Ifihan 20:11-15; 21:1-27; 22:1-5

Lesson 169 - Junior

Memory Verse
“Ọlọrun yio si nù omije gbogbo nù kuro li oju wọn; ki yio si si ikú mọ, tabi ọfọ, tabi ẹkún, bẹẹni ki yio si irora mọ: nitoripe ohun atijọ ti kọja lọ” (Ifihan 21:4).
Notes

Mo si ri itẹ funfun nla kan, ati ẹniti o joko lori rẹ, niwaju ẹniti aiye ati ọrun fò lọ; a kò si ri àye fun wọn mọ.

Mo si ri awọn okú, ati ewe ati àgba, nwọn duro niwaju itẹ; a si ṣi awọn iwe silẹ; a si ṣi awọn iwe miran kan silẹ ti iṣe iwe iyè: a si ṣe idajọ fun awọn okú lati inu ohun ti a ti kọ sinu iwe na, gẹgẹ bi iṣẹ wọn.

Okun si jọ awọn okú ti mbẹ ninu rẹ lọwọ; ati ikú ati ipo-okú si jọ okú ti o wà ninu wọn lọwọ; a si ṣe idajọ wọn olukuluku

gẹgẹ bi iṣẹ wọn.

Ati ikú ati ipo-okú li a si sọ sinu adagun iná. Eyi ni ikú keji.

Bi a ba si ri ẹnikẹni ti a kò kọ orukọ rẹ sinu iwe iye, a sọ ọ sinu adagun iná” (Ifihan 20:11-15).

A Ji Okú Awọn Eniyan Buburu Dide

Lẹhin ogun Gogu ati Magogu, ni opin Ijọba Ẹgbẹrun Ọdún, ni ajinde “awọn oku iyokù” (Ifihan 20:5): Nigbà naa, awọn okú, ewe ati agba, ti a ti sin ni iboji ni ẹgbẹẹgbẹrun ọdún sẹhin yoo jade wa. Bi wọn tilẹ ti rà, ti erupẹ -- ara – si ti pada si erupẹ nibi ti a ti mu un jade wá, sibẹ Ọlọrun ṣeleri pe ao ko awọn ara wọnyi jọ lati ibikibi ti o wu ki wọn wà, ninu okun tabi lori ilẹ. Bi a tilẹ ti dáná sun ara wọnyi ti a si ti gbe eeru wọn lọ ninu afẹfẹ ti o ga to ẹgbaafa (12,000), ẹẹdẹgbẹjọ (15,000) tabi ẹgbaawa (20,000) ẹsẹ, ti a si fẹ eeru naa danu sori awọn oke, Ọlọrun Olodumare yoo gbá eeru wọnyi jọ, wọn o si pada di ara. Nigbà naa ni olukuluku yoo dide duro lori ẹsẹ rẹ niwaju Onidajọ ti o joko lori Itẹ Idajọ Nla Funfun, lati ṣiro ohun ti o ṣe.

Ọlọrun sọ pe olukuluku iṣẹ buburu – ani gbogbo rẹ, -- ni a o mu wa si idajọ pẹlu ohun ikọkọ gbogbo. Gbogbo ohun ti a ti fi pamọ si ookan ayà, awọn aṣiiri ti kò tilẹ hàn si ọrẹ korikosun, ni yoo di mimọ fun gbogbo aye nijọ kan. Gbogbo ohun ti a ṣe ni ikọkọ ni a o kede rẹ lori orule. Ọlọrun mọ; Ọlọrun riran; Ọlọrun ranti; Ọlọrun n kọ akọsilẹ; ẹnikẹni ti a kò ba si fi ẹṣẹ rẹ ji ninu aye yìí, yoo dahùn wọn niwaju Itẹ Idajọ Nla Funfun.

“Mo si ri awọn okú, ati ewe ati agba.” Ẹlomiran lè ro pe oun kere oun kò si nilaari ninu ogbologbo aye yìí, to bẹẹ ti ẹnikẹni kò ni naani ọrọ ti o ti sọ tabi iwa ti o ti hù ninu aye yìí; ṣugbọn awọn okú; ewe ati agba, yoo duro ni ọjọ nla nì, yoo si rò ti ẹnu rẹ fun Onidajọ gbogbo aye. Awọn ẹni ti wọn ti gbajumọ ninu aye to bẹẹ ti ẹnikẹni kò le gbe ẹnu soke bá wọn sọrọ, yoo ri awọn iwe ti yoo ṣi silẹ lọjọ wọnni; gbogbo awọn ẹṣẹ ti wọn ti dá, gbogbo awọn ohun ti wọn rò pe awọn ti ṣe ni aṣegbe ni a o kọ silẹ nibẹ. A o dá olukuluku lẹjọ gẹgẹ bi iṣẹ rẹ.

