Jeremiah 30:5-7, Daniẹli 8:23-25; 9:27; 12:1; Matteu 24:3-28; II Tẹssalonika 2:1-12; Ifihan 13:1-18

Lesson 165 - Junior

Memory Verse
“Oṣe! nitori ọjọ na tobi, tabẹẹ ti kò si ọkan bi iru rẹ: o jẹ àkoko wahala fun Jakọbu; sibẹ a o gbà a kuro ninu rẹ” (Jeremiah 30:7)
Notes

Nitori bayi li OLUWA wi; Awa ti gbọ ohùn iwa-riri, ẹru, ki si iṣe ti alafia.

Ẹnyin sa bere, ki ẹ si ri bi ọkọnrin a ma rọbi ọmọ: Ĕṣe ti emi fi ri gbogbo awọn ọkọnrin pẹlu ọwọ wọn li ẹgbẹ wọn bi obirin ti nrọbi, ti a si sọ gbogbo oju di jijoro?

O ṣe! nitori ọjọ na tobi, tobẹẹ ti kò si ọkan bi iru rẹ: o jẹ àkoko wahala fun Jakọbu; sibẹ a o gbà a kuro ninu rẹ.”

Nitori emi wà pẹlu rẹ, li OLUWA wi, lati gbà ọ: bi emi tilẹ ṣe ipari patapata ni gbogbo orilẹ-ède, nibiti emi ti tu ọ ka si, sibẹ emi ki yio ṣe ọ pari patapata: ṣugbọn emi o ba ọ wi ni iwọn, emi ki o j rẹ lọwọ li alaijiya.

Nitori bayi li OLUWA wi, Ifarapa rẹ jẹ aiwotan, ọgbẹ rẹ si jẹ aijina.

Kò si ẹniti o gba ọran rẹ rò lati di i, ọja imularada kò si.

Gbogbo awọn olufẹ rẹ ti gbagbe rẹ; nwọn kò tẹle ọ; nitori ilù ọta li emi o lù ọ, ni inà alaini ānu, nitori ọpọlọpọ aiṣedede rẹ, nitori ẹṣẹ rẹ pọ si i,

Ĕṣe ti iwọ nkigbe nitori ifarapa rẹ? ikānu rẹ jẹ aiwotan, nitori ọpọlọpọ aiṣedede rẹ: ẹṣẹ rẹ si pọ si i, nitorina ni emi ti ṣe ohun wọnyi si ọ” (Jeremiah 30:5-7, 11-15).

Li akoko na ni Mikaeli, balogun nla nì ti yio gbeja awọn ọmọ awọn enia rẹ yio dide, akoko wahala yio si wà iru eyi ti kò ti isi ri, lati igbà ti orilẹ-ède ti wà titi fi di igba akokò yi, ati ni igba akokò na li a o gbà awọn enia rẹ la, ani gbogbo awọn ti a ti kọ orukọ wọn sinu iwe” (Daniẹli 12:1).

Akoko wahala kikoro n bọ wa sori aye yi. Akoko yi yoo de ba aye gẹgẹ bi akoko idajọ. Ṣugbọn ohun ti yoo ṣẹlẹ ni ọjọ wọnni tayọ idajọ lori awọn ẹlẹṣẹ ti yoo wà ninu ayé nigbà naa. Apa kan eto nla Ọlọrun ni lati ayebaye.

Yoo jẹ akoko wahala fun ogunlọgọ, fun awọn miran ẹwẹ yoo jẹ ogo ninu awọsanma lọhùn. Ni akoko yii, ọpọlọpọ yoo fi ẹmi wọn tan ọrọ ẹri wọn, yoo si jẹ akoko ipalarada fun awọn ẹlomiran. Abajọ ti Woli nì fi kigbe pẹlu iyanu nigbà ti o fi oju Ẹmi ri ohun ti o n bọ wa ṣẹlẹ ni ọjọ iwaju wi pe, “Nitori ọjọ na tobi, tobẹẹ ti kò si ọkan bi iru rẹ.”

Akoko Ipọnju Jakọbu tabi akoko Ipọnju Nla, bi a ti saba maa n pe e, jẹ akoko kukuru ṣiwaju Ifarahàn Kristi ati ibẹrẹ Ijọba ologo ti Kristi lori ilẹ aye. Gbogbo akoko yii dabi ẹni pe kò ni ju ọdún meje (Daniẹl 9:27). Ṣiwaju tabi ni ibẹrẹ rẹ, Ipalarada Ijọ Ọlọrun yoo ṣẹlẹ. A kò mọ bi Ijọ Ọlọrun yoo ti ni ipin ninu Ipọnju Nla yii to. O le jẹ pe Ọlọrun yoo jẹ ki wọn ri diẹ ninu rẹ (II Tẹssalonika 2:1-12). Awọn ohun ti o n ṣẹlẹ ni akoko yii fi hàn fun ni pe ibẹrẹ akoko naa kù si dẹdẹ bi kò ba tilẹ ti de ba wa. Lai si aniani, eyi fi hàn fun ni pẹlu pe Ipalarada awọn eniyan mimọ kù si dẹdẹ. Nitori naa awa ti i ṣe Onigbagbọ n woke, nitori idande wa sun mọ etile. Akoko ti a o lọ wà pẹlu Oluwa nibi Ase Igbeyawo Ọdọ-Agutan kò ni pẹ mọ rara. Boya ki a to tẹ iwe yii jade fun kikà, tabi ki a to kà a lati fi kọ ni, tabi ki a to gbọ ọ lati fi ṣe iwà hù ni Jesu yoo de. A kò mọ akoko ti Oun yoo pada, ṣugbọn a mọ eyi pe o sun mọ tosi, ọjọ naa kù si dẹdẹ.

