Joṣua 14:6-15; 19:49, 50; 21:43-45; 23:1-16

Lesson 177 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ọkọnrin kan ninu nyin yio lé ẹgbẹrun: nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin, on li ẹniti njà fun nyin, gẹgẹ bi o ti sọ fun nyin” (Joṣua 23:10).
Cross References

I Ìní ti Kalẹbu

1. Kalẹbu beere fun ipin ilẹ ti Ọlọrun ti ṣe ileri, Joṣua 14:6-9; Numeri 14:24, 30; Deuteronomi 1:36; Isaiah 1:19

2. Ọlọrun ti pa Kalẹbu mọ láàyè pẹlu pẹlu ara lile, Joṣua 14:10, 11; Deuteronomi 30:20; 34:7; Orin Dafidi 103:4, 5; Owe 3:1, 2

3. Kalẹbu ti mọ pe oun yoo doju ija kọ awọn ọmọ Anaki ṣugbọn igbẹkẹle rẹ wà ninu Ọlọrun, Joṣua 14:12-15; Filippi 4:13: Heberu 11:33, 34

II ọrọ Ọlọrun ṣẹ

1. Joṣua ni ẹni ikẹyin ninu awọn Ọmọ Israẹli lati gba ilẹ-ini, Joṣua 19:49; Filippi 2:3, 4

2. A yan ipin ti rẹ fun un ni ọdọ awọn arakunrin rẹ, awọn ọmọ Efraimu, Joṣua 19:50; Numeri 13:8, 16

3. Gbogbo ohun rere ti Ọlọrun ti ṣeleri ti ṣẹ, Joṣua 21:43-45; 1 Awọn Ọba 8:56; Titu 1:2; Heberu 10:23

III Jagunjagun ati Alakoso ti a Pọnle

1. Joṣua, arugbo, pe awọn olori awọn ẹya, awọn alagba, awọn onidajọ ati awọn olóyè ijọ jọ lati gbà wọn ni iyanju, Joṣua 23:1, 2; Iṣe Awọn Aposteli 20:17-35

2. A ti pin ilẹ naa, ṣugbọn awọn Keferi diẹ ṣẹku sibẹ, Joṣua 23:3-5; Deuteronomi 7:22, 23; Awọn Onidajọ 1:1-4; Orin Dafidi 44:1-3

3. Joṣua kilọ gidigidi fun Israẹli lati sin Ọlọrun, ki wọn si yẹra fun awọn oriṣa ati abọriṣa, Joṣua 23:6-13; Orin Dafidi 1:1, 2; Owe 4:26, 27; 1 Kọrinti 16:13; 2 Kọrinti 6:15, 16

4. Israẹli ti gba ire Ọlọrun ná, ṣugbọn ibi wà bi wọn ba kùnà lati pa awọn ofin Ọlọrun mọ, Joṣua 23:14-16; Awọn Onidajọ 2:11-15; Luku 21:33-36

Notes
ALAYE

A Gba Ilẹ Naa

Joṣua ti di arugbo, ọjọ ayé rẹ si ti n buṣe ni akoko ti wọn fi jà ti wọn si ṣẹ awọn ogun pataki ni Kenaani. Ọlọrun ran Joṣua ati awọn Ọmọ Israẹli lọwọ ninu gbogbo ogun ti wọn ti jà, sibẹ ilẹ pupọ kù lati gbà (Joṣua 13:1-6). Nipa agbara Ọlọrun ati awọn ọmọ-ogun Joṣua, a ti bi ọpọ awọn ọta wó, ṣugbọn yoo gbà wọn ni ọdun diẹ si i ki wọn to gba gbogbo ilẹ naa patapata. Nitori naa, Ọlọrun paṣẹ fun Joṣua lati pin ilẹ naa laaarin awọn ẹya mẹsan an ati aabọ ti o wà ni iwọ-oorun Jordani, Ki olukuluku ẹya le gba ini rẹ ki o si lé awọn iyoku ọta kuro ni ile-ini rẹ. Ileri Ọlọrun ni pe Oun yoo lé awọn ọta kuro “diẹdiẹ niwaju rẹ: ki iwọ ki o máṣe run wọn tán lẹẹkan, ki ẹranko igbẹ ki o má ba pọ si ọ” (Deuteronomi 7:22).

