Isaiah 11:1-10; 35:1-10; Ifihan 20:7-10

Lesson 168 - Senior

Memory Verse
“Nigbana li awọn arọ yio fò bi agbọnrin, ati ahọn odi yio kọrin: nitori omi yio tú jade li aginju, ati iṣàn omi ni ijù” (Isaiah 35:6).
Notes

A fi ilẹ bú nitori rẹ; ni ipọnju ni iwọ o ma jẹ ninu rẹ li ọjọ aiye rẹ gbogbo;

Ẹgún on oṣuṣu ni yio ma hù jade fun ọ, iwọ o si ma jẹ eweko igbẹ:

Li õgun oju rẹ ni iwọ o ma jẹun, titi iwọ o fi pada si ilẹ; nitori inu rẹ li a ti mu ọ wá. erupẹ sa ni iwọ, iwọ o si pada di erupẹ” (Gẹnẹsisi 3:17-19).

Nigbà ti Ọlọrun fi eniyan sinu Ọgbà Edẹni, gbogbo igi ti Ọlọrun dá ni o dara ni wiwò. Ọlọrun bojuwo gbogbo ohun ti O dá, O si wi pe daradara ni. Alaafia wà niha gbogbo, eniyan n gbe ni ailewu laarin awọn ẹranko igbẹ. Ohun gbogbo ni o dara titi Efa fi jọgọ silẹ fun idanwo Satani ti ẹṣẹ si wọ inu aye. Ẹṣẹ fa ègún sori aye.

Ẹṣẹ fa àrun, aisan ati ikú wá sinu aye. Awọn ẹranko wa di ẹhànnà; ẹgun ati oṣuṣu hù jade, idibajẹ de ba awọn ohun meremere ti Ọlọrun dá. A fi ọta saarin irú obirin naa ati ejo, ṣugbọn Ọlọrun ṣeleri pe irú ọmọ obirin naa yoo fọ ejo ni ori. Ileri yii n tọka si igbà ti Kristi yoo wá, ti yoo si bi Satani ṣubu. Wo iru iyipada ti yoo de ba aye nigbà ti a ba mu ẹṣẹ ati Eṣu kuro, ti ègún ẹṣẹ kò ni si mọ!

Kò ni si Aṣálẹ

Iwọ ha mọ ibi kan nibi ti kò si ohunkohun afi yanrin aṣalẹ, nibi ti ẹyọ eweko kan kò le hù, nibi ti ẹfúùfú rẹ gbona to bẹẹ ti o dabi ẹni pe kò tilẹ si afẹfẹ rere nibikibi rara? Nigbooṣe eyi ki yoo ri bẹẹ mọ. Nigba ti a ba gbe Satani dè, ti a si mu ègún kuro, aṣalẹ yoo yọ. Ọlọrun ti ṣeleri pe:

Emi o ṣi odò nibi giga, ati orisun lārin afonifoji: emi o sọ aginjù di abàta omi, ati ilẹ gbigbẹ di orisun omi” (Isaiah 41:18).

Nitori omi yio tú jade li aginju, ati iṣàn omi ni ijù.

Ilẹ yiyan yio si di àbata, ati ilẹ ongbẹ yio di isun omi” (Isaiah 35:6, 7).

Awọn eniyan ti la ọpọlọpọ iṣàn omi lati maa fi bomi rin ohun ọgbin. Wọn ti ṣe aṣeyọri ni fifi omi lọ si ibi iyangbẹ ilẹ diẹ, wọn si mu ki o mu ohun ọgbin jade, ṣugbọn ọpọlọpọ aṣalẹ ni kò ṣe e ṣe fun ẹda lati fa omi de nipa akitiyan wọn. Ni akoko Ijọba Ẹgbẹrun Ọdún, Ọlọrun yoo ṣi awọn odo omi, orisun, adagun ati iṣàn omi nibi ti iyangbẹ ilẹ gbe wa nisinsinyi. Wo bi iyipada yoo ti pọ to nigbà ti Ọlọrun ba gba akoso aye! Aṣalẹ nla ti Sahara ti o tobi to idameji ninu mẹta ilẹ Amẹrika yoo maa tanna bi òdòdó. Omi ki yoo wọn awọn eniyan mọ ni awọn ilẹ yiyán: “Nitori omi yoo tú jade li aginju, ati iṣàn omi ni ijù.”

