Lesson 170 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Olubukun li Ọba ti o mbọ wá li orukọ Oluwa” (Luku 19:38).Notes
Igbọran
Nigbà kan Jesu ati awọn ọmọ-ẹyin mejila wà ni ọna, wọn n lọ si Jerusalẹmu (Luku 18:31). Bi wọn ti sunmọ ilu Bẹtani ati Bẹtfage, Jesu rán meji ninu awọn ọmọ-ẹyin Rẹ niṣẹ kan. Ohun ti O sọ kò ju iba ohun ti wọn ni lati ṣe, iba ohun ti wọn ni lati sọ, ati ki ni wọn o ri. Awọn ọmọ-ẹyin meji naa ṣe nnkan ti Jesu palaṣẹ. Wọn kò ja A niyàn rara, bẹẹ ni wọn kò ṣiyemeji Rẹ. Wọn kò beere pe “Ki ni ṣe?” bẹẹ ni wọn kò wi pe “Bi o ba”. Wọn gbọran wọn si bá a gẹgẹ bi O ti wi.
Ni i Fi I Ṣe
Nigbà ti awọn ọmọ-ẹyin naa wọ ileto kan ti o wà nitosi, wọn ri ọmọ kẹtẹkẹtẹ kan ti wọn so pẹlu iya rẹ, gẹgẹ bi Oluwa ti wi (Matteu 21:2). Jesu ti wi pe ki wọn mu ẹranko naa wá fun Oun. Nigbà ti awọn oluwa rẹ beere idi rẹ ti n wọn fi n tú ọmọ kẹtẹkẹtẹ naa, awọn ọmọ-ẹyin dá awọn oluwa rẹ lohun pẹlu ọrọ ti Jesu ti sọ: “Oluwa ni ifi i ṣe”. Idahun yii tẹ awọn oluwa rẹ lọrun. A kò kà nipa adehùn owo fun yiya ọmọ kẹtẹkẹtẹ naa, bẹẹ ni a ko si gbọ pe wọn ra a. O tẹ wọn lọrun pe ki a mu ohun-ọsin wọn lò nitori Oluwa ni i fi i ṣe. Iwọ ha n fẹ bẹẹ pe ki Oluwa lo ohun ti o n pe ni ti rẹ - igbesi-aye rẹ, talẹnti rẹ, ẹri rẹ ati awọn ohun-ini rẹ? Kò ha tẹ ọ lọrun pe Oluwa ni o ni i fi i ṣe?
Kọ ẹkọ nipa igbọran lati ọdọ awọn ọmọ-ẹyin meji wọnyii. Ọlọrun n reti pe ki gbogbo ọmọlẹyin Rẹ gbọ lai beere ati lai ṣe awawi. Nigbà ti Ọlọrun ba fun ọ ni anfaani lati ṣe iṣẹ kan fun Un, ṣe e gẹgẹ bi O ti wi, sọ ọrọ ti O fi fun ọ lati sọ. Nipa igbọran iwọ yoo bá awọn ileri Rẹ, “gẹgẹ bi o ti wi”.
Inu Ọlọrun a maa dùn nigbà ti awọn ọmọde ba n gbọ ti awọn obi wọn pẹlu. Ninu Kolosse 3:20 a kà pe: “Ẹnyin ọmọ, ẹ mã gbọ ti awọn obi nyin li ohun gbogbo: nitori eyi dara gidigidi ninu Oluwa”. Bibeli tun sọ pe: Ẹ mã gbọ ti awọn ti nṣe olori nyin” (Heberu 13:17).
Asọtẹlẹ ti a Muṣẹ
Boya awọn ọmọ-ẹyin n beere laaarin ara wọn eredi rẹ ti Jesu fi fẹ gun kẹtẹkẹtẹ. A kò kà pe o jẹ àṣà Jesu lati maa gun kẹtẹkẹtẹ. Dajudaju ki i ṣe pe n ṣe ni o rẹ Ẹ to bẹẹ ti O fi fẹ gun un. Rara, bẹẹ kọ. O ṣe bẹ ẹ lati le mu ọrọ ti a ti sọ ni ọpọlọpọ ọdun tẹlẹ ṣẹ (Matteu 21:4): “Yọ gidigidi, iwọ ọmọbirin Sioni; ho, Iwọ ọmọbirin Jerusalẹmu: kiye si i, Ọba rẹ mbọwá sọdọ rẹ: ododo li on, o si ni igbalà; o ni irẹlẹ, o si ngùn kẹtẹkẹtẹ, ani ọmọ kẹtẹkẹtẹ” (Sekariah 9:9).
