Lesson 180 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “O yẹ ki a mã gbadura nigbagbogbo, ki a má si ṣarẹ” (Luku 18:1).Notes
Alaiṣootọ Onidajọ
Jesu tun pa owe miiran lati fi kọ awọn ọmọ-ẹyin Rẹ bi adura ti niyelori to. Owe jẹ itan nipa ohun ti aye eyi ti o n kọ ni ẹkọ nipa ohun ti ẹmi.
Owe yii jẹ nipa ọkunrin kan ti o jẹ onidajọ. O jẹ iṣẹ oojọ rẹ ati ojuṣe rẹ lati gbọ ẹdun awọn eniyan. Oun ki i ṣe onidajọ rere ati oloootọ. Oun kò bẹru Ọlọrun bẹẹ ni kò si ṣe ojusaaju eniyan bi ti rẹ.
Opó Kan
Ni ilu kan naa ni opó kan ti a n jẹ niya wà. O dabi ẹni pé ohun ti o ṣe deedee pẹlu ofin, ti o si tọnà fun un lati ṣe ni lati lọ ba onidajọ naa fun iranwọ. O wi pe ki a gba oun lọwọ aninilara oun. O wi pe ki a fi iyà jẹ ẹni ti o ti n yọ oun lẹnu lainidi. Ki i ṣe pe o n fẹ fi oro san oro tabi fibi san ibi fun ẹni ti o huwa aitọ si i.
Onidajọ naa kọ lati ran opo yii lọwọ. A kò sọ fun ni pe o ṣe alaye kankan fun un nipa eredi rẹ ti o fi kọ. Oun jẹ alaiṣootọ onidajọ ti kò bikita fun ojuṣe rẹ si opó naa. Kò si ṣu si i lati ràn án lọwọ “nigba ọsa kan”.
Wíwá NigbakuugbaỌpọlọpọ ni o maa n sú bi a ba kọ fun wọn lẹẹkan. Obirin opó naa kò mẹnu kuro nigbà ti igbiyanju kan kunà. O mọ pe bi o ba wu onidajọ naa o le ran oun lọwọ. A kò sọ fun ni iye igbà ti o pada sọdọ onidajọ naa pẹlu ibeere rẹ. O pè é ni “wiwa rẹ nigbakugba”, nitori naa o ni lati lọ ba a leralera.
Bẹẹ ni a kò sọ fun ni pẹlu iṣoro ti o ni ki o to ri idahun si ibeere rẹ gbà. O ṣe e ṣe ki o jẹ pe ọna jijin ni o ti n wá ti o si ni lati la aarin ilu kọja ki o to le de ọdọ onidajọ naa. Boya o padanu akoko iṣẹ rẹ ki o ba le mu ẹdun rẹ wa siwaju rẹ.
Opo yii kò jẹ ki irẹwẹsi tabi iṣoro kó aarẹ ba oun. Nikẹyin, onidajọ naa mu ibeere rẹ ṣẹ pe ki a gbẹsan rẹ lara ọta rẹ. O ro o ninu ọkàn rẹ pe obinrin naa yoo fi wiwa rẹ nigbakuugba dá oun lagara ti oun kò ba mu ibeere rẹ ṣẹ.
Adura
Jesu fi owe yii kọ ni lẹkọọ ki awọn ọmọ-ẹyin Rẹ ba le mọ riri adura. Ẹkọ yii wa fun gbogbo eniyan, ṣugbọn Jesu fi apẹẹrẹ naa hàn ni pataki fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ.
Ni ìgbà wahala ati idanwo eniyan le gbadura bi bẹẹ kọ yoo “ṣãrẹ” (eyi ni kí ó ju ọgọ silẹ, sọ ireti nú, tabi din itara rẹ kù). Ohunkohun ti o wu ki a ṣe alaini, a le maa gbadura nigba gbogbo; nigba gbogbo ni adura yoo ṣe iranwọ.
Nigba ti Jesu wi pe “nigbagbogbo” ki i ṣe pe O fẹ ki eniyan maa fi igba gbogbo wà lori eekun rẹ ninu adura. Ninu 1 Tẹssalonika 5:17, a tún ka pe “Ẹ mã gbadura li aisimi.” Ko le ṣe e ṣe fun ẹnikan lati dá nikan wà ninu adura ni gbogbo ìgbà; sibẹ o le mi èémí adura lati inu ọkàn rẹ nibi ti o wu ki o lọ ati ohun ti o wu ki o maa ṣe. Onigbagbọ a maa gbadura gẹgẹ bi obirin opó ti o lọ sọdọ onidajọ naa – a maa wá nigbakuugba.
Onigbagbọ ni lati gbadura ki o le gbé ọràn naa siwaju Oluwa. Jesu wi pe o yẹ ki a maa gbadura nigba gbogbo. O yẹ ki a maa gbadura! Anfaani ni, ojuṣe si ni pẹlu. Gbigbadura jẹ ohun ti o “yẹ” ki a maa ṣe – nigbà gbogbo, ki i ṣe ni akoko wahala tabi aini nikan. Ninu 1 Kronika 16:11 a ka ọrọ Dafidi si awọn Ọmọ Israẹli: “Ẹ ma wá Oluwa, ati ipa rẹ, ma wá oju rẹ nigbagbogbo.” Ni akoko miiran Jesu wi pe, “Ẹ mã ṣọna, ki ẹ si mã gbadura, ki ẹnyin ki o má ba bọ sinu idẹwò” (Matteu 26:41). Ni akoko miiran, ẹwẹ, Jesu wi pe “ẹ bère … ki ayọ nyin ki o le kún” (Johannu 16:24).
