Matteu 24:29-35; Juda 14, 15; Ifihan 1:7; 19:11-21

Lesson 166 - Junior

Memory Verse
“Ọlọrun wa mbọ, ki yio si dakẹ: iná yio má jó niwaju rẹ, ẹfufu lile yio si mā ja yi i ka kiri” (Orin Dafidi 50:3).
Notes

Lojukanna lẹhin ipọnju ọjọ wọnni li õrun yio ṣõkun, oṣupá ki yio si fi imọlẹ rẹ hàn, awọn irawọ yio ti oju ọrun já silẹ, agbara oju ọrun li a o si mi titi:

Nigbana li àmi Ọmọ-enia yio si fi ara hàn li ọrun; nigbana ni gbogbo ẹya aye yio kānu, nwọn o si ri Ọmọ-enia ti yio ma ti oju ọrun bọ ti on ti agbara ati ogo nla.

Yio si rán awọn angẹli rẹ ti awọn ti ohùn ipe nla, nwọn o si kó gbogbo awọn ayanfẹ rẹ lati ori igun mẹrẹrin aiye jọ, lati ikangun ọrun kan lọ de ikangun keji.

Njẹ ẹkọ owe lara igi ọpọtọ: nigbati ẹka rẹ ba yọ titun, ti o ba si ru ewé, ẹnyin mọ pe igba ẹẹrun sunmọ etile:

Gẹgẹ bẹẹli ẹnyin, nigbati ẹnyin ba ri gbogbo nkan wọnyi, ki ẹ mọ pe o sunmọ etile tan lẹhin ilẹkun.

Lõtọ ni mo wi fun nyin, iran yi ki yio rekọja, titi gbogbo nkan wọnyi yio fi ṣẹ.

Ọrun on aiye yio rekọja, ṣugbọn ọrọ mi ki yio rekọja” (Matteu 24:29-35).

Kiyesi i, o mbọ ninu awọsanma; gbogbo oju ni yio si ri i, ati awọn ti o gún u li ọkọ pẹlu; ati gbogbo orilẹ-ède aiye ni yio si mā pohunrere ẹkún niwaju rẹ. Bẹẹna ni Amin” (Ifihan 1:7).

Jesu Oluwa yoo pada wá lati ibi Ase-alẹ Igbeyawo Ọdọ-agutan pẹlu awọn eniyan mimọ Rẹ ti i ṣe aṣẹgun lati gbẹsan ẹjẹ awọn iranṣẹ Rẹ. Wiwa Rẹ yoo jẹ ninu ogo ati agbara to bẹẹ ti imọlẹ didan Rẹ yio pa awọn ẹni buburu run ti o ti gbá ogun jọ lati dojukọ igbekalẹ Ijọba ododo Rẹ (II Tẹssalonika 2:8; Ifihan 16:12:14; 19:11-12).

Oun yoo pada pẹlu ẹgbẹgbaarun awọn eniyan mimọ Rẹ pẹlu idajọ gbigbona. “ Ẹsẹ rẹ yio si duro li ọjọ na lori oke Olifi” (Sekariah 11:15; 19:16). Awọn ọba aye, awọn ẹni nla, ati awọn ọlọrọ yoo fi ara wọn pamọ, wọn o si wi fun awọn apata pe, “Ẹ wólù wa, ki ẹ si fi wa pamọ kuro loju ẹniti o joko lori itẹ, ati kuro ninu ibinu Ọdọ-Agutan na” (Ifihan 6:16). Wọn o si ju oriṣa wura ati fadaka wọn si awọn ekute ati adan (Isaiah 2:19, 20; Luku 23:27-31; Jakọbu 5:1-6).

Gẹgẹ bi ọrọ asọtẹlẹ, Kristi ni lati pada wa ni iran ti a wà yi. O wi pe “iran yi (iran ti yoo ri imuṣẹ awọn ami wọnyi) ki yio rekọja, titi a o fi mu gbogbo nkan wọnyi ṣẹ” (Marku 13:30). Igi ọpọtọ ti bẹrẹ si i ruwe, lai si aniani, ewé rẹ fẹrẹ gbooro to ti igbà ẹẹrun (Marku 13:28, 29). Awọn ami ti Jesu sọ pe yoo ṣẹ ti ṣẹ ná, ohun gbogbo si wà ni imurasilẹ fun ọjọ nla yii, niwọn iba oye wa, afi ohun kan ni o kù, eyi ni pe Iyawo kò tii mura tan patapata (Matteu 24:3-14; 1 Tẹssalonika 3:13; Ifihan 20:6).