Ìwé Ìyè

“A si ṣi awọn iwe miran kan silẹ ti i ṣe iwe iye … Bi a ba si ri ẹnikẹni ti a kò kọ orukọ rẹ sinu iwe iye, a sọ ọ sinu adagun iná.” Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin Rẹ pe: “Ẹ máṣe yọ si eyi, pe, awọn ẹmi nforibalẹ fun nyin; ṣugbọn ẹ kuku yọ, pe, a kọwe orukọ nyin li ọrun” (Luku 10:20). A kọ orukọ awọn ọmọ-ẹhin silẹ ni Ọrun. A n kọ orukọ wa ni Ọrun nigbà ti a ba rà wa pada. Bi a bá n rin ninu imọlẹ ti a jẹ aṣẹgun patapata, orukọ wa ki yoo kuro nibẹ; ṣugbọn bi a ba dẹṣẹ, a o yọ orukọ wa kuro ninu Iwe Iye. Ọlọrun sọ fun Mose pe: “Ẹnikẹni ti o ṣẹ mi, on li emi o parẹ kuro ninu iwe mi” (Ẹksodu 32:33). Jesu ṣe ileri fun awọn aṣẹgun pe a ki yoo yọ orukọ wọn kuro ninu Iwe Iye (Ifihan 3:5). Awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun wọnyi fi hàn wa ninu Iwe Iye, o si tun ṣe e ki a yọ ọ kuro ninu Iwe Iye. A le ri igbala a si tun le sọ ọ nù.

Ẹmi Ki I Sùn

Ni akoko ipalarada, a o ji awọn ti o ti ku ninu Kristi dide lati isa oku wá - a o ji ara iyara wọn dide, ọkàn lati Ọrun wa yoo si dapọ mọ ara wọn ti a ji dide. Nigbà ti ọmọ Ọlọrun ba kú, ẹmi rẹ yoo lọ si Ọrun lẹsẹkẹsẹ. Jesu sọ fun ole ni lori agbelebu pe: “Loni ni iwọ o wà pẹlu mi ni Paradise” (Luku 23:43). nigbà ti ẹlẹṣẹ ba kú, ẹmi rẹ yoo lọ si ọrun apaadi lẹsẹkẹsẹ. Iyè rẹ ji perepere, o le riran; o le mọ bi ohun kan ba kàn an lara; o si le gbọran pẹlu. Ọkunrin ọlọrọ kú, o si lọ si ọrun apaadi, o si wà nibẹ nigbà ti awọn arakunrin rẹ marun wà laaye sibẹ lori ilẹ aye (Luku 16:19-31). Ni idajọ ikẹhin – ni Itẹ Idajọ Nla Funfun – a o ji okú awọn eniyan buburu dide, ara wọn lati inu iboji, ẹmi wọn lati ọrun apaadi. “Ikú ati ipo-okú si jọ awọn okú ti o wà ninu wọn lọwọ.”

Adagun Iná

“Ati ikú ati ipo-okú li a si sọ sinu adagun iná.” Awọn eniyan buburu ti a ji dide fun idajọ niwaju ItẹIdajọ Nla Funfun ni awọn okú ti o kẹhin. Ki yoo si ikú mọ. Ikú tikara rẹ ni a o gbé sọ sinu adagun iná. “Ikú li ọtá ikẹhin ti a o parun” (I Kọrinti 15:26). Ọrun apaadi, tabi Ipo-oku, ti i ṣe ibugbe ọkàn awọn eniyan buburu titi di akoko Idajọ yoo jọwọ awọn okú ti o wà ninu wọn, Ipo-okú tikara rẹ ni a o si gbé sọ sinu adagun iná.

