Joṣua 7:1-26

Lesson 172 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Emi ki yio wà pẹlu nyin mọ, bikoṣepe ẹnyin pa ohun iyasọtọ run kuro lãrin nyin” (Joṣua 7:12).
Notes

Awọn Amí

Ọlọrun ti ran awọn Ọmọ Israẹli lọwọ lọnà iyanu lati ṣẹgun ilu Jẹriko. Okiki wọn, ati ti Joṣua aṣaaju wọn, ti kàn yi gbogbo orilẹ-ède naa ká. Dajudaju eyi jẹ iwuri fun awọn Ọmọ Israẹli wọn si fẹ lati gba ilẹ kún ilẹ si i lai pẹ lara Ilẹ Ileri.

Joṣua rán awọn amí lọ lati yẹ ilu Ai wò. Wọn mu iroyin wa pé ki gbogbo Israẹli má ṣe lọ lati ba ilu naa jagun. Gẹgẹ bi amọran awọn amí naa Joṣua rán awọn eniyan diẹ - nnkan bi ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan lati gba ilu Ai.

Iṣubu

A kò ri i kà pe wọn beere amọran lọdọ Ọlọrun nipa gbigba ilu Ai. Boya awọn Ọmọ Israẹli ṣe iwárapàpà pupọ ju tabi wọn ti ni idaniloju ninu ara wọn pupọ ju. Awọn amí ti wi pe awọn ẹgbaa mẹfa (12,000) eniyan ilu Ai (Joṣua 8:25) kò to nnkan. Pẹlu iranlọwọ Ọlọrun wọn i ba fi irọrun gbà ilu naa, ṣugbọn a kò ri i kà pe wọn beere iranwọ lọdọ Ọlọrun. Awọn ẹlomiran a maa gbiyanju tikara wọn ninu agbara ati ọgbọn wọn lati bá ọta wọn, Satani jà. Gẹgẹ bi awọn Ọmọ Israẹli, Oluwa gbọdọ jẹ iranwọ wọn bi wọn ba n fẹ jẹ aṣẹgun.

O dabi ẹni pe awọn ẹlomiran ki i ni ayọ ninu iṣẹ Oluwa, wọn a si fẹ lati jokoo fi ẹyin tì nigbà ti awọn ẹlomiran ba n ṣiṣẹ. Ni tootọ ni o jẹ pe gbogbo awọn eniyan Ọlọrun kò le wà ni gbogbo ipade isin ti a n ṣe, tabi ki gbogbo wọn wà ninu gbogbo ogun tabi ninu gbogbo iṣe naa, ṣugbọn olukuluku ni o le ni ipin ti o pọ ninu adura gbigba. Ọlọrun n fẹ ki awọn eniyan Rẹ, ọmọde ati agba maa gbadura fun ipade isin kọọkan ati gbogbo iṣẹ itankalẹ Ihinrere. Awọn amí wi fun Joṣua pe ki o má ṣe jẹ ki gbogbo eniyan lọ “ṣiṣẹ.” Ọpọlọpọ ni o wà ninu iṣẹ Oluwa ti wọn ka a si ohun gbẹfẹ lati ṣe e, wọn kò ka ohun ti wọn n ṣe si iṣẹ. Awọn ti wọn ba n beere fun ọna ti o rọrun yoo maa ni ijatilẹ. Dipo ti wọn i ba fi ṣẹgun awọn ara ilu Ai, awọn Ọmọ Israẹli sá niwaju wọn, wọn si pa mẹrindinlogoji (36) eniyan ninu wọn.

