Lefitiku 26:32-39; Deuteronomi 28:1, 2, 63-68; 30:1-9; 31:14-30; Isaiah 11:11,12; 43:5-28; Matteu 24:30, 31

Lesson 161 - Junior

Memory Verse
“Nitori ọjọ pupọ li awọn ọmọ Israẹli yio gbe li aini ọba, ati li aini olori, ati li aini ẹbọ, li aini ere, ati li aini awò-aiyà, ati li aini tẹrafimu. Lẹhin na awọn ọmọ Israẹli yio padà, nwọn o si wá OLUWA Ọlọrun wọn, ati Dafidi ọba wọn; nwọn o si bẹru OLUWA, ati ore rẹ li ọjọ ikẹhin” (Hosea 3:4, 5).
Notes

Yio si ṣe, bi iwọ ba farabalẹ gbọ ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma kiyesi ati ṣe aṣẹ rẹ gbogbo ti mo pa fun ọ li oni, njẹ OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé ọ ga ju gbogbo orilẹ-ède aiye lọ:

Gbogbo ibukún wọnyi yio si ṣẹ sori rẹ, yio si bá ọ, bi iwọ ba fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ” (Dueteronomi 28:1, 2).

Ipadasẹhin

A ti mọ pe ibukún Ọlọrun ti O fẹ fun Israẹli ni ilẹ wọn rọ mọ pe ki wọn gbọran patapata. Wọn ni lati gbọran. Bi wọn ba gbọran, o daju pe wọn yoo ni ibukun. Bi wọn kò ba si gbọran wọn yoo ni ipọnju (Deuteronomi 28:63-68). Abọriṣa ni awọn orilẹ-ède ti o yi wọn ka, ṣugbọn Ọlọrun ti paṣẹ fun Israẹli pe wọn kò gbọdọ bọriṣa. Wọn kò gbọdọ gbagbe Ọlọrun ni akoko itura. Ninu ọjọ meje, a yọọda ọjọ mẹfa fun wọn. Ọjọ keje jẹ ti Ọlọrun. Wọn ni lati pa a mọ daradara.

OLUWA si sọ fun Mose pe, Kiyesi i, ọjọ rẹ sunmọ etile ti iwọ o kú: pe Joṣua, ki ẹ si fara nyin hàn ninu agọ ajọ, ki emi ki ole fi aṣẹ lé e lọwọ. Mose ati Joṣua si lọ, nwọn si fara wọn hàn ninu agọ ajọ.

OLUWA si yọ si wọn ninu agọ na ninu ọwọn awọsanma: ọwọn awọsanma na si duro loke ẹnu-ọna agọ na.

OLUWA si sọ fun Mose pe, Kiyesi i, iwọ o sùn pẹlu awọn baba rẹ; awọn enia yi yio si dide, nwọn o si ma ṣe àgbere tọ awọn oriṣa ilẹ na lẹhin, nibiti nwọn nlọ lati gbé inu wọn, nwọn o si kọ mi silẹ, nwọn o si da majẹmu mi ti mo bá wọn dá.

Nigbana ni ibinu mi yio rú si wọn li ọjọ na, emi o si kọ wọn silẹ, emi o si pa oju mi mọ kuro lara wọn, a o si jẹ wọn run, ati ibi pupọ ati iyọnu ni yio bá wọn; tobẹẹ ti nwọn o si wi li ọjọ na pe, Kò ha jẹ pe nitoriti Ọlọrun wa kò si lārin wa ni ibi yi wọnyi ṣe bá wa?

Emi o fi oju mi pamọ patapata li ọjọ na, nitori gbogbo iwa buburu ti nwọn o ti hù, nitori nwọn yipada si oriṣa.

Njẹ nisisiyi, kọwe orin yi fun ara nyin, ki ẹ fi kọ awọn ọmọ Israẹli: fi i si wọn li ẹnu, ki orin yi ki o le ma jẹ ẹri fun mi si awọn ọmọ Israẹli,

Nitoripe nigbati emi ba mú wọn wá si ilẹ na, ti mo bura fun awọn baba wọn, ilẹ ti nṣàn fun wàrà ati fun oyin; ti nwọn ba si jẹ ajẹyo tán, ti nwọn si sanra; nigbana ni nwọn o yipada si oriṣa, nwọn a si ma sin wọn, nwọn a si kẹgan mi, nwọn a si da majẹmu mi.

Yio si ṣe, nigbati ibi pupọ ati iyọnu ba bá wọn, ki orin yi ki o jẹri ti wọn bi ẹlẹri; nitoripe a ki yio gbagbè rẹ lati ẹnu awọn ọmọ wọn: nitori mo mọ iro inu wọn, ti nwọn nrò, ani nisisiyi, ki emi ki o to mú wọn wa sinu ilẹ na ti mo bura si.

