Isaiah 11:10-16; Matteu 25:31-46; Luku 19:11-27; 22:28-30; Filippi 2:9-11; Ifihan 20:1-6

Lesson 167 - Junior

Memory Verse
“Lõtọ ni mo wi fun nyin, niwọn bi ẹnyin ti ṣe e fun ọkan ninu awọn arakọnrin mi wọnyi ti o kere julọ ẹnyin ti ṣe e fun mi” (Matteu 25:40).
Notes

Nigbati Ọmọ-enia yio wá ninu ogo rẹ, ati gbogbo awọn angẹli mimọ pẹlu rẹ, nigbana ni yio joko lori ìtẹ ogo rẹ:

Niwaju rẹ li a o si kó gbogbo orilẹ-ède jọ: yio si yà wọn si ọtọ kuro ninu ara wọn, gẹgẹ bi oluṣọ-agutan ti iyà agutan rẹ kuro ninu ewurẹ:

On o si fi agutan si ọwọ ọtún rẹ, ṣugbọn awọn ewurẹ si ọwọ osi.

Nigbana li Ọba yio wi fun awọn ti o wà li ọwọ ọtun rẹ pe, Ẹ wá, ẹnyin alabukun-fun Baba mi, ẹ jogún ijọba, ti a ti pese silẹ fun nyin lati ọjọ ìwa:

Nitori ebi pa mi, ẹnyin si fun mi li onjẹ: ongbẹ gbẹ mi, ẹnyin si fun mi li ohun mimu: mo jẹ alejò, ẹnyin si gbà mi si ile:

Mo wà ni ihoho, ẹnyin si daṣọ bò mi: mo ṣe aisan, ẹnyin si bojuto mi: mo wà ninu tubu, ẹnyin si tọ mi wá.

Nigbana ni awọn olõtọ yio da a lohun wipe, Oluwa, nigbawo li awa ri ti ebi npa ọ, ti awa fun ọ li onjẹ? Tabi ti ongbẹ, ngbẹ ọ, ti awa fun ọ li ohun mimu?

Nigbawo li awa ri ọ li alejò, ti a gbà ọ si ile? Tabi ti iwọ wà ni ihoho, ti awa daṣọ bò ọ?

Tabi nigbawo li awa ri ti iwọ ṣe aisan, ti a bojuto ọ? Tabi ti iwọ wà ninu tubu, ti awa si tọ ọ wá?

Ọba yio si dahùn yio si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, niwọn bi ẹnyin ti ṣe e fun ọkan ninu awọn arakọnrin mi wọnyi ti o kere julọ ẹnyin ti ṣe e fun mi.

Nigbana ni yio si wi fun awọn ti ọwọ òsi pe, Ẹ lọ kuro lọdọ mi, ẹnyin ẹni egun, sinu iná ainipẹkun, ti a ti pèse silẹ fun Eṣu ati fun awọn angẹli rẹ:

Nitori ebi pa mi, ẹnyin kò si fun mi li onjẹ: ongbẹ gbẹ mi, ẹnyin kò si fun mi li ohun mimu:

Mo jẹ alejò, ẹnyin kò gbà mi si ile: mo wà ni ihoho, ẹnyin kò si daṣọ bò mi: Mo ṣàisan, mo si wà ninu tubu, ẹnyin kò bojuto mi.

Nigbana ni awọn pẹlu yio dahùn wipe, Oluwa, nigbawo li awa ri ti ebi npa ọ, tabi ti ongbẹ ọ, tabi ti iwọ jẹ alejò, tabi ti iwọ wà ni ihoho, tabi ninu aisan, tabi ninu tubu, ti awa kò si ṣe iranṣẹ fun ọ?

Nigbana ni yio da wọn lohun wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, niwọn bi ẹnyin kò ti ṣe e fun ọkan ninu awọn ti o kere julọ wọnyi, ẹnyin kò ṣe e fun mi.

Awọn wọnyi ni yio si kọja lọ sinu iya ainipẹkun: ṣugbọn awọn olõtọ si iye ainipẹkun” (Matteu 25:31-46).

