Marku 10:17-31

Lesson 182 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹ máṣe fẹran aiye tabi ohun ti mbẹ ninu aiye. Bi ẹnikẹni ba fẹran aiye, ifẹ ti Baba kò si ninu rẹ” (1 Johannu 2:15).
Cross References

I Ibeere Pataki

1. ọdọmọkunrin ijoye ọlọrọ sare lọ ba Jesu lati wadii nipa ìyè ainipẹkun, Marku 10:17, 18; Matteu 19:16; Luku 18:18; Johannu 6:28, 29; Iṣe Awọn Apọsteli 16:30, 31

2. Jesu dá ìjòyè naa lohùn nipa titọka rẹ si Awọn Ofin Mẹwaa, Marku 10:19; Deuteronomi 32:46, 47; Owe 19:23; Esekiẹli 20:11

3. ọdọmọkunrin ìjòyè naa wò pe oun ti pa Awọn Ofin wọnyii mọ lati igbà èwe oun wá, Marku 10:20; Isaiah 58:1, 2; Esekiẹli 33:31, 32

II Ohun ti Ìyè Ainipẹkun Yoo Gbà

1. Jesu fẹran ọdọmọkunrin yii, O si fi ọnà si Ọrun Rere hàn an, Marku 10:21; Owe 23:23; Iṣe Awọn Apọsteli 2:45; 4:34-37; Jakọbu 2:10; 1 Johannu 4:10

2. Ọdọmọkunrin naa lọ pẹlu ibanujẹ nigbà ti o gbọ ohun ti ìyè ainipẹkun yoo gbà a, Marku 10:22; Orin Dafidi 62:10; Owe 11:4, 28; 23:5; 2 Kọrinti 7:10

III Ewu Níní Ọrọ Pupọ

1. Jesu wi pe o ṣoro fun ọlọrọ lati wọ ijọba Ọrun, Marku 10:23-25; Orin Dafidi 49:6-8; Owe 18:11; Jeremiah 9:23; Sefaniah 1:18; 1 Timoteu 6:17

2. Ẹnu ya awọn ọmọ-ẹyin si awọn ọrọ Jesu, Marku 10:26; Isaiah 59:1, 2; Jeremiah 13:23

3. Awọn ohun ti o ṣoro fun eniyan rọrun fun Ọlọrun, Marku 10:27; Numeri 11:23; 2 Awọn Ọba 7:2, 18; Jobu 42:2; Heberu 7:25

4. Awọn ọmọ-ẹyin ti o fi ohun gbogbo silẹ nitori Jesu ni ileri ọpọlọpọ èrè, Marku 10:28-31; Deuteronomi 33:9-11; Orin Dafidi 84:11; Owe 3:9, 10; 16:16; Malaki 3:10; 1 Timoteu 6:6; 1 Johannu 3:1

Notes

Onibeere Oloootọ

Ọdọmọkunrin ti a sọrọ nipa rẹ ninu ẹkọ yii jẹ ẹni ti o n fi tọkantọkan wá ọnà ti o lọ si ibi ìyè ainipẹkun. O sare tọ Oluwa wá, ki i ṣe pẹlu àgálámàṣà, ṣugbọn pẹlu otitọ ọkàn. Kò kuna lati fi ọlá fun Jesu nitori o wolẹ lẹsẹ Rẹ: bẹẹ ni kò ṣe alaimọ ọrọ Ọlọrun nitori ti o wi pe lati igbà èwe oun wá ni oun ti n pa gbogbo ofin Ọlọrun ti Jesu kà silẹ mọ. O ṣe e ṣe ki o maa fi ara pa ofin wọnyii mọ, ṣugbọn o hàn pe kò pa wọn mọ ninu ẹmi. Bi o ba jẹ pe o ṣe bẹẹ Jesu kò ni tun sọ ọrọ yii pe “Ohun kan li o kù ọ kù.”

