Gẹnẹsisi 12:1-3; 17:1-8; 22:15-18

Lesson 157 - Junior

Memory Verse
“Kọju si mi, ki a si gba nyin là, gbogbo opin aiye: nitori emi li Ọlọrun, kò si ẹlomiran” (Isaiah 45:22).
Notes

OLUWA si ti wi fun Abramu pe, Jade kuro ni ilẹ rẹ, ati kuro lọdọ awọn ara rẹ, ati kuro ni ile baba rẹ, si ilẹ kan ti emi o fi hàn ọ:

Emi o si sọ ọ di orilẹ-ède nla, emi o si busi i fun ọ, emi o si sọ orukọ rẹ di nla; ibukun ni iwọ o si jasi:

Emi o bukun fun awọn ti nsúre fun ọ, ẹniti o nfi ọ ré li emi o si fi ré; ninu rẹ li a o ti bukun fun gbogbo idile aiye” (Gẹnẹsisi 12:1-3).

Gẹnẹsisi ori kẹwaa, ti o ṣiwaju awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun ti o wà loke yii ni a n pe ni “Etò awọn Orilẹ-ède”, nitori nibẹ ni a gbé to iran awọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu ati Jafẹti, ati ẹkùn ibi ti wọn n gbé ni ayé. Ọrọ wọnyi ni o pari iwe naa: “Wọnyi ni idile awọn ọmọ Noa, gẹgẹ bi iran wọn, li orilẹ-ède wọn; lati ọwọ awọn wọnyi wá li a ti pin orilẹ-ède aiye lẹhin kíkun-omi” (Gẹnẹsisi 10:32).

Asọtẹlẹ Noa nipa awọn ọmọ rẹ jẹ ibi kan pataki ti o fara kọ awọn orilẹ-ède wọnyi timọtimọ: O si wipe, “Egbe ni fun Kenaani (Hamu); iranṣẹ awọn iranṣẹ ni yio ma ṣe fun awọn arakọnrin rẹ. O si wipe, Olubukun li OLUWA Ọlọrun Ṣemu; Kenaani yio ma ṣe iranṣẹ rẹ. Ọlọrun yio mu Jafeti gbilẹ, yio si ma gbé agọ Ṣemu” (Gẹnẹsisi 9:25-27).

Bakan naa ni a sọ nipa awọn iran Jafeti ti o lọ bẹẹrẹ wi pe, “Lati ọdọ awọn wọnyi li a ti pin erekuṣu awọn orilẹ-ède ni ilẹ wọn, olukuluku gẹgẹ bi ohùn rẹ; gẹgẹ bi idile wọn, li orilẹ-ède wọn” (Gẹnẹsisi 10:5). A sọ fun ni pe awọn orilẹ-ède wọnyii ni o wà ni ipinlẹ Europe ti wọn si tàn lọ si Amẹrika.

Ni akoko yii, lẹyin ti a tú awọn orilẹ-ède ká, Ọlọrun tikara Rẹ yan awọn eniyan kan, gẹgẹ bi “ijọba alufa, orilẹ-ède mimọ”, fun ini pataki fun ara Rẹ, awọn ẹni ti Ọlọrun ba lò ni pataki fun ọpọlọpọ ọdun. I ha ṣe pe a ti gbagbe awọn orilẹ-ède iyoku tabi a ti tá wọn nù? Lodi si eyi, titò ti a tilẹ to orukọ wọn fi hàn pe Ọlọrun kò tá wọn nù, ṣugbọn pe a o kà wọn kún ẹni ti Rẹ gẹgẹ bi a ti le fi ẹsẹ eyi mulẹ nipa awọn asọtẹlẹ inu Majẹmu Laelae nipa ipè awọn Keferi. Eto awọn Orilẹ-ède wọnyi kó gbogbo aye pọ jakejado, lati igbà nì nipa Eto Ọlọrun, ti o kan gbogbo orilẹ-ède aye, nla tabi kekere.