Kristiani Ologun

Ni ọna pupọ ni ogun Onigbagbọ fi fara jọ bi awọn Ọmọ Israẹli ṣe gba ilẹ Kenaani. Ọpọlọpọ ogun ni a n ja lẹgbẹkẹgbẹ pẹlu awọn ará ninu Oluwa, awọn miiran ni a si n dá nikan jà. Nigba ti Onigbagbọ kan ba ri arakunrin rẹ ninu aisan, inunibini tabi aini, iṣẹ rẹ ni lati dide fun iranwọ arakunrin rẹ. “Ẹ mã rù ẹrù ọmọnikeji nyin, ki ẹ si fi bẹẹ mu ofin Kristi ṣẹ” (Galatia 6:2).

Awọn ogun miiran wà ti awọn Onigbagbọ n jà ti kò hàn si ẹlomiran. “Olufẹ, ẹ máṣe ka idanwò iná ti mbẹ larin nyin, eyiti o de si yin lati dan nyin wò bi ẹnipe ohun àjeji li o de bá nyin” (1 Peteru 4:12). Ọlọrun n fẹ awọn ti a ti yiiri wò, ti a si ti danwo. Ọpọlọpọ idanwo ni o kọja oye awa ẹda; nitori naa ko ṣe e fi yé ẹlomiran. Nipa iranlọwọ Ọlọrun nikan ni ipinnu Ọlọrun nipa idanwo naa le fi mu ire jade ni igbesi-aye ọmọ-ogun Kristi naa. Ogun ti olukuluku ni lati jà ki o si molu ni. Paulu sọ nipa awọn ogun bayii nigbà ti ó wi pe: “Nitori olukuluku ni yio rù ẹrù ti ara rẹ” (Galatia 6:5).

Pipin Ilẹ Naa

Bi a ba sọ nipa ti ẹda, ki i ṣe ohun ti o rọrun lati pín ilẹ yii laaarin ẹya Israẹli mẹsan an ati aabọ. Ni tootọ Joṣua jẹ ọlọgbọn oṣelu, gbogbo Israẹli si fẹran rẹ; ṣugbọn bi o ba ṣe pe o dawọ le e lati pín ilẹ yii laaarin awọn ẹya wọnyii nipa ọgbọn ara rẹ, oun i bá bá iṣoro pade kiakia. Ẹlomiran wà ti ipin ti rẹ ko ni tẹ lọrun, nitori o ṣoro lati tẹ gbogbo eniyan lọrun. Nitori naa Ọlọrun ti ṣe eto ni ọjọ pipẹ bi wọn yoo ṣe pin ilẹ naa. “Ṣugbọn kèké li a o fi pín ilẹ na: gẹgẹ bi orukọ ẹya awọn baba wọn ni ki nwọn ki o ní i. Gẹgẹ bi kèké ni ki a pín ilẹ-iní na lãrin awọn pupọ ati diẹ” (Numeri 26:55, 56) “A ṣẹ keke dà si iṣẹpo aṣọ; ṣugbọn gbogbo idajọ rẹ lọwọ Oluwa ni” (Owe 16:33). Ọlọrun tikara Rẹ ti paala si ipin ti ẹya kọọkan, nitori naa, ẹni ti kò ba ni itẹlọrun si ipin ti rẹ, Ọlọrun ni o n bá jà.

