Joṣua 24:1-33

Lesson 178 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Emi ti jà ija rere, emi ti pari ire-ije mi, emi ti pa igbagbọ mọ” (2 Timoteu 4:7).
Cross References

I Joṣua Ka Awọn Ibukun Ọlọrun

1. Joṣua kó awọn Ọmọ Israẹli jọ si Ṣekemu, o si ka awọn ibukun Ọlọrun, Joṣua 24:1; 23:2; 1 Samuẹli 10:19

2. Oluwa pe Abrahamu, Joṣua 24:2, 3; Gẹnẹsisi 11:26-32; 12:1; Iṣe Awọn Apọsteli 7:2-4

3. Jakọbu ati awọn ọmọ rẹ lọ si Egipti; Oluwa rán Mose ati Aarọni, O si tun rán arùn sori Egipti, Joṣua 24:4, 5; Gẹnẹsisi 46:1-6; Ẹksodu 3:7-11; Deuteronomi 4:34

4. A mú Israẹli jade kuro ni ilẹ Egipti; awọn ara Egipti rì sinu Okun Pupa, Joṣua 24:6, 7; Ẹksodu 14:5-10

5. Oluwa gba Israẹli kuro lọwọ awọn ọtá wọn, O si yí ègún Balaamu pada si ìre, Joṣua 24:8-10; Deuteronomi 23:4, 5

6. A fi Jẹriko le wọn lọwọ, a si ṣẹgun awọn ara Amori, Joṣua 24:11, 12; 6:1, 2; Ẹksodu 23:28

7. Oluwa fun Israẹli ni awọn ilu, ọgbà ajara ati ọgbà olifi, Joṣua 24:13; Deuteronomi 6:10, 11

II Ìpè sí Ipinnu

1. Joṣua gba wọn niyanju lati bẹru Oluwa, Joṣua 24:14; Deuteronomi 10:12; 18:13; Gẹnẹsisi 17:1

2. Joṣua sọ ipinnu rẹ fun wọn pe: oun ati awọn ara ile oun yoo maa sin Oluwa, Joṣua 24:15; Rutu 1:15-17; 1 Awọn Ọba 18:21; Gẹnẹsisi 18:19; Esekiẹli 20:39; Johannu 6:67

3. Pẹlu itara, awọn eniyan naa ṣe ileri lati sin Oluwa, Joṣua 24:16-18

4. Joṣua fi mimọ Oluwa hàn wọn, ati ewu ti o wa ninu ipada sẹyin, Joṣua 24:19, 20; Matteu 6:24

5. Awọn eniyan naa ṣeleri igbọran, Joṣua 24:21-24; Gẹnẹsisi 35:2; 1 Samuẹli 7:3; Orin Dafidi 119:173

6. Joṣua bá awọn eniyan naa dá majẹmu, Joṣua 24:25-28; Ẹksodu 15:25; Gẹnẹsisi 28:18; 31:48; Deuteronomi 31:19, 21, 26; Awọn Onidajọ 9:6; 2 Awọn Ọba 11:17

III Ikú ati Isinkú Joṣua ati Eleasari

1. Joṣua kú ni ẹni aadọfa ọdún a si sinku rẹ ni Ori-oke Efraimu, Joṣua 24:29, 30; Awọn Onidajọ 2:6-9

2. Fun igbà kan Israẹli sin Oluwa gẹgẹ bi wọn ti ṣeleri, Joṣua 24:31

3. A sin awọn egungun Josẹfu ni Ṣekemu, Joṣua 24:32; Gẹnẹsisi 50:25

4. Eleasari, olori alufaa, kú, a si sin in ni Ori-oke Efraimu, Joṣua 24:33

Notes

Ṣekemu

A tun ri i pe gbogbo awọn Ọmọ Israẹli pejọ si Ṣekemu. Ihín yii kan naa ni Abrahamu de, ti o si tẹ pẹpẹ si nigbà ti o kọkọ wọ ilẹ Kenaani. Ṣekemu jẹ ibi ti ọpọlọpọ ohun mimọ ti ṣẹlẹ. Ijoko ilu naa jẹ eyi ti o lẹwa lọpọlọpọ. O wà ni afonifoji ti o lọra, Oke Ebali jẹ aabo fun un ni ihà ariwa ati Oke Gerisimu ni ihà guusu. Isun omi si n ṣàn lati gẹrẹgẹrẹ oke ni ihà iwọ-oòrùn, eyi si sọ ilu ti o wà ni afonifoji yii di ọkan ninu ọgbà Kenaani.

Joṣua

O kù fẹẹfẹ ti Joṣua alakoso keji ni Israẹli yoo kọja lati Ilẹ Kenaani lọ si ilẹ Ọrun. Ẹri rẹ fẹrẹ fara jọ ti Paulu ti o wi pe: “Emi ti jà ija rere, emi ti pari ire-ije mi, emi ti pa igbagbọ mọ” (2 Timoteu 4:7).

