Lesson 181 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Iran kan wà, ti o mọ li oju ara rẹ, ṣugbọn a kò ti iwẹ ẹ nù kuro ninu ẽri rẹ” (Owe 30:12).Cross References
I Adura Onirobinujẹ Ọkàn
1. Agbowo-ode gbadura wi pe, “Ọlọrun ṣãnu fun mi, emi ẹlẹṣẹ”, Luku 18:13; Hosea 14:2
2. Adura ẹlẹṣẹ ti o ronupiwada maa n ṣe itẹwọgba lọdọ Ọlọrun, Owe 28:13; 1 Johannu 1:9; Orin Dafidi 34:18; Isaiah 66:2; 2 Kọrinti 7:10; Esekiẹli 18:21
3. Aanu ati idariji Ọlọrun wà fun gbogbo awọn ti o gbadura pẹlu ibanujẹ ẹni iwa-bi-Ọlọrun ati ironupiwada fun ẹṣẹ, Mika 7:18, 19; Efesu 2:1-7; Ẹksodu 34:6, 7; Orin Dafidi 103:8
4. Awọn ti o ronupiwada ni a ṣeleri idariji pipe fún, Isaiah 44:22; 55:7; Jeremiah 3:22; Hosea 14:4; Luku 15:21-24
II Adura Idara-Ẹni-Lare
1. Farisi wá lati gbé ododo ara rẹ kalẹ, ki i si ṣe ododo ti Ọlọrun, Luku 18:10-12; Isaiah 58:2; 65:5; Romu 10:2-13
2. Farisi naa yin iṣẹ ara rẹ pe o sàn ju iṣẹ ti agbowo-ode (ẹlẹṣẹ) ẹni ti n gbadura fun aanu, Luku 18:13; Efesu 2:8, 9; 2 Timoteu 1:9; Titu 3:5; Romu 3:24-28; 1 Kọrinti 1:29
III Igbega ati Irẹsilẹ
1. Agbowo-ode naa lọ silẹ pẹlu idalare lati ọdọ Ọlọrun nitori o gbadura pẹlu ironupiwada ati igbagbọ, ó n beere fun aanu, Luku 18:14; Romu 4:5
2. Farisi naa kò ri i pe o jẹ ọranyan lati ronupiwada ati lati gba igbala, oore-ọfẹ Ọlọrun, nitori naa ni Ọlọrun kò ṣe da a lare, Luku 18:14; Romu 4:2-4; 1 Johannu 5:10
Notes
Oriṣi Adura Meji
A kọ lati inu owe Farisi ati agbowo-ode pe ki i ṣe gbogbo awọn ti wọn n gbadura si Ọlọrun ni o jẹ itẹwọgbà lọdọ Rẹ. Jesu ṣe apejuwe awọn eniyan meji ti iwa wọn yatọ si ara wọn patapata. Ekinni jẹ Farisi, ekeji si jẹ agbowo-ode. Ipo wọn laaarin ilu yatọ pupọ. Ero awọn eniyan ni pe awọn Farisi jẹ eniyan rere, wọn si ṣe pataki ninu isin Tẹmpili. Awọn pẹlu n ro ara wọn si olukọ ati olutumọ Ofin. Ọpọlọpọ wọn ni wọn kẹkọọ giga; ilana isin wọn jẹ eyi ti o le ju lọ ni orilẹ-ède Israẹli.
Awọn agbowo-ode ni wọn n gbà owó-orí fun ijọba Romu eyi si mu ki gbogbo eniyan korira wọn. Ohun ti o fa ikorira yii ni pe awọn agbowo-ode wọnyii n gba apá kan ninu owó ti wọn ba kó jọ. Wọn ba ijọba Romu ṣe adehùn lati gba iye owó kan lọwọ awọn eniyan. Anfaani owó-orí gbigbà yii ni awọn agbowó-ode n lo ni ilokulo, nitori awọn alaṣẹ ijọba Romu ki í saba beere ọnà ti awọn agbowo-ode n gbà fi kó owó naa jọ. Bi ijọba Romu ba sa ti gba iye owó ti wọn fẹ lẹkun rẹrẹ, wọn kò bikita bi awọn agbowó-ode ba tilẹ gba owó lé ju eyi ti wọn fun wọn laṣẹ lati gbà - igbà pupọ ni o si maa n ṣẹlẹ bẹẹ.
Awọn eniyan meji ti ipò wọn laaarin awọn eniyan yatọ si ara wọn pupọ pupọ ni Jesu fi ṣe apẹẹrẹ oriṣi ọnà meji ti eniyan fi n gbadura. Awọn ẹni meji wọnyii lọ si Tẹmpili lati gbadura. Bi wọn ṣe gbadura ati ihà ti olukuluku wọn kọ si Ọlọrun yàtọ gẹgẹ bi igbesi-ayé wọn pẹlu ti yàtọ si ara wọn. Èsì adura wọn si yàtọ bẹẹ gẹgẹ, nitori ẹni kan lọ sile pẹlu idalare, ekeji si lọ pẹlu ẹbi. Ihà ti wọn kọ si Ọlọrun ni o fa ìyàtọ yii.
