Lesson 173 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Ki ẹ jẹ oluṣe ọrọ na, ki o má si ṣe olugbọ nikan, ki ẹ mã tàn ara nyin jẹ” (Jakọbu 1:22).Cross References
I Awamaridi Ọgbọn Ọlọrun
1. Ọlọrun paṣẹ fun Israẹli ki o mu gbogbo awọn ọmọ ogun lọ lati kọju ija si Ai, ki i ṣe iba eniyan diẹ gẹgẹ bi ti igba iṣaju, Joṣua 8:1; 7:2-4
2. Ọlọrun ṣe ileri iṣẹgun lori Ai gẹgẹ bi iru iṣẹgun ti Jẹriko, Joṣua 8:2; 6:2; Orin Dafidi 44:1-7; Daniẹli 2:21; 4:35
3. Oluwa fun Joṣua ni eto ijagun naa, Joṣua 8:3-8; Awọn Onidajọ 20:28-48; Owe 21:30, 31; 1 Samuẹli 14:6-10
II Iṣẹgun ti Ọlọrun
1. Iwewe ogun lati ọdọ Ọlọrun wá fun Israẹli ni iṣẹgun lori Ai, Joṣua 8:9-29; Awọn Onidajọ 20:28-48; 2 Awọn Ọba 3:9-25; Owe 20:18; 24:6
2. Ikogun Jẹriko ni a gbọdọ ya sọtọ bi eso akọso fun Oluwa, ṣugbọn ikogun Ai jẹ ti Israẹli, Joṣua 8:2, 27; 6:18, 19, 24; Ẹksodu 22:29
Notes
ALAYEIleri Iṣẹgun
Iwe Mimọ wi pe : “Ibukún ni fun enia na, ipá ẹniti o wà ninu rẹ” (Orin Dafidi 84:5). Ipá ati agbara Israẹli wà ninu fifi tọkantọkan sin Ọlọrun Alaaye. Israẹli ba iṣubu ẹsín ati ẹlẹya pade ni Ai, nitori ọkan ninu awọn Ọmọ Israẹli ti mú ninu ohun iyasọtọ, nipa bayii o fa ègún wá sori wọn.
Nipa itọni Ọlọrun, Joṣua wadii gbogbo Israẹli wò titi a fi mọ ẹlẹbi naa. A wẹ agọ Israẹli mọ kuro ninu ẹbi nipa pipa Akani, ẹni ti o dẹṣẹ si Ọlọrun. Nisisiyii Ọlọrun tun ṣetan lati bukun Israẹli gẹgẹ bi O ti ṣe ni Jẹriko.
Má ṣe bẹru, bẹẹni ki àiya ki o má ṣe fò ọ: mú gbogbo awọn ọmọ-ogun pẹlu rẹ ki iwọ ki o si dide, ki o si gòke lọ si Ai: kiyesi i, emi ti fi ọba Ai ati awọn enia rẹ, ati ilu nla rẹ, ati ilẹ rẹ lé ọ lọwọ:
“Iwọ o si ṣe si Ai ati si ọba rẹ gẹgẹ bi iwọ ti ṣe si Jẹriko ati si ọba rẹ: kìki ikogun rẹ, ati ohunọsin rẹ, li ẹnyin o mú ni ikogun fun ara nyin: rán enia lọ iba lẹhin ilu na” (Joṣua 8:1, 2).
Bayii ni Ọlọrun ṣe ba Joṣua sọrọ, O si fun un ni iṣiri lati mu awọn ọmọ-ogun lẹẹkan si i lati bá Ai jà. Ọlọrun tun kọ Joṣua lọna ti yoo fi gba ilu naa. Itan ogun igba laelae fi hàn pe ilu olodi ki i saaba ṣubu lọwọ ọta. A ri i kà ninu awọn iwe asiko nipa ogun pe, o kere tan ẹgbẹ ọmọ-ogun ti o ba fẹ gbogun ti ibi ti a ba n ṣọ girigiri ni lati ni to ilọpo mẹta awọn jagunjagun ti wọn fẹ gbogun tì. Ni ayé ìgbà a ni bi a ba ṣẹgun ilu olodi, awọn ilu bẹẹ ki i ṣubu nipa agbara ogun nikan bi ko ṣe nipa ẹtan ati arekereke.
Awọn eniyan Ai gẹgẹ bi gbogbo awọn eniyan Kenaani, ti mọ nipa ogun jija ati itajẹ silẹ, o si ṣe e ṣe ki wọn le lagbara lati farada ogun Israẹli fun ìgbà pipẹ bi o tilẹ jẹ pe Israẹli pọ ju wọn lọ.
Israẹli kò ni ọgagun tabi awọn ọmọ-ogun ti a ti kọ ni ogun jija, nitori orilẹ-ede darandaran ni wọn. Iṣẹgun wọn kò wá nipa agbara tabi ọgbọn wọn bi kò ṣe lati ọdọ Oluwa ti O pinnu lati ṣẹgun fun wọn, ti O si lé orilẹ-ede Keferi jade nitori awọn eniyan Rẹ.
