Joṣua 7:1-26

Lesson 172 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹnikẹni le fi ara pamọ ni ibi ikọkọ, ti emi kì yio ri i? li OLUWA wi, Emi kò ha kún ọrun on aiye? li OLUWA wi” (Jeremiah 23:24).
Cross References

I Irekọja Akani

1. Akani dẹṣẹ nipa mimu ohun ti a ti fi gegun, Joṣua 7:1; 6:17, 18; Deuteronomi 13:17

2. Israẹli kò le ṣẹgun awọn olugbe Ai nitori ẹṣẹ wà laaarin wọn, Joṣua 7:1-12

II Aṣiiri Ẹṣẹ Tú

1. Akani fi ohun ti o ji pamọ, o si ro pe nipa ṣiṣe bayii oun yoo ja ajabọ kuro ninu iya ẹṣẹ oun, Joṣua 7:11; Orin Dafidi 10:6, 11, 13; 73:11; Jobu 22:13

2. Ọlọrun a maa tu aṣiiri gbogbo ẹṣẹ ati awọn ẹlẹṣẹ gẹgẹ bi O ti ṣe ni ti Akani, lai ṣe ojusaaju ẹni ti o wu ki o jẹbi, Joṣua 7:10-18; Jobu 34:22; Numeri 32:23; Oniwasu 12:14; Luku 12:2; 2 Samuẹli 12:13; Amosi 9:2, 3; Jeremiah 17:10; 23:

3. Niwaju Ọlọrun ati eniyan, Akani jẹ alaironupiwada ati ẹni idalẹbi, o si jiya ẹṣẹ - iku, Joṣua 7:20-26; Romu 1:32; I Kronika 10:13; Esekiẹli 18:4; Romu 6:23

III Ipinya pẹlu Gbogbo Ẹṣẹ

1. Oluwa lo akoko ẹṣẹ Akani lati tẹnu mọ ọn fun Israẹli pe gbigba ẹṣẹ láyè laaarin wọn ni o dí iṣẹ Ọlọrun lọwọ, Joṣua 7:11, 12; Awọn Onidajọ 2:14; 1 Kọrinti 5:1-13

2. Ibawi Akani ni gbangba jẹ ikilọ fun Israẹli nipa iru irekọja bawọnni lọjọ miiran, Joṣua 7:25, 26; Owe 26:26; 1 Timoteu 5:20

Notes
ALAYE

Irekọja laaarin Israẹli

“Ilu na yio si jẹ iyasọtọ si OLUWA, on ati gbogbo ohun ti mbẹ ninu rẹ…..Ati ẹnyin, bi o ti wù ki o ri, ẹ pa ara nyin mọ kuro ninu ohun iyasọtọ, ki ẹ má ba yà a sọtọ tán ki ẹ si mú ninu ohun iyasọtọ na; ẹnyin a si sọ ibudó Israẹli di ifibu, ẹnyin a si mu iyọnu bá a” (Joṣua 6:17, 18).

Ṣiwaju iṣẹgun ati idoti Jẹriko a ti kilọ fun gbogbo Israẹli nipa ohun iyasọtọ, pe ẹnikẹni ti o ba fọwọ kan ohun iyasọtọ yoo fa egun wa sori ara rẹ, yoo si ko iyọnu ba Israẹli lọpọlọpọ. Gbogbo Jẹriko ni a gbọdọ parun, àfi fadaka ati wura ati ohun elo idẹ ti a ya si mimọ, ni ki a fi silẹ (Joṣua 6:19). Ninu fadaka ati wura wọnyii ni Akani ti ṣoju kokoro rẹ, ti o si jí.

Nigba ti Israẹli lọ ba Ai pẹlu iwọnba eniyan diẹ, itiju ni wọn ba pada bọ nitori awọn eniyan Ai le wọn sá, wọn si pa eniyan mẹrindinlogoji ninu awọn Ọmọ Israẹli. Ọlọrun ko ba wọn lọ si ogun naa, wọn si ri i pe awọn jẹ alailagbara niwaju awọn alagidi wọnyii. Joṣua beere idi ti wọn fi ṣẹgun Israẹli lọwọ Ọlọrun; Ọlọrun si da a lohun pe ẹni kan laaarin wọn ti mu ninu ohun iyasọtọ o si ti sọ Israẹli di ẹni irira. Ọlọrun ki yoo bá Israẹli lọ si ogun titi wọn yoo fi mú irira naa kuro.

