Orin Dafidi 66:1-20

Lesson 187 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Bi emi ba gbà ẹṣẹ li aiya mi, Oluwa kì yio gbohùn mi” (Orin Dafidi 66:18).
Cross References

I Titobi Agbara Ọlọrun

1. Gbogbo eniyan ni gbogbo agbaye ni a gbà niyanju lati kọrin iyin si Ọlọrun, Orin Dafidi 66:1, 2; 100:1

2. Ọlọrun yoo mú gbogbo awọn ọta Rẹ wá si itẹriba nipa agbára Rẹ nigba ti o ba to akoko, Orin Dafidi 66:3, 4; 65:5; 18:44; 46:8; Isaiah 45:22, 23

3. Agbara Ọlọrun ká gbogbo ayé ó si wà titi lae, Orin Dafidi 66:5-7; Ẹksodu 14:21; Joṣua 3:14-16

II Idanwo Gbigbona fun Iwẹnumọ

1. A gbà wá niyanju lati fi ibukun fún ati lati yin Ọlọrun Ẹni ti o mu wa wà laaye ti ko si jẹ ki ẹsẹ wa ki o yẹ, Orin Dafidi 66:8, 9; 120:1

2. Oluwa a maa wẹ awọn eniyan Rẹ mọ ninu ileru ipọnju, Orin Dafidi 66:10-12; 17:3; Isaiah 48:10; Sekariah 13:9; 1 Peteru 1:6, 7; 4:12, 13

III Sisan Ẹjẹ

1. Dafidi san awọn ẹjẹ ti o jẹ nigba ti o wà ninu idaamu, Orin Dafidi 66:13-15; 116:14; Oniwasu 5:4

2. O sọ ohun wọnni ti Ọlọrun ti ṣe fun un, Orin Dafidi 66:16, 17; 34:11

3. Bi a ba gba ẹṣẹ laya wa, Oluwa ki yoo gbohun wa, Orin Dafidi 66:18-20; Jobu 27:9; Owe 15:29; Isaiah 1:15; Johannu 9:31; Jakọbu 4:3

Notes
ALAYE

Iyin si Oluwa

Ninu Saamu ologo yii, Dafifi mu diẹ ninu ohun ti Ọlọrun ti ṣe fun araye wá si iranti. ọkan Dafidi kún fun ọpẹ akunwọsilẹ, o si gba gbogbo orilẹ ati ède ni iyanju lati kọrin iyin, ki wọn si fi ọpẹ ati ọlá fun Ọlọrun, ki wọn si hó iho ayọ si Ọlọrun.

Nigba ti a ba ka ibukun wa lotitọ -- lọkọọkan -- ifẹ ati aanu Ọlọrun yoo gba ọkàn wa kan to bẹẹ ti a o fẹ lati ké lohun rara pe: “Ki ohun gbogbo ti o li ẹmi ki o yin OLUWA.”

Ọkan ọpẹ tootọ si Ọlọrun ni o n mu ki orin n imisi. Ki i ṣe pẹlu ohun arò ni Dafidi fi ké si awọn eniyan pe ki wọn fi kọrin iyin si Ọlọrun, ṣugbọn o ké si wọn lati “hó iho ayọ si OLUWA.” “Ẹ mu iyìn rẹ li ogo.” Nigba naa, o sọ asọtẹlẹ kan ti o larinrin nipa Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun ti Kristi ti o n bọ wá: “Gbogbo aiye ni yio ma sìn ọ, nwọn o si ma kọrin si ọ; nwọn o ma kọrin si orukọ rẹ.”

Ipè

Dafidi, Onisaamu, jẹ wolii gẹgẹ bi awa naa ti mọ, titobi iṣẹ Ọlọrun gba aya rẹ kan to bẹẹ ti o fi ké si gbogbo eniyan ni gbogbo aye lati “wá wò iṣẹ Ọlọrun.” Ohun ti Ihinrere wà fun ni eyi. “Ẹnikẹni ti o ba fẹ” ni ipe Ọlọrun wà fún. Ohun kin-in-ni ti a ni lati ṣe ni pe ki a wá, lẹyin eyi ki a si “tọ ọ wò, ki o si ri pe, rere ni OLUWA” (Orin Dafidi 34:8).

