Matteu 20:20-28; Jakọbu 4:1-3

Lesson 184 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹnyin bère, ẹ kò si ri gbà, nitoriti ẹnyin ṣì i bère, ki ẹnyin ki o le lò o fun ifẹkufẹ ara nyin” (Jakọbu 4:3).
Cross References

I Adura Alaimoye Kan

1. Iya Jakọbu ati Johannu fi itẹriba wá sọdọ Jesu pẹlu ẹbẹ kan, Matteu 20:20

2. O beere pe ki awọn ọmọ oun mejeeji le jokoo lẹgbẹ Jesu ni Ijọba Rẹ, Matteu 20:21

3. Ifẹkufẹ a maa fa ogun ati ija, Jakọbu 4:1, 2; Romu 7:23; Galatia 5:17; 1 Peter 2:11

4. Adura ki i gbà nitori etekete ọkàn, Jakọbu 4:3; Orin Dafidi 66:18

II Ere Gẹgẹ bi Iṣẹ

1. Jesu fesi si ibeere ọrọ naa, O n beere bi wọn n fẹ maa tẹle Oun, Matteu 20:22; 12:50; Marku 14:36

2. O sọ fun wọn ohun ti oju wọn yoo rí ati ibi ti igbega ti n wá, Matteu 20:23; 19:28; 25:4

III Iṣẹ Kristi

1. Jesu ṣe alaye nipa iyatọ ti o wà laaarin ipo aṣẹ ninu ijọba ti aye yii ati ninu Ijọba ti Ọrun, Matteu 20:25-27; 23:11;1Peteru 5:3

2. O wá gẹgẹ bi iranṣẹ lati sin ati lati fi ẹmi Rẹ ṣe irapada ọpọ eniyan, Matteu 20:28; Isaiah 53:10, 11; Johannu 11:51, 52; 13:4; Filippi 2:7; 1 Timoteu 2:6; Titu 2:14

Notes
ALAYE

Ẹkọ wa bẹrẹ pẹlu akọsilẹ wiwa iya awọn ọmọ Sebede sọdọ Jesu pẹlu awọn ọmọ rẹ, Jakọbu ati Johannu, ti o si wolẹ fun Jesu. Wiwolẹ ti o wolẹ ki i ṣe lati fi iyin fun Jesu nikan bi ko ṣe lati tọrọ ohun kan lọdọ Rẹ. Jesu mọ eyi, O si bi i leere pe, “Kini iwọ nfẹ?” O dahun pe, “Jẹ ki awọn ọmọ mi mejeji ki o mã joko, ọkan li ọwọ ọtún rẹ, ọkan li ọwọ òsi ni ijọba rẹ.” A le ri i pe ifẹ ipò wà ninu ibeere yii ati pe dajudaju, awọn ọmọkunrin meji naa ni o wà nidii ibeere yii.

Ilepa Giga Ọkan Eniyan

Ki i ṣe ohun ti awọn obi wa n fẹ ki á dà, tabi ohun ti awa paapaa n fẹ dà ni o gbọdọ leke ifẹ ọkan wa ninu aye. Ifẹ ati ilepa wa ko ni lati jẹ pe ki Ihinrere gbé wa sori atẹ tabi ki a gbé wa leke ga ju awọn ẹlẹgbẹ wa lọ. Jesu sọ nigba kan pe, “Ati emi, bi a ba gbé mi soke kuro li aiye, emi o fà gbogbo enia sọdọ ara mi.” Ohun ti Ihinrere wà fun ni lati gbe Jesu ga, ki a le fa gbogbo eniyan sọdọ Rẹ. Bi a ba n lepa pe ki Ihinrere fi wa si ipo giga, a n kuna eto Ọlọrun fun wa. Paulu sọ pe: “Ṣugbọn ki a máṣe ri pe emi nṣogo, bikoṣe ninu agbelebu Jesu Kristi Oluwa wa, nipasẹ ẹniti a ti kàn aiye mọ agbelebu fun mi, ati emi fun aiye” (Galatia 6:14). O si tun sọ pe awọn ti o ba jẹbi gbigba iṣẹ ti ara yii laye ki yoo jogun Ijọba Ọlọrun (Galatia 5:20, 21).

