Awọn Onidajọ 2:1-23; Numeri 33:50-53; Joṣua 23:11-13

Lesson 188 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹ kò mọ pe ìbarẹ aiye iṣọtá Ọlọrun ni? nitorina ẹnikẹni ti o ba fẹ lati jẹ ọrẹ aiye di ọtá Ọlọrun” (Jakọbu 4:4).
Cross References

I Aṣẹ, Ikilọ ati Aigbọran

1. Aṣẹ lati lé awọn olugbe Kenaani jade wá lati ipasẹ Mose, Numeri 33:50-53

2. A tipasẹ Joṣua rán ikilọ, Joṣua 23:11-13

3. Angẹli Oluwa bá aigbọran Israẹli wí, Awọn Onidajọ 2:1-5

II Igbọran ni Akoko Joṣua

1. A gba ilẹ naa, Awọn Onidajọ 2:6

2. Awọn eniyan naa sin Oluwa, Awọn Onidajọ 2:7

3. Joṣua kú, Awọn Onidajọ 2: 8, 9

III Ipada Sẹyin Awọn Iran Titun

1. Wọn kò mọ Oluwa, Awọn Onidajọ 2:10

2. Wọn tọ awọn ọlọrun miiran lẹyin, Awọn Onidajọ 2:11-13

3. A rán idajọ Ọlọrun si wọn, Awọn Onidajọ 2:14, 15

IV Ibẹrẹ Akoko Awọn Onidajọ

1. Oluwa gbé awọn onidajọ dide, Awọn Onidajọ 2:16-19

2. Ọlọrun binu nitori aigbọran Israẹli igba gbogbo, Awọn Onidajọ 2:20 – 23

Notes
ALAYE

Ni pẹtẹlẹ Moabu ti o ni koriko ni iha ihin Odo Jordani lati Jeriko, Mose rán awọn eniyan Israẹli leti ọrọ Oluwa. Opin iṣakoso Mose kù si dẹdẹ. O ti di ẹni ọgọfa (120) ọdun, ṣugbọn oju rẹ kò ṣe baibai, agbara rẹ kò si dinku. Ohùn rẹ là keteke, kò si aleebu kan ninu awọn ọrọ itọni wọnyii bi awọn eniyan ti n fi eti ara wọn gbọ ọ: “Nigbati ẹnyin ba gòke odò Jordani si ilẹ Kenaani: nigbana ni ki ẹnyin ki o lé gbogbo awọn ara ilẹ na kuro niwaju nyin; ki ẹnyin si run gbogbo aworán wọn, ki ẹnyin si run gbogbo ere didà wọn, ki ẹnyin si wó gbogbo ibi giga wọn palẹ: ki ẹnyin ki o si gbà ilẹ na” (Numeri 33:51-53).

Iwa Mimọ

Awọn eniyan ti o n gbe ilẹ Kenaani ṣiwaju awọn Ọmọ Israẹli jẹ eniyan buburu. Kenaani jẹ ilẹ ti o dara, ilẹ ti Ọlọrun fẹ. Ọlọrun fẹ ẹ fun awọn eniyan Rẹ, ṣugbọn O fẹ ki a wẹ ẹ mọ. Awọn eniyan Rẹ ko gbọdọ dapọ mọ awọn alaiwa-bi-Ọlọrun tabi ki wọn tọ ọna ibọriṣa wọn. Awọn Ọmọ Israẹli ni lati jẹ orilẹ-ède mimọ. Ọlọrun fẹ ki ilẹ wọn jẹ mimọ, wọn kò gbọdọ da awọn ohun-ọsin wọn kan pọ mọ iru miiran, wọn kò si gbọdọ gbin oniruuru ohun ọgbin pọ si oko kan naa. Ọlọrun fẹ iwa mimọ. Ẹsẹ ati ododo kò le dà pọ. Bi iwọ ba fẹ gbe igbe ayé iwa-bi-Ọlọrun, o ni lati kọ ẹṣẹ silẹ patapata.

