Matteu 20:1 – 16

Lesson 183 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Nitorina ẹ lọ, ẹ ma kọ orilẹ-ède gbogbo, ki ẹ si ma baptisi wọn li orukọ Baba ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmi Mimọ: ki ẹ ma kọ wọn lati ma kiyesi ohun gbogbo, ohunkohun ti mo ti pa li aṣẹ fun nyin: ẹ si kiyesi i, emi wà pẹlu nyin nigbagbogbo, titi o fi de opin aiye” (Matteu 28:19, 20).
Cross References

I Baale Ile Gba Awọn Alagbaṣe si Iṣẹ

1. A ṣe adehun owo ọya ojoojumọ pẹlu awọn ti a gbà siṣẹ ni kutukutu owurọ, Matteu 20:1, 2

2. A ṣe ileri owo ọya ti o tọ fun awọn ẹgbẹ keji ti a gbà ṣiṣẹ ni wakati kẹta ọjọ, Matteu 20:3, 4

3. A ṣe ileri kan naa fun ẹgbẹ kẹta ati ẹgbẹ kẹrin ti a gbà sisẹ, Matteu 20:5

4. Ileri iye owo kan naa ni o wà fun awọn ẹgbẹ karun un ti a gbà siṣẹ ni wakati kọkanla ọjọ, Matteu 20:6, 7

II A San Owo-Ọya ni Opin-Ọjọ Naa

1. A paṣẹ fun iriju lati san owo idẹ kọọkan fun gbogbo awọn alagbaṣe, bẹrẹ lati ọdọ awọn ti a gbà siṣẹ kẹyin, Matteu 20:8, 9; 19:30; 21:31; Luku 13:30

2. Awọn ẹgbẹ kin-in-ni kùn nitori wọn kò gbà ju iye owo kan naa lọ pẹlu awọn ti o ṣe iṣẹ wakati kan pere, Matteu 20:10-12

3. Ọlọrun ki i ṣiro iṣẹ wa gẹgẹ bi eniyan ti i ṣiro, Matteu 20:13-15; 1 Kọrinti 4:2

4. Awọn iranṣẹ ti o gba ere gẹgẹ bi eto Ọlọrun gba ẹtọ fun didara iṣẹ naa, ki i ṣe fun bi iṣẹ ti pọ tó, Matteu 20:16; Ifihan 2:10

Notes
ALAYE

Ọgba Ajara Ọlọrun ati Oko Ikore Rẹ

Ninu awọn ọrọ bi-owe bi-owe ti Ọlọrun fifun ni ninu Bibeli lati ṣe apejuwe awọn otitọ ti o jinlẹ ninu Iwe Mimọ ni awọn iṣẹlẹ daradara ti a n ri ninu ọdun kan yipo: bi ikore ọka ati kiko eso oko jọ sinu abà. A fun wa ni apejuwe wọnyii lati kọ wa nipa ikore aye, nigba ti eso iyebiye ti aye yii - awọn ẹni irapada lati ayeraye - yoo di ẹni ti a mu re Ile wọn ayeraye.

Ọlọrun ti ba wa sọrọ nipa jijẹ oloootọ ati gbigbọran si aṣẹ Rẹ, nipasẹ owe awọn ọmọkunrin meji ti a sọ fun pe ki wọn lọ ṣiṣẹ ninu ọgba ajara baba wọn. Ọkan ninu wọn sọ pe ohun yoo lọ, ṣugbọn kò lọ; eyi ekeji sọ pe ohun ki yoo lọ, ṣugbọn o lọ.

Ọlọrun ti sọ fun wa nipa idajọ ikẹyin ti o n bọ wa sori awọn ẹni ti o kọ Jesu Kristi, Ọmọ Rẹ, ninu owe baale le ti o fi ọgba ajara rẹ ṣe agbatọju fun awọn oluṣọgba. Awọn oluṣọgba wọnyii kọ lati fun awọn iranṣẹ baale ile naa ni eso ti o tọ si i: nigba ti o si rán ọmọ rẹ kan ṣoṣo ti i ṣe arole rẹ, lati gba eso rẹ, wọn pa á.