Nigba diẹ ṣiwaju eyi, Jesu ti mu Jakọbu ati Johannu ati Peteru lọ sori oke, nibẹ ni wọn si ri iran ologo ti ipalarada Jesu. Boya eyi dùn mọ ọkàn ti ara ti o wà ninu Jakọbu ati Johannu to bẹẹ ti wọn fi ro pe a gbe wọn ga ju awọn ọmọ-ẹyin mẹsan iyoku lọ. Nitori naa Peteru nikan ni ẹni ti o ṣe e ṣe ki a gbe ga ju wọn lọ, wọn ro pe boya bi wọn ba tete beere ipo ti ọkàn wọn n fẹ a o fi fun wọn.

Gẹgẹ Bi Ọmọ-Ọwọ

Nigba ti eṣu ba ti fi ilepa ọla tabi ipo giga laaarin eniyan sinu ọkàn ọmọ eniyan, o ti ri ibi fi ẹsẹ mulẹ ninu ọkàn naa, lati bẹrẹ iṣẹ rẹ lati fa ọkàn naa kuro lọdọ Ọlọrun.

Ko ti i pẹ ṣiwaju akoko yii awọn ọmọ-ẹyin n ṣe ariyanjiyan pe ta ni yoo pọ jù ni Ijọba Ọrun. Ni idahun si eyi, Jesu pe ọmọ kekere kan, O si mu un duro laaarin wọn, O wi pe, “Bikoṣepe ẹnyin ba pada, ki ẹ si dabi awọn ọmọ kekere, ẹnyin ki yio le wọle ijọba ọrun. Nitorina ẹnikẹni ti o ba rẹ ara rẹ silẹ bi ọmọ kekere yi, on na ni yio papọju ni ijọba ọrun.” A ni lati wẹ gbogbo ilepa ara mọ kuro ninu ọkàn wa bi a ba fẹ jẹ ẹni iwa-bi-Ọlọrun ati olododo. Ko ni lati si ifẹ lati di ẹni giga ninu ayé, tabi wiwa ipo ati ifẹ iyin eniyan ninu ọkàn wa gẹgẹ bi ko ti si nnkan wọnyii ninu ọmọ kekere. Eyi ti yọ wọ inu ọkàn ọpọlọpọ awọn ọmọlẹyin Onirẹlẹ Ara Nasarẹti lati sọ wọn di ẹni ibajẹ, nigba ti wọn ba fi ara fun idanwo ẹni ibi nì.

Gbigbe ara ga a maa sun ni si iṣọtẹ, eyi ti o sọ Miriamu arabinrin Mose di adẹtẹ. Eyi yoo sọ ọkàn ẹnikẹni ti o ba gba a laye lati ni ibugbe ninu ọkàn rẹ di adẹtẹ nipa ti ẹmi. Iwe Mimọ kọ ni pe, “niti ọlá, ẹ mã fi ẹnikeji nyin saju” nigbagbogbo (Romu 12:10).

Biba Ẹmi Jagun

Ifẹ ati ero ara a maa bá Ẹmi Ọlọrun jagun. Bi a ba gbadura pẹlu itara ati igbona ọkàn, Ọlọrun yoo gbọ ti wa, yoo si dá wa lóhùn, bi a ko ba beere lọna ti kò tọ. Bi a ba gba awọn ifẹ ara wọnyii laaye, wọn yoo dá ija ati asọ silẹ. Nigba ti a bá si ti n bá ẹnikeji wa sọ, ti a si fẹ ki ti wa leke ṣá, eyi yoo maa ba ọkàn wa ati Ẹmi Ọlọrun jagun (nigba miiran kò tilẹ ni di mímọ fun wa). Onigbagbọ ni lati pa ero ati ifẹ wọnyii run lẹsẹkẹsẹ ti wọn ba fara hàn, a ni bi o ti wu ki o kere to.

Kò tó ki ó jẹ ohun rere ni a n beere nikan, a ni lati beere pẹlu ọkàn rere ati ero titọ. “Ẹnyin bère, ẹ kò si ri gbà, nitoriti ẹnyin ṣì i bère, ki ẹnyin ki o le lò o fun ifẹkufẹ ara nyin.” Bi a ba beere lọna ẹtọ, ohun gbogbo ti a n fẹ ni a o fi fun wa. Nigba naa awọn ero ti ko tọ ti o n fa “ogun ati ija” yoo dopin.

