, o si n ruwe. Igboke-gbodo ti kò lẹgbẹ n lọ lọwọlọwọ ni apa kan ilẹ Palẹstini nisisinyi. Ilẹ naa kún fun akitiyan lọpọlọpọ. Awọn Ju n sa gbogbo ipa wọn lati tun ilu wọn kọ. Ni May 15, 1948, Israẹli tun di orilẹ-ède. Eredi eyi? Gẹgẹ bi asọtẹlẹ, iyipada ti o de si awọn Ju kò ni itumọ miran ju eyi pe, ipadabọ Jesu Kristi Oluwa kù si dẹdẹ. Owe igi ọpọtọ jẹ apejuwe ohun ti o n ṣẹlẹ loni. Idọgba kan wà laarin owe yi ati iran egungun gbigbẹ ti Esekiẹli ri, ti o sọ fun ni nipa ariwo kan, mimi, ati wiwa ekinni sọdọ ekeji, egungun si egungun rẹ. A ni lati fi awọn ori Iwe Mimọ meji wọnyi si ọkàn bi a ti n ba ẹkọ wa lọ.

Ọwọ OLUWA wà li ara mi, o si mu mi jade ninu ẹmi OLUWA, o si gbe mi kalẹ li ārin afonifoji ti o kún fun egungun,

O si mu mmi rin yi wọn ká: si wò o, ọpọlọpọ ni mbẹ ni gbangba afonifoji; si kiyesi i, nwọn gbẹ pupọpupọ.

O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, egungun wọnyi le yè? Emi si wipe, Oluwa ỌLỌRUN, iwọ li o le mọ.

O tun wi fun mi pe, Sọtẹlẹ sori egungun wọnyi, si wi fun wọn pe, Ẹnyin egungun gbigbẹ, ẹ gbọ ọrọ OLUWA. Bayi li Oluwa ỌLỌRUN wi fun egungun wọnyi; Kiyesi i, emi o mu ki ẽmi wọ inu nyin, ẹnyin o si yè:

Emi o si fi iṣan sara nyin, emi o si mu ẹran wá sara nyin, emi o si fi awọ bò nyin, emi o si fi ẽmi sinu nyin, ẹnyin o si yè; ẹnyin o si mọ pe emi li OLUWA.

Bẹni mo sọtẹlẹ gẹgẹ bi a ti paṣẹ fun mi: bi mo si ti sọtẹlẹ, ariwo ta, si wò o, mimi kan si wà, awọn egungun na si wá ọdọ ara wọn, egungun si egun rẹ.

Nigbati mo si wò, kiyesi i, iṣan ati ẹran-ara wá si wọn, àwọ si bò wọn lóke: ṣugbọn ẽmi kò si ninu wọn.

Nigbana li o sọ fun mi, pe, ọmọ enia, Sọtẹlẹ si ẽmi, sọtẹlẹ, si wi fun ẽmi pe, Bayi li Oluwa ỌLỌRUN wi: Iwọ ẽmi, wá lati igun mẹrẹrin, si mi si okú wọnyi, ki nwọn ba le yè.

Bẹẹni mo sọtẹlẹ gẹgẹ bi a ti paṣẹ fun mi, ẽmi na si wá sinu wọn, nwọn si yé, nwọn si dide duro li ẹsẹ wọn, ogun nlanla.

Nigbana li o sọ fun mi pe, Ọmọ enia, egungun wọnyi ni gbogbo ile Israẹli: wò o, nwọn wipe, Egungun wa gbẹ, ireti wa si pin: ni ti awa, a ti ke wa kuro.

Nitorina sọtẹlẹ ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa ỌLỌRUN wi; Kiyesi i, ẹnyin enia mi, emi o ṣi iboji nyin, emi o si mu ki ẹ dide kuro ninu iboji nyin, emi o si mu nyin wá si ilẹ Israẹli.

Ẹnyin o si mọ pe emi li OLUWA, nigbati emi bá ti ṣi iboji nyin, ẹnyin enia mi, ti emi bá si mu nyin dide kuro ninu iboji nyin.

Emi o si fi ẹmi mi sinu nyin, ẹnyin o si yè, emi o si mu nyin joko ni ilẹ ti nyin: nigbana li ẹnyin o mọ pe, emi OLUWA li o ti sọ ọ, ti o si ṣe e, li OLUWA wi” (Esekiẹli 37:1-14).

Ojo Arọkuro ti a Ṣeleri

A ti mọ pe Ọlọrun sọ fun awọn Ọmọ Israẹli pe bi wọn ba feti silẹ gidigidi ti wọn si gbọran si aṣẹ Oun, Oun yoo bukun wọn nipa rirọ àkọrọ ati àrọkuro òjo sori ilẹ wọn; ṣugbọn bi wọn kò ba gbọran, a kò ni fun wọn ni òjo (Deuteronomi 11:10-17). Nwọn ṣaigbọran; fun ọpọlọpọ ọdún a kò rọjo sori ilẹ wọn. Ni nkan bi ọgọrun ọdún sẹhin, oju-ọjọ ilu Palẹstini yi pada. Ni ọdún 1869 si 1870 iwọn ojo ti o rọ jẹ inṣi mejila (12 in) abọ (lori oṣuwọn ti a fi n mọ bi òjo ti rọ tó); ni ọdún 1877 si 1878 o fẹrẹ to inṣi mẹtalelogoji (42.95 in). Ṣugbọn ki i ṣe bayi ni o n ri nigbà gbogbo, ti ọdún ti o kẹhin yi si yatọ. Laarin ọdún 1860 si 1892 òjo àrọkuro bẹrẹ si pọ si i ni ọna iyanu. A sọ fun ni pe iwọn ojo ti o n rọ nibẹ ni ọdọọdún nisinsinyi jẹ nkan bi inṣi mẹrindinlọgbọn (26 in), nkan biilọpo meji iwọn ti atẹhinwa fun ọpọlọpọ ọdún – eyi pọ ju iwọn ojo ti o n rọ ni Berlin olu-ilu Jamani tabi London ilu ọba. (Iwọn ojo ti o n rọ ni Portland Oregon, ibujoko Iya Ijọ wa fẹrẹ to inṣi mejilelogoji (42.62 in).

Ibẹrẹ Ipadabọ awọn Ju

Bi ojo arọkuro ti bẹrẹ lati tun maa rọ, awọn “egungun gbigbẹ” ti Esekiẹli sọtẹlẹ nipa rẹ ti bẹrẹ si ji pepe. “Egungun wọnyi ni gbogbo ile Israẹli” ti yoo wà laaye lọjọ wọnni, awọn iboji ni awọn orilẹ-ède ibi ti awọn Ju gbé wà lati nkan bi ẹgbaa ọdún sẹhin.

A rú ireti awọn Ju soke gidigidi gẹgẹ bi orilẹ-ède, nigba ti a dá Ẹgbẹ Sioni Agbaye silẹ ni ọdun 1897, ẹgbẹ oṣelu, ti ki i ṣe ẹgbẹ nipa ẹsin, ti a da silẹ lati ṣe eto bi awọn Ju yoo ṣe pada si ilẹ wọn. Awọn eniyan kò lero wi pe ẹgbẹ yi le ṣe nkan ti o nilaari ni ibẹrẹ. Ṣugbọn o n dagba soke, a si ṣe akiyesi pe ninu awọn ipade ọdọọdun ti wọn maa n ṣe, itara wọn bẹrẹ si pọ si i.

