Jeremiah 32:37-42; Romu 4:9-16; Heberu 8:6-13

Lesson 159 - Junior

Memory Verse
“Nitori eyi li o ṣe jẹ alarina majẹmu titun, pe bi ikú ti mbẹ fun idande awọn irekọja ti o ti wà labẹ majẹmu iṣaju, ki awọn ti a ti pè le ri ileri ogún ainipẹkun gbà” (Heberu 9:15).
Notes

Ṣugbọn nisisiyi o ti gbà iṣẹ iranṣẹ ti o ni ọlá jù, niwọn bi o ti jẹ pe alarina majẹmu ti o dara jù ni iṣe, eyiti a fi ṣe ofin lori ileri ti o sàn jù bẹẹ lọ.

Nitori ibaṣepe majẹmu iṣaju ni kò li àbuku, njẹ a ki ba ti wá àye fun ekeji.

Nitori o ri àbuku lara wọn, o wipe, Kiyesi i, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o bá ile Israẹli ati le Juda dá majẹmu titun.

Ki iṣe gẹgẹ bi majẹmu ti mo ti bá awọn baba wọn dá, li ọjọ na ti mo fà wọn lọwọ lati mu wọn jade kuro ni ilẹ Egipti; nitoriti nwọn kò duro ninu majẹmu mi, emi kò si kà wọn si, ni Oluwa wi.

Nitori eyi ni majẹmu ti emi ó ba ile Israẹli dá lẹhin ọjọ wọnni, li Oluwa wi; Emi ó fi ofin mi si inu wọn, emi o si kọ wọn si ọkàn wọn: emi o si mā jẹ Ọlọrun fun wọn, nwọn o si mā jẹ enia fun mi:

Olukuluku ki yio si mā kọ ara ilu rẹ ati olukuluku arakọnrin rẹ wipe, Mọ Oluwa: nitoripe gbogbo wọn ni yio mọ mi, lati kekere de àgba.

Nitoripe emi o ṣanu fun aiṣododo wọn, ati ẹṣẹ wọn ati aiṣedede wọn li emi ki yio si ranti mọ.

Li eyi ti o wipe, majẹmu titun, o ti sọ ti iṣaju di ti lailai. Ṣugbọn eyi ti o ndi ti lailai ti o si ngbó, o mura ati di asan” (Heberu 8:6-13).

Eto Pipe Ọlọrun

Eto Irapada, nigba ti a ṣi i paya lẹsẹẹsẹ niwaju wa, jẹ iyanu ti kò lẹgbẹ. Ibalo Ọlọrun pẹlu awọn eniyan aye ni ṣisẹ-n-tẹle, ki wọn ba le mọ Ọn ni Ọlọrun ati Baba wọn, fi aanu ati ifẹ hàn, eyi ti o ṣe pe Ọlọrun ayeraye nikan ṣoṣo ni O ni irú rẹ. O ṣoro fun awọn Ọmọ Israẹli, paapaa ju lọ ni ikẹhin igbesi aye wọn bi orilẹ-ède, lati mọ pe Ọlọrun wọn, Oluwa Jehofa jẹ Ọlọrun gbogbo agbaye – ati pe Oun ki i ṣe ojusaju eniyan (Iṣe awọn Apọsteli 10:34). Ọpọlọpọ awọn Farisi ati diẹ ninu awọn Onigbagbọ ni akoko awọn awọn Apọsteli ni èro pe igbala jẹ ti awọn Ju ati pe o wà fun Ju nikan. Wọn a maa wo awọn eniyan orilẹ-ède Keferi bi abọriṣa ti kò ni ireti ninu aye yi ati ninu aye ti n bọ.