Lẹhin ti ifarahàn Kristi ba ti kọja tan ti a si jagun Armageddoni ti a si bori awọn ti o dide si Kristi ati awọn ẹgbẹ ọmọ-ogun ti Ọrun, ohun ti yoo wa tẹle awọn ohun ti o ti ṣẹlẹ wọnyi ninu eto nla Ọlọrun lati ayebaye, ni gbigbé Ijọba Kristi kalẹ ninu aye. Ijọba yii ni a n pe ni Ijọba Ẹgbẹrun (1,000) ọdun tabi Igba Alaafia. Yoo wà fun ẹgbẹrun ọdún, yoo si jẹ akoko ayọ pupọ, paapaa ju lọ fun awọn ẹni irapada, nitori egun kò ni si mọ, a o si gbé Satani dè. Oun kò ni le tan awọn orilẹ-ède jẹ mọ titi opin ẹgbẹrun ọdun. Yoo jẹ akoko ti a o fi ododo ṣe idajọ. Kristi ni i ṣe Adajọ Agba, awọn eniyan mimọ Rẹ aṣẹgun ni a si le pe ni “adajọ kékèké.” Idajọ yii ni a n pe ni Idajọ awọn Orilẹ-ède.

Awọn Idajọ ninu Eto Ọlọrun

Kò si ọrọ “Idajọ gbogbo-gbò” ninu Iwe Mimọ. Bi awọn miran ti ṣe n lo o ti dá ariyanjiyan pupọ silẹ, eyi si ti yọri si oriṣiriṣi ero ati awọn ẹkọ ti o lodi si Bibeli. Ṣugbọn ọna kan wà lati lo ọrọ naa ni ọna ti o tọna. Idajọ Ọlọrun wà fun gbogbo eniyan lọna bayii pe, gbogbo eniyan ni a o ṣe idajọ rẹ (Romu 14:10; II Kọrinti 5:10), ṣugbọn kò tumọ si wi pe gbogbo eniyan ni a o ṣe idajọ fun nigbà kan naa.

Kò tilẹ mu ọgbọn wa rara lati sọ pe awọn eniyan mimọ ti a gbà soke lọ si ibi Ase-alẹ Igbeyawo Ọdọ-Agutan, ati awọn eniyan mimọ ti akoko Ipọnju Nla ti a ji dide nigba Ifarahàn Kristi, ninu ara ologo ti wọn si joko pẹlu Kristi lori aga idajọ, yoo tun duro pẹlu awọn ẹni irira, awọn apaniyan, awọn abanijẹ, awọn ọmuti, awọn eleke, ati awọn oluṣe buburu lati gba idajọ. A kò ni dá awọn eniyan mimọ ti wọn ti ji dide ni Ajinde Kinni lẹjọ ni ibi Itẹ Idajọ Nla Funfun. Awọn ẹlomira n kọ pẹlu atilẹhin awọn ẹsẹ Iwe-Mimọ ti a le fara mọ, wi pe kaka bẹẹ, awọn eniyan mimọ wọnyi, yoo joko lori aga idajọ pẹlu Kristi nibi Itẹ Idajọ Nla Funfun, lati ṣe idajọ awọn ẹlẹṣẹ ti yoo fara hàn nibẹ. Nitori naa a le ri i wi pe awọn Onigbagbọ ti a ti ji dide tabi ti a ti pa lara dà ti wọn si ba Kristi joko lori itẹ ati aga idajọ ati aṣẹ, ni a ti ṣe idajọ wọn ṣiwaju akoko ti Itẹ Idajọ Nla Funfun.

Awọn Onigbagbọ, gẹgẹ bi ẹlẹṣẹ ni a ti ṣe idajọ wọn ninu Kristi. Nigbà ti Kristi kú, O gba iya ẹṣẹ ẹni kọọkan jẹ tikara Rẹ. Nigbà ti a ba fi Ẹjẹ Rẹ wẹ ọkàn kan, ti a si wẹ ẹṣẹ rẹ nù kuro, ẹni naa kò si labẹ idajọ mọ (I Timoteu 5: 24). Kristi ti kó ẹṣẹ rẹ lọ. A ti ṣe ètutu fun ẹṣẹ wọnyi nipa ikú Kristi niwọn igbà ti Kristi ti gba iyà gbogbo wa jẹ. Niwọn igba ti ẹni ti o ṣẹṣẹ di atunbi yii ba wà ninu Ẹjẹ Jesu, ti kò si pada sinu ẹṣẹ mọ, o bọ lọwọ ẹbi tabi idajọ (Romu 8:1). (Ka Johannu 5:24; 3:17-19 pẹlu, ki o si ranti pe, itumọ awọn ọrọ wọnyi: dalẹbi ati ẹbi ninu Iwe Mimọ ja si dalẹjọ tabi idajọ).