Mo si duro lori iyanrin okun, mo si ri ẹranko kan nti inu okun jade wá, o ni ori meje ati iwo mẹwa, ati ade mẹwa lori awọn iwo na, ati li awọn ori rẹ na ni orukọ ọrọ-odi.

Ẹranko ti mo ri na si dabi ẹkùn, ẹsẹ rẹ si dabi ti beari, ẹnu rẹ si dabi ti kiniun: dragoni na si fun u li agbara rẹ, ati itẹ rẹ, ati ọlá nla.

Mo si ri ọkan ninu awọn ori rẹ bi ẹnipe a ṣá a pa, a si ti wo ọgbẹ aṣapa rẹ na san, gbogbo aiye si fi iyanu tẹle ẹranko na.

Nwọn si foribalẹ fun dragoni na nitori o ti fun ẹranko na ni ọla: nwọn si foribalẹ fun ẹranko na, wipe, Tali o dabi ẹranko yi? Tali o si le ba a jagun?

A si fun u li ẹnu lati mā sọ ohun nla ati ọrọ-odi; a si fi agbara fun u lati ṣe bẹẹ ni oṣu mejilelogoji.

O si ya ẹnu rẹ ni blasfimi si Ọlọrun, lati sọ ọrọ-odi si orukọ rẹ, ati si agọ rẹ, ati si awọn ti ngbe ọrun.

A si fi fun u lati mā ba awọn enia mimọ jagun, ati lati ṣẹgun wọn: a si fi agbara fun u lori gbogbo ẹya, ati enia, ati ède, ati orilẹ.

Gbogbo awọn ti ngbe ori ilẹ aiye si mā sin i, olukuluku ẹniti a kò kọ orukọ rẹ sinu iwe iyè Ọdọ-Agutan ti a ti pa lati ipilẹṣẹ aiye.

Bi ẹnikẹni ba li eti ki o gbọ.

Bi ẹnikẹni ba nfẹ ki a di ẹni ni igbèkun, igbèkun ni yio lọ: bi ẹnikẹni ba nfẹ ki a fi idà pa ẹni, idà li a o si fi pa on na. Nihin ni sũru ati igbagbọ awọn enia mimọ gbé wà.

Mo si ri ẹranko miran goke lati inu ilẹ wá; o si ni iwo meji bi ọdọ-agutan, o si nsọrọ bi dragoni.

O si nlò gbogbo agbara ẹranko ekini niwaju rẹ, o si mu ilẹ aiye ati awọn ti ngbe inu rẹ foribalẹ fun ẹranko ekini ti a ti wo ọgbẹ aṣápa rẹ san.

O si nṣe ohun iyanu nla, ani ti o fi nmu iná sọkalẹ lati ọrun wá si ilẹ aiye niwaju awọn enia.

O si ntàn awọn ti ngbe ori ilẹ aiye jẹ nipa awọn ohun iyanu ti a fi fun u lati ṣe niwaju ẹranko na; o nwi fun awọn ti ngbe ori ilẹ aiye lati ya aworan fun ẹranko na ti o ti gbà ọgbẹ idà, ti o si yè.

A si fi fun u lati fi ẹmi fun aworan ẹranko na ki o mā sọrọ, ki o si mu ki a pa gbogbo awọn ti kò foribalẹ fun aworan ẹranko na.

O si mu gbogbo wọn, ati kekere ati nla, ọlọrọ ati talakà, ominira ati ẹrú, ki a fi ami kan fun wọn li ọwọ ọtún wọn, tabi ni iwaju wọn:

Ati ki ẹnikẹni má le rà tabi ki o tà, bikoṣe ẹniti o ba ni ami orukọ ẹranko na, tabi iye orukọ rẹ.

Nihin ni ọgbọn gbé wà. Ẹniti o ba ni oye, ki o ṣiro iye ti mbẹ lara ẹranko na: nitori iye enia ni; iye rẹ na si jẹ ọtalelẹgbẹta o le mẹfa” (Ifihan 13:1-18).

Aṣodi-si-Kristi Ni Akoko Ipọnju Nlá

Aṣodi-si-Kristi ni yoo jẹ ẹni ẹṣẹ ti o buru jai, ni akoko Ipọnju nla, ẹni ti yoo ni agbara ti o tayọ ti ẹda, agbara Satani. Oun yoo jẹ ọba, adapaṣẹ, agbara ẹni ti i ṣe lati ọdọ Satani, nitori dragoni ni o fun un ni “agbara rẹ, ati itẹ rẹ, ati ọlá nla” (Ifihan 13:2). Ibujoko rẹ yoo wà ni Jerusalẹmu, “ni tẹmpili Ọlọrun, ti o nfi ara rẹ hàn pe Ọlọrun li on” (II Tẹssalonika 2:4). Gbogbo awọn olugbe aye ni yoo maa sin in, awọn ẹni ti a kò kọ orukọ wọn sinu Iwe Iye (Ifihan 13:8). Oun yoo gbà agbara nipa ipọnni ẹtan, ileri alaafia ati ọrọ de aye kan, ṣugbọn ni akoko Ipọnju Nla, oun yoo yi mẹbẹ-mẹyẹ iṣakoso rẹ pada, yoo si di onroro ti kò si iru rẹ ri. Oun yoo si ṣe oluṣe buburu ju lọ, ẹlẹtan ti kò lẹgbẹ, yoo si tàn awọn orilẹ-ède aye jẹ (Ifihan 13:1-18).

Bi o si ti joko lori òke Olifi, awọn ọmọ-ẹhin rẹ tọ ọ wá nikọkọ, wipe, Sọ fun wa, nigbawo ni nkan wọnyi yio ṣẹ? Kini yio si ṣe àmi wiwa rẹ, ati ti opin aiye?

