Marku 15:42-47; 16:1-20; Iṣe Awọn Aposteli 1:1-11

Lesson 171 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Nitori iwọ kì yio fi ọkàn mi silẹ ni ipò-okú; bẹẹni iwọ ki yio jẹ ki Ẹni Mimọ rẹ ki o ri idibajẹ” (Orin Dafidi 16:10).
Cross References

I Isinkú Jesu

1. Josẹfu ara Arimatea gba òkú Jesu, Marku 15:42-45

2. A tẹ Jesu sinu iboji titun, Marku 15:46

II Ajinde Jesu

1. Awọn obinrin wá lati fi ororo kùn okú Jesu, lẹyin ọjọ Isinmi, Marku 15:47; 16:1, 2

2. Awọn obinrin naa ri ọdọmọkunrin kan jokoo ninu iboji ti a ṣi silẹ, Marku 16:3-5; Luku 24:3; Johannu 20:11, 12

3. Angẹli naa fun wọn ni ihin ayọ ti ajinde Jesu, Marku 16:6-8;14:28; Matteu 26:32

4. Jesu fara hàn fun Maria Magdalene, lẹyin naa fun awọn ọmọ-ẹyin meji ati fun awọn miiran bi wọn ti n jẹun, Marku 16:9-14; 1 Kọrinti 15:5

III Aṣẹ ti Kristi fun awọn Ọmọ-ẹyin Rẹ

1. Jesu fi aṣẹ iwaasu ihinrere ká gbogbo agbaye fun gbogbo awọn ti n tẹle E, Marku 16:15, 16; Matteu 28:19; Johannu 15:16; 12:48

2. Ami yoo maa tẹle iwaasu Ihinrere, Marku 16:17, 18; Luku 10:17, 19; Iṣe Awọn Aposteli 2:4

3. Jesu fi ara Rẹ hàn laaye fun ogoji ọjọ, nipa ẹri pupọ ti o daju, Iṣe Awọn Aposteli 1:1-3

IV Ileri Baba

1. Jesu paṣẹ fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ lati duro de Olutunu, Iṣe Awọn Aposteli 1:4, 5; Joeli 2:28; Luku 24:49; Johannu 14:16

2. Awọn ọmọ-ẹyin ni ireti ijọba ti ayé yii sibẹ, Iṣe Awọn Aposteli 1:6; Isaiah 1:26

3. Jesu sọ fun wọn pe Baba ti yan awọn nnkan kan nipa agbara Rẹ, Iṣe Awọn Aposteli 1:7

4. Ẹmi Mimọ yoo bà lé wọn, wọn o si maa ṣe ẹlẹri fun Ọlọrun, Iṣe Awọn Aposteli 1:8; 2:1-4

V Igoke-Re Ọrun Jesu

1. A gba Jesu lọ soke Ọrun, kuro ni oju wọn, Iṣe Awọn Aposteli 1:9; Luku 24:51

2. Awọn ọkunrin meji alaṣọ àlà fun wọn ni idaniloju nipa ipadabọ Rẹ, Iṣe Awọn Aposteli 1:10, 11; Marku 16:19; Daniẹli 7:13; Matteu 24:30; 1 Tẹssalonika 4:16; Ifihan 1:7

3. Awọn ọmọ-ẹyin jade lọ waasu nibi gbogbo, Oluwa si n fi ẹsẹ ọrọ naa mulẹ nipa awọn ami ti o n tẹle e, Marku 16:20

Notes
ALAYE

Ninu ẹkọ yii a ri akọsilẹ nipa, ajinde ati igoke-re-Ọrun Jesu. Ni akoko ti wọn mu Jesu lati ba A ṣe ẹjọ, gbogbo awọn ọmọ-ẹyin ni o fi I silẹ ti wọn si sa lọ. Josẹfu ara Arimatea ẹni ti o jẹ ọlọrọ ati ijoye n tẹle Jesu ni ikọkọ fun ibẹru awọn Ju. Ṣugbọn lẹyin ti a ti kan Jesu mọ agbelebu tan, a ri bi Josẹfu ti lọ pẹlu igboya si ọdọ Pilatu lati tọrọ okú Rẹ. Ohun ti o n ba awọn kan lẹru ni o n fi igboya si ọkàn awọn ẹlomiran.

