Joṣua 10:1-27

Lesson 175 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI:“Ohunkohun ti o wù Oluwa, on ni iṣe li ọrun, ati li aye, li okun, ati li ọgbun gbogbo” (Orin Dafidi 135:6).
Notes

Jijà Fun Gibeoni

Awọn Ọmọ Israẹli ti bẹrẹ si gba ilẹ Kenaani. Ẹru nla kún ọkàn awọn olugbe ilẹ naa nigbà ti wọn gbọ nipa iṣẹ-iyanu ti Jẹriko ati Ai ati gẹgẹ bi Gibeoni ti ṣe túúbá fun wọn. Nitori ẹrù yii, awọn ọba Amori marun un sowọpọ lati bá Ọlọrun ati awọn eniyan Rẹ jà. Kò si ironupiwada ninu ọkàn wọn, a fi ibẹru, eyi ti o ti wọn lati gbiyanju lati gba Gibeoni pada. O jẹ ilu nla pẹlu awọn akọni ọkunrin ninu rẹ o si ti bọ lọwọ iparun lati ọwọ awọn Ọmọ Israẹli nitori awọn ara ilu naa túúbá. Gbogbo ogun awọn Amori dó ti Gibeoni lati ba a jà nitori awọn ara Gibeoni ti ṣe ipinnu alaafia pẹlu awọn Ọmọ Israẹli.

A ti paṣẹ fun awọn Ọmọ Israẹli pe wọn kò gbọdọ dá ọkan si ninu awọn olugbe ilẹ Kenaani. Nipa ọgbọn arekereke ati ẹtàn a mu ki awọn Ọmọ Israẹli ṣe adehùn nipasẹ eyi ti a dá awọn ara Gibeoni si. Awọn Ọmọ Isarẹli kunà lati beere amọran lọwọ Ọlọrun. Wọn ti kunà lati gbadura lori ọran ti o ṣe pataki bi ṣiṣe adehùn alaafia. Sibẹ Ọlọrun kò gba fun awọn Ọmọ Israẹli lati yẹ adehùn naa. Nigba ti awọn Amori gbogun ti awọn ara Gibeon, wọn pe awọn Ọmọ Israẹli lati wá daabo bo wọn.

Ọlọrun Ṣeleri Iranwọ

Nitori Joṣua ati awọn Ọmọ Israẹli pa adehùn wọn mọ, Ọlọrun ṣeleri pe ọkan ninu awọn ọta ki yoo le duro niwaju wọn, Ọlọrun ṣeleri lati fi awọn ara Amori le awọn Ọmọ Israẹli lọwọ nitori naa awọn ọta wọnyii ki yoo le ba wọn jà bẹẹ ni wọn ki yoo si le sá.

Awọn Ọmọ Israẹli kò jafara. Nipa iwuri ati imulọkanle ti Ọrọ Ọlọrun ṣe fun wọn, wọn tọ awọn ara Amori lọ lati bá wọn jagun. Wọn kò jokoo fi ẹyin ti ki wọn si maa duro de Ọlọrun lati lọ ja ija naa. Wọn gba Ọlọrun gbọ wọn si ṣe ipa ti wọn.

A Tú Awọn Ọtá Ká

Oluwa ṣẹgun awọn ọta naa. Wo iru idaamu ati ẹrù ti yoo ṣẹlẹ! O daju pe awọn ẹgbẹ ogun ọba Amori maraarun yii dide ogun si awọn Ọmọ Israẹli pẹlu idaniloju nla ninu ọkàn wọn. Ṣugbọn igbẹkẹle wọn kò duro pẹ titi nitori awọn eniyan Ọlọrun ti ileri Oluwa wà fun ni wọn n bá jà. Awọn ọta wọnyii gbẹkẹle awọn ọmọ-ogun wọn ti o pọ lọpọlọpọ ni iye, ohun ija wọn, ati ọgbọn iwéwe wọn. Ṣugbọn niwaju Ọlọrun Israẹli wọn jẹ alailagbara a si tú wọn kaakiri.