Jesu si dahùn, o si wi fun wọn pe, Ẹ kiyesara, ki ẹnikẹni ki o máṣe tàn nyin jẹ.

Nitori ọpọlọpọ yio wá li orukọ mi, wipe, Emi ni Kristi; nwọn ó si tàn ọpọlọpọ jẹ.

Ẹnyin o si gburo ogun ati idagiri ogun: ẹ kiyesi i ki ẹnyin ki o máṣe jaiyà: nitori gbogbo nkan wọnyi kò le ṣe ki o ma ṣẹ, ṣugbọn opin ki iṣẹ isisiyi.

Nitoripe orilẹ-ède yio dide si orilẹ-ède, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba: iyàn, ati ajakalẹ-arùn, ati isẹlẹ yio si wà ni ibi pipọ.

Gbogbo nkan wọnyi ni ipilẹṣẹ ìpọnju,

Nigbana ni nwọn o fi nyin funni lati jẹ ni iya, nwọn o si pa nyin: a o si korira nyin lọdọ gbogbo orilẹ-ède nitori orukọ mi.

Nigbana ni ọpọlọpọ yio kọsẹ, nwọn o si ma ṣòfofo ara wọn, nwọn o si mā korira ara wọn.

Woli eke pipọ ni yio si dide, wọn o si tàn ọpọlọpọ jẹ.

Ati nitori ẹṣẹ yio di pipọ, ifẹ ọpọlọpọ yio di tutù.

Ṣugbọn ẹniti o ba foriti i titi de opin, on na li a o gbalà.

A o si wasu ihinrere ijọba yi ni gbogbo aiye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ède; nigbana li opin yio si de.

Nitorina nigbati ẹnyin ba ri irira isọdahoro, ti a ti ẹnu woli Daniẹli sọ, ti o ba duro ni ibi mimọ (ẹniti o ba kà a ki oyé ki o yé e:)

Nigbana ni ki awọn ti mbẹ ni Judea ki o sálọ si ori òke:

Ki ẹniti mbẹ lori ile ki o maṣe sọkalẹ wá imu ohunkohun jade ninu ile rẹ:

Ki ẹniti mbẹ li oko máṣe pada sẹhin wá lati mu aṣọ rẹ.

Ṣugbọn egbé ni fun awọn ti o lóyun, ati fun awọn ti o nfi ọmú fun ọmọ mu ni ijọ wọnni!

Ẹ si mā gbadura ki sisá nyin ki o máṣe jẹ igba otutu tabi ọjọ isimi:

Nitori nigbana ni ipọnju nla yio wà, irú eyi ti kò si lati igba ibẹrẹ ọjọ iwa di isisiyi, bẹẹkọ, irú rẹ ki yio si si.

Bi kò si ṣepe a ké ọjọ wọnni kuru, kò si ẹda ti iba le là a: ṣugbọn nitori awọn ayanfẹ li a o fi ké ọjọ wọnni kuru.

Nigbana bi ẹnikan ba wi fun nyin pe, Wo o, Kristi mbẹ nihin, tabi lọhun; ẹ máṣe gbà a gbọ.

Nitori awọn eke Kristi ati eke woli yio dide, nwọn o si fi àmi ati ohun iyanu nla hàn, tobẹẹ bi o le ṣe ṣe nwọn o tàn awọn ayanfẹ pāpā.

Wo o, mo wi fun nyin tẹlẹ.

Nitorina bi nwọn ba wi fun nyin pe, Wo o, o wà li aginju; ẹ má lọ sibẹ: wo o, o wà ni iyẹwu; ẹ máṣe gbàgbọ.

Nitori gẹgẹ bi manamana ti ikọ lati ila-õrun, ti isi mọlẹ de iwọ õrun; bẹẹni wiwa Ọmọ-enia yio ri pẹlu.

Nitori ibikibi ti okú ba gbé wà, ibẹ li awọn idi ikojọ pọ si” (Matteu 24:3-28).

Aṣodi-si-Kristi yoo doju ibinu gbigbona rẹ kọ awọn Onigbagbọ ti o ba wà láyé nigbà ti a kò pa larada pẹlu Iyawo Kristi, ati awọn Ju ti o ti kọ Messia wọn silẹ lati ọjọ pipẹ. Abayọrisi ibinu yii ati ifarahan ibi yii ni pe wọn yoo gbà Kristi gẹgẹ bi Messia wọn, ani apakan awọn Ju ti o kù ni akoko Ifarahan Kristi (Sekariah 12:10; 13:6-9; Isaiah 66:7, 8; Eskiẹli 20:40-43; 36:24-28; 39:27-29; Jeremiah 33:7-9; 50:4, 5, 20). Awọn Onigbagbọ ti o ba wa laaye nigbà naa ni wọn yoo kú ikú ajẹrikú fun iduro-ṣinṣin ti wọn mu lati dojukọ agbara ati ogun eṣu (Ifihan 13:6-8, 16, 17; 14:9-11; 20:4).

Li akokò ikẹhin ijọba wọn, nigbati awọn oluṣe irekọja ba de ni kikun, li ọba kan yio dide, ti oju rẹ buru, ti o si moye ọrọ arekereke.

Agbara rẹ yio si le gidigidi, ṣugbọn ki iṣe agbara ti on takararẹ: on o si ma ṣe iparun ti o yani lẹnu, yio si ma ri rere ninu iṣẹ, yio si pa awọn alagbara ati awọn enia ẹni-mimọ run.

Ati nipa arekereke rẹ yio si mu ki iṣẹ ẹtan ṣe dẽde lọwọ rẹ; on o si gbé ara rẹ ga li ọkàn rẹ, lojiji ni yio si pa ọpọlọpọ run, yio dide si olori awọn ọmọ-alade ni; ṣugbọn on o ṣẹ laisi ọwọ” (Daniẹli 8:23-25).