Ilẹ Palẹstini ni pataki yoo ni ọrá yoo si mu ohun ọgbin jade lọpọlọpọ ni akoko Ijọba Ẹgbẹrun Ọdún. “Kiyesii, ọjọ na de, li OLUWA wi, ti ẹniti ntulẹ yio le ẹniti nkore bá, ati ẹniti o ntẹ eso àjara yio le ẹniti nfunrùgbin bá; awọn oke-nla yio si kán ọti-waini didùn silẹ, gbogbo oke kékèké yio si di yiyọ” (Amosi 9:13).

Eweko

Aginju ati ilẹ gbigbẹ yio yọ fun wọn; ijù yio yọ, yio si tanna bi lili.

Ni titanna yio tanna; yio si yọ ani pẹlu ayọ ati orin: ogo Lẹbanoni li a o fi fun u, ẹwà Karmeli on Ṣaroni; nwọn o ri ogo OLUWA, ati ẹwà Ọlọrun wa” (Isaiah 35:1, 2).

Emi o fi igi kedari si aginjù, ati igi ṣita, ati mirtili, ati igi ororó; emi o gbin igi firi ati igi pine ati igi boksi pọ ni aginjù; (Isaiah 41:19).

Nitori ayọ li ẹ o fi jade, alaafia li a o fi tọ nyin: awọn oke-nla ati awọn oke kékèké yio si bú si orin niwaju nyin, gbogbo igi igbẹ yio si ṣapẹ.

Igi firi yio hù jade dipò ẹgún, igi mirtili yio hù jade dipò oṣuṣu” (Isaiah 55:12, 13).

“Gbogbo ẹda li o jumọ nkerora ti o si nrọbi pọ titi di isisiyi” (Romu 8:22). Gbogbo ẹda ni o mọ ègún ẹṣẹ lara. Irẹdanu wà lara gbogbo eweko. Nibi gbogbo ni a n ri idibajẹ, ati arun lara igi, ikán ati oniruuru kokoro ti o n ba ẹwà ati pipé eweko jẹ. Nigbà ti a ba gbé Satani dè, ti Ọlọrun si mu ègún kuro, “awọn oke-nla ati awọn oke-kékèké yio bu si orin niwaju nyin, gbogbo igi igbẹ yio si ṣapẹ.” Gbogbo ẹda yoo gbadun idande kuro ninu ibajẹ ti o jẹ gbogbo ilẹ aye run lọjọ oni. Ogo Lẹbanoni – nibi ti igi kedari ti o ga fiofio gbe ti pọ si ri – igi kedari wọnni yoo tun maa hu jade ni awọn agbegbe ti wọn jẹ kiki iyanri tabi ẹgún ọgàn nisinsinyi. Òdòdó Ṣaroni yoo tanna nibi ti kò si ohunkohun nisinsinyi bikòṣe iyanrin ti afẹfẹ n gba kiri. Ẹwà Karmeli nipa ọna okun pẹlu eweko ti o dudu minimini yoo fara hàn nibi ti aṣalẹ gbé wà nisinsinyi. Awọn itanna rósi (rose) ki yoo ni ẹgun; òṣuṣu ki yoo hù ni igbẹ mọ. Dipo igi ẹgún ati ọgàn, igi mirtili ẹlẹwà ati igi firi giga fiofio ni yoo wà.

Awọn Ẹranko

Ikõkò pẹlu yio ma ba ọdọ-agutan gbe pọ, kininu yio si dubulẹ pẹlu ọmọ ewurẹ; ati ọmọ malũ ati ọmọ kiniun ati ẹgbọrọ ẹran abọpa yio ma gbe pọ, ọmọ kekere yio si ma dà wọn.