Yíyà Kuro Lọdọ Ọlọrun

Iṣubu awọn Ọmọ Israẹli ni Ai rẹ wọn silẹ. Ẹru wà ni gbogbo ibudo. Ọlọrun ti fi aini inu didun si wọn hàn nipa fifà iranwọ Rẹ sẹyin. Ọlọrun kò ha ti ṣe ileri lati wà pẹlu Joṣua (Joṣua 1:5), pe ki yoo si ẹni kan ti yoo le duro niwaju rẹ? A kò ha ti sọ fun awọn Ọmọ Israẹli pe Ọlọrun Alaaye wà laaarin wọn, ati pe Oun ki yoo kuna lati lé awọn olugbe ilẹ Kenaani kuro niwaju wọn? (Joṣua 3:10). Ọlọrun kò ha ti wi pe, “Ẹnyin o si lé awọn ọtá nyin, nwọn o si ti ipa idà ṣubu niwaju nyin. Marun ninu nyin yio si lé ọgọrun, (100), ọgọrun ninu nyin yio si lé ẹgbarun (10,000), awọn ọtá nyin yio si ti ipa idà ṣubu niwaju nyin?” (Lefitiku 26:7, 8). Nibo ni imuṣẹ ileri Ọlọrun gbé wà? Ikuna naa wà lọwọ awọn Ọmọ Israẹli, ki i ṣe nipa aijẹ oloootọ Ọlọrun tikara Rẹ.

Joṣua kò ba awọn amí sọ pe wọn mu ihin ti o mu iṣina wá tabi pe awọn ọmọ ogun hu iwa ojo. Joṣua mu ọran naa tọ Oluwa lọ. O gbadura o si beere lọwọ Ọlọrun ohun ti oun o ṣe ki awọn eniyan ilẹ naa má ba gbọ nipa iṣubu naa tán, ki wọn si ṣe alaibọwọ fun orukọ Oluwa mọ. Nigbà ti Joṣua gbadura bẹẹ tan, Oluwa sọ fun un pe akoko to lati ṣe ohun kan.

Ẹṣẹ Ninu Agọ

Ohun ti i maa ṣẹlẹ ni pe awọn ti o ṣẹgun ni i maa ni ẹtọ si “ikogun” (awọn ohun ti o niyelori) nigbà ti wọn ba ṣẹgun ilu kan. Ṣugbọn kò ri bẹẹ nipa ilu Jẹriko, eyi ti i ṣe iṣẹgun akọkọ fun awọn Ọmọ Israẹli lẹyin ti wọn rekọja Odo Jọrdani si ilẹ Kenaani. Ki wọn to ṣẹgun ilu Jẹriko, a ti sọ fun wọn pe: “Gbogbo fadakà, ati wurà ati ohunelo idẹ ati irin, mimọ ni fun OLUWA” (Joṣua 6:19). Wọn jẹ ti Oluwa, boya gẹgẹ bi akọso (Ẹksodu 34:26). Gbogbo ohun ti o kù já si ohun ifibu, wọn si gbọdọ pa wọn run.

A ti kilọ fun awọn Ọmọ Israẹli ki wọn má ṣe mu ohun kan ninu awọn ikogun Jẹriko. “Ati ẹnyin, bi o ti wu ki o ri, ẹ pa ara nyin mọ kuro ninu ohun iyasọtọ, ki ẹ má ba yà a sọtọ tán ki ẹ si mú ninu ohun iyasọtọ na; ẹnyin a si sọ ibudó Israẹli di ifibu, ẹnyin a si mu iyọnu bá a” (Joṣua 6:18).

Ọkunrin kan ti a n pè ni Akani kò gbọran si ohun ti Joṣua sọ, o si mu ninu ẹru awọn nnkan naa pamọ, o si n rò pe ẹnikẹni ki yoo mọ ohun ti oun ṣe. Ṣugbọn Ọlọrun sọ fun Joṣua pe ẹni kan laaarin awọn Ọmọ Israẹli ti dẹṣẹ nitori wọn ti mu ohun ti i ṣe ti Oluwa. Ọlọrun sọ pe wọn ti jale, ohun ifibu naa si wà ninu ẹru wọn. Wahala de ba agọ Israẹli wọn ko si le duro niwaju awọn ọta wọn. Ọlọrun tọka si ẹṣẹ naa ṣugbọn O si tun wi pe Oun ki yoo tun wà pẹlu wọn mọ titi wọn o fi wẹ ibudo mọ ki wọn si pa ohun iyasọtọ naa run kuro laaarin wọn.