Awọn ọmọ-ẹyin naa mu ọmọ kẹtẹkẹtẹ naa tọ Jesu wá gẹgẹ bi a ti wi fun wọn. Lori kẹtẹkẹtẹ naa ni wọn tẹ aṣọ wọn si pẹlu ifẹ lati lo ohun-ini wọn pẹlu ti awọn ẹlomiran fun Oluwa. Wọn wa gbe Jesu le ori ọmọ kẹtẹkẹtẹ naa eyi ti ẹnikẹni kò gun ri (Matteu 11:2). Ni iwaju Rẹ, loju ọna, wọn tẹ aṣọ wọn ati imọ-ọpẹ silẹ (Johannu 12:13).
Bi Jesu ti sunmọ Oke Olifi lori ọmọ kẹtẹkẹtẹ naa, ogunlọgọ awọn eniyan bẹrẹ si yọ wọn si n yin Ọlọrun logo fun awọn iṣẹ agbara ti wọn ti ri. Wọn pe Jesu ni Ọba, wọn si n kigbe yin In, nitori wọn nireti pe n ṣe ni o n gun kẹtẹkẹtẹ lọ si Jerusalẹmu lati lọ gbé ijọba ti aye kalẹ. Ṣakiyesi pe orin iyin wọn jọ ti awọn ogun ọrun ni alẹ ọjọ ti a bi Jesu: “Ogo ni fun Ọlọrun loke ọrun” (Luku 2:14). Awọn ero ti wọn n lọ niwaju ati awọn ti wọn wà lẹyin Jesu kigbe ni ohùn rara pe: “Hosanna fun Ọmọ Dafidi: Olubukun li ẹniti o mbọ wá li orukọ Oluwa; Hosanna loke ọrun” (Matteu 21:9).
Ọlá fun Jesu
Ọjọ naa ni lati jẹ iyanu fun awọn ọmọ-ẹyin ti wọn ro pe lai pẹ Jesu yoo gbe ijọba Rẹ kalẹ. Awọn ero ti wọn n lọ fun Ajọ Irekọja dapọ ninu iyin naa (Johannu 12:12, 13). Gbiyanju lati fi oju inu wo iṣẹlẹ alárinrin yii bi Jesu ti n fi ọla nla gẹṣin wọ Jerusalẹmu. Wọn ti fi aṣọ ati awọn ẹka igi tẹ oju-ọna, lati dá Jesu lọla. Wọn jẹwọ Jesu ni “Ọmọ Dafidi” (Matteu 21:9), ti a ti sọ asọtẹlẹ rẹ lati jẹ Messia (Isaiah 9:7), Ẹni ti Jesu i ṣe lotitọ (Matteu 1:1). O dabi ẹni pe orin iyin ti o wà ninu Orin Dafidi 118:25 ati 26 ni wọn n kọ “Ṣe igbala nisisiyi, emi mbẹ ọ, Oluwa: … Olubukún li ẹniti o mbọ wa li orukọ Oluwa”. Itumọ “Hosanna” ni “Ṣe igbala nisisiyi.”
Iyin Wọn jẹ Itẹwọgbà
Kò si igbà kan ṣaaju eyi nigbà ti Jesu gba awọn ọmọ-ẹyin ni àyè lati kokiki Rẹ to bẹẹ. Kaka bẹẹ, Jesu ti kilọ fun wọn ni oriṣiriṣi igbà, pe ki wọn má ṣe sọ fun ẹnikẹni nipa awọn iṣẹ-iyanu ti Oun ṣe ati awọn nnkan nlá nlà ti wọn ti ri. Gbogbo awọn wọnyii ni Jesu kilọ fun pe ki wọn pa ẹnu mọ: adẹtẹ kan (Matteu 8:4), afọju meji (Matteu 9:30), ogunlọgọ awọn eniyan ti O wosan (Matteu 12:16), awọn ọmọ-ẹyin lẹyin ti Peteru ti wi pe: “Kristi, Ọmọ Ọlọrun alãye ni iwọ iṣe” (Matteu 16:16, 20); ati fun awọn ti wọn sọkun lẹyin iwosan ọmọbinrin Jairu (Marku 5:43); ati fun awọn ọmọ-ẹyin ti wọn wà pẹlu Jesu ni igbà Ipalarada (Matteu 17:9).