Nigbati nwọn si ngbọ nkan wọnyi, o fi ọrọ kún u, o si pa owe kan, nitoriti o sunmọ Jerusalẹmu, ati nitoriti nwọn nrò pe, ijọba Ọlọrun yio farahàn nisisiyi.

O si wipe, Ọkọnrin ọlọlá kan rè ilu òkere lọ igbà ijọba fun ara rẹ, ki o si pada.

O si pè awọn ọmọ-ọdọ rẹ mẹwa, o fi mina mẹwa fun wọn, o si wi fun wọn pe, Ẹ mā ṣowo titi emi o fi de.

Ṣugbọn awọn ọlọtọ ilu rẹ korira rẹ, nwọn si rán ikọ tẹle e, wipe, Awa kò fẹ ki ọkọnrin yi jọba lori wa.

O si ṣe, nigbati o gbà ijọba tan, ti o pada de, o paṣẹ pe, ki a pè awọn ọmọ-ọdọ wọnni wá sọdọ rẹ, ti on ti fi owo fun nitori ki o le mọ iye ere ti olukuluku fi iṣowo jẹ.

Eyi ekini wá, o wipe, Oluwa, mina rẹ jère mina mẹwa si i.

O si wi fun u pe, O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdo rere: nitoriti iwọ ṣe olõtọ li ohun kikini, gbà aṣẹ lori ilu mẹwa.

Eyi ekeji si wá, o wipe Oluwa, mina rẹ jère mina marun.

O si wi fun u pẹlu pe, iwọ joye ilu marun.

Omiran si wá, o wipe Oluwa, wò mina rẹ ti mbẹ li ọwọ mi ti mo di sinu gèle:

Nitori mo bẹru rẹ, ati nitoriti iwọ ṣe onrorò enia: iwọ a ma mu eyi ti iwọ kò fi lelẹ, iwọ a si ma ká eyi ti iwọ kò gbin.

O si wi fun u pe, Li ẹnu ara rẹ li emi o ṣe idajọ rẹ, iwọ ọmọ-ọdọ buburu. Iwọ mọ pe onrorò enia ni mi, pe emi a mā mu eyi ti emi ko fi lelẹ, emi a si mā ká eyi ti emi kò gbin.

“Ĕha si ti ṣe ti iwọ kò fi owo mi si ile elé, nigbati mo ba de, emi iba si bère rẹ ti on ti elé?

O si wi fun awọn ti o duro leti ibẹ pe, Ẹ gbà mina na lọwọ rẹ, ki ẹ si fii fun ẹniti o ni mina mẹwa.

Nwọn si wi fun u pe, Oluwa, o ni mina mẹwa.

Mo wi fun nyin pe, Ẹnikẹni ti o ni, li a o fifun; ati lọdọ ẹniti kò ni, eyi na ti o ni li a o gbà lọwọ rẹ.

Ṣugbọn awọn ọtá mi wọnni, ti kò fẹ ki emi ki o jọba lori wọn, ẹ mu wọn wá ihinyi, ki ẹ si pa wọn niwaju mi” (Luku 19:11-27).

A o ṣe idajọ awọn eniyan mimọ gẹgẹ bi iṣẹ wọn. Eyi le má jẹ lori ilẹ ayé. O ṣe e ṣe ki eyi jẹ ọkan ninu awọn ohun pataki ti a o ṣe ni akoko Ase-alẹ Igbeyawo Ọdọ-Agutan, nitori pe awọn eniyan mimọ yoo ba Kristi pada bọ gẹgẹ bi oloye. O dabi ẹni pe Iwe Mimọ fi idi rẹ mulẹ pe a o ti fun wọn ni aṣẹ. A o fun wọn ni ipo ọlá ni Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun ti Kristi (I Tẹssalonika 4:13-18; II Tẹssalonika 1:6-10; Ifihan 5:9, 10; 19:11-16). Idajọ fun ẹṣẹ ti a ti fi ji awọn eniyan mimọ wọnyi ti kọja. Gẹgẹ bi a ti ri i, a ti ṣe idajọ yii ni Kalfari (Heberu 9:28). Pipin ere fun awọn eniyan mimọ fun iṣe ati iṣẹ ododo wọn ni yoo ṣẹlẹ niwaju “itẹ-idajọ Kristi”, eyi ti a mọ pe yoo waye ni igba Ase-Alẹ Igbeyawo Ọdọ-Agutan.

