Luku 19:29-48

Lesson 170 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Kiye si i, Ọba rẹ mbọwá sọdọ rẹ: ododo li on, o si ni igbàlà; o ni irẹlẹ, o si ngùn kẹtẹkẹtẹ, ani ọmọ kẹtẹkẹtẹ” (Sẹkariah 9:9).
Cross References

I Imura fun wiwọ Ilu pẹlu Ayọ Iṣẹgun

1. Bi Jesu ti n goke lọ si Jerusalẹmu, O sunmọ Bẹtani, Luku 19: 28, 29; Marku 10:32

2. O rán meji ninu awọn ọmọ-ẹyin Rẹ lọ si ileto lati tú ati lati mu ọmọ kẹtẹkẹtẹ kan wa fun Oun, Luku 19:30; Matteu 21:1

3. A kọ awọn ọmọ-ẹyin naa ni esi ti wọn yoo fun awọn oluwa kẹtẹkẹtẹ naa, Luku 19:31

4. Awọn ọmọ-ẹyin ba a gẹgẹ bi O ti wi, Luku 19:32-34

5. Wọn mu ọmọ kẹtẹkẹtẹ naa wa fun Jesu O si gun un, Luku 19:35

II Kristi Gun Kẹtẹkẹtẹ wọ Jerusalẹmu

1. Awọn ọmọ-ẹyin tẹ aṣọ wọn si oju ọna, Luku 19:36; 2 Awọn Ọba 9:13

2. Gbogbo awọn ọmọ-ẹyin rẹ bẹrẹ si i yọ, wọn si yin Ọlọrun, Luku 19:37, 38; 2:14; 13:35; Orin Dafidi 118:26

3. Awọn Farisi n fẹ ki Jesu bá ijọ eniyan naa wí, ṣugbọn Oun kọ lati ṣe bẹẹ Luku 19:39, 40; Habakkuku 2:11

III Ẹkún Kristi lori Jerusalẹmu

1. Jesu sọkun lori Jerusalẹmu, Luku 19:41, 42; Johannu 11:35

2. Jesu sọ ti awọn ọjọ ti o n bọ nigba ti wọn yoo pa ilu naa run, Luku 19:43, 44; Luku 21:20; Isaiah 29:3, 4

IV Kristi ṣe Iwẹnumọ Tẹmpili

1. Jesu le awọn ti n tà, ti n rà jade kuro ni Tẹmpili, Luku 19:45

2. O sọ fun wọn pe ile adura ni ile Oun ki i ṣe ihò olè, Luku 19:46; Isaiah 56:7; Jeremiah 6:3-6

Notes
ALAYE

Lati ọpọlọpọ ọdun ni awọn ọmọ Israeli ti n foju sọna fun ọba kan ti yoo wá, ti yoo si gba orilẹ-ede wọn silẹ lọwọ awọn ọta wọn. Ogunlọgọ eniyan ni o n tẹle Jesu gẹgẹ bi O ti n gba Jẹriko kọja lọ si Jerusalẹmu. A ko mọ bi iṣẹ iyanu ti Jesu ṣe bi O ti n lọ lọna ti pọ to, ṣugbọn a sọ fun wa nipa ọkunrin afọju kan ti o n ṣagbe lẹba ọna, ti Jesu wosan, ati nipa Sakeu agbowode, ti o fi tayọtayọ gba Ihinrere.

Ọlọrun Ni Jesu i Ṣe

Bi ọpọ eniyan wọnyii ti n sunmọ Jerusalẹmu nipa ọna oke Olifi ti ko ju nnkan bi ibusọ meji si iha oorun ilu naa, Jesu rán meji ninu awọn ọmọ-ẹyin Rẹ si ilu kekere kan ti a n pe ni Bẹtani lati lọ mu ọmọ kẹtẹkẹtẹ kan wa. O sọ fun awọn ọmọ-ẹyin naa pe siso ni wọn so ọmọ kẹtẹkẹtẹ naa si ẹnu ọna aba wọ ileto naa, nitori naa ki wọn ki o tu u ki wọn si mu un wa; bi awọn ti o ni kẹtẹkẹtẹ naa ba beere ohunkohun lọwọ wọn, ki wọn sọ pe Oluwa ni i fi ṣe. Awọn ọmọ-ẹyin Jesu lọ, wọn si ri ọmọ kẹtẹkẹtẹ naa gẹgẹ bi Jesu ti wi. Eyi nikan to lati fi hàn pe Ọlọrun ni Jesu i ṣe. O ṣe e ṣe ki awọn ẹlẹgan wi pe Jesu ti ranṣẹ abẹlẹ lati lọ wo kẹtẹkẹtẹ yii, ṣugbọn ta ni le sọ pe kẹtẹkẹtẹ naa yoo wà ni siso sibẹ nigba ti awọn ọmọ-ẹyin Jesu yoo de ibẹ. Ko si ẹni kan ti o le mọ ohun ti ẹni ti o ni kẹtẹkẹtẹ naa yoo wi bi ko ṣe Oluwa; Oun nikan ni o si le mọ pe ẹni ti o ni kẹtẹkẹtẹ naa yoo fi tọkantọkan yọnda rẹ.

