Marku 10:46-52

Lesson 185 - Senior

Memory Verse
Akọsori:“Ahọn mi yio ma sọrọ ododo rẹ, ati ti iyin rẹ li gbogbo ọjọ” (Orin Dafidi 35:28).
Cross References

I Ẹbẹ Awiidabọ Bartimeu fun Aanu

1. Bartimeu jokoo lẹba ọna o n ṣagbe bi Jesu ti n kọja lọ, Marku 10:46; Matteu 20:29-34; Luku 18:35-43

2. Bartimeu kigbe soke fun aanu, Marku 10:47; Luku 18:13

3. Wọn kuna ninu igbiyanju wọn lati pa á lẹnu mọ, Marku 10:48; Esra 4:4, 5; Nehemiah 4:7-9; Sekariah 3:1; 1 Kọrinti 16:9

II Ere Igbagbọ

1. Jesu gbọ igbe rẹ, O ranṣẹ pè é, Marku 10:49

2. Bartimeu yán agbada rẹ sọnu o si wá sọdọ Jesu, Marku 10:50; Heberu 12:1

3. Nipa igbagbọ oju rẹ là, o si n tẹle Jesu, Marku 10:51, 52

Notes
ALAYE

Iṣẹ iranṣẹ Jesu n sure lọ si opin. O ti pe awọn ọmọ-ẹyin Rẹ mejila mọra O si wi fun wọn pé wọn yoo lọ si Jerusalẹmu, nibẹ ni wọn o ti dá Oun lẹbi, ti wọn o si pa Oun. Igba ikẹyin ti yoo gba Jẹriko kọja ni yii. Okiki Rẹ ti kàn kaakiri, ọpọlọpọ ni o si n tọ Ọ lẹyin. Ifẹ ti awọn eniyan ni si I ti ga pupọ, lai pẹ jọjọ ọpọ eniyan yoo kigbe pe, “Olubukun li Ọba ti o mbọ wá li orukọ Oluwa” (Luku 19:38).

Igbagbọ

Lẹba opopo ọna ti o gba Jẹriko kọja lọ si Jerusalẹmu ni awọn alagbe meji jokoo. Boya wọn ju bẹẹ lọ. Ṣugbọn awọn wọnyii, ẹni ti Matteu 20:30 sọ fun ni nipa wọn, ní igbagbọ. Igbagbọ ni igbẹkẹle ati fifi ọkan tán Ọlọrun. O jẹ igbagbọ pe ohun ti Ọlọrun ba sọ yoo ṣe e dandan. Nigba nigba ti Ọrọ Ọlọrun sọ pe, “Ọkọnrin kan ninu nyin yio lé ẹgbẹrun” (Joṣua 23:10), igbagbọ yoo mu ki ọkunrin kan dide lati pade ẹgbẹrun. Igbagbọ nikan kọ ni ohun ti o n fun ni ni ibukun, ṣugbọn o jẹ apa kan ninu ohun gbogbo ti a n ri gbà lọwọ Ọlọrun. Oun ni idaniloju ohun ti a n reti. Nipa igbagbọ ni awọn ti igba nì fi ṣẹgun awọn ọba, ti awọn obinrn si gba oku wọn laaye. A le lo igbagbọ nipa ṣiṣe ati titẹle ohun wọnni ti a gbagbọ nipa ohun ti i ṣe ti Ọlọrun.

Aanu

Ọjọ diẹ ni o kù fun Kristi lati lọ kú ni Kalfari. Kò tó ogun mile lati Jẹriko si Jerusalẹmu. Ṣugbọn Jesu n ba iṣẹ aanu Rẹ lọ; titi de opin ni O n ṣaanu. O lẹ eti ẹni ti Peteru fi idà gé leti ninu Ọgba, O si gba olè ori agbelebu là.

