Joṣua 14:6-15; 19:49, 50; 21:43-45; 23:1-16

Lesson 177 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ohunkohun kò tase ninu ohun rere ti OLUWA ti sọ fun ile Israẹli; gbogbo rẹ li o ṣẹ” (Joṣua 21:45).
Notes

Pipin Ilẹ Naa

Akoko naa de ti a pin ilẹ awọn Ọmọ Israẹli fun wọn ni Kenaani. Ọlọrun ti paṣẹ pe ki a fi kèké pin ilẹ naa fun awọn ẹya mẹsan ati aabọ si ilẹ ileri (Joṣua 13:7, 8; Numeri 34:13-15). A ti kọ ẹkọ (Ẹkọ 112, Iwe 9) gẹgẹ bi awọn ẹya Reubeni, Gadi ati aabọ ẹya Manasse ti beere aye fun awọn ẹbi wọn lati duro ni ihà ila-oorun Jọrdani ti wọn si ṣe bẹẹ kuna lati gba ilẹ rere ti Ọlọrun ti pese silẹ fun wọn. Ẹya Lefi (awọn ọmọ Lefi ati awọn alufaa) kò ni ilẹ-ini ni Kenaani (Joṣua 13:14), nitori Ọlọrun ni ipin wọn (Deuteronomi 18:1-5).

Kalebu

A ti yan Kalebu lati jẹ aṣoju fun ẹya Juda nigbà ti wọn n pin ilẹ naa (Numeri 34:19). Lati fihàn pe wọn ni inu-didun si ibeere rẹ, ẹya Juda lati inu eyi ti Kalebu ti wá ba a lọ gẹgẹ bi ẹlẹri si ọdọ Joṣua. Ibeere Kalebu ki i ṣe eyi ti kò tọ. Ilẹ ti Ọlọrun ti ṣe ileri fun un ni ini ni o n beere. O rán Joṣua leti akoko naa, ọdun marunlelogoji sẹyin, nigbà ti a rán awọn ami lọ si ilẹ Kenaani. Bi o tilẹ jẹ pe mẹwaa ninu awọn ami naa mu ihin buburu wá Kalebu wi nigbà naa pe: “Ẹ jẹ ki a gòke lọ lẹẹkan, ki a si gbà a; nitoripe awa le ṣẹ ẹ” (Numeri 13:30). Kalebu kò sọrọ bayii lati tẹ Mose lọrun, tabi lati mọọmọ sọ ohun kan ti o lodi si ọrọ awọn ami iyoku – lati inu ọkàn rẹ li o ti sọ ọrọ naa, nitori ó gbẹkẹle Ọlọrun.

Awọn ami naa sọ nipa awọn ọmọ Anaki ti i ṣe omiran (Numeri 13:33), ati nipa awọn ilu ti a fi odi nla yi ká (Numeri 13:28) ti wọn ti ri ni ilẹ Kenaani. Ọlọrun ti wi pe a o fun Kalebu ni ilẹ yii gan an nitori o “tẹle Oluwa lẹhin patapata” (Deuteronomi 1:36).

Ohun ti o wa ninu ọkàn Kalebu ni lati fi ogo fun Ọlọrun. O sọ ẹri oore Ọlọrun si i – pe Ọlọrun ti pa oun mọ laaye laaarin ewu ati aarẹ ninu aginju nigbà ti ọpọlọpọ ti kú. Dajudaju ilẹ awọn omiran ati awọn ilu olodi ni o ṣoro ju lọ lati ṣẹgun. Ṣugbọn Kalebu beere fun ilẹ naa fun ini rẹ nitori o ka ileri Ọlọrun si ohun ti o ṣe iyebiye; o mọ agbara Ọlọrun o si gbẹkẹle e. O mọ pe oun yoo le awọn ọta wọnni jade bi Ọlọrun ba wà pẹlu rẹ. Kalebu ko gbẹkẹle agbara ti rẹ lati fi ṣẹgun bẹẹ ni kò tilẹ gbẹkẹle agbara gbogbo Israẹli. Igbẹkẹle rẹ wà ninu Ọlọrun Ẹni ti o ti fun un ni agbara nipa ti ara to bẹẹ ti o fi ni ipá lati jagun sibẹ lẹyin ọdun marunlelogoji ti a ti ṣe ileri fun un.