Eyi rán wa leti obinrin ara Samaria, nigba ti o ri Messia, o sare pada lọ saarin ilu o si wi fun awọn eniyan rẹ pe, “Ẹ wá, wò….eyi ha le jẹ Kristi na?” (Johannu 4:29).

O si tun rán wa leti igba ti Filippi ri Nataniẹli ti o si sọ fun un nipa Jesu. Nataniẹli kò gbagbọ pe ohun rere kan le ti Nasarẹti jade wá, ṣugbọn Filippi sọ fun un pe, “Wá wò o” (Johannu 1:46). Eyi pẹlu si ni ipe Ihinrere jakejado gbogbo agbaye: “Ẹ wá wò iṣẹ Ọlọrun; o li ẹru ni iṣe rẹ si awọn ọmọ enia.”

Iṣẹ Iyanu Ọlọrun

Onisaamu bẹrẹ si mẹnu ba diẹ ninu ohun ti Oluwa ti ṣe. O ranti iṣẹ iyanu ti O ṣe nigba ti o mu awọn Ọmọ Israẹli jade kuro ni Egipti, ti omi okun di iyangbẹ ilẹ, ti awọn eniyan si fi ẹsẹ rìn ín já. Eyi mu ki ayọ gba ọkàn rẹ kan, o si kigbe pe: “Ẹ fi ibukún fun Ọlọrun wa, ẹnyin enia, ki ẹ si mu ni gbọ ohùn iyìn rẹ.”

Bi a ba farabalẹ ṣiro oore Ọlọrun si wa, ki a si ranti pe O gbà wá lọwọ ẹṣẹ O si da wa nidè kuro ninu igbekun ọta ni ọkàn wa yoo tubọ kún fun ọpẹ si Ọlọrun.

Awọn Eniyan Ti a Ti Yiiri Wò

Laaarin iyin ati ọpẹ si Ọlọrun, Onisaamu ranti pe ki i ṣe igba gbogbo ni a n gbé wọn lori iyẹ apá idì lati ré ipọnju ati wahala kọja. Ọlọrun a maa yiiri awọn eniyan Rẹ wò. O ti sọ pe wọn ni lati jẹ ẹni ti a ti yiiri wò. Ọlọrun mu awọn Ọmọ Israẹli gba ọna aginju lati rẹ wọn silẹ, lati dán wọn wò, lati mọ ohun ti o wà ninu ọkàn wọn. Dafidi sọ ninu Saamu yii pe: “Iwọ mu wa wọ inu àwọn; iwọ fi ipọnju le wa li ẹgbẹ.” Ọlọrun ni ọna pupọ lati yiiri wa wò ti awa kò mọ, O si le yàn lati jẹ ki “ohun kan ti o ṣe ajeji” dé bá ẹnikẹni ninu wa. O jẹ ki awọn ikọ dide lati Babiloni wá sọdọ Hesekiah ki Oun le dán Hesekiah wò ki o le “mọ ohun gbogbo ti o wà li ọkàn rẹ” (2 Kronika 32:31).

Oluwa n dán wa wò lati jẹ ki a mọ ohun ti o wa lọkàn awa tikara wa. O mọ bi a ti wà. O mọ ailera wa. O mọ ikuna wa. Ọgbẹni akọwe kan sọ lootọ pe, “Kò si ẹni ti o le kẹkọọ bi oun ti le mọ inu ara rẹ nibikibi bi ko ṣe lati ọdọ Ẹmi Ọlọrun.” Bi o tilẹ ṣe pe ipọnju ati awọn idanwo ti o de ba wa tilẹ koro, nigba miiran, ti o si dabi ẹni pe a kò tilẹ le fara da kin-n-kinni sii, sibẹ Paulu pe e ni ipọnju wa ti o “fẹrẹ,” o si wi pe wọn n ṣiṣẹ ogo ainipẹkun ti o pọ rekọja fun wa.