Olododo ni Ọlọrun Wa
Ọlọrun ki i ṣe ojusaaju eniyan, ki yoo dahùn adura ẹni kan ki o má dahùn ti ẹni keji. “O ha tọ lati wi fun ọba pe, Enia buburu ni iwọ, tabi fun awọn ọmọ alade pe, Alaimọ-lọrun li ẹnyin? Ambọtori fun ẹniti ki iṣojusaju awọn ọmọ-alade, tabi ti kò kà ọlọrọ si ju takala lọ, nitoripe iṣẹ ọwọ rẹ ni gbogbo wọn iṣe” (Jobu 34:18, 19). “Nitori kò si ìyatọ ninu Ju ati Hellene: nitori Oluwa kanna l’Oluwa gbogbo wọn, o si pọ li ọrọ fun gbogbo awọn ti nkepè e” (Romu 10:12). (Ka Iṣe Awọn Apọsteli 10:34, 35; Jakọbu 2:1-9).
Nitori naa bi awọn ara ilu agbowo-ode yii kò tilẹ fẹran rẹ, ṣugbọn a kò kọ fun un lati mu ẹbẹ rẹ tọ Ọlọrun lọ nitori iwa buburu rẹ. Bẹẹ ni Ọlọrun kò yara tẹwọgba Farisi yii nitori a ka a si ẹlẹsin ti o ga.
Gbigbe Ara Ga
Farisi naa si gbadura bayii “Ọlọrun, mo dupẹ lọwọ rẹ, nitoriti emi kò ri bi awọn ara iyokù, awọn alọnilọwọgba, alaiṣõtọ, panṣaga, tabi emi kò tilẹ ri bi agbowode yi. Emi ngbàwẹ li ẹrinmeji li ọsẹ, mo nsan idamẹwa ohun gbogbo ti mo ni.” Farisi naa rò ninu ara rẹ pe oun pa ara oun mọ kuro ninu awọn ẹṣẹ ayé ti o buru jù, o si yin ara rẹ pe oun kò ri bi agbowo-ode ti o wà ni itosi rẹ, ti o n gbadura. Farisi naa rò pe nipa kika awọn nnkan wọnyii, Ọlọrun yoo boju wo oun gẹgẹ bi olusin Ọlọrun tootọ.
Farisi naa n fi iwa awọn ẹlomiran diwọn ara rẹ. Paulu sọ nipa eyi: “Nitoripe awa kò daṣa ati kà ara wa mọ, tabi ati fi ara wa wé awọn miran ninu wọn ti nyin ara wọn; ṣugbọn awọn tikarawọn jẹ alailoye nigbati nwọn nfi ara wọn diwọn ara wọn, ti nwọn si nfi ara wọn wé ara wọn” (2 Kọrinti 10:12). Odiwọn tootọ ti a le fi wọn ara wa ni ọrọ Ọlọrun. Jesu Kristi ni Ẹni Pipe, ti O doju ami niwaju Ọlọrun (Efesu 4:13). Oun ni apẹẹrẹ wa, kò si si ẹlomiran.
Bi o tilẹ jẹ pe Farisi naa kò jẹbi awọn ẹṣẹ ti o kà silẹ, ṣugbọn o jẹbi awọn miiran ti o buru bi awọn wọnni, tabi ti o buru ju wọn lọ. Pupọ ninu awọn Farisi ni wọn jẹbi iwa agabagebe ti wọn n yi idajọ po. (Ka Matteu 23:23). Farisi yii jẹbi ẹṣẹ kan naa pẹlu awọn Ọmọ Israẹli iyoku nipa eyi ti Paulu wi pe: “Nitori mo gbà ẹri wọn jẹ pe, nwọn ni itara fun Ọlọrun, ṣugbọn ki ṣe gẹgẹ bi imọ. Nitori bi nwọn kò ti mọ ododo Ọlọrun, ti nwọn si nwá ọna lati gbé ododo ara wọn kalẹ, nwọn kò tẹriba fun ododo Ọlọrun” (Romu 10:2, 3).
Pẹlupẹlu, Farisi yii gẹgẹ bi ẹni ti o pe ara rẹ ni olùkọ Ofin ati olutumọ otitọ ẹmi ti o wà ninu rẹ, ti yẹ kuro ninu ohun pataki ti iṣẹ alufaa ati irubọ Agọ jẹ. Idi rẹ ti a fi n rubọ wọnyii ni lati fihàn pe a kò le ṣai ni Ẹbọ pipe kan fun ẹṣẹ arayé, ati ipese Ọlọrun ti a o ṣe ki Ọlọrun lè gbà wọn, ki a si dá wọn lare niwaju Rẹ.
