Joṣua 22:1-34

Lesson 176 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Oluwa, emi ti nfẹ ibujoko ile rẹ, ibi agọ ọlá rẹ” (Orin Dafidi 26:8).
Notes

Ni Ila-Oorun Jọrdani

Ni gẹrẹ ki awọn Ọmọ Israẹli to ṣetan lati wọ Kenaani, wọn la ilẹ kan kọja eyi ti o ni koriko ti o dara lọpọlọpọ. Eweko tutu yọyọ ti o n mi sihin mi sọhun naa dara loju awọn ẹya Reubẹni, Gadi, ati aabọ ẹya Manasse; bi wọn si ti ni ohun-ọsin pupọ wọn tọrọ àye lọwọ Mose lati jokoo nibẹ, nihà ila-oorun Jọrdani.

Ayà Mose ati ti awọn eniyan já si ibeere iru eyi. Ẹru ba wọn pe Ọlọrun le jẹ ki idajọ wá sori wọn bi wọn kò ba rin jalẹ gbogbo ọna ti Ọlọrun ti pinnu rẹ fun wọn. Mose rò pe o le jẹ pe wọn n fẹ gbiyanju lati yẹra fun jija awọn ogun ti o ṣi wà niwaju wọn ni Kenaani. Ṣugbọn awọn ẹya Reubẹni ati Gadi ṣeleri pe ni gẹrẹ ti awọn ba ti fi idi awọn ẹbi wọn kalẹ ni ibugbe wọn, awọn ọkunrin ologun wọn yoo rekọja Jọrdani wọn o si ṣe iranwọ lati gba Kenaani.

Ọlọrun wi pe kò buru bi wọn ba ṣe gẹgẹ bi wọn ti pinnu, nitori naa Mose ati awọn eniyan naa gbà fun awọn ẹya meji aabọ naa lati jokoo ni Gileadi. Awọn ọmọ-ogun wọn ba iyoku awọn Ọmọ Israẹli rekọja Jọrdani, ni ẹgbẹkẹgbẹ ni wọn si jọ n jà pẹlu wọn fun ọdun meje titi wọn fi gba ilẹ ti o pọ to eyi ti olukuluku wọn le fi ni ibugbe.

Isimi

Nisisiyii isimi wà ni ilẹ naa. Gbogbo ibẹ wà ni alaafia ati idakẹjẹ. Ọrọ awọn Ọmọ Israẹli si ti pọ to! Wọn ti kó ọpọlọpọ wura ati fadaka ati idẹ ati ẹwù daradara ati ohun-ọsin, Ọlọrun si ti yọọda rẹ fun wọn. Nigba ti Joṣua rán awọn ẹya meji ati aabọ naa pada si ibugbe wọn, o sọ fun wọn pe ki wọn pin ikogun naa pẹlu awọn arakunrin wọn ti wọn duro lẹyin lati bojuto awọn ẹbi ti o wà ni ile. Wọn ni ọpọlọpọ ọrọ lati pín to bẹẹ ti kò ni si ẹni ti yoo ṣe alaini ohunkohun.

Idupẹ

Igbesi-ayé wọn yoo gbadun, ṣugbọn wọn ni lati ranti ohun kan: wọn ko gbọdọ gbagbe lati fi ọlá fun Ọlọriun, ki wọn si dupẹ fun ohun gbogbo ti O ti fi fun wọn. A ti sọ fun wọn tẹlẹ pe wọn ni lati fi Ofin kọ awọn ọmọ wọn, ki wọn si fi ṣe ọrọ sọ lọsan ati loru. Wọn ti ṣe eleyi nigbà ti wọn n fẹ iranwọ Ọlọrun lati ba wọn ja ogun wọn; ṣugbọn nisisiyii ti iṣẹgun ti de wọn ni lati kiyesara lati má ṣe ainaani Ọlọrun ti O ti ṣe wọn ni aṣẹgun.

Nigbà ti a ba n la iṣoro kọja, ti a si ri pe a n fẹ iranwọ gidigidi, a n ri pe a ni lati gbadura. Nigbà naa a maa n ke pe Ọlọrun ninu hila-hilo ọkàn wa titi idahun yoo fi de. A ha n fi iru ọkàn tootọ bẹẹ gbadura nigbà ti iṣẹgun ba de? A ha n ronu lati ba Jesu sọrọ nigba gbogbo gẹgẹ bi igbà ti a n fẹ iranwọ Rẹ? O n fẹ ki a maa yin Oun logo ninu adura, yala a n fẹ iranwọ tabi a kò fẹ. Bi a ko ba si fẹ iranwọ fun ara wa, ọpọlọpọ eniyan miiran wa ti o yẹ ki a gbadura fún.