Awọn eniyan orilẹ ati ède ti wọn wà laye ni akoko Ifarahàn, awọn ti a kò fi didan ogo Rẹ parun nigba ti Kristi pada wá, gẹgẹ bi awọn ti o dojuja kọ Ọ, ni a o da lẹjọ ni akoko Ijọba Ẹgbẹrun ọdun, nigba ti gọngọ idajọ yoo ma sọ leralera lori awọn orilẹ-ède ti ki i ṣe Onigbagbọ ti wọn wa láyé nigba naa (Ifihan 2:27; 19:15). Kristi ni Onidajọ alaaye ati oku (Iṣe Awọn Apọsteli 10:42; II Timoteu 4:1; I Peteru 1:3-5). Ijọ Ọlọrun tabi awọn eniyan mimọ aṣẹgun ti a ti gbà soke ni akoko Ipalarada, yoo ba Kristi pada wá lati ṣe idajọ aye tabi awọn orilẹ-ède ti o wa laye (I Kọrinti 6:2; Juda 14:15; Matteu 13:40-43). Eyi ni idajọ awọn alaaye ti n bẹ lori ilẹ aye. Awọn Apọsteli yoo joko lori itẹ lati ṣe idajọ awọn ẹya Israẹli mejila.

Ẹnyin li awọn ti o ti duro ti mi ninu idanwo mi.

Mo si yàn ijọba fun nyin, gẹgẹ bi Baba mi ti yàn fun mi;

Ki ẹnyin ki o le mā jẹ, ki ẹnyin ki o si le mā mu lori tabili mi ni ijọba mi, ki ẹnyin ki o le joko lori itẹ, ati ki ẹnyin ki o le ma ṣe idajọ fun awọn ẹya Israẹli mejila” (Luku 22:28-30).

Awọn ti a pa ninu ogun Armageddoni, ati awọn ti o tun kú lẹhin eyi lai ni igbala yoo duro niwaju Itẹ Idajọ Funfun pẹlu awọn eyi ti o kù, awọn okú ati alaaye ti wọn ti wà lati ayebaye, ti a kò ti i dá lẹjọ ṣiwaju idajọ yoo kadi gbogbo idajọ. Ṣugbọn idajọ awọn Orilẹ-ède yatọ si ti Itẹ Idajọ Nla Funfun nitori pe ki yoo dẹkun ni gbogbo akoko Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun; dajudaju ki i ṣe ẹyọ idajọ igbà kanṣoṣo pere bi ti Itẹ Idajọ Nla Funfun.

Idọgba Ọna Idajọ Ọlọrun ati ti Eniyan

Ninu akoso orilẹ-ède wa, a ni oriṣiriṣi ile-ẹjọ ti wọn n ṣe abojuto oriṣiriṣi ati oniruuru ẹjọ ati ọràn didá. Eniyan kan le fara hà ni ile-ẹjọ fun idi pupọ. O le lọ lati mọ bi ofin kan fẹsẹ mulẹ tabi bẹẹ kọ, lati mọ ohun ti i ṣe ojuṣe rẹ labẹ ofin, tabi lati mọ bi ofin kan ti fẹsẹ mulẹ to fun anfaani awọn ẹlomiran. A le mu un wa si ile-ẹjọ lati wa jẹjọ awọn ẹsun ti a fi i sun fun, bi o ba ti ṣe aṣiṣe lọna kan tabi bi o ba ti da ọran kan. Ni oniruuru igbekalẹ ile-ẹjọ wọnyi, a le fi i sinu tubu, tabi ki o san owo itánràn, ki a jẹ ẹ niya, tabi ki a fun un ni imọran, tabi ki a da a lare gẹgẹ bi ẹsun ti a fi i sun fun, tabi bi ọran ti o dá ti a fi gbè e wa sile ẹjọ ba ti ri.

