Luku 18:1-8

Lesson 180 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ọlọrun ki yio ha si gbẹsan awọn ayanfẹ rẹ, ti n fi ọsán ati oru kigbe pè e, ti o si mu suru fun wọn?” (Luku 18:7).
Cross References

I Ipè lati Gbadura

1. Jesu pòwe nipa alaiṣododo onidajọ, ati awọn ọran ti o jọ bẹẹ lati fi ṣe apejuwe bi adura ti jẹ ohun pataki to, Luku 18:1-8; 11:5-13; Matteu 15:22-28

2. Gbigbadura si Ọlọrun lai sinmi a maa mu idahùn ẹbẹ wa wá, Luku 18:2-7; 1 Awọn Ọba 3:16-27; Daniẹli 10:2, 10-12

3. A ni lati gbadura lai ṣaarẹ bi o tilẹ jẹ pe a ri atako ṣiṣe bẹẹ, Luku 18:1; 21:36; Nehemiah 4:7-9; 1 Kronika 16:11; Matteu 26:41; Efesu 6:18; 1 Tẹssalonika 5:17

II Adura Igbagbọ

4. A ni lati ní igbagbọ pẹlu adura gbigba lai sinmi pe Ọlọrun le gbọ adura wa, ati pe yoo dahùn, Luku 18:13; Johannu 4:46-53; Matteu 8:2, 3, 5-10; 21:18-22; 1 Johannu 5:14, 15

5. Jesu beere pe, “Nigbati Ọmọ-enia ba de yio ha ri igbagbọ li aiye?” Luku 18:8; Matteu 24:9-13, 24; 1 Tẹssalonika 5:1-8; Heberu 10:23-25; Jakọbu 5:7-11.

Notes

Gbadura Lai Ṣaarẹ

“O yẹ ki a mã gbadura nigbagbogbo, ki a má si ṣãrẹ”; eyi yii ni imọran Jesu. Lati inu imọran yii a mọ pe ohun ti o tọ, ti kò si gbọdọ falẹ ni ki a maa gbadura pupọ; nigbà ti a ba si n gbadura a kò gbọdọ ṣaarẹ.

Otitọ ti o wà nibẹ ni pe adura agbayọri jẹ iṣẹ kan ti o le ju lọ. O jẹ iṣẹ ti ẹran-ara kò fẹ fi ara mọ, ati eyi ti o yẹ lati tọ ẹmi ati ọkàn si, pẹlu isẹra-ẹni ati aapọn lati ṣe. Kò si iṣẹ miiran ti o lere ti o pọ bi i rẹ. Ọkàn ti o n gbadura igbagbọ n mu lati Orisun Omi Iye, eyi ti i ṣe Jesu Kristi; yoo si ri iye ainipẹkun gbà fun aapọn rẹ.

Nitori ki eniyan le ni iṣiri lati gbadura agbayọri, ati lati tẹra mọ adura titi wọn yoo fi ri idahùn si ibeere wọn gbà lati ọdọ Ọlọrun ni Jesu ṣe pa òwé alaiṣootọ onidajọ yii. Opó kan wà ti wọn ti ṣe ni ibi. O si n fẹ ẹsan, ṣugbọn bi o ti maa n ṣẹlẹ nigbà gbogbo, nitori o jẹ opó kò le jà fun ohun ti i ṣe ẹtọ rẹ. Nitori eyi, o n bẹ onidajọ ti o ni aṣẹ lori ọran yii lati lo àyè rẹ lati dá ẹjọ naa.

Onidajọ yii jẹ alaiṣootọ kò si bẹru Ọlọrun, bẹẹ ni kò ṣe ojusaaju eniyan. Oun kò si naani lati mu ibura ipò iṣẹ rẹ ṣẹ. Ọpọlọpọ igbà ni awọn ti wọn wà ni ipo giga ni ilu n lo aṣẹ ti a fi le wọn lọwọ lati gba èrè aiṣododo fun ara wọn; wọn kò si bikita bi awọn eniyan kan tilẹ n jiya nitori iwa anikanjọpọn wọn yii. Bakan naa ni o ri pẹlu ọkunrin yii; oun kò bẹru ibinu Ọlọrun tabi igbẹsan ẹdá, eyi si mu ki eti rẹ di si ẹbẹkẹbẹ fun iranlọwọ ti o wu ki a mu wa si ọdọ rẹ. ọdọ ọkunrin yii ni opó yii mu ẹbẹ rẹ lọ, ki o le gbẹsan rẹ lara ọtá rẹ.