Ohun Ikọsẹ Ti O Maa N Wá

Oluwa bá wọn sọrọ lori ọran yii gidigidi lati fihan wọn bi ilepa ara ti lewu fun igbesi-ayé ti ẹmi tó. O sọ fun wọn pe ohun ikosẹ ko le ṣe alaiwa, ṣugbọn O fi egun lé oluwarẹ lori, nipasẹ ẹni ti ohun ikọsẹ naa ti wá. “Bi oju rẹ ba si mu ọ kọsẹ, yọ ọ jade: o sàn fun ọ ki o lọ si ijọba Ọlọrun li olojukan, jù ki o li oju mejeji, ki a gbé ọ sọ sinu iná ọrun apadi.” Jesu wi pe, “Ki ẹ si ma wà li alafia lãrin ara nyin” (Marku 9:50).

Ilepa Fun Ipo Giga

Ninu ẹkọ ti a ti ṣe kọja, a kẹkọọ bi Jesu ti ri awọn eniyan ti wọn n wá ipo giga nibi ase, ti O si wi pe: “Nigbati ẹnikan ba pe ọ wá si ibi iyawo, máṣe joko ni ipò ọlá; ki o ma ba jẹ pe, a pè ẹniti o li ọlá jù ọ lọ. Nigbati ẹniti o pè ọ ati on ba de, a si wi fun ọ pe, fun ọkọnrin yi li àye; iwọ a si wa fi itiju mu ipò ẹhin. Ṣugbọn nigbati a ba pè ọ, lọ ki o si joko ni ipò ẹhin; nigbati ẹniti o pè ọ ba de, ki o le wi fun ọ pe, Ọrẹ, bọ soke: nigbana ni iwọ o ni iyin li oju awọn ti o ba ọ joko ti onjẹ. Nitori ẹnikẹni ti o ba gbé ara rẹ ga, li a o rẹ silẹ: ẹnikẹni ti o ba si rẹ ara rẹ silẹ, li a o si gbéga” (Luku 14:7-11).

Awọn ọmọ-ẹyin ti gbọ bi Jesu ti bá awọn Farisi wí nitori wọn fẹ ipò giga nibi ase, ati ipò ọlá ni sinagogu, wọn si n fẹ ikini ni ọjà. Bawo ni o ti rọrun to lati tete gbagbe awọn ẹkọ rere wọnni nigba ti ara bori, ti Ẹmi Ọlọrun si fi ọkàn naa silẹ.

Aago Lati Mu

Ni idahun si ibeere wọn, Jesu sọ fun Jakọbu ati Johannu pe wọn kò mọ ohun ti wọn n beere; O si bi wọn leere bi wọn ba le mu aago kan naa ti Oun yoo mu, ki a si fi baptisimu ti a o fi baptisi Rẹ baptisi wọn – lati fihan wọn pe lati jẹ ọmọ-ẹyin Rẹ kò rọrùn. Wọn dahun pe wọn le mu aago kan naa, ohun ti o de ba wọn nigbooṣe fihan pe otitọ ni eyi: ṣugbọn oore-ọfẹ Ọlọrun nikan ni o mú wọn duro. Hẹrọdu bẹ Jakọbu lori, wọn si wa Johannu lọ si Erekusu Patmo nitori Ihinrere; iwe itan sọ fun ni pe wọn gbé Johannu sinu epo gbigbona laaye, ṣugbọn Ọlọrun dide fun iranlọwo rẹ, O si dá ẹmi rẹ si.

A sọ fun ni pe a fi egun kan si iha Paulu – eyi ti ṣe iranṣẹ Eṣu – lati pọn ọn loju ki o ma baa gberaga nitori ọpọlọpọ iṣipaya ti Ọlọrun fihan fun un. Nigba mẹta ni o bẹbẹ pe ki Oluwa mu un kuro, ṣugbọn Oluwa wi pe, “Ore-ọfẹ mi to fun ọ: nitoripe a sọ agbara mi di pipé ninu ailera” (2 Kọrinti 12:9)

