Lesson 164 - Senior
Memory Verse
“Bi mo ba lọ ipèse àye silẹ fun nyin, emi o tún pada wá, emi o si mu nyin lọ sọdọ emi tikarami; pe nibiti emi gbé wà, ki ẹnyin le wà nibẹ pẹlu” (Johannu 14:3).Notes
“Ṣugbọn niti ọjọ ati wakati na, kò si ẹnikan ti o mọ ọ, awọn angẹli ọrun kò tilẹ mọ ọ, bikoṣe Baba mi nikanṣoṣo.
“Gẹgẹ bi ọjọ Noa si ti ri, bẹẹni wiwa Ọmọ-enia yio si ri.
“Nitori bi ọjọ wọnni ti wà ṣiwaju kikún omi, ti nwọn njẹ, ti nwọn nmu, ti nwọn ngbé iyawo, ti a si nfa iyawo funni, titi o fi di ọjọ ti Noa fi bọ sinu ọkọ,
“Nwọn kò si mọ titi omi fi de, ti o gbá gbogbo wọn lọ; gẹgẹ bẹẹni wiwa Ọmọ-enia yio ri pẹlu” (Matteu 24:36-39).
Awọn Iṣẹlẹ Nla Meji
Ọrọ wọnyi, “ipadabọ Kristi nigba keji” n tọka si iṣẹlẹ nla meji. Ekinni ni Ipalarada Ijọ Ọlọrun ni akoko ti yoo jẹ wi pe awọn ti o ti mura silẹ nikan ni yoo ri Kristi, ti a o si gbà wọn soke lati pade Rẹ ni awọsanma. Iṣẹlẹ nla keji ni Ifarahàn Kristi, nigba ti Oun yoo pada pẹlu awọn eniyan mimọ Rẹ lati fi idi Ijọba Rẹ kalẹ ni aye -- Ijọba ẹgbẹrun ọdun. Laarin Ipalarada Ijọ Ọlọrun ati Ifarahàn Jesu Kristi ni Ase Alẹ Igbeyawo Ọdọ-agutan yoo wà ni ofuurufu, ti Ipọnju nla tabi akoko ipọnju Jakọbu yoo wà ni aye.
Ipalarada Ijọ Ọlọrun ni gbigba Iyawo Kristi soke -- awọn ti o ti mura silẹ -- kuro ni aye yi lọ si ibi ti Jesu ti pese silẹ fun wọn ni ofuurufu, lati wà pẹlu Rẹ nibi Ase Alẹ Igbeyawo Ọdọ-agutan. Jesu wi pe “Emi nlọ ipèse àye silẹ fun nyin. Bi mo ba si lọ ipèse àye silẹ fun nyin, emi o tún pada wá, emi o si mu nyin lọ sọdọ emi tikarami; pe nibiti emi gbé wà, ki ẹnyin le wà nibẹ pẹlu” (Johannu 14:2, 3). Ọrọ ti Jesu sọ gan an ni eyi pe: “Emi o tún pada wá.”
Awọn Apẹẹrẹ lati Inu Majẹmu Laelae
Ni oriṣiriṣi ọna ni Iwe Mimọ gbà sọ nipa Ipalarada. Apẹẹrẹ rẹ wà ninu Majẹmu Laelae. A fi ye ni, nipa awọn apẹẹrẹ ati ojiji, ninu Iwe Mimọ pe ki i ṣe ifẹ Ọlọrun ki Ijọ Rẹ ni ipin ninu idajọ gbigbona ti yoo wá sori ayé nigbà ti Ọlọrun ba bẹrẹ si rọjo ibinu Rẹ sori awọn orilẹ-ède ti o gbagbe Rẹ. Apẹẹrẹ yii fara hàn ninu igbesi aye Noa ati Ikun Omi. “Noa ṣe olõtọ ati ẹniti o pé li ọjọ aiye rẹ, Noa mba Ọlọrun rin.” Noa ti “ri ojurere loju OLUWA” (Gẹnẹsisi 6:8, 9). Oun jẹ apẹẹrẹ ti o dara, ti Ijọ Aṣẹgun ti a o gbà soke kuro ninu aye ni akoko Ipalarada. Nigbà ti Ọlọrun pinnu lati fi idajọ bẹ aye wò, O paṣẹ fun Noa lati kan Ọkọ. Noa kàn Ọkọ lati gbe e leke iṣan omi idajọ Ọlọrun ti n bọ wa aye lọ. Gbogbo awọn olododo yè ninu Ọkọ naa. “Gẹgẹ bi ọjọ Noa si ti ri, bẹẹni wiwá Ọmọ-enia yio si ri” (Matteu 24:37). Gẹgẹ bi a ti daabo bo Noa kuro ninu Ikun Omi, bakan naa ni Ọlọrun da awọn olododo, ani awọn aṣẹgun si nigba ti O ba rọjò idajọ Rẹ sori aye yii nikẹyin ọjọ. Jesu yoo pe wọn lati pade Rẹ ni awọsanma.
