Luku 16:1-31

Lesson 179 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹniti o ba ṣe olõtọ li ohun kikini, o ṣe olõtọ ni pipọ pẹlu: ẹniti o ba si ṣe alaiṣõtọ li ohun kikini, o ṣe alaiṣõtọ li ohun pipọ pẹlu” (Luku 16:10).
Cross References

I Alaiṣootọ Iriju

1. A pe iriju naa lati ṣiro iṣẹ iriju rẹ, Luku 16:1, 2; Oniwasu 12:14

2. Iriju naa rò ninu ara rẹ ọnà ti oun yoo gbà nipa eyi ti oun kò ni túlẹ tabi ṣagbe nigbà ti oun ba padanu ipò oun, Luku 16:3, 4; Johannu 12:36; Efesu 5:8

3. O mu èrò rẹ ṣẹ lati wá oju rere awọn ajigbese oluwa rẹ nipa didin gbese wọn kù, Luku 16:5-7

4. Oluwa iriju naa yin in nitori ọgbọn rẹ lati ṣe nnkan kan nipa ipo rẹ, Luku 16:8

5. Awọn ọmọ ayé yii gbọn ju awọn ọmọ imọlẹ lọ, Luku 16:8, 9

6. Ẹni ti o ba ṣe oloootọ ni ohun kikini yoo ṣe oloootọ ni ohun nlá, Luku 16:10-13; 19:17; Matteu 25:21

II Iyọṣuti awọn Farisi

1. Awọn olojukokoro Farisi yọ ṣuti si Jesu, ṣugbọn Oun sọ fun wọn pe Ọlọrun mọ ọkàn wọn, Luku 16:14, 15; Matteu 23:14

2. Ofin ati awọn wolii wà titi di igbà Johannu, ṣugbọn kikini ninu ofin ki yoo yẹ, Luku 16:16, 17; Matteu 11:12, 13

3. Jesu ba ẹṣẹ panṣaga wi, Luku 16:18; Matteu 5:32; 19:9; Marku 10:11; 1 Kọrinti 7:10, 11

III Ọkunrin Ọlọrọ ati Lasaru

1. Ọkunrin ọlọrọ kan n jẹ ìgbádùn, alagbe kan a si maa jokoo ni ẹnu ọnà rẹ, Luku 16:19-21; Jobu 2:7; 1 Peteru 4:3, 4

2. Alagbe naa kú, awọn angẹli si gbe e lọ si ookan àyà Abrahamu; ọkunrin ọlọrọ naa kú a si sinkú rẹ, Luku 16:22; Oniwasu 9:2; 1 Peteru 4:17

3. Ọkunrin ọlọrọ naa lọ si ọrun apaadi, ibi oró; Lasaru lọ si ibi itura nlá, Luku 16:23

4. Bi o ti n joro ninu ọwọ iná, ọkunrin ọlọrọ naa bẹbẹ fun ìrọra ati itura, Luku 16:24; Marku 9:44

5. Abrahamu sọ fun un pe ki o ranti igbà ayé rẹ ati ti Lasaru; nisisiyii ara tu Lasaru, ọkunrin ọlọrọ si n joro, Luku 16:25; Jobu 21:13; Isaiah 66:24

IV Kò si Rirekọja lati Ọrun Rere lọ si Ọrun Apaadi

1. Kò si ẹni ti o le ti ibi kan kọja si ibi keji, Luku 16:26

2. Ọkunrin ọlọrọ naa bẹ Abrahamu ki o le kilọ fun awọn arakunrin oun marun un, Luku 16:27, 28

3. “Nwọn ni Mose ati awọn woli; ki nwọn ki o gbọ tiwọn,” Luku 16:29; Isaiah 8:20; Johannu 5:39, 45; Iṣe Awọn Apọsteli 15:21

4. Ọkunrin ọlọrọ naa tẹnu mọ ọn pe iṣẹ iyanu kan yoo mu ki wọn ronupiwada, Luku 16:30

5. “Bi nwọn kò ba gbọ ti Mose ati ti awọn woli, a kì yio yi wọn li ọkan wọn pada bi ẹnikan tilẹ ti inu okú dide,” Luku 16:31; Johannu 12:9-11

Notes

A ni akọsilẹ ninu ọrọ Ọlọrun nipa ọkunrin kan ti i ṣe iriju fun ọlọrọ ati olokiki eniyan kan. A fi iriju yii sùn pe o n fi ohun-ini oluwa rẹ ṣòfò. Nigbà ti o si gbọ pe a o pe oun lati ṣiro iṣẹ iriju, o bẹrẹ si i ṣe ètò bi a kò ṣe ni ti oun jade si ayé lairi ibi ti oun yoo gbe. Oju n ti i lati ṣagbe, igberaga kò si le jẹ ki o walẹ fun ounjẹ oojọ rẹ.