Fun ọpọlọpọ ọdun ni awọn orilẹ-ede Keferi ti o kọjuja si Israẹli ti kọ lati fi iyi ati ọla ti o tọ fun Oluwa, Ẹlẹda ayé ati ohun gbogbo ti o wà ninu rẹ. Nitori idojukọ yii wọn n jiya igbogunti lati ọwọ awọn eniyan Ọlọrun, Ọlọrun si ti pinnu iparun wọn nitori ẹṣẹ wọn.
Ètò Ìjà
Ọlọrun mọ pé Israẹli kò ni ẹrọ ìjà lati fi fọ ogiri ilu Ai ki wọn ba le gba ilu naa. Ni ọnà iyanu ni Ọlọrun mú ki ogiri ilu Jẹriko wó lulẹ, awọn Ọmọ Israẹli si wọ ilu naa lai si wahala pupọ. Ọlọrun le ṣe iru iyanu bayii ni Ai, ṣugbọn O yan ọna miiran.
Boya ijọ-ara-ẹni loju ni o mu ki awọn Ọmọ Israẹli tete rán awọn iba eniyan diẹ lati lọ bá Ai jà, nitori a ko ri i ka pe wọn fi ilana naa le Ọlọrun lọwọ, abayọrisi iwarapapa naa si fi han pe Ọlọrun ko lọwọ ninu rẹ. Akani fa egun Ọlọrun wá sori ibudo Israẹli, eyi mu ki awọn Ọmọ Israẹli di alailagbara niwaju ọta wọn, a si ṣẹgun wọn ni iṣẹgun ẹsín ati ẹlẹya.
Nisisiyii ilana Ọlọrun ni pe ki gbogbo awọn ọkunrin ogun ki o lọ bá Ai jà. Kò si olori-ogun ti o dabi Ọlọrun, ki yoo si si laelae. Angẹli Ọlọrun ti o pade Joṣua ṣiwaju ogun Jẹriko sọ fun un pe Oun wá gẹgẹ bi Olori-ogun Oluwa. Olori-ogun naa ti fi ipá Rẹ hàn lọpọlọpọ ìgbà, nitori a gbagbọ pe Oun ki i ṣe elomiiran bi ko se Ọmọ Ọlọrun, Jesu Kristi. Kò si ibẹru fun Joṣua mọ nitori Oluwa ni Olori-ogun naa.
Ọlọrun ṣe ilana ogun naa gẹgẹ bi Joṣua ṣe fi ẹsọ fa awọn ara Ai jade wá si gbangba nibi ti Israẹli yoo ti ráyè bò wọn mọlẹ. Ẹ ko ha ri bi o ti rọrùn to lati bori awọn eniyan buburu, bi a ba gba Ọlọrun láyè lati ṣe eto iṣubu wọn.
Iṣẹgun ni Ai
Joṣua fi awọn ọmọ ogun si ẹyin ilu Ai ni ibuba. Nigba ti o di owurọ awọn ọmọ-ogun iyoku kọju ija si ilu naa, wọn si fi ẹsọ fa wọn jade lati ba wọn jà. Bi awọn ara ilu Ai si ti jade gbangba, awọn Ọmọ Israẹli bẹrẹ si pẹyinda bi ẹni pe a n le wọn. Bi awọn ara ilu Ai ti ri eyi, wọn lero pe iṣẹgun ti jẹ ti wọn, gbogbo ilu si jade lati lepa awọn Ọmọ Israẹli. Lẹsẹkẹsẹ ni awọn Ọmọ Israẹli ti o wa ni ibuba lẹyin ilu sare jade wọ inu ilu naa ti ko si oluṣọ mọ, wọn si ti ina bọ ọ. Nigba ti awọn ara ilu Ai ri i pe ilu wọn n jona, wọn fẹ pada sẹyin, ṣugbọn awọn Ọmọ Israẹli ti bò wọn, wọn si pa wọn. Gbogbo awọn ti o ṣubu ni ilu Ai, ati ọkunrin ati obinrin, to ẹgbaa mẹfa (12,000) eniyan. Bẹẹ ni Ọlọrun ṣe fi iṣẹgun fun Israẹli lori ilu Ai.
A le wi pe awọn eniyan ilu Ai jere gbigbẹkẹ le ara wọn nitori wọn ko ka agbara Ọlọrun Israẹli sí, lati le fi iṣẹgun fun Israẹli. “O yi imọ awọn alarekerekè po, bẹẹli ọwọ wọn kò lè imu idawọle wọn ṣẹ. O mu awọn ọlọgbọn ninu arekereke ara wọn, ati ìmọ awọn onroro ni o tãri ṣubu ni ògedengbé” (Jobu 5:12, 13) Ipin awọn ara ilu Ai kò yatọ si eyi.