Ipè Abrahamu

Abramu (ẹni ti a mọ ni Abrahamu ni ọjọ iwaju), ti idile Ṣemu, ni a bi ni Uri ti Kaldea laaarin awọn abọriṣa, gẹgẹ bi gbogbo awọn eniyan ti igbà naa. Ṣugbọn laaarin awọn ogunlọgọ ati oriṣiriṣi eniyan ti ijọba ila-oorun yii, ni Ọlọrun, ti o mọ ọkàn eniyan ya Abrahamu sọtọ fun ipè Rẹ. A kọ ọ pe “Tera si mu Abramu ọmọ rẹ, Lọti, ọmọ Harani, ọmọ ọmọ rẹ, ati Sarai aya ọmọ rẹ, aya Abramu ọmọ rẹ; nwọn si ba wọn jade kuro ni Uri ti Kaldea, lati lọ si ilẹ Kenaani; nwọn si wá titi de Harani, nwọn si joko sibẹ” (Gẹnẹsisi 11:31). Harani wà ni ihà ariwa, ṣugbọn ibẹ ni oju ọna ti wọn saba maa n gba lọ si Kenaani, nihin yii ni Ọlọrun ti gbe bá Abrahamu sọrọ. Ṣugbọn ọrọ wọnyi, “OLUWA si ti wi fun Abramu pe” fi hàn pe Ọlọrun ti kọ pe Abramu nigbà ti o ti wa ni Uri. Ọrọ Stefanu, ajẹriku si tun fi idi eyi mulẹ, “Ọlọrun ogo fi ara hàn fun Abrahamu baba wa, nigbati o wà ni Mesopotamia, ki o to ṣe atipo ni Harani, o si wi fun u pe, Jade kuro ni ilẹ rẹ, ati lọdọ awọn ibatan rẹ, ki o si wá si ilẹ ti emi ó fi hàn ọ” (Iṣe Awọn Apọsteli 7:2, 3). Eyi fi hàn dajudaju pe lati Uri ti Kaldea, ilu abọriṣa ni Ọlọrun ti kọ pe Abrahamu.

Nigba ti a tun Abrahamu pe ni Harani, ti Oluwa si paṣẹ fun un lati wá “si ilẹ kan ti emi ó fi hàn ọ,” idi pataki ti Ọlọrun fi pe e di mimọ. O sọ fun un pe, “Jade kuro ni ilẹ rẹ, ati kuro lọdọ awọn ara rẹ, ati kuro ni ile baba rẹ.” Eyi tumọ si iya-ara-ẹni-sọtọ, nitori eniyan Ọlọrun ni igbà ayé awọn patriaki kò gbọdọ dara pọ mọ aye ati iwa buburu rẹ, gẹgẹ bi o ti ri ni akoko yii fun awọn Onigbagbọ (2 Kọrinti 6:14-18). A sọ fun ni pe Abrahamu mu awọn ẹbi rẹ, o si kó gbogbo ini rẹ jọ, “nwọn si jade lati lọ si ilẹ Kenaani; ni ilẹ Kenaani ni nwọn si wá si” (Gẹnẹsisi 12:5), eyi fi igbọran pipe Abrahamu hàn. Igbọran si ifẹ Ọlọrun jẹ ọkan ninu awọn ohun ti Iwe Mimọ fi lelẹ pe Ọlọrun n beere lọwọ awọn eniyan Rẹ. Orukọ Abrahamu ti di mimọ gẹgẹ bi “Baba Igbagbọ.” Itumọ kan ṣoṣo naa ni “igbagbọ” ati “igbọran” ni ninu Bibeli. “Igbagbọ” ati “igbọran” ki i ya ara wọn.

Bakan naa ni akọsilẹ wà pe nigba ti Abrahamu de ilẹ Kenaani, o pagọ si ibi kan ti a n pè ni Bẹtẹli, “o si tẹ pẹpẹ kan nibẹ fun OLUWA, o si kepè orukọ OLUWA” (Gẹnẹsisi 12:8). Bi Abrahamu ba lọ si ibi kan, nigbakugba ti o ba tun pada si ilẹ naa, oun yoo lọ si ibẹ gan an, yoo si tun pe orukọ Oluwa. Eyi fi han pe Abrahamu jẹ ẹni ti n gbadura, ti o si n bá Ọlọrun igbala rẹ sọrọ. Jakọbu ni o pe orukọ ibẹ ni Bẹtẹli (Lusi ni a n pe e tẹlẹ ri). Itumọ Bẹtẹli ni “ile Ọlọrun” nitori ni ibi mimọ yii ni Jakọbu gbe ri iran Ọrun, eyi ti a n pe ni “Akasọ Jakọbu.” Nitori naa nigba ti Ọlọrun pe Abrahamu, ẹni ti Oun yoo lò ni O pè.