Malũ ati beari yio si ma jẹ pọ; ọmọ wọn yio dubulẹ pọ; kiniun yio si jẹ koriko bi malũ.

Ọmọ ẹnu-ọmu yio si ṣire ni ihò pāmọlẹ, ati ọmọ ti a já lẹnu-ọmu yio si fi ọwọ rẹ si ihò gunte.

Nwọn ki yio panilara, bẹẹni nwọn ki yio panirun ni gbogbo oke mimọ mi: nitori aiye yio kún fun imọ OLUWA gẹgẹ bi omi ti bò okun” (Isaiah 11:6-9).

Li ọjọ na li emi o si fi awọn ẹranko igbẹ, ati ẹiyẹ oju ọrun, ati ohun ti nrakò lori ilẹ da majẹmu fun wọn, emi o si ṣẹ ọrun ati idà ati ogun kuro ninu aiye, emi o si mu wọn dubulẹ li ailewu” (Hosea 2:18).

Emi o si ba wọn da majẹmu alafia, emi o si jẹ ki awọn ẹranko buburu dasẹ ni ilẹ na: nwọn o si ma gbe aginju li ailewu, nwọn o si sùn ninu igbó” (Esekiẹli 34:25).

Ikõko ati ọdọ-agutan yio jumọ jẹ pọ, kiniun yio si jẹ koriko bi akọ-malu: erupẹ ni yio jẹ onjẹ ejò. Nwọn ki yio panilara, tabi ki nwọn panirun ni gbogbo oke mimọ mi, li OLUWA wi” (Isaiah 65:25).

Bawo ni iyipada naa yoo ti pọ to ninu awọn ẹranko nigbà ti Ọlọrun ba ba ẹranko igbẹ da majẹmu! Oju kiniun yoo wálẹ bi ti ọmọ ologbo, yoo si maa jẹ koriko bi ti malu. Ọmọ kekere yoo le maa da àmọtẹkun kaakiri. Oro ikú ti o wà ninu ejo ki yoo si mọ, ọmọ kekere yoo wà lai lewu ninu igbó. Gbogbo ẹranko yoo maa gbé pọ ni alaafia. Bi a ba yọju loju ferese ti a si ri kiniun ati beari ninu papa pẹlu awọn ọdọ-agutan, ifoya ki yoo si mọ. Wọn yoo jumọ jẹ koriko papọ, awọn ẹranko ti o n bẹru eniyan nisinsinyi yoo wa gba ounjẹ jẹ ni ọwọ wọn.

“Nwọn ki yio panilara, bẹẹni wọn ki yio panirun ni gbogbo oke mimọ mi: nitori aiye yio kún fun imọ OLUWA gẹgẹ bi omi ti bò okun.”

Aisan yoo Dopin

Nigbana li oju awọn afọju yio là, eti awọn aditi yio si ṣi.

Nigbana li awọn arọ yio fò bi agbọnrin, ati ahọn odi yio kọrin” (Isaiah 35:5, 6).

Gbogbo aisan, arun, ati ailera jẹ iṣẹ eṣu ati abayarọsi egun naa. Ọjọ ologo ni ọjọ naa yoo jẹ nigba ti a ba de Satani ti gbogbo aisan si dopin! Ayarọ yoo fò bi agbọnrin. Odi ki yoo fi ọwọ rẹ juwe mọ, ṣugbọn okun ahọn rẹ yoo tú, yoo fọhùn yoo si maa gbọran. A ki yoo ni lo ohun-elo ti a n fi si eti ki a le gbọran ketekete mọ, bẹẹ ni kò ni si awò oju ti a n fi soju kawe mọ tabi ọpa itilẹ fun awọn ti ẹsẹ n dùn. Awọn ọlọgbọn aja ti a n lo lati maa ṣe amọna fun afọju kò ni si mọ, nitori pe gbogbo awọn afọju ni a o ti la loju.