Jesu, Ẹni ti o mọ ọkàn gbogbo eniyan ti ri arun buburu kan ni ọkàn ọdọmọkunrin yii, O si mọ pe ohun ti o lagbara ni o le wo o sàn. Ẹṣẹ jẹ arun ti o buru ju, i baa ṣe ẹyọ ẹṣẹ kan ṣoṣo ni o wà ninu ọkàn, a ni lati fi Ẹjẹ Jesu wẹ ẹṣẹ naa nù. Gẹgẹ bi ọrọ Ọlọrun, “ohun kan” ti o kù ẹnikẹni kù le mu ki ọkàn naa padanu Ijọba Ọrun. Eyi fihàn bi awọn ti o n pe orukọ Kristi, ti o si ni ireti lati wọ Ọrun ni ikẹyin ayé ti ni lati ṣọra pọ to.

Ọrọ ati Ìgbà ọdọ

Ibeere ti ọdọmọkunrin yii beere pe, “Kili emi o ṣe ti emi o fi le jogún iye ainipẹkun?” fi irú itara ti o wà lọkàn rẹ hàn. ọrọ Ọlọrun wi pe o ni ọrọ pupọ; nigbà pupọ ni awọn ọlọrọ n ro pe ohun ti o rẹlẹ ju fun wọn ni lati fiye si ohun ti i ṣe ti ayé ti n bọ. Aniyan nipa ohun ti n ṣegbe ti gbà wọn lọkàn to bẹẹ ti wọn kò ri àyè lati ronu ibi ti ọkàn wọn yoo fi ṣe ibugbe lẹyin ayé yii. Ti ọkunrin ọlọrọ yii yàtọ si eyi. Lai si aniani ọpọlọpọ igbà ni o ti n ronu ohun ti yoo ṣẹlẹ lẹyin ikú. O gba ìyè ainipẹkun gbọ, ṣugbọn akọwe iranti nì ti i ṣe ẹrì-ọkàn rẹ, n sọ fun un lemọlemọ pe o ni ohun kan lati ṣe ti o yàtọ si eyi ti o n ṣe bi o ba fẹ ni ìyè ainipẹkun. Oye otitọ yii ye e pe ohun danindanin ni lati mura fun ìyè ainipẹkun nihin ati nisisiyii ki o má ṣe duro de ẹyin ikú ki o to maa dá èrò yii rò, nitori yoo ti pẹ ju. Ni irú ipò òdodo tabi ẹṣẹ ti eniyan ba wà nigbà ti o fi ayé silẹ, irú ipò bẹẹ gan an ni yoo jí si ni ebute ayérayé. “Nibiti igi na gbe ṣubu si, nibẹ ni yio si ma gbe” (Oniwasu 11:3).

Ohun ti o tun wu ni lori nipa onibeere yii ni pe, o wá ni igbà ọdọ rẹ. Ọpọlọpọ awọn ọdọ ni o ti lọ si ayérayé lai mura silẹ lati pade Ọlọrun nitori wọn gbagbọ pé akoko wà niwaju lati wá Ọlọrun. Satani kò fẹ nnkan miiran ju pe ki awọn ọdọmọde ki o fi akoko wíwá Ọlọrun falẹ. Ọdún pupọ ti eniyan fi dẹṣẹ a mu ki àbámọ ti kò ṣe e gbagbe wọ inu ọkàn bi o tilẹ jẹ pe a ti jẹwọ awọn ẹṣẹ naa ti Ẹjẹ Ọdọ-agutan ti a pa si ti mu ẹbi rẹ kuro. Yoo ti dùn to lati wá sọdọ Kristi ni igbà ọdọ, ki a si duro ti I ni gbogbo igbesi-ayé wa, lai ka iṣoro si! Ọkunrin yii jẹ ọlọrọ, o si jẹ ọdọ ṣugbọn ẹri rẹ ni pe eyi kò fun un ni itẹlọrun. Bi itẹlọrun ba ti wà fun un, oun kò ni sá tọ Oluwa wá lati beere ọnà si ìyè ainipẹkun.