Ni ibẹrẹ pẹpẹ nigba ti eniyan ṣubu, Ọlọrun ṣe ileri Oludande. A ri i idaju pe ileri yi wà fun gbogbo eniyan. Awọn Ọmọ Israẹli tọsẹ ibẹrẹ iran wọn de ọdọ Abrahamu, wọn si n pe ara wọn ni ọmọ Abrahamu (Johannu 8:39; Iṣe Awọn Apọsteli 4:12; 9:7); nitori naa, awọn ileri fun Oludande ati Olurapda ti o ṣiwaju awọn eyi ti a fi fun Abrahamu ni lati jẹ ti gbogbo eniyan lai si iyemeji tabi ijiyan rara. Sibẹsibẹ, a kò fẹ sọ nipa eyi pe awọn ileri ti a ṣe fun Abrahamu, tabi eyi ti a fi fun ni lati igba Abrahamu jẹ ti awọn Ju nikan. Awọn ẹkọ wa ti a ti ṣe nipa awọn Majẹmu ti a dá pẹlu Abrahamu ati awọn Ọmọ Israẹli fi idi otitọ yi mulẹ daradara. “Ninu rẹ li a o ti bukun fun gbogbo idile aiye” ni Majẹmu – ileri ti a fi fun Abrahmu (Gẹnẹsisi 12:3).

Lati ipilẹṣẹ aye ni a ti pa Kristi (I Peteru 1:20; Ifihan 13:8) ki gbogbo eniyan le tọ Ọ wa. A ti ri i pe Ẹbọ pipe ti O rú kò ni odiwọn niwọn igba ti o jẹ pe nitori itoye Rẹ ati nipa ẹbọ ti O ru, gẹgẹ bi irú Abrahamu, ni a o ti “bukun fun gbogbo idile aiye” (Gẹnẹsisi 12:3). A ri i pe eyi ti awọn ti wọn ti wà ṣiwaju Abrahamu ati awọn ti wọn tun wà lẹhin rẹ. Eyi kan Ju ati Keferi, ẹrú ati ominira, ọlọrọ ati talaka; nitori pe ninu Ẹni ti “gbogbo ẹkún Iwa-Ọlọrun ngbé li ara-iyara” ni “ohun gbogbo, ninu ohun gbogbo” (Kolosse 2:9; 3:11). Nigba ti a si ti ri eyi, a le lọ jinna ninu Eto nla Ọlọrun lati ri ati lati ṣe aṣaro lori ipese ti kò lẹgbẹ ti o wà nibẹ fun irapada gbogbo ẹda.

Awọn Iṣẹlẹ Ti O pilẹ Majẹmu Titun

Majẹmu Titun jẹ ohun ijinlẹ si awọn ẹlomiran. Ṣugbọn ki i ṣe eyi ti a kò le mọ. Ọna Ọlọrun rọrun lati yé ni lọna gbogbo ti o jẹ mọ ti igbala ọkàn wa (Isaiah 35:8). Lootọ nigba miran Ọlọrun le ṣi awọn ohun ijnlẹ diẹ paya fun wa ninu Ọrọ Rẹ, ti yoo yà wa lẹnu, ṣugbọn awọn otitọ naa, lati ipilẹṣẹ, rọrun lati yé ni bi ọrọ ipe Ihinrere ti o lọ bayi pe, “eniti o ba fẹ le wa.” Akiyesi Eto Ọlọrun ni apapọ le ṣe iranlọwọ lati fi oye ye ẹni ti oye kò ba yé to nipa ọran yi.

Awamaridi ọgbọn Ọlọrun -- imọtẹlẹ Rẹ -- ni o fi hàn pe a ni lati ni Olurapada ki a to tilẹ dá aye. O fun ọmọ-eniyanni ifẹ (agbara) lati da yàn tikara rẹ -- agbara lati yan rere tabi buburu -- kò si si ohun ti o le du ọmọ eniyan ni anfaani yi lati yan ohun ti o ba fẹ. Ọlọrun tikara Rẹ kò le yi i pada. Eniyan jẹ olu ni ọna kan ṣoṣo yi. Idanwo de; eniyan jọgọ silẹ, o si dẹṣẹ; nipa bẹẹ o ti gbogbo ẹda eniyan sinu ẹṣẹ. Ọlọrun ṣe ileri Olurapada yi lẹsẹkẹsẹ ti a fi yé eniyan yekeyeke idi rẹ ti o ni lati ni Olurapada (Gẹnẹsisi 3:15). Kò le ṣe e ṣe ki a ti ṣe ileri yi ṣiwaju akoko naa. Kò si ironu tabi àbá ninu ọkàn eniyan lati ni Olurapada nigba ti ẹṣẹ, ẹgún, ati ikú kò ti i si. Lati igba naa lọ, ni a ti n ba eto yi bọ lẹsẹẹsẹ.