Ẹmi Gigun

Ki yio si ọmọ-ọwọ nibẹ ti ọjọ rẹ ki yio pẹ, tabi àgba kan ti ọjọ rẹ kò kún: nitori ọmọde yio kú li ọgọrun ọdún; ṣugbọn ẹlẹṣẹ ọlọgọrun ọdún yio di ẹni-ifibu” (Isaiah 65:20).

“Nitori ọmọde yio kú li ọgọrun ọdún.” Eyi fi hàn pe ọmọde patapata ni ẹni ọgọrun ọdun -- ọmọ kekere. Ẹsẹ Iwe Mimọ yii fi ye ni pe o ṣe e ṣe ki ninu awọn ti o la Ipọnju Nla kọja tabi awọn ti a bi ni igba Ijọba Ẹgbẹrun Ọdún ki o kú. Ṣugbọn ẹmi gigun wà fun awọn ti o ba sin Oluwa. Ẹmi wọn yoo gùn bi ti igi igbẹ. Ọjọ ori igi miran to ẹgbẹrun (1,000) ọdún tabi ju bẹẹ lọ. O ṣe e ṣe ki ọpọlọpọ eniyan wà lai kú titi ẹgbẹrun ọdún naa yoo fi dopin. Ṣugbọn o dá ni loju pe awọn wọnni ti o ba Kristi pada wa si aye ninu ara ologo, ara aikú, yoo wa laaye laelae. Arun ki yoo si laye mọ bi kò ṣe lati fi jẹ ẹni ti o ba ṣẹ niya. “Ẹlẹṣẹ ọlọgọrun ọdún yio di ẹni-ifibu.” A o ran àjakalẹ àrun si awọn ti o ba kọ lati gbọran si Ọlọrun lẹnu ni akoko Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun (Ka Sekariah 14:16-19).

Ijọba

Ĕkàn kan yio si jade lati inu kùkute Jesse wá, ẹka kan yio si hù jade lati inu gbòngbo rẹ:

Ẹmi OLUWA yio si bà le e, ẹmi ọgbọn ati oye, ẹmi igbimọ ati agbara, ẹmi imọran ati ibẹru OLUWA.

Õrun didun rẹ si wà ni ibẹru OLUWA, on ki yio si dajọ nipa iri oju rẹ, bẹẹni ki yio dajọ nipa gbigbọ eti rẹ;

Ṣugbọn yio fi ododo ṣe idajọ talakà, yio si fi otitọ ṣe idajọ fun awọn ọlọkàn tutu aiye; on o si fi ọgọ ẹnu rẹ lu aiye, on o si fi ẽmi ete rẹ lu awọn enia buburu pa” (Isaiah 11:1-4).

Ni aye yii gan an ni Kristi yoo gbé jọba fun Ẹgbẹrun Ọdún “Ijọba aye di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rẹ; on o si jọba lai ati lailai” (Ifihan 11:15). Ọrọ Ologo ni eyi! “Nitori a bi ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkọnrin kan fun wa: ijọba yio si wà li ejika rẹ” (Isaiah 9:6). “O si ni lara aṣọ rẹ ati ni itan rẹ orukọ kan ti a kọ: ỌBA AWỌN ỌBA, ATI OLUWA AWỌN OLUWA” (Ifihan 19:16). Wo bi eyi yoo ti yatọ si iṣelu pẹlu idaru-dapọ ti o ti gba aye kan lati ọpọlọpọ ọdún sẹhin! Jesu yoo fi “ọpa irin” ṣe akoso aye – ki i ṣẹ irú akoso ika ti awọn onroro, ṣugbọn ijọba titọ ti Ọlọrun Olodumare. Ẹni ti o beere pe ki awọn ẹda ọwọ Rẹ lati eyi ti o kere ju lọ de eyi ti o ga ju lọ ki o jẹ pipe; ẹni ti o n ṣe akoso ipa ọna oorùn, oṣupa ati awọn irawọ, yoo maa ṣe akoso ti o tọ ninu eto iṣelú ayi yii “On ki yio si dajọ nipa iri oju rẹ, bẹẹni ki yio dajọ nipa gbigbọ eti rẹ; ṣugbọn yio fi ododo ṣe idajọ.” A kò ni fi owo ẹhin bọ awọn àṣayan igbimọ (juri) lọwọ mọ, a kò ni le fi owo pa adajọ lẹnu mọ, kò ni si gbigbe aṣiiri ilu tà fun alejo mọ. A kò ni fi ti ẹgbẹ oṣelu di onipò, ṣugbọn a o fi fun awọn ti o yẹ ti wọn si ni ẹtọ si àyè naa.

