Joṣua 9:1-27

Lesson 174 - Senior

Memory Verse
Akọsori: “Fi gbogbo aiya rẹ gbẹkẹle OLUWA; ma si ṣe tẹ si imọ ara rẹ” (Owe 3:5).
Cross References

I Awọn Ará Gibeoni ati Ète Wọn

1. Awọn ọba Kenaani pa awọn ọmọ-ogun wọn pọ lati gba ara wọn lọwọ Israẹli, Joṣua 9: 1, 2

2. Awọn olugbe Gibeoni rán ikọ fun alaafia, Joṣua 9:3-6

3. Joṣua ati Israẹli ṣe iwadi lọwọ awọn ará Gibeoni lati mọ orilẹ-ède ti wọn jẹ, Joṣua 9:7-13

II Àdéhùn

1. Awọn eniyan Israẹli ba awọn ara Gibeoni ṣe adehun ti wọn n fẹ lai beere imọran Ọlọrun, 9:14, 15

2. Lẹyin ijọ mẹta Israẹli ri i pe aladugbo ti o sunmọ tosi ni awọn ara Gibeoni i ṣe, Joṣua 9:16, 17

3. Israẹli bu ọla fun adehun wọn, Joṣua 9:18-20; Orin Dafidi 15:4

III Isinru, Èrè Itànjẹ

1. Ibẹru ni o mu ki awọn ara Gibeoni lo ọgbọn arekereke, joṣua 9: 24, 25

2. A dá awọn ara Gibeoni si, ṣugbọn wọn di ẹni ti o n sinru laelae, Joṣua 9:21-23, 26, 27

Notes
ALAYE

Awọn ọtá Israẹli

Nigbà ti awọn ọba Kenaani gbọ gbogbo ohun ti Ọlọrun ti ṣe fun Israẹli, nipa pípa gbogbo awọn ara Jẹriko ati Ai run, wọn gbara wọn jọ lati Israẹli jà. Boya imọ awọn ọba wọnyii ko ṣọkan ri lori ohunkohun ṣiwaju akoko yii, ṣugbọn nigba ti ewu yí wọn ká ni apapọ, wọn mọ pe o to akoko lati fi imọ ṣọkan lati jà.

Ki i ṣe akoko yii ti Israẹli, ogun Ọlọrun ti n panirun, wà lẹnu ibode wọn ni o yẹ ki wọn ṣẹṣẹ maa gbá ogun jọ. Ki ni ṣe ti wọn kò ti mu nnkan ṣe ṣiwaju akoko yii, nigba ti akoko ati anfaani wa? Awọn ẹlẹṣẹ duro lonii niwaju Ọlọrun gẹgẹ bi ẹlẹbi fun ẹṣẹ wọn, wọn si mọ daju pe idajọ Ọlọrun yoo wá sori wọn, afi bi wọn ba ronupiwada. O dara pupọ lati yi pada nisisiyii, nigba ti Ẹmi Ọlọrun n bẹbẹ ninu aanu Rẹ. Lati duro titi ẹṣẹ rẹ yoo fi wa ọ ri le pẹ ju. Iku ayeraye ni yoo yọri si bi iwọ ba bo awọn ẹṣẹ wọnni mọlẹ titi yoo fi tẹle ọ lọ si idajọ (1 Timoteu 5:24).

Ero Gibeoni

Kò si ninu awọn ara Kenaani ti o ni ọkàn lati jà nitori Ọga Ogo ti fi ẹrù kún àyà wọn. Wọn le gbiyanju lati gbeja ara wọn lọna ti wọn ba fẹ, ṣugbọn ko si nnkan ti o le ko ibinu Ọlọrun loju. “Bi a ba tilẹ fi ọwọ so ọwọ, enia buburu ki yio lọ laijiya” (Owe 11:21). Ko yẹ ki Israẹli ki o bẹru awọn iranṣẹ Satani ti wọn n gba ara wọn jọ lati ba wọn ja. “OLUWA mu imọ awọn orilẹ-ède di asan: o mu arekereke awọn enia ṣaki” (Orin Dafidi 33:10). Ọlọrun n ṣe itọju awọn ọmọ Rẹ loju mejeeji lọjọ oni gẹgẹ bi O ti ṣe itọju Israẹli nigba ni. “Nitori o da mi loju pe, ki iṣe ikú, tabi ìye, tabi awọn angẹli, tabi awọn ijoye, tabi awọn alagbara, tabi ohun igba isisiyi, tabi ohun igba ti mbọ, tabi òke, tabi ọgbun, tabi ẹda miran kan ni yio le yà wa kuro ninu ifẹ Ọlọrun, ti o wà ninu Kristi Jesu Oluwa wa” (Romu 8:38, 39). Bi a ba ya ẹnikan kuro lara Kristi, idi rẹ ni pe oluwarẹ kuna ninu iṣẹ rẹ si Kristi.