Nitorina ni Mose ṣe kọwe orin yi li ọjọ na gan, o si fi kọ awọn ọmọ Israẹli.

O si paṣẹ fun Joṣua ọmọ Nuni, o si wipe, Ṣe giri, ki o mu aiya le: nitoripe iwọ ni yio mú awon ọmọ Israẹli lọ sinu ilẹ na ti mo bura fun wọn: Emi o si wà pẹlu rẹ.

O si ṣe, nigbati Mose pari kikọ ọrọ ofin yi tán sinu iwé, titi nwọn fi pari,

Mose si paṣẹ fun awọn ọmọ Lefi, ti nru apoti majẹmu OLUWA, wipe,

Gbà iwé ofin yi, ki o si fi i sapakan apoti majẹmu OLUWA Ọlọrun rẹ, ki o mā wà nibẹ fun ẹrí si ọ.

Nitoripe mo mọ ọtẹ rẹ, ati lile ọrún rẹ: kiyesi i, nigbati emi wà lāye sibẹ pẹlu nyin li oni, ọlọtẹ li ẹnyin ti nṣe si OLUWA: melomelo si ni lẹhin ikú mi?

Pe gbogbo awọn àgba ẹya nyin jọ sọdọ mi, ati awọn ijoye nyin, ki emi ki o le sọ ọrọ wọnyi li eti wọn, ki emi ki o si pe ọrun ati aiye jẹri ti wọn.

Nitori mo mọ pe lẹhin ikú mi ẹnyin o ba ara nyin jẹ patapata, ati pe ẹnyin o yipada kuro li ọna ti mo palaṣẹ fun nyin; ibi yio si bá nyin li ọjọ ikẹhin; nitoriti ẹnyin o ma ṣe buburu li oju OLUWA, lati fi iṣẹ ọwọ nyin mu u binu.

Mose si sọ ọrọ orin yi li eti gbogbo ijọ Israẹli, titi wọn fi pari” (Deuternomi 31:14-30).

Oluwa sọ fun Mose pe akoko ikú rẹ sunmọ tosi, O si paṣẹ fun un lati mú Joṣua pẹlu rẹ ki nwọn si fara hàn niwaju Oluwa ninu Agọ-ajọ, nibi ti a o gbe fi aṣẹ fun Joṣua gẹgẹ bi ẹni ti Oluwa ti yàn lati rọpo Mose (Deuteronomi 31:14). Oluwa si fara hàn ninu Agọ-ajọ ninu ọwọn awọsanma. O si kilọ fun Mose pe Israẹli yo fa sẹhin lẹhin ikú rẹ. Oluwa si tun sọ fun Mose pe, “Nitori mo mọ iro inu wọn, ti nwọn nrò, ani nisisiyi, ki emi ki o to mu wọn wá sinu ilẹ na ti mo bura si” (Deutoronomi 31:21).

Oye eniyan kuru pupọ lati mọ ohun ti yoo de bá ẹlẹgbẹ rẹ ni ẹhin ọla. Ohun ti o ṣẹlẹ ni atẹhinwa nikan ni o le fi ṣe odiwọn bi ọjọ iwaju wọn yoo ti ri. Ṣugbọn ti Oluwa kò ri bẹẹ; O mọ opin lati ibẹrẹ wá (Isaiah 4:9, 10). Ṣugbọn a kò yan an mọ awọn eniyan wọnyi lati maa huwa ẹṣẹ. Ọlọrun da eniyan O si fun un ni anfaani lati le dá yàn rere tabi buburu (Joṣua 24:15; Ifihan 22:17). Nigba pupọ ṣiwaju akoko yii, awọn eniyan wọnyi mọọmọ yàn lati ṣe ohun ti o yatọ si ifẹ Ọlọrun ti O ti fi hàn wọn. Wọn ti yan ipa ọna ti o wu wọn. Bi wọn ba si ti ṣe eyi, ti wọn ṣọtẹ si Mose nipa bẹẹ, ti wọn si ṣotẹ si Ọlọrun, ni kikùn, ni riráhùn ati ni titọ oriṣa lẹhin labẹ akoso Mose ti i ṣe alakoso ti o jafafa, alakoso ati oṣelu ti kò lẹgbẹ -- nigba naa a le beere wi pe: kin ni wọn o ha ṣe nigba ti o ba di oloogbe? Nipa imọtẹlẹ Ọlọrun, a fi ipada-sẹhin Israẹli hàn fun Mose,oun naa si ṣe ikilọ fun wọn, gẹgẹ bi a ti ri i kà ninu awọn ẹsẹ ọrọ Ọlọrun ti o wà loke ẹkọ yii.