Nigbà miiran ẹwẹ, a ri apẹẹrẹ Ipalarada Ijọ Ọlọrun ninu iparun Sodomu ati Gomorra. Nigbà ti Abrahamu gbadura fun aburo rẹ ti o wà ni Sodomu, o beere lọwọ Oluwa pe “Iwọ o ha run olododo pẹlu enia buburu?” (Gẹnẹsisi 18:23). Ni idahun si adura Abrahamu, Ọlọrun dá Lọti si, O si yọ ọ kuro ninu iparun. Eyi jẹ apẹẹrẹ aabo Ọlọrun lori awọn eniyan Rẹ nigbà ti idajọ ba wá sori aye. “Gẹgẹ bi o si ti ri li ọjọ Loti; nwọn njẹ, nwọn mu, nwọn nrà , nwọn ntà, nwọn ngbin, nwọn nkọle; Ṣugbọnn li ọjọ na ti Loti jade kuro ni Sodomu, ojo ina ati sulfuru rọ lati ọrun wá, o si run gbogbo wọn. Gẹgẹ bẹẹni yio ri li ọjọ na ti Ọmọ enia yio farahàn” (Luku 17:28-30).
A tun ri apẹẹrẹ Ipalarada ninu idande Israẹli ni akoko ti idajọ gbigbona Ọlọrun wa sori Egipti. Apanirun kò le fọwọ kan ohunkohun ni Goṣeni nibi ti awọn eniyan Ọlọrun wà. Awọn apẹẹrẹ wọnyi, ati awọn ibomiran gbogbo ninu Iwe Mimọ ti o mẹnu kan ọran yi, fi hàn kedere pe Ọlọrun yoo mu awọn eniyan Rẹ kuro ni aye ki gọngọ idajọ to sọ lori aye.
Ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun ti O Ṣeleri Aabo
“Wá, enia mi, wọ inu iyẹwu rẹ lọ, si se ilẹkun rẹ mọ ara rẹ: fi ara rẹ pamọ bi ẹnipe ni iṣẹju kan, titi ibinu na fi rekọja.
“Nitorina, kiye si i, OLUWA ti ipò rẹ jade lati bẹ aiṣedede ẹniti ngbe ori ilẹ wo lori ilẹ; ilẹ pẹlu yio fi ẹjẹ rẹ hàn, ki yio si bò okú rẹ mọ” (Isaiah 26:20, 21).
Ninu awọn ẹsẹ meji yi, a ri i bi Ọlọrun ti n pe awọn eniyan Rẹ jade kuro ninu aye ki a to tú idajọ Rẹ dà sori aye ni akoko Ipọnju Nla. Sefaniah gbà ni niyanju wi pe “Ẹ wá OLUWA, gbogbo ẹnyin ọlọkàn tùtù aiye, ti nṣe idajọ rẹ; ẹ wá ododo, ẹ wá iwa-ipẹlẹ boya a o pa nyin mọ li ọjọ ibinu OLUWA” (Sefaniah 2:3).