Nitori bayi li OLUWA wi; Gẹgẹ bi emi ti mu gbogbo ibi nla yi wá sori awọn enia yi, bẹẹni emi o mu gbogbo rere ti emi ti sọ nipa ti wọn wá sori wọn.

Enia o si rà oko ni ilẹ yi, sipa eyiti ẹnyin wipe, Ahoro ni laisi enia, laisi ẹran, a fi le ọwọ awọn ara Kaldea.

Enia yio fi owo rà oko, nwọn o kọ ọ sinu iwe, nwọn o si di i, nwọn o si pe awọn ẹlẹri ni ilẹ Bẹnjamini, ati ni ibi wọnni yi Jerusalẹmu ka, ati ni ilu Juda, ati ni ilu ọwọ-oke na, ati ni ilu afonifoji, ati ni ilu iha gusu; nitori emi o mu igbekun wọn pada wá, li OLUWA wi” (Jeremiah 32:42-44).

Ki a to dá ẹgbẹ yi silẹ a kò gbà fun awọn Ju lati ra ilẹ ni Palẹstini. Nigba ti ipaarọ ijọba de si orilẹ-ède Turkey ti awọn Ẹgbẹ Ọdọ Turkey di alakoso ijọba, ọba wọn n fẹ owo si i, nitori naa o gbà fun awọn Ju lati ra ilẹ. Nigbà yi ni awọn Ju bẹrẹ si i lọ si ilẹ ileri diẹdiẹ. Wọn bẹrẹ si pọ si i ni iye.

Ni ọdun 1827, awọn Ju ti o wa yi Jerusalẹmu ká jẹ ẹẹdẹgbẹta (500), ṣugbọn ni ọdún 1882, awọn Ju ti di nkan bi ẹgbaaji (4000). Wọn si tun pọ si i nigbà ti ilẹ Palẹstini bọ si abẹ itọju Ijọba Gẹẹsi, Jerusalẹmu si ti bẹrẹ si i di olokiki lọ laarin orilẹ-ède agbaye loni. “Bayi li Oluwa ỌLỌRUN wi; Eyi ni Jerusalẹmu: Emi ti gbe e kalẹ li ārin awọn orilẹ-ède, ati awọn ilẹ ti o wà yi i ka kiri” (Esekiẹli 5:5). Laarin ọdún mejilelọgbọn lati 1882 titi de 1914, ẹyọ Ju meji pere ninu ọgọrun kan ni o wá si ilẹ Palẹstini ninu awon ọpọlọpọ Ju ti o n ṣi kuro ni ilu wọn lati lọ gbe ni ilẹ miran, ṣugbọn lati 1919 si 1931 mẹẹdogun ninu ọgọrun ni o wa. Lati ọdun 1932 si 1947, aadọta tabi ọgọta ninu ọgorun ni o wa si ilẹ Palẹstini. Ki i ṣe pe a ri wura tabi epo wà jade ninu ilẹ tabi pe a dá iṣẹ silẹ nibẹ ni o mu ki wọn maa pọ si i bayi ni ilẹ Palẹstini. Kò si idi miran bi kò ṣe pe igi ọpọtọ ti bẹrẹ si rudi o si n rúwe.

Nwọn o si mọ ibi ahoro atijọ wọnni, nwọn o gbe ahoro atijọ wọnni ro, nwọn o si tun ilu wọnni ti o ṣofo ṣe, ahoro iran ọpọlọpọ” (Isaiah 61:4).

Ikede Balfour

Ni opin ọdun 1916, nigba ti ọpọlọpọ orilẹ-ède n ja Ogun Ajakaye kinni lọwọ, wahala bá orilẹ-ède Gẹẹsi ati Faranse nitori pe ohun alumọni kan bayi ti a n lo lati fi ṣe ohun ijà ogun tan lọwọ wọn. Ọdọmọkunrin Ju kan ara Russia ti i ṣe profẹsọ ninu ẹkọ kẹmistiri ni Yunifasiti ti Manchester ni ilẹ Gẹẹsi ṣe awari ágbà ẹlẹtù kan ti o lagbara gidigidi. Ijọba Gẹẹsi dán nkan naa wò, wọn si ri i pe o n ṣiṣẹ iparun gidigidi ni igbà naa ju awọn ẹtù iyoku. T.N.T. ni a n pe ẹtù naa. Wọn beere lọwọ olukọ Kẹmistiri yi iye owo ti yoo gbà fun iṣẹ rẹ nitori owo nlánlà ni o tọ si i lati gbà. O dahun pe, “N kò fẹ owo rara, ṣugbọn ẹ gba ilẹ Palẹstini ki ẹ si jẹ ki awọn Ju pada sibẹ. Eyi ni ohun ti mo fẹ ki ẹ ṣe fun mi.”

Ijọba Gẹẹsi ri i pe, ohun ijà ti ọgbẹni yi ṣe gba awọn ati awọn ti o wà nià ti wọn silẹ lọwọ iparun ni akoko iṣoro, nitori naa ni November 2, 1917, wọn gbé ikede kan jade ti a npe ni Ikede Balfour, ninu eyi ti wọn ṣeleri lati ran awọn Ju lọwọ lati tun fi Palẹstini ṣe ile wọn. Eyi ni apa kan ohun ti a kọ sinu iwe pataki yi:

Ijọba Gẹẹsi fi tayọtayọ gbà lati fun awọn Ju ni ibugbe ni Palẹstini gẹgẹ bi Ọmọ Ibilẹ, Ijọba yoo si sa ipa rẹ lati mu ki eyi ṣe e ṣe: ṣugbọn ki o di mimọ dajdaju pe, a kò ni ṣe ohunkohun ti o lodi si ofin iṣelu ati ẹtọ ẹsin awọn miran ti ki i ṣe Ju ni Palẹstini, tabi anfaani ti awọn Ju ti o wà ni orilẹ-ède miran.”

Awọn Ju jake-jako gbogbo agbaye yọ ayọ nla nigba ti a gbé ikede yi jade. Awọn ẹlomiran gbà pe eyi fara jọ ikede ti Kirusi Ọba Persia ṣe lati fi opin si igbekun akọkọ awọn Ju. Lori akete ikú rẹ, Ọlọla Balfour ke si awọn Gẹẹsi lati mu ipinnu yi ṣẹ fun awọn Ju, ki wọn má ṣe sọ ẹjẹ ti o lọwọ yi di “iwe lasan ti kò nilaari.”

Jijá Ilẹ Mimọ gbà Lọwọ awọn ara Turkey

Nigba yi, ilẹ Palẹstini wá labẹ akoso awọn ara Turkey ti o ti fara mọ awọn Jamani lati jagun. Fun anfaani Gẹẹsi funra rẹ o kan dandan pe ki a le Turkey kuro ni ilẹ Palẹstini.