A Pè E lati Jẹ Ibukun

Awọn ileri kan ti ipè Abrahamu lẹyin. Ọlọrun sọ fun un pe: “Emi o si sọ ọ di orilẹ­-ède nla, emi o si busi i fun ọ, emi o si sọ orukọ rẹ di nla.” O ṣeleri pe awọn ọmọ rẹ yoo pọ bi iyanrin eti okun ati bi irawọ oju ọrun. Ṣugbọn ileri Ọlọrun yii kò pin sọdọ Abrahamu tabi iran rẹ nikan. O tun sọ pẹlu pe, “ibukun ni iwọ o si jasi … ninu rẹ li a o ti bukun fun gbogbo idile aiye.” Ọrọ wọnyi tun tọka si “Eto awọn Orilẹ-ède”, eyi ti o fi idi ti Ọlọrun fi pe Abrahamu hàn. Ipinnu naa gbooro to bẹẹ ti Ọlọrun fi jẹ ki o kan iran, orilẹ ati ède gbogbo, ki ibukun ti Ọlọrun ti ṣeleri fun Abrahamu le jẹ ti wọn. Nipa eyi, a le mọ bi asọtẹlẹ Noa ti ṣe pataki to: “Ọlọrun yio si mu Jafeti gbilẹ, yio si ma gbé agọ Ṣemu.”

Nigbati Abramu si di ẹni ọkàndilọgọrun (99) ọdún, OLUWA farahàn Abramu, o si wi fun u pe, Emi li Ọlọrun Olodumare; ma rin niwaju mi, ki iwọ ki o si pé,

Emi o si ba ọ dá majẹmu mi, emi o si sọ ọ di pupọ gidigidi.

Abramu si dojubolẹ; Ọlọrun si ba a sọrọ pe,

Bi o ṣe ti emi ni, kiyesi i, majẹmu mi wà pẹlu rẹ, iwọ o si ṣe baba orilẹ-ède pupọ.

Bẹẹli a ki yio si pe orukọ rẹ ni Abramu mọ, bikoṣe Abrahamu li orukọ rẹ yio jẹ: nitori mo ti sọ ọ di baba orilẹ-ède pupọ.

Emi o si mu ọ bi si i pupọpupọ, ọpọ orilẹ-ède li emi o si mu ti ọdọ rẹ wá, ati awọn ọba ni yio ti inu rẹ jade wá.

Emi o si gbe majẹmu mi kalẹ lārin temi tirẹ, ati lārin irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ ni iran-iran wọn, ni majẹmu aiyeraiye, lati mā ṣe Ọlọrun rẹ, ati ti irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ.

Emi o si fi ilẹ ti iwọ ṣe alejo nibẹ fun ọ, ati fun irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ, gbogbo ilẹ Kenaani ni iní titi lailai; emi o si ma ṣe Ọlọrun wọn” (Gẹnẹsisi 17:1-8).

Ibi pataki ninu Iwe Mimọ yii fi hàn pe Ọlọrun n mu Abrahamu lọ sinu iriri ti o jinlẹ ati fifi ara mọ Oluwa timọ-timọ ju ti igba ti a kọkọ pe e ni Uri ti Kaldea, nitori ti O wi pe: “Emi li Ọlọrun Olodumare; mā rin niwaju mi ki o si pé.” Ifarahan Ọlọrun Olodumare ṣiji bo Abrahamu to bẹẹ ti o fi doju bolẹ. A ti da a lare ná, nitori a sọ ninu Gẹnẹsisi ori kẹẹdogun pe: “O si mu u jade wá si gbangba, o si wi pe, Gboju wò oke ọrun nisisiyi, ki o si kà irawọ bi iwọ ba le kà wọn: o si wi fun u pe, Bẹẹni irú-ọmọ rẹ yio ri. O si gba OLUWA gbọ; on si kà a si fun u li ododo” (Gẹnẹsisi 15:5, 6). Eyi ni Paulu Apọsteli pè ni iriri ti idalare nipa igbagbọ (Romu 4:3). Nihin yii ni Abrahamu ti bẹrẹ si ṣe ifararubọ ti o jinlẹ si Oluwa, apẹẹrẹ eyi ti awọn ẹbọ ti o ru si Ọlọrun i ṣe (Gẹnẹsisi 15:9-11; Romu 12:1, 2). Ifararubọ ribiribi ti o ṣe yii si jẹ itẹwọgba lọdọ Ọlọrun, eyi ti o fi hàn nipa “ileru elẽfin, ati iná fitila ti n kọja lārin ẹla wọnni” (Gẹnẹsisi 15:17), ti ó dabi iná ti ó sọkalẹ sori ẹbọ naa (Lefitiku 9:24). Nitori naa nigba ti Oluwa paṣẹ pe; “Ma rin niwaju mi, ki iwọ ki o si pé”, lai si aniani a ti sọ Abrahamu di mimọ patapata, nitori isọdimimọ ni i ṣe iṣẹ aṣepé ninu ọkàn, eyi ti o n fun Onigbagbọ ni agbara lati rin ni pipé iwa (Luku 1:74, 75), ati lati “le ri idi ifẹ Ọlọrun, ti o dara, ti o si ṣe itẹwọgbà, ti o si pé” (Romu 12:2).