Iran ti o gbọ iwaasu Noa ni Ikun Omi de ba (Gẹnẹsisi 6:9, 14-22; II Peteru 2:5). Awọn Ju ti wọn gbọ asọtẹlẹ iparun Jerusalẹmu ri imuṣẹ rẹ lẹhin ogoji ọdún (Matteu 24:1, 2). Nitori naa, eyi mu ki a gbagbọ pe iran yii ti o ri imuṣẹ asọtẹlẹ àmi wọnyi yoo ri ipadabọ Ọmọ Ọlọrun pẹlu.

Ifarahan Kristi Lẹẹmeji

Ifarahàn Jesu lẹẹmeji ni yoo wà ninu wiwá Rẹ lẹẹkan ṣoṣo. ni akọkọ Oun yoo fara hàn ni awọsanma gẹgẹ bi ole ni oru, nigbà ti a o ṣe ipalarada awọn eniyan mimọ ti wọn ṣẹgun patapata, ti wọn ti sun tabi ti wọn wà laaye nigbà naa lati lọ pade Rẹ (Matteu 24:14, 36, 42, 44; Johannu 14:3; I Kọrinti 15:51, 52; I Tẹssalonika 4:13-18). Awọn ẹlẹṣẹ ki yoo ri I ni akoko yi, ayafi awọn ti oju ẹmi wọn ṣi si ti ipadabọ rẹ ti wọn si wa ni imurasilẹ ni yoo ri I. Ifarahàn keji yi ni ẹkọ wa yi duro le lori, ani Ifarahàn Kristi (Matteu 24:30, 31; Iṣe Awọn Apọsteli 1:11; 2 Tẹssalonika 1:7-10). Nigba yi Oun o pada wá pẹlu ẹgbẹgbaarun awọn eniyan mimọ Rẹ, “gbogbo oju ni yoo si ri i” (Ifihan 1:7).

Enoku … ẹni keje lati ọdọ Adamu, sọtẹlẹ … wipe, Kiyesi i, Oluwa mbọ pẹlu ẹgbẹgbārun awọn enia rẹ mimọ,

Lati ṣe idajọ gbogbo enia, lati dá gbogbo awọn alaiwabi-Ọlọrun lẹbi niti gbogbo iṣe aiwa-bi-Ọlọrun wọn, ti nwọn ti fi aiwabi-Ọlọrun ṣe, ati niti gbogbo ọrọ lile ti awọn ẹlẹṣẹ alaiwabi-Ọlọrun ti sọ si i” (Juda 14, 15).

Ni akoko Ipalarada, Oun yoo wá bi Ọkọ Iyawo lati mu Iyawo Rẹ Mimọ ati alai leeri sọdọ ara Rẹ (Matteu 25:1-10; Efesu 5:27). Nigbà Ifarahàn, Oun yoo pada pẹlu Iyawo Rẹ lati wá jọba lori awọn orilẹ-ède ati lati gbe Ijọba Rẹ kalẹ fun ẹgbẹrun ọdún, nigbà ti awọn eniyan mimọ ti wọn ti jinde ati awọn aṣẹgun ti a ti ṣe logo yoo ba A jọba lori ilẹ aye (Ifihan 2:26, 27; 5:10; 12:5; 19:14). Ni akoko Ipalarada, Oun yoo wa pade awọn eniyan mimọ ni awọsanma (I Tẹssalonika 4:17). Ni akoko Ifarahàn, Oun yoo pada wá si aye pẹlu ọlá nla Rẹ. Ni akoko Ifarahan, ẹsẹ Rẹ yoo duro lori Oke Olifi, nibi ti O gbe ti koge re Ọrun ni nnkan bi ẹgbaa (2000) ọdun sẹhin (Sekariah 14:4, 5; Iṣe Awọn Apọsteli 1:11). Gẹgẹ bi ileri Ọlọrun, ipalarada le ṣẹlẹ nigbakigba ni airo tẹlẹ (Matteu 24:26-42). Ṣugbọn Ifarahan Rẹ ki yoo ṣẹlẹ titi a o fi fi Aṣodi-si-Kristi hàn, ti Ipọnju Nla yoo si wà lori ilẹ aye (Daniẹli 12:1; II Tẹssalonika 1:7-10; Ifihan 8, 9, 10).