Awọn Ọmọ Israẹli kò ni itẹlọrun lati le awọn ọta kuro ni Gibeoni nikan, nitori eyi nì le tun mu ki wọn tun ja ogun miiran lati daabo bo awọn ara Gibeoni. Awọn Ọmọ Israẹli le awọn ọta naa wọn si pa ọpọlọpọ ninu wọn.

Yinyin Nlá Nlà

Ọlọrun ran awọn Ọmọ Israẹli lọwọ pẹlu. Bi awọn ara Amori ti bẹrẹ si i sa lọ, Ọlọrun rán yinyin nlá nlà lati Ọrun. Má ṣe ro pe eyi kan dede ṣẹlẹ bẹẹ ni - Ọlọrun rán yinyin nlá nlà naa gẹgẹ bi idajọ sori awọn ara Amori. Eyi ki i ṣe yinyin lasan, nitori awọn ara Amori nikan ni o pa. A kò ri i kà pe yinyin naa pa ẹnikẹni ninu awọn Ọmọ Israẹli tabi ki o tilẹ pa ẹnikẹni ninu wọn lara. Ọlọrun dari wọn lati maa pa awọn ti wọn bà. Awọn ara Amori ti yinyin pa pọ ju iye awọn ti a fi ida pa loju ogun lọ. Ọlọrun pa awọn ọta ti i ba sa lọ, nitori O jà fun Israẹli.

Ṣe akiyesi pe ki i ṣe pe a le ọta sá kuro loju ogun fun igbà diẹ. Awọn ẹlomiran a wi fun ọta ẹmi wọn pe ‘Agbẹdọ’ (rara o), lẹsẹ kan naa wọn a si tun ni in lọkàn pe ni akoko miiran wọn le ṣe iru nnkan bẹẹ. Nigbà ti a ba pe awọn ọmọde miiran si ibi ti kò tọ, wọn a wi pe ‘Emi ko lọ ni alẹ oni’, itumọ eyi ti i ṣe pe wọn o lọ ni igbà miiran. Ohun ti o n yọrisi ni pe ọta ẹmi wọn yoo maa dán wọn wò nigbà gbogbo. Nipa sisọ pe, “Emi ki i lọ si iru ibi bẹ ẹ” tabi “Emi ki i ṣe iru nnkan bẹẹ” eyi ki yoo fi aye silẹ fun nnkan bẹ ẹ lati tun ṣẹlẹ. Ọlọrun ko pa awọn ọta naa lara lasan; O pa wọn run ni.

Adura

Dajudaju aarẹ mu awọn Ọmọ Israẹli, nitori ni gbogbo oru ni wọn ti fi rin lati Gilgali wá (Joṣua 10:9), wọn si tun jagun nigba ọsan. Sibẹ Joṣua kò gbiyanju lati sùn. Ni oju awọn Ọmọ Israẹli ni o gbadura – nitori eyi jasi adura ju aṣẹ lọ. O fi igboya gbadura pẹlu idaniloju ati igbagbọ. Ni tootọ o dabi adura ti o ṣe ajeji, o ni lati jẹ pe Ọlọrun ni O mi si i lati gba a, nitori a dahun adura naa. Lẹsẹ kan naa ti o gba adura naa ni o si ri bẹẹ. Ọlọrun mu ki ọjọ naa gùn ju bi o ti yẹ lọ titi di igbà ti awọn Ọmọ Israẹli fi “gbẹsan lara awọn ọtá wọn.” Aye duro jẹẹ ninu ayika rẹ, bẹẹ ni oorun si duro jẹẹ ni oju ọrun. Bakan naa ni oṣupa ki o ba le wa ni iṣọkan pẹlu awọn iyokù ni ofurufu. Ilẹ kò ṣú bi awọn Ọmọ Israẹli ti n lepa ti wọn si n pa awọn ọtá wọn.