A ti mọ tẹlẹ pe idi rẹ ti Ọlọrun fi pe Abrahamu ni lati le mu Eto Mimọ Rẹ ti o kan gbogbo agbaye ṣẹ. Ṣugbọn ki Ọlọrun to le lo Abrahamu, a ni lati ṣe iṣẹ aṣepé ninu rẹ lati le mu ki o wulo lọwọ Ọlọrun.

Majẹmu pẹlu Abrahamu

A ri i nisisiyii pe ipe Abrahamu wa di Majẹmu ti o ni ọwọ. Majẹmu jẹ “adehun laaarin awọn eniyan ti o ju ẹyọ kan lọ.” Majẹmu yii jẹ adehùn laaarin Ọlọrun ati Abrahamu. Ọlọrun tikara Rẹ ni Olupilẹṣẹ majẹmu naa. Ninu rẹ ni a gbe fi awọn ohun ti Abrahamu ni lati mu ṣe lelẹ, ati awọn ileri ti Ọlọrun tikara Rẹ ni lati mu ṣẹ pẹlu. Nitori naa, Majẹmu yii jẹ eyi ti o ni ọwọ gidigidi, nitori, lọna kin-in-ni, Ọlọrun Olodumare, Ẹlẹda Ọrun ati aye, ni o ba dá majẹmu naa, lọna keji ẹwẹ, ki i ṣe fun ire Abrahamu nikan tabi ti iran rẹ, ṣugbọn o ṣe pataki fun “gbogbo idile aiye.” Ta ni le mọ gbigbooro ifẹ Ọlọrun ti kò lopin ti o gba aye ẹṣẹ yii kan!

Nigba ti Abrahamu ṣe ifararubọ ti o jinlẹ ti o ni ọwọ yii si Oluwa, ti iná si sọkalẹ lati Ọrun wá sori ẹbọ rẹ, a kọ ọ pe, “Li ọjọ na gan li OLUWA bá Abramu dá majẹmu” (Gẹnẹsisi 15:18). Ni ori kẹtadinlogun, a kọ ọ pe “Emi o si gbe majẹmu mi kalẹ lārin temi tirẹ, ati lārin irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ ni iran-iran wọn, ni majẹmu aiyeraiye, lati ma ṣe Ọlọrun rẹ, ati irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ” (Gẹnẹsisi 17:7). Bayii ni Majẹmu naa ṣe pataki ti o si ni ọwọ to -- Majẹmu Ayeraye eyi ti o kan awọn iran-iran, ki wọn ba le gbadun ibukun rẹ ki Ọlọrun Abrahamu le jẹ Ọlọrun wọn. Awọn “iran ti n bọ” kò pin sọdọ irú-ọmọ Abrahamu nikan nitori a kà a pe: “Bi o ṣe ti emi ni, kiyesi i, majẹmu mi wà pẹlu rẹ, iwọ o si ṣe baba orilẹ-ède pupọ.” Nihin yii ni a gbé yí orukọ Abramu pada si Abrahamu itumọ eyi ti i ṣe “baba orilẹ-ède pupọ.”