Ijọba Ọrun

Ifarahan Kristi ni yoo mu ijọba Rẹ bẹrẹ lori ilẹ aye. Akoko Ijọ eyi ti o bẹrẹ nigba ti a tú Ẹmi Mimọ jade sori awọn ọgọfa eniyan ni Yara Oke, ni ọjọ Pẹntikọsti yoo dopin ni akoko Ipalarada. Lẹhin Ipọnju Nla, nigbà ti Jesu yoo mu awọn eniyan mimọ ti wọn ti jinde ati awọn aṣẹgun ti a ti ṣe logo pada sori ilẹ aye ti yoo si ji awọn ti o ti kú ikú ajẹriku ni akoko Ipọnju Nla dide, igbesẹ pataki yoo bẹrẹ ninu Ijọba Ọrun.

Iṣisẹ kinni ninu Ijọba Ọrun ni gbigbe Ijọba naa kalẹ ninu ọkan kọọkan. Ironupiwada ni ẹnu-ọna abawọle si Ijọba naa (Matteu 3:2; 4:17; 6:10; 10:7; 11:11; Luku 17: 20, 21). Ọba yoo wọ inu ọkàn ti o ronupiwada tootọ, ẹni naa yoo si di ọmọ ibilẹ Ọrun nitori pe nibi ti Ọba wà ni Ijọba Rẹ yoo wà pẹlu.

Ijọba naa si wà ninu aye ni ọna miran. Eyi ni agbajọ awọn Onigbagbọ tootọ ti wọn pejọ lati sin Ọlọrun, lati tan Ihinrere kalẹ ati lati wà ni imurasilẹ -- lati pese ọkàn wọn silẹ -- fun Ipalarada Ijọ Ọlọrun, ipadabọ Ọba. Laarin awọn ti wọn pejọ ni orukọ Oluwa ni Ijọ ti a kò le fi oju ri wà, eyi ti Bibeli pe ni Iyawo Kristi. Eyi pẹlu jẹ itẹsiwaju pataki ninu eto Ijọba Ọrun (Ifihan 19:7, 8; 21:2, 9).

Ni akoko Ipalarada, a o gbà Iyawo soke lọ si ibi Ase Alẹ Igbeyawo Ọdọ-agutan nibi ti Ọba yoo wà ninu igunwa ati ọlá nla Rẹ, ati pẹlu bi Ọdọ-agutan Ọlọrun ti a ti pa lati ipilẹṣẹ aye (Ifihan 1:12-18; 5:6-14; 13:8). Nigbà ti akoko ba to ti ohun gbogbo laye ati lọrun ba de gongo, awọn eniyan mimọ wọnyi, gẹgẹ bi ẹgbẹ ogun Ọrun, yoo pada pẹlu Kristi -- Ọba wọn – lati tẹ itẹ laye yi ati lati ba A jọba fun ẹgbẹrun (1,000) ọdun. Awọn eniyan mimọ ti wọn ku iku ajẹri-ku ni akoko Ipọju Nla yoo jinde pẹlu lati ba Kristi jọba ni akoko yii. Akoko yi ni Ijọba Ẹgbẹrun (1,000) Ọdun ti Kristi, iṣisẹ ti o tun ga ninu eto Ijọba Ọlọrun ti logo (Isaiah 35:1-10; 65:18-25; Mika 4:1-4; Sekariah 14:4-21).