Ṣugbọn awa mbẹ nyin, ará, nitori ti wiwá Jesu Kristi Oluwa wa, ati ti ipejọ wa sọdọ rẹ,

Ki ọkàn nyin ki o máṣe tete mi, tabi ki ẹ máṣe jaiya, yala nipa ẹmi, tabi nipa ọrọ, tabi nipa iwe bi lati ọdọ wa wá, bi ẹnipe ọjọ Oluwa de.

Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni tàn nyin jẹ lọnakọna; nitoripe ọjọ na ki yio de, bikoṣepe iyapa nì ba kọ de, ki a si fi ẹni ẹṣẹ ni hàn, ti iṣe ọmọ ègbé;

Ẹniti nṣodi, ti o si ngbe ara rẹ ga si gbogbo ohun ti a npè li Ọlọrun, tabi ti a nsin; tobẹ ti o joko ni tẹmpili Ọlọrun, ti o nfi ara rẹ hàn pe Ọlọrun li on.”

Ẹnyin kò ranti pe, nigbati mo wa lọdọ nyin, mo nsọ nkan wọnyi fun nyin?

Ati nisisiyi ẹnyin mọ ohun ti o nṣe idena, ki a le ba fi i hàn li akoko rẹ.

Nitoripe ohun ijinlẹ ẹṣẹ ti nṣiṣẹ ná: kiki pe ẹnikan wà ti nṣe idena nisisiyi, titi a ó fi mu u ti ọna kuro.

Nigbana li a ó si fi ẹni ẹṣẹ ni hàn, ẹniti Oluwa yio fi ẽmi ẹnu rẹ pa, ti yio si fi ifihan wiwá rẹ sọ di asan:

Ani on, ẹniti wiwa rẹ yio ri bi iṣẹ Satani pẹlu agbara gbogbo, ati àmi ati iṣẹ-iyanu eke.

Ati pẹlu itanjẹ aiṣododo gbogbo fun awọn ti nṣegbé; nitoriti nwọn kò gbà ifẹ otitọ ti a ba fi gbà wọn là.

Ati nitori eyi, Ọlọrun rán ohun ti nṣiṣẹ iṣina si wọn, ki nwọn ki o le gbà eke gbọ;

Ki a le ṣe idajọ gbogbo awọn ti kò gbà otitọ gbọ, ṣugbọn ti nwọn ni inu didùn ninu aiṣododo” (II Tẹssalonika 2:1-12).

Ẹni ẹṣẹ yii, gẹgẹ bi Iwe Mimọ ti pe e, jẹ alailofin. Aṣodi-si-Kristi ni ẹni ti o jẹ alatako Kristi. Ki i ṣe igbekalẹ tabi ẹgbẹ kan ṣa, ṣugbọn ẹni kan, ti agbara rẹ tayọ ti ẹda, eleṣu eniyan ti o gbe àwọ eniyan wọ lati maa sọ blasfemi, ẹni ti ọpọ eniyan yoo maa wọ tẹle ninu aye yii. Aṣodi-si-Kristi yoo tan aye jẹ nipa ami ati iṣẹ-iyanu eke ti oun ati woli eke naa yoo ni agbara lati ṣe, wọn yoo tilẹ maa pe iná sọkalẹ “lati ọrun” wá loju awọn eniyan (Ifihan 13:13). Oun yoo sẹ Ọlọrun ati ohunkohun ti i ṣe ti Ọlọrun.

Lati igba awọn Apọsteli ni ẹmi Aṣodi-si-Kristi ti n ṣiṣẹ, nitori pe Johannu Ayanfẹ kọwe bayii pe: “Gbogbo ẹmi ti kò si jẹwọ pe, Jesu Kristi wá ninu ara, ki iṣe ti Ọlọrun: eyi si li ẹmi Aṣodi-si-Kristi na, ti ẹnyin ti gbọ pe o mbọ, ati nisisiyi o si ti de sinu aiye” (I Johannu 4:3). Johannu ṣe apejuwe ẹmi Aṣodi-si-Kristi lọna ti o ye ni to bẹẹ ti ẹnikẹni kò ni lati ṣI i mọ nigbà ti o ba fara hàn, tabi lati le mọ awọn ohun èlò ati igbekalẹ loriṣiriṣi ti o ti mu ki o maa ṣiṣẹ ṣaaju bibọ Rẹ. “Nitori ẹlẹtàn pupọ ti jade wá sinu aiye, awọn ti kò jẹwọ pe Jesu Kristi wá ninu ara. Eyi li ẹlẹtàn ati Aṣodi-si-Kristi” (II Johannu 7). A le ri i nigbà naa wi pe Aṣodi-si-Kristi yoo jẹ alailofin ti o sẹ iwa Ọlọrun Kristi.

Bi o tilẹ ṣe pe Ipọnju Nla ni awọn iṣẹlẹ nlanla ti yoo tẹle ipalarada Ijọ Ọlọrun, ani akoko ti ijọba Satani gbilẹ kan, akoko ti o tẹle Ipọnju Nla yii jẹ ireti nla fun gbogbo awọn eniyan Ọlọrun, ani fun gbogbo agbayé. Ni akoko naa, Kristi yoo gbe Ijọba Rẹ kalẹ ni aye, Oun yoo si ṣe akoso pẹlu otitọ ati ododo.

