Awọn Onidajọ 4:1-24; Heberu 11:32-40

Lesson 190 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI:“Ẹgbẹ gbogbo awọn ti o bẹru rẹ li emi, ati ti awọn ti npa ẹkọ rẹ mọ” (Orin Dafidi 119:63).
Cross References

I Apa Kan Ere Ẹṣẹ Israẹli

1. Awọn Ọmọ Israẹli ṣe buburu, wọn si yan ọlọrun titun, Awọn Onidajọ 4:1; 5:8; Ẹksodu 20:2-6; Lefitiku 26:1; Joṣua 23:6-16

2. Ọlọrun fi awọn ara Kenaani ṣe paṣan lati jẹ awọn Ọmọ Israẹli niyà, Awọn Onidajọ 4:2, 3; 5:6-8; Oniwasu 2:26; Romu 6:23; 2 Peteru 2:12, 13

3. Akoko ipọnju naa tubọ n gùn bi awọn Ọmọ Israẹli tun ti n dẹṣẹ si i, Awọn Onidajọ 3:8, 14; 4:3; Owe 13:15

II Ileri Idasilẹ ati Awọn Ohun-elo ti Ọlọrun Lò

1. Ọlọrun a maa gbọ igbe ironupiwada tootọ, Awọn Onidajọ 4:3; Orin Dafidi 34:18; Isaiah 63:7-9; 65:24; Mika 7:18

2. Ọlọrun ni awọn iranṣẹ ati aṣoju paapaa ni akoko ipọnju ti o buru ju lọ, Awọn Onidajọ 4:4, 5; Isaiah 1:9; 1 Awọn Ọba 19:18; Romu 11:5; Heberu 11:32-40

3. A pe Baraki a si rán an lati ṣiwaju ogun Israẹli, Awọn Onidajọ 4:6, 7; Jobu 5:17-22

4. Baraki fi iwa-bi-Ọlọrun hàn ni jijẹ ipe Ọlọrun, Awọn Onidajọ 4:8-10; Ẹksodu 33:12-17; l Kronika 21:13

III Idasilẹ fun Ọkàn ti o ba Ronupiwada, Egbé fun Ọkàn ti Kò ba Ronupiwada

1. Awọn ọta ran Sisera lọwọ lati lepa awọn Ọmọ Israẹli, Awọn Onidajọ 4:11-13, 17; Orin Dafidi 33:12-19

2. Deborah ki Baraki laya o si sọ aṣẹ Oluwa fun un, Awọn Onidajọ 4:14; Ẹksodu 33:2; Joṣua 1:9

3. Ọlọrun gbeja Israẹli, O pa awọn ọta run, Awọn Onidajọ 4:15, 16; 5:20-22; Joṣua 23:5

4. Aabo ti ayé yii ati majẹmu iranlọwọ pẹlu eniyan kò le dá idajọ Ọlọrun duro lọnakọna, Awọn Onidajọ 4:17; Isaiah 28:15-18; Amosi 9:10; Obadiah 3; Luku 12:16-21

5. Iparun awọn ara Kenaani ati idasi awọn Ọmọ Israẹli, fi idajọ Ọlọrun hàn lori awọn oluṣe buburu ati aanu Rẹ si awọn olododo, Awọn Onidajọ 4:18-24; Orin Dafidi 37:1-40

Notes
ALAYE

Kíkùn ati Ibọriṣa

O fẹrẹ jẹ pe ohun kan naa ni on ṣẹlẹ si awọn Ọmọ Israẹli leralera lati ọdunmọdun, ni akoko awọn onidajọ, lẹyin ikú Mose ati Joṣua, ti awọn Ọmọ Israẹli si maa n wà ninu ipọnju nigba pupọ. Gẹrẹ ti onidajọ kan ba ti kú, Israẹli a “si tun ṣe eyiti o buru li oju OLUWA,” idajọ Oluwa a si wá sori wọn. Otitọ gan an ni orukọ “ọmọ” ti a fi n pè wọn, nitori o dabi ẹni pe wọn kò le ṣe ohun rere kan lai si alakoso rere kan lati fi ọna hàn wọn, ki o si fẹsẹ wọn mulẹ soju ọna naa. Kíkùn si Ọlọrun ati awọn ohun ti O pese fun wọn ni o n fa iṣubu igbakuugba ti wọn ni ni aginju. Ṣugbọn nisisiyii, ni Ilẹ Ileri, ibi ti ọkàn wọn n tẹ sí ni ibọriṣa.