Ni oṣu kan lẹhin Ikede Balfour, awọn ẹgbẹ ogun Gẹẹsi labẹ ọgagun ti a n pe ni Allenby gba ilẹ Palẹstini. Bi balogun yii ati awọn ọmọ ogun rẹ ti n sun mọ Jerusalẹmu, o n ronu ọna ti o dara ju lati fi gbà Jerusalẹmu. Oun kò fẹ ta ẹjẹ silẹ ni ilu mimọ yii, tabi ki o ba ibikibi nibẹ jẹ. Onigbagbọ ni Ọgagun Allenby i ṣe. Nigbà ti o wà ni tosi ilu yii o tẹ waya abẹ omi ṣọwọ si ọba ilu Oyinbo lati beere pe ki oun pa ilu yii run tabi bẹẹ kọ, bi kò ba ṣe e ṣe lati gba a. Ọba tẹ waya abẹ omi pada pe ki o gbadura ki o ṣe eyi ti o ba tọ loju rẹ. Ni akoko yii gan an ni ihin tàn kalẹ ninu ilu pe ẹgbẹ ogun ti o lagbara pupọ n bọ wá, ọgagun wọn ni a si n pe ni Allenby, eyi ti awọn tumọ ni ède wọn si Allah Be, Woli Ọlọrun. Jinnijinni mu awọn ọmọ-ogun Turkey wi pe Ọlọrun binu si wọn, wọn si pinnu lati ran ikọ wi pe awọn tuba. Ọlọrun ni o ran ẹni ti o tọ ti o si ni orukọ ti o tọ fun iṣẹ naa.

Bi Ọgagun Allenby ati awọn Balogun rẹ gbogbo ti n gbadura lọwọ ni ọjọ kọkanla oṣu kejila ọdun 1917, (11.12.1917), ti awọn ọkọ ofuurufu si n rà bàbà bi ẹyẹ loju ọrun, ikọ ti awọn Turkey rán wa de, wọn si tuuba. Igbà mẹtadinlọgbọn ni a ti kó Jerusalẹmu ṣiwaju akoko yii, ṣugbọn igbà yii nikan ṣoṣo ni a gba a silẹ ni imuṣẹ Ọrọ Ọlọrun yii ti o wi pe: “Gẹgẹ bi ẹiyẹ iti ifi iyẹ apa ṣe, bẹẹni OLUWA awọn ọmọ-ogun yio dábòbò Jerusalẹmu: ni didābòbo o pẹlu yio si gbà a silẹ; ni rirekọja on o si dá a si” (Isaiah 31:5). Ni oṣu kẹta ọdún 1918, a ta asia Ju ti o n fẹ lẹlẹ lati Ile-iṣọ Dafidi ni apa kan ilu ti o wà lati igbà ni; Ọgagun Allẹnby si kede pe ilẹ Palẹstini di ti awọn Ju.

Nitorina, sa wò o, Bayi li OLUWA wi, ọjọ mbọ, ti a ki o wi mọ pe, OLUWA mbẹ ti o mu awọn ọmọ Israẹli jade kuro ni ilẹ Egipti;

Ṣugbọn, OLUWA mbẹ ti o mu awọn ọmọ Israẹli jade wá kuro ni ilẹ ariwa, ati kuro ni ilẹ nibiti o ti lé wọn si: emi o si tun mu wọn wá si ilẹ wọn, eyiti mo fi fun awọn baba wọn.

Sa wò o, emi o ran apẹja pupọ, li OLUWA wi, nwọn o si dẹ wọn: lẹhin eyini, emi o rán ọdẹ pupọ, nwọn o si dẹ wọn lati ori oke-nla gbogbo, ati ori oke kekere gbogbo, ati lati inu palapala okuta jade.

Nitoriti oju mi mbẹ lara ọna wọn gbogbo: nwọn kò pamọ kuro niwaju mi, bẹẹni ẹṣẹ wọn kò farasin kuro li oju mi” (Jeremiah 16:14-17).

Pinpin Ilẹ Naa

Awọn oṣelu gbà wi pe ilẹ ti yoo to fun awọn Ju ni ihà ihin ati ihà ọhun Jọrdani ni lati to nnkan bi ọkẹ mẹta (60,000) mile, ọgbọọgba ni ayika igun mẹrẹẹrin ilẹ naa. Awọn Larubawa ti a gbà silẹ nigbà naa pẹlu, ni a fun ni ilẹ bi aadọta ọkẹ (1,000,000) mile, ọgbọọgba ni ayika igun mẹrẹẹrin. Nigbà naa awọn Larubawa gbà wi pe bi a ti ṣe yanju ẹtọ ti awọn Heberu fun wọn yii tọna o si dara.

Nigbooṣe a ge ilẹ awọn Ju kù si ọkẹ meji le ẹgbẹẹdọgbọn mile (45,000) ọgbọọgba ni ihà igun mẹrẹẹrin, bi o tilẹ jẹ wi pe ọgbẹni Woodrow Wilson, Aarẹ ilẹ Amẹrika tako gige yii, o si wipe eyi ti wọn gee ku ni ilẹ ti o kere ju, ninu eyi ti wọn le maa gbe, ki wọn si le ṣe itọju ara wọn. Eyi ni pipin kinni ilẹ na.

Lẹhin eyi, awọn Gẹẹsi tun ge iha ila-oorun Jọrdani kuro wọn sọ ọ di ẹkun kan ni iha ihin Jọrdani, wọn si fi i fun ọba yẹpẹrẹ kan. Eyi din ilẹ Palẹstini kù si ẹgbaarun (10,000) mile ọgbọọgba ni iha mẹrẹẹrin. ‘Iwe Ikede Eto Ohun Ti Ijọba Yoo Ṣe’ eyi ti Churchill gbé jade ni ọjọ kẹta oṣu kẹfa ọdún 1922 ni aṣẹ ti o ti gige yii lẹhin. Eyi ni pipin ilẹ lẹẹkeji.

Awọn Gẹẹsi tun ṣe fitafita ni ọdun 1937 lati tun ṣe atunpin ilẹ naa. Awọn ti o jẹ aṣiwaju fun awọn Ju tilẹ fẹ gbà bẹẹ ṣugbọn awọn eniyan takú mọ wọn lọwọ. Ṣugbọn awọn Gẹẹsi wá bori nipa kikó si abẹ Igbimọ Awọn Orilẹ-ède lati tun un pin. Ni ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kọkanla ọdun 1974, eniyan mẹtalelọgbọn ninu awọn aṣoju ti o wà ninu Apapọ Igbimọ Awọn Orilẹ-ède fọwọ si i pe ki a tun un pin, awọn mẹtala kò gbà bẹẹ, nipa bayii awọn ti o pọ ju bori a si din ilẹ awọn Ju kù si nnkan bi ẹgbẹẹdọgbọn o le ẹdẹgbẹta (5,500) mile, ọgbọọgba ni ihà mẹrẹẹrin – eyi fi diẹ tobi ju ipinlẹ Connecticut ni ilẹ Amẹrika. Eyi ni pipin ilẹ lẹẹkẹta.