Nigbà ti o ro eyi ti yoo ṣe, o pe awọn ajigbese oluwa rẹ o si beere iye ti ẹni kọọkan wọn jẹ. O jẹ àṣà ni ayé igbà nì fun ajigbese lati ṣe iwe adehùn eyi ti iriju yoo fi ọwọ si. Iriju a maa ni aṣẹ patapata lori ohun-ini oluwa rẹ.

Ọkan ninu awọn ajigbese wi pe oun jẹ ọgọrun oṣuwọn ororo. Iriju naa si wi fun un pe ki o jokoo werewere ki o kọ aadọta, nipa bayii a din gbese rẹ kù. Ẹni keji si wi pe oun jẹ ọgọrun oṣuwọn alikama. Iriju naa si wi fun un pe ki o kọ ọgọrin. Oluwa iriju yii yin in nitori o dọgbọn lati ran ara rẹ lọwọ. Gẹgẹ bi igbekalẹ oun tikara rẹ, iriju yii ti fi ọgbọn ṣe ìpèsè bi yoo ti tọju ara rẹ.

Awọn Ọmọ Imọlẹ

Awọn Ju ni ọmọ imọlẹ, wọn si n pe awọn Keferi ni ọmọ ayé tabi ọmọ okunkun. Jesu sọ otitọ yii pe awọn ọmọ ayé yii gbọn ni iran wọn ju ọmọ imọlẹ lọ. Alaiṣootọ iriju yii lo ohun ti o wà lọwọ rẹ lati pese fun ọjọ iwaju. A mu Ihinrere Ọlọrun tọ awọn Ju wá. Wọn ni anfaani lati wo iwaju ki wọn si pese fun ayeraye; ṣugbọn, yatọ si iriju inu owe yii, wọn lọra lati lo anfaani ti Ọlọrun pese fun wọn.

A kò yin iriju yii fun iwa aiṣododo rẹ. A yin in nitori o ri wahala ti o n bọ wa ba a, o si mu ohun kan ṣe nipa rẹ. Nigbà ti awọn eniyan ri ibi ti ẹṣẹ n ṣe ni igbesi-ayé wọn ati ègbé ayeraye ti n tẹle wíwà ni ipo ẹsẹ, bi wọn ba le ṣe ohun ti o yẹ ki ọmọ imọlẹ ṣe, ti wọn si lo anfaani ti Ọlọrun pese fun igbala wọn; ṣiṣe bẹẹ yoo jasi pe wọn n to iṣura jọ fun ara wọn gẹgẹ bi ipilẹ rere de ọjọ iwaju.

“Ẹ fi mammoni aiṣõtọ yàn ọrẹ fun ara yin.” Jesu n sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ nihin yii pe, gẹgẹ bi ọmọ imọlẹ, wọn kò gbọdọ ya ara wọn kuro lara awọn eniyan ṣugbọn wọn ni lati fi ifẹ hàn fun wọn, ki wọn ba le ni anfaani lati sọ ìtàn Jesu fun wọn ati nipa eyi ki wọn le jere wọn fun Jesu. Wọn ni lati lọ si gbogbo ayé lati waasu Ihinrere (Matteu 28:19; Iṣe Awọn Apọsteli 1:8).

Mammoni Aiṣododo

Owó ni a n pè ni mammoni aiṣododo nihin. Owó wulo fun wa lati ra awọn ohun-elo ti a ni lati lò lojoojumọ, ṣugbọn ifẹ owó ati wíwá a lọnà àìtọ, bi irú eyi ti a tọka wa si nihin yii, jẹ eyi ti o le gbà ọkàn wa kan ti o si le mu ki a sọ ẹmi wa nù. Ifẹ owó ni i ṣe gbongbo ohun buburu gbogbo (1 Timoteu 6:10).