Lẹhin Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun, a o tu Satani silẹ fun sáà kan, awọn orilẹ-ède aye – lori eyiti Kristi ati awọn eniyan mimọ Ọlọrun ti jọba – ni a o fun ni anfaani lati yan ijọba ti o tẹ wọn lọrun. Wọn kò i ti le gbagbé ijọba ododo ti Kristi; ṣugbọn sibẹsibẹ ọkẹ aimọye ologun eniyan yoo dimọ pọ pẹlu Satani, ọta-iyọta Ọlọrun, wọn yoo si kọlu ilu mimọ ni, nibi ti Kristi gbé n jọba. Wọn yoo ba Kristi ati awọn eniyan mimọ Ọlọrun jagun, wọn yoo si sa ipa wọn lati bi ilu naa wó, ki wọn rọ Kristi, Ọba ilu naa loye, ki wọn ki o le ja Ijọba naa gba fun ara wọn. Ṣugbọn iná yoo sọkalẹ lati Ọrun wà yoo si jó awọn eniyan buburu wọnyi run, ti o fi hàn nipa iwa wọn wipe wọn fẹ ọna ibi, aiṣododo ati iparun, bi o tilẹ ṣe pe wọn ti ni anfaani lati wà labẹ akoso Kristi lakoko Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun ti alaafia, otitọ, aiṣegbè ati ododo (Ifihan 20:7-10). “Ọkàn enia (ti kò di atunbi) kún fun ẹtan jù ohun gbogbo lọ, o si buru jai! Tani o le mọ ọ? Emi, OLUWA, ni iwá àwari ọkàn enia, emi ni ndan inu wò, ani lati fi fun olukuluku gẹgẹ bi ọna rẹ, ati gẹgẹ bi eso iṣẹ rẹ” (Jeremiah 17:9, 10).

Nigbà ti ogun ikẹhin yi ba pari, Ọlọrun yoo pe awọn ti a kò ti dá lẹjọ wá sibi Itẹ Idajọ Nla Funfun, lati jihin ohun ti wọn ti ṣe ninu ara. Adagun iná yoo gba awọn olugbe rẹ ti yoo wà nibẹ titi ayeraye ailopin, Ọlọrun yoo si pa ayé ati Ọrun run ki o le sọ ohun gbogbo di ọtun. Kò si ohun kan ti yoo kù lati ran awọn ẹni irapada leti ẹṣẹ, ibanujẹ, aisan tabi ijatilẹ. Ọlọrun yoo nu omije gbogbo nù kuro ni oju wọn, wọn o si lo ayeraye pẹlu Rẹ ni ilẹ ti ọjọ ki i ṣa (Ka Ifihan 14:13; 21:1-27; 22:1-21). Eyi ni iṣisẹ ikẹhin ati gongo pipe ẹwa Ijọba Ọlọrun. Nigbà yi ni Jesu yoo gbé Ijọba pada fun Ọlọrun lẹhin ti o ti pari iṣẹ ti O yọọda ara Rẹ fun, ani Idande eniyan, ati lati ṣẹtẹ ẹṣẹ ati Satani (I Kọrinti 15:22-28).

Ireti Ajinde

Nisinsinyi, Kristi ni “ọkunrin ọlọla” naa ti o re “ilu okere lọ igba ijọba fun ara rẹ” (Luku 19:11-19). Oun yoo pada wa gba ijọba yi ni pipe ni ayé yi nigba Ifarahan Rẹ. Nigbà naa ni gbogbo eekun yoo wolẹ, ti gbogbo ahọn yoo si jẹwọ nitori ti a ti fi orukọ kan fun Un ti o tayọ orukọ gbogbo, nitori ti Oun kò kọ lati tọ iku wo fun ẹni kọọkan ki awa ti o fẹ Ẹ, ti a si n sin In le ni iye ainipẹkun (Romu 14:11; Filippi 2:5-11).

Gbogbo aye n kerora fun ọjọ idande rẹ, nigbà ti Jesu yoo tun pada wá si aye lati ṣakoso ati lati jọba. Ohun ẹlẹmi gbogbo ni o n fẹ ni ipin ninu aye titun naa. Igi igbẹ kò nilaari mọ, kò si ohun ti o lẹwa nisinsinyi bi yoo ti ri nigbà ti Jesu yoo jọba lori ilẹ aye yii (Isaiah 35:1-10; 55:12, 13). Melomelo ni awa, gẹgẹ bi Onigbagbọ, ti “nkerora ninu ara wa” to, “awa nduro de isọdọmọ, ani idande ara wa” (Romu 8:23). Nipa Eto Igbala Ọlọrun, a le ni iriri idalare, isọdi-mimọ patapata, ifi Ẹmi Mimọ ati ina wọni, ki a si wà ni imurasilẹ de Kristi, bi O tilẹ de nisinsinyi. Ṣugbọn oungbẹ kan wà ni ọkàn wa ati ikerora kan lati odo inu wa fun idande ara wa, ki a le wa lae lọdọ Kristi: “Nitori a o sọ ẹda tikararẹ di ominira kuro ninu ẹrú idibajẹ, si omnira ogo awọn ọmọ Ọlọrun” Romu 8:21; I Johannu 3:1-3). Ṣugbọn a ni ireti yi pe, bi Ẹmi Ẹni ti o ji Kristi dide kuro ninu okú ba n gbe inu wa, Ẹni ti o ji Kristi dide kuro ninu okú yoo sọ ara kikú wa di ààyè nipa Ẹmi Rẹ ti o n gbé inu wa (Romu 8:11).