Oluwa fi aṣẹ fun Mose lati tun kọ ikilọ ti a ti fi hàn tẹlẹ yii sinu iwe bi orin, gẹgẹ bi a ti le ri i ni Deutoronomi 32. Ọrọ Ọlọrun ti a ṣẹṣẹ kà tan yii ni ipilẹ ọrọ orin yii. Ki i ṣe pe Mose kàn kọ ọrọ orin ti Ọlọrun fi le e lọwọ yii nikan, ṣugbọn o ni lati fi kọ awọn Ọmọ Israẹli, wọn si ni lati kọ ọ sori. Orin yii, bi o ti n ti ọwọ baba de ti ọmọ, lati irandiran, yoo jẹ ẹri gbe wọn, yoo si jẹ ibawi fun wọn pẹlu fun ifasẹhin wọn. Orin apapọ orilẹ-ède kan jẹ iranti awọn ohun manigbabge ti o ti kọja sẹhin lọkan awọn eniyan, o si jẹ ọna pataki kan lati ba ọkàn awọn eniyan orilẹ-ède naa sọrọ.

Ìtúká

Emi o si sọ ilẹ na di ahoro: ẹnu yio si ya awọn ọtá nyin ti ngbé inu rẹ si i.

Emi o si tú nyin ká sinu awọn orilẹ-ède, emi o si yọ idà ti nyin lẹhin: ilẹ nyin yio si di ahoro, ati ilu nyin yio di ahoro.

Nigbana ni ilẹ na yio ni isimi rẹ, ni gbogbo ọjọ idahoro rẹ, ẹnyin o si wà ni ilẹ awọn ọtá nyin; nigbana ni ilẹ yio simi, ti yio ni isimi rẹ.

Ni gbogbo ọjọ idahoro rẹ ni yio ma simi; nitoripe on kò simi li ọjọ-isimi nyin, nigbati ẹnyin ngbé inu rẹ.

Ati lara awọn ti o kù lāye ninu nyin, li emi o rán ijaiya si ọkàn nwọn ni ilẹ awọn ọtá wọn: iró mimì ewé yio si ma lé wọn; nwọn o si sá, bi ẹni sá fun idà: nwọn o si ma ṣubu nigbati ẹnikan kò lepa

Nwọn o si ma ṣubulu ara wọn, bi ẹnipe niwaju idà, nigbati kò si ẹniti nlepa: ẹnyin ki yio si li agbara lati duro niwaju awọn ọtá nyin.

Ẹnyin o si ṣegbé ninu awọn orilẹ-ède, ilẹ awọn ọtá nyin yio si mú nyin jẹ.

Awọn ti o kù ninu nyin yio si joro ninu ẹṣẹ wọn ni ilẹ awọn ọtá nyin; ati nitori ẹṣẹ awọn baba wọn pẹlu ni nwọn o ma joro pẹlu wọn” (Lefitiku 26:36-39).

Yio si ṣe, bi OLUWA ti yọ sori nyin lati ṣe nyin ni ire, ati lati sọ nyin di pupọ; bẹẹni yio si yọ si nyin lori lati run nyin, ati lati pa nyin run; a o si fà nyin tu kuro lori ilẹ na ni ibi ti iwọ nlọ lati gbà a.

OLUWA yio si tu ọ ká sinu enia gbogbo, lati opin ilẹ dé opin ilẹ; nibẹ ni iwọ o si ma bọ oriṣa ti iwọ ati baba rẹ kò mọ ri, ani igi ati okuta.

Ati lārin orilẹ-ède wọnyi ni iwọki yio ri irọrun, bẹẹli atẹlẹsẹ rẹ ki yio ri isimi: ṣugbọn OLUWA yio fi iwarìri àiya, oju jijoro, ati ibinujẹ ọkàn fun ọ:

Ẹmi rẹ yio sorọ ni iyemeji li oju rẹ; iwọ o si ma bẹru li oru ati li ọsán, iwọ ki yio si ni idaniloju ẹmi rẹ.

Li owurọ iwọ o wipe, Alẹ iba jẹ lẹ! ati li alẹ, iwọ o wipe, ilẹ iba jẹ mọ! nitori ibẹru àiya rẹ ti iwọ o mā bẹru, ati nitori iran oju rẹ ti iwọ o ma ri.