Nisisiyii Jesu gba iyin ati ọlá lati ọdọ awọn eniyan nitori O mọ pe “wakati rẹ de tan” (Johannu 13:1; 12:23). Jesu kò gba iyin wọn nikan, ṣugbọn nigbà ti awọn Farisi lodi si i, O wi pe bi awọn eniyan ba kọ lati yin Oun logo, awọn okuta paapaa yoo kigbe soke. Ọlọrun má jẹ ki a jẹbi fifa iyin wa fun Oluwa sẹyin! Ọlọrun má jẹ ki igbà naa de nigbà ti awọn okuta yoo maa wi iyin Rẹ nitori awa pa ẹnu wa mọ!
Ọjọ Nlá Kan N Bọ
Boya iwọ i ba fẹ lati wà nibẹ ni ọjọ naa lati ju imọ-ọpẹ nigbà ti Jesu gun kẹtẹkẹtẹ wọ Jerusalẹmu. Ọjọ kan n bọ ti o tilẹ logo ju eyi lọ, ninu eyi ti iwọ le ni anfaani nigbà ti Jesu ba de lati jọba bi “ỌBA AWỌN ỌBA, ATI OLUWA AWỌN OLUWA” (Ifihan 19:16). Otitọ ni pe Jesu n jọba ninu ọkàn ati igbesi-aye awọn eniyan Rẹ nisisiyii. Ṣugbọn nigbooṣe oun yoo wá jọba lori ayé fun ẹgbẹrun ọdun (Ifihan 20:6). Akoko naa yoo de nigbà ti a ba sọ “ijọba aiye di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rẹ; on si jọba lai ati lailai” (Ifihan 11:15). Lori ẹṣin funfun ni Oun yoo wá (Ifihan 19:11), pẹlu ẹgbẹgbaarun awọn eniyan mimọ Rẹ (Juda 14; Ifihan 19:14), nigbà ti ohùn ọpọlọpọ eniyan ba n kọrin pe: “Halleluiah: nitori Oluwa Ọlọrun wa, Olodumare, njọba” (Ifihan 19:6).
A ti kẹkọọ nipa bibọ Jesu ati bi ọjọ naa yoo ti jẹ ọjọ nla ati ẹlẹru to. Ọjọ nla fun awọn ti wọn ti mura silẹ de bibọ Rẹ! Ọjọ ẹrù fun awọn ti wọn kọ Jesu ti wọn si ṣe ainaani Rẹ! Iwọ ha mura, ati pe o ha n ṣona fun bibọ Rẹ?
Sisọkun Lori Jerusalẹmu
Nigbà ti wọn sunmọ Jerusalẹmu, Jesu wo ilu naa O si sọkun. Laaarin ohun ti o dabi igbadun yii, ọkàn Ẹni ti wọn n yẹsi gbọgbẹ fun awọn wọnni ti wọn kuna lati gba A gbọ, ti o si jẹ pe, wọn o bọ sinu idajọ nitori aigbagbọ wọn. Dipo alaafia, a o di ọna ti wọn i ba gbà lati sá là nitori naa wọn o di igbekun a o si tu wọn ká, ilu naa funra rẹ ni a o si fi iparun nlá nlà wó lulẹ.
Ni akoko miiran Jesu dárò lori Jerusalẹmu, O si wi pe: “Nigba melo li emi nfẹ iradọ bò awọn ọmọ rẹ, bi agbebọ ti iradọ bò awọn ọmọ rẹ labẹ apá rẹ, ṣugbọn ẹnyin kò fẹ!” (Luku 13:34).