Lé awọn olugbe ilẹ naa jade; pa gbogbo ere yiyá ati aworan oriṣa run; si wo ibi giga wọn lulẹ. Kò si aafo fun ẹṣẹ ni ilẹ mimọ. A kò gbọdọ ba a ṣọrẹ, a kò gbọdọ gba a laye, bẹẹ ni a ko gbọdọ fọwọ kan an. Wo o lulẹ, lé jade, pa a run! Ẹṣẹ buru jai. Ẹṣẹ kan -- iṣubu de; aigbọran kan – Paradise a si bọ sọnu. Ọlọrun leto ohun ribiribi fun Israẹli. Wọn yoo jẹ olu alufaa orilẹ-ède mimọ. Nipaṣẹ wọn ni awọn orilẹ-ede gbogbo yoo fi ni imọ Ọlọrun otitọ. Ṣugbọn wọn kùna ipinnu Ọlọrun fun wọn. Wọn gbọjẹgẹ pẹlu ẹṣẹ, wọn si kùna lati lé awọn olugbe ilẹ naa jade. Ikilọ Joṣa ṣẹ: “Wọn o jẹ okùn-didẹ ati ẹgẹ fun nyin, ati paṣán ni ìha nyin, ati ẹgún li oju nyin” (Joṣua 23:13).

Itọni Kò Sí

Lẹyin ikú Joṣua ati awọn ti o mọ ọn, ti akoko rẹ si rú ifẹ wọn soke, awọn iran miiran dide ti kò mọ Oluwa. O ha le jẹ pe awọn obi wọn kò jẹ olotitọ to lati kọ awọn ọmọ wọn ni ofin Ọlọrun ti o wi pe: “Ati ọrọ wọnyi, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, ki o ma wà li àiya rẹ: ki iwọ ki o si ma fi wọn kọ awọn ọmọ rẹ gidigidi, ki iwọ ki o si ma fi wọn ṣe ọrọ isọ nigbati iwọ ba joko ninu ile rẹ, ati nigbati iwọ ba nrìn li ọna, ati nigbati iwọ ba dubulẹ, ati nigbati iwọ ba dide” (Deuteronomi 6:6, 7). Awọn obi pupọ lonii ni kò naani lati ma ka Ọrọ Ọlọrun fun awọn ọmọ wọn, wọn si ti ipa bẹẹ n já Ọlọrun tilẹ. Wọn ni anfaani ti o logo lati funrugbin otitọ si ọkàn awọn ọmọ ti n bẹ labẹ wọn, ṣugbọn wọn n kùna lati ṣe bẹẹ.

Ailọpẹ

Ọlọrun jẹ olotitọ si awọn iran yii ti kò mọ Ọn. O rán angẹli Rẹ, o tilẹ le jẹ pe Jesu Kristi tikara Rẹ ni. A gbagbọ pe Jesu ni O fi ara han fun Joṣua gẹgẹ bi “olori ogun OLUWA.” Onṣẹ lati Ọrun wá yii sọrọ taṣẹtaṣẹ. “Emi mu nyin gòke lati Egipti wá, emi si mú nyin wá si ilẹ ti emi ti bura fun awọn baba nyin; emi si wipe, Emi ki yio dà majẹmu mi pẹlu nyin lailai: Ẹnyin kò si gbọdọ bá awọn ara ilẹ yi dá majẹmu; ẹnyin o wó pẹpẹ wọn lulẹ: ṣugbọn ẹnyin kò gbọ ohùn mi: Ẽha ti ṣe ti ẹnyin fi ṣe yi?”

“Ẽha ti ṣe ti ẹnyin fi ṣe yi?” Ọkan imoore nikan tó lati mú ki wọn gbọran si Ọlọrun lẹnu. Oluwa ti gbà wọn kuro ni oko-ẹru, O mú Okun pupa gbẹ, O fi manna bọ wọn fun ogoji ọdun ni aginju, O ja fun wọn, O si ti fi ilẹ rere yii fun wọn. Ọkàn imoore fun aanu Ọlọrun yẹ ki o fun awọn eniyan ni ifẹ lati sin Ọlọrun lọjọ oni. Ifẹ Ọlọrun ni fifi Ayanfẹ Ọmọ Rẹ funni lati jẹ etutu fun wa, yẹ ki o mu ki a rìn ni irẹlẹ niwaju Rẹ ni gbogbo ọjọ ayé wa. Ẹ jẹ ki a ro ara wa si onde ti o jẹbi ikú. Baba fi Ọmọ Rẹ ṣe irapada wa. Wọn pa Ọmọ Rẹ, a si tu wa silẹ. A kò ha jẹ Baba ati Ọmọ ni gbese ọpẹ?