Awọn Ami Wiwa Rẹ
Awọn ọmọ-ẹhin beere pe, “kini yio si ṣe àmi wiwa rẹ, ati ti opin aiye?” Apa kan idahun ti Jesu fun wọn ni eyi: “Orilẹ-ède yio dide si orilẹ-ède, ati ilẹ-ọba: iyan, ati ajakalẹ-arùn, ati isẹlẹ yio si wà ni ibi pipọ … Woli eke pipọ ni yio si dide, nwọn o si tàn ọpọlọpọ jẹ. Ati nitori ẹṣẹ yio di pipọ, ifẹ ọpọlọpọ yio di tutù … A o si wasu ihinrere ijọba yi ni gbogbo aiye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ède; nigbana li opin yio si de” (Matteu 24:3-14).
Laarin ọgọrun ọdun ti a wa yi, ogun ajakaye meji ni a ti jà, iyàn ati jajakalẹ àrun si tẹle e, sibẹ kò si iyanjú ninu iṣoro aye yi ju pe ki a maa gbara di fun ogun ajakaye kẹta. Awọn eniyan ti wọn ti ku nipa isẹlẹ laarin ọgọrun ọdun ti a n lo lọ yi pọ ni ilọpo mẹrin ju awọn ti wọn ku iru iku bẹẹ laarin ọgọrun lọna mọkandinlogun ọdun (19 Centuries) ti o ti kọja lọ. Bẹẹ ni isẹlẹ ti o sẹ ni ọgọrun ọdún ṣaaju rẹ tayọ gbogbo isẹlẹ ti o ti n sẹ ni ọgọrun ọdun mejidinlogun (18 Centuries) sẹhin, lati igbà ti Kristi ti wà laye. Ẹsin titun ati woli èké n gbilẹ si i, ṣugbọn isin ni ẹmi ati ni otitọ n rẹhin si i. A ti tumọ Bibeli tabi apa kan ninu rẹ si ede oriṣiriṣi ti o to aadọrunlelẹgbẹrun (1,090) ède, a si ti waasu Ihinrere kaakiri gbogbo agbaye. Opin kù si dẹdẹ!
Ìgbà Ewu
Paulu pe igbà ikẹhin ni igbà ewu. “Nitori awọn enia yio jẹ olufẹ ti ara wọn, olufẹ owo, afunnù, agberaga, asọrọbuburu, aṣaigbọran si obi, alai lọpẹ, alaimọ, alainifẹ, alaile-dariji-ni, abanijẹ, alaile-kó-ra-wọn nijanu, onroro, alai-nifẹ-ohun-rere, onikupani, alagidi, ọlọkàn giga, olufẹ faji jù olufẹ Ọlọrun lọ; awọn ti nwọn ni afarawe iwa-bi-Ọlọrun, ṣugbọn ti wọn sẹ agbara rẹ: yẹra kuro lọdọ awọn wọnyi pẹlu” (2 Timoteu 3:2-5). Eyi jẹ apejuwe ti o yanjú kedere nipa awọn eniyan ti ode-oni to bẹẹ ti o ṣe pe alaye ti a le ṣe kò pọ rara. Ninu awọn iwe irohin, a n kà nipa awọn onikupani alaile-dariji-ni, abanijẹ. Ni awọn opopo ọna, a n ri awọn akọle ipolowo ọja bayi pe, “Jẹun ki o si jó”, “Jẹ ki o si mu.” Bi a ba fi awọn ile-iworan ati ibi afẹ ti o n kun fọfọ we awọn Ṣọọṣi ti o n ṣofo, yoo han si wa pe awọn eniyan jẹ olufẹ faaji ju olufẹ Ọlọrun lọ. kọsílẹ awọn ọlọpa, àkọsílẹ ipẹjọ ìkọsílẹ laarin tọkọ-taya, ati awọn nnkan ti awa paapaa n fi oju ara wa ri lojoojumọ fi hàn pe aigbọran si obi, alainifẹ-ohun-rere, ati ojukokoro kún inu aye. Igba ikẹhin ni eyi! Ipada bọ Oluwa kù si dẹdẹ!
Wọn kò Gba Ikilọ
“Nigbati nwọn ba nwipe, alafia ati ailewu; nigbana ni iparun ojiji yio de sori wọn gẹgẹ bi irọbi lori obirin ti o lóyun; nwọn ki yio si le sálà.