Itujade Arọkuro Ojo ni o pilẹ awọn iṣẹlẹ ti yoo maa ṣẹlẹ lera-lera titi a o fi gbe Ijọba naa kalẹ. Iriri ti ifi-wọni Ẹmi Mimọ, ti a tú jade ni akoko Arọkuro Ojo gẹgẹ bi Joẹli ti sọtẹlẹ (Joẹli 2:21-32), asọtẹlẹ Joẹli eyi ti Ẹmi Mimọ tumọ fun ni lati ẹnu Peteru (Iṣe Awọn Apọsteli 2:6, 16-21), iriri ti awọn ti a ti sọ di mimọ patapata ṣe alabapin rẹ lati igbà ti a ti kọ tu u jade ni ilu Lọs Angeles (ni Amẹrika) ni oṣu kẹrin ọdun 1906, jẹ ọkan ninu awọn ohun pataki fun imurasilẹ ti Ọlọrun ran lati pese Iyawo fun Ọmọ Rẹ, Jesu Kristi. A o gbe Iyawo Kristi lọ si ibi Ase Igbeyawo Ọdọ-agutan ni ofurufu. Ni akoko ayọ ati inu didun nibi Ase Igbeyawo Ọdọ-agutan yi ni a o tú idajọ Ọlọrun dà sori aye yii, nigba ti awọn eniyan yoo jiya ẹṣẹ ati iṣọtẹ wọn, lati ọwọ Aṣodi-si-Kristi, alakoso ti o roro, ati nipa ijẹniya lati ọdọ Ọlọrun Onidajọ ododo wá.

Ni opin Ase Igbeyawo Ọdọ-agutan ni Jesu yoo pada wa si aye nigbà Ifarahàn Rẹ, pẹlu awọn eniyan mimọ Rẹ ti a ti ṣe logo, awọn ti a ti ji dide ni akoko Ipalarada. Awọn eniyan mimọ ti a pa ni akoko Ipọnju, awọn ti a saba maa n pe ni awọn eniyan mimọ igbà Ipọnju ni a o ji dide ni ara ologo, wọn yoo si ba Jesu jọba pẹlu awọn eniyan mimọ ti a ti pa lara dá (Ifihan 20:4). Awọn Ju yoo gba Messia wọn, a o bi orilẹ-ède wọn ni ọjọ kan, Oluwa yoo si gbe Aṣodi-si-Kristi ati woli eke naa sọ sinu adagun iná. A o sọ Satani sinu ọgbun ainisalẹ fun ẹgbẹrun ọdún.

“On (Aṣodi-si-Kristi), o si fi idi majẹmu kan kalẹ fun ọpọlọpọ niwọn ọsẹ kan: ati lārin ọsẹ na ni yio mu ki a dẹkun ẹbọ, ati ọrẹ-ẹbọ, irira isọdahoro yoo si duro lori ibi-mimọ titi idajọ ti a pinnu yio túdà sori asọnidahoro” (Daniẹli 9:27).

Awọn Ju ati Ipọnju Nla

Awọn Ju n pada lọ si ilu wọn nisinsinyi ni aigbagbọ. Wọn n pada lọ lati gbà ilẹ kan ati lati tun orilẹ-ède kan ṣe nibi ti wọn n reti lati maa gbe ni alaafia ati ailewu. Lai si aniani, a o fun wọn ni alaafia ati ailewu ni iwọn iba fun igba diẹ, nitori pe wọn yoo dimọ pọ pẹlu Aṣodi-si-Kristi nigbà ti o ba ku diẹ fun un lati bẹrẹ ijọba rẹ (Daniẹli 9:27).

Yoo gbà pe ki awọn Ju jẹ iya pupọ lati le mu wọn pada sọdọ Ọmọ Ọlọrun, Ẹni ti wọn gba ẹbi tita Ẹjẹ Rẹ silẹ sori ara wọn. Idamẹma wọn pere ni yoo ṣẹkù silẹ lẹhin ikọlu ti yoo de ba wọn lati ọwọ Ọlọrun ati eniyan ni akoko ipọnju nla wọn (Sekariah 13:9). Bi awọn Ju ti n pada si Palẹstini lọjọ oni, wọn kò mọ pe wọn n pada lati lọ la inunibini kikoro kọja, irú eyi ti wọn kò ri ri.

Majẹmu tabi ifimọ-ṣọkan ti wọn yoo tẹ ọwọ bọ pẹlu Aṣodi-si-Kristi yoo bajẹ (Daniẹli 9:27). Aṣodi-si-Kristi yoo gbé aworan ara rẹ kalẹ ni tẹmpili, wọn yoo si maa sin in bi Ọlọrun (II Tẹssalonika 2:4; Ifihan 13:15). A o wẹ awọn Ju mọ kuro ninu ibọriṣa ati aigbagbọ wọn, nitori ti Woli nì sọ pe, “On o si joko bi ẹniti nyọ, ti o si ndá fadakà: yio si ṣe awọn ọmọ Lefi mọ, yio o si yọ wọn bi wurà on fadakà, ki nwọn ki o le mu ọrẹ ododo wá fun OLUWA. Nigbana ni ọjọ igbāni, ati gẹgẹ bi ọdun atijọ” (Malaki 3:3,4). Ẹ wo bi ọjọ naa yoo ti logo to, ti Ọlọrun yoo le boju wò awọn eniyan Rẹ pẹlu ayọ ati inu didùn, nigba ti Jesu yoo ṣe akoko aye ni alaafia ati aiṣegbe!

Gbogbo awọn ti o ba wà laye ti kó ba gba ami ẹranko naa kò ni le tà bẹẹ ni wọn kò ni le rà, nitori pe Aṣodi-si-Kristi ni yoo maa ṣe akoso ọrọ aje gbogbo aye, òwò, iṣelu ati ìsìn. Kò ni si ọba miran a fi oun nikan ṣoṣo, agbara rẹ lori awọn eniyan yoo jẹ ti ikú oun iyè. Awọn ti o ba si kọ lati gbọ ti rẹ, ti wọn yàn lati duro tiiri fun Ọlọrun ati otitọ, ni a o pa (Ifihan 12:1-17; 13:1-18; Daniẹli 8:23-25).