Joṣua sure fun Kalebu o si fi ilẹ-ini naa eyi ti Ọlọrun ti ṣeleri fun un – “òke” naa nibi ti ilu Hebroni gbe wa. Lẹyin eyi, nigbà ti ilu Hebroni di ti awọn alufaa ti o si di ọkan ninu awọn ilu aabo (Joṣua 21:9-13), Kalebu ni itẹlọrun pẹlu ilẹ ti o yi ilu naa ka. O ti beere fun imuṣẹ ileri Ọlọrun wọn si ti gba ilẹ naa, awọn eniyan naa si simi kuro lọwọ ogun.

Ọkàn Ti O Yatọ

Ki ni ohun ti o ṣẹlẹ si awọn ami iyoku, awọn mẹwaa ti o mu ihin buburu wá? Wọn kú nipa arun, awọn ti o tẹti si wọn ko wọ Ilẹ Ileri. Ni tootọ laaarin gbogbo awọn eniyan naa kiki Kalebu ati Joṣua ni o wọ Kenaani lati gba ileri Ọlọrun. Ọlọrun wi pe, “Ṣugbọn Kalebu iranṣẹ mi, nitoriti o ni ọkàn miran ninu rẹ, ti o si tẹle mi mọtimọti, on li emi o múlọ sinu ilẹ na nibiti o ti rè” (Numeri 14:24). Kalebu ni “ọkàn miran” – ki i ṣe eyi ti o n tan ihin buburu kalẹ. Nigbà miiran awọn ọmọde a maa mu ihin tọ awọn obi wọn tabi awọn ọdọ miiran nipa Ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi ati ti Isin Awọn Ọdọ eyi ti o le ba ọkàn jẹ; o si le jẹ ihin ti ọkàn miiran ti o gbẹkẹle Ọlọrun ti o si tọ Ọ lẹyin patapata. Ihin ti eniyan ba mu lọ fun awọn ẹlomiran le ṣiṣẹ ninu wọn to bẹẹ ti wọn o fi le gba ogún ti Ọlọrun pese silẹ fun wọn, tabi ki wọn ma le de àyè ti wọn fi le gba ileri Ọlọrun.

Ileri Ti A Mu Ṣẹ

Ileri Ọlọrun fun Joṣua pe oun ni “yio mu Israẹli ní” Ilẹ Kenaaani (Deuteronomi 1:38) ni a muṣẹ pẹlu. Lẹyin ti a ti pin ilẹ naa tán, awọn Ọmọ Israẹli fun Joṣua ni ilu kan ninu ilẹ awọn ẹya ti rẹ, ẹya Efraimu. Bi o tilẹ jẹ pe Joṣua ni aṣaaju wọn ti o si ti jẹ oloootọ gẹgẹ bi ami pẹlu Kalebu, ki i ṣe oun ni o kọkọ yan ilẹ ti o wu u. Iṣẹ rẹ kin-in-ni ni si orilẹ-ède rẹ; lẹyin eyi ni o to wa rò nipa ti ara rẹ. Joṣua kò ya ilu kan sọtọ fun ilo ara rẹ, ṣugbọn a fun un ni ini rẹ “gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA” (Joṣua 19:50).

