Luku 16:1-31

Lesson 179 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹnyin kò le sin Ọlọrun pẹlu mammoni” (Luku 16:13).
Notes

Iriju

Ninu apa kin-in-ni ẹkọ yii Jesu bá awọn ọmọ-ẹyin Rẹ sọrọ pẹlu owe. O jẹ nipa iriju alaiṣotọ kan ti o fi ohun-ini oluwa rẹ ṣòfò. Iriju jẹ ẹni kan ti a fi ṣọ iṣẹ ẹlomiran - ẹni ti a fi ọkàn tán lati maa bojuto ọran ti ki i ṣe ti rẹ.

Jesu kọ ni ninu awọn owe miiran pe gbogbo eniyan jẹ iriju, awọn ti Ọlọrun fi ṣọ awọn ohun ti wọn ni, pẹlu ẹmi wọn ati talẹnti wọn, ati awọn iṣura wọn iyoku. Ọjọ n bọ nigbà ti olukuluku wa “yio jihin ara rẹ fun Ọlọrun” (Romu 14:12).

Alaiṣootọ iriju ti Jesu fi pa owe yii ti fi ohun-ini oluwa rẹ ṣofò. A kò sọ fun ni ọna ti a gba fi wọn ṣofò, yala a ji wọn lọ ni, a lò wọn ni ilokulo ni, tabi n ṣe ni a ba wọn jẹ ti a si jẹ ki wọn ṣegbe nipa aibikata. Akoko to nigba ti a beere pe ki o ṣiro iṣẹ iriju rẹ.

Njẹ bi a ba pe ọ lonii lati ṣiro iṣẹ igbesi-aye rẹ, a o ha ba ọ gẹgẹ bi alaiṣootọ iriju bi? Iwọ ha lo igbesi-aye rẹ lati fi ogo ati iyin fun Ọlọrun nipa pe o wà laaye fun Un? Tabi ẹṣẹ ti ba a jẹ, o si ṣegbe nipa lilo o fun igbadun ati anfaani ara rẹ nikan, ti o si n fi iwa aikiyesara gbagbe Ọlọrun.

Oluwa iriju naa yin in nitori o huwa ọlọgbọn, ki i ṣe nitori o ṣe ohun ti kò tọ. Bi a ba le alaiṣotọ iriju naa kuro yoo di alaini. Boya kò ti ronu nipa rẹ tẹlẹ ri, ṣugbọn o wa ronu ohun ti oun yoo ṣe. O sọ pe, “Emi kò le walẹ: lati ṣagbe oju ntì mi”. Lai ṣe aniani ohun ti o wà lọkàn rẹ ni pe oun kò fẹ, ki i ṣe pe oun kò le. A ko kà pe o yarọ tabi pe o darugbo. Boya n ṣe ni o ya ọlẹ ti ilẹ wiwa kò si mọ ọn lara, ti o gberaga pupọ ti kò fi le ṣagbe.

Ọpọ eniyan wà ti ọkàn wọn wà ni ipò aini. Wọn ko ni bẹbẹ fun aanu. Mimọọṣe wọn ati laalaa ayé yii kò ni le tẹ wọn lọrun, bẹẹ ni ki yoo le gba ọkàn wọn là lae.

Hihuwa Ọlọgbọn

Nipa wiwa ojú rere awọn ajigbese naa, nigbà ti a ba le e kuro, iriju alaiṣootọ yii reti lati ri àyè fun ara rẹ ninu ilé wọn. Bi o tilẹ jẹ pe o ro pe akoko ti pẹ fun oun bayii, o ronu ọjọ iwaju, ninu iwa rẹ o si ṣe ohun ti o wà ni ipá rẹ ninu ipò yii. O ṣe adehùn pẹlu awọn ajigbese naa lori iye-owo ti o kere pupọ si iye ti wọn jẹ - lati ri ojú rere fun ara rẹ lọdọ awọn ajigbese naa.