Ijọba Ti O Yatọ

Ninu ijọba ayé yii, awọn ọlọla a maa jẹ gaba lori awọn ti o wà labẹ wọn. Ṣugbọn ki yoo ri bẹẹ ni ijọba ti Kristi n gbé kalẹ lọkan awọn ọmọ-ẹyin Rẹ. Jesu wi pe, “Ẹnikẹni ti o ba fẹ pọ ninu nyin, ẹ jẹ ki o ṣe iranṣẹ nyin; ani gẹgẹ bi Ọmọ-enia kò ti wá ki a ṣe iranṣẹ fun u, bikoṣe lati ṣe iranṣẹ funni, ati lati fi ẹmi rẹ ṣe iràpada ọpọlọpọ enia.” Irapada ti kò lẹgbẹ wo ni eyi! Jesu fi irẹlẹ Rẹ ati itara Rẹ hàn, bi O ti n lọ sori igi agbelebu. Nibẹ ni O gbe jiya ti o si ku fun wa, ki awa, ẹlẹbi ati ẹlẹṣẹ ti o wà labẹ idajọ má ṣe san gbese ijiya tí ẹṣẹ wa beere. Ihinrere ologo yii ti jẹ mimọ alaileeri, alailabula, ti o to tán ti o si lagbara jù lọ tó! “Onirẹlẹ yio gbọ, inu wọn yio si ma dùn” (Orin Dafidi 34:2).

Niwọn bi Jesu ti wá saye gẹgẹ bi iranṣẹ, lati fi ẹmi Rẹ ṣe etutu fun ọpọlọpọ eniyan, a ni lati ranti pe awa pẹlu, gẹgẹ bi iranṣẹ Rẹ, ni lati jẹ onirẹlẹ. A mọ pe a ni lati tọ ipasẹ Rẹ ki a si jẹ alabapin ìyà Rẹ nigba ti a wà laye yii, bi a ba fẹ rí bi Oun ti rí nigba ti a ba lọ wà pẹlu Rẹ ni Ọrun (2 Timoteu 2:11, 12; l Peteru 2:21-23). Iṣẹ iranṣẹ Ọlọrun tootọ ni lati fi ifẹ atinuwa ṣiṣẹ fun Ọlọrun ati Ijọba Ọlọrun ti o wà ninu ayé nisisiyii. Ọpọlọpọ ni o ti ṣi ipò yii ati anfaani ti o wà ninu rẹ lò, nitori wọn ni ero pe wọn ga ju awọn ti a pè wọn lati ṣe iranṣẹ fún lọ. Otitọ ni pe awọn ojiṣẹ Ọlọrun yẹ fun ọlá ilopo meji (l Timoteu 5:17), ṣugbọn eyi ki i ṣe lati gbé wọn ga, - paapaa ju lọ, loju ara wọn, - nipa ero giga nipa ara wọn, eyi ti o lodi si ilana ati apẹẹrẹ ti Jesu fi lelẹ.

Niwọn iba oye wa, ẹkọ yii fi opin si ilepa ara Jakọbu ati Johannu lati ṣe olori. Wọn di onirẹlẹ iranṣẹ Ọlọrun, ṣugbọn wọn jẹ akọni, wọn si fihan pe wọn yẹ fun iṣẹ ti a pè wọn si: nitori ni ibi Ounjẹ-alẹ Oluwa, lẹyin ti Jesu mu ninu ago tán, ti o si fi fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ, O wi fun wọn pe, “Ẹnyin li awọn ti o ti duro tì mi ninu idanwo mi. Mo si yàn ijọba fun nyin, gẹgẹ bi Baba mi ti yàn fun mi; ki ẹnyin ki o le mã jẹ, ki ẹnyin ki o si le mã mu lori tabili mi ni ijọba mi, ki ẹnyin ki o joko lori itẹ, ati ki ẹnyin ki o le mã ṣe idajọ fun awọn ẹya Israẹli mejila” (Luku 22:28-30).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Nibo ni ogun ati ija ti wá saarin awọn eniyan?
  2. Nigba wo ni a ṣi beere?
  3. Ki ni orukọ baba Jakọbu ati Johannu?
  4. Ki ni ẹbẹ iya wọn?
  5. Jesu ha fi fun un bi?
  6. Ki ni Jesu sọ nipa ibeere naa?
  7. Ki ni fa ibinu laaarin awọn ọmọ-ẹyin?
  8. Ta ni yoo ṣe olori laaarin wọn?
  9. Jesu ha wá ki a ṣe iranṣẹ fun Un tabi lati ṣe ranṣẹ fun ni?