“Ṣugbọn ẹnyin, ará, kò si ninu òkunkun, ti ọjọ na yio fi de bá nyin bi olè.
“Nitori gbogbo nyin ni ọmọ imọlẹ, ati ọmọ ọsán: awa ki iṣe ti oru, tabi ti òkunkun.
“Nitorina ẹ máṣe jẹ ki a sùn, bi awọn iyoku ti nṣe; ṣugbọn ẹ jẹ ki a mā ṣọna ki a si mā wà li airekọja.
“Nitori awọn ti nsùn, a mā sùn li oru; ati awọn ti nmọtipara, a mā mọtipara li oru.
“Ṣugbọn ẹ jẹ ki awa, bi a ti jẹ ti ọsan, mā wà li airekọja, ki a mā gbé igbaiya igbagbọ ati ifẹ wọ; ati ireti igbala fun aṣibori” (I Tẹssalonika 5:3-8).
Pẹlu gbogbo ikilọ ti Bibeli fun ni ati awọn asọtẹlẹ ti a n ri ti o n ṣẹ loju wa lojoojumọ, aye kò ni kọ ọna ẹṣẹ rẹ silẹ titi Jesu yoo fi pada de lojiji ti yoo si gbà awọn eniyan Rẹ kuro li aye. “Nitori gẹgẹ bi manamana ti ikọ lati ila-õrun, ti isi mọlẹ de iwọ-õrun; bẹẹni wiwa Ọmọ-enia yio ri pẹlu” (Matteu 24:27). Yoo de ba aye bi Ikun Omi ti ọjọ Noa. Noa fi ọgọfa (120) ọdun kan Ọkọ o si n pese ọna ti yoo gbà yọ fun ara rẹ ati ẹbi rẹ, bakan naa ni o si n waasu Ihinrere ti o si n kilọ fun awọn eniyan nipa iparun ti n bọ wá. Anfaani wà fun awọn eniyan naa lati mura silẹ, ṣugbọn wọn kò feti si kilọ yii, wọn si fi agidi ọkan tẹ siwaju ninu ẹṣẹ wọn. “Ti nwọn njẹ, ti nwọn nmu, ti nwọn ngbé iyawo, ti a si nfa iyawo funni, titi o fi di ọjọ ti Noa fi bọ sinu ọkọ, nwọn kò si mọ titi omi fi de, ti o gbá gbogbo wọn lọ; gẹgẹ bẹẹni wiwa Ọmọ-enia yio ri pẹlu” (Matteu 24:38, 39). Awọn eniyan aye ti gbọ ikilọ ti o pọ to nipa ipadabọ Oluwa, ṣugbọn eniyan diẹ ni o mura silẹ lati pade Jesu nigbà ti yoo tun pada wá. Wiwa Rẹ yoo ba aye ni airò tẹlẹ; yoo de ba wọn lojiji.
Iparun Ojiji
“Nigbati nwọn ba nwipe, alafia ati ailewu; nigbana ni iparun ojiji yio de sori wọn” (I Tẹssalonika 5:3). Iparun ojiji yi ni Ipọnju nla ti yoo de ba aye nigbà ti a ba ti gba Iyawo Kristi soke kuro ninu aye yii. Awọn eniyan mimọ ti n ṣọna -- awọn aṣẹgun ni kikún – ni Iyawo Kristi. Awọn ni wọn n ṣọna fun bibọ Rẹ. “Yio farahan nigbakeji laisi ẹṣẹ fun awọn ti nwọna rẹ fun igbala” (Heberu 9:28). Iyawo Ọdọ-agutan ni kan ni yoo ri I. Awọn alaigbagbọ yoo mọ nipa wiwa Rẹ nigbà ti wọn ba fẹ awọn ti a ti mu lọ kù. “Nigbana li ẹni meji yio wà li oko; a o mu ọkan, a o si fi ekeji silẹ. Awọn obirin meji yio jùmọ ma lọ ọlọ pọ; a mu ọkan, a o si fi ekeji silẹ” (Matteu 24:40, 41). Ayè kò ni si nigbà naa mọ lati sare gbadura tabi lati ṣe imurasilẹ kankan. Boya “Ẹni keji” yoo maa sùn titi ilẹ yoo fi mọ, lati mọ pe ẹni ti o wà ni ẹgbẹ oun ti lọ.