Olukuluku eniyan ni o le ri ẹkọ kọ lara apẹẹrẹ Joṣua yii. Kò si ẹni ti o ti i padanu rí nipa ṣiṣe alai-mọ-ti-ara-rẹ-nikan, ṣugbọn ọpọlọpọ ni o n padanu ibukun ti ẹmi ati ti ara pẹlu nipa gbigbájúmọ ohun ti ara wọn ṣiwaju ti awọn ẹlomiran. Ninu odiwọn fun igbesi-aye Onigbagbọ ni aimọ-ti-ara-ẹni-nikan wà. Paulu kọ nipa rẹ ninu iwe rẹ si awọn ara Romu nibi ti o gbe fun ni ni apẹẹrẹ igbesi-aye Onigbagbọ. “Niti ifẹ ará, ẹ mã fi iyọnu fẹran ara nyin: niti ọlá, ẹ mã fi ẹnikeji nyin ṣaju” (Romu 12:10).

Ki i ṣe fun Joṣua ati Kalebu nikan ni Ọlọrun mu ileri Rẹ ṣẹ. Ọkan ṣoṣo ko kuna ninu gbogbo ohun rere ti Ọlọrun ti ṣeleri fun awọn Ọmọ Israẹli. Ọlọrun fun wọn ni iṣẹgun lori awọn ọta wọn (Joṣua 21:44) nitori O ti ṣeleri lati lé awọn ara Kenaani jade diẹdiẹ (Ẹksodu 23:30). Ọlọrun fi isinmi fun awọn Ọmọ Israẹli – isinmi kuro ninu aarẹ irin-ajo, isinmi lọwọ ogun, isinmi lọwọ iwọsi lati ọdọ awọn ọta wọn - gẹgẹ bi O ti ṣeleri. Gbogbo ileri naa ni o ṣẹ. Ki i ṣe diẹ ninu wọn, tabi awọn ti o tobi ju, tabi awọn ti o kere ti o si rọrun, ṣugbọn gbogbo rẹ ni o ṣẹ (1 Awọn Ọba 8:56).

Ìní Rẹ

Bi gbogbo ileri Ọlọrun ba ṣẹ, ki ni ṣe ti gbogbo awọn ti o jade ni Egipti kò wọ Kenaani? Nitori wọn ṣe aigbọran; wọn kò gbẹkẹ wọn le Ọlọrun, wọn si ba adehùn wọn pẹlu Rẹ jẹ. Ẹbi awọn eniyan naa ni, nitori Ọlọrun a maa pa ipa ti Rẹ mọ ninu majẹmu.

Ki ni ṣe ti gbogbo eniyan lonii kò ni ini ti ẹmi ti Ọlọrun ti ṣeleri? Ọwọ awọn eniyan ni ikuna wà. Ninu 2 Peteru 1:3, 4, a ka pe Ọlọrun “ti fi awọn ileri rẹ ti tobi pupọ ti o si ṣe iyebiye fun wa” pe eniyan le gbé igbesi-aye iwa-bi-Ọlọrun lai lọ sinu awọn ẹṣẹ ayé yii. Gẹgẹ bi awọn Ọmọ Israẹli, iwọ paapaa (ọmọkunrin ati ọmọbinrin ati agba pẹlu), le ni iṣẹgun lori ọta ẹmi rẹ: o le ni isinmi ati alaafia, ki o si gbé igbesi-ayé rẹ lọna ti iwọ yoo fi ni ini ni Ọrun. Gbogbo nnkan rere wọnyii le jẹ ti rẹ nipa kika ileri Ọlọrun si, nipa gbigba Ọlọrun gbọ ati gbigbẹkẹle E, nipa titẹlẹ E pẹlu gbogbo ọkàn ti o yatọ si ti aye. O le gbà ileri Ọlọrun nipa igbọran.