O ṣe e ṣe lati wà labẹ Imọlẹ Ihinrere ni akoko yii ki a má si mura silẹ lati pade Oluwa ni akoko Ipalarada. Awọn ti kò ni oore-ọfẹ Ọlọrun to bẹẹ ninu ọkàn wọn lati duro fun otitọ Ihinrere nisinsinyi, kò ni lagbara to lati doju kọ Aṣodi-si-Kristi, ki wọn si maagbọ ofin lile rẹ bi o ti n pe Ọlọrun nijà. Nitootọ, a ko le sọ wi pe ireti pupọ wa fun ẹnikẹni ti kò rin ninu gbogbo Imọlẹ Ihinrere ti o ti tàn si ọna rẹ.

Bi ẹnikan kò ba ni oungbẹ fun ohun ti i ṣe ti ẹmi tó lati fa gbogbo ẹkún ibukun Ọlọrun wá sinu ọkàn rẹ nisinsinyi ti o jẹ pe Ẹmi Mimọ wà fun gbogbo ọkàn ti o ba ṣafẹri tọkàn-tọkàn lati ni In, bawo ni ẹni naa yoo ṣe ni ireti lati fara dà iná eṣu ati idojukọ ti kò ni loṣuwọn lẹhin ti a ba ti gba Ẹmi Mimọ kuro ninu aye? Kò si ohun kan lati rú ifẹ ọkàn soke lati ṣe rere nigbà naa. Yoo ti pari patapata. Ami ẹranko naa kò ni iyemeji ninu, awọn ti wọn ba si gbà ami yi ti fi ọwọ ara wọn ṣe ara wọn nibi (Ifihan 14:9-11). Lati gbà ami yi ni lati gbà Aṣodi-si-Kristi ni ipo Ọlọrun ati Kristi. Onigbagbọ kò si gbọdọ ṣe eyi.

Wiwá Aṣodi-si-Kristi

Lai si aniani, otitọ ni pe Aṣodi-si-Kristi wà ninu aye loni. Bi o tilẹ ṣe pe a ko ti i fi i hàn, o daju pe o ti n gbá ogun jọ lati ja labẹlẹ. Iṣubu kuro ninu igbagbọ, eyi ti asọtẹlẹ rẹ wà ninu Iwe Mimọ ti de na (II Tẹssalonika 2:2-4). Awọn Ju ti bẹrẹ si pada si ilẹ wọn, wọn si ti ni ijọba ti ara wọn. Ṣugbọn ijọba Israẹli bi o ti wà loni yi ki i ṣe eyi ti Ọlọrun jẹ Ọba le lori, gẹgẹ bi Ọlọrun ti fẹ, ti a o si fi idi rẹ kalẹ nigba ti awọn Ju ba gba Kristi ni Messia wọn ti Oun si di Ọba wọn. Ni ọjọ naa ti wọn ba gbà Jesu ni a o bi orilẹ-ède wọn ni tootọ (Isaiah 66:7,8; Sekariah 12:10; 13:6-9).

Ayà awọn eniyan le to bẹẹ lonii ti kò fi si irú rẹ ri. Wọn kò fẹ otitọ. Wọn fẹ ailofin. Wọn sẹ Kristi, wọn tẹmbẹlu awọn iṣẹ iyanu Rẹ, wọn kò naani aṣẹ Rẹ, wọn fi oju tinrin iṣẹ iranṣẹ Rẹ to bẹẹ ti kò jamọ nkankan rara loju wọn (I Johannu 2:18,22; 4:1-3). Ni kukuru wọn n gba ẹmi Aṣodi-si-Kristi, wọn si n ṣe onigbọwọ ẹmi Aṣodi-si-Kristi ki a tilẹ to fi Aṣodi-si-Kristi hàn!. Wọn n mura silẹ. Awọn atako ti kò ti mu ki ijọba Aṣodi-si-Kristi ṣe e ṣe ni wọn ti n yi pada, ti wọn gbọjẹgẹ rẹ, tabi ti wọn n sọ di yẹpẹrẹ lọna ti o ya ni lẹnu. A n fa awọn Onigbagbọ tootọ kuro ninu aye lati sunmọ Ọlọrun si i, a n wẹ wọn mọ, a n fun wọn ni okun, wọn si n gbaradi silẹ de ohun ti o n bọ lọjọ iwaju.

Nigba ti Ọlọrun ba wi pe “O to,” nigba naa ni Ọmọ Rẹ yoo de, pẹlu ipe olori angẹli ati ohun ipe Ọlọrun, lati mu awọn ti o ti n wọna fun bibọ Rẹ lọ (I Tẹssalonika 4:13-18). Nigbà naa ni agbara ibi ninu aye yii kò ni ni akoso mọ, a o si tu ogun aigbagbọ jade ninu eeri rẹ, ikorira ohun rere, ipaniyan, irẹjẹ ati agbara eṣu lai lẹgbẹ (II Tẹssalonika 2:1-12). Kò ni si iṣoro fun Aṣodi-si-Kristi lati ṣẹgun nigba ti o ba to akoko lati fi i hàn. O tilẹ le gbé ijọba rẹ kalẹ nisinsinyi pẹlu irọrun bi a ba gbà awọn eniyan mimọ Ọlọrun ati Ẹmi Mimọ kuro ninu aye; niwọn iba oye wa, awọn ohun ti o n ṣe idena rẹ lati ṣe bẹẹ nisinsinyi ni iwọnyi.