Nigba ti awọn ọba Kenaani n gbero ohun ti ko le gba wọn la kuro lọwọ Israẹli, awọn ara Gibeoni ati apapọ ilu mẹta miiran n ṣe eto yatọ lati sá asala. Awọn ilu wọnyii wà ni ikorita ọna ti o lọ si Palẹstini, awọn ni o si yẹ ki Joṣua kọjuja si nisisiyii. Bi awọn ara Gibeoni ba fẹ sá asala, wọn ni lati tete ṣe eto kiakia.

Wo bi oye awọn ara Gibeoni ti pọ to nipa ọrọ Ọlọrun. Wọn mọ pe Ọlọrun ti paṣẹ fun Israẹli lati pa gbogbo awọn ara Kenaani run (wo ẹsẹ 24). O dabi ẹni pe wọn mọ pẹlu pe awọn Ọmọ Israẹli ni anfaani lati ṣe adehùn alaafia pẹlu awọn orilẹ-ede ti o jinna réré si Kenaani (Deuteronomi 20:10-15).

Awọn eniyan dibọn bi ẹni pe wọn kò mọ ọrọ Ọlọrun lonii. Nigba ti a kà á pe, “Nwọn kò ha gbọ bi? Bẹni nitõtọ, Ohùn wọn jade lọ si gbogbo ilẹ, ati ọrọ wọn si opin ile aiye” (Romu 10:18), a gbagbọ pe awọn eniyan mọ Ọrọ Ọlọrun ju bi wọn ti le jẹwọ pe wọn mọ ọn lọ. Kò si ẹni ti a o dá lẹjọ fun ohun ti kò mọ, ṣugbọn yoo ṣe iṣiro lori gbogbo imọlẹ ti o ni. “Imọlẹ otitọ mbẹ ti ntàn mọlẹ fun olúkulùku enia ti o wá si aiye” (Johannu 1:9).

Ikọ Èké

Awọn ara Gibeoni lo anfaani ti wọn ni yii, wọn si fi ẹtàn gba ara wọn là. Wọn fi ara wọn pe ikọ ti o wá lati ọna jijin si Israẹli lati sin Oluwa Ẹni ti okiki Rẹ ti tàn kaakiri. Lati fi idi rẹ mulẹ pe ilu okeere ni wọn ti wá, awọn ara Gibeoni wọnyii wọ aṣọ akisa, bata yiya, wọn si mu akara ti o hùkàsì, ati igo awọ ti wọn ti lẹ. Wọn wi pe gbogbo awọn nnkan wọnyii ni wọn wà ni titun nigba ti wọn bẹrẹ irin-ajo wọn.

O dabi ẹni pe Joṣua ko gba awọn ikọ ti wọn ti Gibeoni wa wọnyi gbọ, nitori itan wọn kò daniloju. O beere ibi ti wọn ti wá lati fi hàn pe wọn ko le ba awọn ará Kenaani dá majẹmu. Awọn ara Gibeoni dahun pe ilu wọn jinna réré, boya ni Joṣua ti gbọ nipa rẹ ri, nitori naa ko ṣanfaani lati darukọ rẹ. Bata, aṣọ ati ohun-elo wọn ko ha fi hàn ju bi ọrọ wọn ti le ṣe? Wọn ro pe awọn kò beere nnkan nla lọwọ Joṣua, ju eyi, “Ẹ bá wa dá majẹmu”.

