Marku 15:42-47; 16:1-20; Iṣe Awọn Apọsteli 1:1-11.

Lesson 171 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹ lọ si gbogbo aiye, ki ẹ si ma wasu ihinrere fun gbogbo ẹda” (Marku 16:15).
Notes

Ireti Pin

Fun ọpọlọpọ ọgọrun ọdun ni awọn Ju ti n wo ọna fun ẹni kan ti yoo ti aarin wọn dide ti yoo jẹ ọba alagbara. Wọn ṣafẹri ẹni kan ti yoo ṣẹ agbara awọn ti o n ni wọn lara, ti yoo si tun sọ wọn di orilẹ-ède ominira lẹẹkan si i. Nigbà naa ni Jesu de ti O n ṣe ọpọlọpọ iṣẹ iyanu: O n wo awọn alaisan sàn, O n ji oku dide, O n fi iba akara marun un pere ati ẹja diẹ bọ ẹgbẹẹgbẹrun eniyan. Dajudaju O le ṣe ohunkohun; awọn eniyan kan si wà ti wọn gba A gbọ ti wọn si rò pe nisisiyii Oludande tabi Messia naa ti de ná.

Ṣugbọn lẹyin ọdún mẹta pere ti O n kiri laaarin awọn eniyan, ti O n ṣe rere, wọn kàn An mọ agbelebu; sibẹ wọn wà labẹ isinru ijọba Romu. Nitootọ eniyan pupọ ni wọn ti ri igbala, ti a ti dari ẹṣẹ wọn jì, ti wọn si ti di ominira nipa ti ẹmi; ṣugbọn wọn fẹ ni ijọba ti o wà lominira.

Ominu kọ wọn, wọn si n beere laaarin ara wọn bayii: Ki ni ṣe ti O fi jẹ ki awọn ọta Rẹ lu u pẹlu ẹgba tabi ọgọ? Ki ni ṣe ti O tẹle wọn de Oke Kalfari ki wọn le kàn An mọ agbelebu? O ti wi pe Oun le pe ẹgbẹ legioni awọn angẹli lati ran Oun lọwọ bi o ba jẹ pe Oun fẹ bẹẹ. Ki ni ṣe ti Oun kò fi sọkalẹ lati ori agbelebu? Wọn ti ni ireti titi de opin - ṣugbọn O ti kú nisisiyii.

Iwe Mimọ Ti O Ṣẹ

Ọkunrin kan wà ti a n pè ni Josẹfu ara Arimatea ẹni ti o ti n reti pe ki Ọlọrun gbe ijọba kalẹ ninu aye, o si ni lati ro pe Jesu ni ipa kan lati kó ninu rẹ, bi o tilẹ jẹ pe O ti kú. A kò gbọ ki a darukọ rẹ pẹlu awọn ọmọ-ẹyin Jesu, ṣugbọn ni akoko yii oju kò ti i lati tọ Pilatu lọ lati beere okú Jesu ki oun ba le fun Un ni isinkú ti o ni ọla. Josẹfu jẹ ọlọrọ o si ni iboji daradara eyi ti o fi tọkantọkan yọnda fun Jesu, ni imuṣẹ asọtẹlẹ Isaiah: “O si ṣe iboji rẹ pẹlu awọn enia buburu, ati pẹlu ọlọrọ ni ikú rẹ” (Isaiah 53:9). Awọn eniyan buburu naa ni awọn ole ti wọn kàn Jesu mọ agbelebu pẹlu wọn, Josẹfu si ni ọlọrọ ninu iboji ẹni ti a tẹ Ẹ si.

Ọjọ Kẹta

Awọn olori alufaa ti wọn ti dá Jesu lẹbi ikú ranti pe Jesu ti sọ pe Oun yoo jinde ni ọjọ kẹta. Ki i ṣe pe wọn gbagbọ pe yoo jinde, ṣugbọn ẹrù ba wọn pe ninu awọn ọmọ-ẹyin Rẹ le wá ji okú Jesu gbe ki wọn si wi pe O ti jinde. Wọn fẹ ki Pilatu ri i daju pe wọn ṣọ iboji naa rekọja ọjọ kẹta ki awọn Ju má ba de ibẹ.