Awọn Iṣẹlẹ Pataki ni Akoko Ifarahan Kristi

Nigbà Ifarahàn Kristi, tabi ti O ba ti fara hàn, ohun pataki pupọ ni yoo ṣẹlẹ. Ipadabọ Kristi ni yoo jẹ ohun ti o ṣe pataki ju lọ ni akoko yi. Gbogbo nnkan miran kàn rọ mọ ọn ni.

Awọn Ju yoo wo Ẹni ti wọn ti gún ni ọkọ. Ṣaaju eyi, wọn o ti maa ṣọfọ, wọn o si maa gbadura pe ki O wá gbà wọn kuro ninu ipọnju ati wahala wọn ni akoko Ipọnju Nla. Wọn o gba Kristi ni Messia wọn ni akoko Ifarahàn (Isaiah 25:9; 66:8-13; Esekiẹli 20:40-42; 36:24; Amosi 9:15; Sekariah 12:10; 13:6; Ifihan 1:7).

Awọn eniyan mimọ Ọlorun yoo ti gbà èrè wọn nigbà Ase-alẹ Igbeyawo Ọdọ-agutan, fun ijolootọ wọn; nigbà Ifarahàn Kristi a o fun wọn laṣẹ lori awọn ilu gẹgẹ bi ipa ati ijolootọ wọn ti atẹhin wa (Luku 19:11-27).

Idajọ ni ipadabọ Kristi yoo jẹ fun gbogbo orilẹ-ède alaaye. Oun yoo gbé Itẹ Idajọ Rẹ kalẹ ki O le mu ohun gbogbo ti n mu ni kọsẹ ati awọn ti n dá ẹṣẹ kuro (Matteu 13:40-43; 25:31-46). Nitootọ gbogbo akoko Ijọba Ẹgbẹrun (1,000) ọdun ni a o fi ṣe idajọ ti Kristi ati awọn eniyan mimọ yoo joko bi onidajọ lori awọn orilẹ-ède aye, niwọn igbà ti o ṣe pe abẹ akoso ododo ti Jesu ati awọn eniyan mimọ Rẹ ni awọn orilẹ-ède wà.

Ogun Armageddoni

Ṣugbọn ohun pataki ti yoo ṣẹlẹ ni akoko Ifarahàn Kristi, ṣiwaju Ijọba Rẹ ti Ẹgbẹrun ọdun ni Ogun Armageddoni. Johannu Ayanfẹ ri Kristi ti O n bọ wá sinu aye lori ẹṣin funfun, o si wi pe O n ṣe idajọ ninu ododo, O si n jagun (Ifihan 19:11-16) Iparun pupọ ti o si buru jai ni yoo wà ni ọjọ naa (Ifihan 14:20; 17:14; 19:11-21). Awọn ẹlẹṣẹ ti wọn ba doju kọ Ọ ni ao fi agbara nla Rẹ parun (Isaiah 13:9; 29:5-7; 24:20). Awọn ẹlẹṣẹ wọnyi tabi awọn ẹgbẹ ọmọ ogun Aṣodi-si-Kristi, yoo jẹ ti a ti gba jọ lati gbogbo orilẹ-ède agbaye, nipasẹ awọn ẹmi buburu ti Satani ati Aṣodi-si-Kristi ati woli eke ran sori ilẹ aye (Ifihan 16:13) ni akoko Ipọnju Nla, ni imurasilẹ fun ogun ti Satani ti mọ tẹlẹ pe o n bọ wa (Ifihan 16:12-14). Eyi yoo jẹ ọkan pataki ninu ọna ti Satani yoo gbà sa ipa rẹ lati já Ijọba gbà kuro lọwọ Kristi.