Nibi pupọ ninu Iwe Mimọ ni Ọlọrun gbe tọka si iṣẹ itankalẹ Ihinrere gẹgẹbi iṣẹ ikore ninu oko (Matteu 9:37; Luku 10:2; Johannu 4:35, 36; Galatia 6:9). Ninu ẹkọ yii, O kọ wa ni otitọ iyebiye kan nipa fifi awọn ọkunrin ti a gba ni alagbaṣe lati ṣiṣẹ ninu oko ṣe apejuwe, ati bi a ti sanwo ọya fun wọn ni opin ọjọ gẹgẹ bi adehun ti a ba wọn ṣe nigba ti wọn bẹrẹ iṣẹ ninu oko. A le ri i pe owe yii n sọ nipa iṣẹ itankalẹ Ihinrere ni akoko Majẹmu Titun yii.

Iṣẹ Ẹmi Mimọ ninu Aye

Ni akoko Majẹmu Laelae, Ọlọrun fi ọgba ajara Rẹ ṣe agbaṣe fun orilẹ-ède Israẹli. O fi Majẹmu so wọn pọ mọ ara Rẹ ki wọn le jẹ orilẹ-ède mimọ, eniyan ọtọ, at ijọba alufaa -- iranṣẹ Majẹmu Ayeraye lati waasu Ihinrere fun gbogbo agbaye (Ẹksodu 19:3-6; Deuteronomi 5:2, 3). A ti ri i bi wọn ti kuna ipe wọn patapata, ti wọn fa sẹyin, ti wọn si ba Majẹmu ti Ọlọrun ba wọn dá jẹ; ni opin rẹ wọn pa Ọmọ Ọlọrun kan ṣoṣo ti a rán si wọn. Ni akoko Majẹmu Titun yii Ẹmi Mimọ tikara Rẹ ni o n ṣe ọpọlọpọ “iṣẹ ninu ọgba ajara”, nitori Oun ni o n fi oye ye araye “niti ẹṣẹ, ati niti ododo ati niti idajọ.”

Ṣugbọn a kò gbọdọ ro pe Ẹmi Mimọ ṣẹṣẹ bẹrẹ iṣẹ ṣiṣe ninu aye fun igba akọkọ ni, nitori nigba ti Ọlọrun ri i pe iwa buburu eniyan pọ ni akoko Noa, O wi pe, “Ẹmi mi ki yio fi igba-gbogbo ba eniyan jà” (Gẹnẹsisi 6:3). Nipa eyi a le ri i pe Ẹmi Mimọ ti n rọ awọn eniyan, O n fi oye ye wọn niti ẹṣẹ, O si n du u lati mu wọn wa si ironupiwada. Onisaamu pẹlu mọ riri Ẹmi Mimọ ati ibi ti yoo ba a ti a ba gba Ẹmi Mimọ lọwọ rẹ, nitori ti o wi pe, “Máṣe ṣa mi ti kuro niwaju rẹ; ki o má si ṣe gbà Ẹmi Mimọ rẹ lọwọ mi” (Orin Dafidi 51:11). Ẹmi Ọlọrun naa ni o bá Israẹli lò, ti o n kọ wọn, ti o si n du u lati tọ wọn si ọna pipe Ọlọrun; Ẹmi Ọlọrun naa si ni wọn n mú binu nigba ti wọn ṣọtẹ ti wọn si ya si ọna ti ara wọn (Nehemiah 9:20: Isaiah 63:10, 11).