Ọrọ Tootọ

Ọlọrun n fẹ ki ilepa ohun ti ẹmi maa gba awọn eniyan Rẹ lọkàn kan gẹgẹ bi ohun ti ara ti i maa gba ọkàn awọn ọmọ aye yii kan.

Awọn miiran a maa kó ilọsiwaju wọn nipa ti ara lọkàn pupọ pupọ, ani nigbà ti wọn tilẹ wà ni ọdọmọde ironu wọn a maa jẹ lati pese silẹ fun akojọ ohun ti isisiyii. Nipa owe yii Ọlọrun n fẹ sọ fun wa lati din apọnle ọrọ aye yii kù, ọrọ ti n fò lọ, ki a si kuku fi ọkàn wa fun oore-ọfẹ ati ogo Ọlọrun siwaju si i.

Eniyan kò le sin oluwa meji - Ọlọrun ati Satani - pọ ni akoko kan naa. Nipa sisin Ọlọrun eniyan le ni ọrọ tootọ. “Ọrọ ati ọlá mbẹ lọwọ mi, ani ọrọ daradara ati ododo” (Owe 8:18). Fun awọn ti wọn jẹ “ọlọrọ ni igbagbọ” Ọlọrun ti ṣeleri pe awọn ni yio jẹ “ajogun ijọba na” (Jakọbu 2:5). Ẹ jẹ ki a gbẹkẹle “Ọlọrun alãye, ti nfi ohun gbogbo fun wa lọpọlọpọ lati lo”; ẹ jẹ ki a “mã pọ ni iṣẹ rere”, ki a maa to iṣura ipilẹ rere jọ fun ara wa dè igba ti n bọ, ki a le di iye ainipẹkun mu (1 Timoteu 6:17-19).

Awọn Alariwisi

Awọn kan laaarin awọn Farisi gbọ Jesu n pa owe yii nipa alaiṣootọ iriju, wọn si bẹrẹ si fi Jesu ṣẹsin. Ninu ọkàn wọn, wọn dá ara wọn lare. Wọn lepa awọn nnkan ti o mú ki eniyan pọn wọn le dipo ki wọn maa ṣafẹri awọn nnkan ti Ọlọrun. Nigbà naa ni Jesu wá kọ wọn ni owe kan nipa nipa ayé ti n bọ. Irú igbesi-ayé ti eniyan ba gbe ni yoo fihàn ibi ti yoo ti lo ayérayé. Jesu fi opin igbesi-ayé awọn ọkunrin meji hàn awọn afini-ṣẹsin wọnyii ati ohun ti o ṣẹlẹ si wọn lẹyin ti wọn fi ayé yii silẹ. Jesu sọ eyi gẹgẹ bi ohun ti o ṣẹlẹ gan an ki i ṣe bi owe.

Ọkunrin Meji

Ọkunrin ọlọrọ kan, orukọ ẹni ti a kò sọ, ti fi aṣọ olowo-iyebiye ti o dara ṣe ara rẹ lọṣọ. O ti pese ohunkohun ti ero ati ifẹ ọkàn rẹ n fẹ ti owo rẹ si le ra, fun ara rẹ. A le wi pe o fi ara rẹ fun ohun ti ara rẹ gbadun – igbesi-aye gbẹfẹ ati igbadun, ti o si jẹ iparun fun ọkàn rẹ. A kò sọ fun ni bi o ti ni ọrọ rẹ; boya nipa ọnà ti o tọ ni.

Ki i ṣe ohun ti o lodi lati ni ounjẹ daradara, aṣọ daradara ati ọrọ; ṣugbọn nigbà pupọ ni o lewu lati ni ọrọ. Nigbà pupọ awọn eniyan maa n di agberaga ti wọn si n gbagbé Ọlọrun.

A maa n gbé Lasaru jokoo ni ẹnu-ọna ilé ọkunrin ọlọrọ naa. Oun jẹ alagbe, otoṣi ati olupọnju. Ẹrún ti o gbọn lati ori tabili ọkunrin ọlọrọ naa i ba tẹ ẹ lọrun. O fẹ ki a fun oun jẹ, ṣugbọn a ko sọ fun ni pe o ri iranwọ tabi ibakẹdun lati ọdọ ọkunrin ọlọrọ naa. Wahala ọkunrin alagbe yii ni lati ju ebi lọ, nitori ara rẹ kun fun ooju. Awọn aja ṣoore fun un ju ọkunrin ọlọrọ naa lọ, nitori wọn la ooju Lasaru, boya ni ibakẹdun ati imunilọrẹ.

