Joṣua 8:1-35

Lesson 173 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ibukún ni fun awọn ti nfọ aṣo wọn, ki nwọn ki o le ni anfani lati wá si ibi igi ìye na” (Ifihan 22:14).
Notes

Iṣẹgun Nipa Igbọran

Israẹli ti kọ ọgbọn gidigidi nipa iṣubu ti o bá wọn ni Ai. Ọlọrun fihàn wọn pe wọn ni lati gbọran bi wọn ba n fẹ iranwọ Rẹ.

Ọlọrun kò yi ipinnu Rẹ pada fun Israẹli lati ṣẹgun ilu Ai. O fẹ fi iṣẹgun fun awọn eniyan Rẹ; nigbà ti ẹlẹṣẹ si jẹwọ, ti wọn si ti pa a run, Ọlọrun tun mura lati mu wọn lọ si oju ogun – nisisiyii pẹlu idaniloju iṣẹgun. Ọlọrun ṣe ileri pe wọn o pa ilu yii run gẹgẹ bi o ti rí fun Jẹriko nigbà ti wọn kọlu gẹgẹ bi aṣẹ Rẹ.

Nigbà miiran awọn eniyan ti o bẹrẹ lati maa sin Ọlọrun a ṣaigbọran si I, wọn a si fà sẹyin. Oun ti bukún fun wọn niwọn igbà ti wọn gbọ ti Rẹ; ṣugbọn nigbà ti ẹṣẹ yọ wọle, Oluwa fi wọn silẹ. Ẹni ti o ba wà ni ipo yii kò i ti di ẹni ti a tanu patapata lati ṣegbe lai ni ireti. Bi o ba jẹwọ ẹṣẹ rẹ tọkantọkan ti o ba si ronupiwada rẹ, Jesu yoo dariji i, Oun yoo si tun fi oju-rere hàn fun un.

Boya iṣẹ kan ni Ọlọrun ti fi fun oluwa rẹ lati ṣe, eyi ti o kuna lati ṣe; ti ikuna naa si di ẹṣẹ. Nigbà ti o ba ronupiwada, iṣẹ naa ṣi wà nibẹ o si ni lati mu un ṣe.

Akọso

A ti kọ pe awọn akọso ti ikore ati ti ibisi agbo-ẹran ati ẹran-ọsin awọn Ọmọ Israẹli jẹ ti Ọlọrun. Nipa bayii ikogun ti wọn kó ni Jẹriko jẹ ti Ọlọrun gẹgẹ bi akọso, nitori on ni ilu kin-in-ni ti wọn gbà ni Kenaani. Dajudaju ọrọ Jẹriko yoo tobi to loju awọn Ọmọ Israẹli ti ko ri iru nnkan bẹẹ ri ninu irinkiri wọn fun ogoji ọdun ninu aginju. Ṣugbọn i ba ṣe pe Akani ti ṣe suuru diẹ Ọlọrun i ba ti fun un ni gbogbo eyi ti o n fẹ ninu ikogun naa.

Nigbà ti Ọlọrun fun Joṣua ni aṣẹ nipa ibiwo Ai, O sọ fun un pe awọn eniyan naa le mú ohun gbogbo ti wọn ba n fẹ: wurà ati fadakà, aṣọ ati ẹran-ọsin. Ronu bi wọn yoo ti layọ to lati le kó gbogbo iṣura wọnyii jọ! Awọn Ọmọ Israẹli ti wọn duro titi Ọlọrun fi wi pe wọn le mu wọn lò, ni wọn gbadun gbogbo iṣura naa, ṣugbọn Akani kú nitori aini suuru rẹ.

Awa pẹlu le kọ ẹkọ mimu suuru ninu ẹkọ yii. Ọlọrun ri ohun ti a ṣe alaini, O si ti ṣeleri lati pese gẹgẹ bi ọrọ Rẹ ninu ogo. A kò ni ẹtọ lati gbiyanju ati lọ ṣaaju lati ran ara wa lọwọ nitori a ro pe awọn ibukun naa pẹ jù ki o to de. Dafidi wi pe: “Emi duro dè Oluwa, ọkàn mi duro, ati ninu ọrọ rẹ li emi nṣe ireti” (Orin Dafidi 130:5). Oju-rere ti Dafidi si ri lọdọ Ọlọrun pọ to bẹẹ ti o fi di Ọba Israẹli ti o tobi ju lọ. Inu wahala ni a o bọ si nigbà ti a ba n gbiyanju lati ran ara wa lọwọ.