Gbogbo awọn ti orukọ wọn kò si ninu Iwe Iye ni a o gbé sọ sinu adagun iná, tọkàn t’ara. Jesu wi fun ni pe, “Ẹ kuku fòya ẹniti o le pa ara ati ọkàn run li ọrun apadi” (Matteu 10:28). Eṣu, ẹranko naa, ati woli eke naa ni a o gbé sọ sinu adagun iná, “a o si mā dá wọn loro t’ọsan-t’oru lai ati lailai” (Ifihan 20:10). Adagun iná kò lopin; ibugbe ikẹhin ti awọn eniyan buburu ni eyi i ṣe. “Eyi ni iku keji.” “Ṣugbọn awọn ojo, ati alaigbagbọ, ati awọn ẹni irira, ati apania, ati agbere, ati oṣo, ati abọriṣa, ati awọn eke gbogbo, ni yio ni ipa tiwọn ninu adagun ti nfi iná ati sulfuru jó; eyi ti ise ikú keji” (Ifihan 21:8).

Kiká Ọrun ati Aye Isinsinyi Kuro

A o ṣẹgun awọn ọta Kristi a o si gbà wọn sọ sinu adagun iná. Johannu sọ fun ni nipa Ọrun titun ati aye titun.

Mo si ri ọrun titun kan: nitoripe ọrun ti iṣaju ati aye iṣaju ti kọja lọ; okun kò si si mọ” (Ifihan 21:1).

Aye ti o wà nisinsinyi, ti o tobi ti o si duro gbọningbọnin labẹ ẹsẹ wa yii, yoo kọja lọ. Ọrun ti o wà nisinsinyi kò ni si mọ. Peteru sọ fun ni pe: “Ṣugbọn awọn ọrun ati aiye, ti mbẹ nisisiyi, nipa ọrọ kanna li a ti tojọ bi iṣura fun iná, a pa wọn mọ de ọjọ idajọ, ati iparun awọn alaiwabi-Ọlọrun … awọn ọrun yio kọja lọ ti awọn ti ariwo nla, ati awọn imọlẹ oju ọrun yio si ti inu oru gbigbona gidigidi di yiyọ, aiye ati awọn iṣẹ ti o wà ninu rẹ yio si jóna lulu … awọn ọrun yio gbiná, ti nwọn yio di yiyọ, ti awọn imọlẹ rẹ yio si ti inu õru gbigbona gidigidi di yiyọ” (II Peteru 3:7, 10, 12). Ọrun titun ti Johannu ri ki i ṣe Aye ti a tun ṣe tabi Ọrun ti a tun kọ, bi kò ṣe Ọrun titun ati ayé titun. “Ẹ gbé oju nyin soke si awọn ọrun, ki ẹ si wò aiye nisalẹ: nitori awọn ọrun yio fẹ lọ bi ẹẹfin, aiye o si di ogbó bi ẹwù” (Isaiah 51:6). Jesu wi pe: “Ọrun on aiye yio rekọja” (Matteu 24:35). “Ṣugbọn gẹgẹ bi ileri rẹ, awa nreti awọn ọrun titun ati aiye titun, ninu eyiti ododo ngbé” (II Peteru 3:13).

Nigba itẹ Idajọ Nla Funfun, “aiye ati Ọrun fò lọ: a kò si ri àye fun wọn mọ” (Ifihan 20:11). Ẹda ti ẹṣẹ ti bajẹ, ki yoo duro niwaju Onidajọ gbogbo aye. Nigbà ti a ba fi gbogbo ọta sabẹ ẹsẹ Kristi, awọn ohun idibajẹ yoo parẹ bi eefin iná. Ọlọrun yoo dá Ọrun titun ati aye titun ti Satani ati awọn ẹmẹwa rẹ kò sọ di idibajẹ nipa wiwa nibẹ wọn. “Ẹniti o joko lori itẹ nì wipe, “Kiyesi i, mo sọ ohun gbogbo di ọtun.”

Mo si ri ilu mimọ nì, Jerusalẹmu titun nti ọrun sọkalẹ lati ọdọ Ọlọrun wá, ti a mura silẹ bi iyawo ti a ṣe lọṣọ fun ọkọ rẹ.

Mo si gbọ ohùn nla kan lati ori itẹ ni wá, nwipe, Kiyesi i, agọ Ọlọrun wà pẹlu awọn enia, on o si mā ba wọn gbé, nwọn o si mā jẹ enia rẹ, ati Ọlọrun tikararẹ yio wà pẹlu wọn, yio si ma jẹ Ọlọrun wọn.

Ọlọrun yio si nù omije gbogbo nù kuro li oju wọn; ki yio si si ikú mọ, tabi ọfọ, tabi ẹkún, bẹni ki yio si irora mọ; nitoripe ohun atijọ ti kọja lọ” (Ifihan 21:2-4).