Awọn eniyan kan ba Ọlọrun rin ti wọn si wu U ni igba nì lẹhin iṣubu ti o mu ki a ṣe ileri Messia (Gẹnẹsisi 5:21-24; Heberu 11:5,6). A ṣe awọn eniyan kan pé ki a tilẹ to gbe Isin Agọ kalẹ (Gẹnẹsisi 6:9). Ọlọrun ba awọn eniyan sọrọ (Gẹnẹsisi 7:13-21; 9:8-17). A le ri i pẹlu pe O ba wọn dá majẹmu. O sọ ifẹ ati idajọ Rẹ di mimọ. Awọn olododo eniyan wà ni ọjọ wọnni (Heberu 11:4). A tilẹ pe ẹni kan ni “Ọrẹ Ọlọrun” (Jakọbu 2:23).

Awọn wọnyi ati ohun miran gbogbo fi hàn wa dajudaju pe awọn eniyan ni idalare ati isọdi-mimọ ni ọjọ wọnni. Lai si aniani, akọsilẹ igbesi aye wọn wà fun wa gẹgẹ bi apẹẹrẹ iwa-bi- Ọlọrun, eyi ti o ṣe e ṣe nipa igbagbọ ninu Ọlọrun Ọrọ naa, ati igbagbọ ninu Ọrọ Ọlọrun wọn.

Ni akoko naa, igba pupọ wà ti kò si “iran” (I Samuẹli 3:1). Akoko wà ti o ṣe pe iná ẹmi awọn ti o yẹ ki wọ mọ Ọlọrun kò jo geere mọ (I Awọn Ọba 19:10). Akoko si wà ti o jẹ pe iwa buburu ati ẹṣẹ gbilẹ to bẹẹ ti kò si iru rẹ afi ni ikẹhin ọjọ wọnyi (Gẹnẹsisi 6:5-7; Matteu 24:37,38). Ṣugbọn sibẹsibẹ awọn kan wà -- awọn “agbo kekere”, -- ti wọn ri oore-ọfẹ ni oju Oluwa (Gẹnẹsisi 6:8), bakan naa ni o ri, lai fi gbogbo ifasẹhin pè, iṣipaya ifẹ mimọ olọrun ati Ọrọ Rẹ n hàn siwaju ati siwaju.

A ri i pe Ọlọrun ti ri Abrahamu pe o jẹ ẹni ti Oun le fọkan tan. O yiiri ọgbẹni yi wò gidigidi, O si mu ki o fi ara rẹ rubọ patapata lati fi hàn bi ifẹ ati igbẹkẹle ti ọmọ eniyan le ni si Ọlọrun rẹ ti le pọ to (Gẹnẹsisi 22:12; Heberu 11:8-10, 17-19). Laarin Ọlọrun tikara Rẹ ati eniyan Ọlọrun yi ni a gbe majẹmu kan kalẹ, nipa eyi ti a ti kọ ẹkọ ni ibẹrẹ iwe yi. A ṣe akiyesi pe Majẹmu ti Ọlọrun ba Abrahamu dá yi ni ileri nla kan ninu fun gbogbo idile aye. Awa ti igbẹhin aye de ba le ri i ni iwọnba ohun ti o wà ninu ileri yi; a si tun le fi oju ẹmi wo o de aye kan bi ileri yi ti jinlẹ, ti o si gboorò to.

Ohun ti o tẹle e ni Majẹmu ti Ọlọrun ba Israẹli dá. Ifẹ Ọlọrun ni pe ki Israẹli jẹ “ijọba alufa, ati orilẹ-ède mimọ” (Ẹksodu 19:6), ki wọn si jẹ “iṣura iyebiye” fun Un (Ẹksodu 19:5), ati ohun elo nipasẹ ẹni ti Eto Majẹmu Rẹ yoo ṣẹ ti yoo si di mimọ fun gbogbo eniyan (Iṣe Awọn Apọseli 7:38; Romu 3:2). Wọn yoo jẹ orilẹ-ède momọ, aṣoju Ọlọrun ninu aye ẹṣẹ yi. Ọlọrrun fẹ ki o jẹ pe nipasẹ wọn ni Ọrọ Rẹ yoo di mimọ fun araye. Nipasẹ ibi Olugbala lati inu ẹni kan ninu idile wọn, ni a o mu ileri Ọlọrun ṣẹ le wọn lori.

