Awọn Onidajọ 3:1-31

Lesson 189 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Bi aiṣedede kan ba mbẹ lọwọ rẹ, mu u kuro si ọna jijin rére, máṣe jẹ ki iwàkiwa ki o wà ninu agọ rẹ” (Jobu 11:14).
Cross References

I Otnieli

1. A fi awọn orilẹ-ède Kenaani diẹ silẹ lati fi wọn dán Israẹli wò, Awọn Onidajọ 3:1-4

2. A ta Israẹli si ọwọ ọba Mesopotamia, Awọn Onidajọ 3:5-8

3. Otnieli gba Israẹli silẹ, Awọn Onidajọ 3:9-11

II Ehudu

1. Israẹli sin Moabu, Awọn Onidajọ 3:12-14

2. Ehudu ṣẹgun Moabu, Awọn Onidajọ 3:15-30

III Ṣamgari

1. Ṣamgari gba Israẹli silẹ kuro lọwọ awọn Filistini, Awọn Onidajọ 3:31

Notes
ALAYE

Ibi Idanwo

“Njẹ wọnyi li awọn orilẹ-ède ti OLUWA fisilẹ, lati ma fi wọn dan Israẹli wò.” Eniyan fẹrẹ le maa ro o wò pé ki ni ṣe ti Ọlọrun ni lati fi awọn eniyan orilẹ-ẹde Keferi wọnyii silẹ lati jẹ idẹkùn ati idanwo fun Israẹli. Ki ni ṣe ti O fi gba oludanwo layè lati wọ Ọgbà Edẹni? A le foju wo o bi ẹkọ ti a n kọ awọn ọmọ-ogun lati gba ibi iṣoro gbogbo kọja lailewu. Ni akọkọ, ẹkọ naa nira, ṣugbọn bi o ti n fo awọn ohun idena ati ohun idabu gbogbo kọja, ọmọ-ogun yoo lagbara, yoo si ni okun lati dojukọ iṣoro ti o wù ki o bá pade nigbakuugba.

Iná ni a fi n dán wura. A sọ fun ni pe awọn igi nla ti o wà lori oke nibi ti iji n jà a maa lagbara ju awọn ti o wà ni afonifoji nibi ti iji kò si. Iṣẹ ṣiṣe ni o n mu egungun lagbara. Bi a ti n fi iṣẹ ara mú egungun wa le sii bẹẹ naa ni igbagbọ wa ti n le sii nipa ṣiṣe amulo rẹ. Peteru sọ fun ni pe: “Nisisiyi fun igba diẹ, niwọnbi o ti yẹ, a ti fi ọpọlọpọ idanwo bà nyin ninu jẹ: ki idanwo igbagbọ nyin, ti o ni iye lori jù wura ti iṣegbe lọ, bi o tilẹ ṣe pe iná li a fi ndán a wò, ki a le ri i fun iyìn, ati ọlá, ati ninu ogo ni igba ifarahàn Jesu Kristi” (1 Peteru 1:6, 7). Awọn alagbara ninu igbagbọ ni awọn ti a ti danwò.

Nipa idanwo ni suuru fi n pọ sii, nitori a ka a pe, “idanwò igbagbọ nyin nṣiṣẹ sũru” (Jakọbu 1:3). Iwe Mimọ tun sọ fun ni pe, “ibukún ni fun ọkọnrin ti o fi ọkàn rán idanwò: nitori nigbati o ba yeje, yio gbà ade iye, ti Oluwa ti ṣe ileri fun awọn ti o fẹ ẹ” (Jakọbu 1:12). Ohun rere ni fun awọn onigbagbọ lati ranti laaarin idanwò pe, “Ohun gbogbo li o nṣiṣẹ pọ si rere fun awọn ti o fẹ Ọlọrun” (Romu 8:28). Eyi yoo fun un ni ikiya, agbara ati igboya ni akoko idanwò, ki o le yege bi wura ti a ti dà ninu iná.

Ọjẹgẹ

“Awọn Ọmọ Israẹli si joko lãrin awọn ara Kenaani ……. nwọn si fẹ awọn ọmọbirin wọn li aya, nwọn si fi awọn ọmọbirin wọn fun awọn ọmọkunrin wọn, nwọn si nsìn awọn oriṣa wọn.” Lọna kin-in-ni, awọn awọn Ọmọ Israẹli kọwọ bọ ẹṣẹ nipa biba awọn ara Kenaani gbé pọ, ati nipa didapọ mọ wọn, ati lopin rẹ, nipa sisin ọlọrun wọn.