Ileri nla kan si tun rọ mọ majẹmu yii pẹlu. “Emi o si fi ilẹ ti iwọ ṣe alejo nibẹ fun ọ, ati fun irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ, gbogbo ilẹ Kenaani ni iní titi lailai; emi o si ma ṣe Ọlọrun wọn.” Ilẹ yii bẹrẹ lati odo Egipti titi de odo Euferate, gẹgẹ bi Majẹmu ti Ọlọrun ba Abrahamu dá, ti a si ṣeleri rẹ fun iran Abrahamu: “Irú-ọmọ rẹ ni mo fi ilẹ yi fun, lati odò Egipti wá, titi o fi de odò nla ni, odò Euferate” (Gẹnẹsisi 15:18). A mu ileri yii ṣẹ patapata ni akoko ijọba Sọlomọni ti ogo ijọba naa tàn jade bi wura: “Juda ati Israẹli pọ gẹgẹ bi iyanrin ti mbẹ li eti okun ni ọpọlọpọ, nwọn njẹ, nwọn si nmu, nwọn si nṣe ariya. Sọlomọni si jọba lori gbogbo awọn ọba lati odò (Euferate) titi de ilẹ awọn ara Filista, ati titi de eti ilẹ Egipti” (1 Awọn Ọba 4:20, 21).

Ilẹ Ileri wà lara Majẹmu Ayeraye ti a ba Abrahamu dá, a si tun ṣeleri pe yoo jẹ ini ayeraye fun awọn ọmọ Abrahamu. Bi awọn Ọmọ Israẹli ba gbọran si Ọlọrun lẹnu nigba ti o dara fun wọn gẹgẹ bi Mose ti tẹnu mọ ọn fun wọn gbọnmọ-gbọnmọ ki wọn to re Jọrdani kọja, ilẹ naa ki ba ti bọ kuro lọwọ wọn. Ṣugbọn lẹyin ijọba Sọlomọni, ijọba naa pin si meji. Awọn ẹya mẹwaa ti o wà ni ariwa wà labẹ akoso Jeroboamu ẹni ti o mu Israẹli dẹṣẹ, ijọba Juda ati Bẹnjamini wà ni iha guusu. Ṣugbọn nikẹyin awọn ẹya mejeejila pada si ibọriṣa ti o buru jai, Ọlọrun si mu ki a kó wọn lẹrú ki a si tú wọn kaakiri awọn orilẹ-ède. A wó Tẹmpili wọn daradara lulẹ, a fi iná kun ilu wọn ti wọn fẹran, ilẹ eleso wọn pada di aṣalẹ. Fun ọpọlọpọ ọdun ni Palẹstini fẹrẹ má sàn ju papa oko lọ, lọwọ awọn ọta wọn.

Ṣugbọn Ọlọrun kò gbagbé Majẹmu Rẹ pẹlu awọn baba Israẹli, Abrahamu, Isaaki ati Jakọbu. Iwe Mimọ kún fun ọpọ asọtẹlẹ pe nikẹyin ọjọ, awọn Ọmọ Israẹli yoo pada si ilẹ Ileri, apákan ninu wọn yoo là nigba Ipọnju Nla, wọn yoo si yí pada si Messia wọn lẹẹkan si i nigba ti O ba tun fara hàn. Ilẹ naa yoo si jẹ ini wọn titi laelae. Bayii ni Iwe Mimọ fi ye ni pe nipa Majẹmu ti Ọlọrun ba Abrahamu dá, awọn ọmọ rẹ yoo wà ni ipo pataki nikẹyin ọjọ, ninu Eto Nla Ọlọrun. Nitori ni Jerusalẹmu ni a o gbe fi idi “itẹ” Dafidi mulẹ, “OLUWA yio si jọba lori gbogbo aiye: li ọjọ na ni OLUWA kan yio wà, orukọ rẹ yio si jẹ ọkan” (Sekariah 14:9).

Angẹli OLUWA nì si kọ si Abrahamu lati ọrun wá lẹrinkeji,

O si wipe, Emi tikalami ni mo fi bura, li OLUWA wi, nitori bi iwọ ti ṣe nkan yi, ti iwọ kò si dù mi li ọmọ rẹ, ọmọ rẹ na kanṣoṣo:

Pe ni bibukún emi o bukún fun ọ, ati ni bíbisi emi o mu irú-ọmọ rẹ bísi i bi irawọ oju-ọrun, ati bi iyanrin eti okun; irú-ọmọ rẹ ni yio si ni ẹnubode awọn ọta wọn;

Ati ninu irú-ọmọ rẹ li a o bukún fun gbogbo orilẹ-ède aiye: nitori ti iwọ ti gbà ohùn mi gbọ” (Gẹnẹsisi 22:15-18).