Pẹpẹ

Odo Jọrdani wà laaarin Kenaani ati ilẹ-ini awọn ẹya meji ati aabọ naa. Nigbà ti awọn ọmọ-ogun ti n pada bọ naa de odo yii, wọn pinnu lati mọ pẹpẹ kan.

Ni akoko yii Ágọ wà ni Ṣilo ni Kenaani. Aṣẹ Ọlọrun ni pe olukuluku ni lati lọ sibẹ lati ru ẹbọ. Nitori ibọriṣa awọn eniyan ti wọn ti ṣẹgun rẹ, a ti paṣẹ lile fun awọn Ọmọ Israẹli pe wọn kò gbọdọ mọ pẹpẹ nibomiran fun irubọ.

Laipẹ iroyin de ọdọ awọn Ọmọ Israẹli pe awọn ẹya Reubeni ati Gadi n mọ pẹpẹ nihà keji Jọrdani. Ki ni a le mọ eyi si? I ha ṣe pe wọn ti tete gbagbe Ọlọrun otitọ bẹẹ? Bi Ọlọrun ba jẹ ki idajọ bọ sori gbogbo wọn fun aigbọran yii n kọ?

Awọn Ọmọ Israẹli kò ara wọn jọ siwaju Agọ, wọn si ipinnu lati doju ija kọ awọn arakunrin wọn ti awọn ro pe wọn jẹ ọlọtẹ. Ṣugbọn wọn kọkọ rán awọn aṣoju kan lọ lati wadii boya ni tootọ ni wọn mọ pẹpẹ naa. A rán olori kan lati inu ẹya kọọkan lati bá Finehasi, ọmọ Eleasari, olori alufaa lọ.

Ẹsùn Naa

Nigbà ti wọn de ọdọ awọn ẹya Reubeni, Gadi ati Manasse, wọn wi pe: “Ẹṣẹ kili eyiti ẹnyin da si Ọlọrun Israẹli, lati pada li oni kuro lẹhin OLUWA, li eyiti ẹnyin mọ pẹpẹ kan fun ara nyin, ki ẹnyin ki o le ṣọtẹ si OLUWA li oni?”

Finehasi rán wọn leti idajọ ti o wá sori Israẹli ni akoko ti wọn bẹrẹ si sin awọn oriṣa Moabu. Ajakalẹ-arun kan wá saarin wọn gẹgẹ bi idajọ, ninu awọn eniyan naa si n jiya rẹ lọwọlọwọ paapaa. Awọn ẹya meji aabọ wọnyii ha tun fẹ ṣe nnkan miiran ti o le mu ki iyà wọn tubọ pọ si i?

Alufaa ati awọn olori naa tẹ siwaju lati sọ fun wọn pe bi o ba jẹ pe wọn kò le gbe ni Moabu lai jẹ pe wọn sin awọn ọlọrun ajeji, ki wọn kuku goke lọ si Kenaani, ki wọn si maa ba awọn Ọmọ Israẹli iyoku gbé.

Idahun

Awọn eniyan naa tẹti si gbogbo ẹsun wọnyii, boya o yà wọn lẹnu lọpọlọpọ. Ki i ṣe pe wọn fẹ ṣọtẹ si Ọlọrun. Wọn wi pe: “OLUWA, Ọlọrun awọn ọlọrun, OLUWA Ọlọrun awọn ọlọrun, On mọ, Israẹli pẹlu yio si mọ; bi o ba ṣepe ni iṣọtẹ ni, tabi ni irekọja si OLUWA, … ni awa fi mọ pẹpẹ fun ara wa.” Jẹ ki Ọlọrun jẹ onidajọ rẹ boya n ṣe ni wọn n ṣe aigbọran tabi bẹẹ kọ. Bi o ba ṣe pe wọn n ṣe aigbọran si Ọlọrun ni, Oun yoo fihàn nipa pipa wọn run; awọn paapaa ṣetan lati gba idajọ naa sori ara wọn. Ṣugbọn bi wọn ba wa laaye, gbogbo eniyan ni yoo mọ pe ki i ṣe pẹlu ero ibi ni wọn fi mọ pẹpẹ naa.