Ko si Omije

Ọrun titun ati aye titun yoo tayọ ohun ti ẹnu eniyan le ṣe apejuwe. “Ohun ti oju kò ri, ati ti eti kò gbọ, ti kò si wọ ọkàn enia lọ, ohun wọnni ti Ọlọrun ti pèse silẹ fun awọn ti o fẹ ẹ” (I Kọrinti 2:9). Johannu ṣe iranwọ lati la wa loye bi Jerusalẹmu Titun yoo ti ri nipa fifi ohun ti kò si nibẹ hàn. “Nitoripe ohun atijọ ti kọja lọ.” A fi ye ni dajudaju pe awọn ohun idaamu wọnni ti o wọpọ ninu aye wa yi ki yoo si nibẹ. Irora, omije, ibanujẹ, ẹkun, ati ikú paapaa ki yoo si nibẹ rara. Ki yoo si okuta iranti ni Jerusalẹmu Titun. Ki yoo si igbekalẹ kankan ni iranti awọn ti o ti lọ ṣiwaju, nitori pe gbogbo awọn ẹni irapda tikara wọn paapaa yoo wà nibẹ, a o si ke iranti awọn eniyan buburu kuro. “Egun ki yio si si mọ” (Ifihan 22:3). Lọjọ oni, ibi ti ègun ẹṣẹ mu wá wà kaakiri. Arun ati irẹdanu wa kaakiri gbogbo aye; ṣugbọn Ọlọrun ti ṣeleri pe, “Egun ki yio si si mọ.”

O si mu mi lọ ninu Ẹmi si òke nla kan ti o si ga, o si fi ilu nì hàn mi, Jerusalẹmu mimọ, ti nti ọrun sọkalẹ lati ọdọ Ọlọrun wá” (Ifihan 21:10).

Ile Baba

Johannu kọwe rẹ pe: “Mo si ri ilu mimọ nì, Jerusalẹmu titun, nti ọrun sọkalẹ lati ọdọ Ọlọrun wa.” Nipa awọn ẹsẹ Iwe Mimọ wọnyi, o dabi ẹni pe Jerusalẹmu Titun yoo sọkalẹ lati oke wa yoo si dapọ pẹlu aye titun. O di mimọ fun ni wi pe Jerusalẹmu titun yii ni Ile Baba nibi ti ọpọlọpọ ibugbe wà, ibẹ ni Kristi si pese fun Iyawo Rẹ. Ni ilu mimọ yii ni Oluwa Ọlọrun Olodumare ati Ọdọ-agutan yoo maa gbe pẹlu awọn aṣẹgun ti Jesu ti gbé ni Iyawo.

Emi kò si ri tẹmpili ninu rẹ: nitoripe Oluwa Ọlọrun Olodumare ni tẹmpili rẹ; ati Ọdọ-Agutan.

Ilu na kò si ni iwá õrùn, tabi oṣupa, lati mā tan imọlẹ si i: nitoripe ogo Ọlọrun li o ntan imọlẹ si i, Ọdọ-Agutan si ni fitila rẹ.

Awọn orilẹ-ède yio si mā rin nipa imọlẹ rẹ: awọn ọba aiye si nmu ogo wọn wá sinu rẹ.

A ki yio si sé awọn ẹnubode rẹ rara li ọsán: nitori ki yio si oru nibẹ” (Ifihan 21:22-25).

Ayé Titun

A kò ni wá oorun tabi oṣupa mọ, nitori pe ogo Ọlọrun ni yoo maa ṣe imọlẹ Jerusalẹmu Titun yii, yoo si maa tan imọlẹ lati fun gbogbo awọn ti n bẹ ni aye ni imọlẹ. A ki yoo fi ọsan ati oru ka ọjọ mọ, nitori pe ki yoo si òru ni Jerusalẹmu Titun. Ki yoo si agbara òkunkun bẹẹ ni okunkun paapaa ki yoo si mọ. “Awọn orilẹ-ède yoo si maa rin nipa imọlẹ rẹ: awọn ọba aiye si nmu ogo wọn wa sinu rẹ.” Ohun gbogbo ni o n ṣiṣẹ pọ deedee lọwọkọwọ nitori pe eyi yii ni “Ọrun titun ati aiyé titun, ninu eyiti ododo ngbé” (II Peteru 3:13).