O jẹ aṣa aye igba a nì lati maa fi turari oloorun didun kun ara oku ki wọn to sin in. Ṣugbọn nitori àyè ti ko si, nitori Ọjọ Isinmi ti o sunmọ tosi, wọn fi ikanju gbe oku Jesu sinu iboji ni ireti ati wa fi turari kun Un lẹyin ti Ọjọ Isinmi ba ti kọja tan. Ni kutukutu owurọ, awọn ẹgbẹ obinrin kan ti o mu ikunra oloorun didun lọwọ ti mu ọna iboji pọn. Bi o tilẹ jẹ pe Jesu ti n sọ lemọlemọ pe oun yoo jinde, o dabi ẹni pe oye otitọ yii ko i ti i yé wọn. O yà wọn lẹnu, ẹru ba wọn, wọn si daamu nigba ti wọn ri i a ti yí okuta kuro lẹnu iboji, ti angẹli kan si wi pe, “Ẹ má bẹru: ẹnyin nwá Jesu ti Nasarẹti, ti a kàn mọ agbelebu: o jinde; kò si nihinyi: ẹ wò ibi ti nwọn gbé tẹ ẹ si.”

Iboji ati okuta ti wọn fi di ẹnu ọna rẹ ko le di Ọmọ Ọlọrun lọna. Oun ni Ajinde ati Iye! Nigba ti akoko to ti yoo jinde, ko si ohun ti o le da A duro. Awọn ọmọ-ogun Romu ṣubu lulẹ bi oku. Edidi ọba kò lè ko agbara Ọlọrun loju. Jesu jinde, O ṣẹgun iku, ọrun apaadi, ati ipo oku.

Nigba ti awọn ọmọ-ogun sọji, wọn mu ọna ilu pọn lati lọ royin ohun ti o ṣẹlẹ fun olori alufaa. Awọn alaiwa-bi-Ọlọrun wọnyii kọ awọn ọmọ-ogun lati purọ pe wọn sùn, pẹlu ikiya pe bi a fẹ jẹ wọn niya nitori wọn sùn lẹnu iṣẹ wọn ko ni jẹ ki a jẹ wọn niya. Ṣugbọn ododo ajinde Jesu di mimọ fun ọpọlọpọ awọn eniyan nigba a nì bi o tilẹ jẹ pe iroyin irọ ti awọn ọmọ-ogun pa tàn kalẹ.

Ajinde jẹ Otitọ ti o Fẹsẹ Mulẹ

Otitọ ti o fẹsẹ mulẹ ni pe Jesu jinde kuro ninu oku. Ajinde ni igbagbọ ati ireti Onigbagbọ. Ajinde Jesu ni ohun pataki ti iwaasu Paulu rọ mọ. Nitori ireti ajinde kuro ninu oku ni a ṣe mu Paulu wá siwaju igbimọ. Awọn diẹ wà ni ijọ Kọrinti ti wọn wi pe ko si ajinde oku, eyi ti o mu ki Paulu kọ Kọrinti kin-in-ni ori kẹẹdogun ti i ṣe idakọro ati ireti awọn onigbagbọ lati ayebaye. “Ṣugbọn bi ajinde okú kò si, njẹ Kristi kò jinde:……Bi a kò ba si jí Kristi dide, asan ni igbagbọ nyin; ẹnyin wà ninu ẹṣẹ nyin sibẹ” (1 Kọrinti 15:13, 17).

Jesu fara han ọpọlọpọ awọn eniyan mimọ lẹyin ajinde Rẹ ni ara-iyara. Nigba miiran O fara han ẹni kan ṣoṣo, nigba miiran fun eniyan meji tabi ju bẹẹ, ati nigba kan fun awọn eniyan ti o ju ẹẹdẹgbẹta ti wọn kó ara wọn jọ. Ninu ọkan ninu awọn akoko ifarahan wọnyi ni o fi aṣẹ yii fun wọn, “ Ẹ lọ si gbogbo aiye, ki ẹ si ma wasu ihinrere fun gbogbo ẹda. Ẹniti o ba gbagbọ, ti a ba si baptisi rẹ yio là; ṣugbọn ẹniti kò ba gbagbọ yio jẹbi.” Gbogbo ẹda - i ba a ṣe olowo, tabi talaka, ẹni giga tabi ẹni ti o rẹlẹ, ọlọgbọn tabi ope - gbogbo wọn ni o ni lati gbọ Ihinrere. Ki i ṣe awọn aṣayan diẹ ti Oluwa yàn, ni yoo ri igbala ti awọn iyoku yoo si ṣegbe. A lati fun ipe ihinrere si “Ẹnikẹni ti o ba fẹ” ẹnikẹni ti o ba si gbagbọ, yoo yè. Ẹni ti kò ba gbagbọ yoo ṣegbe.