Ètò Ọlọrun

Ọlọrun ni eto nipa eyi ti awọn Ọmọ Israẹli le fi ṣẹgun Ai. Oun ni Ọgagun-agba, Joṣua si ni balogun Rẹ ti o ni irawọ marun un. Balogun naa gbọran si eto yii.

Ni akọkọ, Joṣua rán ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) akọni ọkunrin ni iṣẹ abẹlẹ kan. Ni oru, wọn yọ lọ si ihà iwọ-oorun Ai, nibi ti wọn fi ara pamọ si ni ibuba. Ni kutukutu owurọ ọjọ keji Joṣua kó iyoku awọn ọmọ-ogun lọ, o si tẹgun ni ibudo kan nihà ariwa Ai. Ni oru naa o kó ẹgbẹ ogun diẹ sọkalẹ si afonifoji ti o wà laaarin wọn ati ilu naa.

Ijọra-Ẹni-Loju Ọba Naa

Boya ọba Ai ro pe oun ti ṣẹgun awọn Ọmọ Israẹli patapata to bẹẹ ti wọn kò fi ni tun pada wa mọ. O le ti ṣe ẹfẹ nigbà ti o ri Joṣua ati ẹgbẹ ọmọ-ogun rẹ kekere ni afonifoji, ti aya kò ó to bẹẹ lati kọju ija si ilu rẹ ti o lagbara. O dide ni kutukutu owurọ ọjọ keji, o si kó awọn ọmọ-ogun rẹ jade lati lé awọn onijọngbọn Ọmọ Israẹli nì ti wọn n yọ ọ lẹnu kuro.

Ṣugbọn ohun ti ọba kò reti ni o ba pade. Oun kò mọ nipa gbogbo awọn ọmọ-ogun ti Joṣua fi sori oke ni ihà ariwa, tabi ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) akọni ọkunrin ti wọn wà ni ibuba nihà ẹnu ibode ti iwọ-oorun ilu rẹ. Gbogbo ohun ti o ri kò ju Joṣua ati ẹgbẹ kekere nì ti o wà ni afonifoji. Ọba kó gbogbo ọmọ-ogun rẹ jade lọ lati yọ lori iṣubu awọn Ọmọ Israẹli. Awọn ọmọ-ogun Beti-eli paapaa, ilu kekere kan ni ihà iwọ-oorun jade wá lati ṣe iranwọ lati doju ti awọn ọmọ-ogun Israẹli.

Nigbà pupọ ni awọn ẹlẹṣẹ maa n kugbu ṣe nnkan, ti wọn si n jọ ara wọn loju pupọ jù, lai ranti pe Ọlọrun n bojuto awọn ọmọ ti Rẹ. A kà nipa ọba Nebukadnessari ti o paṣẹ pe ki olukuluku eniyan ti o wà ni ijọba rẹ wolẹ fun ere ti oun gbé kalẹ. Ibinu rẹ ru nigba ti o gbọ pe awọn ọmọ Heberu mẹta kọ lati wolẹ. O paṣẹ pe ki wọn sọ wọn sinu iná, o si wi pe: “Ta li Ọlọrun na ti yio si gbà nyin kuro li ọwọ mi?” (Daniẹli 3:15). Ọlọrun fi hàn an! Iná ti o gbona to bẹẹ ti o fi jó awọn ẹṣọ ti wọn gbe awọn igbekun naa sinu rẹ, kò le pa awọn ọmọ Ọlọrun lara. Ati pẹlu, Oluwa tikara Rẹ sọkalẹ wa O si n bá wọn rin laaarin iná naa. Nigbà ti a si mu wọn jade kuro ninu ileru naa, oorùn iná kò tilẹ si lara aṣọ wọn.

Dafidi wi pe oun ti ri eniyan buburu ninu agbara nla, “O si fi ara rẹ gbilẹ bi igi tutu nla. Ṣugbọn o kọja lọ, si kiyesi i, kò si mọ … Ma kiyesi ẹni pipé, ki o si ma wò ẹni diduro ṣinṣin: nitori alafia li opin ọkọnrin na” (Orin Dafidi 37:35-37).