Awọn miiran ni inu dudun lati dara pọ mọ awọn Onigbagbọ ṣugbọn wọn ko fẹ gbe igbesi-aye Onigbagbọ. Awọn ẹlomiran bi Balaamu, fẹ kú ikú olododo; ṣugbọn ẹni ti yoo ba ku iku olododo yoo gbe igbesi-aye olododo. Irẹpọ tabi idapọ pẹlu eniyan le mu ki ọjọ ẹni gun laye, gẹgẹ bi o ti ri nipa ti awọn ara Gibeoni, ṣugbọn eyi kò le fun ni ni iye ainipẹkun. Lati ni iye ainipẹkun gba pe ki a ba Ọlọrun paapaa dá majẹmu, ki a si jẹ aṣẹgun ni ojoojumọ, nigba naa a o ni idapọ tootọ pẹlu awọn Onigbagbọ.

Wọn kò Gba Imọran lọwọ Ọlọrun

Joṣua ati awọn ọmọ alade Israẹli ba awọn Gibeoni dá majẹmu ti wọn n fẹ. Boya awọn ọmọ alade Israẹli tilẹ se ase fun awọn Gibeoni. Titi di isisiyii, ounjẹ ajọjẹ ni ilu awọn eniyan ila-oorun jẹ apẹẹrẹ ọrẹ timọtimọ. A sọ fun wa pe awọn ti o ba ba ara wọn jẹun papọ lọna bayii gbà pe majẹmu alaafia ti ko le parun ti so wọn pọ. “Awọn ọkunrin si gbà ninu onjẹ wọn, nwọn kò si bere li ẹnu OLUWA” (ẹsẹ 14). Awọn wọnyii ni ọrọ ti o ba ni ninu jẹ ju lọ ti a sọ nipa Joṣua ninu gbogbo Bibeli. Ki ni ṣe ti Joṣua ko fi beere imọran lọwọ Ọlọrun nipa Urimu ati Tummimu, ti i ṣe oju Ọlọrun, ti a fi fun un lati lò ni iru akoko bayii? Nigba pupọ ni awọn eniyan le tan ẹda ẹlẹgbẹ wọn jẹ, ṣugbọn wọn kò le tan Ọlọrun jẹ. “Jesu… ko si wa ki ẹnikẹni ki o jẹri enia fun on: nitoriti on mọ ohun ti mbẹ ninu enia” (Johannu 2:24, 25).

Njẹ iwọ ro pe inu Ọlọrun le dùn ki awọn ọmọ Rẹ maa gboke-gbodo lojoojumọ lai beere imọran lọwọ Rẹ. Jesu ko ha ba Marta wi nitori o n ṣe aniyan ayé pupọ: Oun ko ha si yin Maria nitori o jokoo lati kẹkọọ labẹ ẹsẹ Rẹ. Iru ọrọ ti o ba ninu jẹ ti a sọ nipa Joṣua ni lati jẹ ẹkọ fun wa ki iru ohùn kan naa ma ba fọ si wa. Kikuna lati beere imọran lọwọ Oluwa lori ohun kan ṣoṣo le mu aṣiṣe ti yoo mu inira ba wa ni gbogbo iyoku ọjọ ayé wa.

Ọlọgbọn Ayé

Awọn ara Gibeoni fi hàn pé ọlọgbọn ayé ni wọn, ṣugbọn Oluwa wi pe: “Emi ó pa ọgbọn awọn ọlọgbọn run, emi ó si sọ oyé awọn oloyé di asan…. Ọlọrun kò ha ti sọ ọgbọn aye yi di wère?” (1 Kọrinti 1:19, 20).

Ọpọlọpọ eniyan ni i ṣe ọlọgbọn aye lọjọ oni, wọn si ti kó awọn ẹsin jọ ti wọn ro pe yoo gbe wọn lailewu de Ọrun. Adabọwọ eto ofin ati ọgbọn ori awọn eniyan pọ lai lonka, olukuluku eniyan ni o ni ero ti rẹ ti o yatọ diẹdiẹ si ti ẹlomiran, ṣugbọn eto ofin ati igbekalẹ wọnyii kò to. Gẹgẹ bi ilana ọgbọn awọn ara Gibeoni ti yọri si ibanujẹ, dajudaju bẹẹ ni ohunkohun miiran yoo yọri si iparun afi eto igbala Ọlọrun nikanṣoṣo.