Kò yẹ ki awọn alufaa yọnu nipa awọn ọmọ-ẹyin rara. Wọn kò tilẹ ranti pe Jesu ti sọ pe Oun yoo tun jí dide. Inu wọn bajẹ to bẹẹ ti o fi jẹ pe gbogbo nnkan ti wọn n ro kò ju pe olufẹ wọn ti lọ kuro lọdọ wọn. Ninu ibanujẹ wọn, wọn wi pe: “On li awa ti ni ireti pe, on ni iba dá Israẹli ni ìde” (Luku 24:21). Wọn si ro pe ireti ti dopin patapata niyẹn.

Ireti Iye

Jesu ti gbiyanju lati kilọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ pe Oun ni lati jiya ki Oun si kú: ṣugbọn O ṣe ileri fun wọn pe Oun yoo tun wà laaye. Ni akoko kan lẹyin Ipalarada, O wi fun Peteru, Jakọbu, ati Johannu pe ki wọn má ṣe sọ ohun ti wọn ti ri titi di igbà ti “Ọmọ-enia ba ti jinde kuro ninu okú” (Marku 9:9). Wọn ti n bi ara wọn pe: ki ni itumọ ohun ti O sọ nipa ajinde “kuro ninu okú”? Ni akoko miiran O ti wi fun wọn pe Oun ni agbara lati fi ẹmi Oun lelẹ ati lati tun gbà á pada; ṣugbọn irú nnkan bẹẹ kò i ti ṣẹlẹ ri. Irú ède yii ṣe le yé wọn?

Jesu tun ti wi fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ pe lẹyin ti Oun ba ti jinde Oun yoo pade wọn ni Galili. Ṣugbọn awọn ọmọ-ẹyin kò wa A lọ si Galili nitori wọn kò tun ni ireti ati ri I mọ lae.

Aigbagbọ

Maria Magdalene ati Maria miiran wà nibẹ nigbà ti wọn tẹ Jesu sinu iboji Josẹfu, wọn si ti lọ si ile lati tọju turari ti wọn fẹ kun ara Rẹ lẹyin Ọjọ Ọsẹ. Kò tilẹ wá si ọkàn wọn rara pe O le ti lọ nigbà ti wọn pada.

Ro bi ẹnu ti yà wọn to nigbà ti wọn de ni Ọjọ kin-in-ni ọsẹ pẹlu turari wọn, ti wọn si bá iboji ni ofifo! Jesu ti lọ kuro nibẹ: ṣugbọn angẹli kan jokoo nibẹ lati sọ fun wọn pe: “O jinde; kò si nihin yi”. Aṣọ ọgbọ wiwẹ ti Josẹfu ti mu wá fun isinkú Kristi wà nibẹ nitori naa kò si iyemeji pe boya wọn ti ṣi iboji yà. Iroyin naa dẹruba awọn obinrin naa wọn kò si le gbagbọ.

Jesu ti jinde pẹlu ara ti o jẹ pe, ni iri o dabi ẹran-ara eniyan. Nigbà ti O pade Maria Magdalene ninu ọgbà ti O si ba a sọrọ, oun kọkọ ro pe oluṣọgba ni I ṣe, o si bi I leere bi Oun ni ẹni ti o gbe okú Jesu kuro. Nigbà ti O pe e ni orukọ, nigbà naa ni o mọ pe Oluwa oun ni. O sure lọ sọ fun awọn ọmọ-ẹyin iyoku pe ni tootọ ni O ti jinde kuro ninu oku, ati pe oun ti ri I. Ṣugbọn wọn kò gbà á gbọ.

Lẹyin naa ni ọjọ kan naa bi awọn meji ninu awọn ọmọ-ẹyin ti n rin lọ si Emmausi, Jesu bá wọn rin O si bá wọn sọrọ; o dẹsẹ duro O si ba wọn jẹun. Oun ki i ṣe iwin bi ko ṣe Jesu, láàyè ninu ara. Nigbà ti O sure si ounjẹ ki wọn to jẹ ẹ, wọn ri pe Oun ni. O nù mọ wọn loju, wọn si pada kiakia si Jerusalẹmu lati sọ fun awọn Apọsteli pe awọn ti ri Jesu láàyè. Ṣugbọn awọn eniyan ti wọn sọ fún kò gbagbọ!