Awọn ile-ẹjọ miiran si wà ti o ni agbara ikú ati iye lori awọn ti a ba mu wá siwaju wọn ti a si sùn ni ẹsun lile. Awọn ile-ẹjọ wọnyi le paṣẹ ti yoo gba ominira tabi ẹmi ọdaran naa paapaa bi o ba tọ bẹẹ loju wọn. Nigba ti a ba si mu iru idajọ bayii ṣẹ a fi òté le ọrọ naa niwọn igba ti a ti gbà ẹmi arufin, orilẹ-èdè a si bọ lọwọ ewu ati ibalo ẹni ti kò naani ẹtọ awọn ẹlomiran, ti o si gba ẹmi ẹlomiran lai nidii.

Bakan naa ni o ri pẹlu eto idajọ Ọlọrun, ṣugbọn lọna ti o yanju ju lọ. Idajọ wà fun awọn Onigbagbọ ninu eyi ti a o fun ni ni iyin, ti a o si pin èrè, ti a o si fun awọn eniyan mímọ ni aṣẹ gẹgẹ bi iṣẹ ati isin wọn ni aye ba ti ri (II Timoteu 4:8). Ṣugbọn idajọ si tun wà nibi ti a o gbe jẹ awọn eniyan niya.

Eniyan a maa jiya fun ẹṣẹ rẹ láyé ni iwọnba. Idajọ ninu aanu ni eyi, ni igbesi aye ẹni kọọkan wa. Ọlọrun a maa ba wa wi bi a ba ṣe aṣiṣe, lati fi ìkùnà ti o wà ni ọna wa hàn wa, ki O le mu wa pada sọdọ ara Rẹ lọna bayii. Oun a maa fi okùn ifẹ fa wa, eyi ti o le jẹ fifi ọwọ ibawi lé wa lara lati mu wa pada si ironupiwada nigbà ti a ba ṣe agidi. Aanu wà ninu irú awọn idajọ bawọnyi.

Ṣugbọn irú idajọ wọnyi kò mu idajọ ti ikẹyin ti o n bọ wa kuro (Heberu 9:27). Ọlọrun ni ẹtọ lati mu olukuluku eniyan wa si idajọ fun ẹṣẹ ti ẹni naa kò ronupiwada rẹ, ki a si dariji i. Eyi yoo ṣẹlẹ ni opin Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun, eyi naa ni a si n pe ni Itẹ Idajọ Nla Funfun, eyi ti a ti mẹnu kàn ninu ẹkọ yii tẹlẹ. A fi otitọ yii ye ni nibi pupọ ninu Iwe Mimọ. Lẹhin igbà ti Kristi ba fara hàn, ati ṣiwaju Itẹ Idajọ Nla Funfun ni akoko Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun, a o ṣe idajọ awọn orilẹ-ède ti o wà laaye. Idajọ yii fara jọ ọpọlọpọ idajọ ati eto akoso ilu ti igbesi aye wa lọjọọjọ.

Idajọ awọn Orilẹ-ède ti O Wà Laaye

Mo si ri angẹli kan nti ọrun sọkalẹ wá, ti on ti iṣika ọgbun ni, ati ẹwọn nla kan li ọwọ rẹ.

O si di dragoni na mu, ejò atijọ ni, ti iṣe Eṣu, ati Satani, o si dè e li ẹgbẹrun ọdún.

O si gbè e sọ sinu ọgbun na, o si ti i, o si fi èdidi di i lori rẹ, ki o má bā tan awọn orilẹ-ede jẹ mọ titi ẹgbẹrun ọdún na yio fi pé: lẹhin eyi, a kò le ṣai tu u silẹ fun igba diẹ.

Mo si ri awọn itẹ, nwọn si joko lori wọn, a si fi idajọ fun wọn: mo si ri ọkàn awọn ti a ti bẹ lori nitori ẹri Jesu, ati nitori ọrọ Ọlọrun, ati awọn ti kò si foribalẹ fun ẹranko na, ati fun aworan rẹ, tabi ti kò si gbà àmi rẹ ni iwaju wọn ati li ọwọ wọn: nwọn si wà lāye, nwọn si jọba pẹlu Kristi li ẹgbẹrun ọdún.

Awọn okú iyokù kò wà lāye titi ẹgbẹrun ọdún na yio fi pé. Eyi li ajinde ekini.

