Lesson 174 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Li ọwọ rẹ li awa wà: bi o ti dara si ati bi o ti tọ si li oju rẹ lati ṣe wa, ni ki iwọ ki o ṣe” (Joṣua 9:25).Notes
Wọn Dojuja Kọ Israẹli
Awọn ara Kenaani ti gbọ nipa iṣẹgun ti awọn Ọmọ Israẹli ti ni. Boya wọn si gbọ pẹlu, pe Ọlọrun Israẹli ti ṣe ileri lati lé awọn ọta wọn jade, eyi ti yoo jẹ iparun fun awọn ara Kenaani. Wọn le túúbá bi Rahabu (Joṣua 2:11-13, 18), tabi ki wọn ṣọtẹ. Wọn yàn lati ṣọtẹ nitori bẹẹ wọn kó ara wọn jọ lati gbiyanju ati ṣe idena fun awọn Ọmọ Israẹli. Lai ṣe aniani wọn ti jà laaarin ara wọn nigbà pupọ, ṣugbọn nisisiyii wọn kó ara wọn jọ. Wọn ni ohun kan ti o pa wọn pọ - wọn dojuja kọ Israẹli.
Awọn ti wọn n ṣọtẹ lode oni si Ọlọrun ki i ṣe aṣeyọri lọnakọna gẹgẹ bi o ti ri fun awọn ara Kenaani. Wọn le kó ara wọn jọ ki wọn si bá Ọlọrun jà, ṣugbọn fun iparun ara wọn ni (Orin Dafidi 2:2-4). Awọn ẹlomiran a tùùbá fun agbara Ọlọrun; awọn ẹlomiran a si sé ọkàn wọn le si Oluwa. Ninu ẹkọ yii, a n kọ nipa oriṣi awọn eniyan kẹta, awọn ti wọn n fẹ lati wá ọna miiran lọ si Ọrun yatọ si eto Ọlọrun.
Ẹtàn
Awọn ara Gibeoni kò ba awọn iyoku lọ si ogun. Wọn fi ọna ẹtàn ṣe adehun alaafia. Awọn Ọmọ Israẹli pagọ si Gilgali, ni iwọnba irin ọjọ diẹ si awọn ara Gibeoni. Sinu ibudo Israẹli ni awọn ọkunrin kan lọ bi ẹni pe ikọ ọba ni wọn jẹ lati ilu okeere wá. Wọn wọ bata gbigbo ati ẹwù gbigbo. Ounjẹ ti wọn mu lọwọ ti gbẹ o si ti hùkàsi. Igo ọti waini wọn (boya awọ ni wọn fi ṣe wọn) ti fàya, wọn si tun wọn rán. Nipa ifarahan wọn o dabi ẹni pe lati ọna jijin ni awọn ọkunrin naa ti wá.
Wo bi ẹṣẹ kan ti n yara mú ni lọ sinu omiran! Awọn ara Gibeoni fi ifarahan wọn tan awọn Ọmọ Israẹli jẹ, wọn kò si sọ otitọ nigbà ti wọn n bẹbẹ fun adehùn alaafia. Ẹkọ yii n kọ ni pe bi o ti jẹ ẹṣẹ lati fi ọrọ tan ni jẹ bakan naa ni o jẹ ẹṣẹ lati tan ni jẹ nipa ifarahan tabi ihuwasi wa.
Ni akoko miiran Oluwa sọ fun Samuẹli pe: “Oluwa ki iwò bi enia ti nwò: enia a ma wò oju, Oluwa a ma wò ọkàn” (1 Samuẹli 16:7). Bakan naa ni ọrọ yii ri nipa awọn ara Gibeoni ati ihuwasi wọn pẹlu awọn Ọmọ Israẹli, ti wọn ro pe otitọ ni awọn ara Gibeoni n sọ nitori bi wọn ti fi ara hàn lode. Ṣugbọn awọn ara Gibeoni ko tan Ọlọrun, nitori Oun n wo inu ọkàn wọn.
Imọ Ara Wọn
Boya ori awọn Ọmọ Israẹli wule pe awọn jẹ eniyan pataki to bẹẹ ti awọn ikọ lati ilu okeere fi wá bẹ wọn wò. Wọn gbẹkẹle imọ ara wọn dipo ki wọn beere lọwọ Ọlọrun ohun ti wọn i ba ṣe (Joṣua 9:14).
Bi o tilẹ jẹpe o dabi ẹni pe otitọ ni awọn ara Gibeoni n sọ, o dabi ẹni pe awọn Ọmọ Israẹli fura iwa jamba si wọn, wọn si beere ilu ti wọn ti wá. Awọn ara Gibeoni kò sọ. Ki aṣiiri wọn má ba tú, awọn ara Gibeoni tubọ n sọ itan wọn ni asọdun si i, pe ni gbigbona ni awọn mu akara wọn jade ni ọjọ ti wọn dide, ṣugbọn pe nisisiyii o ti gbẹ o si ti bu. Ẹwu wọn wà ni ipo ti o buru ju eyi ti awọn Ọmọ Israẹli ti wọn fi rin kiri ninu aginju fun ogoji ọdùn (Deuteronomi 8:4).