A Bá Awọn Ọmọ-ẹyin Wí

O dun Jesu pe kò si ẹni ti o jẹ gbagbọ - kò tilẹ si ẹni kan ninu awọn Apọsteli Rẹ ti o gbagbọ - titi di igbà ti wọn fi ri I láayè. O ti sọ fun wọn pe Oun ni lati kú, ṣugbọn pe Oun yoo jinde ni ọjọ kẹta. Nigbà ti Jesu bá awọn mọkanla pade, O beere ohun ti o ṣe ti wọn kò fi gbà ohun ti Oun ti wi gbọ. Awọn ohun ti awọn wolii si ti kọ silẹ nipa Rẹ n kọ? Wọn kò ha le gbà wọn gbọ bi? O ha yẹ ki a ṣẹṣẹ fihàn wọn ki wọn to le gbagbọ bi? Jesu wi fun Tọmasi pe: “Nitoriti iwọ ri mi ni iwọ ṣe gbagbọ: alabukun-fun li awọn ti ko ri, ti nwọn si gbagbọ” (Johannu 20:29). Ibukun nì wà lori gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun lonii ti wọn kò ri Jesu ninu ara ṣugbọn ti wọn gbagbọ pe O kú fun ẹṣẹ wa O si tun ji dide.

Àṣẹ Kristi

Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ pe Oun ti pari iṣẹ ti Baba ti rán Oun lati ṣe ni aye, ati pe lai pẹ Oun yoo lọ si Ọrun lati lọ wà pẹlu Baba. Lẹyin ti Oun ba ti lọ wọn ni lati waasu gbogbo ohun ti Oun ti waasu; ironupiwada ati idariji ẹṣẹ. Wọn gbọdọ kọ awọn eniyan pe Jesu fẹran wọn, ati pe wọn ni lati gba A gbọ ki wọn ba le ri igbala. Wọn ni lati gbagbọ pe Jesu ti kú gẹgẹ bi etutu fun ẹṣẹ wọn O si tun jí dide.

Awọn ọmọ-ẹyin kò ni dá nikan wa nigbà ti wọn ba lọ n waasu – ni Jerusalẹmu, fun awọn eniyan ti wọn ti pa Jesu; ni Samaria, laaarin awọn eniyan ti awọn Ju korira; ni gbogbo igberiko yika agbegbe wọn, ati fun awọn ajeji eniyan ti wọn wà ni opin ilẹ ayé. Jesu yoo ba wọn lọ yoo si maa ba wọn ṣiṣẹ, yoo si maa “fi idi ọrọ naa kalẹ.” Itumọ eyi ni pe Oun yoo fi ibukun sori iṣẹ iranṣẹ wọn Oun yoo gba awọn ọkàn là Oun yoo si wo awọn alaisan sàn ni idahun si adura wọn, gẹgẹ bi O ti ṣeleri.

Ami ti N Tẹle e

Jesu wi pe: “Àmi wọnyi ni yio si ma ba awọn ti o gbagbọ lọ.” Ọpọlọpọ eniyan lonii ni wọn n sọ pe akoko iṣẹ iyanu ti kọja lọ; pe iṣẹ-iyanu wà ni ọjọ wọnni lati fi idi ijọ mulẹ, ṣugbọn pe lonii kò si mọ nitori wọn kò ṣanfaani mọ. Ṣugbọn Jesu wi pe: “Àmi wọnyi ni yio si ma ba awọn ti o gbagbọ lọ: Li orukọ mi ni nwọn o ma lé awọn ẹmi èṣu jade; nwọn o si ma fi ède titun sọrọ; Nwọn o si ma gbé ejò lọwọ; bi nwọn ba si mu ohunkohun ti o li oró, ki yio pa wọn lara rara: nwọn o gbé ọwọ le awọn olokunrun, ara wọn ó da”. Bi awọn ami wọnyii kò ba wà ninu igbesi-aye wa gẹgẹ bi Onigbagbọ, o ni lati jẹ pe a kò gbagbọ ni; bẹẹ “li aisi igbagbọ ko ṣe iṣe lati wù u” (Heberu 11:6).

Bi ara awọn alaisan kò ba dá ni idahun si adura wa, ti iṣẹ-iranṣẹ wa kò si yọri si iyipada awọn ẹlẹṣẹ, o ni lati jẹ pe igbagbọ wa kuna. Apọsteli Jakọbu kọwe pe: “Fi igbagbọ rẹ hàn mi li aisi iṣẹ, emi o si fi igbagbọ mi hàn ọ nipa iṣẹ mi” (Jakọbu 2:18). Eyi ni pe, iwọ wi pe o ni igbagbọ, fi i hàn nipa iṣẹ rẹ gẹgẹ bi ileri Ọlọrun. Ọrọ Ọlọrun kò le yẹ, ileri Rẹ si wà fun awọn ti o ba gbagbọ.