Oluwa yio si fi ọkọ tun mú ọ pada lọ si Egipti, li ọna ti mo ti sọ fun ọ pe, Iwọ ki yio si tun ri i mọ: nibẹ li ẹnyin o si ma tà ara nyin fun awọn ọtá nyin li ẹrú ọkọnrin ati ẹrú obirin, ki yio si si ẹniti yio rà nyin” (Deuteronomi 28:63-68).

Asọtẹlẹ jẹ ifihàn ohun ti o n bọ ki ohun naa to ṣẹlẹ. Eyi ni asọtẹlẹ ipo oṣi ati ibanujẹ ti awọn Ju yoo wà. Akọsilẹ mejeeji wọnyi si jẹ otitọ to bẹ ti a fi le sọ itàn igbesi aye awọn eniyan wọnyi perepere, lati igba Mose titi di oni-oloni yi, nitori pe asọtẹlẹ wọnyi ṣẹ kinnikinni to bẹẹ ti wọn yi pada kuro ni asọtẹlẹ di itan nisinsinyi. Nihin yi, ni ẹgbẹẹgbẹrun ọdún sẹhin, Ọlọrun, nipasẹ Mose Woli Rẹ, n sọ itan igbesi aye awọn eniyan ti a tuká wọnyi, ati wahala pẹlu ipọnju wọn. Nihin ni otitọ yi pa alai gbagbọ lẹnu mọ. A sọ fun ni pe awọn Ju ati itan igbesi aye wọn, ipọnju ati wahala wọn ati bi a ti pa wọn mọ lọna iyanu jẹ ẹri ti o daju pe nipa imisi Ọlọrun ni a fi kọ Bibeli. Orin Dafidi 106 sọ nipa iṣọtẹ Israẹli ati aanu Ọlọrun. O sọ nipa ẹṣẹ, ikoro ati ipọnju ti o ba awọn eniyan wọnyi gẹgẹ bi ijiya ti o jẹ apa kan eto ituka ati inilara ti yoo de ba wọn.

Ninu Deuteronomi 28:49-57, a ri asọtẹlẹ ti o daju nipa ijọba Romu, ti a o fi ṣe ohun-elo lati tú awọn Ju ká ni nkan bi irinwo-din-lẹgbaa (1,600) ọdún lẹhin asọtẹlẹ yi, bi wọn ba takú sinu aigbọran sibẹ. A ti sọ asọtẹlẹ yi nigba ti ijọba Romu kò si rara. “OLUWA yio gbé orilẹ-ède kan dide si ọ lati ọna jijin, lati opin ilẹ wa bi idi ti ifo: orilẹ-ède ti iwọ ki yio gbọ ède rẹ” (Deuteronomi 28:49). Awòran ẹyẹ idi ni o wà lori ọpagun awọn ẹgbẹ ọmọ-ogun ti ilu Romu. Ọpọlọpọ ède awọn orilẹ-ède igbà ni ni awọn Ju gbọ, ṣugbọn a sọ fun ni pe wọn kò gbọ ède awọn ara Romu.

Iwe itan sọ fun pe a mu apa ibi yi ninu Iwe Mimọ ṣẹ kinnikinni nigbà ti Titu, ọgagun Romu gbogun ti Jerusalẹmu ti o si bi i wo ni n kan bi aadọrin (70 A.D.) ọdun lẹhin ti a bi Jesu Kristi; eyi ni o pilẹ ituka awọn Ju kaakiri gbogbo agbaye. Ìtúká yi n lọ bẹẹ lati bi ẹẹdẹgbẹwa (1900) ọdun sẹhin o si wa bẹẹ titi di isinsinyi. Ni ọdun diẹ ṣiwaju ituká yi, awọn Ju ti kọ Olugbala wọn, wọn si kan An mọ agbelebu, nipa bẹẹ ago ẹṣẹ wọn kun bamubamu, o si kún akúnwọsilẹ. Jesu sọtẹlẹ nipa akoko yi nigba ti O wipe: “Nwọn o si ti oju idà ṣubu, a o si di wọn ni igbekun lọ si orilẹ-ède gbogbo. Jerusalẹmu yio si di itẹmọlẹ li ẹsẹ awọn Keferi, titi akoko awọn Keferi yio fi kún” (Luku21:24). A sọ fun ni pe ni Jerusalẹmu nikan, ọkẹ marundinlọgọta (1,100,000) eniyan ni wọn kú nipa idà, iyàn, ati ajakalẹ-arun laarin oṣu mẹfa ti a gbogun ti wọn yi, o si fẹrẹ jẹ pe akoko yi ni ẹmi ọmọ-eniyan ṣofo lọpọlọpọ ju eyikeyi ti iwe itan kọ silẹ. Nibomiran ni Ilẹ Mimọ yi, ogunlọgọ eniyan ni wọn ṣegbe, a si fi ẹgbaagbeje ṣowọ si Egipti lati lọ sinru.