Agbara fun Isin

Ki Jesu to goke re Ọrun, O sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ lati duro ni Jerusalẹmu, titi ti a o fi fi agbara wọ wọn lati oke wá. Ifi agbara wọ ni yoo fun wọn ni aṣẹ fun iṣẹ iranṣẹ wọn ati agbara lori gbogbo ipá ọta. Yoo fi idi otitọ ni mulẹ pe ami yoo maa tẹle iwaasu wọn. Wọn yoo sọrọ ni ède titun, eyi ti a muṣẹ ni ọjọ Pẹntikọsti nigba ti a fi agbara Ẹmi Mimọ wọ wọn. Ẹwẹ Jesu wi pe: “Nwọn o si ma gbé ejò lọwọ; bi nwọn ba si mu ohunkohun ti o li oró, ki yio pa wọn lara rara.” Jesu ko sọ fun wọn nibikibi lati maa ṣe aṣehàn tabi ki wọn maa táákà agbara wọn. A fi i fun wọn lati gbe ogo Ọlọrun ga ati lati jẹ ibukun fun awọn eniyan. Wọn ko gbọdọ dán Ọlọrun wò lati mọọmọ maa gbé ejò lọwọ lati ṣe aṣehàn agbara ti wọn ni ninu Ọlọrun, gẹgẹ bi awọn miiran ti n ṣe lode oni. Itumọ ọrọ Ọlọrun hàn kedere ninu Bibeli. Nigba ti igbesi-aye Paulu n lọ si opin, o n ṣa igi jọ lati dana, ejo paramọlẹ si di mọ ọn lọwọ. Awọn alaigbede erekusu naa si ri i, wọn n reti igba ti Paulu yoo kú nitori wọn mọ bi ejo buburu yii ti muna to. Ṣugbọn nigba ti Paulu yán ejo yii sinu ina ti ko si pa a lara, eyi fi agbara ti ó wà ninu Ihinrere hàn fun wọn (Iṣe Awọn Aposteli 28:1-6). Oluwa yoo pa awọn ti Rẹ mọ kuro lọwọ ejo ati ohun oloro gbogbo ti a ba ṣe agbako nipa eeṣi, ṣugbọn a ko gbọdọ ṣe aṣehàn fun ayé, lati gbe ogo ara wa ga pe awa ni agbara kan.

Igoke-re-Ọrun Jesu

Fun ogoji ọjọ lẹyin ajinde Rẹ, Jesu fara han fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ, nigba miiran ninu ile ti wọn sé ilẹkun, ati nigba miiran ni eti okun. Nitori O gbé ara ologo wọ, Oun le fara hàn lojiji laaarin wọn, ki O si tun nù mọ wọn loju bẹẹ gẹgẹ. Ọrọ Ọlọrun sọ fun wa pe Jesu fi ara hàn laaye lẹyin iku Rẹ nipa awọn ẹri ti o daju. O kọ awọn ọmọ-ẹyin Rẹ ni ohun pupọ nipa ijọba Ọlọrun. O dabi ẹni pe oye awọn ọmọ-ẹyin tubọ là si i lẹyin ti Jesu ti jinde, nitori ni oju wọn kòrókòró ni ọpọlọpọ ẹkọ ti Jesu ti kọ wọn siwaju ti ṣẹ.