Ọnà Titọ

Ta ni o tọna, tabi ewo ni ọna ti o dara? Laaarin ọpọlọpọ otitọ Ọrọ Ọlọrun, Bibeli sọ otitọ ipilẹsẹ meji fun ni, “Ọmọ-enia kò ti wá ki a ṣe iranṣẹ fun u, bikoṣe lati ṣe iranṣẹ funni, ati lati fi ẹmi rẹ ṣe iràpada ọpọlọpọ enia” (Matteu 20:28) ati “Bikoṣepe a tún enia bí, on kò le ri ijọba Ọlọrun” (Johannu 3:3). Jesu tun sọ ohun kan naa lọna miiran pe: “Bikoṣepe ẹnyin ronupiwada, gbogbo nyin ni yio ṣegbé bẹẹ gẹgẹ” (Luku 13:3). Paulu jẹ ki o di mimọ fun awọn ara Kọrinti pe, “Emi ki yio mọ ohunkohun larin nyin, bikoṣe Jesu Kristi, ẹniti a kàn mọ agbelebu” (1 Kọrinti 2:2). Eyi yii ni ipilẹ ti o duro ṣinṣin, tí isin ti i ṣe itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun duro le lori: ati lati mọ Kristi ni lati ṣe ohun ti wu U lojoojumọ. Ohunkohun ti o ba yatọ si eyi ki yoo le duro ni ọjọ idajọ.

Ko si ọnà àbùjá si Ọrun. Jesu wi pe, “Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti kò ba gbà ẹnuọna wọ inu agbo agutan, ṣugbọn ti o ba gbà ibomiran gùn oke, on na li olè ati ọlọṣà….Emi ni ilẹkun: bi ẹnikan bà ba ọdọ mi wọle, on li a o gbà là” (Johannu 10:1, 9). Ọpọlọpọ eniyan ni wọn dabi awọn ara Gibeoni! Kiki ero wọn ni lati ni alaafia ti ara, ohunkohun ti o ba ṣẹlẹ si ọkàn kò ja mọ nnkan kan fun wọn mọ.

Àdéhùn ti a Kà Si

Nipa ọgbọn ẹwẹ ati ẹtàn, awọn ara Gibeoni ri ojurere Israẹli. Lẹyin ọjọ mẹta, Israẹli gbọ pé Gibeoni ati awọn ilu wọnni ti o kó ara wọn jọ, ko ju irin ọjọ diẹ si Gilgali, Israẹli si lọ sibẹ. Gbogbo ijọ eniyan Israẹli fẹ pa awọn ilu naa run, ṣugbọn Joṣua ati awọn ọmọ- alade Israẹli sọ fun awọn eniyan nipa majẹmu ti wọn ti ba Gibeoni dá. Bi o tilẹ ṣe pe lọnà ẹtàn ni wọn fi dá majẹmu yii, sibẹ ni iwaju Ọlọrun ni wọn ti dá a, awọn alaṣẹ Israẹli si fara mọ ọn. Bi awọn alaṣẹ Israẹli ba le ṣe bayii pẹlu eniyan, kò ha tọ ki awọn eniyan lọjọ òní fi ọwọ danindanin mú majẹmu ti wọn dá tọkantọkan pẹlu Ọlọrun ati pẹlu imọ ifẹ Ọlọrun si eniyan. Ọpọlọpọ ni o n ba Ọlọrun jẹ ẹjẹ nigba ti wọn ba wa ninu wahala, ṣugbọn nigba ti Ọlọrun ba ti gbọ adura wọn ti O si mu wahala naa kuro, wọn kò ni kà a si ohun danindanin lati san ẹjẹ wọn. Bawo ni yoo ti dara to lati dabi Joṣua ati awọn ọmọ-alade Israẹli ni iru ọna bayii, ki a si pa majẹmu ti a da niwaju Ọlọrun mọ. Nigba ti ọkàn kan ba pa majẹmu rẹ pẹlu Ọlọrun mọ, itanṣan ifẹ Ọlọrun yoo tàn sinu ọkàn bẹẹ.

Èrè Itanjẹ

Iyọrisi ẹtàn awọn ara Gibeoni ni pe a sọ wọn di wọn di ẹrú laelae gẹgẹ bi apọnmi ati aṣẹgi. Iwọ kò ha ri bi irọ ti n sọ eniyan di yẹpẹrẹ? Awọn ti o ti jẹ alagbara tẹlẹ ni a sọ di ẹru nitori wọn kò ni igboya lati sọ otitọ.