Olubukun ati mimọ ni ẹniti o ni ipa ninu ajinde ekini na: lori awọn wọnyi ikú ekeji kò li agbara, ṣugbọn nwọn o jẹ alufa Ọlọrun ati ti Kristi, nwọn o si mā jọba pẹlu rẹ li ẹgbẹrun ọdún” (Ifihan 20:1-6).

Ẹwà awọn ohun ti Ọlọrun kọkọ da si ayé yii ti o wọmi nigbà ti eniyan ṣubu, ki yoo fara hàn mọ titi “ifihan awọn ọmọ Ọlọrun” – ajinde awọn eniyan mimọ ni ara ologo. A o mu ègún ẹṣẹ kuro ninu aye, gbogbo aye yoo si di Paradise.

A o de Satani a o si sọ ọ si ọgbun ainisalẹ fun ẹgbẹrun ọdún, ki yoo si le danwo tabi tan awọn eniyan ti o wà ni aye jẹ ni gbogbo akoko naa (Ifihan 20:1-3). Kristi yoo fi ọpá irin ṣe akoso awọn orilẹ-ède: ṣugbọn yoo jẹ Ijọba ododo ati àìṣègbè (Iṣe Awọn Apọsteli 17:31; Ifihan 19:15). Ṣugbọn bi awọn eniyan ba mọọmọ yan ni idanu ara wọn lati ṣọtẹ, a o dá wọn lẹjọ, a o si jẹ wọn níyà (Isaiah 28:17). Irú agbara bayii ni awọn adajọ ile-ẹjọ orilẹ-èdè wa ni, bakan naa ni yoo ri ni Igba Alaafia, nitori pe Kristi ni yoo jẹ Olu Ijọba ti o wà labẹ akoso Ọlọrun nigba naa.

Fun igba kin-in-ni lẹyin ti eniyan ti ṣubu, eniyan yoo wà ninu aye lai si idanwo Eṣu, ti n gbokegbodo nisinsinyi, ti o n bu ramuramu bi kinniun, “ti o n wa ẹniti yio pa jẹ kiri” (I Peteru 5:8). Kò ni si aiṣododo mọ, nitori pe Ijọba Kristi yoo jẹ ti otitọ ati ododo (Jeremiah 23:5,6). Awọn ọlọrọ ti o ni ọkẹ aimoye naira, ki yoo jẹ gaba lori awọn talaka mọ, nitori lati Jerusalẹmu ni idajọ otitọ yoo maa jade lọ (Mika 4:1-4). Awọn eniyan yo gbe ni alaafia ati ailewu (Esekiẹli 34:25). Akoko yii yoo jẹ akoko idajọ, ati igbọran si Onidajọ aayè ati okú (Romu 14:10).

Ati li ọjọ na, (ọjọ Oluwa), kukute Jesse kan yio wà, ti yio duro fun ọpágun awọn enia; on li awọn keferi yio wá ri: isimi rẹ yio si li ogo.

Yio si ṣe li ọjọ na, ni Oluwa yio tun nawọ rẹ lati gbà awọn enia rẹ iyokù padà, ti yio kù, lati Assiria, ati lati Egipti, ati lati Patrosi, ati lati Kuṣi, ati lati Elamu, ati lati Ṣinari, ati lati Hamati, ati lati awọn erekùṣu okun wá.

On o si gbe ọpagun kan duro fun awọn orilẹ-ède, yio si gbá awọn àṣati Israẹli jọ, yio si kó awọn ti a tuka ni Juda jọ lati igun mẹrin aiye wá.

Ilara Efraimu yio si tan kuro; a o si ke awọn ọta Juda kuro; Efriamu ki yio ṣe ilara Juda, Juda ki yio si bà Efriamu ninu jẹ.

Ṣugbọn nwọn o si fò mọ ejika awọn Filistini siha iwọ-õrun; nwọn o jùmọ bà awọn ti ila-õrun jẹ: Nwọn o si gbe ọwọ le Edomu ati Moabu; awọn ọmọ Ammoni yio si gbà wọn gbọ.

OLUWA yio si pa ahọn okun Egipti run tũtũ; ẹfũfu lile rẹ ni yio si mi ọwọ rẹ lori odo na, yio si lù u ni iṣàn meje, yio si jẹ ki enia rekọja ni batà gbigbẹ.