A kọkọ gbọ nipa Joṣua gẹgẹ bi iranṣẹ kekere labẹ Mose, o ba a lọ si Oke Sinai, o duro lẹba oke naa nigbà ti Mose wà pẹlu Oluwa ninu okunkun biribiri lori oke fun ogoji ọsan ati ogoji oru. Lẹyin ti wọn ti ori oke sọkalẹ, wọn si ri awọn Ọmọ Israẹli bi wọn ti n jó yí ẹgbọrọ maluu ká. Joṣua duro ti Mose gbọnin-gbọnin ni gbogbo igbesi-ayé Mose, lẹyin ikú Mose, o di alakoso awọn Ọmọ Israẹli.

Joṣua jẹ alakoso ogun wọnni ti awọn Ọmọ Israẹli kọkọ jà, o si wà gẹgẹ bi ọgagun titi wọn fi ṣẹgun Ilẹ Kenaani. Igbà kan ṣoṣo ti wọn bori rẹ ni ogun Ai, nigbà ti ẹṣẹ wà ninu ibudo. Nigbà ti wọn si mu ẹṣẹ naa kuro, Ọlọrun fun wọn ni iṣẹgun ti wọn i ba ti ní tẹlẹ.

Nigbà miiran ẹwẹ ti wọn n jà lati gba Ilẹ Kenaani, Joṣua ti pinnu lati ṣẹgun awọn ọtá, ṣugbọn nigba ti o ri i pe oòrùn n wọ, o mọ pe ọjọ kò gùn tó fun wọn lati ni iṣẹgun kikún; nitori naa pẹlu igbagbọ ati igboya ti ẹnikẹni kò danwo ri, o jade si iwaju awọn eniyan, o si wi pe: “Iwọ run, duro jẹ lori Gibeoni; ati Iwọ, Oṣupa, li afonifoji Aijaloni” (Joṣua 10:12). Ṣiwaju eyi, ẹni kan kò ṣakoso awọn imọlẹ oju-ọrun lọna bayii ri.

O dabi pe ipejọpọ nlá yii ti awọn Ọmọ Israẹli pejọ ṣiwaju ikú Joṣua jẹ lati mu awọn eniyan naa dá majẹmu atọkanwa pẹlu Oluwa, ati lati fun wọn ni ìkìlọ ikẹyin nipa ibọriṣa. A gbagbọ pe Joṣua fi gbogbo ọkàn ati gbogbo àyà rẹ si ọrọ idagbere rẹ fun awọn eniyan wọnyii ti wọn jumọ jọ jade kuro ninu isinrú; ti wọn si ti ri ọwọ Ọlọrun lara wọn fun itọni laaarin aginju si ilẹ-ini wọn. Gẹgẹ bi iranṣẹ Ọlọrun ti n ṣẹṣọọ lori agutan kọọkan ninu agbo Ọlọrun, ti o si n fẹ lati ran olukuluku lọwọ lati wọ ẹnu-ọna Ogo, bẹẹ ni Joṣua n tọ Israẹli, ti o si n ṣaniyan lori wọn titi idile kọọkan fi gba ilẹ-ini ti rẹ ni Kenaani.

Ọrọ Ikẹyin Joṣua

Awọn ọmọde maa n duro leti ibusun obi wọn lati gbọ ọrọ ìkẹyìn lẹnu wọn ki wọn to kú; a gbagbọ pe bẹẹ ni o ri fun awọn Ọmọ Israẹli ti wọn tẹti lelẹ lati gbọ ọrọ ikẹyin aṣiwaju wọn ọwọn. O sọ gbogbo ibukun ti Oluwa ti fi fun wọn. O rán wọn leti gẹgẹ bi Ọlọrun ti mu wọn jade kuro ninu isinrú Egipti, ti O mu wọn kọja Okun Pupa ati laaarin aginju ti o ba ni lẹru, titi O fi mu wọn de Ilẹ Ileri nikẹyin.

Joṣua lo anfaani daradara yii lati rọ awọn eniyan ki wọn má ṣe lọwọ ninu ibọriṣa. O mọ ailera wọn ati bi o ti rọrun fun wọn to lati dara pọ mọ iwa awọn orilẹ-ède ti o yi wọn ká. Joṣua rán wọn leti oore Ọlọrun si Israẹli, lati igbà ipe Abrahamu si ibi ti i ṣe ibugbe rere fun wọn nisisiyii ni Ilẹ Ileri.