Ọrọ Ọlọrun si awọn Ọmọ Israẹli jẹ eyi ti gbogbo eniyan ni lati fiye si ni akoko yii pẹlu. O sọ pe wọn ni lati ya ara wọn si mimọ - ki wọn wadii ara wọn wò – lati duro niwaju Ọlọrun. Gẹgẹ bi Ọlọrun ti kọ lati wà pẹlu awọn eniyan ni igbà aye Joṣua bẹẹ ni ki yoo wà pẹlu awọn eniyan nisisiyii a fi bi a ba pa ohun iyasọtọ (ẹṣẹ) nì run. Eniyan a maa di ẹni ifibu nipasẹ ohun irira si Oluwa ti o wà ninu ayé rẹ. Ẹṣẹ a maa ya eniyan ya Ọlọrun. A ni lati ronupiwada rẹ tọkantọkan, nitori kiki nipa ironupiwada ẹni ti o ṣẹ si Ọlọrun nikan ni afi le pa a run kuro ninu ọkàn ati ayé ẹni naa. Ki i ṣe gbogbo awọn Ọmọ Israẹli ni o ya ara wọn si mimọ nitori ọkan ninu wọn jẹbi a si ni lati jẹ ẹ ni iya.

A fi Ẹṣẹ Hàn

Gẹgẹ bi Ọlọrun ti darukọ ẹṣẹ naa, O le darukọ ẹlẹṣẹ naa lẹsẹkẹsẹ. Ṣugbọn ọna ti Ọlọrun ni o dara ju lọ, nitori O fun Akani ni anfaani lati jẹwọ ẹṣẹ rẹ ki a to fi ipá mu un jẹwọ nipasẹ idajọ, ṣugbọn oun kò ṣe bẹẹ. Bi awọn Ọmọ Israẹli ti duro niwaju Oluwa, ni ẹya kọọkan, a mu ẹya Juda pe o jẹbi. Lẹyin naa wọn duro ni ẹbi kọọkan, agboole kọọkan ati ọkunrin kọọkan niwaju Oluwa. Ọna ti o falẹ ṣugbọn ti o daju ni a gbà wadii ọkunrin naa ti o jẹbi, ani Akani. “Ki o si dá nyin loju pe, ẹṣẹ nyin yio fi nyin hàn” (Numeri 32:23).

Boya Akani ro pe oun ti fi ohun iyasọtọ naa pamọ daradara to bẹẹ ti ẹnikẹni ki yoo fi mọ. Awọn ẹlomiran ni ọjọ oni ro pe awọn ni ẹṣẹ ti wọn ro pe o pamọ, ṣugbọn “Kò si ohun ti a bò, ti a ki yio si fihàn; tabi ti o pamọ, ti a ki yio mọ” (Luku 12:2). Awọn ọmọde tabi agba miiran a maa gbiyanju lati fi èké, olè tabi ẹtàn wọn pamọ. Boya a ko i ti fi wọn hàn ṣugbọn Ọlọrun mọ nipa wọn. Ni ọna ti Rẹ ati ni akoko ti Rẹ a o fi wọn hàn, gẹgẹ bi ti ẹṣẹ Akani. Ni 1 Timoteu 5:24 a kà pe, “Ẹṣẹ awọn ẹlomiran a mã han gbangba, a mã lọ ṣaju si idajọ; ti awọn ẹlomiran pẹlu a si mã tẹle wọn.” Akani jẹ ẹni kan ti ẹṣẹ rẹ tọ ọ lẹyin lọ sinu idajọ. Nibẹ ni o duro, oun nikan pẹlu ẹbi.