Ni Airo-tẹlẹ
“Nitorina ẹ mā ṣọna: nitori ẹnyin kò mọ wakati ti Oluwa nyin yio de.
“Ṣugbọn ki ẹnyin ki o mọ eyi pe, bāle ile iba mọ wakati na ti olè yio wá, iba mā ṣọna, on ki ba ti jẹ ki a runlẹ ile rẹ.
“Nitorina ki ẹnyin ki o mura silẹ: nitori ni wakati ti ẹnyin kò rò tẹlẹ li Ọmọ-enia yio de.
“Tani iṣe olõtọ ati ọlọgbọn ọmọ-ọdọ, ẹniti oluwa rẹ fi ṣe olori ile rẹ, lati fi onjẹ wọn fun wọn li akokò?
“Alabukún-fun li ọmọ-ọdọ na, nigbati oluwa rẹ ba de, ẹniti yio ba a ki o mā ṣe bẹ.
“Lõtọ ni mo wi fun nyin pe, On o fi ṣe olori gbogbo ohun ti o ni.
“Ṣugbọn bi ọmọ-ọdọ buburu na ba wi li ọkàn rẹ pe, ‘Oluwa mi fa àbo rẹ sẹhin;
“Ti o si bẹrẹ si ilù awọn ọmọ-ọdọ ẹlẹgbẹ rẹ, ati si ijẹ ati si imu pẹlu awọn ọmuti;
“Oluwa ọmọ-ọdọ na yio de li ọjọ ti kò reti, ati ni wakati ti kò daba.
“Yio si jẹ ẹ ni iya gidigidi, yio yàn ipa rẹ pẹlu awọn agabagebe, nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà” (Matteu 24:42-51).
O hàn gbangba ninu Iwe-Mimọ pe kò si ẹni ti o mọ ọjọ tabi wakati ti Jesu yoo de. “Ṣugbọn niti ọjọ ati wakati na, kò si ẹnikan ti o mọ ọ, kò si, ki tilẹ iṣe awọn angẹli ọrun, tabi Ọmọ, bikoṣe Baba mi nikanṣoṣo” (Mark 13:32). Lẹhin igbà ti a ti sọ fun ni gbangba wi pe kò si ẹnikan – ki tilẹ ṣe Ọmọ Ọlọrun – ti o mọ ọjọ naa, tabi wakati naa, o ya ni lẹnu bi ẹni kan ti ṣe le sọ pe ọjọ kan bayi ni Jesu yoo de tabi ti aye yoo dopin. Ṣugbọn awọn kan ti sọ pe ọjọ bayii ni, lodi si ikilọ Iwe Mimọ ati otitọ Ọrọ Ọlọrun ti o yanjú kedere. Wọn ti mu ki awọn ọmọ ẹgbẹ wọn ta ohun-ini wọn, ki wọn si gbe aṣọ funfun wọ ni akoko ti wọn dá fun wọn, ki wọn si lọ si ori òke kan lati maa ṣọna fun bibọ Jesu. Ki i ṣe lọna bayii ni a sọ fun ni lati maa ṣọna fun bibọ Rẹ. Jesu sọ fun awọn iranṣẹ Ọlọrun lati maa ṣiṣẹ titi Oun yoo fi pada de. A sọ fun ni pe obinrin meji yoo maa lọ ọlọ pọ; a o mu ọkan a o si fi ekeji silẹ. Bi a tilẹ wá ni oko tabi ni idi ẹrọ, tabi a n sun ni oru, ọkàn wa le maa ṣọna ki a si mura silẹ de igbà ti ipe yoo dun wi pe, “Wo o, ọkọ iyawo mbọ.”