Oju Ọlọrun n Ṣẹṣọ

“Dide, yà awọn enia na simimọ, ki o si wipe, Ẹ yà ara nyin simimọ fun ọla: nitori bayi li OLUWA, Ọlọrun Israẹli wipe; Ohun ìyasọtọ kan mbẹ ninu rẹ, iwọ Israẹli: iwọ yio le duro niwaju awọn ọtá rẹ, titi ẹnyin o fi mú ohun iyasọtọ na kuro ninu nyin” (Joṣua 7:13).

Bi aṣẹ yii ti n lu bi agogo ni eti wọn, a paṣẹ fun awọn Ọmọ Israẹli lati wá ohun iyasọtọ naa laaarin wọn. Iwadii yii si bẹrẹ ni ọjọ keji ni owurọ kutukutu. Ẹya-ẹya, idile-idile, laaarin gbogbo Israẹli ni Joṣua dibo titi o fi kan ile Akani ni ẹya Juda. Ni opin gbogbo rẹ Akani duro niwaju Joṣua gẹgẹ bi ẹlẹbi. Akani ti lero lati fi ẹṣẹ rẹ pamọ, ki aṣiiri ma tú, ki oun si le lọ laijiya. Ki i ṣe Akani nikan ni o kọ ro ninu ara rẹ pe, “Ọlọrun ti ṣe mọ?” (Jobu 22:13). Ki i ṣe oun ni ẹni ti o kẹyin.

Lati igba ti Adamu ti gbiyanju lati fi ara rẹ pamọ ninu Ọgbà Edẹni kuro loju Ọlọrun, niwaju Ẹni ti ohun kan ko pamọ, awọn eniyan ti sa ipá wọn lati fi ẹṣẹ wọn pamọ ni ero pe aṣiiri wọn ki yoo tú. Wọn ni ero pe bi a ba tilẹ ri wọn, wọn yoo bọ ninu rẹ lailewu (Wo Sẹfaniah 1:12). Adamu wá ọna lati di ẹbi ẹṣẹ rẹ ru aya rẹ ṣugbọn Ọlọrun kò gba awawi Adamu, ko si si ẹni ti o ti ṣe awawi ti o tẹ Ọlọrun lọrun fun ẹṣẹ rẹ nigbakugba.

A Tú Aṣiiri Ẹṣẹ Akani

Kò pẹ ti aṣiiri Akani fi tu, nitori ẹṣẹ rẹ han si gbangba. Akani dabi ọlọtẹ si Ọlọrun, ti ko ronupiwada nidi gbogbo ọrọ yii. Igba ti Oluwa tú aṣiiri Akani, lẹyin ti a ti fi ibo wadii rẹ, ni o to jẹwọ ẹṣẹ rẹ. Awọn ọrọ ti o sọ ni iwọnyi: “Nigbati mo ri ẹwu Babeli kan daradara ninu ikogun, ati igba ṣekeli fadakà, ati dindi wurà kan oloṣuwọn ãdọta ṣekeli, mo ṣojukokoro wọn, mo si mú wọn; sawò o, a fi wọn pamọ ni ilẹ lãrin agọ mi, ati fadakà na labẹ rẹ” (Joṣua 7:21).

Eyi yii ni iba ijẹwọ ti Akani ṣe ti a kọ sinu Bibeli; ko si si ibikibi ti a gbe le ri ohun kan lati fi hàn pe Akani ki i ṣe alagidi ati ẹlẹṣẹ ti o buru jai. O ku bi ẹlẹṣẹ, pẹlu ainaani ninu ọkàn rẹ lati bẹbẹ fun aanu, tabi ki o gbiyanju lati ṣe atunṣe fun yiyọ Israẹli ati ile rẹ lẹnu.

Idajọ Ododo Ọlọrun

“Joṣua, ati gbogbo Israẹli pẹlu rẹ, si mu Akani ọmọ Sera, ati fadakà na, ati ẹwu na, ati dindi wurà na, ati awọn ọmọ rẹ ọkọnrin, ati awọn ọmọ rẹ obirin, ati akọmalu rẹ, ati kẹtẹketẹ rẹ, ati agutan rẹ, ati agọ rẹ ati ohun gbogbo ti o ní;…..Gbogbo Israẹli si sọ ọ li okuta pa; nwọn si dánasun wọn, nwọn sọ wọn li okuta. Nwọn si kó òkiti okuta nla lé e lori titi di oni-oloni” (Joṣua 7:24-26).