Nebukadnessari, ninu Majẹmu Laelae, jẹ apẹẹrẹ Aṣodi-si-Kristi. O yá ere, o si paṣẹ buburu pe: “Ẹniti kò ba si wolẹ, ki o si tẹriba, lojukanna li a o gbé e sọ si ārin iná ileru ti njo” (Daniẹli 3:6). A sọ tẹlẹ pe Aṣodi-si-Kristi yoo ya aworan ararẹ, yoo si mu ki a pa gbogbo awọnn ti wọn kọ lati fi ori balẹ fun un (Ifihan 13:1-18). Ọpọlọpọ li a o tanjẹ ni akoko yii ti wọn yoo si gba ami ẹranko naa, nipa bẹẹ ti wọn yoo si ṣegbe laelae (Ifihan 14:9,10).

A ri ọpọlọpọ agbara ti wọn n parapọ lati la ọna silẹ fun Aṣodi-si-Kristi; awọn oriṣiriṣi ẹgbẹ a-gbọ-tara- ma-gbọ-tẹmi, ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ti n tako iṣàkoso nile iṣẹ, ati oriṣiriṣi igbekalẹ ẹtan ati eke, ati adalu ẹsin. Ohun ijinlẹ ẹṣẹ ti n ṣiṣe lọwọlọwọ. Majẹmu orilẹ-ède si orilẹ-ède ati oriṣiriṣi idapọ ati oriṣiriṣi ibi, àdámọ, igbekalẹ ati ailonka ẹgbẹ ti wọn n pe ni ẹgbẹ ifẹ, yoo di ọkan ṣoṣo nikẹhin ninu ẹni ti i ṣe Aṣodi-si-Kristi. Ohunkohun tí ó bá lòdì sí Ọlọrun, tabi ti o ba sẹ Kristi lọnàkọnà jẹ ohun èlò pataki lọwọ ẹni-ibi nì. Nitori ìdí eyi, Onigbagbọ tootọ, aṣẹgun patapata ni lati ri i dajú pé oun fi gbogbo ifẹ oun fun Ọlọrun tokàn-tọkàn, ati fun ohun ti i ṣe ti Rẹ, ati fun awọn eniyan Ọlọrun nigbà gbogbo (I Johannu 2:15-17).

Ni akoko naa, a o ran àrùn tí ó pọ sori ayé. Ago ẹsẹ ayé yii fẹrẹ kún. Ọlọrun pa ayé ti ìgbà Noa run. O kó awọn eniyan Rẹ jade lọ sinu Ọkọ ki wọn ki o má ṣe ni ìpín ninu imunà ìbínú Ọlọrun (Genesisi 7). Bakan naa ni Oun yoo ṣe kó awọn eniyan Rẹ jade kuro ninu ayé ni akoko Ipalarada, ti wọn yoo lọ sibi sè Alẹ Igbeyawo Ọdọ-agutan ki wọn ki o le sá là kuro ninu ẹṣẹ buburu ti yoo tú jade (Isaiah 26:20, 21).

Ìwé Ifihan ati awọn apá kan Ìwé Mimọ ti ó sọ gẹgẹ bí Ọlọrun ti ṣe kọlu awọn ara Egipti nitori awọn eniyan Rẹ ni ilẹ Egipti sọ fun ní nipa ọpọlọpọ àrùn ti a o tú dà sori gbogbo awọn eniyan ti ó wà ni ayé (Ẹksodu 7:14-25; 8:1-32; 9:1-35; 10:1-29; 11:1-10; 12:23-30). A kò le fi itumọ miran fun awọn akọsilẹ Bibeli ti kò ni itumọ ikọkọ (Ifihan 22:18, 19). A sọ awọn ohun ti a sọ fun ni ní ẹdà-ọrọ nitori pé kò si èdè ọmọ eniyan ti o lè ṣe apejuwe idaamu ati ipaya wọnyi ni ẹkún-rẹrẹ. A ni lati mọ dajúdajú pé awọn otitọ ti a fi yé ni nipa apẹẹrẹ tabi ẹdà-ọrọ tilẹ buru ju bi apejuwe rẹ ti ri.

Ogun, ìjà-igboro, iruke-rudo, ìyàn, ikú ajakalẹ-àrùn, mimi gbogbo agbayé kijikiji, ìsẹlẹ, yoo wà; ìgbà ati akoko yoo si maa yí lodílodí ní akoko ipọnju yi. Ìjì líle yoo maa jà, yìnyín-dídì ti yoo maa wọ yoo wuwo tó kilo mẹẹdọgbọn ni iwọn, ojo iná yoo dapọ mọ ẹjẹ, irawọ kan yoo já lati Ọrun sori ayé, lẹsẹ kan naa awọn olùgbé ayé yoo maa ri manamana bí o ti n kọ, wọn yoo si maa gbọ sísán ààrá, Oṣupa ati awọn irawọ tí ó bá kù kò ni lè tan imọlẹ dídán bi ti atẹyin wá, gẹrẹ lẹhin eyi, ọgbun ainisalẹ yoo ṣi silẹ, yoo si tú ogunlọgọ eéṣú jade ninu ikuuku èéfín. A o si fi agbara fun wọn lati dá awọn tí wọn ti gba àmì ẹranko naa loró, ati lati pa wọn lara. Awọn eniyan yoo wá ikú ṣugbọn wọn ki yoo ri i . Awọn adaniloró wọnyii yoo dabí silẹ fun ogun tí a ti dì ní àmùrè lati dá eniyan loró fun oṣù marun (Ifihan 6: 1-17; 8:1-13; 9:1-12; 16:17-21).

Lẹyin eyi, ẹgbaarun (200,000,000) ọkẹ ologun ti a ti pèsè silẹ lori ẹṣin ni a o tú jade sori ayé lati pa idamẹta awọn eniyan tí o wà laayé run nipa iná, èéfín ati iná tí n fi sulfuru jo tí ó n ti ẹnu wọn jade wá. Ayé yoo dabi ọrun apaadi nitori ìwà buburu ati òkunkun ati idaloro (Ifihan 9:13-19).