Ijẹwọ

Bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun ti fi hàn pe Akani ni o jẹbi, Joṣua tun gba Akani ni iyanju lati jẹwọ. Joṣua kò pe e ni ole ati ọlọṣa. Pẹlu inu rere ni o sọ fun Akani, “Ọmọ mi … sọ fun mi nisisiyi, ohun ti iwọ ṣe.” A sọ fun Akani pe ki o jẹwọ ẹṣẹ rẹ ni kikún, ki o má kàn wi pe “Mo jẹbi.” Awọn ẹlomiran yoo gbà pe ẹlẹṣẹ ni awọn i ṣe. Iṣísẹ kan ṣoṣo ni eyi. Nigbà ti eniyan ba ni lati bá Ọlọrun lò ki o si duro niwaju Onidajọ gbogbo ayé, yoo jẹwọ ikọọkan ninu gbogbo iṣẹ buburu rẹ, nitori a ki yoo gboju fo ọkan.

Akani gbà pe oun ti dẹṣẹ, o ni nigbà ti oun ri ẹwù, fadaka ati wura naa, o jẹ idanwo fun oun. Abajọ ti a fi n kilọ fun wa ninu orin kan ti awọn ọmọde n kọ nigbà gbogbo: “Oju mi ma ṣe wo ohun ti kò tọ!” Lẹyin eyi Akani ṣe ojukokoro o si n fẹ wọn. Wò o bi ẹṣẹ kan ti maa n ti eniyan lọ sinu omiran! “Iwọ kò gbọdọ ṣe ojukokoro … ohun gbogbo ti iṣe ti ẹnikeji rẹ” jẹ ọkan ninu Ofin Mẹwaa (Ẹksodu 20:17). Nigbà ti a dán Akani wo bẹẹ, o yẹ ki o bẹ Ọlọrun pe ki O gba oun. Dajudaju ki Akani to jale náa o wo ihin o si wo ọhun lati kiyesi bi ẹnikẹni ba n ṣọ oun. I ba ṣe pe o gbọn oun i ba woke ninu adura si Oluwa. Kaka bẹẹ o mu ohun iyasọtọ naa. Dajudaju oun kò duro lati ro pe oun ki yoo le lo ẹwù Babeli naa. Ẹnikẹni ti o ba ri i yoo mọ pe jiji ni o ji i ni Jẹriko. Akani fi ohun ti o ji pamọ ki a ma ba fi ẹṣẹ rẹ hàn – eyi ni oun rò.

Jija Ọlọrun Lólè

Igba ṣekeli fadakà ati dindi wurà wọnni jẹ ti Ọlọrun. Bawo ni Akani ṣe le ni ero lati gbadun tabi lati lo ohun ti i ṣe ti Ọlọrun nipa ẹtọ? Ṣugbọn awọn eniyan wà nisinsinyi ti wọn n fi ohun ti i ṣe ti Ọlọrun du U. “Enia yio ha jà Ọlọrun li olè? ṣugbọn ẹnyin sa ti jà mi li olè. Ṣugbọn ẹnyin wipe, nipa bawo li awa fi jà ọ li olè? Nipa idamẹwa ati ọrẹ” (Malaki 3:8). Eyi yii jẹ ọrẹ owo wa ati ọrẹ iyin ati ẹri wa. A ni lati kọ awọn ọmọde lati san idamẹwa - idamẹwa ohun ti wọn n gba ati eyi ti o n wọle fun wọn – ki wọn si tun fi ọrẹ wọn silẹ pẹlu. Nigba pupọ o le jẹ kọbọ kan tabi meji, sibẹ ti Rẹ ni. Ọlọrun n fẹ ọrẹ iyin ati ẹri lati ọwọ ọmọde ati agba pẹlu. Nipa jija Ọlọrun lolè, kò si ere kan ti ẹnikẹni le ri gbà ju eyi ti o jẹ ipin Akani.

A tun kà nipa aigbọran miiran. Nigbà ti Saulu jẹ ọba lori Israẹli, a ràn án lati lọ pa awọn Amaleki run, Saulu kò pa awọn ti o dara ju lọ run ninu awọn agutan ati maluu ati ohun gbogbo ti o dara (1 Samuẹli 15:9). O ṣe awawi pe oun dá wọn si lati fi wọn rubọ si Oluwa (1 Samuẹli 15:15). O ṣe aigbọran, nitori aṣẹ Ọlọrun ni pe ko gbọdọ dá ohunkohun sí. A sọ fun Saulu pe “igbọran sàn jù ẹbọ lọ” (1 Samuẹli 15:22). A kò le ṣẹṣẹ maa wi pe, Saulu ko ṣe aṣeyọri. Ko ronupiwada, Ọlọrun si kọ ọ silẹ.