Ni nnkan bi ẹẹdẹgbẹrinla (2700) ọdun sẹhin, Oluwa ṣe ikilọ fun awọn orilẹ-ède ti yoo pin ilẹ Rẹ ni ikẹhin ọjọ: “Nitorina kiyesi i, li ọjọ wọnni, ati li akokò na, nigbati emi o tun mu igbèkun Juda ati Jerusalẹmu pada bọ. Emi o kó gbogbo orilẹ-ède jọ pẹlu, emi o si mu wọn wá si afonifoji Jehoṣafati, emi o si ba wọn wijọ nibẹ nitori awọn enia mi, ati nitori Israẹli ini mi, ti nwọn ti fọn ka sārin awọn orilẹ-ède, nwọn si ti pin ilẹ mi” (Joẹli 3:1, 2). (Ka Daniẹli 11:36-39 pẹlu). Ilẹ Palẹstini, bi o ti ri lọjọ oni, kò ju nnkan bi idamẹwa ilẹ ti Ọlọrun ṣeleri fun wọn. Ibu rẹ jẹ aadọta (50) mile, gigun rẹ si jẹ aadọjọ (150) mile. Awọn aala ilẹ ileri ni ibẹrẹ pẹpẹ ni iwọnyi: odò Egipti ni ihà gusu, Euferate ni ihà ariwa, Aṣalẹ Arabia ni ihà ila-oorun, ati okun Mediterranean ni ihà iwọ-oorun. Ilẹ ti atijọ tobi ni ilọpo mẹẹdọgbọn ibi ti Israẹli wà nisinsinyi (Gẹnẹsisi 15:18; Ẹksodu 23:31).

Awọn Gẹẹsi fẹ mú abojuto wọn lori ilẹ Palẹstini wá si opin kankan, wọn si jọwọ rẹ fun awọn Alaṣẹ Igbimọ Awọn Orilẹ-ède ni ọjọ kẹẹdogun oṣu karun ọdun 1948, nipa bẹẹ akoso wọn ọdún mẹrindinlọgbọn (26) ti o bẹrẹ pẹlu ọpọlọpọ ileri wá si opin laarin idarudapọ, idaamu ati ijatilẹ.

Orilẹ-ède Titun

Awọn Ju kaakiri gbogbo agbayé ti n foju sọna pe ki akoso awọn Gẹẹsi dopin. Wọn si ṣeto gidigidi lati da orilẹ-ède ti yoo jẹ ti awọn ọmọ ibilẹ Ju silẹ. Wọn mura silẹ lati kede idasilẹ orilẹ-ède titun -- orilẹ-ede ISRAẸLI. Iwe irohin pataki kan ti ogunlọgọ eniyan n kà kọ akọsilẹ ti o dún mọ ni pupọ nipa ohun ti o ṣẹlẹ gẹrẹ bi ọjọ kẹrinla oṣu karun ọdún 1948 ti n lọ sopin ti ilẹ ọjọ kẹẹdogun oṣu karun si n mọ. Eyi ni adàkọ apa kan irohin naa: “A bi Israẹli ninu irora irọbi ati ireti. Bi ilẹ ti n ṣu lọ ni May 14, 1948 – eyi ti i ṣe ọjọ kẹrinlelogun oṣu Iyari ti wọn ni ẹgbẹẹdọgbọn o le ẹẹdẹgbẹrin le mẹjọ (5708) ọdún lẹhin dida aye -- awọn Ju ti o wà ni Palẹstini pejọ ni ilu ati ileto wọn gbogbo lati ṣe ajọyọ ọjọ má-ni-gbagbe ninu igbesi aye wọn yi. O ku wakati mẹjọ ki akoko awọn Gẹẹsi dopin, ṣugbọn aṣoju ikẹhin fun ijọba Gẹẹsi nibẹ ti yẹra sinu ọkọ oju omi kan ni ebute Haifa. Nibẹ ni o wà ti o si n woye bi oorun ti n wọ lọ lori okun Mediterranean ti wiriwiri aṣaalẹ si boju ajakù ijọba ogbologbo. O jinna pupọ si ebute, kò si le gbọ bi awọn Ju ti n kọ orin wọn HATIKFAH (Orin Ireti), ṣugbọn o mọ ọrọ orin naa: ‘Awa kò ti i gbagbe, a ki yoo si gbagbe ileri ọwọ wa …’ Ni Tel Aviv, ti kiki awọn Ju nikan n gbe, ti wọn fẹ fi ṣe olu-ilu wọn ni Olootu David Ben-Gurion mu ẹgbaa (2000) ọdún ti awọn Ju ti fi n reti lati ni igbugbe ti ara wọn, bi ọmọ ibilẹ wá si opin, o si fi ikuku ọwọ rẹ lu tabili bi o ti n sọrọ. O sọ ni ohun jẹjẹ pe, “Israẹli ni a o maa pe orilẹ-ède wa;” bayi ni orilẹ-ède titun bẹrẹ.”

Gbara ti wọn di orilẹ-ède ni awọn orilẹ-ède miran bẹrẹ si i fọwọ si i wi pe wọn kà wọn si. Amẹrika ati Russia gba lati ka wọn si orilẹ-ède ni kiakia. Nigba ti yoo fi di ọjọ kejilelogun oṣu kẹta ọdun 1949, orilẹ-ède mẹrindinlaadọta (46) fi ọwọ si i wi pe wọn gbà tootọ pe orilẹ-ède ni Israẹli i ṣe. Ni ọjọ kọkanla oṣu karun ọdun 1949, a gbà Israẹli si ẹgbẹ Awujọ Awọn Orilẹ-ède gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ kọkandinlọgọta (59).

Ni ọjọ kẹrindinlogun oṣu karun ọdun 1948, Dokita Chaim Weizmann, ọlọgbọn ori ti o ṣe awari T.N.T ni wọn sọ pe yoo jẹ Aarẹ orilẹ-ède wọn ti o wà ni ikorita agbaye, nitosi ibi ti mẹta ninu awọn ipinlẹ mẹfa ti a pin oju ilẹ aye si gbe pade. Ni ọjọ kẹtadinlogun oṣu keji ọdun 1949 (17-2-49), ni a fi jẹ Aarẹ kinni orilẹ-ède Israẹli ti a fi ibo yan. Fun igbà akọkọ lati nnkan bi ẹgbaa ọdun, awọn Ju yan ẹni kan ninu ara wọn lati jẹ olotu orilẹ-ède wọn.

Awọn adajọ agbaagba ti Ile Idajọ giga ju lọ ni Israẹli gori aga idajọ lai pẹ lẹhin eyi; iru wọn ko tii si lati nnkan bi ẹgbaa ọdun sẹhin. Ni oṣu keji ọdun 1949, awọn ọgọfa aṣoju ti awọn eniyan tikara wọn yàn pade ni Jerusalẹmu. Lati igbà ti igbimọ awọn Ju, alaadọrin eniyan (ti a n pe ni Sanhedrin) ti kásẹ lati nnkan bi ẹgbaa ọdún, kò si iru awọn aṣoju bayi mọ ni Ilẹ Mimọ.