Ọkàn awọn Farisi kún fun ojukokoro, Oluwa si n tẹ otitọ yii mọ wọn leti. Wọn kẹgàn Jesu, wọn kò si fẹ gbà iṣẹ ti O jẹ fun wọn, ṣugbọn Jesu wi fun wọn pe, “Ẹnyin li awọn ti ndare fun ara nyin niwaju enia; ṣugbọn Ọlọrun mọ ọkàn nyin: nitori eyi ti a gbé niyin lọdọ enia, irira ni niwaju Ọlọrun.”

Jijẹ Oloootọ

Jesu fi hàn kedere pe bi a ba jẹ oloootọ ninu ohun kekere awa yoo jẹ oloootọ ninu ohun nlá; bi awa kò ba si le ṣe oloootọ ninu ohun kekere, a kò le ṣe oloootọ ninu ohun nlá. Ninu owe talẹnti, Jesu sọ fun ẹni ti o lo talẹnti rẹ ni ọnà ẹtọ pe: “O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ: iwọ ṣe olõtọ, ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pipọ: iwọ bọ sinu ayọ Oluwa rẹ” (Matteu 25:21). Boya a kò le ṣe ohun ti o tobi, ṣugbọn a le fi otitọ ṣe ohun kekere fun Jesu. O sọ pe ẹni ti o ba fi aago omi tútù fun ni ki yoo padanu èrè rẹ, bi o ba fi fun ni ni orukọ Jesu fun ogo ati ọlá Rẹ.

Ofin ati Awọn Wolii

Jesu wi pe Ofin ati awọn Wolii wà titi di akoko Johannu. Ofin ti ṣe iṣẹ rẹ, Jesu si wá lati mu un ṣẹ. Ofin jẹ apẹẹrẹ ati ojiji ohun rere ti n bọ. Johannu Baptisti ni o wá tun ọnà Kristi ṣe, o si kede igbà Ihinrere. Kristi wá, O n waasu ironupiwada. Ironupiwada ni irobinujẹ ẹni iwa-bi-Ọlọrun fun ẹṣẹ, o si jẹ ohun ti o ṣe pataki ju lọ fun wa lati wọ Ijọba Ọrun. Ibinujẹ ẹni iwa-bi-Ọlọrun fun ẹṣẹ yoo mu ki a kigbe lati ọkàn wa fun aanu, aanu yoo si mu idalare wá. Idalare ni o n fi ọkàn titun fun ẹlẹṣẹ, on ni o si n sọ ọ di ẹda titun ninu Kristi Jesu. Awọn ti o wà ni igbà ayé Ofin n ri igbala kan naa gbà gẹgẹ bi awa, nipa igbagbọ ninu Ẹjẹ Jesu ti yoo wa ta silẹ nigbà ikú Rẹ.

Ikọsilẹ

Jesu wi pe a fi àyè silẹ fun ikọsilẹ tọkọ-taya labẹ Ofin Mose nitori lile àyà wọn “ṣugbọn lati igba àtetekọṣe wá kò ri bẹẹ” (Matteu 19:8). Bi ẹni kan ba tun lọ ṣe igbeyawo miran nigbà ti alabagbe rẹ iṣaaju wà laayè sibẹ, oluwarẹ wa ni ipo panṣaga o si wà labẹ idalẹbi Ọlọrun, nitori pe o ṣe lodi si ẹkọ ọrọ Ọlọrun. (Wo iwe pẹlẹbẹ tí Ijọ Apostolic Faith tẹ jade lori Ikọsilẹ Tọkọ-taya Ati Igbeyawo Miiran).