Awiiyannu
Leke ẹkọ nipa niniyelori adura, a fun ni ni apẹẹrẹ iru adura kan. A pe obinrin yii li alawiiyannu opo. Lati wi awiiyannu ju gbigbadura lọ. A pe e ni alawiiyannu nitori kò jẹ dakẹ. O sa n lọ titi a fi mu ibeere rẹ ṣẹ; o sa n lọ ni, titi onidajọ naa fi ro pe yoo dá oun lagara. Obinrin opo naa wi awiiyannu titi o fi ri ohun ti o n beere gbà.
I ba ṣe pe opó naa duro lẹyin ìgbà kin-in-ni, a ki ba ti gbẹsan rẹ lara ọtà rẹ. Bi o ba ṣe pe o kunà lati maa lọ sọdọ onidajọ naa ohun ti o n fun un ni wahala ki ba ti fi i silẹ lae. Bi kò ba jẹ pe o ti wi awiiyannu ni, oun ki ba ti ri ohun ti o n beere ti o ṣe alaini – ohun ti o si jẹ ẹtọ rẹ gbà.
Ohun ti o ṣe e ṣe fun awọn eniyan Ọlọrun ni lati wi awiiyannu ninu adura titi wọn o fi ri ohun ti Ọlọrun ti ṣe ileri, ti o si jẹ ẹtọ wọn gbà. Awọn nnkan kan wà, bi iriri igbala, isọdimimọ ati agbara Ẹmi Mimọ, ti wọn jẹ ifẹ Ọlọrun ti wọn si jẹ gẹgẹ bi Ọrọ Rẹ. Eniyan le ṣafẹri ki o si gbadura gẹgẹ bi opo naa ti ṣe – ki o si ri idahun nipa awiiyannu. Awọn ọmọde le gbadura lati maa jẹ aṣẹgun ki wọn má si “ṣãrẹ” ki wọn si jọgọ silẹ fun ọta. Ọlọrun n reti pe ki awọn ọmọde ati agba maa gbadura nigba gbogbo titi wọn o fi ri ibukun naa gbà lọwọ Oluwa.
Elijah
Apẹẹrẹ miiran ninu Bibeli nipa ọkunrin kan ti o gbadura nigba gbogbo ti o si wi awiiyannu ni Elijah. A kà pe o gbadura pe ki o ma ṣe si ojo tabi iri lori ilẹ (1 Awọn Ọba 17:1), o si ri bẹẹ fun ọdun mẹta ati aabọ (Jakọbu 5:17). Lẹyin naa Ọlọrun sọ fun Elijah pe oun yoo rọ ojo bi Elijah yoo ba lọ fi ara rẹ hàn fun Ahabu (1 Awọn Ọba 18:1). Elijah gbọran, o si gbagbọ pe Ọlọrun yoo mu ileri Rẹ ṣẹ. Elijah sọ fun Ahabu pe ojo yoo rọ (1 Awọn Ọba 18:41). O di ileri Ọlọrun mu bi o tilẹ jẹ pe igba meje ni iranṣẹ rẹ lọ wò boya ami ojo hàn. Elijah wi awiiyannu – “ojo pupọ si rọ” (1 Awọn Ọba 18:45).
Ileri Ọlọrun
Jesu pari owe naa nipa sisọ pe Ọlọrun yoo gbẹsan awọn eniyan Rẹ kánkán. Alaiṣootọ onidajọ ni obinrin naa tọ lọ: ninu adura awa maa n lọ sọdọ Ọlọrun oloootọ. Lai ṣe aniani, alejo ni obinrin naa jẹ; ọmọ Rẹ ni awa ti a ti gbala i ṣe (Johannu 1:12; 1 Johannu 3:1). Oun nikan ṣoṣo ni o dá ibeere rẹ beere: awa gẹgẹ bi eniyan Ọlọrun, maa n kó ara wa jọ lati gbadura. “Bi ẹni meji ninu nyin ba fi ohùn ṣọkan li aiye yi niti ohunkohun ti nwọn o bère; a o ṣe e fun wọn lati ọdọ Baba mi ti mbẹ li ọrun wá. Nitori nibiti ẹni meji tabi mẹta ba kò ara wọn jọ li orukọ mi, nibẹ li emi o wà li ãrin wọn” (Matteu 18:19, 20).
Ọlọrun yoo mu ipa ti Rẹ ṣẹ. A le fi ọkàn tán An. Oun ha le fi ọkàn tán ọ lati ni igbagbọ bi o tilẹ jẹ pe O le ri i pe o ṣanfaani lati fawọ ileri Rẹ sẹyin fun igba diẹ? Nigba ti Jesu ba tun pada wa si aye, igbagbọ ni Oun yoo wò. O ha ni in ninu ọkàn rẹ? “Njẹ ki ẹ mã ṣọna, ki ẹ si mã gbadura nigbagbogbo, ki ẹ ba le … duro niwaju Ọmọ-enia” (Luku 21:36).
Questions
AWỌN IBEERE- Irú onidajọ wo ni opó naa tọ lọ?
- Ki ni ṣe ti opó naa tọ ọ lọ?
- Ki ni ṣe ti kò dẹkun lati maa lọ bá onidajọ naa?
- Ki ni o ri gbà nipa lilọ sọdọ rẹ leralera?
- Ki ni ṣe ti onidajọ naa fi gbẹsan rẹ lara ọtà rẹ?
- Ki ni awọn eniyan le ṣe lonii dipo ki wọn sọ ireti nù?
- Bawo ni wọn ṣe le wi awiiyannu?
- Ki ni ṣe ti awọn eniyan Ọlọrun fi gbọdọ maa gbadura?