Ti o ni ogo Ọlọrun: imọlẹ rẹ si dabi okuta iyebiye gidigidi, ani bi okuta jasperi, o mọ bi kristali;

O si ni odi nla ati giga, o si ni ẹnubode mejila.”

Ẹnubode mejejila jẹ parli mejila: olukuluku ẹnubode jẹ perli kan” (Ifihan 21:11, 12, 21).

Ẹwà Didan

Fi oju inu wo ẹwà ilu naa pẹlu ogiri jasperi rẹ nla ati giga ti o mọ gaara bi kristali. Jasperi ayé yii kò mọ gaara, ṣugbọn o dabi ẹni pe gbogbo Jerusalẹmu Titun ni yoo mọ gaara, wura rẹ dabi awojiji ti o mọ gaara, jasperi rẹ si mọ gaara bi kristali. Ilu mimọ ti kò leeri ni. Bi o ba jẹ ọmọ-ibilẹ Ilu yii, iwọ ni lati mọ bi wura ti o yege – wura ti a danwo ninu iná. Ninu aye yii ni a o ti yọ gbogbo idàrọ kuro. Kò si iná iwẹnumọ kan fun ẹnikẹni wa nibi ti a o gbé wẹ aiṣedeedee tabi ẹṣẹ ati abawọn wa nù lẹhin ikú. A ti pese etutu kan silẹ ná, o si wà nisinsinyi fun gbogbo eniyan. Eyi ni Ẹjẹ Jesu Kristi. Bi o ba wà ninu Ẹjẹ naa, ti o si duro ninu rẹ, tayọtayọ ni a o fi gbà ọ si Ilu naa. Awọn eniyan i ba jẹ le ri iran Ilu Mimọ naa: ẹṣẹ kò si nibẹ, eleke kò si nibẹ, iṣoro kò si nibẹ, ija ko si nibẹ, ijatilẹ kò si nibẹ!

Ilu na si lelẹ ni ibú mẹrin li ọgbọgba, gigun rẹ ati ibú rẹ si dọgba o si fi ifefe ni wọn ilu na, o jẹ ẹgbafa oṣuwọn furlọngi: gigun rẹ ati ibú rẹ ati giga rẹ si dọgba.

O si wọn odi rẹ o jẹ ogoje igbọnwọ le mẹrin, gẹgẹ bi oṣuwọn enia, eyini ni ti angẹli na” (Ifihan 21:16, 17).

Iwọn

Ibu mẹrin ọgbọọgba ni Ilu naa ni, ibu rẹ jẹ ẹgbaafa furlọngi – nnkan bi ẹẹdẹgbẹjọ (1,500) mile -- ẹẹdẹgbẹjọ mile ni gigun ati ẹẹdẹgbẹjọ mile ni giga rẹ. Bi a ba gbe Jerusalẹmu Titun kalẹ ni apa ila-oorun Amẹrika, yoo gbe ipinlẹ mẹrindinlogoji mì ninu ipinlẹ mejidinlaadọta ti o wà nibẹ. Giga Ilu yii ju òye eniyan lọ. Pẹtẹsi alatopọ! Fi oju inu wo awọn ogiri jasperi ti o mọ bi kristali! O ṣe e ṣe ki wọn ga ba Ilu naa dọgba -- ẹẹdẹgbẹjọ mile ni giga soke. A sọ fun ni pe iwọn awọn ogiri naa jẹ igbọnwọ mẹrinlelogoje – eyi le ni igba ẹsẹ. Lai si aniani, ninipọn ogiri naa ni eyi. Fi oju inu wo awọn ibode perli. Kò ni jẹ asọdun lati wi pe wọn yoo fẹ ni ọgọrun mile, wọn o si ga ni ọpọlọpọ mile. Ipilẹ mejila ni Ilu naa ni, a si fi okuta iyebiye kan ṣe ipilẹ kọọkan lọṣọ. A kọ orukọ awọn Apọsteli mejila ti Ọdọ-agutan lọkọọkan si ipilẹ kọọkan. Wo irú ọlá ti Ọlọrun fi fun awọn onirẹlẹ eniyan ti n tọ Jesu lẹhin ni akoko iṣẹ-iranṣẹ Rẹ layé, ti wọn si tun kede Ihinrere lẹhin Igoke-re-Ọrun Rẹ! Ere yoo si wà fun awọn ti wọn fi tọkan-tọkàn sin Kristi lọjọ oni. Anfaani nla ni o jẹ fun ni lati wà ninu awọn ti yoo ba A jọba lae ati laelae.