A le wi pe awọn ara Gibeoni mọ pupọ nipa Ọlọrun. Wọn tilẹ ti gbọ nipa awọn iṣẹ ti O ti ṣe fun awọn Ọmọ Israẹli ni Egipti, ati iṣẹgun lori awọn Ọba awọn Amori nihà ila-oorun odo Jọrdani. Wọn kò ni ṣai mọ pẹlu pe Ọlọrun kò kọ fun awọn Ọmọ Israẹli lati ba awọn olugbe ilu ti o jinna rere ṣe adehùn alaafia (Deuteronomi 20:10-16), nitori bi wọn ti fi ara hàn ni yii. Wọn fi ẹnu jẹwọ pe wọn bọwọ fun Ọlọrun. Wọn n fẹ alaafia lọnakọna wọn si gbà lati jẹ iranṣẹ fun awọn Ọmọ Israẹli. Nigbà naa ni wọn beere fun majẹmu.
Kò Si Ironupiwada
Anfaani kan ṣoṣo ti awọn ara Gibeoni ni lati là ni fun wọn lati wá alaafia pẹlu awọn Ọmọ Israẹli. Yoo ti pẹ ju lẹyin ti awọn Ọmọ Israẹli ba ti wọ inu ilu wọn. Ọna a ti sá fun idajọ ni lati pade rẹ pẹlu ironupiwada tootọ. A kò gbọ pe awọn ara Gibeoni kọ awọn oriṣa wọn silẹ tabi pe wọn fi ara wọn le aanu Ọlọrun lọwọ. Nipa ẹtàn wọn dá majẹmu eyi ti o fun wọn ni anfaani lati wà laaye. Wọn kò beere ju eyi lọ - lati wà laaye. Anfaani ti wọn ri yii kò dá wọn lare fun iwa buburu ti wọn hù. Bi o tilẹ jẹ pe a fun wọn láyè lati wà laaye, sibẹ wọn o duro niwaju Ọlọrun lati ṣiro nipa ẹtàn ati èké ti o wà ninu igbesi-ayé wọn.
Gbogbo ẹlẹṣẹ lonii wà ni ipò awọn ara Kenaani. Idajọ ati iparun Ọlọrun wà niwaju fun wọn. Ki ni wọn yoo ṣe? Awọn miiran yoo ṣọtẹ gẹgẹ bi ọpọlọpọ awọn ara Kenaani ti a parun nigbooṣe. Awọn miiran yoo ṣe afarawe awọn Gibeoni. Nipa ẹtàn ati eke wọn yoo gbiyanju lati “gbà ibomiran gùn oke” (Johannu 10:1). Awọn eniyan bayii ni Kristi pe ni olè ati ọlọṣa, wọn kò si ni lọ si Ọrun laelae.
Awọn ẹlẹṣẹ miiran dabi awọn ara Gibeoni ti wọn npe ara wọn ni ohun ti wọn kò jẹ gẹgẹ bi awọn ara Gibeoni ti fi ẹtàn pe ara wọn: oungbẹ n gbẹ ọkàn wọn nitori ẹṣẹ ti kuna lati tẹ wọn lọrun. Akara wọn ti bu o si ti gbẹ: nigbà gbogbo ni iyàn wà nipa ti ẹmi ninu ayé. Ẹwù wọn ti gbó: “ododo” wọn “si dabi akisa ẹlẹgbin” (Isaiah 64:6). Wọn ti gbọ iroyin nipa agbara Ọlọrun lati gba ni là ati lati fun ni ni iṣẹgun. Wọn n fẹ ri aanu Ọlọrun lọnakọna. Wọn mọ pe anfaani wọn kan ṣoṣo ni yii lati le ni iye ainipẹkun. Awọn ẹlẹṣẹ wọnyii gbà tọkantọkan lati maa sin Ọlọrun, lati kọ oriṣa wọn ati lati wá pẹlu ironupiwada. Ọna kan ṣoṣo ti eniyan fi le bọ ninu iparun ayeraye ni lati kepe Ọlọrun fun aanu ki o si gba idariji fun ẹṣẹ rẹ.
Majẹmu
Awọn Ọmọ Israẹli kò beere imọran lọwọ Ọlọrun. Wọn gbẹkẹle iro inu ara wọn. Wọn bá awọn ará Gibeoni dá majẹmu. Lẹyin naa ni wọn ri aṣiṣe wọn, nitori ará itosi Kenaani ni awọn ara Gibeoni i ṣe.Wọn ki i ṣe ikọ lati ilu okeere. A le fi ẹtàn ati eke pamọ fun sáà kan, ṣugbọn o pẹ ni tabi o yá, wọn yoo di mimọ. “Ahọn eke, ìgba diẹ ni” (Owe 12:19), a o si fi otitọ hàn.