Pataki ọrọ Naa

Ni ìdáhùn si ibeere ti ọdọmọkunrin naa beere, Jesu tọka rẹ si ọrọ Ọlọrun: “Iwọ sá mọ ofin.” Itumọ rẹ ni pe bi ẹni kan ba pa gbogbo eyi ti o mọ nipa ọrọ Ọlọrun mọ tọkantọkan ti o si n rin ninu gbogbo imọlẹ ti o tan si ọnà rẹ, yoo ni ìyè ainnipẹkun. Njẹ eniyan le ṣe eyi ninu agbara rẹ? Eyi gbà pe ki a ni àyà titun, ati ìrírí atunbi lati le ba Ọlọrun rìn ki a si maa ba A gbé. “Bi awa ba nrin ninu imọlẹ, bi on ti mbẹ ninu imọlẹ, awa ní ìdapọ pẹlu ara wa, ẹjẹ Jesu Kristi Ọmọ rẹ ni nwẹ wa nù kuro ninu ẹṣẹ gbogbo” (1 Johannu 1:7).

Àìní Ọkunrin Ọlọrọ

Jesu fẹran ọdọmọkunrin ìjòyè yii – O fẹran rẹ to bẹẹ ti O fi sọ otitọ fun un gẹgẹ bi O ti n sọ otitọ fun gbogbo eniyan. “Ẹ ó si mọ otitọ, otitọ yio si sọ nyin di omnira” (Johannu 8:32). Nigbà ti Jesu sọ fun ọdọmọkunrin naa pe, “Lọ tà ohunkohun ti o ni,” eyi kò fi hàn pe Jesu n ta awọn ọlọrọ nù kuro ni Ijọba Ọrun. Jesu n tọka si ohun ti ọkunrin yii ṣe alaini - ìgbàgbọ ninu Jesu bi Messia, ati pe ki o si yọnda ìfẹ rẹ patapata fun Ọlọrun.

Ìjòyè yii gbà lẹsẹkẹsẹ pe Jesu jẹ Olukọni Rere, ṣugbọn n jẹ igbagbọ rẹ kọja eyi? Jesu dahùn pe: “Ẽṣe ti iwọ fi npè mi li ẹni rere? ẹni rere kan ko si bikoṣe ẹnikan, eyini li Ọlọrun” (Marku 10:18). Jesu fẹ tẹ ẹ mọ ọdọmọkunrin naa ati awọn miiran bi ti rẹ leti pe “Gbogbo ẹbun rere ati gbogbo ẹbun pipé lati oke li o ti wá, o si nsọkalẹ lati ọdọ Baba imọlẹ wá” (Jakọbu 1:17). Jesu jẹ ẹni rere ati ẹni pipe, eyi ti o jẹ ẹrí pataki pe O ti ọdọ Baba ti n bẹ ni Ọrun wá. Nitori idi eyi, ohun ti ọdọmọkunrin yii ati gbogbo ẹni ti o ba wá sọdọ Ọmọ Ọlọrun ni lati ṣe ni ki wọn gbé agbelebu wọn ki wọn si maa tọ Ọ lẹyin. Bi ohun ìdíwọ kan ba wà ti yoo jẹ idena lati tọ ọnà ìyè ainipẹkun, Jesu fi hàn pe a ni lati mu un kuro.

Igbagbọ jẹ Kò-ṣe é-má-ni

Ohun ti Jesu n beere ni igbesi-ayé ìjòyè ọlọrọ yii kò mọ sipa ti ara nikan. Ifẹ Ọlọrun ni pe ki gbogbo eniyan ni igbagbọ ninu Rẹ ki wọn si gbẹkẹ le E fun gbogbo ohun ti wọn ṣe alaini ninu ayé yii ati ayérayé. Ṣugbọn o ti ṣoro to fun awọn eniyan lati fi ayé wọn ji fun Ọlọrun ati lati gbẹkẹ wọn le E. ọdọ Ọlọrun ni gbogbo ohun rere ti eniyan ni ninu ayé yii ti n wá, eniyan i ba fi ogo rẹ fun Ọlọrun tabi bẹẹ kọ. Orin Dafidi wi bayi pe: “Enia jade lọ si iṣẹ rẹ ati si lãla rẹ titi di aṣalẹ. …Eyi ti iwọ fi fun wọn ni nwọn nkó: iwọ ṣí ọwọ rẹ, a si fi ohun rere tẹ wọn lọrùn. Iwọ pa oju rẹ mọ, ara kò rọ wọn: iwọ gbà ẹmi wọn, nwọn kú, nwọn si pada si erupẹ wọn” (Orin Dafidi 104:23, 28, 29).