Pipese fun Aini Oluwa

“Oluwa ni ifi i ṣe” Ki ni awa naa ni lonii ni ikawọ wa, ti Oluwa ni i fi ṣe? I ha ṣe akoko wa, tabi talẹnti wa tabi ohun miiran? Njẹ a le fi tifẹtifẹ fi i fun Oluwa gẹgẹ bi ọkunrin yii ti ṣe? Ẹni ti o ni kẹtẹkẹtẹ naa nikan ni o le ṣe ipinnu nipa rẹ. Awa bi ẹni kọọkan yoo ni lati ṣe ipinnu nipa ohun ti a ni lọwọ wa ti Oluwa ni i fi ṣe.

A tun le yẹ ibeere naa wo lọna miiran, ki a si wi pe: wo iru anfaani ti ọkunrin ti o yọnda kẹtẹkẹtẹ rẹ fun Oluwa lati gun ni! Ohun idalọla ti o ga pupọ ni anfaani naa yoo ja si ni oju rẹ. Njẹ ọkunrin yii mọ pe Ọba Ogo ni Jesu i ṣe? Njẹ o ni idaniloju pe a o dá kẹtẹkẹtẹ rẹ pada fun un? Iyemeji ha n ṣe ọ nigba ti Oluwa ba n beere pe ki o jọwọ ohunkohun silẹ fun Oun? Tayọtayọ ni iwọ yoo ha fi jọwọ eyi ti o dara ju lọ fun Un?

Ṣiṣe Jesu ni Ọba

Iba ọna kekere yii a ti fi han fun awọn eniyan pe Jesu ni Messia naa -Kristi naa- Ọmọ Ọlọrun Alaaye, ti bẹrẹ si di nnkan nla nigba ti awọn ọmọ-ẹyin mú kẹtẹkẹtẹ naa de ọdọ Rẹ. Boya awọn eniyan ti bẹrẹ si i sọrọ kẹlẹkẹlẹ laaarin ara wọn pe: “Jesu ti ranṣẹ fun ọmọ kẹtẹkẹtẹ kan. Lai si aniani yoo gun un lọ si Jerusalẹmu gẹgẹ bi Ọba, yoo gba ijọba le ejika Rẹ.” Nitori naa wọn bẹrẹ si i tẹ aṣọ wọn le ori kẹtẹkẹtẹ naa, wọn si gbe Jesu le e lori. Aṣa igba naa ni pe; bi a ba ti fi ẹni kan jọba, awọn eniyan a maa tẹ aṣọ wọn soju ọna lati fi ọla ati ọwọ fun un; eyi ni awọn eniyan wọnyii ṣe fun Jesu.

Iṣipaya ti Ẹmi

Ipá ati ogo Ọlọrun kò ni ṣai ti kun ọkan awọn ẹgbẹ onigbagbọ naa bi wọn ti n sọkalẹ bọ lati Oke Olifi. Iru Ẹmi kan naa ti o mi si awọn ogun Ọrun loru ọjọ naa ti a bi Jesu ni Bẹtlẹhẹmu ti Judea ti wọn fi n kọrin pe, “Ogo ni fun Ọlọrun loke ọrun, ati li aiye, alafia, ifẹ inu rere si enia” (Luku 2:14), ki yoo ṣai ti kun ọkan awọn onigbagbọ wọnyii nitori wọn n yọ, wọn si n yin Ọlọrun logo ni ohùn rara fun iṣẹ iyanu ti wọn ti ri. Wọn si n wi pe : “Olubukun li Ọba ti mbọ li orukọ Oluwa: alafia li ọrun ati ogo loke ọrun.”

Ninu Ihinrere ti Arọkuro Ojo yii, awa naa ti ri bi agbara Ọlọrun ti n sọkalẹ sori ijọ; ti wọn yoo si gbe ohun iyin wọn soke si Ọlọrun Ọrun fun iṣẹ iyanu Rẹ si awọn ọmọ-eniyan.

Bi Jesu ti wọ Jerusalẹmu pẹlu iṣẹgun yii jẹ apẹẹrẹ tabi ojiji ọjọ nla ti a o dé Jesu ni adé gẹgẹ bi “ỌBA AWỌN ỌBA, OLUWA AWỌN OLUWA”.

Nisisiyii, Jesu wá gẹgẹ bi oninu tutu ati onirẹlẹ, O si n gun kẹtẹkẹtẹ; ṣugbọn ki yoo ri bayii ni ipadabọ Rẹ lẹẹkeji nigba ti yoo gun ẹṣin funfun, ida mimu yoo si jade lati ẹnu Rẹ wá, ẹgbẹ ogun nla ti awọn eniyan mimọ ti o wà lori ẹṣin funfun yoo si maa tẹle E. Akoko fẹrẹ to ti yoo jọwọ ara Rẹ lọwọ fun awọn onikupani, ti Oun yoo si ta ẹjẹ Rẹ silẹ fun imukuro ẹṣẹ gbogbo agbaye. Lẹẹkeji Oun yoo fi iṣẹgun jọba lori gbogbo agbara ọta, ijọba Rẹ yoo si tan ka gbogbo agbaye, Oun yoo si fi ọpá irin ṣe akoso ayé.