A le sọ lọna kan pe, ni igba Majẹmu Titun, Ẹmi Mimọ ni olukọni lati mu wa wa sọdọ Kristi. Ni igba Majẹmu Laelae, a fi ofin fun awọn Ju gẹgẹ bi olukọni lati mu wọn wa sọdọ Kristi, ki wọn le mu aye to kún fun awọn ẹlẹṣẹ yii wá sọdọ Rẹ. Ni iwọn iba diẹ Ofin ti a fi fun ni ni Oke Sinai n ṣiṣẹ yii sibẹ, nitori nipasẹ rẹ ni ọpọlọpọ eniyan fi mọ pe wọn ni lati ni igbala ati idande Kristi. Ṣugbọn ni tootọ a ti mu ofin ṣẹ patapata ninu Kristi ati wíwá Rẹ ninu ara: awọn irubọ ti ofin bere ni a si mu ṣẹ nipa iku Kristi, aṣẹ ati ilana ofin ni a si ti mu ṣẹ ninu igbesi-aye Kristi ati awọn ẹkọ Rẹ.

Awa ti o wa ni Igba Ihinrere yii ni anfaani lati gba Ẹmi Mimọ ẹkunrẹrẹ ju awọn eniyan mimọ ti igba Majẹmu Laelae lọ. Nitori eyi a le ri i pe ki i ṣe pe Ẹmi Mimọ tikara Rẹ n lọ kaakiri aye yii nikan lati fi oye ẹṣẹ ati iwa buburu awọn ọmọ eniyan ye wọn lọna ti o ga ti o fi n ṣiṣe lonii, ṣugbọn o tun ranṣẹ si aye ẹṣẹ yii nipasẹ awọn onigbagbọ ti o gba A sinu ọkan wọn ni ẹkunrẹrẹ -- awọn ti a ti fi Ẹmi Mimọ baptisti. Ẹmi Mimọ ati Iyawo Ọdọ-Agutan ni awọn onṣẹ ti Ọlọrun n lo lati nawọ ipè Rẹ si awọn ẹlẹṣẹ lonii (Ifihan 22:17).

Iṣẹ Onigbagbọ ninu Ayé

Nitori naa a le ri pe iṣẹ Ẹmi Mimọ pọ gidigidi ninu ibalo Ọlọrun pẹlu eniyan ni akoko yii, otitọ yii si fi ara han ninu ọrọ ti Jesu sọ, pe, Ẹmi Mimọ ki yoo sọkalẹ titi Oun yoo fi goke re Ọrun. Ẹmi Mimọ sọkalẹ ni ọjọ kẹwaa lẹyin igoke-re-Ọrun Jesu, a si fi wọ awọn ọmọ-ẹyin ti wọn wa ni yara oke ni Jerusalemu. A si n lati fi ọpẹ fun Ọlọrun pe O n ṣe bakan naa lonii.

A le ri i pe ni Igba Laelae, “Bãle ile” -- Ọlọrun Baba – fi ọgba ajara ṣe agbaṣe fun awọn ẹlomiran; ṣugbọn nigba Majẹmu Titun yii, a le ri pe Oun ati Jesu Kristi Ọmọ Rẹ, nipasẹ Ẹmi Mimọ, n fi iṣẹ jijere ọkàn sinu Ijọba Rẹ le ọwọ awọn ti wọn n du u lati jẹ ọmọ Ijọ ti a kò foju ri – Iyawo Ọdọ-Agutan. Ọpọlọpọ ni o wà lai ri ṣe lonii, Ọlọrun si n pe iru awọn ẹni bẹẹ. O n rọ wọn lati wá ṣiṣẹ ninu ọgba ajara Rẹ bi O ti n fi ye wọn pe akoko kuru ati pe awọn alagbaṣe ko to nnkan. Titi de opin ni Oun n ṣiṣẹ yii – titi de wakati kọkanla ọjọ -- ki ọpọlọpọ ìtí iyebiye le bọ kuro ninu iparun ti o n bọ wá ni opin aye wọn.