Lẹyin Ikú

Ninu ẹkọ ọrọ Ọlọrun ti o kàn yii, Oluwa ká iboju ti o bò wa loju kuro, O si fun wa ni òye igbesi-ayé ti o wà lẹyin ikú. Opin ẹkọ yii ni ti ọlọrọ kan ni ọrun apaadi, ti o n joró ninu iná àjóòkú ati talaka kan ti o wà ninu itura ni ookan-àyà Abrahamu – eyi ti i ṣe ibi itura ti awọn olododo n lọ. Ọkunrin ọlọrọ yii, ni igbà ayé rẹ, a maa wọ aṣọ olowó iyebiye a si maa jẹ ounjẹ adidun ni ojoojumọ. A n gbe ọkunrin alagbe yii si ẹnu-ọnà ọlọrọ yii ki o le maa ri ẹrún akara ti o n jabọ lati ori tabili ọlọrọ yii jẹ. Jesu sọ fun wa pe Lasaru ni orukọ talaka yii. Fun idi ti a ko mọ, Jesu kò sọ orukọ ọlọrọ yii, ṣugbọn a mọ pe o wà fun ara rẹ nikan nigbà ti o wà láyé, kò si naani talaka alagbe ti o jokoo lẹnu ọnà rẹ. Oun kò tilẹ ṣe to awọn onigbagbọ alafẹnujẹ, ẹmi imọ-ti-ara-rẹ nikan ati ainaani ẹlomiran ni o ní.

Ọlọrọ ati Lasaru si kú. Laisi aniani wọn sin ọlọrọ pẹlu ẹyẹ ati ogo ayé yii, ṣugbọn isinkú Lasaru dara ju eyi lọ, bi o tilẹ ṣe pe oju ẹda kò ri i. Awọn angẹli gbe ẹmi Lasaru lọ si ookan àyà Abrahamu, nibi ti awọn eniyan mimọ ti o ti kọja lọ gbe n duro de owurọ Ọjọ Ajinde nlá nì.

Ọrọ Laaarin Abrahamu ati Ọlọrọ

Ọkunrin ọlọrọ yii bẹ Abrahamu ki o rán Lasaru lati tẹ ori-ika rẹ bọ omi ki o fi tọ ahọn oun ti o ti gbẹ, nitori o n joró ninu ọwọ iná. Nigbà ti ọlọrọ yii wà layé, èrò pe ki Lasaru olooju ati ẹni ẹgàn fi ọwọ kan oun laṣọ i ba jẹ irira si i, ki a má tilẹ sọ pe ki o fi ọwọ kan an ni ahọn. Ayipada dé! Abrahamu sọ fun un pe ọgbun nlá kan wà laaarin wọn, eyi ti kò si ẹni ti o le mu un kuro. Kò si ẹni ti o le rekọja lati ihà kan si ihà ekeji ọgbun naa.

Ọlọrọ naa si bẹ Abrahamu lati rán Lasaru pada si ayé lati kilọ fun awọn “arakunrin” rẹ marun un ki awọn naa má ba wá si ibi iṣẹ oró naa. Nigbà ti o ti pẹ ju ni o ṣẹṣẹ fẹ naani igbala awọn ara ile rẹ Lẹyin ti nnkan ba ti pẹju ni ọpọlọpọ eniyan ṣẹṣẹ n ji giri! Abrahamu sọ fun un pe wọn ni Mose ati awọn wolii, eyi ti i ṣe ọrọ Ọlọrun ti ki i tase, jẹ ki wọn gbọ ti wọn. Ṣugbọn ọlọrọ yii tẹnu mọ ọn pe bi ẹni kan ba jinde kuro ninu òkú wọn yoo gbagbọ. Abrahmu sa ti mọ èrò ọkàn awọn ti a kò tun bí ju bi ọlọrọ yii ti mọ lọ, o sọ fun un pe bi wọn kò ba gbọ ti Mose ati awọn wolii, wọn ki yoo gbagbọ bi ẹni kan tilẹ jinde kuro ninu òkú. Bi ọrọ wọnni ti jẹ otitọ to! Jesu ti jinde kuro ninu òkú - sibẹ ọpọlọpọ awọn eniyan kò gbagbọ. Ẹ wo irú ikilọ ti a ti ri ninu ẹkọ yii, nitori Jesu fun wa ni òye bi ọrun apaadi ti ri; O fi hàn wa pe gbogbo awọn ti o n lọ sibẹ ni a n dá loró, O si tun fi èrò wọn si ilana Ọlọrun hàn nigbà ti wọn tilẹ wà ninu iya ainipẹkun. O dabi ẹni pe ọkunrin yii ni itara pe ki awọn eniyan rẹ le bọ kuro ninu ijiya bi irú ti rẹ, ṣugbọn o n wa ọnà igbala miiran ti o yatọ si ilana Ọlọrun (Johannu 10:1-18).

