Luku 18:9-14

Lesson 181 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Oluwa fi ãnu rẹ hàn fun wa, ki o si fun wa ni igbala rẹ” (Orin Dafidi 85:7).
Notes

Owe

Nigba pupọ ni Jesu maa n fi owe ba awọn eniyan sọrọ. Owe jẹ ìtàn ti o n ṣe alaye ohun ti ẹmi ni ọnà ti yoo fi rọrun fun awọn eniyan lati ni òye nipa rẹ.

Ni ọjọ kan Jesu wà laaarin agbajọ awọn eniyan kan ti wọn rò pe awọn jẹ eniyan rere ti n tẹle Ọlọrun nitori wọn maa n ṣe iṣẹ oore lọpọlọpọ. Wọn kò i ti bẹ Ọlọrun pé ki O dari ẹṣẹ wọn ji wọn ki wọn ba le ri igbala ki wọn si le mura silẹ fun ìyè ainipẹkun; ṣugbọn wọn ni idaniloju pe inú Oluwa yoo dùn lati gbà wọn si Ọrun nitori wọn n san owó sinu àpò ijọ, wọn si n gbadura gigun nigbà ti wọn ba duro ni ikorita ọnà nibi ti awọn eniyan ti le ri bi wọn ti jẹ ẹlẹsin to. Wọn ni awọn ọjọ ti wọn ki i jẹun rara. Eyi ni aawẹ, wọn si ro pé yoo sọ wọn di olododo.

Ju Meji Ni ọnà Tẹmpili

Jesu fẹ lati kọ awọn eniyan wọnyii ti O n ba sọrọ pé yoo gbà wọn lati ni ohun ti o ju ododo ti ara wọn lati ṣe wọn yẹ fun Ọrun. Nitori bẹẹ, O sọ ìtàn fun wọn nipa ọkunrin meji ti wọn lọ si Tẹmpili lati gbadura.

Boya ojú awọn ọkunrin meji wọnni jọra pupọ. Ju ni awọn mejeeji jẹ, o si le jẹ pé irú aṣọ kan naa gan an ni wọn wọ. Ṣugbọn bi wọn ti gbadura ti yatọ to!

Ọkunrin kan jẹ Farisi. Eyi ni pe kò fi ọwọ yẹpẹrẹ mú ẹsìn rẹ. O ti kọ nipa Ofin Mose ati gbogbo ofin atọwọdọwọ ti awọn alufaa fi lelẹ lati ọwọ ìran kan dé omiran. Ewu ti o wà nibẹ ni pé o ti fi ọkàn fun ofin atọwọdọwọ yii ju fun Ofin lọ. Ofin wi pe ki o fẹran ẹni keji rẹ gẹgẹ bi ara rẹ, ṣugbọn kò ni pẹ ki a to ri bi Farisi yii ti fẹran ọkunrin ti o ba a lọ si Tẹmpili lati gbadura tó.

Agbowo-ode

Awọn agbowo-ode jẹ Ju ti ijọba Romu gbà si iṣẹ pẹlu owó ọya lati maa gba owo ori lọwọ awọn ọlọtọ Ju. A kò san owó pupọ fun wọn. Ki wọn le ri owó si i fun ara wọn ki wọn si di ọlọrọ, wọn bu àbùlé owó fun awọn ẹni ti n san owó orí naa. Dajudaju a korira wọn nitori wọn ṣe bẹẹ.

Agbowo-ode yii ti a n kẹkọọ nipa rẹ ri i ni ọjọ kan pe iwà oun kò dara. Ọkàn rẹ ni lati maa dá a lẹbi nitori lati maa gba owó ni ọnà ti o n gba yii jẹ ìwà olè gidi. Ofin si wi pé, “Iwọ kò gbọdọ jale.” Nitori bẹẹ o lọ si Tẹmpili lati bẹ Ọlọrun lati dariji i fun riru Ofin naa.

Ẹṣẹ Farisi Naa

Ki ni ṣe ti Farisi naa lọ si Tẹmpili? I ha ṣe pé lati inú ọkàn otitọ ni o ti fẹ ba Ọlọrun sọrọ? Bẹẹ kọ. ọrọ naa sọ fun ni pe o “ngbadura ninu ara rẹ bayi.” O ka ara rẹ si eniyan pataki. Sa wo ọkunrin ẹlẹsin yii bi o ti duro nibẹ! “Ọlọrun, mo dupẹ lọwọ rẹ, nitoriti emi kò ri bi awọn ara iyokù … emi kò tilẹ ri bi agbowode yi,” ẹni ti n gba owo ti ki i ṣe ti rẹ. Lootọ ni agbowo-ode naa ti rú Ofin ṣugbọn nipa kikorira agbowo-ode naa Farisi naa n rú u pẹlu. Ṣugbọn oun kò tilẹ tọrọ idariji.