Nisisiyii bi Jesu ti fi Jẹriko silẹ, eti Bartimeu afọju, ọmọ Timeu, gbọ iro ẹsẹ ọpọ eniyan. Pẹlu ẹni keji rẹ ti i ṣe afọju bi ti rẹ, nipa ẹni ti a kò mọ pupọ. Bartimeu beere eredi irọkẹkẹ yii. Ireti sọji ninu ọkàn rẹ bi o ti n sọ fun ẹni keji rẹ pe Jesu ni. Awọn mejeeji kigbe pe, “Oluwa, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun wa” (Matteu 20:30). Ọpọ eniyan naa bá wọn wí. Ero ọkàn wọn ni eyi pe, Ẹ ma ṣe yọ Ọlukọni lẹnu, awọn afoju ti ko nilaari bi ẹyin ko gbọdọ yọ Ọ lẹnu. Ṣugbọn Ọmọ Dafidi ṣaanu fun wọn.

Idakẹjẹ

Awọn eniyan ha ti i sọ fun ọ ri pe: “Dakẹ, kò ṣanfaani”; “Ọmọde ni ọ”; “O fẹ sọ ẹmi rẹ nù”; “Kò ṣe dandan lati gbadura pupọ”; “Ko si ikanju”; “O n fi ara rẹ wọlẹ?” Má ṣe fi eti si ti wọn. Tẹle E. Oniyọnu – Alaanu ni. Gbogbo ara Ninefe kigbe kikankikan si Ọlọrun. O si dá ilu wọn si. Hesekiah sọkun kikoro Ọlọrun si fi ọdun mẹẹdogun kún ọjọ ayé rẹ. Bi Satani tilẹ n fẹju ti gbogbo ogun ọrun apaadi si n dena, a le la ọna wa já. Awọn ọpọ eniyan yoo duro, ariwo yoo dopin, a o sì gbọ ohùn Rẹ pe, “Kili ẹnyin nfẹ ki emi ki o ṣe fun nyin?”

Okunkun

Bartimeu ki i ṣe ẹni ti a le pa lẹnu mọ kiakia. Lai si aniani, lati ọpọlọpọ ọdun ni ọkàn rẹ ti n poungbẹ lati ri imọlẹ. Kò mọ adun ohun meremere ti Ọlọrun dá. Ki i ṣe eyi nikan, iṣẹ oojọ rẹ bọ lọwọ rẹ nitori ko riran. Ki i ṣe ifẹ ọkàn rẹ lati maa ṣe agbe. O ṣoro lati gbẹkẹ le itọrẹ-aanu. Fifi ọpa ọwọ rẹ wa ọna, o n ta ràrà kiri, o n fẹsẹ kọ, okunkun biribiri nigba gbogbo -- ẹnu ha ya ọ pe Bartimeu kigbe lóhùn rara?

Nigba ti ẹlẹṣẹ ba mọ ipò rẹ -- pe oun jẹ ẹni “òṣi, ati àre, ati talakà, ati afọju, ati ẹni-ìhoho” (Ifihan 3:17), oun pẹlu yoo kigbe pe “Jesu, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi.” Ọlọrun jọwọ jẹ ki gbogbo ẹlẹṣẹ mọ pe wọn n rin ninu okunkun, wọn si n ṣubu lọ si idajọ ayeraye! Ha, wọn i ba jẹ ké pe Olugbala fun aanu.

Ohun Idiwọ

“Jesu si dẹsẹ duro.” Ọmọ Ọlọrun, Ẹlẹda ohun gbogbo, dẹsẹ duro lati gbọ ti alagbe. Awọn ero ti Bartimeu si apakan, ṣugbọn Jesu pasẹ ki a mu un tọ Oun wá. Ọpọlọpọ lọjọ oni ni wọn ko fẹ “pa ohun idiwọ gbogbo tì si apakan, ati ẹṣẹ ti o rọrun lati dì mọ wa” (Heberu 12:1). Ọpọlọpọ ni ko fẹ pa erokero ti ara wọn ti sapa kan. Awọn ẹlomiran jokoo ti iṣẹ ododo ara wọn tabi iṣẹ rere wọn, wọn fẹ fi wá oju rere Ọlọrun. “Gbogbo ododo wa si dabi akisa ẹlẹgbin” (Isaiah 64:6). Titi eniyan yoo fi ri idande, ireti kan ṣoṣo ti o ní ni lati wá aanu Ọlọrun gẹgẹ bi awọn ọkunrin afọju wọnni.