Awọn Eniyan Mimọ ti wọn n Jọba

Jesu wi pe, “Ẹniti o ba ṣẹgun” -- awọn ẹni irapada ti a ti ṣe ni aṣepe lati igbà ti aye ti ṣẹ -- “li emi o fifun lati joko pẹlu mi lori itẹ mi” (Ifihan 3:21). Oun yoo wi fun awọn ti o ba jẹ olootọ si Ọlọrun ni aye yii pe, “O ṣẹun, iwọ ọmọ-ọdọ rere: nitoriti iwọ ṣe olõtọ li ohun kikini, gbà aṣẹ lori ilu mẹwa” (Luku 19:17). Fun awọn ti o ni ipin ninu Ajinde Ekinni ni a ṣeleri fun pe: “Nwọn o jẹ alufa Ọlọrun ati ti Kristi, nwọn o si mā jọba pẹlu rẹ li ẹgbẹrun ọdún” (Ifihan 20:6). Fun awọn ti a bẹ lori fun Ọrọ Ọlọrun nitori ti wọn kọ lati fori balẹ fun ẹranko naa ni a sọ wi pe, “Nwọn si wà lāye, nwọn si jọba pẹlu Kristi li ẹgbẹrun ọdun” (Ifihan 20:4). Ọrọ itunu wọnyi wà fun awọn Onigbagbọ ti o n jiya ti o si n fara da irora: “Bi awa ba farada, awa ó si ba a jọba” (II Timoteu 2:12). Orin ti awọn ẹni irapada yoo maa kọ yi itẹ naa ka ni eyi: “A ti pa ọ, iwọ si ti fi ẹjẹ rẹ ṣe irapada enia si Ọlọrun lati inu ẹyà gbogbo, ati ède gbogbo, ati inu enia gbogbo, ati orilẹ-ède gbogbo wá; Iwọ si ti ṣe wọn li ọba ati alufa si Ọlọrun wa: nwọn si njọba lori ilẹ aiye” (Ifihan 5:9, 10). Awọn eniyan mimọ ti a ṣe logo pada sori ilẹ aye pẹlu Jesu lati ba A jọba fun ẹgbẹrun ọdun.

Jerusalẹmu, Olú –Ìlú

Nigbà ti Jesu wà ni aye, awọn Ju n ro pe yoo gbé ijọba Rẹ kalẹ. Lẹhin Ajinde, awọn ọmọ-ẹhin beere pe: “Oluwa, lati igbayi lọ iwọ ó ha mu ijọba pada fun Israẹli bi? (Iṣe Awọn Apọsteli 1:6). Wọn mọ nipa ileri yii pe , “Oluwa yio si jọba lori wọn li oke-nla Sioni” (Mika 4:7). Ọpọlọpọ ninu wọn ni o fẹ mu Kristi, ki wọn si fi I jọba lẹsẹkẹsẹ, ṣugbọn akoko Ọlọrun kò ti i to. Ṣugbọn a o mu awọn ileri yii ṣẹ ni akoko Ijọba Ẹgbẹrun Ọdún pe, “lati Sioni ni ofin yio ti jade lọ, ati ọrọ OLUWA lati Jerusalẹmu” (Mika 4:2). Jesu yoo jọba lori gbogbo aye; Jerusalẹmu ni yoo si jẹ olu-ilu Rẹ.

