Joṣua 10:1-27

Lesson 175 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: Ṣugbọn Ọlọrun wa mbẹ li ọrun: o nṣe ohunkohun ti o wu u” (Orin Dafidi 115:3).
Cross References

I Awọn Marun un Doju Ija kọ Ọkan Ṣoṣo

1. Iroyin pe Gibeoni ti ba Israẹli dọrẹ mu ipaya ba awọn ara Kenaani, Joṣua 10:1-3

2. Awọn ọba marun un pinnu lati gbe ogun ti Gibeoni, Joṣua 10:4, 5

3. Awọn ara Gibeoni ranṣẹ si Joṣua fun iranlọwọ, Joṣua 10:6; Isaiah 33:22

II Ọlọrun Ologun

1. Joṣua lọ fun igbala Gibeoni pẹlu ileri iranlọwọ Ọlọrun, Joṣua 10:7, 8; Awọn Onidajọ 4:14; Orin Dafidi 27:1, 2; Romu 8:31

2. Israẹli rìn ni gbogbo oru, wọn si yọ si awọn ọta lojiji, Joṣua 10:9, 10; 2 Timoteu 2:3; 4:7

3. Ọlọrun rọjo yinyin sori awọn ọta, lati pari iṣẹgun naa, Joṣua 10:11; Jobu 38:22, 23; Isaiah 30:30; Ifihan 16:21

III Ọjọ Gigun Julọ lati Igbà Dida Ayé

1. Lẹyin ti Joṣua ti ba Oluwa sọrọ, o paṣẹ pe ki oorun ati oṣupa duro jẹẹ, Joṣua 10:12, 13; Isaiah 38:8; Habakkuku 3:11

2. Bibeli sọ pe kò i ti si iru ọjọ ti o dabi ọjọ naa, Joṣua 10:14

IV Awọn Ọba ti a Ṣẹgun

1. Awọn Ọmọ Israẹli ri ọba marun un ti wọn sá si inu iho, Joṣua 10:15-17; Isaiah 2:10-12, 19-21; Ifihan 6:15-17

2. A yí awọn okuta nla di ẹnu iho naa, Israẹli si lepa awọn ọta, Joṣua 10:18, 19

3. Iṣẹgun jẹ ti awọn Ọmọ Israẹli patapata, Joṣua 10:20, 21; Orin Dafidi 2:8, 9

4. Joṣua ati awọn eniyan Israẹli pada bọ lati ṣẹtọ fun awọn ọba maraarun naa, Joṣua 10:22-27; Orin Dafidi 18:40; 110:1, 5; Isaiah 26:5, 6; Romu 16:20

Notes
ALAYE

Idaamu Laaarin Awọn ọtá

Irẹpọ ti awọn eniyan Gibeoni wá ti wọn si ri gbà lati ọdọ awọn Ọmọ Israẹli ti dá idagiri silẹ laaarin awọn olugbe iyoku ni Kenaani. Gibeoni jẹ ilu nla, awọn eniyan inu rẹ si jẹ akọni. Ki i ṣe kiki pe awọn ara Kenaani padanu oluranlọwọ pataki nikan, ṣugbọn awọn Ọmọ Israẹli jere awọn ọmọ-ogun ti Kenaani padanu. Ohun ti o tun kó ironu bá awọn ọba Kenaani ni pe ilu Gibeoni wà ni ikorita, ibẹ si ni ọna ti o lọ taara si Palẹstini.

Awọn ọba Kenaani, ọta wọnyii ronu pe ọna kanṣoṣo ni o kù wọn kù. Ọna naa ni pe ki wọn ṣẹgun Gibeoni, ki wọn si pa awọn ará ilu naa run, nitori wọn ti bá Israẹli dá ọrẹ. Wo o bi nnkan ti yí biri mọ awọn ara Gibeoni lọwọ! Wọn ti bá Israẹli dá majẹmu lati gba ara wọn là; ṣugbọn nisisiyii awọn ti wọn ti jẹ ọrẹ fun wọn ri ni o fẹ kọju ija si wọn lati pa wọn run yii. Gbogbo ẹni ti o ba yi pada si Ọlọrun yoo ri i pe ayé yii ki i ṣe ọrẹ oore ọfẹ; ṣugbọn eyi kò fi hàn pe majẹmu ti wọn ti wọn bá Ọlọrun dá kò niye lori.

Diduro de Ọlọrun

Awọn ara Gibeoni rán ikọ lọ sọdọ Joṣua lati sọ fun un pe awọn ọba awọn ara Amori ti kó ara wọn jọ pọ lati ba awọn ara Gibeoni jà. Wọn si fẹ ki Israẹli wá lati ràn wọn lọwọ ki o si gbà wọn silẹ lọwọ awọn ọta wọn.

Israẹli wà ni ibudo wọn ni Gilgali sibẹ, ni ibi kan naa ti wọn ti dó si lati igbà ti wọn ti ré Jọrdani kọja (Joṣua 4:19). Lati ibudo yii ni wọn ti ṣe aṣeyọri ogun Jẹriko ati Ai.

O le ya ni lẹnu pe eredi rẹ ti Israẹli kò fi tubọ ja lakoko yii lati gbà ilẹ wọn ni Kenaani. Awọn diẹ le wà ni ibudo ti eredi ilọra yii kò yé, ṣugbọn Joṣua n tẹlẹ Ọlọrun. Joṣua rí Ọgagun rẹ, o si gbọ awọn ọrọ oore-ọfẹ ni pe: “Bi olori ogun OLUWA ni mo wá si nisisiyi” (Joṣua 5:13, 14). O ti pinnu ninu ọkàn rẹ lati tẹle Olori ogun yii ati lati gbọran si aṣẹ Rẹ lai yẹ si ọtun tabi osi. Aṣiiri iṣẹgun Joṣua ni eyi, eyi nikan si ni ireti iṣẹgun awọn Onigbagbọ lonii. Jesu ni Ọgagun awọn ọmọ-ogun Oluwa; bi awa ba fẹ ṣe aṣeyọri ninu isin Rẹ, a ni lati ni ifẹ lati tẹle E lọ si ibikibi ti O ba n tọ wa si, Nigba ti O ba n tọ wa, ati lọnakọna ti O ba gbà n tọ wa. Jesu n ṣe itọni! Oun kò jẹ ti awọn ọmọ-ẹyin Rẹ si ibikibi ti Oun paapaa ki yoo le lọ.

“Bi Ọlọrun Bá Wà Fun Wa”

Laaarin igba ti Joṣua gbọ nipa idaamu ti o ba awọn ara Gibeoni, ni Oluwa wi pe: “Má ṣe bẹru wọn: nitoriti mo ti fi wọn lé ọ lọwọ; ki yio si ọkunrin kan ninu wọn ti yio le duro niwaju rẹ” (Joṣua 10:8). Gbogbo ikiya ti awọn Ọmọ Israẹli n fẹ ni yii. Lẹsẹkẹsẹ ni wọn gbe ogun nla dide, iru eyi ti o fẹrẹ ma lẹgbẹ titi di ọjọ oni. Wọn rin lati Gilgali titi de Gibeoni (irin bi ogoji ibusọ) ni oru ọjọ kan. Wọn tẹ ogun lati owurọ kutu, wọn si n jà fun nnkan bi i wakati mẹrinlelogun gbako lai sinmi. Bawo ni Israẹli ṣe le fara da iru inira bayii? A sọ fun wa ninu iwe Isaiah pe: “Awọn ti o ba duro de OLUWA yio tun agbara wọn ṣe; nwọn o fi iyẹ gùn oke bi idì; nwọn o sare, ki yio si rẹ wọn; nwọn o rìn, ãrẹ kì yio si mu wọn” (Isaiah 40:31).

Israẹli n duro de Ọlọrun - nitori naa wọn le rọ mọ ileri naa. Ileri miiran ti wọn tun le rọ mọ ni: “Bi ọjọ rẹ, bẹẹli agbara rẹ yio ri” (Deuteronomi 33:25). Ọjọ yii, jẹ ọjọ ti o yatọ, ṣugbọn awọn Ọmọ Israẹli ri agbara Ọlọrun ti o yatọ gbà lati le ri opin ọjọ naa pẹlu iṣẹgun.

Ohun Ìjà Ọlọrun

Ogun yii ko i ti i pẹ pupọ ti Ọlọrun ti bẹrẹ si bi awọn ọta ṣubu niwaju Israẹli. Awọn ọta bẹrẹ si sá lọ, Israẹli si n lepa wọn kikankikan. Ni akoko yii ni Ọlọrun ṣí ile ohun ija dà silẹ lati Ọrun wá, O si rọjo yinyin sori awọn ọta bi wọn ti n sá lọ. Ija afọnja kan kò moke to bayii ri. Bi atamatase ni yinyin n ta lu awọn ọta. Lati fi hàn pe Ọlọrun ni o n bà awọn Ọmọ Israẹli jà, a ri i pe yinyin naa kò ta ba ẹnikẹni ninu awọn Ọmọ Israẹli. Iye awọn ara Kenaani ti yinyin pa pọ ju awọn ti ogun Ọmọ Israẹli pa lọ.

Igbeja Iyanu

Bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun ti lé awọn ọta niwaju Israẹli, ti O si ti rọjo yinyin pa awọn ọmọ Amori, Joṣua ri i pe akoko ko ni si tó lati ṣẹgun ni kikún ki ilẹ to ṣú. O ṣe e ṣe ki awọn ọta fi oru boju ki wọn tun pada sinu awọn ilu olodi lati tun gbé ija ko awọn Ọmọ Israẹli. Joṣua mu ọrọ tọ Ọlọrun lọ ninu adura. Iyọrisi adura yii ni pe, Ọlọrun mí sí Joṣua lati paṣẹ fun oorun ati oṣupa lati duro jẹẹ, ki ọjọ naa ba le gun ju gbogbo ọjọ lọ. “Bẹẹli õrùn duro li agbedemeji ọrun, kò si yára lati wọ nìwọn ọjọ kan tọtọ. Kò si ọjọ ti o dabi rẹ ṣaju rẹ tabi lẹyin rẹ, ti OLUWA gbọ ohùn enia: nitoriti OLUWA jà fun Israẹli” (Joṣua 10:13, 14).

Aṣeyọri Joṣua

Wo aṣeyọri Joṣua ni ọjọ ti máni-gbàgbé yii. Ọlọrun ti fi ọta le Israẹli lọwọ. Lai si aniani Joṣua jẹ alakikanju ologun ti o n dari awọn ọmọ ogun rẹ bi wọn ti n lepa awọn ọta; sibẹ Joṣua wá ààye lati gbadura. Ki i ṣe ohun ti o ṣoro lati wá ààye lati gbadura ni igba ipọnju; ṣugbọn wo bi o ti yatọ nigba ti gbogbo nnkan ba n lọ deedee ti eniyan si n ro pe iṣẹ n di oun lọwọ to bẹẹ ti oun kò le ri ààyè to lati gbadura. Ki ni i ba ṣẹlẹ bi Joṣua ba duro de igba ti okunkun kùn ti ilẹ si ti ṣú ki o to wá imọran Ọlọrun? Iṣẹ iyanu ti Ọlọrun ṣe yii kò ni ṣe, ọjọ kò ni gùn siwaju, iṣẹgun ti wọn ni kò ni dé oju ami. Ohun ibanujẹ ni o jẹ pe awọn ọmọ ogun Ọlọrun ki i ri iṣẹgun ti o pe gba nitori wọn ki i gbadura nigba ti Ẹmi Ọlọrun ba n rọ wọn lati gbadura. Boya ọwọ wọn di pupọ nigba naa, wọn a si pinnu lati duro de igba ti o wọ; nígbà ti wọn ba si lọ gbadura, ibukun ti Ọlọrun ti pese silẹ fun wọn yoo ti rekọja. Ṣọra, ki o si jẹ mimọ!

Ọjọ Gigun un Nì

Ọlọrun ni o mi si Joṣua lati beere pe ki oorun ati oṣupa duro jẹẹ, - lati wà ni ipo wọn si Gibeoni fun akoko ti o tayọ ọjọ lasan. Joṣua kò jẹ beere ohun iyanu bayii ni idanu ara rẹ tabi lati fi gbé ogo ara rẹ ga; bi o ba ṣe eyi, Oluwa ki bá ti dahun adura rẹ (Jakọbu 4:3). Bi Ọlọrun ba mi si eniyan lati ṣiṣẹ, tabi ti O ba paṣẹ fun eniyan lati ṣe ohun kan, bi oluwarẹ ba si lọ pẹlu igbagbọ ninu Ọlọrun lati ṣiṣẹ naa, Oluwa yoo ṣí oke nidi, yoo si mu ki oorun duro jẹẹ, yoo ṣe ohunkohun ti o ba tọ lati mu ki iṣẹ naa yọri. Bi iṣẹ kan ba kuna, ẹbi rẹ ki i ṣe ti Ọlọrun, ohun ti o fa ikuna wà ninu àìní igbàgbọ tabi aigbọran si Ọlọrun ti ẹni naa, ti Ọlọrun n lò.

O jẹ ohun iṣoro fun awọn ẹlomiran lati gbagbọ pe Ọlọrun le mu ki oorun duro ni agbedemeji ọrun fun akoko diẹ ju bi o ti wà tẹlẹ ri. Awọn ọlọgbọn ori sọ fun wa pe aye ki i fi iṣẹju kan pere tase akoko ti o fi n yi oorun po lọdọọdun. Bakan naa ni ọwọ airi n ṣe akoso yiyi rẹ ni ojoojumọ to bẹẹ ti ki i tase rara. Bawo ni Ọlọrun ṣe pa ofin ti o n ṣakoso ẹda tì lati mu ki iṣẹ iyanu fifa ọjọ gùn si i ṣe e ṣe?

Sa Gbagbọ Nikan

O le ṣoro fun wa lati ṣe alaye bi Ọlọrun ti ṣe iṣẹ iyanu yii, o to fun lati gbagbọ pe Ọlọrun ṣe iṣẹ iyanu naa. Iṣẹ iyanu jẹ nnkan ti agbara Ọlọrun paapaa ṣe, eyi si ri bẹẹ nitori Ọlọrun ni o dá ohun gbogbo, ohun gbogbo wà ni ikawọ Rẹ, O si n ṣe akoso ohun gbogbo. Gbogbo ẹdá wà labẹ Ẹlẹda. Kò ṣoro fun ọmọ Ọlọrun lati gbagbọ pe Baba oun ti n bẹ lọrun le ṣe ohun gbogbo. Awa le sọ pẹlu Jeremiah pe: “A! Oluwa Ọlọrun! wò o, iwọ ti o da ọrun on aiye nipa agbara nla rẹ ati ninà apa rẹ; kò si ohun-kohun ti o ṣoro fun ọ” (Jeremiah 32:17).

Ohun ti o tun jẹ iyanu nipa ọjọ ti o gùn yii ni pe o fi afo kan silẹ titi. Awọn akẹkọọ nipa irawọ sọ pe wakati mẹrinlelogun din ninu akoko - wọn ko si le sọ idi rẹ nitori wọn kò wo inu Iwe Mimọ. Ninu rẹ ni idahun wa fun gbogbo ọkàn ti o ba fẹ mọ. Joṣua wi fun wa pe oorun “kò si yára wọ niwọn ọjọ kan tọtọ.” Bi a ba wo iwe Isaiah, a ka a pe Oluwa mu oorun pada sẹyin ni iwọn mẹwaa lara agogo-oorun Ahasi gẹgẹ bi ami fun Hesekiah: “Bẹẹni õrun pada ni ìwọn mẹwa ninu ìwọn ti o ti sọkalẹ” (Isaiah 38:8). Akopọ ohun ti o ṣẹlẹ wọnyii ni o fa wakati mẹrinlelogun naa ti awọn amoye irawọ wi pe o dín ninu akoko.

Israẹli Yọ Ayọ Iṣẹgun

Ki ọjọ gigun yii to pari, awọn Ọmọ Israẹli ti bori awọn ọta wọn patapata. Eyi jẹ ogun pataki julọ ti Israẹli jà ki wọn to gba ilẹ Kenaani. Israẹli ṣẹ ogun yii. “nitoriti OLUWA jà fun Israẹli.

Nigba ti gbogbo Israẹli pada si ibudo ni Makkeda, Joṣua paṣẹ pe ki wọn mu awọn ọba marun un wọnni lati inu ihò jade wá fun idajọ. Ohun iyanu ṣẹlẹ. Joṣua paṣẹ fun awọn balogun rẹ lati gbé ẹsẹ wọn le ọrùn awọn ọba wọnyii. Bayii ni a pa awọn ọba naa ti wọn lero tẹlẹ lati pa awọn Ọmọ Israẹli. Njẹ ìṣe Joṣua yii, ẹni ti oun funra rẹ i ṣe apẹẹrẹ Kristi, kò ha fi iṣẹ nla ti Ọmọ Ọlọrun wa ṣe laye hàn wa? “Nitoripe on (Kristi) kò le ṣaima jọba titi yio fi fi gbogbo awọn ọta sabẹ ẹsẹ rẹ. Ikú ni ọtá ikẹhin ti a ó parun” (1 Kọrinti 15:25, 26).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Nitori ki ni awọn ọba Kenaani ṣe daamu to bẹẹ nigba ti wọn gbọ pe awọn ara Gibeoni ti dá majẹmu alaafia pẹlu Israẹli?
  2. Ki ni awọn ọba wọnyii pinnu lati ṣe nitori ọrọ yii?
  3. Ìhà wo ni awọn ara Gibeoni kọ si wahala ti o wà niwaju wọn yii?
  4. Sọ ohun ti ogun Israẹli ṣe nígbà ti wọn gbọ nipa ìrọkẹkẹ awọn ọba Amori?
  5. Ta ni ran Israẹli lọwọ ninu ogun ti wọn bá awọn Keferi jà?
  6. O kere tán, sọ ọnà meji ti a gbà ran wọn lọwọ?
  7. Joṣua gbadura si Ọlọrun laaarin ogun yii. Sọ ohun ti o ṣẹlẹ ni idahun si adura naa.
  8. Ta ni ṣẹgun? Ki ni ṣe?
  9. Sọ ohun ti o ṣẹlẹ si awọn ọba Keferi wọnni.
  10. ọtá wo ni awọn Onigbagbọ yoo bori nipa ileri Ọlọrun?