Wahala n Bọ

Gẹrẹ ti awọn Gẹẹsi yọwọ kuro ninu akoso ilẹ yii ti a si dá orilẹ-ède Israẹli silẹ, ogun dó ti wọn. Awọn Larubawa pọ ni ilọpo meji ju awọn Ju ni Palẹstini, awọn orilẹ-ède Larubawa meje ti kò fẹran wọn ni o wa yii wọn ka: Iha-ihin Jọrdani, Iraq, Siria, Lẹbanoni, Egipti, Yemen ati Saudi Arabia ti apapọ wọn jẹ aadọta-le-lẹgbẹjọ ọkẹ eniyan (33,000,000). Wọn fẹrẹ ma ti i pari ikede pe Israẹli di orilẹ-ède tan ti awọn Larubawa ti o ti ni ẹtanú si wọn yii ti dide ijà. O dabi ẹni pe gbogbo rẹ pin fun Israẹli. Ṣugbọn akẹkọ Bibeli, kò ṣoro lati mọ ẹni ti yoo ṣẹ ogun naa: Israẹli ni o ni iṣẹgun. Ọrọ Ọlọrun kò ni ṣe alai ṣẹ. Eyi jẹ ọkan ninu awọn eto Ọlọrun lati tun fi idi awọn eniyan Rẹ mulẹ ni ilẹ wọn. “Akoko awọn keferi” n sure tete lọ si opin.

Lẹhin oṣu mẹwa-aabọ ti Israẹli ti tun pada di orilẹ-ède, awọn ọmọ-ogun wọn ti ṣẹgun apapọ orilẹ-ède mẹfa ti o dojujà kọ wọn. Wọn fọwọ si iwe pe ogun pari, wọn si bẹrẹ si ṣe eto bi wọn yoo ti ṣe dá majẹmu ki alaafia ba le wà.

Apakan Jerusalẹmu ibi atijọ ti a mọ odi yika ni o wa lọwọ awọn ọmọ-ogun Larubawa sibẹsibẹ. O fẹrẹ jẹ pe gbogbo Jerusalẹmu ti kò si ninu odi ni wà lọwọ Israẹli, o si wa lọkàn wọn lati sọ Jerusalẹmu di olu-ilu wọn. Ani awọn alakoso ijọba wọn tilẹ ti pinnu lati gbé awọn Minista marun ati ile-iṣẹ ijọba marun lọ si Jerusalẹmu, won si ti yàn igbimọ eniyan mẹta lati ṣe abojuto bi a o ti ṣe kó awọn ibi iṣẹ ijọba iyokù wa si Ilu Mimọ. Jesu wi pe “Jerusalẹmu yio si di itẹmọlẹ li ẹsẹ awọn Keferi, titi akoko awọn Keferi yio fi kún” (Luku 21:24).

Apakan Jerusalẹmu ti i Ṣe Ti Atijọ

“Ilu Atijọ” yi ni awọn ibi mimọ ti o kun fun itan wà. A sọ fun Abrahamu lati lọ sibẹ lati fi ọmọ rẹ kan ṣoṣo, Isaaki, rubọ ni ibi ti Mọsalasi Omar gbe wa nisinsinyi. Nibẹ kan naa, lori oke Moria ni Sọlomọni kọ Tẹmpili si. Esra tun un kọ lẹhin isinru wọn ni Babiloni. Nibẹ kan naa ni Tẹmpili Hẹrọdu Nla gbé wa titi Titu Alaṣẹ Romu fi wo o palẹ ni aadọrin ọdún lẹhin ibi Jesu.

Ibi Ogiri Ọfọ ti o fọ kù ninu Tẹmpili ti atijọ nikan ni o wà lọwọ awọn Ju. Fun ọpọlọpọ ọdún ni wọn ti maa n pejọ sibẹ lati gbadura ati lati ṣọfọ ni ọjọọjọ kẹfa ọsẹ. Ọgbẹni akọwe kan wi pe: “Wọn a maa gbe oju wọn le ogiri, wọn a si maa sọkun sori okuta pẹlu omije pẹrẹpẹrẹ loju wọn, wọn a kigbe wi pe, “Ha! Ọlọrun ran Messiah si wa!” Nibomiran o sọ fun ni wi pe wọn a maa fi ẹnu ko awọn okuta lẹnu, wọn a da omije loju pẹrẹpẹrẹ. Ẹni kan pataki ninu awọn oloye Ẹgbẹ Sioni ṣe apejuwe ẹkún wọn pẹlu ọrọ wọnyi: “Hihan ti o dun leti ni, pẹlu imi-ẹdùn taanu-taanu, ẹkún ti o ṣe ni laanu, pẹlu orin adapọ ohùn ti o ti ete jade wi pe, “Yoo ti pẹ to, Ọlọrun?”

Ohun ti o leke ọkàn awọn Ju ni lati tun Tẹmpili kọ. Ọpọlọpọ ninu awọn Ju ti o wà ni Jerusalẹmu kọwe ẹbẹ si awọn Ẹgbẹ Agbajọ Orilẹ-ède pe ki wọn yọọda ilẹ Tẹmpili atijọ fun wọn lati tun un kọ, ṣugbọn wọn ba ijatilẹ pade; lai pẹ yii wọn dá ile-ẹkọ oniwaasu kan silẹ ni Jerusalẹmu lati kọ awọn ọdọ bi a ti ṣe n ṣe iṣẹ-isin Tẹmpili ati irubọ. Ninu awọn iwe ti ile-ẹkọ awọn oniwaasu yi tẹ jade ni a ti ri awọn ọrọ wọnyi ka: “Ọjọ ologo naa fẹrẹ de ti a o tun kọ Tẹmpili lọtun, ti a o si tun bẹrẹ si ṣe irubọ lẹẹkan si i.”

Ìṣílọ

Tani wọnyi ti nfò bi awọsanma, ati bi awọn ẹiyẹle si ojule wọn?

Nitõtọ erekuṣu wọnni yio duro dè mi, ọkọ Tarṣiṣi wọnni li ekini, lati mu awọn ọmọ rẹ ọkọnrin ti ọna jijin wá fadaka wọn, ati wura wọn pẹlu wọn, fun orukọ OLUWA Ọlọrun rẹ, ati fun Ẹni-Mimọ Israẹli, nitoriti on ti ṣe ọ logo.

Awọn ọmọ alejo yio si mọ odi rẹ: awọn ọba wọn yio si ṣe iranṣẹ fun ọ: nitori ni ikánnu mi ni mo lù ọ, ṣugbọn ni inu rere mi ni mo si ṣānu fun ọ” (Isaiah 60:8-10).

Fun ọpọlọpọ ọdún ni awọn Ju ti a tú kaakiri gbogbo orilẹ-ède aye fi n gbadura si ihà Jerusalẹmu pẹlu ọkàn ti o fẹ pada si ilẹ wọn. Nisinsinyi, ogunlọgọ wọn ni o n pada si ilẹ wọn lati ọpọlọpọ orilẹ-ède agbaye. Palẹstini kò dá ijọba ti rẹ ni lati gba ti Ijọba Romu ti ṣẹgun wọn ni ọdun kẹtalelọgọta ṣiwaju ibi Jesu, ṣugbọn wọn n ti abẹ ijọba kan bọ si omiran. Awọn Ju ti o pada sile ni nnkan bi ọgọrun ọdún ṣiwaju bá ilẹ naa bi ahoro, awọn eniyan ti wọn si wa nibẹ kò ju nnkan bi ọkẹ mẹẹdogunn (300,000). Ni nnkan bi ọdun diẹ sẹhin awọn Larubawa ti o n wọ ilẹ naa jẹ ilọpo mẹfa awọn Ju ti o n pada wa si ilẹ wọn. Idi rẹ ti o fi ri bẹẹ ni pe awọn Ju ti tun ilẹ naa ṣe, osi wulo ni akoko yi. Ọpọlọpọ awọn nnkan ti awọn Ju ni loni ni wọn rà lọwọ awọn Larubawa ni ọdun pupọ sẹhin ni ọwọn-gogo si oju-owo ohun ti wọn jẹ gan an bi a ba wo iru ipo alòkù ti awọn nnkan bẹẹ wa.

