Luku 19:1-10

Lesson 186 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Kò si ẹnikan ti o le wá sọdọ mi, bikoṣepe Baba ti o rán mi fà a: Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ” (Johannu 6:44)
Cross References

I Ọjọ Ibẹwo

1. Sakeu, olori awọn agbowode, fẹ lati ri Jesu, Luku 19:1:1-4; 5:15; Matteu 4:24; 9:31; Isaiah 52:13, 15; Johannu 6:2

2. Ifẹ ọkàn Sakeu jẹ idahun si agbara oofa Ọlọrun, Luku 19:5; Orin Solomoni 1:4; Jeremiah 31:3; Hosea 11:4; Johannu 6:44

3. Sakeu jẹ ipe Jesu tọkantọkan o si gba A pẹlu ayọ, Luku 19:5, 6; Isaiah 9:2; Johannu 1:4, 9

4. Awọn ope nipa iṣẹ-iyanu ti igbala ati pe Ọlọrun ni Kristi I ṣe, ṣe ariwisi pe ẹlẹṣẹ gba A ni alejo sile, Luku 19:7: 19:44; Johannu 1:5, 26; 3:9, 10, 19; Efesu 4:18; Matteu 13:15

II Awọn Eso Ironupiwada

1. Pipade ti Sakeu pade Jesu jẹ apẹẹrẹ iyipada ọkàn ẹlẹṣẹ lẹsẹkẹsẹ, pẹlu ami ti o n tẹle e, Luku 19:6; Iṣe AwọnAposteli 2:41; 16:34

2. Ijẹwọ aṣiṣe atẹyinwa ti Sakeu ṣe loju kan naa ati ileri atunṣe jẹ ami ironupiwada ẹni iwa-bi-Ọlọrun si igbala, Luku 19:8; 3:8; 18:22, 23; Orin Dafidi 41:1; Lefitiku 6:1-6; Owe 6:30, 31; Matteu 5:23, 24; 2 Kọrinti 7:10

3. Jesu jẹri si otitọ iyipada ọkàn Sakeu, Luku 19:9, 10; 2:30-32

4. Sakeu fi ara rẹ hàn bi ọmọ Abrahamu tootọ nipa gbigba Jesu gẹgẹ bi Kristi, Luku 19:8-10; 13:16; Galatia 3:7-9, 29; Johannu 8:33, 37-44, 52-58.

Notes
ALAYE

Ifẹ Ọkàn Agbowo-ode Kan

Sakeu, agbowo-ode ọlọrọ, fẹ rí Jesu. Eyi jẹ ilepa ti o dara fun ẹnikẹni, ani bẹẹ ni o ri fun Sakeu, ẹni ti i ṣe ọkan pataki ninu awọn agbowo-ode. Iṣẹ agbowo-ode (eyi ti i ṣe aṣoju Ijọba Romu nipa owo-ori gbigba) jẹ eyi ti awọn Ju korira nitori ó kún fun irẹjẹ ati ilọnilọwọgba. Awọn ti o n ṣe iṣẹ agbowo-ode ki i saaba sọ anfaani ati rẹ ni jẹ nù. Bi o tilẹ ṣe pe Iwe Mimọ ko sọ fun ni pe Sakeu ṣe aiṣododo ninu iṣẹ rẹ, ṣugbọn ẹri oun tikara rẹ fihan fun ni pe ó ti rẹ awọn eniyan jẹ lati ẹyin wá.

Ko wọpọ fun ẹni ti o ba n ṣe iru iṣẹ ti Sakeu n ṣe lati ni ifẹ si eniyan bi Jesu Kristi, ki i si ṣe ofintoto kan ti ko nilaari n Sakeu fẹ ṣe. Ohun ti o ru ifẹ ọkàn Sakeu soke ni bi eto iṣẹ irapada Ọlọrun ti n ṣe nipasẹ Jesu Kristi. Okiki Kristi ati iroyin awọn iṣẹ iyanu ribiribi ti O ti ṣe ti rú ọkàn awọn eniyan soke kaakiri agbegbe ati ilu ti o yí wọn ká.