Èrè Ifarada

Alaiṣootọ onidajọ yii kọ lati feti si ẹbẹ opó yii. Nitori kò si ọnà miiran ti o tun le gbà mọ, opó yii tẹra mọ ẹbẹ rẹ fun igbẹsan. Bi o tilẹ jẹ pe aini obinrin yii kò mu ki ọkunrin naa bikita, ti ojuṣe rẹ gẹgẹ bi àyè ti o wà kò si jọ ọ loju, ti kò si naani ohun ti eniyan le sọ si oun, ti ẹrù Ọlọrun kò ba a, o woye pe obinrin yii n dá oun lagara igbakuugba. Lai si idi miiran ju pe ọkunrin yii kò fẹ iyọlẹnu mọ, o dá obinrin naa lohun; o si mu ibeere rẹ ṣẹ. “Ọlọrun ki yio ha si gbẹsan awọn ayanfẹ rẹ, ti nfi ọsán ati oru kigbe pè e, ti o si mu suru fun wọn? Mo wi fun nyin, yio gbẹsan wọn kánkán” (Luku 18:7, 8). Bẹẹ ni ileri Jesu pe, kò si adura agbayọri ti a le gbà si Ọlọrun ti ki yoo jẹ itẹwọgba.

Nitori o tẹra mọ ọn lati maa wa si ọdọ alaiṣootọ onidajọ yii ni opó naa ṣe ri idahùn si ẹbẹ rẹ. Bi o ba jẹ pe awiyannu lasan ni opó yii fi ri oju rere onidajọ, n jẹ a ki yoo ri idahùn ti o dara ju eyi gbà nigbà ti a ba gbadura si Ọlọrun olododo!

Adura Agbayọri

Ọtá wa ẹmi ni a n ba jà, wọn si n sa gbogbo agbara wọn lati dè wa lọnà, lati sé ọnà ati lati mu sisu ba wa; ati pẹlu lati pa awọn ti n wá Ọlọrun nipa adura run. Bibeli kún fun ẹrí pe agbara Satani ati ibi ni o doti gbogbo awọn ti o n gbadura igbagbọ si Ọlọrun. “Nitoripe ki iṣe ẹjẹ ati ẹran-ara li awa mba jijakadi, ṣugbọn awọn ijoye, awọn ọlọla, awọn alaṣẹ ibi òkunkun aiye yi, ati awọn ẹmi buburu ni oju ọrun … Pẹlu gbogbo adura ati ẹbẹ ni ki ẹ mã gbadura nigbagbogbo ninu Ẹmi, ki ẹ si mã ṣọra si i ninu iduro-ṣinṣin gbogbo, ati ẹbẹ fun gbogbo enia mimọ” (Efesu 6:12, 18). “Gbogbo aiye li o wa ni agbara ẹni buburu nì” (1 Johannu 5:19). Nitori idi eyi ati nitori awọn ipa ẹni ibi ni Jesu fi n tẹnu mọ ọn pe a ni lati gbadura pẹlu irora ati imi-ẹdun titi a o fi ri idahùn si ibeere wa gbà.

Ki i ṣe pe ki a gbadura nikan ṣugbọn ki a ni ifarada nitori eṣu yoo mu sisu wa a o si fẹ sá lọ bi a kò ba ni ipinnu lati duro ṣinṣin ninu Ọlọrun. O ti jẹ iriri awọn eniyan mimọ Ọlọrun nigbà miran lati fi irora gbadura ati lati taku ti Ọlọrun titi èsì yoo fi de.

Daniẹli wá oju Ọlọrun nitori awọn eniyan rẹ, gẹgẹ bi ilana Ọlọrun, ṣugbọn Satani dena adura rẹ fun odidi ọsẹ mẹta titi Ọlọrun fi dahùn adura rẹ (Daniẹli 10:1-13).

Jakọbu fi gbogbo oru gbadura titi o fi di afẹmọjumọ, itan rẹ si yẹ lori ike nitori ọpọ adura rẹ. Sibẹ Jakọbu tẹra mọ ọn o si ba Ọlọrun jijakadi titi o fi ri idahùn si adura rẹ (Gẹnẹsisi 32:24-26).

Bartimeu afọju, ti o n ṣagbe, kigbe ni ohun rara si Jesu bi O ti n kọja lọ. Gbogbo awọn ero ti o yi Jesu ká si n dá a lẹkun ki o pa ẹnu rẹ mọ; ṣugbọn o kigbe ju bẹẹ lọ titi Jesu fi dẹsẹ duro ti o si fun un ni ibeere rẹ, ki o le riran (Marku 10:46-52).

Lẹyin ajinde Kristi, meji ninu awọn ọmọ-ẹyin Rẹ pade Rẹ ni ọnà Emmausi. Wọn kò mọ Ọn, wọn si bẹrẹ si sọ ohun ti o ṣẹlẹ si Kristi ni ọjọ diẹ sẹyin fun un. Ninu ọrọ wọn Jesu fa igbagbọ ti wọn ni ninu Rẹ jade. Nigbà ti O si fẹ fi wọn silẹ wọn rọ Ọ lati duro ki O le ba wọn gbé, O si gbà bẹẹ. Titẹnu mọ ọn pe ki Jesu ki o duro ti wọn ni o mu ki Jesu duro lọdọ wọn ki O si ba wọn jẹun.