Lati inu ohun kekere ni igbọjẹgẹ ti n bẹrẹ. Ijọgọ silẹ diẹ nihin, rírẹ odiwọn igbagbọ silẹ diẹ lọhun, nigba naa ẹṣẹ á rọ wọle, iduro Onigbagbọ a bọ sọnu, ati ni opin rẹ a o bẹrẹ si sin awọn ọlọrun ayé yii patapata.

Awọn miiran wà ti o fẹ pa gbogbo awọn ẹsin pọ ṣọkan sabẹ alakoso kan. Wọn n wá ọna lati maa bá ara wọn ṣe pọ. Iru igbekalẹ bayii a maa sún ni lati gbọjẹgẹ lori ẹkọ ati ilana Bibeli, eyi lodi si ifẹ Ọlọrun. Ofin beere pe, “Bi arakọnrin rẹ, ọmọ iya rẹ, tabi ọmọ rẹ ọkọnrin, tabi ọmọ rẹ obirin, tabi aya õkan-àiya rẹ, tabi ọrẹ rẹ, ti o dabi ọkàn ara rẹ, bi o ba tàn ọ ni ikọkọ, wipe, Jẹ ki a lọ ki a ma sìn ọlọrun miran…..pipa ni ki o pa a” (Deuteronomi 13:6, 9). Bakan naa ni Paulu Aposteli mu irú iduro bayii nipa ti ẹmi nipa awọn ti o n yí Ihinrere Kristi pada. O sọ bayii pe, “Ṣugbọn bi o ṣe awa ni, tabi angẹli kan lati ọrun wá, li o ba wasu ihinrere miran fun nyin ju eyiti a ti wasu fun nyin lọ, jẹ ki o di ẹni ifibu” (Galatia 1:8).

Onidajọ Kin-in-ni

Nigba ti Israẹli gbọran si Ọlọrun lẹnu, kò si ọkunrin kan ti o lè duro niwaju wọn; ṣugbọn nigba ti wọn dẹṣẹ, Ọlọrun tà wọn si ọwọ awọn ọta wọn. Ọba Mesopotamia ni ajeji ti o kọ gbógun tì wọn, ilu kan ni oke ariwa ilẹ Palẹstini, o si jinna niwọn ọpọlọpọ mile. Fun ọdun mẹjọ ni ọba ajeji yii fi pọn Israẹli loju titi Israẹli fi kigbe si Ọlọrun. Nigba naa ni Ọlọrun gbé onidajọ kin-in-ni ti a n pè ni Otnieli ọmọ arakunrin Kalebu dide.

Kalebu ni eniyan Ọlọrun ti o duro gangan, pẹlu Joṣua, ti wọn si mu ihinrere pada tọ Mose wá nipa ilẹ Kenaani. Mẹwaa ninu awọn amin wi pe: “Alagbara ni awọn enia ti ngbé inu ilẹ na, ilu olodi si ni ilu wọn, nwọn tobi gidigidi: ati pẹlupẹlu awa ri awọn ọmọ Anaki nibẹ” (Numeri 13:28). Ṣugbọn Kalebu ni ẹmi miran. O fẹ goke lọ lati gba ilẹ naa. Ni ogoji ọdun lẹyin eyi, nigba ti o di ẹni aadọrun ọdun o din marun un, Kalẹbu beere pe ki a fi Oke Hebroni fun oun ni ini. Oke Hebroni, nibi ti awọn ọmọ Anaki n gbé pe igbagbọ ọkunrin akin ati eniyan Ọlọrun yii nijà.

Otnieli, ọmọ arakunrin Kalebu, pẹlu ni iru ẹmi ti o tayọ ti o wà ninu Kalebu yii. Nigba ti Kalẹbu wi pe, “Ẹniti o ba kọlù Kiriati-seferi, ti o sì kó o, on li emi o fi Aksa ọmọbirin mi fun li aya” (Awọn Onidajọ 1:12), Otnieli ni o gba ilu yii. Nigba ti Ẹmi Ọlọrun bà lé Otniẹli, o lọ si ogun o si gba Israẹli kuro lọwọ ọba Mesopotamia. Ọlọrun wà pẹlu Otnieli, ilẹ naa si sinmi fun ogoji ọdun.