Idojukọ nlá nlà ni o mu ki o ṣe e ṣe lati bẹrẹ ipadabọ awọn Ju. Ṣiwaju Ogun Ajakaye Keji, awọn Ju ti o wà ni Jamani jẹ alatako fun awọn Ẹgbẹ Sioni ati ipada lọ si Palẹstini. Wọn ti di alagbara ati olokiki ni ilu Jamani, wọn si lọrọ gidigidi. Ṣugbọn Ọrọ Ọlọrun ki yoo ṣe alai ṣẹ! Gbogbo awọn Ju ni lati pada si ilẹ wọn nigbooṣe; bayii ni Oluwa mu ki “ibinu eniyan” ki o yin Oun, O si gba adánikan-paṣẹ kan layè lati dide, ipinnu ẹni ti i ṣe lati pa awọn Ju run kuro lori ilẹ aye. Awọn Ju ti ọwọ kò tẹ ni orilẹ-ède Jamani ati Austria nigba naa n wa ọna lati pada lọ si ilẹ Israẹli nisinsinyi.

Laarin ogun ajakaye ekinni ati ekeji, nnkan bi ọkẹ mẹẹdọgbọn (500,000) Ju ni wọn ti pada sile. Ni akoko Ogun Ajakaye Keji, o ṣoro fun wọn lati pada sile, paapaa ju lọ, nitori ofin lile koko ti Gẹẹsi fi lelẹ. Ṣugbọn nisinsinyi awọn Ju le pada bi wọn ba fẹ: ọkẹ mẹfa ati aabọ (130,00) ninu awọn Ju lati aadọrin orilẹ-ède ni wọn ti pada de Israẹli ni ọdun 1948. Iye awọn ti wọn n pada nisinsinyi jẹ nnkan bi ẹgbẹrun (1,000) lojumọ, iru awọn eniyan ti o pọ to bayii kò tii ṣe bẹẹ maa wa si ilẹ Amẹrika lati igbà ti a ti tẹ ẹ do. Ni ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹta ọdun 1949, ẹdẹgbaarin (7,000) ni wọn pada si Israẹli. Ile-iṣẹ awọn Onirohin Israẹli ti o wà ni Amẹrika gbe iṣiro le e pe awọn Ju ti yoo pada si ilẹ wọn ni ọdun 1949 yoo to ọkẹ mẹtadinlogun ati aabọ (350,000). Nigba ti a ka iye awọn eniyan ti o wa labẹ akoso ijọba Israẹli ni ọjọ kẹjọ oṣu kọkanla ọdun 1948, o jẹ nnkan bi ogoji ọkẹ (800,000) eniyan, nnkan bi ọkẹ mẹrindinlogoji (720,000) jẹ Israẹli, awọn iyoku jẹ Larubawa ati orilẹ-ède miran. Awọn Ju ti o wà ni ilẹ wọn ni opin ọdun 1949 ju aadọta ọkẹ (1,000,000) lọ.

Li ọjọ na li emi o gbe agọ Dafidi ti o ṣubu ró, emi o si di ẹya rẹ: emi o si gbe ahoro rẹ soke, emi o si kọ ọ bi ti ọjọ igbani:

Ki nwọn le ni iyokù Edomu ni ini, ati ti gbogbo awọn keferi, ti a pè nipa orukọ mi, li OLUWA ti o nṣe eyi wi.

Kiyesi i, ọjọ na de, li OLUWA wi, ti ẹniti ntulẹ yio le ẹniti nkorè bá, ati ẹniti o ntẹ eso àjara yio le ẹniti o nfunrugbin bá; awọn oke-nla yio si kán ọti-waini didun silẹ, gbogbo oke kékèké yio si di yiyọ.

Emi o si tun mu igbèkun Israẹli enia mi padà bọ, nwọn o si kọ ahoro ilu wọnni, nwọn o si ma gbe inu wọn; nwọn o si gbin ọgbà-ajara, nwọn o si mu ọti-waini wọn; nwọn o ṣe ọgbà pẹlu, nwọn o si jẹ eso inu wọn.

Emi o si gbìn wọn si ori ilẹ wọn, a ki yio si fà wọn tu mọ kuro ninu ilẹ wọn, ti mo ti fi fun wọn, li OLUWA Ọlọrun rẹ wi” (Amosi 9:11-15).

A ṣe apejuwe bi Tel Aviv ti ri fun ni bayii: “Igboro rẹ kún fọfọ, lati ri ile gbe di ọran: iṣẹ ile kikọ n lọ lọtun losi. Bi ero ti n rọ wọ ilẹ Israẹli lati gbogbo agbaye yoo jẹ iyanu fun ni bi a ba mọ pe laarin ọdun mẹta tabi mẹrin si i, awọn ero ti o ti wọle yoo to ilọpo meji awọn ti o wà nibẹ ni ibẹrẹ ọdun 1949.” Bi awọn eniyan ba ṣe bẹ wa si Amẹrika laarin ọdun mẹta, wọn o pọ to ẹgbaa mejila aabọ ọkẹ (500,000,000) eniyan. Ṣugbọn a sọ fun ni pe awọn Ju ti a ba n ṣe inunibini si nibikibi ni gbogbo agbaye le maa bọ wá ki wọn si gba ikini kaabọ; bi eyi tilẹ ni wahala pupọ ninu, wọn o wá ọna tabi ọgbọn lati bori iṣoro naa. Akọwe kan sọ bayii pe: “Mo ti rori rori lati mọ ọrọ ti mo le fi ṣe apejuwe ohun ti mo ri ni Israẹli, ọrọ ti o bọ si mi lọkàn ni: Eyi ga ju. Mo ti kọ sọ pe iyanu ni, ha ṣe mi, eyi yatọ -- ṣugbọn ọrọ yi nikan (eyi ga ju) ni o ṣe apejuwe rẹ gan an.” Wọn n gba ori ilẹ, oju omi, ati ofuurufu pada si Israẹli. Ọgbẹni gbajumọ aṣèwé kan sọ pe oun ri i pe “eniyan ọtọ” ni awọn Ju i ṣe nitori pe awọn “nikan ni ajeji” ti o le lọ si ilu miran -- gẹgẹ bi awọn paapaa ti sọ fun ni – ki ‘ara tù wọn’ bi ẹni pe wọn wà ni ilu ti wọn.”