Ṣugbọn wọn kuna patapata ninu ipe Ọlọrun! O fẹrẹ jẹ pe ki ọrọ wọnyi pe “Ohun gbogbo ti OLUWA wi li awa o ṣe” to jade li ẹnu wọn tan, ti ogo mimọ Ọlọrun si fara hàn ni wọn tun kigbe wi pé, “ki Ọlọrun maṣe ba wa sọrọ,” wọn si fa sẹhin kuro ni ayè ati ipo ti Ọlọrun pe wọn si. Wọn fẹrẹ ma ti i fi ọwọ si adehùn Majẹmu ti Ọlọrun ba wọn dá tan ti wọn ti yan ẹgbọrọ malu, ere ti wọn fi ọwọ ara wọn yá, dipo Jehofa Ọlọrun wọn (Ẹksodu 24:3-7; 32:1,4).

Ọlọrun ti sọ Ọrọ Rẹ -- Majẹmu Rẹ pẹlu Abrahamu – O si ti fi idi rẹ mulẹ nipa ibura. Oun yoo mu Majẹmu yi ṣẹ ani bi o tilẹ ṣe e ṣe pe ki O pa odindi orilẹ-ède kan run ni aginju ki O si gbe orilẹ-ède miran dide lati inu iru ọmọ Mose, olubẹbẹ ati ẹni bi ti inuỌlọrun. Oun le ṣe eyi lai ba Majẹmu ti O ba Abrahamu dá jẹ (Ẹksodu 32:10). Messia kò le ṣai wá. Olurapada ni lati san gbese fun igbala araye. Ọlọrun ti ṣeleri, Olugbala naa yoo si wá lai fi ti ifasẹhin awọn eniyan ti a ti yàn pè. Bi wọn ba kùna gẹgẹ bi orilẹ-ède, wọn o padanu ogún ati èrè ayeraye ti i ṣe ti wọn, bi o tilẹ jẹ pe imọlẹ Ọlọrun yoo maa tan ni gbogbo ọjọ aye wọn nipasẹ ijolootọ awọn eniyan diẹ ti o mu ipa ti i ṣe ti ẹni kọọkan ṣẹ ninu majẹmu – ileri naa.

Laarin ọkẹ aimọye Ju ti a o bi, ogunlọgọ ninu wọn ni kò ni tẹ eekun wọn ba fun Baali tabi ki wọn fi ẹnu ko ère rẹ lẹnu. Awọn eniyan Ọlọrun yoo wa ti kì yoo naani alaiwa-bi-Ọlọrun ayaba ti yoo si pa awọn woli Ọlọrun mọ ki a ba le dá ẹmi awọn eniyan Ọlọrun wọnyi si. Bakan naa ni kò le ṣe alai si awọn olootọ bi Joṣua ati Kalẹbu, akin ti yoo mu “ẹri rere” pada wa nigba ti awọn miran kò gba Ọlọrun gbọ ti wọn si ṣọtẹ si aṣẹ Rẹ. Bakan naa ni ọmọde kekere kan yoo wà ti yoo le gbọ ohun Ọlọrun nigba ti “ifihan ko pọ” ti yoo si wa di onidajọ ni Israẹli ni akoko rogbodiyan wọn. Awọn miran yoo wa pẹlu ti a o gbe dide lati wà ni ipo ọlá ati aṣẹ, ti yoo pa isin ibọriṣa ti wọn mu wá lati orilẹ-ède ti o yi wọn ka, ti wọn yoo si mu isin Jehofa pada bọ si aye rẹ. Majẹmu Ọlọrun kò le ṣe alai ṣẹ. Aye ati Ọrun yoo kọja lọ ki kinnkinni ninu rẹ ko to le lọ lai ṣẹ!