Ibeere Kalẹbu

Ki a to ṣẹ kèké, awọn ọmọ Juda ati Kalẹbu wá si ọdọ Joṣua, wọn si beere pe ki o mu ileri Ọlọrun ṣẹ fun Kalẹbu (Numeri 34:19). Kalẹbu tun sọ gbogbo rogbodiyan ti o ṣẹlẹ ni Kadeṣi-barnea fun Joṣua, oun paapaa ko gbagbe. Ọlọrun ti ṣeleri fun Kalẹbu nigba naa pe “Ilẹ na nibiti o ti rè,” iru-ọmọ rẹ ni yoo si ni in (Numeri 14:24). Ọlọrun ṣe ileri yii fun Kalẹbu nitori “o ni ọkàn miran ninu rẹ, ti o si tẹle mi mọtimọti” (Numeri 14:24). Nisisiyii Kalẹbu beere ilẹ ini rẹ, “ọkàn miran” si tun fara hàn. Kalẹbu kò beere ibi ti o gbooro ti o si tẹju bi Lọti ti ṣe; oun beere Oke Hebroni nibi ti awọn ọmọ Anaki n gbé. Ilẹ ibi ti oun ti lọ ṣe ami rẹ ni eyi; ibẹ ni o si ti mú iroyin wa ba Mose pe: “Mo si mú ìhin fun u wá gẹgẹ bi o ti wà li ọkàn mi.”

Bi ọdun tilẹ n yi lu ọdun agbara Kalẹbu kò dinku. “Sibẹ emi lí agbara li oni gẹgẹ bi mo ti ní li ọjọ ti Mose rán mi lọ: gẹgẹ bi agbara mi ti ri nigbana, ani bẹẹli agbara mi ri nisisiyi, fun ogun, ati lati jade ati lati wọle” (Joṣua 14:11). Ọkan Kalẹbu ti n pongbẹ fun Ilẹ Ileri yii, ifẹ ọkàn rẹ fun ọpọ ọdun sẹyin ni pe, “Ẹ jẹ ki a gòke lọ lẹẹkan, ki a si gbà a: nitoripe awa le ṣẹ ẹ” (Numeri 13:30). O sọ fun awọn Ọmọ Israẹli nígbà naa ki wọn má ṣe bẹrù awọn eniyan ilẹ naa, “nitoripe onjẹ wá ni nwọn; àbo wọn ti fi wọn silẹ” (Numeri 14:9).

Awọn Èrè Igbagbọ

Kalẹbu fẹ fi han awọn eniyan nisisiyii pe igbagbọ oun ninu Ọlọrun fẹsẹ mulẹ. “Bọya OLUWA yio wà pẹlu mi, emi o si lé wọn jade, gẹgẹ bi OLUWA ti wi” (Joṣua 14:12). Ọlọrun bu ọlá fun ọrọ Rẹ ati ìgbàgbọ Kalẹbu nitori a kà a pe, “Kalẹbu si lé awọn ọmọ Anaki mẹta kuro nibẹ, Ṣeṣai, ati Ahimani ati Talmai, awọn ọmọ Anaki” (Joṣua 15:14).

Bi iwọ ba fẹ ki ogo Ọlọrun ki o fara hàn lara rẹ, iwọ ni lati mu iduro ti o yege ki o si rọ mọ eyikeyi ninu awọn ileri Rẹ pẹlu igbagbọ ti ko ṣaarẹ. Kalẹbu ni lati di ileri yii mu fun aadọta ọdun o din marun un (45). O ni lati kọja ninu iyangbẹ ilẹ ti o gbona nitori awọn arakunrin rẹ kuna: sibẹ Ọlọrun mu ileri Rẹ ṣẹ. Nigba ti iwọ ba di ileri Ọlọrun mu, awọn ohun ti ọwọ rẹ kò ka le yi ọ ká, má ṣe sọ ireti nù, ṣugbọn jẹ ki igbagbọ ati oju rẹ ki o wà lara Rẹ nitori Oun yoo mu ọ là á já.

Ipin Aṣẹgun

Joṣua, alakoso alakoso Israẹli ni o gba ilẹ-ini rẹ kẹyin ninu awọn Ọmọ Israẹli. Eyi jẹ ohun ti o jọ ni loju pupọ, o si fi hàn ni tootọ irú ẹmi iyanu ti o wà ninu eniyan Ọlọrun yii. Joṣua ni ẹni ti o dàgbà ju lọ ti o si ga ju ninu gbogbo awọn Ọmọ Israẹli ni akoko yii. Oun ni ọgagun awọn ẹgbẹ ogun ti o ṣẹgun Kenaani, eyi si mu ki o ni ẹtọ lati tete yan ilẹ-ini fun ara rẹ ati ile rẹ; ṣugbọn iru iduro yii fi hàn pe oun fi ilu ati awọn eniyan ṣiwaju ohun ti i ṣe ti ara rẹ. Joṣua ko ronu nipa ti ara rẹ titi oun fi ri i pe gbogbo Israẹli ti jokoo ni ilẹ-ini wọn. Ayé yoo jẹ ibi alaafia lati gbe bi olukuluku eniyan ati paapaa awọn alaṣẹ, ba le tẹle apẹẹrẹ iwa rere Joṣua yii.