Israẹli n gbin dòo labẹ ilagbà awọn akoniṣiṣẹ ni Egipti ki wọn to la ọkun Pupa kọja ni iyangbẹ ilẹ. Wọn la ileru ipọnju kikoro kọja; a si dán wọn wò, bi a ti n dán fadaka wò, ki wọn to ri igbala lati ọdọ Ọlọrun. Ọlọrun a maa jẹ ki a ni iṣoro titi a o fi la iná idanwo kọja. O mọ ohun ti o dara fun wa, a mọ a si gbagbọ pe a n ri ire gbà ninu idanwo kọọkan ti a n la kọja.

Nigba ti Ọlọrun ri i pe ó tó, O mú Israẹli wá si ibi ti o lọrà -- ani Ilẹ Kenaani. Nigba ti O ba si ri i pe idanwo ati wíwẹ ti a n wẹ wá bá to, Oun yoo mu wa bọ sinu ọrọ ibukun ti ẹmi.

Sisan "Ẹjẹ Wa

Nigba ti awọn ọmọ Ọlọrun tootọ ba la ileru ipọnju kọja, ti Ọlọrun si ti mu wọn jade tan, wọn yoo di onirẹlẹ, ọkàn wọn yoo kún fun ọpẹ; gẹgẹ bi ti Dafidi, wọn yoo fẹ lọ si ile Ọlọrun lati lọ san ẹjẹ ti ete wọn ti jẹ nigba ti wọn wà ninu ipọnju. Wọn mọ daju pe Oluwa ni o yọ wọn jade kuro ninu iṣoro wọn, pẹlu ọkàn ọpẹ wọn yoo fi iyin fun Ọlọrun, wọn yoo si fẹ lati maa yin In ninu àwujọ awọn olododo.

Ṣugbọn ọpọlọpọ eniyan ki i pẹ gbagbe ẹjẹ wọn ati ohun gbogbo ti Ọlọrun ti ṣe fun wọn. Wọn kigbe kikan-kikan si Ọlọrun nigba ti wọn wà ninu ipọnju, ṣugbọn nigba ti Ọlọrun bá gbà wọn, wọn ki i pẹ gbagbe Rẹ, wọn a si rò pe wọn le maa ṣe atọkọ ayé wọn. ọrọ Ọlọrun sọ fun ni pe, “Nigbati iwọ ba jẹ ẹjẹ fun Ọlọrun, máṣe duro pẹ lati san a” (Oniwasu 5:4). Iya nla yoo de ba wa bi a ba ṣe alainaani nipa ọran yii. Ọlọrun beere pe ki a san eyi ti a ṣeleri fun Un nigba ti a wà ninu iṣoro.

Nigba ti wọn ba mú ọpẹ ati ẹjẹ wọn wá, awọn Ọmọ Israẹli ni lati mú ọrẹ ẹbọ wá pẹlu – eyi ti o dara ju lọ ninu agbo ẹran wọn, pẹlu “ọrá àgbo.” A ha n ranti lati ṣe eyi nigba gbogbo? “Ọlọrun fẹ oninudidun ọlọrẹ”; ati pe “Ati funni o ni ibukún jù ati gbà lọ.”

Nigba ti ọrẹ wa ba ṣe ohun pataki kan fun ni, ohun ti o n tẹle e ni pe awa naa yoo fẹ san án fun un lọna kan. Nigba ti Oluwa ba si ṣe ohun pupọ fun wa, ohun ti o si n tẹle e lẹsẹkẹsẹ ni pe awa yoo fẹ san an pada fun Un. A ko le san oore ti Ọlọrun ṣe fun wa pada, nitori ko ṣe e ṣe. Ṣugbọn ọrẹ ọpẹ ti dara pọ to! O le jẹ ohun pupọ. Ọlọrun fẹ isin atọkanwa, ifọkansin wa, ẹri wa, ini wa, ati ohunkohun ti O ba fi fun wa. O fẹ gbogbo ohun ti a ní!