Ìsìn Mímọ

Gbogbo isin eke ki yoo si mọ. “Nitoriti aiye yio kún fun imọ ogo OLUWA, bi omi ti bò okun” (Habakkuku 2:14). “Awọn ẹniti ngbe ilu-nla kan yio lọ si omiran, wipe, Ẹ jẹ ki a yara lọ igbadura niwaju OLUWA, ati lati wá OLUWA awọn ọmọ-ogun; emi pẹlu o si lọ. Nitõtọ ọpọlọpọ enia, ati awọn alagbara orilẹ-ède yio wá, lati wá OLUWA awọn ọmọ-ogun ni Jerusalẹmu; ati lati gbadura niwaju OLUWA” (Sekariah 8:20-22).

Opopo kan yio si wà nibẹ, ati ọna kan, a o si ma pè e ni, Ọna iwà-mimọ; alaimọ ki yio kọja nibẹ; nitori on o wà pẹlu wọn: awọn èro ọna na, bi nwọn tilẹ jẹ òpe, nwọn ki yio ṣi i.

Kiniun ki yio si nibẹ, bẹẹni ẹranko buburu ki yio gùn u, a ki yio ri i nibẹ; ṣugbọn awọn ti a ràpada ni yio ma rin nibẹ:

Awọn ẹni-irapada OLUWA yio padà, nwọn o wá si Sioni, ti awọn ti orin, ayọ ainipẹkun yio si wà li ori wọn: nwọn o ri ayọ ati inu didùn gbà, ikānu on imi-ẹdùn yio si fo lọ” (Isaiah 35:8-10).

Nigba ti Oluwa ba jọba ni Jerusalẹmu, ohun aimọ kan kò ni si nibẹ. “Nitõtọ, gbogbo ikòko ni Jerusalẹmu ati ni Juda yio jẹ mimọ si OLUWA awọn ọmọ-ogun” (Sekariah 14:21). “Li ọjọ na ni MIMỌ SI OLUWA yio wà lara ṣaworo ẹṣin” (Sekariah 14:20). Kiki awọn ẹni irapada ni yoo maa gbe ibẹ. “Bẹli ẹnyin o mọ pe, Emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti ngbe Sioni oke mimọ mi: nigbana ni Jerusalẹmu yio jẹ mimọ, awọn alejo ki yio si là a kọja mọ” (Joẹli 3:17). “Ara Kenaani ki yio si si mọ ni ile OLUWA awọn ọmọ-ogun” (Sekariah 14:21). Gbogbo orilẹ-ède ni yoo maa wa Oluwa ni Jerusalẹmu. “Li ọjọ wọnni, yio ṣẹ, ni ọkunrin mẹwa lati inu gbogbo ède ati orilẹ-ède yio di i mu, ani yio di eti aṣọ ẹniti iṣe Ju mu, wipe, A o ba ọ lọ, nitori awa ti gbọ pe, Ọlọrun wà pẹlu rẹ” (Sekariah 8:23).

Awọn Ju

Awọn ti o la Ipọnju Nla kọja, ti wọn si yi pada si Kristi, yoo maa gbe ni ilẹ wọn ni Palẹstini. Awọn Apọsteli mejila “o si joko pẹlu lori itẹ mejila”, wọn o si “ma ṣe idajọ ẹya Israẹli mejila” (Matteu 19:28). Nipa iṣubu awọn Ju, igbala de ọdọ awọn Keferi. “Ṣugbọn bi iṣubu wọn ba di ọrọ aiye, ati bi ifasẹhin wọn ba di ọrọ awọn Keferi; melomelo ni kikun wọn?” Bawo ni akoko naa yoo ti ni ogo to nigba ti a ba mu Israẹli pada bọ sipo! Abajọ ti eniyan mẹwa yoo fi rọ mọ Ju kan ti wọn yoo si maa wi pe, “A o ba ọ lọ, nitori awa ti gbọ pe Ọlọrun wà pẹlu rẹ.”