Igbe fun Aanu

“Awọn Ọmọ Israẹli si tun ṣe eyiti o buru li oju OLUWA; OLUWA si fi agbara fun Egloni ọba Moabu si Israẹli.” Bawo ni itan igbesi-ayé awọn Ọmọ Israẹli ì bá ti yatọ to! “Ibaṣepe nwọn gbọn, ki oyé eyi ki o yé wọn, nwọn iba rò igbẹhin wọn!” (Deuteronomi 32:29). O dabi ẹni pe Ẹni ti O gbe Israẹli lori “iyẹ idi” ti kọjuja si wọn O si ti fun awọn ọta wọn lagbara si wọn. Fun ọdun mejidinlogun (18) ni wọn fi sin ọba Moabu nitori wọn ṣaigbọran si ofin Ọlọrun. Ọpọlọpọ eniyan ni o wà ninu igbekun lonii nitori ẹṣẹ. Ọwọ eṣu yoo tubọ maa le sii lara ẹlẹṣẹ titi yoo fi mọ pe o yẹ ki oun ke pe Ọlọrun fun idande kuro ninu ipọnju yii, bi o ba fẹ bọ lọwọ egbé ayeraye. Ọlọrun ninu aanu Rẹ a maa feti si igbe ẹlẹṣẹ ti o ba ronupiwada. O gbé olugbala dide fun Israẹli, Ehudu ọmọ Gera, ẹya Bẹnjamini, ọlọwọ-osi.

Ohun Ija

Ehudu rọ idà oloju-meji. Ohun ijà ọmọ Ọlọrun ki i ṣe ti ara ṣugbọn “o li agbara ninu Ọlọrun lati wó ibi giga palẹ” (ll Kọrinti 10:4). A paṣẹ fun Onigbagbọ lati “gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ, ki ẹnyin ki o le kọ oju ija si arekereke Eṣu” (Efesu 6:11). A ni ogun kan lati jà, ogun naa ki i ṣe ogun yẹpẹrẹ; ṣugbọn a ni Balogun kan ti kò sọ ogun kan nù ri. A le ja ija rere ti igbagbọ pẹlu idaniloju yii pe Oun yoo mu wa là á já.

Ọlọrun fun ọlọwọ-osi ẹya Bẹnjamini yii ni igboya lati dojuja kọ ọta ni ilẹ ara rẹ pẹlu idà agbelẹrọ lasan. O gún un lẹẹkan ṣoṣo, ṣugbọn ó ṣe é pẹlu gbogbo agbara rẹ. Ki Ọlọrun ran awọn ajagun Rẹ lọwọ lonii lati fi gbogbo igbagbọ ati agbara wọn dojuja kọ ẹṣẹ! Egún wà lori ẹnikẹni ti o ba n fi imẹlẹ ṣiṣẹ Ọlọrun tabi “ẹniti o dá idà rẹ duro kuro ninu ẹjẹ. Nipa akoso Ehudu gẹgẹ bii aṣiwaju a bi Moabu wó, ilẹ naa si sinmi fun ọgọrin (80) ọdun.

Ṣamgari

Itan Ṣamgari kò gun, ṣugbọn a kò gbọdọ foju yẹpẹrẹ wo ẹni ti o ba le fi ọpa ti a fi n da maluu pa ẹgbẹta (600) ọkunrin. Ọlọrun lo Ṣamgari, Ṣamgari si lo ohun ti o wà lọwọ rẹ. Ọpọlọpọ eniyan le jokoo ki wọn si maa kẹdun pe wọn kò ni talẹnti tabi ohun ijà, ṣugbọn Ṣamgari mu ọpá ti o fi n da maluu, o si lọ soju ijà. O gba Israẹli là.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti Ọlọrun fi diẹ ninu awọn ara Kenaanin silẹ ni ilẹ naa?
  2. Wá ẹsẹ kan ninu Bibeli ti o kọ fun awọn Ọmọ Israẹli lati gbé awọn ara Kenaani niyawo.
  3. Ẹkọ ti o fara jọ eyi wo ni o wà ninu Majẹmu Titun nipa igbeyawo?
  4. Ta ni onidajọ kin-in-ni ni Israẹli?
  5. Bawo ni a ṣe yàn án?
  6. Ilu wo ni o kọ ṣẹgun awọn Ọmọ Israẹli ni akoko awọn onidajọ?
  7. Awọn ara Moabu meloo ni a pa ninu ogun ti a jà ni iwọdo Jordani?
  8. Ọdun meloo ni ilẹ naa fi ni isinmi lẹyin ti Otniẹli gbà wọn silẹ? ati Ehudu
  9. Ẹkọ wo ni a ri kọ ni igbesi-ayé Ṣamgari?
  10. Ki ni ọpa ti a fi n da maluu?