A gbọdọ ranti ẹni ti o tú awọn eniyan wọnyi ka kaakiri. Gbogbo inu Iwe Mimọ ni a gbe le ri i pe Oluwa tikara Rẹ ni O tú wọn ká. (Awọn ibomiran ninu Iwe Mimọ ti o ṣotẹlẹ nipa ituka awọn Ju ti a tú kaakiri gbogbo agbaye titi di ọjọ oni ni wọnyi: Deuteronomi 32:26; Isaiah 18:7; Jeremiah 24:9; Esekiẹli 22:15; Amosi 9:9; Sekariah 7:14; Matteu 24:9; Johannu 7:35; Iṣe Awọn Apọsteli 2:5; Romu 11:1, 20, 25).

Imupada

Nipa imisi Ọlọrun, Mose ti sọ awọn ègún ti yoo wá sori awọn Ọmọ Israẹli tẹlẹ ati ituká wọn kaakiri gbogbo agbaye. Gẹrẹ lẹhin eyi Ọlọrun tun rán an ni iṣẹ miran, ti o yatọ. Iṣẹ ti Ọlọrun ran an yi ni ipilẹṣẹ awọn asọtẹlẹ miran nipa akoko ologo ti yoo jẹ ti Israẹli nigbooṣe. Ikolọ ti a tọka si nibi yi ki i ṣe eyi ti a kó wọn lọ si Babiloni fun aadọrin ọdun pere, lẹhin eyi ti awọn diẹ pada sile. Bakan naa ni ki i ṣe nipa ikolọ awọn ẹya mẹwa. Ituká ti eyi n tọka si ni eyi ti Oluwa wa sọ nipa rẹ ninu Luku 21:24 ti a ti tọka si tẹlẹ.

Yio si ṣe, nigbati gbogbo nkan wọnyi ba dé bá ọ, ibukún ati egún, ti mo filelẹ niwaju rẹ, ti iwọ ba si ranti ninu gbogbo orilẹ-ède, nibiti OLUWA Ọlọrun rẹ ti tu ọ ká si.

Ti iwọ ba si yipada si OLUWA Ọlọrun rẹ, ti iwọ ba si gbà ohùn rẹ gbọ, gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo filelẹ li aṣẹ fun li oni, iwọ ati awọn ọmọ rẹ, pẹlu àiya rẹ gbogbo, ati pẹlu ọkàn rẹ gbogbo;

Nigban na OLUWA Ọlọrun rẹ yio yi oko-ẹrú rẹ pada, yio si ṣānu fun ọ, yio si pada, yio si kó ọ jọ kuro ninu gbogbo orilẹ-ède wọnni nibiti OLUWA Ọlọrun rẹ ti tu ọ ká si.

Bi a ba si lé ẹni rẹ kan lọ si iha opin ọrun, lati ibẹ ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio kó ọ jọ, lati ibẹ ni yio si mú ọ wá:

OLUWA Ọlọrun rẹ yio si mú ọ wá sinu ilẹ na ti awọn baba rẹ ti ni, iwọ o si ni i; on o si ṣe ọ li ore, yio si mu ọ bi si i ju awọn baba rẹ lọ.

OLUWA Ọlọrun rẹ yio si kọ àiya rẹ nilà, ati àiya irú-ọmọ rẹ, lati ma fẹ OLUWA Ọlọrun rẹ pẹlu àiya rẹ gbogbo, ati pẹlu ọkàn rẹ gbogbo, ki iwọ ki o le yè.

OLUWA Ọlọrun rẹ yio si fi gbogbo egún wọnyi lé awọn ọtá rẹ lori, ati lori awọn ti o korira rẹ, ti nṣe inunibini si ọ:

Iwọ o si pada, iwọ o si gbà ohùn OLUWA gbọ, iwọ o si ma ṣe gbogbo ofin rẹ ti mo palaṣẹ fun ọ li oni.

OLUWA Ọlọrun rẹ yio si sọ ọ di pupọ ninu gbogbo iṣẹ ọwọ rẹ, ninu ọmọ inu rẹ, ati ninu ohunọsin rẹ, ati ninu eso ilẹ rẹ, fun rere: nitoriti OLUWA yio pada wa yọ sori rẹ fun rere, bi o ti yọ sori awọn baba rẹ” (Deuteronomi 30:1-9).