Ṣugbọn awọn idaloro wọnyi kò ní mú ki awọn eniyan ayé yi yí pada si Ọlọrun. Dipò eyi, kò ní sí ààfo lọkàn wọn fun ironupiwada (Ifihan 9:20, 21), wọn yoo maa bá ọnà ẹṣẹ, ibi ati ibọriṣa wọn lọ.

Awọn eniyan tí ó ku tí wọn kò fori balẹ fun ẹranko naa, tí wọn si ti gba àmi rẹ ni egbò kíkẹ yoo da. Òkun yoo dabi ẹjẹ yoo òkú eniyan. Omi ati orisun omi yoo dabi ẹjẹ pẹlu, nitori naa awọn eniyan kò ní rí omi mu. Agbara ríran oòrùn yoo gboná si i lati maa ta awọn eniyan lara, sibẹ wọn ki yoo ronupiwada. Kàkà ki wọn ronupiwada, wọn yoo maa sọ blasfemi si Ọlọrun Ọrun. Nigbà naa ni Ọlọrun yoo kọlu ijoko ijọba Aṣodi-si-Kristi, awọn eniyan yoo si maa gé ahọn wọn jẹ nitori irora. Nigbà ti òpin akoko ipọnju yi bá kù sí dẹdẹ, awọn ẹmi àìmọ yoo jade lọ lati ọdọ Satani ati Aṣodi-si-Kristi lati gbá ogun jọ lati bá Jesu Kristi Oluwa jagun nigbà tí Oun yoo tun pada ni akoko Ifarahàn Rẹ (Ifihan 16:1-14).

Ó mà ṣe o, ibi ati ibanujẹ ni o wà ninu aiwa ni imurasilẹ fun Ajinde Kinni! Bawo ni awọn ohun imulẹ-mofo ayé yi ti ṣe alai niye lori tó - bí a bá fi gbogbo nnkan wọnyii tọrẹ fun ẹni kọọkan wa dipò Ọlọrun ati oju rere Rẹ -- nigbà tí a bá wo àdánù tí ó wà ninu wọn! Ayérayé! Ayé ainipẹkun pẹlu awọn ẹni ẹbi, ẹni irira, alaimọ, apaniyan, agbèrè, eke, awọn ti n fi ọkunrin tabi obinrin bara wọn jẹ, olè, akorira-Ọlọrun, alainaani-Kristi! AYERAYE

Bi ẹnikẹni ba nforibalẹ fun ẹranko nì, ati aworan rẹ, ti o si gbà ami si iwaju rẹ tabi si ọwọ-rẹ,

On pẹlu yio mu ninu ọti-waini ibinu Ọlọrun, ti a tú jade li aini àbula sinu ago irunu rẹ: a o si fi iná ati sulfuru da a loró niwaju awọn angẹli mimọ, ati niwaju Ọdọ-Agutan:

Ĕfin oró wọn si nlọ soke titi lailai, nwọn kò si ni isimi li ọsán ati li oru, awọn ti nforibalẹ fun ẹranko na ati fun aworan rẹ, ati ẹnikẹni ti o ba si gbà àmi orukọ rẹ” (Ifihan 14:9-11).

Bawo ni o ti dùn pọ to lati wà pẹlu awọn eniyan mimọ, awọn ẹgbẹ alabukún ti a fi Ẹjẹ wẹ, ju lati wà pẹlu awọn ẹgbẹ ti kò ni ireti ti Iwe Mimọ ṣe apejuwe rẹ fun ni yii.

Ẹniti o ba ṣẹgun ni emi o fi eso igi iye nì fun jẹ, ti mbẹ lārin Paradise Ọlọrun.

Ẹniti o ba ṣẹgun ki yio farapa ninu ikú keji.

Ẹniti o ba ṣẹgun li emi o fi manna ti o pamọ fun jẹ, emi o si fun u li okuta funfun kan, ati sara okuta na orukọ titun ti a o kọ si i, ti ẹnikẹni kọ mọ bikoṣe ẹniti o gbà a.

Ẹniti o ba si ṣẹgun, ati ẹniti o ba pa iṣẹ mi mọ titi de opin, emi o fun u li aṣẹ lori awọn orilẹ-ède.

Ẹniti o ba ṣẹgun, on li a o fi aṣọ funfun wọ; emi ki yio pa orukọ rẹ rẹ kuro ninu Iwe Iye, ṣugbọn emi o jẹwọ orukọ rẹ niwaju Baba mi ati niwaju awọn angẹli rẹ.

Ẹniti o ba ṣẹgun, on li emi o fi ṣe ọwọn ninu tẹmpili Ọlọrun mi, on ki yio si jade kuro nibẹ mọ: emi o si kọ orukọ Ọlọrun mi si i lara, ati orukọ ilu Ọlọrun mi, ti iṣe Jerusalẹmu titun ti o nti ọrun sọkalẹ lati ọdọ Ọlọrun mi wá, ati orukọ titun ti emi tikarami.

Ẹniti o ba ṣẹgun li emi o fifun lati joko pẹlu mi lori itẹ mi, bi emi pẹlu ti ṣẹgun, ti mo si joko pẹlu Baba mi lori itẹ rẹ” (Ifihan 2:7, 11, 17, 26; 3:5, 12, 21).

Olubukun ati mimọ ni ẹniti o ni ipa ninu ajinde ekini na: lori awọn wọnyi ikú ekeji kò li agbara, ṣugbọn nwọn o jẹ alufa Ọlọrun ati ti Kristi, nwọn o si mā jọba pẹlu rẹ li ẹgbẹrun ọdún” (Ifihan 20:6).