Ọlọrun yipada si awọn Keferi nigba ti awọn Ju kọ Ọ, ṣugbọn ko ti i si orilẹ-ede kan ninu awọn orilẹ-ede Keferi - gẹgẹ bi orilẹ-ede - ti O ba dá majẹmu, bi O ti ṣe pẹlu Israẹli! Kò yàn wọn bi orilẹ-ède lati jẹ ijọba alufaa, orilẹ-ède mimọ, tabi eniyan ọtọ! Ṣugbọn awọn ẹni kọọkan ti wọn jẹ ipe lati ṣiṣẹ ninu ọgba ajara Rẹ ni a fun laṣẹ, nitori wọn wa labẹ Majẹmu Ayeraye ti Ọlọrun bá Abrahamu dá, iru awọn eniyan bẹẹ ni o si n ṣe iṣẹ itankalẹ Ihinrere.

Nigba ti Oluwa rán awọn aadọrin ọmọ-ẹyin jade ni meji-meji, O wi pe “Ikore pọ, ṣugbọn awọn alagbaṣe ko to nkan: nitorina ẹ bẹ Oluwa ikore, ki o le rán awọn alagbaṣe sinu ikore rẹ” (Luku 10:2). Nigba ti baale ile ri i ti awọn eniyan kawọ gbenu lasan ninu ọjà lai ri iṣẹ ṣe, O wi pe, “Ẽṣe ti ẹnyin fi duro lati onimoni li airiṣe?”

A le sọ pe wakati kọkanla aye yii ni a wà yii, nigba ti ikore pọ nitootọ ṣugbọn ti alagbaṣe kò tó. Ko si aye fun airiṣe ninu ọgba ajara Oluwa nigba nì ati nisisiyii. Ayé yii ni ọgba ajara Rẹ, ẹni kọọkan ti o ba si pe ni a fi aṣẹ fun lati lọ ṣiṣẹ ninu ọgba ajara Oluwa, ki o má si ṣe fa sẹyin bi awọn Ju ti ṣe ni igba laelae.

A ko pe Onigbagbọ lati jokoo ki o si kawọ gbenu, lati wà “ni irọra ni Sioni.” A ko gbọdọ “ṣarẹ ni rere iṣe.” ọpọlọpọ li a pè, ṣugbọn diẹ li a o ri yàn,” nitori wọn ko jẹ ipe lati ṣiṣẹ fun Oluwa. Ẹnikẹni ti i ṣe ero Ijọba Ọrun nipa atunbi jẹ alagbaṣe fun Ọlọrun ni aye kan. A kò yọ ẹnikẹni silẹ!

Ere Onigbagbọ Fun Iṣẹ Rẹ

Ere wà fun iṣẹ ti a ba ṣe tọkantọkan. Jesu sọ fun ni nibomiran nipa oniruuru ipo ti a o fi fun ni ni Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun, gẹgẹ bi a ti fi tọkantọkan ṣiṣẹ fun Un sí ninu iṣẹ-iranṣẹ wa ninu ọgba ajara ti Ijọba Rẹ. A tun sọ fun ni nipa oriṣiriṣi ere ti a o fi fun ni, nitori Iwe Mimọ sọ fun ni pe awọn ti o n yi ọpọlọpọ pada si ododo yoo maa tàn “bi irawọ lai ati lailai”, ati pẹlu pe a o fun ni ni ere nitori “kìki ago omi tutù” ti a fi fun “ọkan ninu awọn onirẹlẹ wọnyi mu nitori orukọ ọmọ-ẹhin,” bakan naa ni ere wolii yoo jẹ ti ẹnikẹni ti o ba gba awọn eniyan Ọlọrun bẹẹ, bakan naa ni ere olododo yoo jẹ ti ẹni ti o ba ṣe iranṣẹ fun olododo (Matteu 10:41, 42).