Nigbà naa ni Farisi naa wa ka bi oun ti dara to: “Emi ngbàwẹ li ẹrinmeji li ọsẹ, mo nsan idamẹwa ohun gbogbo ti mo ni.” O dara bẹẹ, ṣugbọn eyi kò tó. Ni akoko miiran nigba ti awọn Farisi n sọ fun Jesu nipa iṣẹ rere wọn, O wi pe: “Wọnyi li ẹnyin iba ṣe, ẹ kì ba si ti fi ekeji silẹ laiṣe” (Luku 11:42). Ki ni wọn fi silẹ lai ṣe? Wọn kò fẹran awọn alaini, bẹẹ ni wọn kò ran awọn opo lọwọ. Wọn kò laanu. Wọn kò si fẹran Ọlọrun ju ara wọn lọ.

Farisi yii kò beere ohunkohun lọwọ Ọlọrun. O ro pe ohun gbogbo ti oun n fẹ ni oun ti ni. O kàn fẹ fi iwa rere rẹ ti ode ara wu Ọlọrun, ati awọn eniyan ti wọn ri i bi o ti n gbadura. Jesu ṣapejuwe irú eniyan bayii nigbà ti O wi pe, “Ẹnyin dabi iboji funfun, ti o dara li ode, ṣugbọn ninu nwọn kún fun egungun okú, ati fun ẹgbin gbogbo” (Matteu 23:27). Ọlọrun le wò inu rẹ taara ki O si ri i pe oun kò dara rara to bi oun ti fi ara hàn lode.

Adura Agbowo-ode

Ẹ jẹ ki a tẹti si adura agbowo-ode naa nisisiyii. N ṣe ni o dá duro, ni ibi kọrọ nitori o mọ pé Farisi naa kò fẹran oun. O mọ pé oun gbọdọ ni iranwọ Ọlọrun, o si n gbadura ni ọnà ti oun yoo fi ri i gbà.

Agbowo-ode naa kẹdun fun ohun ti o ti ṣe, ojú si ti i to bẹẹ ti kò jẹ gboju soke si Ọlọrun. O mọ pé mimọ ni Ọlọrun, oun si jẹ alainilaari ẹlẹṣẹ. Ọlọrun yii ti O dá awọn ọrun ati ayé pẹlu ohun gbogbo ti o wà ninu wọn, n jẹ yoo bojuwo oṣi oun, ki O si ran oun lọwọ? Njẹ yoo ha tẹti si adura ẹlẹṣẹ ti n wariri yii?

Adura naa kuru, ṣugbọn o wá lati odò irobinujẹ ọkàn rẹ: “Ọlọrun ṣãnu fun mi, emi ẹlẹṣẹ.” O mọ pe oun jẹ ẹlẹṣẹ, ṣugbọn kò fẹ jẹ bẹẹ. Ah! aanu Ọlọrun Ẹni ti O boju wolẹ bayii lati dahun igbe naa fun aanu.

Irẹlẹ

Eniyan ni lati rẹ ara rẹ silẹ ki o to le jẹwọ ẹṣẹ rẹ; ohun iyebiye ni irẹlẹ si jẹ lojú Oluwa. Ni akoko kan nigbà ti Dafidi jọba ni Israẹli, o dá ẹṣẹ kan ti o buru jai. Ṣugbọn bi o tilẹ jẹ ọba ni, o rẹ ara rẹ silẹ o si jẹwọ pé: “Iwọ, iwọ nikanṣoṣo ni mo ṣẹ si.” O bẹbẹ pe, “Ọlọrun, ṣãnu fun mi, gẹgẹ bi iṣeun ifẹ rẹ” (Orin Dafidi 51:1). Kò si ohun ti a le ṣe ti o le mu wa tọ si idariji. Kiki aanu Ọlọrun ati Ẹjẹ Jesu ni o le kó ẹṣẹ wa lọ.

“Ko s’ohun ti mo mu wa,

Mọ rọ mọ agbelebu.”

Awọn Ileri Fun Ẹni ti o bá Ronupiwada

Awọn ileri wà fun awọn ti o bá ronupiwada ninu eyi ti boya agbowo-ode naa ti kà tabi ki o ti gbọ. ọkan ninu wọn ni “Jẹ ki enia buburu kọ ọna rẹ silẹ, ki ẹlẹṣẹ si kọ ironu rẹ silẹ: si jẹ ki o yipada si Oluwa, on o si ṣãnu fun u, ati si Ọlọrun wa, yio si fi jì lọpọlọpọ” (Isaiah 55:7). Nigbà tí ó gbadura pe, “Ọlọrun ṣãnu fun mi, emi ẹlẹṣẹ”, ó gbagbọ pé Ọlọrun yoo dariji oun.

O ṣe e ṣe ki o ti ka Orin Dafidi yii: “Oluwa mbẹ leti ọdọ awọn ti iṣe onirobinujẹ ọkàn: o si gbà iru awọn ti iṣẹ onirora ọkàn là” (Orin Dafidi 34:18).