Mo si ri ọrun ṣi silẹ, si wo o, ẹṣin funfun kan; ẹniti o si joko lori rẹ ni a npe ni Olododo ati Olõtọ, ninu ododo li o si nṣe idajọ, ti o si njagun.

Oju rẹ dabi ọwọ iná, ati li ori rẹ ni ade pupọ wà; o si ni orukọ kan ti a kọ, ti ẹnikẹni kò mọ, bikoṣe on tikararẹ.

A si wọ ọ li aṣọ ti a tẹ bọ inu ẹjẹ: a si npè orukọ rẹ ni Ọrọ Ọlọrun.”

Awọn ogun ti mbẹ li ọrun ti a wọ li aṣọ ọgbọ wiwẹ, funfun ati mimọ, si ntọ ọ lẹhin lori ẹṣin funfun.

Ati lati ẹnu rẹ ni idà mimu ti njade lọ, ki o le mā fi iṣá awọn orilẹ-ède: on o si mā fi ọpá irin ṣe akoso wọn: o si ntẹ ifúnti irunu ati ibinu Ọlọrun Olodumare.

O si ni lara aṣọ rẹ ati ni itan rẹ orukọ kan ti a kọ: ỌBA AWỌN ỌBA, ATI OLUWA AWỌN OLUWA.

Mo si ri angẹli kan duro ninu õrun; o si fi ohùn rara kigbe, o nwi fun gbogbo awọn ẹiyẹ ti nfò li agbedemeji ọrun pe, Ẹ wá, ẹ si kó ara nyin jọ pọ si àse-alẹ nla Ọlọrun;

Ki ẹnyin ki o le jẹ ẹran-ara awọn ọba, ati ẹran-ara awọn olori ogun, ati ẹran-ara awọn enia alagbara, ati ẹran awọn ẹṣin, ati ti awọn ti o joko lori wọn, ati ẹran-ara enia gbogbo, ati ti omnira, ati ti ẹrú, ati ti ewe ati ti àgba.

Mo si ri ẹranko na ati awọn ọba aiye, ati awọn ogun wọn ti a gbájọ lati ba ẹniti o joko lori ẹṣin na ati ogun rẹ jagun.

A si mu ẹranko na, ati woli eke nì pẹlu rẹ, ti o ti nṣe iṣẹ iyanu niwaju rẹ, eyiti o ti fi ntàn awọn ti o gbà àmi ẹranko na ati awọn ti nforibalẹ fun aworan rẹ jẹ. Awọn mejeji yi li a sọ lāye sinu adagun iná ti nfi sulfuru jo.

Awọn iyoku li a si fi idà ẹniti o joko lori ẹṣin na pa, ani idà ti o ti ẹnu rẹ jade: gbogbo awọn ẹiyẹ si ti ipa ẹran ara wọn yó” (Ifihan 19:11-21).

Mo si ri angẹli kan nti ọrun sọkalẹ wá, ti on ti iṣika ọgbun ni, ati ẹwọn nla nkan li ọwọ rẹ.

O si di dragoni na mu, ejò atijọ nì, ti iṣe Eṣu, ati Satani, o si dè e li ẹgbẹrun ọdún.

O si gbe e sọ sinu ọgbun na, o si ti i, o si fi èdidi di i lori rẹ, ki o má bā tan awọn orilẹ-ède jẹ mọ titi ẹgbẹrun ọdún na yio fi pé: lẹhin eyi, a kò le ṣai tu u silẹ fun igba diẹ.

Mo si ri awọn itẹ, nwọn si joko lori wọn, a si fi idajọ fun wọn: mo si ti ọkàn awọn ti a ti bẹ lori nitori ẹri Jesu, ati nitori ọrọ Ọlọrun, ati nitori awọn ti kò si foribalẹ fun ẹranko na, ati fun aworan rẹ, tabi ti kò si gbà àmi rẹ ni iwaju wọn ati li ọwọ wọn; nwọn si wà lāye, nwọn si jọba pẹlu Kristi li ẹgbẹrun ọdún” (Ifihan 20:1-4).