Awọn alatako awọn Ju maa n kọwe wi pe awọn Ju kaakiri gbogbo agbaye kò fẹ lati pada si ilẹ wọn, wọn tun sọ pe gbogbo awọn irohin miran ti n jade wi pe awọn Ju ti wọn wà ni ilẹ Europe gbogbo fẹ pada jẹ ikede eke lati ọdọ awọn ọmọ Ẹgbẹ Sioni ti wọn fẹ ki Igbimọ awọn Orilẹ-ède kin wọn lẹhin ki wọn ba le kó awọn ohun alumọni ti o wà ni ilẹ naa; ṣugbọn ijadelọ awọn Ju lati oriṣiriṣi ilu wa si Israẹli já awọn alatako wọnyi nirọ. Irohin fi hàn gbangba pe ida-aadọrun (90) ninu ọgọrun (100) eniyan ti o wà ni Agọ awọn ti kò ni ibugbe ati idá marundinlaadọrun 985) ninu ọgọrun (100) eniyan ti kò si ninu iru agọ wọnni ti o wà labẹ akoso awọn Amẹrika ni. Jamani ni wọn ti kọwe pe wọn fẹ pada si Israẹli, o si daju pe awọn ti yoo fẹ pada si ilẹ Israẹli, ninu awọn ti n bẹ ni ipinlẹ Jamani miran gbogbo kò tilẹ ni i ṣe fẹnu sọ tan. Ni ibẹrẹ 1949, awọn Ju ti o wà ni agọ awọn Faranse ati ti awọn Italy, ti wọn n duro de ọkọ ti wọn yoo wọ lọ si ilẹ wọn to nnkan bi ọkẹ marundinlogoji (700,000); awọn eniyan ti o si to ọkẹ meje (140,000) ti kò ni ibugbe ni ilu Jamani ati Austria fẹ pada si Israẹli ki ọdun 1949 to pari.

Idagbasoke

Eto awọn Alaṣẹ Afonifoji Jọrdani lati ná ẹẹdẹgbẹta lé ni egbaafa dọla ($250,000,000) naira jẹ ọkan ninu iṣẹ inawo ti o tobi ju lọ ti ọmọ eniyan ti i dawọ le. Eyi yoo pin Odo Jọrdani yẹlẹyẹlẹ ki wọn le maa fi bomi rin ilẹ wọn. Ọmọran kan sọ wi pe nnkan bi ọgbọn ọkẹ (600,000) ekari (acre) ilẹ aṣalẹ ni yoo di ilẹ ọlọra lọna bayi, eyi yoo si pese ilẹ fun ẹgbẹẹgbẹrun eniyan lati fi ṣe iṣẹ ọgbin.

Ọgbẹni ọjọgbọn kan ti n ṣeto ile kikọ nilu wi pe ọpọlọpọ ilu ti o le gba ọkẹ meji aabọ (50,000) tabi ọkẹ mẹta (60,000) eniyan ni wọn yoo kaakiri ilẹ Israẹli. Wọn ti bẹrẹ si kọ ile ti yoo to ọkẹ kan (20,000) ojule ni 1949 ati ọkẹ kan miran (20,000) ni 1950.

Awọn ile iṣẹ ti o n gbòrò si i yoo gba ọpọlọpọ ninu awọn ti wọn ṣẹṣẹ wọ ilu si iṣẹ gẹgẹ bi iṣẹ-ọwọ ti olukuluku mọ. Awọn ijọba paapaa fẹ ki a tubọ tẹra mọ iṣẹ aṣọ hihun, egbogi pipò, iṣẹ awọn ohunelo iná manamana (electricity) ati awọn ẹrọ kékèké rirọ. Awọn ara Amẹrika oniṣowo aṣọ ati ohun ti a fi rọbà ṣe ti bẹrẹ si dá ile-iṣẹ silẹ lati ṣe nnkan wọnyi ni Isaẹli. Ile iṣẹ ti a ti n ṣe digi nibẹ kò ni pẹ ti yoo fi di ọkan ninu awọn ti o tobi ju ni ila-oorun agbegbe Mẹditerranean.

Owo ti a n ná lori iṣẹ àgbẹ lọwọlọwọ bayi jẹ ẹẹdẹgbẹta le ni ẹgbẹẹdogun ọkẹ ($35,000,000) dọla, ki a le ri ounjẹ fi bọ awọn Ọmọ Israẹli ti wọn n pọ si i wọnyi, o kere tan mẹẹdogun ninu ọgọrun eniyan ni o ni lati maa ṣe iṣẹ àgbẹ ṣugbọn eniyan mẹwa ninu ọgọrun ni o n ṣe àgbẹ lọwọlọwọ bayii. Ọsàn, ti i ṣe ohun pataki ti awọn Ọmọ Israẹli n tà fun awọn orilẹ-ède miran ni eniyan marun ninu ọgọrun awọn olugbe Israẹli n gbin. Ẹgbẹẹgbẹrun rẹ ti a ti kó sinu apoti ni a n fi ranṣẹ si ilu okeere ni ọdọọdún, wọn si n mu ipo kinni nibikibi ti wọn ba ta ọja wọn si ni gbogbo agbaye. Wọn ti n dá ẹgbẹ Agbẹ silẹ ni agbegbe Galili. Ounjẹ ti bẹrẹ si pọ gan an ni ibi ti awọn Larubawa ti kò lo irin iṣẹ oko riro ti ode oni ti n gbe tẹlẹ ri. Awọn ipẹẹrẹ Israẹli ti wọn jade ni ile-ẹkọ ijọba ti bẹrẹ si lo irin iṣẹ oko riro ati eto titun ti ode oni, wọn si n mu ilọpo meji ọkà ati ọsan gbàndù gbàndù ni ilọpo marun jade ju eyi ti awọn Larubawa ti n gbin lori ilẹ kan naa. Awọn ohun ọgbin miran ni agbado, ọkà bali, ẹfọ, ọdunkun, afara oyin ati ororo. “Ilẹ ahoro li a o si ro, ti o ti di ahoro li oju gbogbo awọn ti o ti kọja. Nwọn o si wipe, Ilẹ yi ti o ti di ahoro ti dabi ọgbà Edẹni; ati ilu ti o tú, ti o di ahoro, ti o si parun, di ilu olodi, o si ni olugbe” (Esekiẹli 36:34,35). Ọpọlọpọ igi ni wọn n gbin ni imuṣẹ asọtẹlẹ (Esekiẹli 36:8, 9; Isaiah 60:13), ọkẹ aimọye igi ni wọn si tun gbin ni iranti awọn olugbeja Israẹli ati ọdunrun ọkẹ (6,000,000) Ju ti awọn ikà ara Jamani pa ni ipakupa.

Iye owo awọn ohun alumọni ti o wà ninu Okú Okun kò ṣe e fẹnu sọ. Bi awọn eniyan ti n wa alumọni wọnyi jade ni Ẹlẹda ti n fi omiran dipo. A sọ fun ni pe gbogbo owo ti a ti n dà lati igba Julius Ceasar kò to lati fi ra awọn alumọni wọnyi ti a ba ni ki a rà wọn ni apapọ ni abẹ omi nibẹ. Fun ẹgbẹẹgbẹrun ọdun sẹhin ni awọn alumọni wọnyi ti wà ninu Okú Okun. Ẹnikẹni kò mọ pe o wà nibẹ titi a fi dá ilẹ naa pada sọdọ olowo rẹ -- ani awọn Ju. A sọ fun ni pe: “Bi a ba tilẹ fi Palẹsitini ta orilẹ-ède miran lọrẹ, kò jámọ nkankan fun wọn, ṣugbọn nisinsinyi a mọ pe o to ohun ti eniyan le ja ajakú fun nitori awọn ohun alumọni rẹ kò ṣe e fẹnu sọ, paapaa ju lọ eyi ti o wà ninu Okú Okun”.