A Wẹ Tẹmpili Mọ
Jesu wọ inu Tẹmpili ni Jerusalẹmu. O ri i pe o yẹ ki Oun wẹ ẹ nù, nitori awọn eniyan n ba ile Ọlọrun jẹ. Ni ibẹrẹ iṣẹ-iranṣẹ Jesu, O ti lé awọn onipaṣiparọ owo kuro ninu Tẹmpili (Johannu 2:15). Awọn eniyan wá lati ọna jijin lati jọsin. Boya awọn miiran ni iru owo ti o yatọ, gẹgẹ bi o ti jẹ pe ni ilu okeere lonii, oriṣiriṣi owo ni wọn n lò. Wọn ro pe ki ijọsin ba le rọrun, awọn eniyan le paarọ owo ti ilu okeere fun iru eyi ti wọn n lò Jerusalẹmu. Awọn miiran n ta awọn ẹran ti wọn maa fi ṣe irubọ ki awọn olujọsin má ba ṣe wahala ati kó ọwọ-ẹran ati agbo-ẹran irubọ wọn wá lati ọna jijin.
Ofin gbà wọn láyè lati mu owo wá si Tẹmpili dipo irubọ irugbin wọn ati ẹran-ọsin wọn nigba ti wọn “ki yio fi le rù u” tabi ti ọna ba “jìn jù” (Deuteronomi 14:24). Ṣugbọn ohun ti o lodi ni awọn eniyan naa n ṣe ni ṣiṣe paṣipaarọ naa ninu Tẹmpili, nitori Ofin tun sọ pe lẹhin ti wọn ba ti yi awọn irubọ naa si owo, wọn ni lati mu un lọ si ibi kan ti Ọlọrun yoo yàn (Deuteronomi 14:25).
Ilé Adura
Jesu ti wi pe, “Ẹ máṣe sọ ile Baba mi di ile ọjà tità” (Johannu 2:16). Jesu tun bá Tẹmpili yii ninu ipò kan naa, o si tun ṣanfaani lati lé awọn olutà ati olurà jade. O ti buru to lati sọ ile Ọlọrun di ihò awọn ọlọṣa (Marku 11:17), ihò olè (Jeremiah 7:11), nigbà ti o jẹ pe ile adura ni! Bi Jesu ba wa lati bẹ ile-isin rẹ wò, a o ha le ọ jade nitori o n lò ó ni ilokulo dipo ki o lò ó bi ile adura?
Ọjọ Isinmi ọpẹ
Ọjọ Oluwa ti oni ni a n ṣe iranti ọjọ nì eyi ti Jesu fi iho ayọ wọ inu ilu Jerusalẹmu. Ọjọ Isinmi Ọpẹ ni a n pe e, o si jẹ ibẹẹrẹ akoko ti a n pe ni Ọsẹ Ijiya, ọsẹ ti o ṣiwaju Ọjọ Ajinde. Eyi maa n rán awọn eniyan Ọlọrun leti ọjọ ti O fi iho ayọ wọ inu igbesi-aye wọn. Lati ete wọn ni iyin n bú jade si I fun gbogbo iṣẹ agbara Rẹ. O ha ti jẹ ki Jesu wọ inu igbesi-aye rẹ lati ṣe akoso ati lati jọba nibẹ? O ko le ni akoko ti o san ju oni yii lọ. Má ṣe jafara, ki iparun, ti o wá sori Jerusalẹmu ma ba wá sori iwọ naa.
Questions
AWỌN IBEERE- Nibo ni Jesu gbe ri ọmọ kẹtẹkẹtẹ naa?
- Ki ni ṣe ti O fi gun ọmọ kẹtẹkẹtẹ?
- Ki ni igbe ti awọn eniyan naa n ké?
- Ki ni ṣe ti awọn eniyan naa yin In logo?
- Ki ni iba ṣẹlẹ bi o ba ṣe pe awọn eniyan naa ba pa iyin wọn mọ?
- Ki ni ṣe ti Jesu sọkun lori Jerusalẹmu?
- Ki ni ṣe ti o fi yẹ lati wẹ Tẹmpili mọ?
- Bawo ni awọn eniyan ṣe sọ ọ di “ihò awọn ọlọṣà” dipo “ile adura”?