Aigbọran

Akani pẹlu gbogbo Israẹli ni o jiya fun aigbọran rẹ. Ẹṣẹ kan ṣoṣo yii mu wahala pupọ bá Israẹli, o si yọri si ikú Akani. Ẹṣẹ a maa fa wahala wá sori ẹlẹṣẹ ati nigbà pupọ fun awọn ti wọn wa yí i ká. Ẹṣẹ aigbọran kan ti ọmọkunrin kan tabi ọmọbinrin kan ṣẹ le ṣe ibi fun gbogbo ẹbi tabi fun gbogbo ijọ, gẹgẹ bi ẹṣẹ Akani ti ṣe.

Lẹyin ti Akani ti jẹwọ ibi ti o fi awọn ohun ti ó jí pamọ si, awọn iranṣẹ sare lọ si agọ rẹ lati wẹ Israẹli mọ ati lati mu ohun iyasọtọ kuro. A ri wọn nibẹ, ninu ẹru Akani, bi ẹni pe o ni ẹtọ si wọn ati bi ẹni pe a ki yoo beere lọwọ rẹ lati ṣe iṣiro lori wọn ati bi ẹni pe ki yoo tilẹ ṣe atunṣe lori wọn.

Idajọ

A fi awọn ohun iyasọtọ naa lelẹ niwaju Oluwa, niwaju Joṣua ati niwaju gbogbo Israẹli. Ki wọn ba le ni Ọlọrun laaarin wọn, o kù ohun kan ti wọn ni lati ṣe – lati pa ohun iyasọtọ naa run. Awọn ẹlomiran a jẹwọ ẹṣẹ wọn ṣugbọn wọn a si tun di wọn mú sibẹ. Ki iranwọ Ọlọrun to jẹ ti ẹnikẹni Ọlọrun n fẹ ki a kọ ẹṣẹ silẹ gẹgẹ bi O ti fẹ ki a jẹwọ rẹ. “Ẹniti o bo ẹṣẹ rẹ mọlẹ ki yio ṣe rere: ṣugbọn ẹnikẹni ti o jẹwọ ti o si kọ ọ silẹ yio ri ãnu (Owe 28:13).

Awọn Ọmọ Israẹli kò fi ọran naa falẹ. Akani ati gbogbo ile rẹ (awọn ẹni ti o ṣe e ṣe ki wọn mọ nipa ohun ti ó fi pamọ sinu agọ wọn) ni wọn pa; ẹwù Babeli naa, fadakà ati wurà ati ohun gbogbo ti i ṣe ti Akani ni wọn parun. Lẹyin ibudo ni a ti sọ wọn ni okuta ti a si fi ina sun wọn. A kó okuta jọ si ori eeru wọn lati maa rán awọn Ọmọ Israẹli, ati awa paapaa lonii leti pe ẹṣẹ kan ninu igbesi-aye eniyan yoo yà á kuro lọdọ Ọlọrun.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti a ṣẹgun awọn Ọmọ Israẹli ni Ai?
  2. Bawo ni wọn i ba ti ṣe ti wọn i ba fi bọ lọwọ iṣubu naa?
  3. Ki ni irekọja?
  4. Ki ni ṣe ti dindi wurà naa jẹ ohun iyasọtọ?
  5. Bawo ni a ṣe ri i?
  6. Ki ni awọn iṣisẹ mẹrin si ẹṣẹ ti Akani ṣẹ?
  7. Ki ni ẹṣẹ Akani?
  8. Awọn wo ni o jiya nitori ẹṣẹ Akani?
  9. Bawo ni a ṣe jẹ Akani niya?