Imurasilẹ
Jesu wi pe, “Kiyesi i, mo mbọ bi ole” (Ifihan 16:15). “Nitorina ki ẹnyin ki o mura silẹ: nitori ni wakati ti ẹnyin kò rò tẹlẹ li Ọmọ-enia yio de” (Matteu 24:44). Owe awọn wundia mẹwa, ninu Matteu 25:1-13, jẹ ikilọ fun ni nipa ewu jijafara lati mura silẹ fun bibọ Oluwa. Bi a ba mọ ohun ti a ni lati ṣe lati jẹ wundia ọlọgbọn ti a kò si ṣe imura ti o tọ, ẹbi rẹ yoo jẹ ti wa, a o si fara mọ ohunkohun ti o ba de. Bi a ba n rin ninu gbogbo imọlẹ ti o tan sọna wa, ti o si ṣe pe a ṣẹṣẹ mọ nipa idalare ni, Oluwa yoo mu wa la a ja. Bi a ba ti sọ wa di mimọ patapata, ti otitọ yii si n gbe inu ọkàn wa, ti a kò si ni imọ ju bayii lọ nipa Ọrọ Ọlọrun, Oluwa yoo mu wa la a ja. Ṣugbọn bi a ba ti dá wa lare, ti a si sọ wa di mimọ, ti imọlẹ ifiwọni Ẹmi Mimọ si ti tan si ọna wa, ti a si kuna lati gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ, yoo ri fun wa bi o ti ri fun awọn wundia alaigbọn. Lẹhin ti a ba tilẹ ti gbà ifiwọni Ẹmi Mimọ, o ṣe pataki fun ni lati maa rin ninu imọlẹ ki a ba le pa wa lara dà. “Awa o ti ṣe là a, bi awa kò ba nāni irú igbala nla bi eyi?” (Heberu 2:3).
Ninu owe yii, jijẹ wundia jẹ apẹẹrẹ ọkàn mimọ tabi isọdimimọ. Ororo duro fun Ẹmi Ọlọrun. Ẹmi Ọlọrun ni odiwọn diẹ a maa wọ inu ẹni nigba ti a ba ni idalare ati isọdimimọ; ṣugbọn nini ororo ninu fitila wọn – ati omiran ninu kolobo ororo – fi hàn pe awọn wundia ọlọgbọn ni ifi-wọni Ẹmi Mimọ. Awọn wundia alailọgbọn kò mu ororo lọwọ pẹlu wọn, eyi fi hàn pe wọn kò bikita lati ni ifi-wọni Ẹmi Mimọ. Awọn ọlọgbọn ba Ọkọ Iyawo wọle lọ si ibi igbeyawo; awọn alailọgbọn kùna. Iwọ ha jẹ ọkan ninu awọn wundia ọlọgbọn, ati pe nipa ifarada ati ipinnu, o ti mura silẹ, ohunkohun ti o wu ki o gbà ọ? “Ẹ jẹ ki a yọ, ki inu wa ki o si dùn gidigidi, ki a si fi ogo fun u: nitoripe igbeyawo Ọdọ-Agutan de, aya rẹ si ti mura tan. On ni a si fifun pe ki o wọ aṣọ ọgbọ wiwẹ ti o funfun gbõ: nitoripe aṣọ ọgbọ wiwẹ nì ni iṣe ododo awọn enia mimọ” (Ifihan 19:7, 8).
Ainaani
Awọn ti ki i ṣe aṣẹgun patapata, ti kò rin ninu gbogbo imọlẹ, yoo kù sẹhin ninu ayé lati jiya akoko Ipọnju kikoro ati ijọba Aṣodi-si- Kristi. Lati wà ni oloootọ nigbà naa, yoo gba wi pe ki a pa ẹni naa nitori Ihinrere. Ẹni ti o ba jọgọ silẹ yoo gbà ami ẹranko naa yoo si ṣegbe laelae. “Gbogbo awọn ti ngbe ori ilẹ aiye yio si mā sin i … o si mu ki a pa gbogbo awọn ti kò foribalẹ fun aworan ẹranko na” (Ifihan 13:8, 15). Bi ẹni kan kò ba le duro nisinsinyi, lakoko ti a nwaasu Ihinrere ti awọn Ọmọ Ọlọrun si n ṣe iranwọ, bawo ni ẹni naa ṣe le rò pe oun yoo le duro lẹhin ti a ba ti mu Iyawọ Kristi kuro laye? “Bi iwọ ba ba ẹlẹsẹ rin, ti ārẹ si mu ọ, iwọ o ha ti ṣe ba ẹlẹṣin dije? Ati pẹlu ni ilẹ alafia, bi iwọ ba ni igbẹkẹle, ti ārẹ si mu ọ, kini iwọ o ṣe ninu ẹkún odo Jọrdani?” (Jeremiah 12:5).