Ki ni i ba ṣẹlẹ si awọn ara Gibeoni bi o ba jẹ pe wọn sọ otitọ ki wọn si wá pẹlu ironupiwada tootọ. Njẹ Ọlọrun kan naa ti o pa Rahabu ati awọn ara ile rẹ mọ ninu iparun Jẹriko ko ha ni dá awọn ara Gibeoni wọnyii si? Njẹ Ọlọrun kan naa ti O pinnu lati pa Ninefe run kò yi ipinnu Rẹ pada nigba ti awọn olugbe inu rẹ fi tọkantọkan ronupiwada? A pa Ninefe run nikẹyin, ṣugbọn ironupiwada mu alaafia bá ilu naa fun nnkan bi igba (200) ọdún dipo iparun lẹyin ogoji ọjọ. “Ẹwẹ, nigbati emi wi fun enia buburu pe, Kikú ni iwọ o kú; bi on yipada kuro ninu ẹṣẹ rẹ, ti o si ṣe eyi ti o tọ ti o si yẹ; Bi enia buburu ba mu ògo pada, ti o si san ohun ti o ti jí padà, ti o si nrin ni ilana iye, li aiṣe aiṣedẽde; yiyè ni yio yè, on ki o kú” (Esekiẹli 33:14, 15). A ni idaniloju pe awọn ara Gibeoni i ba ri aanu gbà bi wọn ba fi ara wọn hàn gbangba fun Ọlọrun. Ọna kan ṣoṣo ni o wa lati bọ kuro ninu idajọ Ọlọrun, ọna naa si ni lati rọ mọ aanu Rẹ.

Iranṣẹ Tootọ

O ha tẹ Ọlọrun lọrun lati jẹ ki awọn ẹru wọnyii maa ṣiṣẹ fun Oun? O dabi O gba bẹẹ lati fi hàn pe Oun fọwọ si ohun ti Joṣua ati awọn ọmọ-alade awọn eniyan Israẹli ṣe; nitori ọwọ ti wọn ni si pipa majẹmu ti wọn ṣe niwaju Ọlọrun mọ. Ṣugbọn eyi le ṣai jẹ ilana pipe Ọlọrun. Ọlọrun kò fẹ awọn ọmọ-ogun ti a fi agbara fà wá sinu ogun Rẹ; awọn ti o tikara wọn yọnda ara wọn nikan ni Ọlọrun n fẹ. Awọn ọmọ Lefi wá gẹgẹ bi apẹẹrẹ fun gbogbo awọn ti o ba ṣiṣẹ fun Ọlọrun. Nigba ti Mose kigbe nigba a ni pe: “Ẹnikẹni ti o wà ni iha ti OLUWA, ki o tọ mi wá” (Ẹksodu 32:26), gbogbo awọn ọmọ Lefi dide fun iranlọwọ Ọlọrun. Apẹẹrẹ pataki miiran ni ti Isaiah, ti o dahun pe: “Emi nĩ; rán mi,” nigba ti o gbọ ohun Ọlọrun ti o wi pe, “Tali emi o rán, ati tani o si lọ fun wa?” (Isaiah 6:8). Iru awọn eniyan bayii lọkunrin ati lobinrin - awọn iranṣẹ ti yoo fi tinutinu yọnda ara wọn - ni Ọlọrun n fẹ lonii.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni iṣẹgun awọn Ọmọ Israẹli lori Jẹriko ati Ai mú bá awọn ọba Kenaani?
  2. Ki ni awọn ara Gibeoni ṣe nigba ti wọn gbọ nipa iṣẹgun awọn Ọmọ Israẹli?
  3. Bawo ni ilu awọn ara Gibeoni ti jinna tó si ibudo Israẹli ni Gìlgali?
  4. Ki ni ẹbẹ kan ṣoṣo ti awọn ara Gibeoni fi si iwaju Joṣua ati awọn ọmọ-alade Israẹli?
  5. Bawo ni awọn ikọ lati Gibeoni ṣe ri ibeere wọn gbà?
  6. Njẹ iwọ ro pe o dara lati lo ẹtan lati ri nnkan gbà ni ayé yii?
  7. Bawo ni a ṣe jẹ awọn ara Gibeoni niyà fun irọ ti wọn pa?
  8. Ki ni yoo ṣẹlẹ si gbogbo awọn èké ni ọjọ idajọ?
  9. Iru awọn eniyan wo ni Oluwa n fẹ ki wọn sin Oun?