Bi Jesu ṣe n tumọ akọsilẹ awọn wolii laelae ati Ofin Mose yatọ patapata si igbekalẹ awọn Farisi pẹlu ofin ati ofin atọwọdọwọ wọn eyi ti o ti mu iyapa ati iyàn jija pupọ wá. Awọn eniyan nibi gbogbo n royin Jesu ati ohun wọnni ti O ti sọ ati eyi ti O ti ṣe.

Bi a ti n wo Jesu nipasẹ Ọrọ Ọlọrun, a ri i bi Sakeu ti ri i nikẹyin pe Jesu ju eniyan lọ. Ọmọ Ọlọrun ni Oun i ṣe, Oun ni Ẹni ti yoo wá ṣe etutu, ti o si ti ṣe etutu fun ẹṣẹ awọn eniyan. O wá lati wá gba awọn ti o nù là; Sakeu pẹlu si jẹ ọkan ninu awọn ti o nù, ti Kristi wá rí.

Imọlẹ Ọlọrun

Nigba kan, Isaiah sọ asọtẹlẹ pe Kristi ni i ṣe imọle nla: “Awọn enia ti nrin li okunkun nin imọlẹ nla: “Awọn ti ngbe ilẹ ojiji ikú, lara wọn ni imọlẹ mọ si” (Isaiah 9:2). Johannu Baptisti sọ pe Jesu ni imọlẹ fun awọn eniyan: “Imọlẹ otitọ mbẹ ti ntàn mọlẹ fun olúkulùku enia ti o wá si aiye” (Johannu 1:9) Imọlẹ yii, a ni imọlẹ imọ ati oye ti Kristi ni o ti bẹrẹ si tàn si ọkàn Sakeu. (Wo 2 Peteru 1:3).

A ko mọ ohun ti o wà lọkan Sakeu ti ó mú ki o fẹ ri Jesu, ṣugbọn ó ni lati jẹ pé inu rẹ kò dùn. Niwọn igba ti o ṣe pe gbogbo eniyan ni o korira rẹ. Sakeu ri i pe ofo ati asán ni ọrọ, agbara ati àṣẹ ti o wà ninu ipò ti ó ní. O wá si ọdọ Ẹni ti o tọ nigba ti o n fẹ iranwọ. Iwe Mimọ sọ bayii nipa Jesu: “Nitori didun inu Baba ni pe ki ẹkún gbogbo le mã gbé inu rẹ” (Kolosse 1:19), lai si aniani, itumọ eyi ni pe, ninu Kristi pẹlu iwa Ọlọrun miiran gbogbo ni ẹkún iye gbé wà, a kò si le ri i nibomiran.

O le jẹ pe anfaani kan ṣoṣo ti Sakeu ni lati ri Jesu ni eyi. Iyì ati ayọ ayeraye ni o jẹ fun un nitori ko fi tafala. Jesu kò gba Jeriko kọja mọ. Nigba ti akoko Jesu laye kú fẹfẹ, iru ẹni bi Sakeu ni ko tilẹ yẹ ki o ri ohunkohun gbà lọdọ Jesu Kristi; ṣugbọn o wà ninu awọn diẹ ti ó ri gbà. Sakeu dabi ọkunrin afọju Jẹriko ti o n ṣagbe ati olè ni lori agbelebu, awọn ẹni ti o ri idahun si ẹbẹ wọn nigba ti wọn ké pe Jesu fun aanu. Pipade Jesu lẹẹkan ṣoṣo to fun Sakeu lati fi mọ pe Oun ni Iye, ati Imọlẹ araye (Johannu 1:4).

Bi Sakeu ti jẹ eniyan kukuru, o gun igi lọ ki o ba le ri Jesu daradara bi O ti n kọja lọ. Si iyalẹnu ati idunnu Sakeu, ki i ṣe pe Jesu ri i lori igi nikan ṣugbọn O wi fun un pe ki o sọkalẹ kankan, nitori O fẹ ba a gbe ni ọjọ naa. A kò mọ gbogbo ohun ti o ṣẹlẹ laaarin Jesu ati Sakeu ni iṣeju diẹ ti o tẹle e, ṣugbọn a mọ pe lai pẹ jọjọ Sakeu ni iyipada ọkan, ẹmi ati igbesi-ayé rẹ. Awọn ọrọ ti Sakeu sọ ni gbàrà ti ó sọkalẹ fi ọkàn ironupiwada tootọ hàn. “Wo o, Oluwa, àbọ ohun ini mi ni mo fifun talakà: bi mo ba si fi ẹsun eke gbà ohun kan lọwọ ẹnikẹni, mo san a pada ni ilọpo mẹrin.” Ọrọ wọnyii yoo wà titi lae bi alatako awọn alaigbagbọ ti o sẹ ẹkọ Bibeli nipa pe atunṣe jẹ mọ igbala ati igbesi-ayé Onigbagbọ.