Idaniloju Ọrun Apaadi

Ọrun apaadi jẹ ibi ti o dá ọlọrọ yii loju. Gbogbo òye ti o ni nigbà ti o wà láyé ni o pe ṣánṣán sibẹ. O mọ Abrahamu, o si mọ Lasaru. O le ri wọn. O le sọrọ, nitori a ri i pe o ba Abrahamu sọrọ. O le ranti, nitori a kà pe, o ranti awọn arakunrin rẹ marun un ni ile baba rẹ, awọn ẹni ti o n rin ọnà kan naa ti oun ti rin, eyi ti i ṣe ọnà gbooro ti o lọ si iparun. O mọ irora, nitori a n dá a loro ninu ọwọ iná. O lóye gbogbo nnkan. Abrahamu wi fun un pe ki o ranti pe oun ti ni ohun rere ni igbesi-ayé rẹ, Lasaru si ti gbà buburu ti rẹ. Nisisiyii a n da a loró, Lasaru si wà ninu itura. Kò si ọkàn ti o n sùn ni ọrun apaadi tabi Ọrun rere. Gbogbo awọn eniyan ti o wà ni ibi mejeeji ni wọn mọran ti wọn si ni òye wọn ni pipe perepere. A kò gbà Lasaru là nitori o jẹ talaka, ṣugbọn nitori ó gba Ọlọrun gbọ. Ọkunrin ọlọrọ naa kò ṣegbe nitori o ni ọrọ, bi o tilẹ jẹ pe Jesu wi pe: “Yio ti ṣoro to fun awọn ti o li ọrọ lati wọ ijọba Ọlọrun!” (Marku 10:23); ṣugbọn o ṣegbe nitori o kùnà lati gbagbọ ati lati tẹriba fun ọrọ Ọlọrun.

Ki i ṣe otitọ lati sọ pe a bi awọn kan ni ọmọ igbala a si bi awọn ẹlomiran lati ṣegbe, gẹgẹ bi ẹkọ ti awọn kan n kọ awọn eniyan. “Ẹnikẹni ti o ba si fẹ” le wá ki o “gbà omi ìyè na lọfẹ” (Ifihan 22:17). “Ẹ yàn ẹniti ẹnyin o ma sìn li oni” (Joṣua 24:15). “Ẹnyin kò le sin Ọlọrun pẹlu mammoni.” Ọrun apaadi wà ti a ni lati takete si, Ọrun rere si wà ti a ni lati jogun. Iṣipaya diẹ ti Jesu fi hàn fun ni lati mu wa mọ ohun ti ọrun apaadi ati oró rẹ jẹ ti to lati lé wa níré lọ sinu Ẹjẹ Jesu fun igbala ayérayé, ki a ma ba ni ipin ninu ibi ìṣẹ oró buburu nì, ki a si wà laayè titi lae pẹlu Oluwa. A ni lati fi ọwọ meji di eti wa ki a si sure lọ si ẹnu-ọnà kekere nì - eyi ti a le ri gẹgẹ bi ẹnu-ọnà si igbala – bi Kristiani ti inu iwe Ilọsiwaju Ero Mimọ ti ṣe nigbà ti o n ké pé “Ìyè! Ìyè!” Kukuru ni akoko lori ilẹ ayé, ṣugbọn ayérayé wà titi laelae.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ọgbọn ti iriju naa dá lati wá oju rere lọdọ awọn ajigbese oluwa rẹ?
  2. Ki ni ṣe ti oluwa rẹ fi yin in fun ohun ti o ṣe?
  3. Ki ni ṣe ti Jesu fi rò pe awọn ọmọ ayé yii gbọn ju awọn ọmọ imọlẹ lọ?
  4. Ki ni ṣe ti a kò fi le sin oluwa meji?
  5. Ki ni ya ọlọrọ ati Lasaru nipa lẹyin ikú wọn?
  6. Ọlọrọ ha le riran lẹyin ikú rẹ. Njẹ ó lè sọrọ?
  7. Ki ni ṣe ti ọlọrọ fi fẹ rán Lasaru pada wá si ayé?
  8. Ẹnikẹni ha ti i ji dide kuro ninu òkú ki o si maa ba awọn eniyan sọrọ ni ayé yii?
  9. Ki ni Bibeli pe ni gbongbo ohun buburu gbogbo?