Joṣua sọ fun Israẹli pe wọn jẹ ajigbese si Ọlọrun fun idasi orilẹ-ède wọn, ki i ṣe nitori wọn ni ẹtọ si eyi tabi nitori iwa rere wọn ni, ṣugbọn nipa oore-ọfẹ Ọlọrun. Awọn baba wọn ti o ti gbe ihà keji odo lọhun ni, ni apa keji odo Euferate jẹ abọriṣa. Ṣugbọn Oluwa pe Abrahamu o si mu un wá si Kenaani, O sọ irú ọmọ rẹ di pupọ, O si ṣe ileri ilẹ naa fun un ni ini; nisisiyii Oluwa ti fi idi wọn kalẹ ni ilẹ rere naa - ilẹ ti wọn kò ṣe laalaa fun, ati ilu ti wọn kò tẹdo. Wọn n jẹ ninu ọgbà ajara ati ọgbà igi olifi ti wọn kò gbin. Gbogbo eyi ni wọn ri gbà nipa oore-ọfẹ Ọlọrun.

Ibukun ti o wà fun awọn Ọmọ Israẹli nipa ti ara, jẹ apẹẹrẹ ibukun ti ẹmi ti a fi fun wa nigbà Ihinrere yii. Kò si ohun kan ti a le ṣe lati ni ẹtọ si igbala. O n ti ọwọ Ọlọrun wá gẹgẹ bi ẹbun ọfẹ, eyi ti a rà fun wa lori Oke Kalfari. Ṣugbọn gẹgẹ bi ibukun awọn Ọmọ Israẹli ṣe rọ mọ igbọran wọn si ofin Ọlọrun bakan naa ni ibukun ti ẹmi ṣe rọ mọ igbọran wa si ọrọ Ọlọrun lonii.

Ìpè Joṣua si Ipinnu

Lẹyin ti awọn Ọmọ Israẹli ti pejọ, ti Joṣua si sọ gbogbo oore Ọlọrun lori orilẹ-ède wọn, eyi ti ọpẹ yẹ fun, o ké si gbogbo wọn lati fi hàn tọkàntọkàn bi wọn ba fẹ jẹ oloootọ ti wọn si fẹ gbọran si Ọlọrun lẹnu ki wọn si sin In lododo ati lotitọ; tabi “Bi o ba si ṣe buburu li oju nyin lati sin OLUWA, ẹ yàn ẹniti ẹnyin o ma si li oni” (Joṣua 24:15). Akoko ti o lọwọ ni eyi ni igbesi-ayé awọn Ọmọ Israẹli gẹgẹ bi orilẹ-ède. O si jẹ akoko ti o lọwọ ni igbesi-ayé ẹni kọọkan nigbà ti Ẹmi Ọlọrun n pe e lati ṣe ipinnu fun Kristi. Awọn kan ti mọ ninu ara wọn pe ipe ikẹyin ni wọn n gbọ. Ipe ikẹyin ni awọn Ọmọ Israẹli n gbọ lati ọdọ Joṣua ti i ṣe aṣiwaju wọn yii. Oun mọ bi akoko yii ti ṣe pataki to, o si pe wọn nijà nipa fifi apẹẹrẹ rere siwaju wọn nigbà ti o wi pe: “Bi o ṣe ti emi ati ile mi ni, OLUWA li awa o ma sin.”

Ikorita

A maa n sọ nigbà miiran nipa dide “ikorita” ni igbesi-ayé wa. Rutu ati Orpa de ikorita ni igbesi-ayé wọn nigbà ti wọn tẹle Naomi, iya-ọkọ wọn, jade lati ilu wọn lọ si Ilẹ Kenaani. Wọn de ibi iṣoro. Ọran ti o wá siwaju wọn ni pe: Njẹ wọn yoo ha lọ si Ilẹ Kenaani lati sin Ọlọrun Israẹli tabi wọn yoo ha padà lati sin awọn oriṣa Moabu? Ọpọlọpọ ni wọn n yan ohun kan naa ti Orpa yàn yii, eyi ni lati sin oriṣa ayé yii. Ṣugbọn Rutu fà mọ iya-ọkọ rẹ o si sọ ọrọ otitọ ti kò le parun yii, “Awọn enia rẹ ni yio ma ṣe enia mi, Ọlọrun rẹ ni yio si ma ṣe Ọlọrun mi” (Rutu 1:16), eyi ti o ti ru ifẹ ọpọlọpọ ọkàn soke lati wá Oluwa ati lati sin In. Wolii Joẹli mọ riri akoko ipinnu ninu asọtẹlẹ rẹ, o wi pe: “ọpọlọpọ, ọpọlọpọ li afonifoji idajọ, nitori ọjọ Oluwa kù si dẹdẹ ni afonifoji idajọ” (Joẹli 3:14).