Eso Ironupiwada

Johannu Baptisti kilọ fun awọn Farisi nigba ti wọn tọ Ọ wa pe ki wọn so eso ti o yẹ fun ironupiwada (Matteu 3:8). Isaiah sọ ohun ti ironupiwada jẹ fun Israẹli apẹyinda: “Awẹ ti mo ti yàn kọ eyi? lati tú ọjá aiṣododo, lati tú ẹrù wiwo, ati lati jẹ ki anilara lọ lọfẹ, ati lati já gbogbo ajàga. Ki ha ṣe lati fi onjẹ rẹ fun awọn ti ebi npa, ati ki iwọ ki o mu awọn otòṣi ti a tì sode wá si ile rẹ? nigbati iwọ ba ri arinhòho, ki iwọ ki o bò o, ki iwọ, ki o má si fi ara rẹ pamọ kuro lọdọ ẹran-ara tirẹ” (Isaiah 58: 6, 7). Iru iwa bayii jẹ ẹri niwaju Ọlọrun ati eniyan pe a ronupiwada tọkantọkan.

Sakeu fi ẹmi ronupiwada tootọ hàn nigba ti ó ṣeleri lati ṣe ohun wọnni ti o tọ lẹsẹkẹsẹ: lati ṣe iranwọ fun awọn alaini ati lati ṣe atunṣe ohun ti o ti wọ lati ẹyin wá.

Fun awọn ti wọn sẹ otitọ atunṣe, ti wọn si n kọ ni pe Ọlọrun kò beere pe ki a ṣe atunṣe, a ni eyi lati sọ pe, Ẹ gbé ọrọ wọnyii ti Sakeu sọ yẹwo: “Bi mo ba si fi ẹsun eke gbà ohun kan lọwọ ẹnikẹni, mo san a pada ni ilopo mẹrin.” Gbogbo Ofin Ọlọrun ni o beere pe ki a ṣe atunṣe, Ọlọrun kò si ti yí odiwọn Rẹ pada titi di oni-oloni. Nigba pupọ, a ni lati jẹwọ aṣiṣe ti a ti ṣe, bakan naa nigba ti aṣiṣe yii ba ni ọran owó sisan ninu, a ni lati san án. “Ọlọrun si bère eyi ti o ti kọja lọ” (Oniwasu 3:15).

Jesu fi idi iyipada Sakeu mulẹ nipa sisọ fun un pe,” Loni ni igbala wọ ile yi.” Ohunkohun ti o ba yatọ si iyipada ti yoo mu eso jade fun Ọlọrun lẹṣẹkẹṣẹ, ati ẹri ti Ọlọrun le fọwọ si, ki i ṣe iyipada rara.

Ko si ẹni ti o n ṣe iru iṣẹ ti Sakeu n ṣe yii tabi oniwa bi ti rẹ, tabi ẹni ti o lọla tabi ti o rẹlẹ jù ú lọ, ti o le jẹwọ ni gbangba lati ṣe atunṣe afi bi Ọlọrun bá lọwọ ninu ọrọ naa. O dabi ẹni pe o ti di mimọ fun Sakeu pe atunṣe ṣe dandan. Boya ikaanu fun ẹṣẹ rẹ gba oorun kuro ni oju rẹ ni ọjọ pupọ, bi Ọlọrun ti n ba a sọrọ.

Nigba ti Jesu nawọ ipe si Sakeu, o ni lati jẹ pe o pinnu lati jẹ ipe naa, ohunkohun ti o wu ki o le gbà á. Sakeu jẹwọ ẹṣẹ rẹ fun Jesu o si ṣeleri lati ṣe eyi ti a ba bere lọwọ rẹ, ayọ igbala si gba ọkàn rẹ kan.