Nigba ti awọn Ọmọ Israẹli ti rìn fun ọjọ mẹta, wọn de awọn ilu mẹrẹẹrin ti awọn ara Gibeoni. A ti dá majẹmu lati jẹ ki wọn wà laaye, nitori bẹẹ a ko pa awọn ara Gibeoni run. Majẹmu nipa iyè ni. Awọn Ọmọ Israẹli mọ pe Ọlọrun fi ọwọ danindanin mu adehùn ti a ba ṣe. A ko gbọdọ fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ẹjẹ tabi ki a fi i ṣẹsin. Ọlọrun yoo beere majẹmu wa pẹlu Rẹ ni kikún.
O yẹ ki awọn ọmọde kọ ọgbọn ninu ẹkọ yii ki wọn ba le maa ṣọra nipa jijẹ ẹjẹ. Ọlọrun n fẹ ki eniyan gbero lori ẹjẹ ti o fẹ jẹ, pẹlu ipinnu ninu ọkàn rẹ lati mu un ṣẹ, dipo ki o fi iyarapapa, aibikita ati aifarabalẹ jẹ ẹjẹ. Inu Ọlọrun kò dun nipa ẹjẹ ti a ko le mu ṣẹ. O sàn ki a má jẹ ẹjẹ naa ju pe ki a jẹ ẹ ki a si ba a jẹ lọ. “Nigbati iwọ ba jẹjẹ kan fun OLUWA Ọlọrun rẹ, ki iwọ ki o máṣe fàsẹhin lati san a: nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ yio bère rẹ nitõtọ lọwọ rẹ; yio si di ẹṣẹ si ọ lọrùn” (Deuteronomi 23:21). A kò kọ ni ni ẹkọ yii lati mu irẹwẹsi ba awọn eniyan nipa ẹjẹ jijẹ ati ifararubọ. Ọlọrun n beere lọwọ gbogbo Onigbagbọ lati fi ayé wọn rubọ nigbà gbogbo fun Oun.
Awọn ẹlomiran maa n fẹ lati ṣe awawi pe eniyan tàn wọn ni, tabi pe ẹjẹ tabi majẹmu naa jẹ eyi ti awọn ko fi ara balẹ ṣe. Ṣugbọn kò si awawi ti o jẹ itẹwọgba lọdọ Ọlọrun. O n ka ẹjẹ ti eniyan ba jẹ si i lọrun. Majẹmu pẹlu Ọlọrun jẹ eyi ti o wà titi aye ainipẹkun (Isaiah 55:3). Kristi ru ẹbọ kan fun ẹṣẹ titi lae (Heberu 10:12). A kò ṣe e fun akoko ti o wọ bi ko ṣe fun aye ainipẹkun ati titi lae. Ẹni ti o ti ba Ọlọrun ṣe adehun, majẹmu ti iye, ni lati ka a si danindanin ki o ma ba ti ipasẹ biba a jẹ fa ibinu Ọlọrun wá sori ara rẹ. Nigba ti ọpọlọpọ ọdun tilẹ ti kọja, nigbà ti Saulu pa awọn ara Gibeoni (eyi ni pe o ba majẹmu naa jẹ) Ọlọrun rán iyàn fun ọdun mẹta si aarin awọn Ọmọ Israẹli (2 Samuẹli 21:1).
Ki ṣe Ará bi kò ṣe Ẹrú
Awọn ará Gibeoni ti fi eke ra ẹmi wọn. O ṣe e ṣe ki wọn padanu awọn ilu wọn, nitori wọn di ara ilẹ-ini ẹya Bẹnjamini (Joṣua 18:25-28). Wọn padanu ominira wọn, nitori awọn ara Gibeoni di ẹrú tabi iranṣẹ - “aṣẹgi ati apọnmi” (Joṣua 9:23). Awọn ará Gibeoni kò ṣe awawi kankan fun ara wọn. Wọn wi pe ki awọn Ọmọ Israẹli ṣe si awọn gẹgẹ bi o ba ti tọ. Wọn wà lọwọ awọn Ọmọ Israẹli ati labẹ aanu wọn.
Awọn Ọmọ Israẹli ti gbẹkẹle ọgbọn ti ara wọn eyi kò si tó. Wọn jiya fun ikuna wọn lati beere imọran Ọlọrun, ati fun ikanju wọn. Nitori wọn dá awọn ará Gibeoni sí, awọn Ọmọ Israẹli ni lati lọ jà lati daabo bo wọn (Joṣua 10:6).
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni ṣe ti awọn ara Gibeoni n fẹ lati bá awọn Ọmọ Israẹli dá majẹmu?
- Iwa buburu wo ni wọn hù?
- Ki ni ṣe ti wọn tan awọn Ọmọ Israẹli jẹ?
- Nigbà wo ni ẹtàn naa di mimọ?
- Dipo jijẹ arakunrin awọn Ọmọ Israẹli, ki ni awọn ará Gibeoni wá dà?
- Aṣiṣe wo ni Israẹli ṣe?
- Lọna wo ni bibeere imọran lọwọ Ọlọrun fi le jẹ iranwọ fun wa?