Àlàyé

Wọn ri pe ọna awọn jìn si Agọ, o si hàn gbangba pe wọn kò gbero lati kó awọn ọmọ wẹẹrẹ wọn lọ sibẹ; nitori bẹẹ awọn ọmọ wọn kò ni mọ bi pẹpẹ Ọlọrun naa ti ri. Nipa mimọ pẹpẹ yii ni iri eyi ti o wà ninu Agọ, awọn ọmọ wọn le ri i funra wọn bi pẹpẹ naa ti ri, wọn kò si ni gbagbe nipa bi a ti n sin Ọlọrun otitọ.

Lẹyin naa, pẹlu, awọn Ọmọ Israẹli ni Kenaani le gbagbe nipa awọn ibatan wọn ti o wà ni Gileadi, nigba ti wọn ba si la ilẹ naa kọja wọn le ro pe ilẹ Keferi ni. Bi wọn ba ri pẹpẹ kan ti a mọ gẹgẹ bi iru eyi ti o wà ni Ṣilo, wọn o mọ pe awọn eniyan wọnyii pẹlu ni lati mọ Ọlọrun otitọ.

Awọn ọmọ Reubeni ati Gadi ṣe ileri pe lae, awọn kò ni ṣe irubọ lori pẹpẹ ti awọn ti mọ. Nigbà ti awọn alufaa pẹlu awọn olori gbọ alaye wọnyii, wọn woye pe awọn arakunrin wọn kò dẹṣẹ. Nigba ti wọn si mu iroyin pada wá fun awọn Ọmọ Israẹli ni Kenaani, inu awọn naa dùn pẹlu.

“Awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi si sọ pẹpẹ na ni Edi: nwọn wipe, Nitori ẹrí ni li agbedemeji awa ati ẹnyin pe OLUWA on li Ọlọrun.”

Bi o tilẹ jẹ pe ni akoko yii awọn eniyan naa kò dẹṣẹ si Oluwa, a ri pe ni ọjọ iwaju awọn ni a kọkọ kó lọ si oko-ẹru. Jijinna ti wọn jinna bayii si ibi ijọsin tootọ mu ki o rọrun fun wọn lati gbagbe Ọlọrun. A le ri ẹkọ kọ nipasẹ eyi pe o ṣanfaani pupọ fun wa pe ki a wa nitosi awọn Onigbagbọ miiran ki a ba le ba wọn jọsin ki a si sọ nipa ohun ti i ṣe ti Ọlọrun. Ṣugbọn bi o ba di ọranyan fun wa ni ọna jijin si ile Ọlọrun, O le fun wa ni agbara lati jẹ oloootọ. Ṣugbọn bi o ba ṣe pe nipa aibikita tabi ilepa imọ-ti-ara-ẹni-nikan ni a ṣe lọ jinna, a wà ninu ewu sisọ ifẹ Ọlọrun nù kuro ninu ọkàn wa.

“Alabukún-fun li ẹniti iwọ yàn, ti iwọ si mu lati ma sunmọ ọdọ rẹ, ki o le ma gbe inu agbala rẹ wọnni: ore inu ile rẹ yio tẹ wa lọrùn, ani ti tẹmpili mimọ rẹ” (Orin Dafidi 65:4).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Awọn ẹya wo ni o ti duro ni apa keji Jọrdani?
  2. Ki ni ṣe?
  3. Ki ni wọn ṣeleri lati ṣe nigbà ti awọn idile wọn ti ni ibujoko?
  4. O ti pẹ to ti awọn ọkunrin ologun ti ẹya meji ati aabọ naa fi wà ni Kenaani?
  5. Ki ni wọn ṣe ni bebe odo Jọrdani nigba ti wọn pada de?
  6. Ki ni awọn Ọmọ Israẹli ṣe nigba ti wọn gbọ nipa mimọ pẹpẹ naa?
  7. Alaye wo ni awọn ẹya meji ati aabọ naa ṣe?
  8. Ta ni awọn Ọmọ Israẹli gbọdọ sin? Nibo?
  9. Ta ni awa n sin? Bawo?