Ọjọ Ti O Gùn

Oorun ati oṣupa duro jẹẹ fun iwọn ọjọ kan nigbà ti Ọlọrun n jà fun Israẹli. A ti fi idi otitọ nipa ọjọ gigùn yii mulẹ ninu itan awọn orilẹ-ède miiran yatọ si awọn Ju. Awọn olugbe Mexico nigba atijọ ni akọsilẹ ọjọ gigun yii, bakan naa ni awọn olugbe erekusu Okun Guusu, awọn ará Egipti ati China.

Ẹkọ ijinlẹ tootọ (Science) fohùn ṣọkan pẹlu akọsilẹ Bibeli nipa ọjọ ti a fà gùn yii. Awọn ẹlẹkọ ijinlẹ ti aye yii ti o lẹsẹ nilẹ, nipa iwadi wọn nipa oorun ati awọn ẹda oju ọrun, ti fi idi rẹ mulẹ aye yii fi ọjọ kan dín si iye ti o yẹ ki ọjọ rẹ jẹ nipa iṣiro, ọjọ kan ti sọnu ninu akoko. Gẹgẹ bi iṣiro oluwadii irawọ kan ti awọn eniyan kà si ẹni nla, akọsilẹ ti o wà ninu ori kẹwaa Joṣua ati ti Isaiah ori ikejidinlogoji ni o sọ fun ni perepere nipa bi akoko ti o din naa ṣe ri bẹẹ.

Nigba ti ọjọ gigùn naa dopin, oorun ati oṣupa tun bẹrẹ irin-ajo wọn. Ọlọrun ni o dá awọn imọlẹ nla meji yii (Gẹnẹsisi 1:16), dajudaju wọn si gbọran si aṣẹ Rẹ, nitori Ọlọrun ni alakoso gbogbo agbaye. Kò tun si ọjọ kan bi eyi ṣaaju rẹ tabi lẹyin rẹ ti Ọlọrun gbọ ohùn awọn eniyan ni ọna bayii.

Dajudaju ọjọ yii ni agbara nla lori awọn iyoku olugbe ilẹ naa pẹlu. Laaarin awọn Keferi ni awọn kan wà ti wọn n sin awọn ẹda Ọlọrun dipo Ọlọrun Ẹlẹda. Awọn miiran tilẹ n sin oorun ati oṣupa. Iṣẹ iyanu iru eyi ti Ọlọrun ṣe fun awọn Ọmọ Israẹli – fifa ọjọ gùn – yoo fihàn fun awọn olusin oorun ati oṣupa yii pe awọn ọlọrun wọn wà labẹ akoso Ọlọrun Israẹli.

Fifi Ara Pamọ Sinu Ihò

Ni ọna ti a kò le sọ awọn ọba Amori maraarun wọnyii ri ọna sá asala kuro lọwọ yinyin ati idà. Bi o tilẹ jẹ pe wọn sá, wọn si fi ara pamọ ninu ihò, wọn kò sá asala pẹ lọ titi. Jakọbu Apọsteli sọ ninu ọrọ itọni rẹ fun Onigbagbọ, ninu ori kẹrin ẹsẹ ikeje: “Ẹ kọ oju ija si Èṣu, oun ó si sá kuro lọdọ nyin.” Bẹẹ gẹgẹ, nigba ti awọn Ọmọ Israẹli bẹrẹ si i jà, awọn ọba awọn ọta wọn kò duro lati bá wọn jà - wọn sá lọ.

Awọn ẹlomiran i ba ni itẹlọrun lati fi awọn ọba naa silẹ lati sá asala ṣugbọn Joṣua kò ni itẹlọrun titi o fi pa gbongbo wahala naa run. Nigbà ti a sọ fun Joṣua pe awọn ọba maraarun naa fi ara pamọ sinu ihò, o sọ fun awọn eniyan rẹ lati yí okuta nla di ẹnu ọna ihò naa ki wọn si maa ṣọ ọ ki awọn ọba naa ma ba le sá asala.