Lati inu apẹẹrẹ wọnyii a ni lati kẹkọọ pe a ni lati gbadura pẹlu ipinnu ati iforiti to bẹẹ ti iṣoro tabi ohun kan ki yoo le fa wa sẹyin ki a má ri ohun ti a n fẹ gbà.

Ijẹri Igbagbọ

Lẹyin ti Jesu ti pa owe alaiṣootọ onidajọ lati gba awọn eniyan niyanju lati gbadura, O beere ibeere yii: “Nigbati Ọmọ-enia ba de yio ha ri igbagbọ li aiye”

A mọ ohun ti Bibeli pe ni igbagbọ: “Igbagbọ ni idaniloju ohun ti a nreti, ijẹri ohun ti a kò ri” (Heberu 11:1). Igbagbọ ki i ṣe ohun ofifo lasan ti a kò le di mu, bi kò ṣe otitọ ati ẹrí Ọlọrun ti a le di mu. “Ṣugbọn li aisi igbagbọ ko ṣe iṣe lati wù u; nitori ẹniti o ba ntọ Ọlọrun wá kò le ṣai gbagbọ pe o mbẹ, ati pe on ni olusẹsan fun awọn ti o fi ara balẹ wá a (Heberu 11:6). Ohun ti Jesu yoo wò ni ọkàn olukuluku eniyan nigbà ti o ba pada si ayé lẹẹkeji ni eyi. Igbagbọ ninu Ọlọrun! Njẹ Oun yoo ri i? Awa mọ lati inu Bibeli pe Oun ki yoo ri igbagbọ pupọ.

“Bi o si ti ri li ọjọ Noa, bẹẹni yio ri li ọjọ Ọmọ-enia. Nwọn njẹ, nwọn nmu, nwọn ngbeyawo, nwọn si nfà iyawo fun ni, titi o fi di ọjọ ti Noa wọ inu ọkọ lọ, kíkun omi si de, o si run gbogbo wọn. Gẹgẹ bi o si ti ri li ọjọ Lọti; nwọn njẹ, nwọn nmu, nwọn nrà, wọn ntà, nwọn ngbìn, nwọn nkọle; Ṣugbọn li ọjọ na ti Lọti kuro ni Sodomu, ojo ina ati sulfuru rọ lati ọrun wá, o si run gbogbo wọn. Gẹgẹ bẹẹni yio ri li ọjọ na ti Ọmọ-enia yio farahàn” (Luku 17:26-30).

Bẹẹ ni ipò ọpọlọpọ awọn eniyan yoo ri ninu ayé nigbà ti Jesu ba pada wa. Wọn ki yoo ni igbagbọ ninu Ọlọrun, wọn ki yoo si naani ẹkọ ati ilana Bibeli. Wọn o maa gbé igbesi ayé ifọju ati imọ-ti-ara-ẹni-nikan, wọn o maa gbé ninu ẹṣẹ. Ọpọlọpọ ohun ti ayé n sọ ati ọnà ti awọn eniyan n gbà yoo jẹ ohun ìdíwọ fun awọn ẹni ti yoo ba gbé igbesi ayé ẹni iwa-bi-Ọlọrun ninu Kristi Jesu. Ni ọjọ wọnni awọn ẹni ti o pinnu lati pa igbagbọ wọn mọ ninu Ọlọrun nikan ni yoo le gbadura agbayọri.

Awọn ọkàn ti kò ni idaniloju pe Ọlọrun wà ati pe yoo gbọ adura, o pẹ tabi o ya, ki yoo le kọju ìjà si ẹṣẹ ni ọjọ wọnni. Njẹ awa ni igbagbọ? Nitori naa a ni lati gbadura si Ọlọrun ni ojoojumọ. Ẹni ti o ni igbagbọ n gbadura, nitori o gbagbọ pe Ọlọrun yoo dahùn adura rẹ. Adura awiyannu ati igbagbọ ni o n rin lọwọkọwọ, nitori naa a kò le ni ọkan lai si ekeji.

“O yẹ ki a mã gbadura nigbagbogbo, ki a má si ṣãrẹ” eyi ni ikilọ ti Jesu ṣe fun gbogbo eniyan; o si ṣe pataki ni akoko yii ti o ṣiwaju bibọ Rẹ si ayé lẹẹkeji. Ọlọrun lagbara O si n fẹ lati pa awọn eniyan Rẹ mọ ni pipe ati mimọ bi wọn ba le gbadura igbagbọ lai ka ohun aibarade ati idena ti o le dí wọn lọwọ lati gbé igbesi-ayé Onigbagbọ si.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti alaiṣootọ onidajọ fi dahùn ẹbẹ opó naa?
  2. Ta ni Onidajọ Ododo?
  3. Ta ni n dena adura awọn eniyan Ọlọrun?
  4. Ki ni ṣe ti a ni lati ni iforiti ninu adura gbigba?
  5. Nitori ki ni awọn eniyan yoo fi jẹ alaigbagbọ ni igbà ikẹyin?
  6. Awọn ohun meji wo ni n rin lọwọkọwọ?
  7. Ki ni igbagbọ?