Ọrọ wọnyii ni o bẹrẹ ori kejilelogun yii. “O si ṣe lẹhin nkan wọnyi ni Ọlọrun dan (yiiri) Abrahamu wò, o si wi fun u pe, Abrahamu: on si dahùn pe, Emi niyi. O si wi fun u pe, Mu ọmọ rẹ nisisiyi, Isaaki, ọmọ rẹ na kanṣoṣo, ti iwọ fẹ, ki o si lọ si ilẹ Moria; ki o si fi i rubọ sisun nibẹ lori ọkan ninu oke ti emi o sọ fun ọ” (Gẹnẹsisi 22:1, 2).

Ẹni ọdun marundinlọgọrin (75) ni Abrahamu nigbà ti o wọ ilẹ Kenaani ni idahùn si ipè Ọlọrun. Ọkan ninu awọn ileri ti Ọlọrun ṣe fun un nitori igbọran rẹ ni pe iru ọmọ rẹ yoo pọ bi iyanrin eti okun; O tun ṣeleri lati fun un ni ọmọ kan. Eniyan Ọlọrun yii mọ dajudaju pe, Oluwa Ọlọrun Ọrun kò ṣe ileri yii pe, “Emi o si sọ ọ di orilẹ-ède nla, emi o si busi i fun ọ, emi o si sọ orukọ rẹ di nla”; ki i ṣe ki Abrahamu ba le di olokiki nikan, ṣugbọn pe, nipasẹ iru ọmọ rẹ, ni ọna iyanu kan ti Ọlọrun kò ti i fi hàn patapata, Eto iyanu Rẹ yii ni yoo sún wọn kan ileri tabua-tabua yii pe, “Ninu rẹ li a o ti bukun fun gbogbo idile aiye.” Ọdún gori ọdún, ileri yii nipasẹ idile rẹ kò ti i ṣẹ, i bá à tilẹ ṣe apakan ninu rẹ -- Abrahamu kò bimọ. Igbagbọ Abrahamu – nitori pe nipa igbagbọ ni a fi n mú ileri Ọlọrun ṣẹ -- ni a danwò fun ọdún marundinlọgbọn. Nikẹyin ni igbà ogbo Abrahamu ni a mu ileri yii ṣẹ; a bi Isaaki ọmọ ileri.

Nigba naa, lẹyin ọdun diẹ si i ni aṣẹ ti o ṣajeji yii kan Abrahamu lara lati Ọrun wá pe, “Mu ọmọ rẹ nisisiyi, Isaaki, ọmọ rẹ na kanṣoṣo, ti iwọ fẹ, ki iwọ ki o si lọ si ilẹ Moria; ki o si fi i rubọ sisun nibẹ.” A kò le fẹnu sọ irú ohun ti ọrọ wọnyii ṣe lọkàn Abrahamu bi wọn ti de eti igbọ rẹ lojiji. Wọn mu un lọkan ṣinṣin. Ṣugbọn o mọ pe Ọlọrun ni o fọhùn. O pa ọrọ yii mọ ni ookan àyà rẹ, o si dide ni kutukutu owurọ ọjọ keji, o si di kẹtẹkẹtẹ ni gaari, o mu meji ninu awọn ọdọmọkunrin rẹ, ati Isaaki ọmọ rẹ, ati igi fun “ẹbọ sisun”, o si mu ọna ilẹ Moria pọn. Irin ọjọ mẹta ni wọn rin; bi wọn si ti ri ibẹ ni okeere, o sọ fun awọn ọdọmọkunrin rẹ pe, “Ẹnyin joko nihin pẹlu kẹtẹkẹtẹ; ati emi ati ọmọ yi yio lọ si ọhùn nì, a o si gbadura, a o si tun pada tọ nyin wá.” Bi wọn ti n lọ Isaaki beere pe, “Wò iná on igi; ṣugbọn nibo li ọdọ-agutan ẹbọ sisun na gbé wà?” Baba rẹ dahùn pe, “Ọmọ mi, Ọlọrun tikalarẹ ni yio pèse ọdọ-agutan fun ẹbọ sisun.”