Sisọkun Le Jerusalẹmu Lori

Laaarin gbogbo iho ayọ, ti awọn ogunlọgọ eniyan n ke “Hosanna si Ọmọ Dafidi,” ọkàn Jesu gbọgbẹ. O wo yika ilu Jerusalẹmu, nigba ti ara Rẹ ko gba a mọ, O sọkun. O ti ri iyọnu nla ti yoo de ba ilu yii nitori wọn kọ Ọ. Oun i ba radọ bo wọn gẹgẹ bi agbebọ adiẹ ti n radọ bo awọn ọmọ rẹ -- ṣugbọn wọn ko fẹ. Nisisiyii a fi ile wọn silẹ fun wọn lahoro. Alaafia ti i ba jẹ ti wọn ti fi wọn silẹ. Nisisiyii oju wọn ti fọ si otitọ.

Nitori wọn ko mọ ọjọ ibẹwo wọn, Jesu sọ tẹlẹ pe ọjọ n bọ ti a o wo Jerusalẹmu lulẹ bẹẹrẹ: a ki yoo si fi okuta kan lelẹ lori ekeji. Asọtẹlẹ yii ṣẹ ni nnkan bi aadọrin ọdun (A.D. 70) lẹyin iku Jesu, nigba ti ọgagun ilu Romu, ti a n pe ni Titu, gbogun ti Jerusalẹmu o si sọ ọ di ahoro. Iya ti awọn Ju jẹ nigba naa pọ lọpọlọpọ. Nitori ijọba Romu ko ni agbelebu to lati kan awọn Juu mọ, ọpọlọpọ eniyan n wọn kan mọ agbelebu kan ṣoṣo. “Ki ẹjẹ rẹ wà lori wa, ati li ori awọn ọmọ wa,” wọn ko mọ ibi ti yoo wá sori wọn. Awọn Ju n jiya titi di oni-oloni nitori wọn kọ Kristi. Ni igba tiwa yii, a tun ri iya nla ti wọn tun jẹ lọwọ awọn eniyan orilẹ-ede Jamani.

Iwọ ha tun n kọ eti didi si ẹbẹ Jesu lonii? Iwọ ha n ṣe alainaani aanu nla ti O fi lọ ọ? Ranti pe bi Ọlọrun ti jẹ alaanu to bakan naa ni O si tun jẹ Ọlọrun Onidajọ pẹlu.

Ṣiṣakoso pẹlu ọpá Irin

A sọ fun wa pe Ọjọ Oluwa ni Jesu gun kẹtẹkẹtẹ wọ ilu Jerusalẹmu – eyi tun jẹ ọkan ninu idi rẹ ti a fi n pe ọjọ yii ni “Ọjọ Oluwa.”

Nigba ti Jesu wọ Tẹmpili O fi ipá ati aṣẹ Rẹ hàn nipa lile awọn ti n ba ile Ọlọrun jẹ jade - eyi jẹ itọkasi ohun ti yoo ṣẹlẹ nigba ti Jesu ba jọba lori gbogbo agbaye ti o ba si ṣe akoso pẹlu ọpa irin (Ifihan 2:27; 12:5).

Awọn eniyan ti sọ Tẹmpili Ọlọrun di aimọ nipa tita ati rira ohun ẹbọ wọn ni ile Ọlọrun. Ibi pupọ kọ ha ni awọn eniyan ti yà sọtọ fun isin Ọlọrun ti wọn si sọ wọn di aimọ nipa tita ọja ikore, tẹtẹ ati nipa ijó!

Mimọ ni Ọlọrun. Oun si n gbe ibi mimọ. O si n fẹ ki awọn ti yoo sin Oun jẹ mímọ. O wi pe, “Ile mi yio jẹ ile adura; ṣugbọn ẹnyin ti sọ ọ di ihò olè”

Questions
AWỌN IBEERE.
  1. Ọjọ wo ninu ọsẹ ni Jesu wọ Jerusalẹmu pẹlu ayọ iṣẹgun?
  2. Ki ni a kọ ninu ẹkọ yii ti o fi hàn pe Ọlọrun ni Jesu i ṣe?
  3. Ki ni ṣe ti awọn eniyan fi n tẹ aṣọ wọn si oju ọna?
  4. Sọ akoko kan ti wọn ṣe bẹẹ ni ọjọ awọn ọba Israẹli.
  5. Nigba ti awọn eniyan n kigbe pe “Olubukun ni Ọba ti mbọ wá li orukọ Oluwa,” ki ni awọn Farisi fẹ ki Jesu ṣe?
  6. Ki ni Jesu wi pe awọn okuta yoo ṣe bi awọn eniyan ba dakẹ lati yin Oun?
  7. Ki ni Jesu ṣe nigbà ti O wọ inu Tẹmpili?