Gogu ati Magogu

Kristi yoo jọba ni aye yii fun ẹgbẹrun (1,000) ọdún. Fun ẹgbẹrun ọdún, aye yoo bọ lọwọ ogun ati iwa ipá. “Nwọn o fi idà wọn rọ ọbẹ-plau, nwọn o s fi ọkọ wọn rọ dojé; orilẹ-ède ki yio gbe idà soke si orilẹ-ède; bẹẹni nwọn ki yio kọ ogun jijà mọ” (Isaiah 2:4). Kò ni si ẹgbẹ ọmọ-ogun mọ, tabi ile-ẹrọ ti a gbe n rọ ohun ijà tabi awọn àfọnja ti a fi n pa ni run. Ọmọ-Alade Alaafia ni yoo maa jọba lori ilẹ aye.

Nigbati ẹgbẹrun ọdún na ba si pé, a o tú Satani silẹ kuro ninu tubu rẹ,

Yio si jade lọ lati mā tàn awọn orilẹ-ède ti mbẹ ni igun mẹrẹrin aiye jẹ, Gogu ati Magogu, lati gbá wọn jọ si ogun: awọn ti iye wọn dabi iyanrin okun.

Nwọn si gòke lọ la ibú aiye ja, nwọn si yi ibudo awọn enia mimọ ká ati ilu ayanfẹ na: iná si ti ọrun sọkalẹ wá, o si jo wọn run.

A si wọ Eṣu ti o tàn wọn jẹ lọ sinu adagun iná ati sulfuru, nibiti ẹranko ati woli eke ni gbé wà, a o si mā dá wọn loro t’ọsan-t’oru lai ati lailai (Ifihan 20:7-10).

Ọlọrun n fẹ awọn ti a ti danwo ti a si ti yiiri rẹ wò lati maa sin Oun. O mu ki Israẹli rin ni aginju ni ogoji ọdún lati dan wọn wò lati mọ bi wọn yoo sin Oun tabi bẹẹ kọ (Wo Deuteronomi 8:3). Fun ẹgbẹrun ọdún, aye yoo wà lai si oludanwo. Lẹhin naa a o tú Satani silẹ fun iwọn igbà diẹ ki awọn eniyan le funra wọn yàn lati sin Ọlọrun. Bi o tilẹ jẹ pe, imọ Ọlọrun yoo bori aye bi omi ti bori okun, sibẹ Satani yoo tun tàn awọn eniyan jẹ, yoo si pa ẹgbẹẹgbẹrun laya dà lati ba awọn eniyan Ọlọrun ja. A o waasu Ihinrere fun eniyan gbogbo fun ẹgbẹrun ọdún ṣugbọn ẹgbẹẹgbẹrun yoo tun ṣubu sinu idẹkun eṣu, wọn yoo si ṣegbe. Eyi mu ki a mọ bi o ti ṣe danindanin to lati ni ipilẹ ti o daju lori eyi ti a le kọ ile iriri ti kò ni já ni tilẹ le.

Satani yoo lọ si igun mẹrẹẹrin aye lati tan awọn orilẹ-ède jẹ -- ni ihà gbogbo – Gogu ati Magogu, lati gbá wọn jọ lati gbogun ti Jerusalẹmu. Yoo fẹrẹ jẹ pe gbogbo awọn orilẹ-ède Keferi ni yoo wa ninu “Gogu ati Magogu.” Ogun yii kọ ni Esekiẹli 39 n sọ nipa rẹ: eyi ni yoo ti bẹ silẹ ṣiwaju Ijọba Ẹgbẹrun Ọdún, ninu eyi ti a sọ fun ni pe wọn “wa lati ihà ariwa.”

“Nwọn si gòke lọ la ibú aiye ja, nwọn si yi ibudo awọn enia mimọ ká ati ilu ayanfẹ na: iná si ti ọrun sọkalẹ wá, o si jo wọn run” (Ifihan 20:9).

Nigba ti a ba dán ayanfẹ Ọlọrun kan ti o kẹhin wò, ti o si yege, Ọlọrun yoo gé iṣẹ eṣu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ kuru. A o gbé eṣu sinu adagun ina, ina lati Ọrun wa yoo si jo awọn ẹmẹwa rẹ run. Iṣẹgun yoo si jẹ ti Ọlọrun wa ti o ṣe ohun gbogbo daradara.