Awọn Apẹẹrẹ

Wọn jẹ gbese ọpẹ pupọ, igbesi-ayé wọn paapaa rọ mọ ṣiṣẹ ifẹ Ọlọrun. “Nitoripe ki iṣe ohun asan fun nyin; nitoripe ìye nyin ni” (Deuteronomi 32:47). Ki i ṣe pe a tilẹ tẹ otitọ yii mọ wọn leti nipa sisọ ọ ni asọtunsọ ninu Ofin nikan, ṣugbọn ọpọlọpọ apẹẹrẹ ninu itan igbesi-ayé wọn fihàn bẹẹ. Wo apẹẹrẹ Akani ati iṣubu wọn ni Ai. Awọn ẹgbaa meje o le ẹẹdẹgbẹrin (14,700) ti o kú nigba ti Oluwa rán ejò amubina si wọn? Igbesi-ayé wọn rọ mọ igbọran ṣugbọn wọn ṣaigbọran. Abajọ ti angẹli Oluwa nì fi beere pé, “Ẽha ti ṣe ti ẹnyin fi ṣe yi?”

Aileduro

Bi Israẹli tilẹ sọkun ti wọn da omi loju pẹrẹpẹrẹ, ti wọn si rubọ si Oluwa, ọkàn wọn kò pẹ yà kuro si awọn ohun ti ayé yii. O dabi ẹni pe o rọrun fun wọn lati jọgọ silẹ! Igbesi-ayé Onigbagbọ lonii ni lati gbé ihamọra rẹ wọ ki o si maa ja ija rere ti igbagbọ. Ijafara ati aibikita kò pẹ sun ni si kikọ Oluwa silẹ lati maa sin ọlọrun ayé yii. A le gba iṣẹ ati afẹ layè lati gbá ifẹ Ọlọrun kuro lọkan wa.

Awọn Onidajọ

“OLUWA si gbé awọn onidajọ dide, ti o gbà wọn li ọwọ awọn ẹniti nkó wọn lẹrù” (Awọn Onidajọ 2:16). Ẹsẹ yii ati iyokù ori iwe yii dabi ẹni pe ó kó akopọ itan igbesi-ayé awọn Ọmọ Israẹli ni akoko awọn onidajọ lati Otniẹli titi de Samuẹli. Gideoni, Samsoni, Jefta, ati Samuẹli wà ninu awọn onidajọ wọnyii, pẹlu awọn miiran, nipa awọn ẹni ti Ọlọrun sọ bayii pe, “Awọn ẹni nipasẹ igbagbọ ti nwọn ṣẹgun ilẹ ọba, ti nwọn ṣiṣẹ ododo, ti nwọn gbà ileri, ti nwọn dí awọn kiniun li ẹnu, ti nwọn pa agbara iná, ti nwọn bọ lọwọ oju-idà, ti a sọ di alagbara ninu ailera, nwọn di akọni ni ìja, nwọn lé ogun awọn àjeji sá” (Heberu 11:33, 34).

Itan igbesi-aye awọn Ọmọ Israẹli ni akoko awọn onidajọ jẹ kiki ikuna, ṣugbọn aanu nla Ọlọrun fara hàn ninu eyi pe, nigba ti wọn ba n gbin labẹ inilara, Oluwa a gbé awọn onidajọ dide lati gbà wọn lọwọ awọn ọta wọn ni gbogbo ọjọ awọn onidajọ wọnni. Israẹli fihan pé, “OLUWA li alãnu ati olõre, o lọra ati binu, o si pọ li ãnu” (Orin Dafidi 103:8).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Nibo ni Gilgali wà? Ki ni ṣẹlẹ nibẹ?
  2. Ki ni ṣe ti a ni lati lé awọn olugbe Kenaani jade?
  3. Ki ni ẹsun ti a fi Israẹli sùn?
  4. Ki ni idajọ ti angẹli naa fi lé wọn lori?
  5. Ipá wo ni igbesi-ayé Joṣua ni lori Israẹli?
  6. Ẹni ọdun meloo ni Joṣua nigba ti ó kú?
  7. Fi ikilọ ti o wà ninu Joṣua 23:11-13 wé iṣẹ ti angẹli nì wá jẹ.
  8. Lọna wo ni ikilọ yii fi jọ ikilọ ti Mose ṣe ninu Numeri 33:50-53?
  9. Darukọ diẹ ninu awọn Onidajọ Israẹli.
  10. Ki ni ṣe ti Ọlọrun kò fi gbogbo orilẹ-ède Kenaani lé Joṣua lọwọ patapata?