Iṣẹgun Kikùn

Lẹyin ti ogun naa pari, gbogbo awọn Ọmọ Israẹli pada lai sewu ati ni alaafia (Joṣua 10:21). O daju pe a kò pa ẹnikẹni ninu wọn, ẹnikẹni kò si fi ara pa tabi sọnu laaarin wọn.

Joṣua paṣẹ pe ki wọn mu awọn ọba marun un naa wá lati inu iho naa. Awọn ọgagun awọn ọmọ-ogun si fi ẹsẹ wọn le ọrun awọn ọba awọn ọta wọnyii gẹgẹ bi ami iṣegun patapata; awọn ọtá wà labẹ atẹlẹsẹ wọn. Bẹẹ ni o gbọdọ ṣe si ọta ẹmi rẹ, bi kò ba ri bẹẹ nnkan le yi pada biri iwọ yoo si ba ara rẹ labẹ akoso Satani.

Lati ipo ọla gẹgẹ bi ọba awọn Amori, ni wọn ti wá si ipo ijatilẹ, itiju, ati iku. Iho ti wọn ti gbẹkẹle pada di tubu ati iboji wọn. A kò dá awọn ọba marun un wọnyii si; a so wọn rọ a si sin wọn sinu iho ti o ti jẹ ibi isapamọ si fun wọn.

Kò si ibi isapamọ si kuro niwaju Ọlọrun. O mọ ibi ti olukuluku fi ṣe aabo rẹ kuro lọwọ ibinu Ọlọrun ni idajọ. Awọn miiran ti ni ireti lati ri aabo ninu ọrọ ti wọn ti kó jọ. Awọn miiran a fi gbogbo agbara wọn ṣiṣẹ ki a ba le gbe wọn si ipo ti o dara, ni ireti à ti ri ifẹyinti nipa rẹ. Bẹẹ ni awọn ẹlomiran ti fi ipá wọn tabi ọrẹ wọn ṣe ireti aabo wọn. Gbogbo nnkan wọnyii ni iriri ti fihàn pe a maa já ni tilẹ ni igbà iṣoro. Kò si ọkan ninu awọn nnkan wọnyii ti o le mu wa ri oju-rere lọdọ Ọlọrun. Ohun kan naa gan an ti wọn gbẹkẹle fun aabo, le jẹ ohun ti yoo yà wọn nipá kuro lọdọ Ọlọrun ati Ọrun. Ohun ini ayé yii le jẹ okunfa iku wọn nipa ti ẹmi dipo jijẹ ibi aabo fun wọn. Onigbagbọ le ni ipò daradara, agbara, awọn ọrẹ, tabi ọrọ, ṣugbọn ireti rẹ wa ninu Oluwa. Nibo ni iwọ wà? Ẹjẹ Jesu ha jẹ aabo rẹ, tabi igbẹkẹle rẹ wà ninu ohun ti yoo kuna?

Ọrọ Joṣua si awọn Ọmọ Israẹli i ba le jẹ ikiya nipa ti ẹmi fun awọn eniyan Ọlọrun lonii! “Ẹ má ṣe bẹru, ẹ má si ṣe fòya; ẹ ṣe giri, ki ẹ si mu àiya le: nitoripe bayi li Oluwa yio ṣe si awọn ọtá yin gbogbo ti ẹnyin mbájà”.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti awọn ọba Amori maraarun gbogun ti Gibeoni?
  2. Ki ni ṣe ti Israẹli ni lati jà fun Gibeoni?
  3. Ki ni ṣe ti a fa ọjọ nì gùn?
  4. Bawo ni a ṣe fa ọjọ naa gun?
  5. Ta ni jà fun Israẹli?
  6. Ki ni ṣe ti Ọlọrun rán yinyin?
  7. Ki ni ohun ti o ṣẹlẹ si awọn ọba maraarun?
  8. Dipo ibi aabo ki ni iho naa dà fun wọn?
  9. Ki ni itumọ ọrọ yii: “Fi ọtá sabẹ ẹsẹ rẹ”?