Majẹmu Titun

Gẹgẹ bi orilẹ-ède, Israẹli fa sẹhin. Ofin Ọlọrun ti a ba ti kọ si wọn lọkàn ni Sinai, gẹgẹ bi orilẹ-ède ni a kò kọ si ọkàn wọn. Ẹni kọọkan ri ibukun yi gba ṣugbọn orilẹ-ède yi kùnà patapata “lati wá si iranwọlọ Oluwa,” wọn si yi pada lati ma a tọ Ọ lẹhin. A o ri ibi ti o de ba wọn bi a ti n ba ẹkọ wa yi lọ, lai tilẹ sọ ohun ti o ṣi n bọ wa ba wọn nigbooṣe. Ifasẹhin ati iṣọtẹ wọn mu ki a tú wọn ka ki a si jẹ wọn niyà ti a kò fi iru rẹ jẹ ẹnikẹni laye yi ri. Wọn jiya pọ ju bi ẹnu ti le sọ lọ, wọn wà ninu ipọnju lati igba ti wọn ti kọ Ẹni ti o wá lati mu ileri Ọlọrun ṣẹ fun wọn ati gbogbo agbaye.

Ọlọrun kò gbagbe Majẹmu Rẹ pẹlu Abrahamu, Isaaki ati Jakọbu. Ọlọrun kò ti i gbagbe pe Israẹli, nipa ipe, ijẹ ayanfẹ Rẹ. O n ṣafẹri wọn bi baba ti n ṣafẹri ọmọ rẹ (Jeremiah 31:9). O n fi okùn ifẹ fà wọn. O n rọ wọn jẹjẹ, bi Baba ayeraye ti n ṣe fun ọmọ ti kò gbọran. O n ba wọn wi ninu aanu Rẹ fun wọn, ati nitori pe o ranti Majẹmu Rẹ pẹlu awọn baba wọn; O n ṣe eyi lati mu wọn pada sọdọ ara Rẹ.

Nihin yi, awamaridi ọgbọn – tabi imọtẹlẹ -- Ọlọrun tun fara hàn. Ninu awọn asọtẹlẹ, O ba ni sọrọ O si wi pe nipa ibawi ati ipọnju wọnyi, diẹ ninu awọn orilẹ-ède yi yoo wo Ẹni ti wọn gun ni ọkọ, wọn yoo si gba A ni Olukọni ati Oluwa, (Sekariah 12:10; 14:16-21). Ọlọrun mọ ẹhin ọla, nipa bẹẹ O mọ pe nipa ifarada ati suuru Rẹ, a o gba apakan ninu wọn là. Ọlọrun ti sọ fun ni pe Oun yoo ba awọn wọnyi ti a o gbala dá Majẹmu ayeraye, wọn ki yoo si ya kur lọdọ Oun titi laelae. A o mu wọn pada si ilẹ wọn -- Ilẹ Ileri -- nibẹ ni wọn yoo gbe gba Jesu ni Messia wọn, wọn o si di eniyan Ọlọrun, Oun yoo si jẹ Ọlọrun wọn.

Wò o, emi o kó wọn (Israẹli) jọ lati gbogbo ilẹ jade, nibiti emi le wọn si ninu ibinu mi, ati ninu irunu mi, ati ninu ikannu nla; emi o si jẹ ki nwọn ki o mā gbe lailewu:

Nwọn o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn.

Emi o si fun wọn li ọkàn kan, ati ọna kan, ki nwọn ki o le bẹru mi li ọjọ gbogbo, fun rere wọn, ati ti awọn ọmọ wọn lẹhin wọn:

Emi o si ba wọn dá majẹmu aiyeraiye, pe emi ki o yipada lẹhin wọn lati ṣe wọn ni rere, emi o fi ibẹru mi si ọkàn wọn, ti nwọn ki o lọ kuro lọdọ mi.

Lõtọ, emi o yọ lori wọn lati ṣe wọn ni rere, emi o si gbìn wọn si ilẹ yi li otitọ tinutinu mi ati tọkàntọkàn mi.

Nitori bayi li OLUWA wi; Gẹgẹ bi emi ti mu gbogbo ibi nla yi wá sori awọn enia yi, bẹẹni emi o mu gbogbo rere ti emi ti sọ nipa ti wọn wá sori wọn” (Jeremiah 32:37-42).