Ijẹwọ

Nigba ti Bartimeu de, Jesu bi leere pe, “Kini iwọ nfẹ ki emi ki o ṣe fun ọ?” Ọkunrin afọju naa dahun pe, “Rabboni, ki emi ki o le riran.”

O jẹwọ pe oun fọju, o si n fẹ bọ ninu ifọju naa. “Ẹniti o bo ẹṣẹ rẹ mọlẹ ki yio ṣe rere: ṣugbọn ẹnikẹni ti o jẹwọ ti o si kọ ọ silẹ yio ri ãnu” (Owe 28:13). Yoo buru fun afọju lati wi pe oun ko fọju, bakan naa ni o buru fun eniyan ti o ti dẹsẹ lati wi pe oun ko dẹṣẹ tabi ki o bo ẹṣẹ rẹ mọlẹ.

Iwosan

Nigba ti Jesu gbọ ẹbẹ Bartimeu, O wi fun un pe, “Mã lọ; igbagbọ rẹ mu ọ larada.” Igbagbọ fun ọkunrin yii ni iriran. Ninu Marku 11:24 a ka ohun ti Jesu wi: “Ohunkohun ti ẹnyin ba tọrọ nigbati ẹ ba ngbadura, ẹ gbagbọ pe ẹ ti ri wọn gbà na, yio si ri bẹẹ fun nyin.” Nipa igbagbọ ninu Ọlọrun, ọpọlọpọ iṣẹ iyanu ti iwosan ni o n ṣe lonii. Ọlọrun fẹ ki awọn eniyan Rẹ gbẹkẹle Oun fun iwosan. O sọ fun awọn Ọmọ Israẹli pe, “Emi li OLUWA ti o mu ọ lara dá” (Ẹksodu 15:26). Iwosan fun ara ati ọkàn wà ninu iṣẹ Etutu ti Jesu ṣe lori agbelebu. Isaiah sọtẹlẹ pe, “A ṣá a li ọgbẹ nitori irekọja wa, a pa a li ara nitori aiṣedede wa; ìna alafia wa wà lara rẹ, ati nipa ìna rẹ li a fi mu wa lara da” (Isaiah 53:5).

Awọn ọmọ Ọlọrun kò gbọdọ gbẹkẹle oniṣegun tabi egbogi fun iwosan ara wọn, nitori a pasẹ fun ni pe: “Ẹnikẹni ṣe aisan ninu nyin bi? ki o pè awọn àgba ijọ, ki nwọn si gbadura sori rẹ, ki nwọn si fi oróro kùn u li orukọ Oluwa: adura igbagbọ yio si gbà alaisan na là, Oluwa yio si gbé e dide” (Jakọbu 5:14, 15). Jesu kan naa ti Bartmeu tọ lẹyin ni ọna Jẹriko nigba nì ṣi n wosan sibẹ lonii. “Jesu Kristi ọkanna ni li aná, ati li oni, ati titi lai” (Heberu 13:8).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Yẹ inu Iwe Mimọ wò lati ibi kan si ekeji nibi ti a pe airiran nipa ti ẹmi ni ifọju.
  2. Lọ wo itan Jẹriko jakejado Bibeli.
  3. Sọ bi Bartimeu afọju ti o fẹ riran ṣe dabi ẹlẹṣẹ ti o n wá igbala.
  4. Darukọ diẹ ninu awọn iwa amuyẹ ti Bartimeu ní.
  5. Fi idi ẹkọ iwosan nipa agbara Ọlọrun mulẹ lati inu Iwe Mimọ.
  6. Ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun wo ni o n fi hàn pe awọn Onigbagbọ ni lati gbẹkele Ọlọrun fun iwosan dipo gbigbẹkẹle oniṣegun tabi egbogi?
  7. Ki ni igbagbọ?
  8. Darukọ diẹ ninu ohun ti Bibeli sọ fun ni pe a ṣe nipa igbagbọ.