Asọtẹlẹ gidi ni awọn ọrọ wọnyii jẹ. “Ọlọrun tikalarẹ ni yio pèse ọdọ-agutan!” Boya Abrahamu ti ri Ileri ohun ti ọmọ rẹ ti yoo fi rubọ tọka si, tabi nipa iwaya-ija ti o wà ninu irin-ajo rẹ si oke Moria ni o fi mọ, a kò le sọ. Ṣugbọn ohun kan ni o mọ, eyi ni pe, Ọlọrun ti sọrọ “Bẹẹli awọn mejeji jùmọ nlọ.” O tẹ pẹpẹ kan. O to igi rere. “Abrahamu si nawọ rẹ, o si mu ọbẹ na lati dúmbu ọmọ rẹ,” nigba ti Angẹli Oluwa kọ si i lati Ọrun wa pe, “Abrahamu, Abrahamu”: “o si dahùn pe, Emi niyi. O si wipe, Máṣe fọwọkàn ọmọde nì, bẹẹni iwọ kò gbọdọ ṣe e ni nkan: nitori nisisiyi emi mọ pe iwọ bẹru Ọlọrun, nigbati iwọ kò ti dù mi li ọmọ rẹ, ọmọ rẹ na kan kanṣoṣo.” Abrahamu si gbé oju rẹ soke, si wo o, o ri agbo kan ti o fi iwo há pantiri: Abrahamu si lọ mu àgbò naa, o si fi i rubọ sisun dipo ọmọ rẹ -- ẹbọ irọpò.

Kò ṣẹṣẹ tun ni ki a sọ pe o mu Abrahamu lomi, lai si aniani o la irora nlá kọja ni mimu aṣẹ ti Ọlọrun fi fun un yii ṣẹ. Ohun ti o ṣọwọn fun un jù ni ayé yii ni Isaaki, ki i ṣe nitori Isaaki nikan ṣoṣo ni o bi nikan ṣugbọn ninu rẹ ni ireti gbe wà nipa ileri ti a ṣe pé awọn irú-ọmọ Abrahamu yoo pọ bi iyanrin eti òkun ati bi irawọ oju ọrun. Abrahamu, gẹgẹ bi awọn wolii ti igbà nì ri awọn ileri wọnyii ni okeere, ṣugbọn o mọ pe ni ọna iyanu kan, nnkan wọnyii fara kọ Eto Ọlọrun. Nisisiyii Ọlọrun ṣe tan lati fi awọn ohun ijinlẹ kan hàn nipa Majẹmu Ayeraye ti O bá Abrahamu dá yii. Nitori naa, nipa idanwo igbagbọ yii, a n fa Abrahamu, baba igbagbọ lati tubọ ba Ọlọrun rẹ rin timọtimọ. Ọlọrun ki i fi ijinlẹ iwa-bi-Ọlọrun kọ ni nipa ọgbọn ori, bi o tilẹ jẹ pe ọnà yii ni o wu eniyan. Ọnà ti Rẹ jinlẹ pupọ Oun a maa mu awọn ti Rẹ lọ lati ibu jinjin si ibi giga nipa idanwo gẹgẹ bi O ti ṣe pẹlu Jefta, Jobu ati Abrahamu – bi O si ti le ṣe pẹlu wa ni ọjọ kan. Ọlọrun, ni akoko yii, fọwọ le ohun ti o ṣọwọn fun ọkàn Abrahamu. Abrahamu si yeje. O fi ara rẹ han bi ẹni ti o le jẹ “onjẹ lile”, nipa bẹẹ, o di ohun elo ti o muna lọwọ Ọlọrun.