Nigba kan Jesu sọ fun awọn akọwe ati Farisi pe, “Lõtọ ni mo wi fun nyin, awọn agbowode ati awọn panṣaga ṣiwaju nyin lọ si ijọba Ọlọrun” (Matteu 21:31). Awọn wọnyii tete wọ ijọba Ọlọrun ṣiwaju ọpọlọpọ. Ki i ṣe pe Ọlọrun fi ọwọ dẹngbẹrẹ mú wọn tabi pe O ṣaanu fun wọn yatọ nitori ẹṣẹ nla wọn, ṣugbọn ó jọ pé wọn tete gba otitọ Ọrọ Ọlọrun gbọ kankan, wọn si ṣetan lati tete jẹwọ pe wọn fẹ ri Kristi, yatọ si awọn ti wọn jẹ olododo loju ara wọn. Sakeu jẹ iru ẹni bẹẹ. O ri pe oun ṣe alaini Kristi ati igbala Rẹ, o si gbá anfaani yii mú bi o ti tọ ọ wá.

Wolii Esekiẹli sọrọ iwuri fun awọn eniyan buburu: “Nigbati emi wi fun eniyan buburu pe, Kikú ni iwọ o kú; bi on ba yipada kuro ninu ẹṣẹ rẹ, ti o si ṣe eyi ti o tọ ti o si yẹ, bi enia buburu ba mu ògo pada, ti o si san ohun ti o ti jí pada, ti o si nrin ni ilana ìye, li aiṣe aiṣedẽde; yiyè ni yio yè, on kì o kú” (Esekiẹli 33:14, 15). Sakeu ṣe bẹẹ. Bakan naa ni ogunlọgọ eniyan ti ṣe bẹẹ lati igba yii, bakan naa ni ẹnikẹni ti o fẹ ri igbala kuro ninu ẹṣẹ wọn le ṣe lọjọ oni. Nipa bẹẹ ni Ọlọrun yoo tẹwọgba wọn.

Ẹri Ọlọrun

Bi a ba di atunbi ni tootọ, ti a si sọ igbesi-aye wa di ọtun nipa agbara awamaridi Ọlọrun, Ọlọrun yoo jẹri si otitọ ẹri wa. Bakan naa ni o ri fun Sakeu, o si wà bakan naa fun gbogbo awọn ti o ri iypada tootọ gbà.

Jesu sọ fun Sakeu pe, “Loni ni igbala wọ ile yi, niwọnbi on pẹlu ti jẹ ọmọ Abrahamu.” Awọn Farisi, ninu ọrọ ti wọn n ba Jesu sọ, a maa fi ẹsin wọn jalankato, wọn a si maa wi pe awọn jẹ ọmọ Abrahamu. Jesu sọ fun wọn pe: “Ibaṣepe ọmọ Abrahamu li ẹnyin iṣe, ẹnyin iba ṣe iṣe Abrahamu. Ṣugbọn nisisiyi ẹnyin nwá ọna ati pa mi, ẹniti o sọ otitọ fun nyin, eyi ti mo ti gbọ lọdọ Ọlọrun: Abrahamu kò ṣe eyi” (Johannu 8:39, 40).

Sakeu ri igbala, o si di ọmọ Abrahamu ni tootọ nitori ó ni igbagbọ ninu Kristi pe Oun ni Olugbala araye. Awọn Farisi, pẹlu ododo ara wọn, ko le di ọmọ Ọlọrun nitori wọn kò gbà pe Kristi ni Messia naa.

Igbagbọ ninu ọrọ Ọlọrun ati ẹri Ọlọrun si awọn iṣẹ Rẹ ni i ṣe ọna si igbala. Nigba gbogbo ni ilẹkun igbala ṣi silẹ fun gbogbo ẹni ti o ba ni igbagbọ ninu Ọlọrun ati Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun, gẹgẹ bi Olugbala araye. Ọna miiran kò sí.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta ni Sakeu i ṣe, ki ni iṣẹ rẹ?
  2. Ki ni ṣe ti awọn eniyan fi korira awọn agbowo-ode?
  3. Ki ni ṣe ti Sakeu fẹ ri Jesu?
  4. Ki ni Jesu wi fun Sakeu nigba ti o ri i lori igi?
  5. Ki ni ẹri idaniloju ti a ní lati fi mọ pe Sakeu ri igbala?
  6. Ki ni a n pè ni eso ironupiwada?
  7. Awọn ta ni i ṣe ọmọ Abrahamu?