Awọn wọnyi, apakan ti o kù ni Israẹli – ni Ọlọrun n sọ nipa rẹ nigba ti o wi pe: “Emi o fi ofin mi si inu wọn, emi o si kọ ọ si aiya wọn; emi o si jẹ Ọlọrun wọn, awọn o si jẹ enia mi … gbogbo nwọn ni yio mọ mi, lati ẹni-kekere wọn de ẹni-nla wọn, li OLUWA wi; nitori emi o dari aiṣedede wọn ji, emi ki o si ranti ẹṣẹ wọn mọ” (Jeremiah 31:33,34). Nipa awọn wọnyi ni Balaamu sọtẹlẹ nipa imisi Ẹmi Mimọ wi pe: “Awọn enia yi yio dágbé, a ki yio si kà wọn kún awọn orilẹ-ède … ki igbẹhin mi ki o si dabi tirẹ (Igbẹhin)!” (Numeri 23:9,10). Nipa wọn ni Mose sọtẹlẹ pe, “Israẹli si joko li alafia, orisun Jakọbu nikan, ni ilẹ ọkà ati ti ọti waini; pẹlupẹlu ọrun rẹ nsẹ iri silẹ. Alafia ni fun iwọ, Israẹli: tali o dabi rẹ, iwọ enia ti a ti ọwọ OLUWA gbàla” (Deuteronomi 33:28, 29). Wọn yoo gba irú igbala kan naa ti Abrahamu gbà ati ti ẹnikẹni ti o ba ronupiwada tootọ n ri gbà nigba ti ó ba wá pẹlu igbagbọ, ti ó jẹwọ ẹṣẹ rẹ ti o si wá iwà mimọ Ọlọrun.

Nigba ti Messia ba de ninu ogo iṣẹgun Rẹ gẹgẹ bi Ọba Ayeraye, nigba naa Israẹli ti o jẹ alaigbagbọ, ẹni ti o ko Jesu ati akorira Ọlọrun tẹlẹ ri, ti wọn ti la Ipọnju Nla kọja, yoo wo Ẹni ti wọn gun un ni ọkọ, wọn yoo si yi pada si I pẹlu ironupiwada tootọ. Oun yoo gbà wọn la! Oun yoo si rà wọn pada! Oun yoo fun wọn ni gbogbo ibukún ti o wà ninu Majẹmu Ileri! Wọn o jẹ eniyan Rẹ, Oun yoo jẹ Ọlọrun wọn. Bi o tilẹ jẹ pe wọn ti sọnù fun ọpọlọpọ ọdun sẹhin nipa ipada-sẹhin, aigbọran ati iṣọtẹ si Ọlọrun, wọn o pada si àyè wọn. Nigbà naa a o kọ Ofin si ọkàn wọn, anfaani ologo ti o jẹ ti awọn Onigbagbọ ni gbogbo orilẹ-ède nipasẹ Ẹjẹ Etutu naa, ṣugbọn ti a fi du ainiye Israẹli nitori aigbagbọ wọn ati nitori pe wọn kọ Ẹni ti o mu idariji ati iwa mimọ wa. Nigba naa ni wọn yoo ri ibukun ti a ti ṣeleri ti a si n fi fun awọn ti o ba tọ Woli tootọ, Olori Alufa ati Ọba wa. Nigba naa ni wọn yoo di ọmọ Abrahamu nitootọ, bi awa ti a lọ mọ Ajara Tootọ nipasẹ Ẹjẹ Majẹmu Ayeraye, ti a si ni iriri idalare, isọdimimọ nipa agbara Ẹjẹ Isọnidimimọ ati Iwẹnumọ, ati Olutunu ti a fi fun ni.

Ibukún yi ha jẹ ti awọn akọla nikan ni, tabi ti awọn alaikọla pẹlu? Nitori a wipe, a kà igbagbọ fun Abrahamu si ododo.

Bawo li a ha kà a si i? Nigbati o wà ni ikọla tabi aikọla? Ki iṣe ni ikọla, ṣugbọn li aikọla ni.