Majẹmu ti a fi Idi rẹ Mulẹ nipa Ibura

Nisisiyii, nipa Majẹmu ti a ri pe a ri i ṣipaya fun Abrahamu lẹsẹẹsẹ yii: “Angẹli OLUWA nì si kọ si Abrahamu lati Ọrun wá lẹrinkeji, O si wipe, Emi tikalami ni mo fi bura, li OLUWA wi, nitori bi iwọ ti ṣe nkan yi, ti iwọ kò si dù mi li ọmọ rẹ, ọmọ rẹ na kanṣoṣo”; awọn ọrọ wọnyii fi han ni bi Majẹmu ti Ọlọrun ba Abrahamu dá yii ti ni ọwọ to. Ọlọrun wi pe “Emi tikalami ni mo fi bura” nitori kò si ẹlomiran ti o pọ ju U lọ ti O tun le fi bura. Sakariah sọ asọtẹlẹ pe Ọlọrun ti boju wo awọn eniyan Rẹ lati ranti ara ti o ti bú fun Abrahamu. Nigba ti Apọsteli nì n ṣe alaye lori ọrọ yii, o sọ pe, “Nitori nigbati Ọlọrun ṣe ileri fun Abrahamu, bi kò ti ri ẹniti o pọju on lati fi bura, o fi ara rẹ bura, wipe, Nitõtọ ni bibukún emi o bukún fun ọ, ati ni bibisi emi o mu ọ bisi i. Bẹna si ni, lẹhin igbati o fi sũru duro, o ri ileri na gbà. Nitori enia a mā fi ẹniti o pọjù wọn bura: ibura na a si fi opin si gbogbo ijiyan wọn fun ifẹsẹ mulẹ ọrọ. Ninu eyiti bi Ọlọrun ti nfẹ gidigidi lati fi aileyipada imọ rẹ han fun awọn ajogún ileri, o fi ibura sārin wọn” (Heberu 6:13-17). Alaye kekere kan sọ fun ni pe itumọ awọn ọrọ diẹ ti o kẹyin yii ni pe, “O fi ibura dé ara Rẹ.”

Ni fifi ẹsẹ Majẹmu ti o ni ọwọ yii mulẹ, a ti ri i pe Ọlọrun ni o ṣiwaju iṣisẹ kọọkan. Ọlọrun ni Oludasilẹ rẹ lati ibẹrẹ de opin. Ọlọrun tikara Rẹ ni o ṣe gbogbo ileri ti o wà nibẹ. Ọpọlọpọ ileri bẹẹ si ni o wà ti ki i ṣe fun ire ati anfaani Abrahamu ati iru-ọmọ rẹ nikan, ṣugbọn Majẹmu naa gbooro to bẹẹ ti o wà fun “gbogbo idile aiye.” Ni opin ohun gbogbo, Ọlọrun, ninu Ẹni ti kò si ojiji iyipada, fi ibura dè ara Rẹ, nipasẹ awọn ileri wọnyii. Bayii ni a ri i pe a fi idaniloju si i pe gbogbo ileri ti o wà ninu Majẹmu yii ni a o mu ṣẹ patapata. Nihin yii ni a gbe ri Majẹmu kan eyi ti Ọlọrun fi idi rẹ mulẹ tikara Rẹ nipa ibura. Awọn ibomiran ninu Bibeli yoo fi hàn fun ni bi Ọlọrun ṣe n mu awọn ileri ologo ti O ti ṣe ṣẹ ni ẹsẹẹsẹ.

Ohun miiran pataki ti o wà ninu Majẹmu yii ni àyè ti Abrahamu yoo wà nipa igbekalẹ Majẹmu naa. Ninu adehun laaarin awọn eniyan, majẹmu naa yoo kó ipa kan, awọn ti o dá majẹmu yoo kó ipa keji. Ṣugbọn o dabi ẹni pe Abrahamu wà ni ipa kan naa pẹlu majẹmu naa gan an lati igba ipè rẹ titi de akoko ti a yiiri igbagbọ rẹ wò yii. Idanwo nla ti Abrahamu là kọja yii tayọ iriri ti Abrahamu ni nipasẹ rẹ. Idanwo yii ni o fa ibura ti a fi fi ẹsẹ Majẹmu yii mulẹ. Ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun yii si pari pẹlu ọrọ wọnyii: “Ati ninu irú-ọmọ rẹ li a o bukún fun gbogbo orilẹ-ède aiye: nitori ti iwọ gbà ohùn mi gbọ.”

Ohun ti o tobi ti o si ni ọwọ ni ki eniyan, erupẹ ilẹ, bá Ọlọrun Ọga-Ogo ju lọ dá majẹmu. Ẹjẹ mimọ ni o jẹ, o si fi ohun kan naa ti o de Abrahamu de ara rẹ -- eyi yii ni igbọràn pipe si Ọlọrun ayeraye. Nipa bayii ni oun yoo ri imuṣẹ ileri Ọlọrun.

O ti ranti majẹmu rẹ lailai, ọrọ ti o ti pa li aṣẹ fun ẹgbẹrun iran.

Majẹmu ti o ba Abrahamu dá, ati ibura rẹ fun Isaaki;

O si gbé eyi na kalẹ li ofin fun Jakọbu, ati fun Israẹli ni majẹmu aiyeraiye” (Orin Dafidi 105:8-10).