“Li aisi igbagbọ ko ṣe iṣe lati wù u” (Heberu 11:6). “Nitorina ẹ maṣe ṣe aniyan, wipe, Kili a o jẹ? tabi, Kili a o mu? tabi, aṣọ wo li a o fi wọ wa? (Nitori gbogbo nkan wọnyi li awọn Keferi nwá kiri). Nitori Baba nyin ti mbẹ li ọrun mọ pe, ẹnyin kò le ṣe alaini gbogbo nkan wọnyi. Ṣugbọn ẹ tète mã wá ijọba Ọlọrun na, ati ododo rẹ; gbogbo nkan wọnyi li a o si fi kún u fun nyin” (Matteu 6:31-33). ọdọmọkunrin ìjòyè yii kò ni igbagbọ irú eyi ti Jesu n beere. Oun kò fẹ ṣe ohun ti o lè mu ki o ni “pearli olowo iyebiye” ni igbesi-ayé rẹ.

Lai si Ibukun

“Tà ohunkohun ti o ni.” Awọn ọrọ wọnyii fi hàn bi ohun ayé ti ṣe alainilaari to lati fun ni ni ìyè ainipẹkun, wọn i ba pọ tabi ki wọn niye lori lọpọlọpọ. Ọrọ ayé yii kò le ra ohunkohun ti Ọrun, wọn kò si niye lori lọhun. Jesu wi pe: “Ère kini fun enia, bi o jèrè gbogbo aiye, ti o si sọ ẹmí rẹ nù? tabi kili enia iba fi ṣe paṣiparọ ẹmí rẹ?” (Matteu 16:26). Bi o ba jẹ pe ọdọmọkunrin ìjòyè yii fẹ lati ta gbogbo ohun ti o ni ki o si tẹle Oluwa ni, eyi i ba ti fi ifẹ ti o ni si Ọlọrun hàn kedere ju bi ohunkohun miiran ti le fihàn lọ.

Lilọ ti ọdọmọkunrin yii lọ pẹlu ibinujẹ ti mu ki o dá gbogbo eniyan loju pe o fẹran ohun-ini rẹ ju Ọlọrun lọ. Ofin kin-in-ni sọ bayii pe: “Iwọ kò gbọdọ li ọlọrun miran pẹlu mi” (Ẹksodu 20:3). Ọkunrin yii ti fi owó ṣe ọlọrun rẹ kò si fẹ fi i silẹ. Kò di igbà ti eniyan ni ọrọ pupọ ki o to ṣubu sinu aṣiṣe yii. “Ifẹ owo ni gbongbo ohun buburu gbogbo: eyiti awọn miran nlepa ti a si mu wọn ṣako kuro ninu igbagbọ, nwọn si fi ibinujẹ pupọ gún ara wọn li ọkọ” (1 Timoteu 6:10). “Ẹniti o ba fẹ fadaka, fadaka ki yio tẹ ẹ lọrun; bẹẹli ẹniti o fẹ ọrọ ki yio tẹ ẹ lọrun” (Oniwasu 5:10). Solomoni fi ọpọ igbà ni igbesi ayé rẹ wá ohun pataki wọnni ti yoo jẹ ki eniyan le gbadun ayé yii, o si pari gbogbo rẹ si pe: “Bẹru Ọlọrun ki o si pa ofin rẹ mọ: nitori eyi ni fun gbogbo enia” (Oniwasu 12:13).

Èrè Iṣẹ-Isin ti o Tọnà

Iṣẹ-isin ti o tọnà nikan ni Oluwa n fẹ, ṣugbọn gẹgẹ bi a ti sọ fun ni, isin ti o tọnà yii gba gbogbo ayé eniyan – igbesi-ayé rẹ, ifẹ rẹ, ireti rẹ, ilepa rẹ, ati isin atọkanwa si Ọba rẹ. Eyi le ṣoro loju ẹda; ṣugbọn ranti pe eyi yàtọ si ohun igbà isisiyii. Ọdọmọkunrin yii n gbèrò nipa ìyè ainipẹkun, bakan naa ni olukuluku ẹni ti o ba fẹ fi Ọrun ṣe Ile ayérayé ni lati ṣe. Ijoye yii ni ipá lati ṣe ohun ti Oluwa beere yii ṣugbọn o lọ pẹlu ibinujẹ. Oun kò fẹ ṣe ohun ti Jesu n beere lọwọ rẹ.