Kò ṣẹṣẹ gbà ki a maa ro o lọ titi lati mọ èwo ninu awọn ọkunrin mejeeji yii ni o gba ibukun ti o pọ jù lọdọ Oluwa fun wíwá ti wọn wá si Tẹmpili. Dajudaju agbowo-ode ni. Jesu wi pe, “Ọkọnrin yi sọkalẹ lọ si ile rẹ ni idalare jù ekeji lọ.” Ọlọrun ti gbọ adura rẹ, O ti dari ẹṣẹ rẹ jì, oun si ti di ọmọ Ọlọrun.

Farisi naa n kọ? O wa ni ipo ẹlẹṣẹ ti o gbadura “ninu ara rẹ.” Kò beere nnkan kan lọwọ Ọlọrun, bẹẹ ni kò si ri ohunkohun gbà. Gbogbo ikorira rẹ fun agbowo-ode naa wà sibẹ. Boya o n san idamẹwa rẹ lọ o si n gba adura gigun bakan naa, ṣugbọn Ọlọrun kò pe e ni ọmọ Rẹ.

Ọlọrun n fẹ ki a fi gbogbo ọkàn wa sin Oun. Nigbà ti a ba n gbadura, a ni lati jọwọ ifẹ inú wa fun Un ki ọrọ wa si ti inú ọkàn wá. A si ni lati gbe igbesi-ayé ti yoo fi hàn pé tọkantọkan ni a fi sọ ọ.

Iyipada Ninu Adura Paulu

Paulu Apọsteli, ti a n pè ni Saulu ara Tarsu tẹlẹ, ti jẹ Farisi olufọkansi kan tẹlẹ rí. Lai ṣe aniani o ti gba ọpọlọpọ adura gigun ṣugbọn a ko mẹnu ba wọn ninu Bibeli. Ni ọjọ kan ni ọnà Damasku, a lu u bolẹ, Ọmọ Ọlọrun si pe e wa si ironupiwada. Lẹyin ti Paulu ti lọ si ile Juda, Ọlọrun wi fun Anania lati lọ bẹ ẹ wò, nitori “sá wo o, o ngbadura” (Iṣẹ Awọn Apọsteli 9:11). Ki ni iyatọ ti o wà laaarin adura yii ati gbogbo adura gigun ti o ti n gbà tẹlẹ rí? Adura rẹ atijọ kò ni ṣai dabi irú ti Farisi ti o gbadura “ninu ara rẹ”. Nisisiyii Paulu n ronupiwada o si n ké pe Ọlọrun fun aanu - Ọlọrun si gbọ O si dari ẹṣẹ rẹ ji, o si wa di akọni eniyan Ọlọrun.

Ẹbọ Awọn Ọmọ Israẹli

Ọlọrun ti sọ fun awọn Ọmọ Israẹli lati ṣe irubọ ninu isin Agọ wọn lati fihàn wọn pe Messia, eyi nì ni Ọdọ-Agutan Ọlọrun, yoo wá ni ọjọ kan lati fi ara Rẹ ṣe Ẹbọ nlá nlà eyi ti yoo wẹ ẹṣẹ wọn nù. Pẹlu ẹbọ wọn, ohun ti o yẹ ki wọn ṣe ni lati gbadura lati inu ọkàn wọn wá, ki wọn si gba Ẹni ti n bọ wa gbọ. Ṣugbọn ni igbà pupọ wọn kò gba adura atọkanwa. Wọn pa awọn ẹran, wọn si se ase pataki fun igbadun ara wọn. Ni igba kan ninu itan igbesi-aye wọn, Ọlọrun dá wọn niji nipa kikigbe tako wọn: “Emi kún fun ọrẹ sisun agbò, ati fun ọrá ẹran abọpa; bẹẹni emi kò si ni inu didùn si ẹjẹ akọ malũ, tabi si ti ọdọ-agutan, tabi si ti obúkọ … Oṣù titun nyin ati ajọ idasilẹ nyin, ọkàn mi korira; … Nigbati ẹnyin ba gbà adura pupọ, emi ki yio gbọ” (Isaiah 1:11-15).

Ṣugbọn adura kekere nì lati inu ọkàn irobinujẹ, “Ọlọrun ṣãnu fun mi, emi ẹlẹṣẹ” ni Ọlọrun maa n gbọ ti O si n dahùn. Olukuluku eniyan ni o le ri igbala ti o bá gba adura naa. Bi o ba gbagbọ pe Ọlọrun ti dariji oun, yoo sọkalẹ “lọ si ile rẹ ni idalare.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta ni lọ si Tẹmpili lati lọ gbadura?
  2. Bawo ni Farisi nì ṣe gbadura?
  3. Darukọ ofin kan ti o rú bi o ti duro nibẹ.
  4. Bawo ni Jesu ti ṣe apejuwe Farisi naa?
  5. Awọn wo ni agbowo-ode?
  6. Bawo ni agbowo-ode yii ṣe ka ara rẹ si nigbà ti o lọ gbadura?
  7. Adura ti ta ni Ọlọrun dahun, nitori ki ni?
  8. Ki ni ṣẹlẹ si ọkunrin ti a dahun adura rẹ?
  9. Irú adura wo ni o maa n mú idahùn wá lati ọdọ Ọlọrun?
  10. Ki ni eniyan gbọdọ ṣe lati ri igbala?