Asia ati Edè

Awọn àwọ asia Israẹli jẹ bulu ati funfun, awọn àwọ yii ni o wà lara aṣọ ti Olori Alufa maa n wọ nigba ti o ba fẹ wọ Ibi Mimọ Julọ ni Ọjọ Etutu nigbà ti a kò tii wo Tẹmpili lulẹ. Ni aarin rẹ ni irawọ Dafidi wà ti o ni igun mẹfa. Irawọ yii ni igun mẹta-mẹta meji ti o wọ inu ara wọn, awọ bulu ni eyi ni pẹlu. A sọ fun ni pe “Igun mẹta keji gẹgẹ bi itàn awọn Ju duro fun Mẹtalọkan Ọlọrun eyi ti Messia yoo tumọ fun wọn nigba ti O ba de.”

Edè ti Israẹli n sọ ti awọn ijọba wọn si n lo ni èdè Heberu, ede ti awọn eniyan gbà pe a ki i sọ mọ. Gbogbo wọn ni n kọ ede yii ni kété ti wọn ba ti gunlẹ sibẹ. Iwe irohin mẹtadinlogun ti n jade lojoojumọ ni o wà ni Palẹstini nisinsinyi, a si n tẹ mẹjọ ninu rẹ jade ni ede Heberu.

A kò gbọdọ gbagbe pe ohun ti a n ri nisinsinyi jẹ apẹẹrẹ ohun ti o n bọ wa ṣẹ. Igi ọpọtọ ti n rudi o si ti bẹrẹ si ruwe. “Bayi li Oluwa ỌLỌRUN wi fun egungun wọnyi; Kiyesi i, emi o mu ki ẽmi wọ inu nyin, ẹnyin o si yè: Emi o si fi iṣan sara nyin, emi o si mu ẹran wá sara nyin, emi o si fi àwọ bo nyin, emi o si fi ẽmi sinu nyin, ẹnyin o si ye; ẹnyin o si mọ pe emi li OLUWA” (Esekiẹli 37:5, 6). A kò gbọdọ gboju fo otitọ yii pe fifi idi Israẹli kalẹ lori ilẹ wọn, ati awọn ibukún ti o tun tẹle e nipa ti ara ati nipa ti ẹmi rọ mọ wi pe ki Israẹli gba Jehofa ni Oluwa wọn. “Ẹnyin o si mọ pe emi li OLUWA, nigbati emi ba ti ṣi iboji nyin, ẹnyin enia mi, ti emi bá si mu nyin dide kuro ninu iboji nyin. Emi o si fi ẹmi mi sinu nyin, ẹnyin o si yè, emi o si mu nyin joko ni ilẹ ti nyin: nigbana li ẹnyin o mọ pe, emi OLUWA li o ti sọ ọ, ti o si ti ṣe e, li OLUWA wi” (Esekiẹli 37:13, 14). Nigba naa ni igbala tabi ìbí nipa ti ẹmi ti orilẹ-ède kan yoo ṣẹlẹ ni ọjọ kan. “Tali o ti igbọ iru eyi ri? Tali o ti iri iru eyi ri? Ilẹ le hù nnkan jade li ọjọ kan bi? tabi a ha le bi orilẹ-ède li ẹrinkan? nitori bi Sioni ti nrọbi gẹ, bẹẹli o bi awọn ọmọ rẹ” (Isaiah 66:8).

“Emi o si tú ẹmi ore-Ofẹ ati ẹbẹ sori ile Dafidi ati sori Jerusalẹmu: nwọn o si ma wò mi ẹniti nwọn ti gún li ọkọ, nwọn o si ma ṣọfọ rẹ; gẹgẹ bi enia ti nṣọfọ fun ọmọ ọkọnrin rẹ kanṣoṣo, nwọn o si wà ni ibanujẹ, bi ẹniti mbanujẹ fun akọbi rẹ … Ilẹ na yio ṣọfọ, idile idile lọtọtọ” (Sekariah 12:10-12). Eyi fi hàn fun ni pe ọfọ ati ibanujẹ ti yoo pọ to bẹẹ gẹẹ ti wọn o pin ara wọn ni idile lati ṣọfọ naa ni yoo ṣiwaju ọjọ idande Israẹli. Nwọn yoo mọ ara wọn ni ẹlẹṣẹ nigba ti wọn yoo ri Messia wọn ni ojukoju, Jesu Kristi Oluwa, Ẹniti a gun lọkọ. Kò si apẹẹrẹ iru ọfọ ati ibanujẹ bayi ni Palẹstini nisinsinyi.

O daju pe orilẹ-ède Israẹli kò ti i mọ Ọlọrun. Wọn n fi ẹnu jẹwọ Rẹ ni gbangba, ṣugbọn ohun ti o hàn kedere ni pe orilẹ-ède ti o gbe nnkan ti ara pọn ni awọn Ju gbe kalẹ ni Palẹstini. Eyi dùn mọ ẹgbẹ oṣelu ti a n pe ni Ẹgbẹ Sioni ti i ṣe igi lẹhin ọgbà fun Israẹli nitori pe pẹki ni irú ilepa bayi ṣe pẹlu igbekalẹ wọn. Ẹgbẹ yii kò fi igbà kan jẹwọ ri pe wọn ni i fi Ọlọrun tabi Ọrọ rẹ ṣe. Ninu aṣoju mọkanlelọgọfa (121) ti o wà ni Ile Aṣofin Israẹli, aṣoju mẹtadinlogun pere ni awọn Ẹgbẹ Apapọ Ẹlẹsin ni ninu ibò ti wọn kọkọ di lati yàn Aṣoju. Orin orilẹ-ède Ju kò mẹnu kan Ọlọrun rara. Awọn baba ẹgbẹ Ẹgbẹ Sioni kò darukọ Ọlọrun rara tabi ilana Rẹ fun Israẹli ninu irohin wọn nipa ohun ti wọn ṣe. bi o tilẹ jẹ pe awọn Ju n pada si ilẹ wọn ninu aigbagbọ, lai si aniani ọwọ Agbara ti o tayọ imọ wọn ni o n kó wọn jọ.

O daju pe Oluwa ni O n kó Israẹli jọ. Ki i ṣe ọwọ Agbajọ Igbimọ Agbaye ni yoo gbá wọn jọ, bẹẹ ni ki i ṣe awọn Ẹgbẹ Sioni ni yoo ṣe e, tabi ọwọ agbara ti o wu ki o jẹ ninu aye yii; bi kò ṣe Oluwa, Ẹniti o tú wọn ká ni yoo tun kó Israẹli jọ. Oun yoo ṣa wọn jọ lati orilẹ-ède gbogbo, yoo si fi idi wọn kalẹ si ilẹ ti wọn.

Ọpọlọpọ iṣẹlẹ ni o ti ṣẹlẹ ni nnkan bi ọdun mẹwa tabi ogun ọdun yii sẹhin ni imuṣẹ asọtẹlẹ nipa awọn Ju, ju bi a ti ri ni nnkan bi ẹẹdẹgbẹta (500) ọdun sẹhin. Igi ọpọtọ n ruwe nisinsinyi – a si mọ pe ẹẹrùn sun mọ tosi! Ohun ti o yẹ wa ni lati woke ki a si gbe ori wa soke nitori “idande” wa “kù si dẹdẹ” (Luku 21:28).