Iṣẹgun Nipa Igbọran
“Igbọran sàn jù ẹbọ lọ, ifetisilẹ si sàn jù ọra àgbo lọ” (1 Samueli 15:22). Ọlọrun fi iṣẹgun fun awọn Ọmọ Israẹli lori Ai nitori wọn gbọran si aṣẹ Ọlọrun. Nigba ti a rẹ wọn silẹ nitori aigbọran ti o wà laaarin wọn, wọn gbọran si Ọlọrun lẹnu wọn si wá ẹni ti n yọ Israẹli lẹnu. Nigba ti wọn si ti wẹ ibudo wọn mọ kuro ninu irira gbogbo, Ọlọrun wá saarin wọn lati fi iṣẹgun fun wọn lori awọn ọta wọn.
Awọn ara ilu Ai ki ba ti ni ija pẹlu Ọlọrun Israẹli bi o ba jẹ pe wọn ti gba ohùn Rẹ gbọ ni gbogbo ọdun ti o kọja ṣiwaju akoko iparun yii. Orikunkun ti wọn ṣe si aṣẹ Ọlọrun ni o mu ni ki Ọlọrun fi Israẹli ṣe ohun elo idajọ fun ilu Ai ati iyoku ilẹ Kenaani nitori ẹṣẹ wọn.
Ọlọrun sọ fun Israẹli pe ki i ṣe nitori ododo wọn ni a ṣe n fun wọn ni iṣẹgun lori awọn ọta wọn. “Ki iṣe nitori ododo rẹ, tabi nitori pipé ọkàn rẹ, ni iwọ fi nlọ lati gbà ilẹ wọn: ṣugbọn nitori iwabuburu awọn orilẹ-ède wọnyi li OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe lé wọn kuro niwaju rẹ, ati ki o le mu ọrọ na ṣẹ ti OLUWA ti bura fun awọn baba rẹ, Abrahamu, Isaaki ati Jakọbu. Nitorina ki o yé ọ pe, OLUWA Ọlọrun rẹ kò fi ilẹ rere yi fun ọ lati ní i nitori ododo rẹ; nitoripe enia ọlọrùn lile ni iwọ” (Deuteronomi 9: 5, 6).
A ri i kà pe Israẹli ṣe aigbọran to bẹẹ ti Ọlọrun fi tu wọn ká si gbogbo aye, a si pa wọn run gẹgẹ bi orilẹ-ède. Fun ọpọlọpọ ọdun Israẹli ko ni ibujoko ijọba nitori aigbọran wọn. Lai pẹ yii (1948) ni wọn ṣẹṣẹ di ẹni ti a mọ gẹgẹ bi orilẹ-ède oṣelu. Nipa aṣẹ Ọlọrun ni ẹni kọọkan ninu wọn ṣe wà laaye. Eyi kò ri bẹẹ fun awọn orilẹ-ede iyoku. Orilẹ-ede ti ko ba sin Ọlọrun ti ko si gbe ọla Rẹ ga yoo parun nigbooṣe. Iwe itan kun fun awọn orukọ orilẹ-ede nla, ti kò tun si mọ ni akoko yii nitori wọn kò ni akoko lati bu ọla fun Ọlọrun. Bakan naa ni o ri fun olukuluku eniyan. Akani jẹbi iwa buburu bẹẹ; o yọ Israẹli lẹnu, a si pa a run. Awọn ara ilu Ai kò sin Ọlọrun ki wọn si bu ọla fun Un, nitori naa ni a ṣe pa wọn run lati ọwọ awọn ti o fi ọla fun Ọlọrun, ti wọn si n sin In.
Jijọba pẹlu Kristi
Awọn eniyan mimọ Ọlọrun ni yoo ṣe akoso ayé nikẹyin, nitori Ọlọrun ti ṣe ilana rẹ pe awọn ti o ba fẹ Oun yoo maa ṣe akoso, wọn yoo si maa jọba pẹlu Oun. Gbogbo awọn ẹlẹṣẹ ni a o dà si adagun ina ti n jó laelae.
Questions
AWỌN IBEERE- Ṣe apejuwe eto bi Israẹli ṣe ba awọn ara Ai ja ti wọn ti wọn si ṣẹgun wọn.
- Ta ni ẹni ti o ṣe eto bi wọn yoo ṣe ja ija naa?
- Ki ni ṣe ti Ọlọrun fi ran Israẹli lọwọ lati bori awọn eniyan Ai?
- Ki ni ṣe ti Ọlọrun fi fẹ ki Joṣua kó gbogbo awọn ologun pẹlu rẹ lati bá Ai jà?
- Ki ni ṣẹlẹ si Israẹli nitori wọn ṣe aigbọran si Ọlọrun?
- Ta ni olori-ogun Israẹli?