Ẹri Kan

Nigba ti Dafidi wo ohun gbogbo ti Ọlọrun ṣe fun Israẹli, o ké si awọn eniyan naa lati “wá wò.” Ṣugbọn lẹyin lilọ si ile Ọlọrun lati san ẹjẹ rẹ ati lati mu ọrẹ ẹbọ rẹ wá, o ke si awọn ẹniyan pe “ẹ wá gbọ.” O fẹ royin ohun ti Ọlọrun ṣe fun ọkàn rẹ. Ẹri naa ti dara to! O fẹ lati sọ ọ! Dajudaju, ẹri kan naa ni o sọ nigba ti o wi pe: “Fi ibukún fun OLUWA, iwọ ọkàn mi, ati gbogbo ohun ti o wà ninu mi, fi ibukún fun orukọ rẹ mimọ. Fi ibukún fun OLUWA, iwọ ọkàn mi, má si ṣe gbagbe gbogbo ore rẹ: Ẹniti o dari gbogbo ẹṣẹ rẹ jì; ẹniti o si tan gbogbo àrun rẹ. Ẹniti o ra ẹmi rẹ kuro ninu iparun; ẹniti o fi iṣeun-ifẹ ati iyọnu de ọ li ade: Ẹniti o fi ohun didara tẹ ọ lọrun: bẹẹni igba ewe rẹ di ọtun bi ti idì” (Orin Dafidi 103:1-5). O ti san ẹjẹ rẹ. O ti mú ọrẹ rẹ wá fun Ọlọrun. O ti mú ọrẹ ọpẹ wá si ile Ọlọrun. Nitori idi eyi, Ọlọrun bukun fun un.

Ẹṣẹ -- Ohun Idena

Lẹyin ti a ba ka iru ẹri bayii tán, a o ri i pe ọkàn Dafidi mọ laulau. O mọ pe Ọlọrun gbọ adura oun. O mọ pe ohun danindanin ni lati ri i pe Ọlọrun gbọ adura oun. O wi pe: “Bi emi ba gbà ẹṣẹ li aya mi, Oluwa ki yio gbohùn mi: ṣugbọn nitõtọ Ọlọrun ti gbohùn mi.” Eyi pẹlu si tun jẹ ẹri pe olododo ni Dafidi i ṣe. Kò si ẹṣẹ ni àyà rẹ. Ọkan rẹ pe si Ọlọrun.

Ẹṣẹ n ya ni ya Ọlọrun. Bi a ba gba ẹṣẹ laye lọkàn wa, a kò le wa lailẹbi niwaju Ọlọrun. Ki ọkàn kan to le ni idalare niwaju Ọlọrun, ó ni lati kọ ẹṣẹ silẹ. O ni lati yipada kuro ninu ẹṣẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ki ó si sọ fun Ọlọrun pe oun kò ni i fi ẹṣẹ ṣe mọ. Nigba ti ó ba ṣe eyi, adura rẹ yoo goke lọ si Ọrun, Ọlọrun yoo si boju wolẹ, yoo si dari ẹṣẹ rẹ jì í. Ẹmi Ọlọrun yoo fi Ẹjẹ Jesu wẹ ẹbi ẹṣẹ rẹ kuro, yoo si wà ni ailẹbi niwaju Ọlọrun. Nigba naa ni o to le kọrin iyin kikan si Ọlọrun ki o si sọ, pẹlu Dafidi pe, “Olubukún li Ọlọrun, ti kò yi adura mi pada kuro, tabi ãnu rẹ kuro lọdọ mi.”

Saamu yii jẹ orin iyin ti o gbamuṣe, koko rẹ si ni ipè lati kọrin, lati yọ ati lati fi ibukún fun Ọlọrun. Orin gbogbo Onigbagbọ tootọ ni eyi, ani ti ẹni kọọkan ninu agboole igbagbọ, ati ti ẹni kọọkan ninu awọn ẹgbẹ Onigbagbọ tootọ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni kókó ti Saamu yii dá le lori?
  2. Ta ni Dafidi fẹ ki o kọrin naa?
  3. Ki ni ṣe ti Dafidi fi lọ si ile Ọlọrun?
  4. Ki ni o ṣe nibẹ?
  5. Ki ni ṣe ti Ọlọrun n dán awọn eniyan Rẹ wò?
  6. Nigba wo ni Ọlọrun kò ni gbọ adura wa?