Loni a n ri apa kan imupada bọ sipo awọn eniyan ti Ọlọrun ti yanfẹ lati ayebaye yi. Ṣugbọn sibẹsibẹ wọn n pada si ilẹ wọn ninu aigbagbọ. Oju wọn yoo wo Jesu, bi Olugbala wọn, nigba ti O ba fara hàn ni igba Ifihan, gẹgẹ bi Ẹni ti wọn gún li ọko (Ifihan 1:7). Wọn yoo yi pada kuro ninu aigbagbọ wọn, a o si gbà wọn là: “Emi o si tú ẹmi ore-ọfẹ ati ẹbẹ sori ile Dafidi ati sori Jerusalẹmu: nwọn o si ma wò mi ẹniti nwọn ti gún li ọkọ, nwọn o si ma ṣọfọ rẹ, gẹgẹ bi enia ti nṣọfọ fun ọmọ ọkọnrin rẹ, kanṣoṣo, nwọn o si wà ni ibinujẹ, bi ẹniti mbanujẹ fun akọbi rẹ” (Sekariah 12:10). Paulu Apọsteli sọ fun ni nipa igbala awọn Ju diẹ ti yoo kù pe: “Bẹẹli a o si gbà gbogbo Israẹli la” (Romu 11:26). Ibomiran ninu Iwe Mimọ sọ otitọ yi kan naa fun ni.

Yio si ṣe li ọjọ na, ni Oluwa yio tun nawọ rẹ lati gbà awọn enia rẹ iyoku padà, ti yio kù, lati Assiria, ati lati Egipti, ati lati Patrosi, ati lati Kuṣì, ati lati Elamu, ati Ṣinari, ati lati Hamati, ati lati awọn erekùṣu okun wá.

On o si gbe ọpagun kan duro fun awọn orilẹ-ède, yio si gbá awọn aṣati Israẹli jọ, yio si kó awọn ti a tuka ni Juda jọ lati igun mẹrin aiye wá” (Isaiah 11:11, 12).

Nigbana li àmi Ọmọ-enia yio si fi ara hàn li ọrun; nigbana ni gbogbo ẹya aiye yio kānu, nwọn o si ri Ọmọ-enia ti yio ma ti oju ọrun bọ ti on ti agbara ati ogo nla.

Yio si rán awọn angẹli rẹ ti awọn ti ohùn ipè nla, nwọn o si kó gbogbo awọn ayanfẹ rẹ lati ori igun mẹrẹrin aiye jọ, lati ikangun ọrun kan lọ de ikangun keji” (Matteu 24:30, 31). (Ka Isaiah 27:13 ati Jeremiah 16:4-16).

Jesu n tọka si iyokù awọn Ju gan an ti yoo la Ipọnju Nla koja, nigba ti O wi pe “Nitori nigbana ni ipọnju nla yio wà, irú eyi ti kò si lati igba ibẹrẹ ọjọ iwa di isisiyi, bẹẹkọ, irú rẹ ki yio si si. Bi kò si ṣepe a ké ọjọ wọnni kuru, kò si ẹda ti iba le là a; ṣugbọn nitori awọn ayanfẹ li a o fi ké ọjọ wọnni kuru” (Matteu 24:21, 22).

A o mu awọn Ju pada si ilẹ wọn lati ni in ni ini, a ki yoo si le wọn kuro nibẹ mọ niwọn igbà ti aye yoo wà. Jesu Kristi pẹlu yoo tun pada wa si aye yi lati jọba, gbogbo awọn Ọmọ Israẹli pẹlu yo tun pada si ilẹ wọn. Ni akoko imupada ti akọkọ, awọn ti o fẹ ni wọn pada bọ lati Babiloni (Esra 7:13, 14). A sọ fun ni pe ọpọlọpọ ni o duro lẹhin nibẹ, ati ni Egipti ati nibomiran gbogbo. Ṣugbọn ni akoko imupada bọ sipo ti igbà keji ti o n bọ niwaju, ki yoo kù ẹnikẹnii si ẹhin laarin awọn orilẹ-ède agbaye (Deuteronomi 30:4; Isaiah 43:5-7; Esekiẹli 34:11-13; 39:28, 29). Ni igbà imupada bọ ti akọkọ, ọkẹ meji le ẹgbẹẹdọgbọn (45,000) eniyan ti ẹya mejì ni wọn pada bọ. Ni akoko imupada bọ keji ti o n bọ niwaju, gbogbo Juda -- ẹya meji – ati gbogbo Israẹli -- awọn ẹya mẹwa ni yoo pada, (Jeremiah 3:18; Esekiẹli 36:10; 37:15-22). Ni imupada bọ ti akọkọ, wọn pada si ilẹ wọn, ṣugbọn nigbooṣe ọtá tun bori wọn, a si un tú wọn kaakiri. Ṣugbọn nigba ti a o mu wọn pada bọ ni igba keji, wọn o pada si ilẹ wọn, wọn yo si wà nibẹ. A ki yoo tun kó wọn lẹrú lọ si gbogbo orilẹ-ède agbaye mọ. A o gbé wọn ga, wọn o si maa gbe ni alaafia, awọn orilẹ-ède Keferi yoo si maa wọ tọ wọn. “Emi o si gbin wọn si ori ilẹ wọn, a ki yio si fà wọn tu mọ kuro ninu ilẹ wọn, ti mo ti fi fun wọn, li OLUWA Ọlọrun rẹ wi” (Amosi 9:15). (Wo Isaiah 49:18, 22, 23; 60:15, 16; Esekiẹli 34:28; 36:8-12; Mika 4:1, 2; Sekariah 8:20-23; 14:6).