A fiyesi pé ọkunrin ọlọrọ naa kò bú Lasaru bẹẹ ni kò sọ pe ki o má dubulẹ lẹba ẹnu-ọna rẹ. O ṣe aibikita, boya o maa n kọja lara Lasaru lai sọ ọrọ aanu tabi ibakẹdun kan si i.

Ikú

Nigbà ti o ṣe awọn ọkunrin mejeji kú, nitori ikú wà fun gbogbo eniyan, ọlọrọ ati talaka bakan naa. “A si ti fi lelẹ fun gbogbo enia lati kú lẹẹkanṣoṣo, ṣugbọn lẹhin eyi idajọ” (Heberu 9:27).

A kò le fi bi eniyan ṣe ri nipa ìrí ojú mọ àyè ti irú ẹni bẹẹ wà nipa ti ẹmi. Bi o ti ṣe e ṣe fun eniyan lati jẹ ọlọrọ ki o si jẹ olododo, bẹẹ ni o ṣe e ṣe fun eniyan lati jẹ talaka, olupọnju ati alainaani Ọlọrun. A gbé Lasaru lọ si ookan-aya Abrahamu nitori o jẹ olododo eniyan, ki i ṣe nitori o jẹ alaisan ati talaka.

Lẹyin Ikú

A sin ọkunrin ọlọrọ naa, boya pẹlu isinkú ti o larinrin. Fi ọlá ati ayọ Lasaru wé oró ti ọkunrin ọlọrọ yii n jẹ, ọkunrin ti o kuna lati bá Ọlọrun laja.

Ọkunrin ọlọrọ naa gbadura - ṣugbọn o pẹ jù. Ni ipo-oku, nigbà ti o n fara da ibanujẹ ati iṣẹ ti o pọ rekọja o ri itura Lasaru. Ọkunrin ọlọrọ naa ri pe ọrun apaadi wà nitootọ. Ki i ṣe pe o sùn. O wà ninu iyè rẹ, ọpọlọ rẹ si jí perepere. O le ri Lasaru, eyi ti, lai ṣe aniani, o fi kún iṣẹ-oró rẹ. O mọ pe iná n jó oun, oun ko si run. O le gbọ ohùn Abrahamu; o si ranti awọn nnkan ti oun ti n jẹ igbadun rẹ rí.

Ninu Ìṣẹ-oró

Ninu arodun rẹ ọkunrin ọlọrọ yii kigbe pe Abrahamu. Ọkunrin yii ti kò fi aanu hàn, bẹbẹ pe ki a rán Lasaru, ẹni ti oun ti fi iwa ailaanu ṣe aibikita fún, lati fi aanu hàn fun oun. Ọkunrin ọlọrọ naa kò bẹbẹ pe ki a da oun silẹ. Fun itura diẹ kinun ni o bẹbẹ. Ibeere rẹ kò pọ, - ki Lasaru fi ika rẹ bọmi lati fi tu oun ni ahọn. Oun kò tilẹ ni ki wọn fun oun ni omi mu – iba pe ki Lasaru sa fi ika rẹ bọmi lati tu ahọn oun. Irora pupọ ni fun eniyan lati maa joró ninu ọwọ iná, a si maa mu ipọnju ti o pọ rekọja wa fun ara.

Ìyà ti ọkunrin ọlọrọ naa jẹ ju irora lọ, nitori Abrahamu wi fun un pe ki o “ranti”. Boya o ronu itura ati irọra ilé rẹ nibi ti o ti n paṣe fun awọn ẹlomiran. Nisisiyii o n bẹbẹ fun itura. Boya o ranti pẹlu abamọ iye igba ti oun i ba ti ṣe aanu fun Lasaru.