Ajinde
“Ṣugbọn awa kò fẹ ki ẹnyin ki o jẹ òpe, ará, niti awọn ti o sùn, pe ki ẹ má binujẹ gẹgẹ bi awọn iyoku, ti kò ni ireti.
“Nitori bi awa ba gbagbọ pe Jesu ti kù, o si ti jinde, gẹgẹ bẹẹni Ọlọrun yio mu awọn ti o sùn pẹlu ninu Jesu wá pẹlu ara rẹ.
“Nitori eyiyi li awa nwi fun nyin nipa ọrọ Oluwa, pe awa ti o wà lāye, ti a si kù lẹhin de atiwá Oluwa, bi o ti wu ki o ri ki yio ṣaju awọn ti o sùn.
“Nitori Oluwa tikararẹ yio sọkalẹ lati ọrun wá ti on ti ariwo, pẹlu ohùn olori awọn angẹli, ati pẹlu ipè Ọlọrun; awọn okú ninu Kristi ni yio si kọ jinde;
“Nigbana li a o si gbà awa ti o wà lāye ti o si kù lẹhin soke pẹlu wọn sinu awọsanma, lati pade Oluwa li oju ọrun: bẹẹli awa ó si mā wà titi lai lọdọ Oluwa.
“Nitorina, ẹ mā fi ọrọ wọnyi tu ara nyin ninu” (I Tẹssalonika 4:13-18).
Awọn aṣẹgun patapata ti o wà laaye ngbà ti Jesu ba pada de ati awọn aṣẹgun ti o ti kú ninu Kristi ni a o pa lara dà. Awọn ti o wà ni iboji ni yoo kọ gbọ ohùn Oluwa, awọn ni yoo si kọ ji dide, ṣugbọn awa ti o ku lẹhin yoo pade Oluwa ati awọn naa ni awọsanma. Awọn okú yoo ji dide pẹlu ara ologo, awa ti a pa lara dà yoo bọ ara kikú yii silẹ, lọgan, a o si gbe ara aikú tabi ara ologo wọ. “Kiyesi i, ohun ijinlẹ ni mo sọ fun nyin; gbogbo wa ki yio sùn, ṣugbọn gbogbo wa li a o palarada, Lọgan, ni iṣẹju, nigbà ipè ikẹhin: nitori ipè yio dún, a o si ji awọn okú dide li aidibajẹ, a ó si pa wa lara dà. Nitoripe ara idibajẹ yi kò le ṣaigbé aidibajẹ wọ, ati ara kikú yi kò le ṣaigbé ara aiku wọ” (I Kọrinti 15:51-53). Ki i ṣe gbogbo okú ni yoo jinde ni akoko yii, bi ko ṣe kiki awọn aṣẹgun patapata ti o kú ninu Kristi. Okú awọn eniyan buburu ki yio jinde titi di opin Ijọba ẹgbẹrun ọdún. “Awọn okú iyokù kò wa lāye mọ titi ọdún na yio fi pé” (Ifihan 20:5).
Gbogbo Onigbagbọ ni o ni lati lakakà gidigidi bi ti Paulu, “bi o le ṣe”, ki oun le ni ipin ninu Ajinde Kinni ki oun si le bọ kuro ninu idajọ gbigbona Ọlọrun ti o n bọ wa sori aye. “Olubukun ati mimọ ni ẹniti o ni ipa ninu ajinde ekini na: lori awọn wọnyi ikú ekeji kò li agbara, ṣugbọn nwọn o jẹ alufa Ọlọrun ati Kristi, nwọn o si mā jọba pẹlu rẹ li ẹgbẹrun ọdún” (Ifihan 20:6).