Ṣugbọn ọna Ọlọrun yatọ si ti eniyan. Ninu owe yii a ri i pe baale ile yii sanwo fun gbogbo awọn alagbaṣe rẹ ni opin ọjọ, “lati ẹni ikẹhin lọ si ti iṣaju.” Ko bẹrẹ lati ọdọ awọn ti a kọ gba si iṣẹ, kaka bẹẹ, o bẹrẹ lọdọ awọn ti o lọ sinu ọgba ajara ni wakati kọkanla ọjọ. Eyi jẹ apẹẹrẹ daradara nipa ọna ti Ọlọrun yoo gba fun awọn iranṣẹ Rẹ ni ere. Iwe Mimọ sọ fun ni pe ẹni iwaju n bẹ ti yoo di ẹni ẹyin, bẹẹ ni ẹni ẹyin n bẹ ti yoo di ẹni iwaju.

Eyi jẹ itunu fun awọn ti a kò fun ni anfaani fun iṣẹ ninu ọgba ajara Ọlọrun titi di wakati kọkanla ọjọ, pe eyi ko ni jẹ ibawi fun wọn, bi wọn ba jẹ oloootọ si ipe Ọlọrun nigba ti a ba nawọ rẹ si wọn! Ọpọlọpọ wa ni o ti ni anfaani lati ṣiṣẹ fun Ọlọrun fun ọdun pupọ, iṣẹju kọọkan si ti fun wa ni ayọ ati inu didun. Eyi jẹ ere nla fun iṣẹ ti a ṣe, nitori anfaani ologo ni o jẹ lati ṣe ohunkohun fun Oluwa, bi o tilẹ jẹ pe ohun ti ayé rò pé kò nilaari. Ṣugbọn nigba ti ọjọ naa ba de ti Ọlọrun yoo pin ere ayeraye, awa yoo ri awọn wọnni ti wọn ṣe ohun ti Ọlọrun beere lọwọ wọn nigba ti a ba fun wọn ni ere ayeraye kan naa, bi o tilẹ jẹ pe akoko ti wọn fi ṣiṣe fun Ọlọrun kuru. Otitọ ni pe eyi yatọ si ọna eniyan: ṣugbọn ọna Ọlọrun ni. Eyi si ni ọna ti o dara!

Awọn ti o n gba alagbaṣe si iṣe a maa diwọn owo ọya wọn nipa akoko ti wọn fi ṣiṣẹ fun wọn ati bi iṣe ti wọn ṣe ti pọ to. Eyi ni ọna ti o tọ lati ṣiro owo ọya iṣe ti ara, nibi ti a ni lati sanwo fun awọn alagbara ati onitara, fun agbara ati akoko ti wọn ti lò fun iṣẹ ti a fi fun wọn lati ṣe. A o fun awọn ti o ṣiṣẹ fun Ọlọrun ni ere, ki i ṣe bi iṣẹ ti wọn ṣe ti pọ to, tabi iye wakati ti wọn lò, ṣugbọn bi iṣẹ ti wọn ṣe fun Ọlọrun ti nilaari to. Ninu awọn nnkan ti n fi bi iṣẹ wa ti dara to hàn ni wọnyii.

Ijolootọ wa si Ọlọrun ati si iṣẹ Rẹ lai si aniani ni yoo wa ni ipo kinni ninu awọn nnkan ti n fi iṣẹ wa hàn. Ọpọlọpọ ni o n bẹrẹ, ṣugbọn diẹ ni o n ṣe e de opin. Ọpọlọpọ a maa layọ lati ṣiṣẹ fun Ọlọrun nigba ti iṣẹ naa ṣẹṣẹ yọju ti o jẹ ọtun, ti o ba si fa wọn mọra nitori o gbadun mọ wọn. Ṣugbọn ẹni ti yoo gba ere atọrun wa ni ẹni ti o ba tẹra mọ iṣẹ naa nigba ti ko larinrin mọ ti o si dabi pe ko nilaari loju awọn ẹlomiran, tabi nigba ti ko tilẹ wu ọpọlọpọ eniyan mọ. Oṣiṣẹ tootọ yoo de ni akoko ti o tọ, yoo si jẹ ọkan ninu awọn ti yoo lọ kẹyin, yoo duro nidii iṣẹ titi yoo fi pari. Ki i ṣe pe ẹni kan ni yoo ṣẹṣẹ sọ fun un lati ṣe bẹẹ, ṣugbọn tọkantọkan ni oun funra rẹ yoo fi ṣe e.