Ni ọjọ kan, bi Jesu ti ba wọn pejọ ni Jerusalẹmu, O mu wọn jade lọ si Bẹtani ni Oke Olifi. Nibẹ ni o fi aṣẹ ikẹyin le wọn lọwọ. Wọn ko gbọdọ kuro ni “Jerusalẹmu, ṣugbọn ki wọn ki o duro dè ileri Baba, eyiti, o wipe ẹnyin ti gbọ li ẹnu mi.” Nigba naa ni O gbe ọwọ Rẹ soke Ọrun, O si sure fun wọn. Bi O si ti n ṣe eyi, a gba A kuro ni oju wọn, a si gbe E lọ soke Ọrun. Awọn ọmọ-ẹyin si tẹju mọ Ọn titi awọsanma fi gba A kuro ni oju wọn. Bi wọn ti n woke, angẹli meji duro nitosi, wọn si wi pe: “Ẹnyin ará Galili, ẽṣe ti ẹ fi duro ti ẹ nwò oju ọrun? Jesu na yi, ti a gbà soke ọrun kuro lọwọ nyin, yio pada bẹẹ gẹgẹ bi ẹ ti ri i ti o n lọ si ọrun.” Wọn si pada si Jerusalẹmu pẹlu ayọ. Eyi yii ti yatọ fun wọn to nisisiyii si oru ọjọ naa ti wọn sin Jesu sinu iboji Josẹfu titun!

Ipadabọ Jesu

Jesu n pada bọ! Ọrọ wọnyii ti jẹ idunnu awọn eniyan mimọ Ọlọrun lati ayebaye. A gbagbọ pe bibọ Rẹ sunmọ tosi. Eyi yii jẹ ireti ologo fun Ijọ Ọlọrun, nigba gbogbo ni a si n tẹti lelẹ lati gbọ iro ipè ati ariwo olori awọn angẹli.

Ipa ọna ti Ọlọrun yàn fun ayanfẹ Ọmọ Rẹ nihin ti ṣajeji to! Ibi irẹlẹ ati iku ẹsin, ṣugbọn ajinde ologo! Ohun ribiribi ṣẹlẹ ni aarin iba akoko diẹ. Wọn sẹ Ọmọ Ọlọrun, wọn kan An mọ agbelebu, a si gbe E sinu iboji; lẹyin gbogbo rẹ, ni owurọ ọjọ kẹta, O jinde! Ilẹ mì, apata sán, iboji si ṣi silẹ, awọn angẹli si ti Ọrun sọkalẹ, wọn si yí okuta kuro. Kristi, Ọmọ Ọlọrun, fi Ẹmi Rẹ lelẹ ki O le gba A pada.

Lẹyin ajinde Rẹ, obinrin ni O kọ fara hàn. Obinrin ni o kọ dẹṣẹ, ṣugbọn oun ni o si kọ de iboji lati ri Olugbala nigba ti O jinde. Obinrin ni a si kọ fi iṣẹ Ihinrere le lọwọ; “Lọ……..sọ.” Pẹlu itara ni o fi tan ihin ayọ naa kalẹ pe Jesu, Ọmọ Ọlọrun, ti ṣẹgun iku, O si wà laaye - O wà laaye titi lae!

Nitori Oun wà laaye, awa yoo wà laaye pẹlu. Ihinrere ologo! Ta ni jẹ kọ ọ? O kú fun ẹṣẹ wa; O si jinde fun idalare wa. O goke re Ọrun; o si tun n pada bọ. Paulu ka gbogbo nnkan sofo ki o le jere Kristi ati ki o le mọ Jesu ati agbara ajinde Rẹ. Awa ha n ka gbogbo nnkan sofo ki awa ki o le ni anfaani ipalarada? A ha n lakaka lati wà ni imurasilẹ de bibọ Jesu? “Olubukun ati mimọ ni ẹniti o ni ipa ninu ajinde ekini na” (Ifihan 20:6).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta ni sin Jesu sinu iboji titun ti ara rẹ?
  2. Ta ni Kristi kọ fara hàn lẹyin ajinde Rẹ?
  3. Ta ni yí okuta kuro ni ẹnu ọna iboji?
  4. Aṣẹ wo ni Kristi fi fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ?
  5. Awọn wo ni a o gbala? Awọn wo ni a o si dá lẹbi?
  6. Sọ diẹ ninu awọn igba ti a ri Kristi lẹyin ajinde Rẹ?
  7. Nibo ni O ti goke re Ọrun?
  8. Ki ni ikede ti awọn angẹli nì ṣe nigba ti Jesu goke re Ọrun?
  9. Eyi ha mu ayọ tabi ibanujẹ wá sinu ọkàn awọn ọmọ-ẹyin?
  10. Ki ni aṣẹ ikẹyin ti Jesu pa fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ.