Joṣua 22:1-34

Lesson 176 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ki a má mã kọ ipejọpọ ara wa silẹ, gẹgẹ bi àṣa awọn ẹlomiran; ṣugbọn ki a mã gbà ara ẹni niyanju: pẹlupẹlu bi ẹnyin ti ri pe ọjọ nì nsunmọ etile” (Heberu 10:25).
Cross References

I Iranpada ati Ibukun

1. Awọn ọmọ Reubẹni, Gadi, ati aabọ ẹya Manasse ti jẹ oloootọ si awọn àṣẹ Mose ati Joṣua, Joṣua 22: 1, 2; Numeri 32:20-29; Joṣua1:12-18

2. Wọn ti dara pọ pẹlu awọn arakunrin wọn lati jagun titi Ọlọrun fi fun Israẹli ni isinmi, Joṣua 22:3, 4; 21:43-45

3. Lẹyin ti o ti yin awọn aabọ meji ati aabọ tán fun iṣẹ wọn, Joṣua rán wọn pada lọ sile, Joṣua 22:5-8; 1 Kọrinti 15:58

II Pẹpẹ Kan ni Gileadi

1. Awọn ẹya meji mọ pẹpẹ kan ni iha ila-oorun Jordani, Joṣua 22:9, 10

2. Nigba ti awọn Ọmọ Israẹli ti o wà ni Kenaani gbọ nipa eyi, ẹru ibọriṣa bà wọn, Joṣua 22:11, 12; Deuteronomi 13:12-15

3. Finehasi ṣe aṣiwaju ikọ awọn olori lati ṣe iwadi ọran naa, Joṣua 22:13-20; Deuteronomi 13:14; Matteu 18:15; Iṣe Awọn Aposteli 15:2

III Pẹpẹ Ẹrí

1. Awọn eniyan Gileadi dahun pe pẹpẹ naa wà fun ẹrí nikan, Joṣua 22:21-28; Orin Dafidi 7:4, 5; 44:20, 21

2. Awọn ọmọ Reubẹni ati aabọ ẹya Manasse jẹ ẹjẹ ọtun lati gbọran si Ọlọrun lẹnu, Joṣua 22:29; 24:15-18, 21; Johannu 6:66-69

3. Ọrọ èsi awọn eniyan Gileadi tẹ awọn eniyan Israẹli lọrun, Joṣua 22:30, 31; Awọn Onidajọ 8:3; Owe 15:1; Romu 12:17, 18

4. Awọn ikọ naa pada sile lati royin fun awọn Ọmọ Israẹli, Joṣua 22:32-34; Iṣe Awọn Aposteli 15:22-31.

Notes
ALAYE

Isinmi fun Israẹli

Awọn ogun pataki ti Israẹli ní lati jà ki wọn to gba ilẹ Kenaani ti dopin, nitori Ọlọrun ti fi isinmi fun awọn ẹya Israẹli ni ilẹ ini wọn. Ogun jija ki i ṣe iṣẹ awọn Ọmọ Israẹli ṣugbọn bi o ti di ọran dandan wọn kò le kọ lati jà; nitori naa, Joṣua, ọgagun rere yii, mọ pe wọn kò ni i fi ọmọ-ogun pupọ ṣe mọ. Nitori eyi o pe awọn ọmọ-ogun Reubẹni, Gadi ati aabọ ẹya Manasse sọdọ rẹ lati dá wọn silẹ kuro ninu iṣẹ ogun ati lati rán wọn pada si ilẹ wọn ni iha keji Jordani.

Awọn eniyan wọnyii ti jẹ ọmọ-ogun rere. Bibeli kò sọ fun wa bi akoko ti wọn fi wà pẹlu Joṣua ti pẹ to, ṣugbọn awọn ti wọn n ṣiro akoko sọ fun wa pe o to nnkan bi ọdun mẹfa tabi meje ki wọn ṣẹgun, ati ki wọn to pin ilẹ Kenaani tán. Gẹgẹ bi a ti le mọ, awọn eniyan wọnyii kò pada si ilẹ wọn laaarin gbogbo akoko yii. Wọn ti pa gbogbo aṣẹ ti Mose fi lelẹ mọ nipa riran awọn arakunrin wọn lọwọ ninu ogun, wọn si ti gbọran si Joṣua lẹnu.

Aayun Ile

Lai si ani ani ọkàn awọn ọmọ-ogun yii n fà si ile nígbà miiran, ki wọn ki o le ri awọn ti wọn fẹran, ki wọn si wà pẹlu wọn; ṣugbọn gẹgẹ bi ọmọ-ogun tootọ, wọn mu suuru titi ọgagun fi jọwọ wọn lọwọ lọ. Wo bi eyi ti fara jọ igbesi-ayé ọmọ-ogun Kristi tootọ to. Oun wa ni oju ija ni ilẹ ti o jinna réré si Ilu-ibi rẹ. Ogun le gbona janjan, ṣugbọn Ọlọrun ti fi orin ati ireti kan sinu ọkàn rẹ fun awọn ohun ti o dara ju lọ

“Aye ki i ṣe temi

Mo n rekọja lọ ni

Iṣura on ’reti mi

Wa loke Ọrun giga”

Aayun Ọrun ati ile n yun ún nigbakuugba; ṣugbọn gẹgẹ bi olotitọ si Ọgagun rẹ, o fẹ duro nidii iṣẹ rẹ titi aṣẹ yoo fi de ti a o si fi tú u silẹ lati fi ayé silẹ. Ero nipa ti ile Ọrun ati awọn olufẹ rẹ ti o wà lọhun kò ṣi i lọwọ iṣẹ isin rẹ ti o niyelori si Ọlọrun. Kaka bẹẹ wọn tubọ tẹra mọ iṣẹ isin wọn, iru ero bayii a si mú ki Onigbagbọ di ọmọ-ogun tootọ si i.

Joṣua tú awọn ọmọ-ogun wọnyii silẹ, o si sure fun wọn pẹlu. Bi o tilẹ jẹ pe iṣẹ ti wọn ṣe jẹ sisan gbese ti wọn jẹ tabi imuṣẹ ileri wọn, sibẹ a sure fun wọn pẹlu, nitori wọn fi tọkantọkan ṣe iṣẹ naa. Awọn ọmọ-ogun wọnyii ti gbà lati ran awọn arakunrin wọn lọwọ lati gba ilẹ Kenaani, bi o tilẹ jẹ pe a ti fi ilẹ iha keji odo Jordani fun wọn ni ini. Wọn ti ṣe ojuṣe wọn, a si tun fun wọn ni ere ọpọlọpọ ọrọ: ohun ọsin, fadaka, wura, idẹ, irin ati aṣọ lọpọlọpọ, pẹlu ilẹ-ini ti i ṣe ti wọn tẹlẹ nipa majẹmu.

Èrè Onigbagbọ

“Gẹgẹ bẹẹli ẹnyin pẹlu, nigbati ẹ ba ti ṣe ohun gbogbo ti a palaṣẹ fun nyin tan, ẹ wipe, Alailere ọmọ-ọdọ ni wa: eyi ti iṣe iṣẹ wa lati ṣe, li awa ti ṣe” (Luku 17:10). Onigbagbọ kò ṣiṣẹ nitori èrè, ṣugbọn bi o ba fi tọkantọkan ṣe awọn ohun wọnni ti o jẹ iṣẹ rẹ lati ṣe ati awọn ohun ti Balogun rẹ pa laṣẹ fun un, èrè rẹ daju. Onigbagbọ ti jẹjẹẹ fun Oluwa rẹ lati sin In ati lati wà pẹlu Rẹ titi lae, ọpọlọpọ ọrọ ati ayọ ni a o si fi kun un. “Oluwa rẹ wi fun u pe, O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ: iwọ ṣe olõtọ ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pipọ: iwọ bọ sinu ayọ Oluwa rẹ” (Matteu 25:21).

Fi ere olododo yii wé ẹsan ti a o san fun awọn ti o tẹle Satani lẹyin. “Ikú ni ère ẹṣẹ” (Romu 6:23). Jesu yoo wi fun awọn ti o wà ni ọwọ osi Rẹ ni ọjọ idajọ pe “Ẹ lọ kuro lọdọ mi, ẹnyin ẹni egun, sinu iná ainipẹkun, ti a ti pèse silẹ fun Eṣu ati fun awọn angẹli rẹ” (Matteu 25:41). Ọna kan ṣoṣo ni o pe ti eniyan le yàn- oun naa ni pe ki a maa sin Baba wa Ọrun tọkantọkan láyé yii titi Oun yoo fi wi pe “Ọrẹ, bọ soke” (Luku 14:10).

Pẹpẹ Iranti

Awọn ẹya Reubẹni, Gadi ati aabọ ẹya Manasse pada lọ si ilẹ wọn ni iha keji ila-oorun odo Jordani. Ọkàn wọn ki yoo ṣai gbọgbẹ bi wọn ti dé aala ti o wà laaarin ilẹ wọn ati ile Ọlọrun ni Ṣilo. Wọn ni lati maa ronu boya iru irẹpọ ti wọn ni pẹlu awọn arakunrin wọn nigba ti wọn n pada lọ yii tun le jẹ ti wọn mọ. Boya ọjọ n bọ ti awọn Ọmọ Israẹli ti o wa ni ilẹ Kenaani yoo sọ fun awọn ti o wà ni ìhà keji Jordani pé: “Kili o kàn nyin niti OLUWA Ọlọrun Israẹli?”. Lati ri i daju pe eyi ki yoo ṣẹlẹ, awọn ẹya meji ati aabọ naa tẹ pẹpẹ kan ni ìhà ti wọn ni odikeji Jordani.

Itara fun Ọlọrun

Kò pẹ ti iroyin nipa pẹpẹ naa ni iha keji Jordani fi de eti igbọ awọn Ọmọ Israẹli. Lẹsẹkẹsẹ ni wọn kó ara wọn jọ ni Ṣilo lati bá awọn ẹya meji aabọ wọnyii jà. Eredi iyipada kankan bayii? Kò ti i pẹ ti wọn dagbere fun awọn arakunrin wọn wọnyii ti wọn si rán wọn lọ pẹlu ire. Ohun ti o wá kàn nisisiyii ni ogun? Ọlọrun ti paṣẹ fun awọn Ọmọ Israẹli pe wọn kò gbọdọ ni ju pẹpẹ kan lori eyi ti wọn yoo maa mu ẹbọ ati ọrẹ wọn wa. Ẹbọ ti wọn ba rú ni ibomiran bi kò ṣe ẹnu-ọna agọ ati niwaju awọn alufaa jẹ irubọ si eṣu (Lefitiku 17:3-9). Awọn Ọmọ Israẹli tun ni ofin lati pa ẹnikẹni ninu wọn ti o ba rú ofin Ọlọrun (Deuteronomi 13:12-15). A le ri I, nigba naa, pe itara rere ni fun Ọlọrun ni o fa a ti awọn eniyan Israẹli fi ta giri lati ṣe eyi.

Iwadii Otitọ

“Nigbana ni ki iwọ ki o bère, ki iwọ ki o si ṣe àwari, ki o si bère pẹlẹpẹlẹ (Deuteronomi 13:14). Nitori naa awọn Ọmọ Israẹli rán ikọ lati Ṣilo lọ si ọdọ awọn ẹya Reubẹni, Gadi ati aabọ ẹya Manasse lati wadii ohun ti o fa a ti wọn fi tẹ pẹpẹ nla yii. Finehasi alufaa ni aṣiwaju awọn eniyan wọnyii, pẹlu ọmọ-alade kọọkan lati inu ẹya mẹwaa Israẹli ti o wà ni iha ìwọ-oòrùn Jordani.

Nigba ti awọn ikọ wọnyii de ọdọ awọn eniyan ti wọn ro pe o jẹ arufin si Ọlọrun, wọn sọ pato ohun ti wọn bá wá. Finehasi ti o ṣe ẹnu fun awọn ọmọ-alade iyoku rán awọn eniyan naa leti pe ibọriṣa yoo mu idajọ kikoro wa lati ọdọ Ọlọrun, gẹgẹ bi ẹṣẹ ti Baali-peori. Agbegbe ibi kan naa ti awọn Ọmọ Israẹli ti dẹṣẹ yii ni wọn wà yii, ninu eyi ti ẹgbaa mejila (24,000) eniyan Israẹli kú nitori ẹṣẹ naa (Numeri 25:3, 9).

Finehasi tun tẹnu mọ otitọ yii pe ẹṣẹ awọn iba eniyan diẹ le fa ibinu Ọlọrun wá sori gbogbo ijọ. Akani ni ẹni kan ṣoṣo ti o rú ofin Ọlọrun ni Jẹriko, ṣugbọn gbogbo ogun Israẹli kò le tẹ siwaju ni Ai titi a fi mu ẹṣẹ naa kuro ninu agọ. Awọn Ọmọ Israẹli kò fẹ ki iru rẹ tun ṣẹlẹ mọ.

Ilẹ ha jẹ Alaimọ?

Finehasi le ti fi itara sọrọ ni ti ẹsùn rẹ si ẹya meji aabọ yii, ṣugbọn ifẹ si Ọlọrun ati otitọ ni o fa a. Ohun tí ẹya meji aabọ yii ṣe fara jọ ibi nitootọ, o si dabi iṣọtẹ si Ọlọrun. Finehasi sọ fun awọn eniyan naa pe bi wọn ba ro pe ilẹ-ini wọn kò jẹ mimọ, wọn ni lati fi ibẹ silẹ ki wọn si kọja odi keji Jordani lọ si ilẹ-ini Oluwa. Bi a tilẹ ti pin ilẹ Kenaani, awọn eniyan ṣetan lati wá ààyè fun awọn ẹya meji aabọ yii bi wọn ba fẹ lati wá si ibi ti Agọ Ọlọrun wà. O san ki awọn eniyan ti o wa ni Kenaani yọnda irọra wọn ati ohun-ini wọn ju lati gba isọtẹ laaye laaarin wọn. Ẹmi Onigbagbọ tootọ kọ ha ni eyi?

Ìdáhùn Pẹlẹ

Awọn ẹya meji ati aabọ gbọ ọrọ awọn ikọ yii titi delẹ. O dabi ẹni pe ọpọlọpọ eniyan ni wọn pé jọ lati gbọ ọrọ yii. Awọn ọmọ-ogun ti o ṣẹṣẹ ti Kenaani wá ti wọn si tẹ pẹpẹ yii, le wà nitosi lati gbọ ẹsùn naa.

Lẹyin ti ikọ yii ti dakẹ ọrọ i sọ,awọn ara Gileadi si sọ ti ẹnu wọn. Wọn sọ pe pẹpẹ yii ki i ṣe fun irubọ tabi ẹbọ, wọn si pe Ọlọrun lati jẹri si i pe otitọ ni ọrọ ti awọn sọ yii. Wọn sọ pe wọn bẹru pe akoko le de, ti a le ta wọn nù kuro ninu isin Ọlọrun ni pẹpẹ Ṣilo. Bi eyi ba ri bẹẹ, wọn n fẹ nnkan ẹri ti o le fi otitọ yii mulẹ pe Ọmọ Israẹli ni wọn ni tootọ. Wọn ro pe pẹpẹ yii ti wọn tẹ ni ihà ila-oorun Jordani, ti o fara jọ pẹpẹ Ọlọrun, yoo jẹ ẹri. Wọn tẹnu mọ ọn pe kò si ero iṣọtẹ lọkan wọn. Awọn ikọ gba ọrọ wọn si otitọ, wọn si pada si ilẹ wọn, wọn si yọ pe ọla Ọlọrun ti leke. Nigba ti awọn Ọmọ Israẹli gbọ iroyin rere yii, wọn fi ibukun fun Oluwa, wọn si mu ero ati gbogun ti ẹya meji ati aabọ naa kuro.

Gbigba Iyin

Gbogbo awọn Ọmọ Israẹli ati awọn ara Gileadi ni o yẹ ki o gba iyin fun ihuwasi wọn ni akoko yii. Awọn Ọmọ Israẹli ni ẹtọ lati wadii ọran awọn arakunrin wọn ti o rú wọn loju yii, wọn si yara lati mu ọrọ naa wá si iyanju. Wọn kò kọ ohun yoo gbà wọn, ṣugbọn wọn ṣetan lati ṣe ohunkohun lati ri i daju pe iṣọtẹ si Ọlọrun kò si laaarin wọn. Itara wọn fun Ọlọrun mu ire jade.

Awọn ara Gileadi fi hàn bi o ti yẹ lati huwa nigba wahala. Bi o tilẹ jẹ pe a ti gba ohun ti wọn ṣe lódì, sibẹ wọn farabalẹ lati gbọ gbogbo ibawi yii ki o to di pe wọn fesi. Iṣe wọn fara jọ ibi, ti awa Onigbagbọ si ni lati takete sí (1 Tẹssalonika 5:22); ṣugbọn gẹgẹ bi a ti le ri i, ọkàn wọn mọ niwaju Ọlọrun.

Akọsilẹ Rere

Iṣẹ olukuluku Onigbagbọ ni lati ni akọsilẹ rere niwaju Ọlọrun, ki Ẹmi Ọlọrun ki o le ba ẹmi rẹ jẹri pe ọmọ Ọlọrun ni oun i ṣe (Romu 8:16). Bi a ba n ba Onigbagbọ kan wi, yoo jẹ itunu pupọ ki oluwarẹ le lọ pẹlu irẹlẹ ati igboya lati fi ọrọ naa le Ọlọrun lọwọ lati jẹri si otitọ ọkàn rẹ (1 Kọrinti 4:3, 4); pẹlupẹlu ijẹri otitọ wà ti kò le ṣai fara hàn fun aye nígbà gbogbo nipa eso Ẹmi. “Ki ẹ si mura tan nigbagbogbo lati dá olukuluku lohùn ti mbere ireti ti o mbẹ ninu nyin, ṣugbọn pẹlu ọkàn tutù ni ìbẹru. Ki ẹ mã ni ẹri-ọkàn rere, bi nwọn ti nsọrọ nyin ni ibi, ki oju ki o le ti awọn ti nkẹgan iwa rere nyin ninu Kristi” (1 Peteru 3:15, 16).

A le wi pe Kristi ni Pẹpẹ nla fun wa ti O si n sọ olukuluku ẹbun di mímọ. Bi awa ba ni apẹẹrẹ Pẹpẹ yii ninu ọkàn wa, yoo jẹ ẹri ti dara ju lọ nipa ifẹ wa si I, ati ẹri fun gbogbo aye pe awa ni ipa ati ìpín ninu Rẹ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti Joṣua fi dá awọn ọmọ-ogun Reubẹni, Gadi ati Manasse silẹ?
  2. Awọn ọmọ-ogun Joṣua meloo ni o ti ẹya meji ati aabọ wá?
  3. Nigba ti Joṣua dá awọn ọmọ-ogun wọnyii silẹ, o ha jẹ ki wọn lọ lọwọ ofo?
  4. Ki ni ero ti o kọ wọ inu awọn Ọmọ Israẹli nigba ti wọn gbọ pe awọn ẹya meji ati aabọ ti tẹ pẹpẹ titun kan?
  5. Ki ni awọn Ọmọ Israẹli ṣe nipa ọrọ yii?
  6. Ki ni ohun ti awọn ara Gileadi wi lati dá ara wọn lare nipa pẹpẹ wọn?
  7. Njẹ iwọ ro pe ohun ti o mu ọgbọn lọwọ ni lati mọ pẹpẹ yii?