Bayii ni Akani ati awọn ara ile rẹ ṣe kú iku ẹsin nitori ojukokoro rẹ, aigbọran rẹ si Ọlọrun ati sisọ agọ awọn ọmọ Israẹli di irira. Njẹ a ṣe aisododo si Akani bi? Bẹẹ kọ. Akani jẹ iru awọn ti a n ka nipa rẹ ninu Iwe owe pe: “Ẹniti a ba mbawi ti o wà ọrùn kì, yio parun lojiji, laisi atunṣe” (Owe 29:1).

Iru iṣẹlẹ bayii ni Ọlọrun fi n tẹ ẹ mọ olukuluku eniyan leti pe Oun ki dá eniyan buburu lare. Ọlọrun ko ni inu didun ni iku eniyan buburu, ṣugbọn O n mu suuru O si n fara da a, eyi kò di I lọwọ ki O ma rán idajọ Rẹ ti o muna ti o si daju sori awọn ti o kẹgan aanu ati oore Rẹ (Ka Nahumu 1:3; Esekiẹli 18:23).

A ba Akani wi ni gbangba, a si fi ẹṣẹ rẹ hàn fun gbogbo Israẹli ki awọn ati awa naa le ri i, ki a si kẹkọọ nipa rẹ pe olukuluku ẹlẹṣẹ ti kò ba ronupiwada yoo duro ni ọjọ kan niwaju Ọlọrun ati eniyan, igbesi-aye rẹ yoo si fara hàn gbangba. Iru ipin Akani ni yoo jẹ ti ẹni naa - iku ati egbe ayeraye! Lẹyin ijọba Ẹgbẹrun Ọdun, Ọlọrun yoo gbe idajọ ododo kalẹ, gbogbo ohun ikọkọ ati ẹṣẹ ni a o si fi han gbangba; olukuluku ẹlẹṣẹ yoo si gba idajọ fun ẹṣẹ rẹ.

Iyara Ẹni Sọtọ Awọn Eniyan Ọlọrun

Bibeli jẹ akede otitọ, awọn ẹni ti o si n sin Ọlọrun ni ẹmi ati ni otitọ si ti jumọ fi ohùn ati ẹri wọn ṣọkan lati kede pẹlu pe ẹnikẹni ti o ba tẹle Ọlọrun ni lati jọ Ọlọrun ni ododo ati iwa mimọ. O ni lati yàgò fun gbogbo ẹṣẹ patapata ( Ka 1 Johannu 1:6, 7; 3:5, 10).

Ọrọ Oluwa si Israẹli ni pe “Ẹnyin o jẹ iṣura fun mi jù gbogbo enia lọ: nitori gbogbo aiye ni ti emi. Ẹnyin o si ma jẹ ijọba alufa fun mi, ati orilẹ-ède mimọ” (Ẹksodu 19:5, 6). Oluwa si tun sọ fun Israẹli pe: “ Ki ẹnyin ki o jẹ mimọ fun mi: nitoripe mimọ li Emi OLUWA, mo si ti yà nyin sọtọ kuro ninu awọn orilẹ-ède, ki ẹnyin ki o le jẹ ti emi” (Lefitiku 20:26). (Ẹ tun wo Numeri 23:9; Isaiah 52:11; Orin Dafidi 119:115). Eyi si ni iṣẹ ati ojuṣe olukuluku eniyan ti o n tẹle Ọlọrun Israẹli: lati jẹ mimọ gẹgẹ bi Oun ti jẹ mimọ. (Ka Lefitiku 19:2). Awa le ri nigba naa pe ki i ṣe kiki pe ki ẹni ti o n tẹle Ọlọrun ki o jẹ mimọ nikan, bi ko ṣe pe ki o pa ara rẹ mọ kuro ninu abawọn ayé. Nigba ti eniyan mimọ ba sọ ibarẹ Ọlọrun nu ti o si dẹṣẹ ẹlẹṣẹ ni a o maa pe e. O ti sọ isọdọmọ rẹ pẹlu Ọlọrun nù, o si ti di ọta Kristi.

Idi rẹ ni eyi ti iya ẹṣẹ Akani ṣe muna ti o si yá kankan bẹẹ. Ki i ṣe pe o ru ofin ẹri ọkàn rẹ nikan nipa jijale, ṣugbọn o tun rú ofin Ọlọrun, o si yọ Israẹli lẹnu nipa mimu ẹṣẹ wọnu ibudo awọn eniyan Ọlọrun, ti Ọlọrun ti paṣẹ fun pe ki wọn takete si ẹṣẹ.