Joṣua gba ilẹ-ini rẹ laaarin awọn arakunrin rẹ “gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA.” Boya Ọlọrun ṣe ileri ilẹ-ini fun Joṣua gẹgẹ bi O ti ṣe fun Kalẹbu. Joṣua yan ilẹ Timnati-sera ni oke Efraimu o si “kọ ilu naa.” Pupọ ninu awọn Ọmọ Israẹli ni o gba ilu ti wọn kò kọ, ati ọgbà ajara ati ọgbà olifi ti wọn kò gbin funra wọn, ṣugbọn Joṣua ni lati tún ilẹ-ini ti rẹ ṣe. Bẹẹ ni Kristi, Ẹni ti Joṣua n ṣe apẹẹrẹ Rẹ, n gbe pẹlu irẹlẹ laaarin awọn eniyan - ninu aini. Ẹni ti o wá lati fi isinmi fun awọn eniyan Rẹ, kò ni ibi ti yoo fi ori Rẹ lé (Luku 9:58).

Àníyàn Joṣua

Akọsilẹ ikẹyin itan igbesi-ayé Joṣua fi iduro tiiri ati iṣoro hàn ni igbesi-aye awọn Ọmọ Israẹli. Wọn ti gba ilẹ Kenaani nipa jijẹ oloootọ si Ọlọrun, ijẹ oloootọ yii kò si wá bẹẹ lasan, bi kò ṣe nipa akoso Joṣua. Nisisiyii akikanju alakoso yii ti di arugbo, ọjọ aye rẹ si n buṣe, iṣẹ pupọ si wà nilẹ lati ṣe. Aṣẹgun Kenaani yii bẹrẹ si ṣe aniyan pupọ nitori awọn eniyan rẹ. Wọn ti pin ilẹ naa tán, gbogbo eniyan si n gbe ni alaafia ni ilẹ-ini wọn, ṣugbọn pupọ ninu awọn keferi si kù sibẹ.

Nipa iṣẹgun wọn lori ilẹ naa, awọn Ọmọ Israẹli ti lu awọn ara Kenaani bolẹ ti wọn kò le tete gberi. Bi o tilẹ jẹ pe awọn Ọmọ Israẹli ti wà ni ilẹ yii fun ọdun diẹ sẹyin, sibẹ wọn kò mura lati tun lé awọn eniyan wọnyii ti wọn kù sinu odi ati ilu olodi laaarin wọn jade mọ.

Nitori eyi Joṣua pe awọn Ọmọ Israẹli jọ, awọn agba wọn, awọn olori, onidajọ ati awọn alaṣẹ wọn. O ti mọ ibi ti ewu gbe wà fun Israẹli: eyi ti i ṣe ìdàpọ pẹlu awọn ara Kenaani ti o ṣẹkù. Niwọn bi awọn Keferi yii ba si wa ni ilẹ naa sibẹ, awọn Ọmọ Israẹli wa ninu ewu àkóràn ibọriṣa eyi ti awọn eniyan naa n sìn. Iwuwo ọkàn Joṣua ni lati fi ipò awọn eniyan hàn fun wọn gbangba ati lati mu wọn bá Ọlọrun dá majẹmu ọtun, bi eyi ba le ṣe e ṣe.

Iṣẹ sí Ọlọrun

Jakọbu ti sure fun awọn ọmọ rẹ ki o to kú, bakan naa ni Mose ti sure fun awọn ẹya Israẹli mejila. Joṣua ati awọn eniyan Israẹli ti ri ọpọlọpọ imuṣẹ ire yii. Ọlọrun ti le mi si Joṣua lati sọ asọtẹlẹ si i nipa ohun ti yoo ṣẹlẹ si awọn Ọmọ Israẹli nigbooṣe, ṣugbọn eyi ko wulo mọ. Ṣugbọn ohun kan ni o ṣe danindanin, eyi ni lati tẹ ẹ mọ awọn ọmọ wọn leti lati ni ọkàn lati mọ iṣẹ wọn si Ọlọrun. Bi Israẹli ba le sin Ọlọrun, Joṣua mọ pe ọjọ iwaju yoo dara.