Ọna opopo kan yio si wà fun iyokù awọn enia rẹ, ti yio kù, lati Assiria; gẹgẹ bi o ti ri fun Israẹli li ọjọ ti o goke jade kuro ni ilẹ Egipti” (Isaiah 11:10-16).

O rọrun lati ri aworan ọna iyanu Ọlọrun ti o gún ti o si tọ bi o ba tilẹ jẹ wi pe oju aanu, ifẹ, ati ododo wa bi eniyan ni a fi wo inu Ọrọ Mimọ Rẹ. Bi “OLUWA (ba) lọra lati binu, (ti) o si tobi li agbara, ni didasilẹ (ti) ki yoo dá enia buburu silẹ”, bi O ba “ni ọna rẹ ninu ājà ati ninu iji, (ti) awọsanma si jẹ ekuru ẹsẹ rẹ” (Nahumu 1:3), nigbà naa o yẹ ki o dá wa loju pe ni ẹgbẹrun ọdún ti a o fi de Satani, ti Kristi yoo si jọba ninu aye yii, Oun yoo jọba gẹgẹ bi ọna otitọ ati ododo Rẹ. Kò ni si abẹtẹlẹ, yiyi idajọ po, yiyi akọsilẹ ile-ẹjọ po, piparun ẹri ti o le fi otitọ hàn, yiyi ẹjọ po, aṣiṣe ninu iwadii ati iṣakoso, ati awọn ohun miiran bẹẹ bẹẹ nipasẹ eyi ti awọn ọmọ-eniyan n jiya lọjọ oni.

Nitorina Ọlọrun pẹlu si ti gbé e ga gidigidi, (Jesu), o si ti fi orukọ kan fun u ti o bori gbogbo orukọ:

Pe, li orukọ Jesu ni ki gbogbo ẽkun ki o mā kunlẹ, awọn ẹniti mbẹ li ọrun, ati awọn ẹniti mbẹ ni ilẹ, ati awọn ẹniti mbẹ nisalẹ ilẹ;

Ati pe ki gbogbo ahọn ki o mā jẹwọ pe, Jesu Kristi ni Oluwa, fun ogo Ọlọrun Baba” (Filippi 2:9-11).

Gbogbo aṣẹ yoo wà lọwọ Kristi, Onidajọ ododo (Sekariah 14:9). Oun yoo mọ aṣiri gbogbo eniyan (Romu 2:16). Oun yoo ṣe idajọ ododo (Iṣe Awọn Apọsteli 17:31). Oun ni yoo ṣe akoso idajọ gbogbo (Isaiah 45:23; Johannu 5:22; Romu 14:10-12; Filippi 2:10). Oun yoo fun awọn olododo ni ère (Orin Dafidi 58:11). Gbogbo eniyan ni yoo ni anfaani lati ni imọ pipé nipa ofin ti a fi n ṣe idajọ wọn, nitori pe Ọrọ Ọlọrun ni ofin naa (Orin Dafidi 96:13; Isaiah 2:2-4; Sekariah 14:16-19). (Ni akoko Ase Agọ ni awọn Ọmọ Israẹli maa n ni anfaani pataki lati kọ Ofin Ọlọrun).

Akoko ti a le maa foju sọna fun pẹlu ayọ ni yii ti ki i si ṣe pẹlu abamọ. Akoko yii ni gbogbo ẹda n kerora fun, ti ọkán gbogbo eniyan si n ṣafẹri, bi o tilẹ jẹ pe wọn kò mọ okodoro nnkan ti wọn n lepa, ti wọn n ṣaapọn fun, ti wọn si n ṣiṣẹ fun (Romu 8:18-23). Akoko ologo ni yoo jẹ fun awọn eniyan mimọ Ọlọrun ti wọn ti jinde (Isaiah 35:1-10; 65:25). Wọn yoo ni ara titun – ara ologo. Ara atijọ ti o mọ aisan, irora, ijatilẹ, ati ailera kò ni si mọ. Wọn yoo dabi Ọba wọn, nitori nigba naa ni a o ri Oluwa ati Olugbala ni ojukoju, a o si mọ, gẹgẹ bi awa pẹlu si ti di mimọ (I Kọrinti 13:9-12; I Johannu 3:2, 3; Romu 18:18-23).