Ọlọrun fun ẹlẹṣẹ layè lati bọ kuro ninu ẹṣẹ rẹ nipa itoye Etutu naa ti Ẹjẹ Jesu ṣe. Nitori naa Ọlọrun kò le fi ara da ẹṣẹ rara, ati ni ọjọ idajọ Ọlọrun, gbogbo ẹṣẹ ni a parun pẹlu gbogbo awọn ti o gba ẹṣẹ layè. Eṣu, awọn angẹli rẹ ati awọn ẹlẹṣẹ ni a o gbe sọ sinu adagun ina ainipẹkun (Ifihan 20:10-15).

Akani fẹ ẹṣẹ. O lepa rẹ ju ododo lọ; nigba ti ẹṣẹ rẹ ko o loju oun ko ronupiwada, nitori naa ni o ṣe parun. Eyi ni o mu ki wọn ṣẹgun Israẹli ni Ai. Ẹṣẹ wà laaarin wọn, ki Ọlọrun si to wà pẹlu wọn, wọn ni lati mu ẹṣẹ kuro.

Ọlọrun Paṣẹ Iwa Mimọ Lonii

Njẹ ọmọ Ọlọrun ti o n jẹwọ Kristi ni lati jẹ mimọ? Njẹ o ṣe e ṣe lati yẹra fun gbogbo ẹṣẹ? Dajudaju a ni lati jẹ mimọ. Ọlọrun ọkan naa lana, ati lonii, ati titi lae. Ohun ti pa laṣẹ fun ẹnikan, a pa a laṣẹ fun gbogbo eniyan. Ni akoko yii ti otitọ Bibeli tubọ fara hàn, ojuṣe ti o ga ni o beere.

Awa ko gbọdọ bá aileso iṣẹ okunkun kẹgbẹ pọ (Efesu 5:11). Paulu sọ fun wa pe: “Ba awọn ti o ṣẹ wi niwaju gbogbo enia, ki awọn iyoku pẹlu ki o le bẹru” (1 Timoteu 5:20). Yẹra kuro lọdọ awọn ti “nwọn ni afarawe iwa-bi-Ọlọrun, ṣugbọn ti nwọn sẹ agbara rẹ” (2 Timoteu 3:5). Paulu tun kọwe si ijọ Kọrinti nipa ọrọ bẹẹ: “ṣugbọn nisisiyi mo kọwe si nyin pe, bi ẹnikẹni ti a npè arakunrin ba jẹ àgbere, tabi olojukòkoro, tabi abọriṣa, tabi ẹlẹgàn, tabi ọmọtipara, tabi alanilọwọgbà; ki ẹ máṣe ba a kẹgbẹ; irú ẹni bẹẹ ki ẹ má tilẹ ba a jẹun. Nitori ewo ni b’emi lati mã ṣe idajọ awọn ti o nbẹ lode? Ki ha ṣe awọn ti o wà ninu li ẹnyin ṣe idajọ wọn? Ṣugbọn awọn ti o wà lode li Ọlọrun nṣe idajọ wọn. Ẹ yọ enia buburu na kuro larin ara nyin” (1 Kọrinti 5:11-13).

“Nitorina ẹ jade kuro larin wọn, ki ẹ si yà ara nyin si ọtọ, li Oluwa wi, ki ẹ máṣe fi ọwọ kàn ohun aimọ; emi o si gbà nyin. Emi o si jẹ Baba fun nyin, ẹnyin o si jẹ ọmọkunrin mi ati ọmọbirin mi, li Oluwa Olodumare wi,” (2 Kọrinti 6:17, 18).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni abayọri si ogun ti Israẹli kọ bá Ai jà?
  2. Ki ni fa iṣẹgun Israẹli ni Ai?
  3. Sọ gbogbo ọna ti Akani fi dẹṣẹ.
  4. Ki ni ṣe ti Ọlọrun fi kọ lati ran Israẹli lọwọ nitori ẹṣẹ ẹnikan?
  5. Ki ni ẹṣẹ Akani fà wá ba oun paapaa?
  6. Njẹ ijiya Akani pọ ju eyi ti awọn ẹlẹṣẹ miiran yoo fara gbá?
  7. Ki ni ṣe ti awọn ti o n tẹle Ọlọrun fi ni lati jẹ mimọ?
  8. Iru irẹpọ wo ni a lè ní pẹlu awọn ẹlẹṣẹ?