A sọ fun ọkunrin ọlọrọ naa pe ibeere rẹ kò ṣe e ṣe. Kò si ibeere ti a n dahùn rẹ ni ọrun apaadi. Ẹṣẹ rẹ ti yà á kuro lọdọ Ọlọrun titi ayeraye (Isaiah 59:2). Ki a tilẹ wi pe Lasaru fẹ lati ran an lọwọ, ko ni le ṣe e ṣe nitori ọgbun nlá kan wà lagbedemeji wọn.

Ọkunrin ọlọrọ pa gbogbo ireti fun ara rẹ tì, ṣugbọn o tún ṣe ibeere miiran. O n ro ti awọn ibatan rẹ. Lai si aniani, kò ṣe nnkan kan ninu ayé lati ran wọn lọwọ nipa ti ẹmi. Nisisiyii o n fẹ ki wọn mú gbogbo anfaani ti wọn ni lò, nigbà ti wọn ṣi wa laaye ti wọn si le bá Ọlọrun laja. Niwọn igbà ti ẹmi wà, anfaani ṣi n bẹ lati sá fun iru opin ti ọkunrin ọlọrọ yii ni. Lẹyin iku, a kò le ṣe ohunkohun mọ. “Bi igi ba si wó siha gusu tabi siha ariwa, nibiti igi na gbe ṣubu si, nibẹ ni yio si ma gbe” (Oniwasu 11:3).

O Pẹ Jù

Ọkunrin ọlọrọ naa mọ Lasaru o si pe e ni orukọ, o si mọ pe awọn arakunrin oun yoo da Lasaru mọ. O ro pe dajudaju awọn arakunrin oun yoo ronupiwada ti Lasaru ba jinde kuro ninu oku. Boya Lasaru ti sọ ẹri rẹ fun wọn ki o to kú, bi kò tilẹ ṣe nipa ọrọ ẹnu ṣugbọn nipa igbesi-aye rẹ. A sọ fun ọkunrin ọlọrọ pe Bibeli a maa sọ fun awọn eniyan bi wọn ṣe le ri igbala, ki wọn si bọ lọwọ iyà bi wọn ba gba ohun ti awọn wolii kọ silẹ gbọ. Bi ẹni kan kò ba gba Bibeli gbọ oun kò ni gbagbọ bi ẹni kan tilẹ ti inu oku dide. O pẹ ju ki ọkunrin ọlọrọ naa to ronu ipo rẹ ati ti awọn arakunrin rẹ.

Jesu kọ wa ni ẹkọ yii lati fi ere ti o wà hàn fun awọn ti wọn n sin Ọlọrun, ati iṣẹ-oró ti n duro de ẹni ti n sin mammoni.Bawo ni igbesi-aye rẹ ti ri? Gẹgẹ bi Lasaru, eniyan le ṣai fi igba gbogbo ni gbogbo nnkan ti aye yii lati mu ki o wà ni irọrun; ṣugbọn nipa ironupiwada ati ijolootọ ninu sinsin Ọlọrun, o le ni ayọ nihin ki o si bọ lọwọ iṣẹ-oró igba ti n bọ. “Ibaṣepe nwọn gbọn, ki oye eyi ki o yé wọn, nwọn iba rò igbẹhin wọn!” (Deuteronomi 32:29).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti iriju naa fi jẹ alaiṣootọ?
  2. Bawo ni iwọ ṣe jẹ gẹgẹ bi iriju?
  3. Ki ni ṣe ti a fi yin iriju naa?
  4. Bawo ni Lasaru ati ọkunrin ọlọrọ ṣe yatọ si ara wọn ninu ayé?
  5. Bawo ni wọn ṣe yatọ lẹyin ikú?
  6. Ki ni fa iyatọ yii?
  7. Bawo ni eniyan ṣe le bọ ninu ìṣẹ-oró ti ọkunrin ọlọrọ naa jiya rẹ?
  8. Ki ni ṣe ti ọkunrin ọlọrọ naa kò ri itura diẹ gbà?