Ìpè Elijah si Israẹli Afasẹyin

Ni nnkan bi ẹẹdẹgbẹta (500) ọdún lẹyin eyi, Elijah duro lori Oke Karmeli o si pe Israẹli afasẹyin nijà bayii pe: “Yio ti pẹ to ti ẹnyin o ma ṣiyemeji? Bi Oluwa ba ni Ọlọrun, ẹ mã tọ ọ lẹhin: ṣugbọn bi Baali ba ni ẹ mã tọ ọ lẹhin!” (1 Awọn Ọba 18:21). Awọn eniyan naa kò si dá a lohùn ọrọ kan; ṣugbọn nigbà ti Elijah fi ẹni ti i ṣe Ọlọrun otitọ hàn wọn, wọn da oju wọn bolẹ wọn si wi pe: “OLUWA, on li Ọlọrun; OLUWA, on li Ọlọrun.”

Iwọ ha ti dahùn ipe Kristi si ọkàn rẹ? Iwọ ha ti kọ ẹyin si ayé, ara ati eṣu, ki o si sọ lati ọkàn rẹ bi Joṣua pe: “Bi o ṣe ti emi ati ile mi ni, OLUWA li awa o ma sin.” Ni igbà ayé Jesu, nigbà ti ọnà naa há jù fun ọpọlọpọ ninu awọn eniyan naa, ti wọn si pada lẹyin Rẹ, Jesu kọju si awọn ọmọ-ẹhin Rẹ O si wi pe, “Ẹnyin pẹlu nfẹ lọ bi?” Peteru da A lohùn pe, “Oluwa, Ọdọ tali awa o lọ? iwọ li o ni ọrọ ìye ainipẹkun” (Johannu 6:67, 68).

Okuta Ìrántí

Ni ayé atijọ o jẹ aṣa lati maa to okuta jọ fun ọwọn iranti ohun pataki ti a ṣe ni ilu. Joṣua si mu okuta nlá kan o si gbe e kalẹ labẹ igi oaku kan ti o wà ni ibi mimọ Oluwa, gẹgẹ bi ẹri fun Israẹli pe Oluwa ti gbọ gbogbo ọrọ Majẹmu naa. Nigbà ti a ba bá Ọlọrun dá majẹmu, yoo rán Ẹmi Rẹ lati bá ọkàn wa jẹri pe majẹmu naa duro, adura wa si ti jẹ itẹwọgbà.

Isinkú Awọn Eniyan Nlá Mẹta

Ṣiwaju ikú Josẹfu ni ilẹ Egipti, o sọ fun awọn arakunrin rẹ pe ni tootọ Oluwa yoo bẹ wọn wò yoo si mu wọn jade lati Egipti wa si ilẹ ti O ti bura fun Abrahamu, Isaaki ati Jakọbu. “Josẹfu si mu awọn ọmọ Israẹli bura, wipe, Ọlọrun yio bẹ nyin wò nitõtọ, ki ẹnyin ki o si rù egungun mi lati ihin lọ” (Gẹnẹsisi 50:24, 25). O ni igbagbọ ti o yanilẹnu ninu ileri Ọlọrun. Ninu gbogbo irin-ajo wọn lati Egipti lọ si Ilẹ Ileri, wọn ru egungun Josẹfu ninu posi ti a fi okuta ṣe. Nisisiyii nigbà ti Oluwa ti fi idi wọn kalẹ ni ilẹ naa, wọn sin egungun Josẹfu ni ilẹ Ṣekemu, ibẹ si di ilẹ-ini awọn ọmọ Josẹfu.

Ori iwe yii sọ nipa ikú ati isinkú Joṣua ati Eleasari, olori alufaa. A sọ fun wa pe awọn eniyan naa si sin Oluwa ni gbogbo ọjọ Joṣua ati ni gbogbo ọjọ awọn àgbà ti o wà lẹyin Joṣua. Oluwa pe Joṣua lọ si Ọrun, o jẹ ẹni aadọfa (110) ọdún. O jẹ apẹẹrẹ Kristi, o si duro laaarin awọn eniyan nlá ayé. “Nigbà ti awọn olododo wà lori oyè, awọn enia a yọ; ṣugbọn nigbati enia buburu ba gori oyè, awọn enia a kẹdùn” (Owe 29:2).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Sọ awọn ohun pataki ti o sọ Ṣekemu di ilu nlá.
  2. Ki ni ṣe ti Joṣua fi kó awọn Ọmọ Israẹli jọ ni akoko yii?
  3. Nibo ni a ti kọkọ darukọ Joṣua ninu Iwe Mimọ?
  4. Ki ni ẹṣẹ ti o rọgbà yi Israẹli ká?
  5. Sọ diẹ ninu awọn ohun ti Joṣua kà ninu ọrọ ikẹyin rẹ?
  6. Ki ni ìpènijà ti Joṣua pe awọn Ọmọ Israẹli?
  7. Irú ipinnu wo ni a pe Israẹli lati ṣe ni ọjọ naa?
  8. Ki ni ṣe ti Josẹfu kò fi fẹ ki a sin oun si Egipti?