Lẹhin ipada bọ ti akọkọ ni wọn kọ Jesu Olugbala wọn ti wọn si ka An mọ agbelebu. Ifọju ti ẹmi ati ọkan lile, ọkàn okuta wọn ni o fa eyi. Ṣugbọn ni akoko imupada ti o n bọ wa, wọn yoo ronupiwada ẹṣẹ wọn, wọn o si kọ ọ silẹ, won o si ke pe Messia wọn. A o wẹ wọn nù kuro ninu ẹṣẹ wọn, a o si fun wọn ni ọkà titun ati ẹmi titun. (Ka Jeremiah 31:9, 10, 33; Esekiẹli 36:16-38; 37:23-27; Sekariah 12:10-14; Ifihan 1:7).

Gẹgẹ bi a ti sọ, lẹẹkan, a n ri apa kan imupada bọ awọn Ju loni si ibi kekere kan lara ilẹ ti i ṣe ti wọn tẹlẹ ri. Wọn n pada ninu aigbagbọ. Wọn kò le di ajogun ohun ini wọn patapata ninu irú ipo bayi. “Akoko ipọnju Jakọbu” n bọ niwaju nigbà ti a o pa ọpọlọpọ, ṣugbọn ìdá kan ninu mẹta ti o ṣẹkù ninu wọn yoo la akoko iwẹnumọ yi kọja a o si gbà wọn là (Sekariah 13:8; Romu11:26, 27). Eyi ni ohun ti Esekiẹli sọ nipa iyipada wọn: “Nitori emi o mu nyin kuro lārin awọn keferi, emi o si ṣà nyin jọ kuro ni gbogbo ilẹ, emi o si mu nyin pada si ilẹ ti nyin. Nigbana ni emi o fi omi mimọ wọn nyin, ẹnyin o si mọ: emi o si wẹ nyin mọ kuro ninu gbogbo ẹgbin nyin ati kuro ninu gbogbo oriṣa nyin. Emi o fi ọkàn titun fun nyin pẹlu, ẹmi titun li emi o fi sinu nyin, emi o si mu ọkàn okuta kuro lara nyin, emi o si fi ọkàn ẹran fun nyin. Emi o si fi ẹmi mi sinu nyin, emi o si mu ki ẹ ma rin ninu aṣẹ mi, ẹnyin o pa idajọ mi ọ, ẹ o si ma ṣe wọn” (Esekiẹli 36:24-27).

A ka ninu Deuteronomi pe: “Ti OLUWA Ọlọrun wa ohun ikọkọ: ṣugbọn ohun ti Ifihàn ni ti wa ati ti awọn ọmọ lailai, ki awa ki o le ma ṣe gbogbo ọrọ ofin yi” (Deuteronomi 29:29).

Oluwa yàn nipasẹ Ọrọ Rẹ, lati ṣi ọpọlọpọ asọtẹlẹ paya fun ni nipa awọn Ju. Ọpọlọpọ ninu awọn asọtẹlẹ wọnyi ni o ti ṣẹ ná. Ọpọlọpọ ninu awọn asọtẹlẹ wọnyi n ṣẹ lọwọlọwọ loju wa, awọn miran si n bọ wa ṣẹ lai pẹ jọjọ. Wa inu iwe Mimọ. Maa ṣe akiyesi igboke-gbodo awọn Ju loni, iwọ yoo si gbagbọ pe opin akoko awọn Keferi ni a wà yi. Jesu fẹrẹ dé!

Má bẹru: nitori emi wà pẹlu rẹ; emi o mu iru-ọmọ rẹ lati gabasi wá, emi o si ṣà ọ jọ lati yama wa.