Ọgbọn Joṣua

Joṣua ati awọn eniyan rẹ yi pada wọn si sá, gẹgẹ bi ọba ti ro pe wọn o ṣe. Gbogbo ogun Ai si lepa wọn, titi wọn fi de inu aginju, jinna réré si ilu wọn. Nigbà naa ni Ọlọrun sọ fun Joṣua lati na ọkọ rẹ soke gẹgẹ bi ami fun awọn ọmọ-ogun ti wọn wà ni ibuba lati dide lọ gba ilu naa. A le ri oorun ti n kọ mọnà lara oju irin ọkọ naa lati ọna jijin. Awọn ẹgbẹ ọmọ-ogun ti wọn fi ara pamọ naa fò soke! Wọn sare wọ inu ilu naa, wọn si kó ohun gbogbo ti wọn n fẹ ninu awọn ile iṣura ati ibugbe ati ibi ipaka, lẹyin naa ni wọn ti iná bọ Ai.

Ronu bi ẹnu yoo ti ya awọn ọmọ-ogun Ai ati ọba wọn nigbà ti wọn boju wo ẹyin ti wọn si ri eefin ti n yọ bi ẹfufu lati inu ilu wọn. Ọna wọn ti jinna ju eyi ti wọn fi le ri nnkan ṣe nipa rẹ, awọn ọmọ-ogun Israẹli si doju kọ wọn lati ihà gbogbo, wọn fẹ ha wọn mọ fun iṣẹgun. Ni ọjọ naa ẹgbẹ ogun Joṣua pa ẹgbaa mẹfa (12,000) eniyan; a si fi ilu Ai silẹ ni okiti alapa.

Awọn ọmọ-ogun Israẹli ti mu ọba Ai ni igbekun, wọn si mu un tọ Joṣua lọ. Joṣua so ó rọ lori igi titi di aṣalẹ lẹyin naa ni o si sin in si atiwọ ibode ilu ti a parun naa. A ko okiti okuta le e lori lati rán awọn eniyan ti o ba ri i leti ohun ti yoo ṣẹlẹ si ẹnikẹni ti o ba gbiyanju lati bá Ọlọrun ati awọn eniyan Rẹ jà.

Idupẹ Fun Iṣẹgun

Awọn Ọmọ Israẹli kọ orin iṣẹgun pada si ibudo wọn. Wọn ru ẹrù ikogun ti wọn kó ni Ai. Inu wọn ti dùn to pe Ọlọrun fun wọn ni iṣẹgun! Bawo ni inu wa ti maa n dùn to nigba ti a ba gbọ ti Ọlọrun, ti O ba si mu wa jade gẹgẹ bi aṣẹgun!

Joṣua ranti lati dupẹ lọwọ Ọlọrun fun iṣẹgun naa. O tẹ pẹpẹ kan fun Ọlọrun lori Oke Ebali, gẹgẹ bi a ti palaṣẹ fun Mose. Lori pẹpẹ yii ni a ti rú ẹbọ ọpẹ si Ọlọrun fun alaafia.

Si ara pẹpẹ naa ni Joṣua kọ Ofin Mẹwaa ni oju gbogbo awọn eniyan naa. A ni lati maa rán wọn leti lojoojumọ pe wọn gbọdọ pa gbogbo Ọrọ Ọlọrun mọ. Niwọn igbà ti wọn ba n gbọran si Ọlọrun lẹnu nikan ni wọn yoo ni iṣẹgun. Joṣua ka awọn ibukun ti wọn yoo rí gbà fun igbọran si wọn leti; ati awọn ègun ti yoo wà fun aigbọran.

Lonii a ni Bibeli pẹlu gbogbo ofin Ọlọrun ninu rẹ. Bi a ba fẹ a le mọ ohun ti Ọlọrun n fẹ ki a ṣe gan an. Bi a kò ba si ṣe e, a o fi idakẹ-yadi niwaju Oluwa nigbà ti O ba dide duro ni idajọ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta ni ṣe eto bi a ti ṣe kọlu Ai?
  2. Ṣe alaye eto ijà naa.
  3. Ki ni awọn Ọmọ Israẹli yoo ri gẹgẹ bi erè ninu ogun naa?
  4. Ki ni ṣẹlẹ lẹyin ti awọn ọmọ-ogun Ai fi ilu wọn silẹ?
  5. Awọn wo ni wọn bori ninu ogun naa? Ki ni ṣe?
  6. Ki ni ṣẹlẹ si awọn ara ilu Ai?
  7. Ki ni ṣẹlẹ si ilu wọn?
  8. Ki ni Joṣua ṣe lẹyin ti wọn pada si ibudo Israẹli?
  9. Bawo ni a ṣe le bori ogun Satani?