Gbogbo igbekalẹ Ofin Mose ni lati fihàn pe nipa iṣẹ Ofin kò si ẹni ti a o dalare (Galatia 2:16). Ati pẹlu “Ofin ti jẹ olukọni lati mu ni wá sọdọ Kristi, ki a le da wa lare nipa igbagbọ” (Galatia 3:24).
Bi Farisi yii ti n gbadura ninu ara rẹ, ti o n rò ninu ara rẹ pe a o dá oun lare niwaju Ọlọrun nitori iṣẹ rere oun, Ọlọrun kọ ọ nitori o n dá ara rẹ lare.
Adura fun Aanu
Wo bi adura agbowo-ode ati ọnà ti o gbà tọ Ọlọrun lọ ti yàtọ to. “Ọlọrun ṣãnu fun mi; emi ẹlẹṣẹ.” Kò funnu nipa iṣẹ rere rẹ. O tẹ orí ara rẹ ba, kò tilẹ jẹ gbé oju rẹ soke ọrun. O lu ara rẹ ni ookan-àyà pẹlu irora ati irobinujẹ ọkàn ti o mu ki o lọ si ile Ọlọrun nibi ti yoo gbé ri itura fun ọkàn rẹ. Tẹmpili ki i ṣe ibi ti a gbe maa n ri awọn agbowo-ode to bẹẹ, sibẹ ile Ọlọrun jẹ ibi ti o yẹ fun agbowo-ode lati wá alaafia fun ọkàn rẹ.
Ọlọrun kò fara mọ ẹṣẹ lọnalọna. Ẹṣẹ ni ẹṣẹ n jẹ, bi aṣiṣe kan ti yẹ fun idalẹbi, bẹẹ ni gbogbo aṣiṣe yẹ fun idalẹbi pẹlu. Farisi yii kò sàn ju agbowo-ode lọ, oun tikara rẹ jẹ ẹlẹbi bakan naa. Agbowo-ode yii ṣí ọkàn rẹ paya si Ọlọrun; Ọlọrun si ti fi òye ẹṣẹ rẹ ye e, o si n gbadura ti o dara ju lọ ti ẹlẹṣẹ ni lati gbà, “Ọlọrun ṣãnu fun mi, emi ẹlẹṣẹ.”
Agbowo-ode naa lọ si ile rẹ pẹlu idalare lati ọdọ Ọlọrun nitori o jẹwọ ẹṣẹ rẹ. O ké pe Ọlọrun fun aanu, a si ṣaanu fun un. “Ẹniti o bo ẹṣẹ rẹ mọlẹ ki yio ṣe rere: ṣugbọn ẹnikẹni ti o jẹwọ ti o si kọ ọ silẹ yio ri ãnu” (Owe 28:13). Nitori Farisi naa kò fẹ jẹwọ ẹṣẹ rẹ tabi ki o kà wọn lẹsẹẹsẹ, oun kò tilẹ fẹ gbà pe ẹlẹṣẹ ni oun i ṣe, o lọ sile rẹ lai ri aanu tabi idariji gbà, ki i ṣe pe o kuna lati jẹwọ wọn nikan, ṣugbọn kò fẹ kọ wọn silẹ. Bi o ti wu ki agbowo-ode yii ti buru to lati ẹyin wá, o gbadura pẹlu ọkàn ti o jẹwọ, o kaanu fun ẹṣẹ rẹ o si n fẹ kọ wọn silẹ ki o si maa tẹle ilana Ọlọrun.
“Nitori ẹnikẹni ti o ba gbé ara rẹ ga, on li a o rẹ silẹ; ẹniti o ba si rẹ ara rẹ silẹ on li a o gbéga” (Luku 18:14). Afi awọn ẹni ti o ba le tọ Ọlọrun lọ pẹlu ọkàn pe wọn kò lẹtọọ si oju rere kan lati ọdọ Ọlọrun, ti wọn si mọ pe alaiṣododo ni wọn, ni yoo ri idariji gbà. Ọlọrun ba Jobu sọrọ lori ọràn òdodo bayii pe: “Iwọ ha fẹ imu idajọ mi di asan? iwọ o si da mi lẹbi, ki iwọ ki o le iṣe olododo?” (Jobu 40:8). Farisi naa fẹ fi ara rẹ hàn bi olododo, bi o tilẹ jẹ pe ẹsìn rẹ kò kọ ọ bẹẹ, nitori naa kò ni òdodo rara. Agbowo-ode naa mọ pe oun kò ni òdodo, nitori naa o wá òdodo kan ṣoṣo ti o wà, eyi ti i ṣe òdodo Ọlọrun!
Questions
AWỌN IBEERE- Sọ bi igbesi-ayé Farisi ati agbowo-ode ti ri.
- Ki ni iṣẹ agbowo-ode?
- Ki ni ṣe ti gbogbo eniyan fi korira awọn agbowo-ode?
- Irú àyè wo ni awọn Farisi kó laaarin awọn eniyan?
- Lọnà wo ni adura agbowo-ode fi yàtọ si ti Farisi?
- Ta ni Ọlọrun dá lare?
- Ki ni idalare?