Joṣua le fi ẹnu kan awọn iṣẹgun ti wọn ti ni lati ẹyin wá. Ninu gbogbo ogun ti wọn jà, Ọlọrun ti fun wọn ni iṣẹgun; Ọlọrun ti fi gbogbo ilu wọnni ti wọn doti fun wọn. Ọlọrun ti O ṣe eyi ti o kọjá, ni ireti wọn ninu eyi ti o n bọ, bi Israẹli ba le gbẹkẹle E. Boya ọpọlọpọ awọn ọmọ-ogun ni a ti dà silẹ, ṣugbọn eyi kò ja mọ nnkan. “Ọkọnrin kan ninu nyin yio lé ẹgbẹrun: nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin, on li ẹniti njà fun nyin, gẹgẹ bi o ti sọ fun nyin” (Joṣua 23:10).

“Kò si ohun kan ti o tase ninu ohun rere gbogbo ti OLUWA Ọlọrun nyin ti sọ niti nyin” (Joṣua 23:14). Jijolootọ si Ọlọrun ti mu ere nla wá, yoo si maa mu un wá titi. Ọlọrun mu ọrọ Rẹ ṣẹ nitori awọn Ọmọ Israẹli pa majẹmu wọn mọ ni akoko yii. Joṣua fi hàn pe gẹgẹ bi ire ti maa n tẹle jijẹ oloootọ si Ọlọrun, gẹgẹ bẹẹ ni ibi n tẹle ṣiṣe ainaani Ọlọrun. Bi awọn Ọmọ Israẹli ba kọ lati pa Ọrọ Ọlọrun mọ, a o le wọn kuro ni ilẹ rere naa ti Ọlọrun ti fi fun wọn. Ọrọ Joṣua ṣẹ nigba ti a kó wọn lẹrú lọ si Babiloni, o si ṣẹ ni kikun nigba ti a tú awọn Ju kaakiri si gbogbo agbaye lẹyin ti wọn kan Kristi mọ agbelebu.

A kò le ka ọrọ Joṣua si awọn Ọmọ Israẹli ki a fi mọ lọdọ wọn nikan. Ọlọrun ni o mi si i lati sọ ọrọ wọnyii, wọn si n ba gbogbo eniyan wi nibi gbogbo. Bi o ti jẹ otitọ nigba aye Israẹli, bakan naa ni o ri ni ayé wa yii. Bi eniyan ba ti jẹ oloootọ si Ọlọrun to ninu ohun gbogbo, bẹẹ ni ibukun Ọlọrun, ire ati iye ainipẹkun yoo jẹ ti oluwarẹ to: bi eniyan ba si ti jẹ alainaani ati ọlọtẹ si Ọlọrun ati si Ọrọ Rẹ to, bẹẹ ni ibi ati iku ayeraye yoo jẹ opin rẹ “afi bi o ba ronupiwada”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Bawo ni wọn ṣe pín ilẹ Kenaani?
  2. Njẹ gbogbo awọn ara Kenaani ni wọn ṣẹgun nigbà ti wọn pín ilẹ naa?
  3. Ta ni Kalẹbu, ki ni o si beere lọwọ Joṣua? Njẹ o ri ibeere rẹ gbà?
  4. Nibo ni ilẹ-ini Joṣua wa, ìgbà wo ni o si gbà á?
  5. Ki ni Joṣua rò nipa igbẹyin awọn Ọmọ Israẹli?
  6. Ki ni ohun ti Joṣua ṣe lati mú ki ẹyin-ọla le san awọn Ọmọ Israẹli?
  7. Meloo ni ohun wọnni ti o tasè ninu ileri rere ti Ọlọrun ṣe fun Israẹli?
  8. Bawo ni awọn Ọmọ Israẹli ti tẹle imọran Joṣua pẹ tó?