O si gbà àmi ikọla, edidi ododo igbagbọ ti o ni nigbati o wà li aikọla: ki o le ṣe baba gbogbo awọn ti o gbagbọ, bi a kò tilẹ kọ wọn ni ilà; ki a le kà ododo si wọn pẹlu:

Ati baba ikọla fun awọn ti kò si ninu kiki awọn akọla nikan, ṣugbọn ti nrin pẹlu nipasẹ igbagbọ Abrahamu baba wa, ti o ni li aikọla.

Nitori ileri fun Abrahamu tabi fun irú-ọmọ rẹ pe, on ó ṣe arole aiye, ki iṣe nipa ofin, bikoṣe nipa ododo igbagbọ.

Nitori bi awọn ti nṣe ti ofin ba ṣe arole, igbagbọ di asan, ileri si di alailagbara:

Nitori ofin nṣiṣẹ ibinu: ṣugbọn nibiti ofin kò ba si, irufin kò si nibẹ.

Nitorina li o fi ṣe ti ipa igbagbọ, ki o le ṣe ti ipa ore-ọfẹ; ki ileri ki o le da gbogbo irú-ọmọ loju; ki iṣe awọn ti ipa ofin nikan, ṣugbọn ati fun awon ti inu igbagbọ Abrahamu pẹlu, ẹniti iṣe baba gbogbo wa” (Romu 4:9-16).

Ha ọjọ ayọ! Gbogbo aye ni n kerora ti wọn si n wọna fun afẹmọjumọ rẹ! Ohun iyanu ni yoo ṣẹlẹ nigba ti awọn Ju ba ke pe Messia wọn ti Oun si gbà wọn! Ọwọ Ọlọrun wà lara awọn Ju loni. Oun kò ti i kọ awọn eniyan Rẹ ti O ti mọ tẹlẹ silẹ (Romu 11:2). Ki i ṣe gbogbo orilẹ-ède Isaẹli ni ogba ohun ti wọn n lepa, bẹẹ ni ki i ṣe gbogbo wọn ni yoo gbà a; ṣugbọn awọn “ayanfẹ” -- awọn iyoku – ni yoo ri i gbà (Romu 11:7). Nipa iṣubu wọn, igbàla ọdọ awọn Keferi. Ọlọrun fi oju-rere wo awọn Keferi nitori pe Israẹli ti O yàn kùna lati ṣe ifẹ Rẹ (Romu 11:11). Nipa mimú wọn jowu, Ọlọrun n ru ifẹ wọn soke lati mu wọn pada sọdọ ara Rẹ. “Ṣugbọn bi iṣubu wọn ba di ọrọ aiye, ati ifasẹhin wọn ba di ọrọ awọn keferi: melomelo ni kikún wọn?” (Romu 11:12).

Awa Keferi ti o gba Ọba awọn ọba laye lati gúnwa ninu ọkàn wa, ni a fun ni anfaani lati jẹ alabapin Eto nla naa. Ọlọrun n ba wa lo lọna àrà, ki O ba le ba Israẹli lo. O ti fun wa ni ẹkún ibukun Rẹ, ohun ti awọn woli igba ni n foju sọna fun pẹlu iyanu ati ireti, eyi ti awọn angẹli paapaa fẹ lati wò (Matteu 13:17; I Peteru 1:9-12). A ti gba ohun ti Ọlọrun fẹ ki awọn ayanfẹ Rẹ ri gba, ki wọn ba le jẹ alufa tootọ fun gbogbo agbaye.

Ṣugbọn Ọlọrun n ba awọn Ọmọ Israẹli lo sibẹsibẹ, gẹgẹ bi a ti le ri i. Kò ṣe e ṣe ki a le fẹnu sọ nisinsinyi bi ọjọ ayọ naa yoo ti dùn to fun gbogbo ẹda nigba ti Oun yoo tun boju wo wọn ti Oun yoo si le pe wọn ni eniyan Rẹ lotitọ. Ọjọ yi ni a n lepa rẹ, oun ni a wà laaye fun, oun ni ireti wa. Ni ọjọ naa, egun kò ni si mọ, gbogbo ẹda yoo jumọ kọrin iyin si Olodumare, Ọlọrun onifẹ ati alaanu.

Nitori bi titanu wọn ba jẹ ilaja aiye, gbigbà wọn yio ha ti ri, bikoṣe iyè kuro ninu okú?” (Romu 11:15).