Emi o wi fun ariwa pe, Da silẹ; ati fun gusu pe, Máṣe da duro; mu awọn ọmọ mi ọkọnrin lati okere wá, ati awọn ọmọ mi obinrin lati opin ilẹ wá

Olukuluku ẹniti a npè li orukọ mi: nitori mo ti dá a fun ogomi, mo ti mọ ọ, ani mo ti ṣe e pé.

Mu awọn afọju enia ti o li oju jade wá, ati awọn aditi ti o li eti.

Jẹ ki gbogbo awọn orilẹ-ède ṣa ara wọn jọ pọ, ki awọn enia pejọ; tani ninu wọn ti o le sọ eyi, ti o si le fi ohun atijọ han ni? jẹ ki wọn mu awọn ẹlẹri wọn jade, ki a le dá wọn lare; nwọn o si gbọ, nwọn o si wipe, Õtọ ni.

Ẹnyin li ẹlẹri mi, ni OLUWA wi, ati iranṣẹ mi ti mo ti yàn: ki enyin ki o le mọ, ki ẹ si si gbà mi gbọ, ki o si ye nyin pe, Emi ni; a kò mọ Ọlọrun kan ṣāju mi, bẹẹni ọkan ki yio si hù lẹhin mi.

Emi, ani emi ni OLUWA; ati lẹhin mi, kò si olugbala kan,

Emi ti sọ, mo ti gbalà, mo si ti fi hàn, nigbati kò si ajeji ọlọrun kan lārin nyin: ẹnyin ni iṣe ẹlẹri mi li OLUWA wi, pe, Emi li Ọlọrun.

Lõtọ, ki ọjọ ki o to wà, Emi na ni, kò si si ẹniti o le gbani kuro li ọwọ mi: emi o ṣiṣẹ, tani o le yi i pada?

Bayi li OLUWA olurapada nyin, Ẹni Mimọ Israẹli wi; Nitori nyin ni mo ṣe ranṣẹ si Babiloni, ti mo si jù gbogbo wọn bi isansa, ati awọn ara Kaldea, sisalẹ si awọn ọkọ igbe-ayọ wọn.

Emi ni OLUWA, Ẹni-Mimọ nyin, ẹlẹda Israẹli Ọba nyin.

Bayi li OLUWA wi, ẹniti o la ọna ninu okun, ati ipa-ọna ninu alagbara omi;

Ẹniti o mu kẹkẹ ati ẹṣin jade, ogun ati agbara, nwọn o jumọ dubulẹ, nwọn ki yio dide; nwọn run, a pa wọn bi owú fitila

Ẹ máṣe ranti nkan ti iṣaju mọ, ati nkan ti atijọ, ẹ máṣe rò wọn.

Kiyesi i, emi o ṣe ohun titun kan; nisisiyi ni yio hù jade; ẹnyin ki yio mọ ọ bi? lõtọ, emi o là ọna kan ninuaginju, ati odò li aṣalẹ.

Awon ẹran igbẹ yio yin mi logo, awọn dragoni ati awọn owiwi; nitori emi o funni li omi li aginjù, ati odo ni aṣalẹ, lati fi ohun mimu fun awọn enia mi, ayanfẹ mi;

Awọn enia yi ni mo ti mọ fun ara mi; nwọn o fi iyin mi hàn.

Ṣugbọn iwọ kò ké pe mi, Jakọbu: ṣugbọn ārẹ mu ọ nitori mi, iwọ Israẹli.

Iwọ kò mu ọmọ-ẹran ẹbọ sisun rẹ fun mi wá; bẹni iwọ kò fi ẹbọ rẹ bu ọlá fun mi. Emi kò fi ọrẹ mu ọ sin, Emi kò si fi turari da ọ li agara.

Iwọ kò fi owo rà kalamu olõrun didun fun mi, bẹẹni iwo kò fi ọra ẹbọ rẹ yó mi; ṣugbọn iwọ fi ẹṣẹ rẹ mu mi ṣe lāla, iwọ si fi aiṣedede rẹ da mi li agara.

Emi, ani emi li ẹniti o pa irekọja rẹ rẹ nitori ti emi tikalami, emi ki yio si ranti ẹṣẹ rẹ.

Rán mi leti: ki a jumọ sọ ọ; iwọ rò, ki a le da ọ lare, Baba rẹ iṣāju ti ṣẹ, awọn olukọni rẹ ti yapa kuro lọdọ mi.

Nitorina mo ti sọ awọn olori ibi mimọ na di aimọ, mo si ti fi Jakọbu fun egún, ati Israẹli fun ẹgàn” (Isaiah 43:5-28).