Ero ti o wà lọkan wa ninu ṣiṣe iṣẹ fun Ọlọrun jẹ ohun pataki miiran ti o n fihan bi iṣẹ wa fun Ijọba naa ti dara to. A ha n ṣe eyi ti a ṣe fun ogo Ọlọrun nikan bi? Tabi a n ṣe e lati tẹ ara wa lọrun? fun ogo ara wa ni bi? tabi ki eniyan le ri wa? tabi lati wa oju rere lọdọ eniyan? Ni kukuru, ṣe lati tẹ ifẹ ara wa lọrun lọnakọna ni? Ero pipe nikan ni o le mu ki iṣẹ wa nilaari ki o si fun ni ni ere ayeraye.

Ọna ti a gba ṣe iṣẹ wa fun Ọlọrun tun jẹ odiwọn pataki. Ṣe afipa ṣe ni iṣẹ ti a n ṣe? Tabi a ṣe lati inu ifẹ rere si Ọlọrun ati fun ọkàn ọmọ eniyan? Arojuṣe a wà ni ọkàn wa tabi ni iwa wa si awọn ti a n bá ṣiṣẹ pọ ninu iṣẹkiṣẹ ti a n ṣe? A ha fara n balẹ di aafo ti a pe wa lati dí? Awa naa a dabi awọn alagbaṣe ti o ṣiṣẹ lati owurọ di aṣalẹ ti a sọ nipa wọn ninu owe yii, awọn ti o kùn si baale ile nitori o san owo iṣẹ oojọ fun awọn ti o bẹrẹ iṣẹ ni wakati kọkanla ọjọ? Ohunkohun ha wa ninu wa ti ko kun fun awọn eso ti Ẹmi?

Ọlọrun beere eyi ti o dara ju lọ ninu wa fun ohunkohun ti a n ṣe fun Un. Eyi ti o rẹlẹ ju bẹẹ lọ ko dara to. O fi ẹmi Rẹ fun wa! A ni lati fi gbogbo aye wa fun Un. Nigba ti a ba ti ṣe ohun gbogbo ti a palaṣẹ fun wa tan, ti a si yẹ fun ere, a o wi pe, “Alailere ọmọ-ọdọ ni wa: eyi ti iṣe iṣẹ wa lati ṣe, li awa ti ṣe” (Luku 17:10).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Sọ itan awọn Alagbaṣe ti a gbà sinu Ọgba Ajara lati ibẹrẹ titi de opin iṣẹ oojọ wọn.
  2. Ta ni a kọ sanwo fún?
  3. Iru iwa wo ni awọn ti a tete gbà si iṣẹ kọ si awọn ti o dé kẹyin?
  4. Iru iwa bẹẹ a tọ? Baale ile naa ha ṣe aiṣododo si wọn?
  5. Ọna wo ni odiwọn Ọlọrun nipa iṣẹ ti a ṣe fun Un fi yatọ si ti eniyan?
  6. Darukọ diẹ ninu ohun ti yoo fihan bi iṣẹ wa ti dara to.
  7. Iwọ ha le darukọ awọn ohun miiran ti a kò mẹnu kan pato ninu ẹkọ yii?
  8. Yẹ iṣẹ isin rẹ si Ọlọrun wò pẹlu ifarabalẹ ati adura, lati mọ bi yoo yege ninu ayẹwo ti Ọlọrun.