Fun ohunkohun ti a le beere lọwọ eniyan pe ki o ṣe tabi ti a n fẹ ki o ṣe ki o le ri igbala ati ìyè ainipẹkun, Oluwa ti ṣe ileri ti o nilaari tayọ ohun naa ti a beere. “Tà ohunkohun ti o ni … iwọ ó si ni iṣura li ọrun.” Kò si ọrọ ayé yii ti a le fi wé ọrọ ti o wà ni Ọrun. Kò si ọlá ayé yii ti a le fi wé ogo ti a o fi hàn lara awọn eniyan mimọ ni ayérayé. Ẹni kan ha le sọ igbadun ayé yii ti a le fi wé ayọ ti a o ri gbà ni ọwọ ọtún Ọlọrun? Kò si rara. Pẹlu ireti didùn ti o si logo ti ó wà niwaju wa yii, irú eniyan wo ni Onigbagbọ ni lati jẹ ni gbogbo igbesi-ayé iwa mimọ ati ọrọ sisọ?

Agbelebu

Yàtọ si pe ki o ta ohun ti ó ni, ẹ jẹ ki a ṣe ayẹwò ohun miiran ti ọkunrin yii ni lati ṣe ki o to ni igbala. Oluwa wi fun un pe: “Wá, gbé agbelebu, ki o si mã tọ mi lẹhin.” Eyi ni igbala ọkunrin yii rọ mọ. O le ta gbogbo ohun ti o ni ki o má si jogun ìyè ainipẹkun, ti kò ba fẹ lati tẹle Jesu. Ninu iwe Paulu Apọsteli si awọn ara Kọrinti nipa bi ifẹ ti ga to, o sọ bayii: “Bi mo si nfi gbogbo ohun ini mi bọ awọn talaka, bi mo si fi ara mi funni lati sun, ti emi kò si ni ifẹ, kò li èrè kan fun mi” (1 Kọrinti 13:3).

Awọn eniyan tilẹ wà ti wọn n fẹ lati fi ọpọlọpọ owó funni ti eyi nì ba le ra ìyè ainipẹkun, ṣugbọn wọn kò fẹ ki a mọ wọn gẹgẹ bi ọmọ-ẹyin Oniwatutu ati Onirẹlẹ ara Nasarẹti. Wọn fẹ lati di ipò wọn mu ki wọn si niyi niwaju awọn eniyan. Jesu wi pe: “Egbé ni fun nyin, nigbati gbogbo enia ba nsọrọ nyin ni rere!” (Luku 6:26). Agbelebu kan wà ti Onigbagbọ gbọdọ gbé ni ayé yii, ṣugbọn ade kan wà ti awọn ti o ru agbelebu yoo gbà. Jesu sọ nipa agbelebu yii pe: “Àjaga mi rọrun, ẹrù mi si fuyẹ” (Matteu 11:30). Ẹrí yii dùn ju gbogbo eyi ti awọn ti n sin ayé ati ẹṣẹ ní lọ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ibeere ti ọdọmọkunrin ijòyè ọlọrọ naa beere lọwọ Jesu?
  2. Njẹ ibeere yii kàn wa lonii?
  3. Njẹ ọdọmọkunrin ìjòyè ọlọrọ yii fi tinutinu beere ọrọ yii, tabi o tilẹ fẹ dán Jesu wò lasan ni?
  4. Bawo ni Jesu ti dahùn ibeere ọdọmọkunrin ìjòyè ọlọrọ yii?
  5. Nigbà ti ọdọmọkunrin ijòyè ọlọrọ yii sọ fun Jesu pe oun ti pa gbogbo Ofin mọ lati igbà èwe oun, ki ni Jesu tun sọ fun un pe ki o ṣe?
  6. Njẹ idahùn keji ti Jesu fun ijòyè yii mú inu rẹ dùn tabi o mú inu rẹ bajẹ? Nitori ki ni?
  7. Ki ni ṣe ti ẹnu fi ya awọn ọmọ-ẹyin Jesu?
  8. Bawo ni Jesu ṣe fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ ni idaniloju pé kò si ohun ti o ṣoro fun Ọlọrun?