Jesu gbadura fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ pe ki igbagbọ wọn má ṣe yẹ. Bi a ba n ka Bibeli ti a si n gbadura si Jesu, Oun yoo fun wa ni igbagbọ eyi ti yoo ṣiṣẹ agbara fun Ọlọrun. A ni lati kọkọ ni idariji ẹṣẹ wa ná; nigbà naa ti a kò ba ni idalẹbi ninu ọkàn wa, a o ni igboya pe Ọlọrun n gbọ ti wa nigbà ti a ba gbadura, a o si ri idahun gbà. “Àmi wọnyi ni yio si ma ba awọn ti o gbagbọ lọ,” wà ninu awọn ọrọ ikẹyin Jesu. Lẹyin naa ni O paṣẹ fun wọn lati pada si Jerusalẹmu ki wọn duro de ileri ifi Ẹmi Mimọ wọ ni, eyi ti yoo ṣe wọn ni ẹlẹri ti o ni agbara nibikibi ti wọn ba lọ. Igbagbọ wọn yoo pọ si i ki awọn ami wọnni ba le maa tẹle iwaasu wọn.

Sinu Awọsanma

Gbogbo rẹ ti pari bayii. Fun ogoji ọjọ Jesu ti n rin laaarin wọn, O si ti fun wọn ni ọpọlọpọ ẹri ti a kò le ṣiyemeji rẹ pe Oun wà laaye ni tootọ, Jesu kan naa ti O ti kú lori agbelebu. Lori Oke Olifi, bi awọn ọmọ-ẹyin ti n wo O, a gba Jesu soke ninu awọsanma lọ si Ọrun – O si lọ.

Awọn ọmọ-ẹyin duro sibẹ pẹlu iyanu wọn tẹju mọ ibi ti Jesu ti goke lọ. A o tun sọ ireti wọn di asan bi? O ha le jẹ pe Ẹni ti wọn fẹran pupọ to bẹẹ ti lọ titi laelae? Lojiji awọn angẹli meji duro laaarin wọn, wọn si wi pe, “Jesu na yi, ti a gbà soke ọrun kuro lọwọ nyin, yio pada bẹẹ gẹgẹ bi ẹ ti ri i ti o nlọ si ọrun.” Eyi jẹ ileri kan pe Oun yoo tun pada wá, o si tẹ awọn ọmọ-ẹyin lọrun. Lai ṣe aniani wọn wá ranti pe Jesu ti sọ pe: “Emi nlọ ipèse àye silẹ fun nyin. Bi mo ba si lọ ipèse àye silẹ fun nyin, emi o tún pada wá, emi o si mu nyin lọ sọdọ emi tikarami; pe nibiti emi gbé wà, ki ẹnyin le wa nibẹ pẹlu” (Johannu 14:2, 3).

Awa gẹgẹ bi Onigbagbọ ni Jesu n sọ bẹẹ fun lonii. O wà ni Ọrun, O n pese ayè silẹ fun wa, O si n pese wa silẹ fun ibẹ; ni ọjọ kan lai pẹ Oun yoo si tun pada wá lati mu awọn eniyan Rẹ lọ si Ọrun nibi ti wọn yoo ti jẹ igbadun gbogbo iyanu ti O ti pese silẹ fun awọn ti wọn fẹ Ẹ.

Ki O to de, a ni lati fi tọkantọkan ṣiṣẹ wa fun Oluwa, ki a fi igbagbọ wa ninu Rẹ hàn nipa iṣẹ ti a n ṣe.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta ni kan Jesu mọ agbelebu? Ki ni ṣe?
  2. Ta ni sin Jesu? asọtẹlẹ inu Iwe Mimọ wo ni ó mu ṣẹ?
  3. Bawo ni a ṣe mọ pe awọn Maria mejeeji kò gbagbọ pe Jesu yoo tun jinde?
  4. Bawo ni o ti ri ni ọkàn Jesu nipa ihà ti awọn ọmọ-ẹyin Rẹ kọ si iroyin nipa pe O wà láàyè?
  5. Darukọ diẹ ninu awọn igbà tabi akoko ti Jesu fara hàn lẹyin ti O jinde.
  6. Sọ diẹ ninu ọrọ ikẹyin Jesu.
  7. Ta ni yoo gba awọn ibukun ti Jesu ṣeleri.
  8. Bawo ni Jesu ṣe fi ayé yii silẹ?
  9. Ki ni iṣẹ tí awọn angẹli ti wọn pade awọn ọmọ-ẹyin lori Oke Olifi jẹ fun wọn?