Ọrọ Idagbere Joṣua

Ọdun diẹ si i lẹyin eyi Joṣua pe awọn agbaagba ati awọn aṣoju awọn eniyan naa. O sọ ọrọ idagbere fun wọn nitori akoko iku rẹ fẹrẹ to. Joṣua ti di arugbo o si kun fun iriri – o ti to ẹni aadọfa (110) ọdun (Joṣua 24:29). Joṣua n fẹ lati sọ ọrọ iṣiri fun awọn Ọmọ Israẹli lati jẹ oloootọ si Ọlọrun ki wọn si fi otitọ ọkàn sin In. Kò rán awọn Ọmọ Israẹli leti ohun ti oun ṣe tabi eyi ti wọn ṣe. O sọ pe “Ẹnyin si ti ri ohun gbogbo ti OLUWA Ọlọrun nyin ti ṣe.” Ọlọrun ti ṣe amọna wọn, O ti bọ wọn, O ti pa wọn mọ, O ti jà fun wọn. Ki i ṣe bẹẹ nikan, Ọlọrun ṣetan lati tun ṣe bẹẹ gẹgẹ fun wọn ni ọjọ iwaju awọn nnkan ti O ti ṣe fun wọn kọja niwọn igba ti awọn Ọmọ Israẹli ba di Oluwa mú ninu igbọran. Bi wọn kò ba ya si ọtun tabi si osi, Ọlọrun yoo jà fun wọn, ẹnikan ninu wọn yoo “lé ẹgbẹrun” awọn ọtá wọn.

Ọrọ ti Joṣua sọ fun wọn kún fun ikilọ ati iṣiri. A tun kilọ fun awọn Ọmọ Israẹli nipa ibọriṣa ki wọn má tilẹ bu ọlá kankan fun oriṣa. Bi wọn ba kiyesara wọn, wọn ki yoo pada sẹyin sinu aijolootọ. A kilọ fun wọn ki wọn ma ba tipasẹ didá awọn ará Kenaani sí kọ Ọlọrun silẹ diẹ diẹ. Ohun ti yoo ṣẹlẹ ni pe wọn bẹrẹ si ba wọn kẹgbẹ, lẹyin eyi wọn o di ọrẹ, wọn a si maa ṣe igbeyawo pẹlu awọn ti o lodi si Ọlọrun ati isin otitọ. Nigba naa ni awọn Ọmọ Israẹli yoo ri i pe awọn ti ba adehùn wọn ati majẹmu wọn pẹlu Ọlọrun jẹ.

Ninu ẹsẹ mẹta ọtọtọ ni Joṣua ti sọ fun awọn Ọmọ Israẹli pe a o pa wọn run, wọn a si ṣegbe kuro ni ilẹ rere naa a fi bi wọn ba tẹle Oluwa sibẹ ati Ofin Rẹ. Nigbà ti wọn ba ṣẹ si Ol

uwa, nigba naa ni ileri Ọlọrun fun idajọ ati iparun yoo ṣẹ gẹgẹ bi awọn ohun rere ti Ọlọrun ti ṣeleri ki yoo ṣe kuna.
Questions
AWỌN IBEERE
  1. Gẹgẹ bi amí, iroyin wo ni Joṣua ati Kalebu mu wa fun awọn Ọmọ Israẹli?
  2. Iroyin wo ni awọn ami mẹwaa iyoku mu wá?
  3. Ki ni abajade iroyin naa?
  4. Ki ni ṣe ti Kalebu n fẹ ilẹ awọn omiran ati awọn ilu olodi?
  5. Ki ni ṣe ti a fun Kalebu ni ipin ni Kenaani?
  6. Bawo ni a ṣe mu ileri Ọlọrun fun Joṣua ṣẹ?
  7. Ki ni ohun ti o ṣẹlẹ si awọn amí mẹwaa iyoku?
  8. Meloo ni o kunà ninu gbogbo ileri Ọlọrun fun Israẹli?
  9. Ki ni ṣe ti Joṣua fi kilọ fun awọn Ọmọ Israẹli nipa ibọriṣa?
  10. Bawo ni awọn Ọmọ Israẹli ṣe le wà ninu ibukun Oluwa titi?