Ọlọrun ti ṣeleri isimi, alaafia, ọrọ ati wiwa lailewu ni Kenaani, fun awọn Ọmọ Israẹli, bi wọn ba pa awọn orilẹ-ède ti o wà ni ilẹ naa run, ki wọn si mu ohunkohun ti o le mu ki wọn fà sẹyin kuro lọdọ Ọlọrun kuro. O ṣeleri lati jẹ Ọlọrun wọn – Oludande wọn kuro ninu ẹṣẹ -- bi wọn ba tẹle E. Ṣugbọn wọn kuna ninu eyi. Wọn kò bikita lati tẹle ilana Ọlọrun pe ki wọn pa orilẹ-ède Kenaani abọriṣa run patapata; nitori idi eyi, awọn Keferi wọnyii mu wọn ṣina, nitori ọkàn awọn “ọmọ” -- ọpọ awọn Ọmọ Israẹli, ogunlọgọ ti kò tẹle Ọlọrun ki wọn si gbé ododo Rẹ wọ nipa ipese mimọ ti Ọlọrun ti ṣe silẹ ani Ẹjẹ Majẹmu Ayeraye nì – ko ṣafẹri awọn “ohun ti mbẹ loke” gẹgẹ bi ọkàn Abrahamu baba wọn ti o “nreti ilu ti o ni ipilẹ; eyiti Ọlọrun tẹdo ti o si kọ.” Dipo eyi, ifẹ ati ọkàn wọn wà ninu “ohun aiye yi”; nitori eyi, wọn di ijẹ lọwọ Satani, ọta ẹmi ọmọ eniyan, ẹni ti o n fẹ gbé ijọba ti o tako ti Ọlọrun kalẹ.

“ọna Awọn Olurekọja” ati Ilana Ọlọrun

Yiya ti Israẹli yà sinu ibi lẹyin ikú Ehudu kó wọn si wahala ti o koro gidigidi. Nitori eyi, awọn ara Kenaani pọn wọn loju fun ogun (20) ọdun. Opopo ọna ilẹ naa dá awọn arinrin-ajo si n rin àbùjá ọna dipo òpopo ọna. Awọn ti o wà ni ileto wọn kekeke ti kò ni odi silẹ lati lọ si ibi ti wọn yoo gbé wà labẹ aabo. Ogun wà lẹyin odi ilu wọn, kò si si ọkọ tabi idà kan lọwọ awọn eniyan ọkẹ meji (40,000) ni iha ihin yii, ni ilẹ Israẹli. Eyi de ba wọn nitori wọn tọ ọlọrun miiran lẹyin, wọn si kọ Ọlọrun Abrahamu, Isaaki ati Jakọbu, awọn baba wọn silẹ. Bi ọna olurekọja ti ri ni eyi!

Bi ipọnju wọn tilẹ dabi ẹni pe o buru loju wọn, “ère” ti o tọ ti ẹṣẹ n mu wa ni eyi, ti yoo si mu wa ba ẹnikẹni ti kò ba ronupiwada ki o si yipada si Ọlọrun tọkantọkan. Ere yii kò ṣe yẹ silẹ. Ọgbọn mẹbẹmẹyẹ kan kò le da a duro. Kò si ohun ti o le sun ọjọ ẹsan yii siwaju. Ikú ni ère ẹṣẹ, ọna kan ṣoṣo ti a si le gba bọ ni pe ki a ke pe Ọlọrun fun aanu.

Ipese Ọlọrun Olodumare ti dara pọ to! Eto ti O ṣe pe ki a ma baa “lé” “isánsa” Rẹ kuro lọdọ Rẹ, ti dara ti o si jẹ iyanu pọ to! (2 Samuẹli 14:14). Ẹṣẹ wa fa ikú wá sori wa; ṣugbọn Kristi jọwọ ẹmi Rẹ, O jiya, O kú lati san gbese ẹṣẹ ki a ba le dá wa lare nipa oore-ọfẹ Rẹ ati aanu Rẹ ti ko lopin. Ofin Rẹ lati ayeraye kò yipada nipasẹ eyi, nitori O san gbese naa perepere. Oun jẹ olododo, O si di Oludare gbogbo awọn ti o ba Jesu gbọ.

Ẹda kan kò le ṣe eyi, nitori gbogbo wa ni a wà labẹ egún ẹṣẹ nitori ẹṣẹ wa. Ẹjẹ alaiṣẹ ni ti a ti ta silẹ nikan ni o to fun etutu ẹṣẹ araye. Ofin ti kò lopin ni a rú; nitori idi eyi, ijiya rẹ pẹlu kò lopin. Olurọpo pẹlu ni lati jẹ alailopin. Ẹni kan ṣoṣo ni o le tán gbogbo ọran naa; orukọ Rẹ si ni Jesu!

Ohun ti “Ọjá Ododo” Ṣe

Niwọn igba ti o ti jẹ pe ninu ọkàn Ọlọrun Baba lọhun, “a ti pa Kristi lati ipilẹṣẹ aiye”, ati nitori Majẹmu-ileri wà fun “gbogbo idile aiye,” awọn eniyan kan kò ṣalai wà ti o gba awọn ipese wọnni ti wọn si ti ri idande tootọ gbà kuro ninu ẹṣẹ wọn gbogbo. Ki i ṣe ọpọlọpọ lẹẹkan ṣoṣo – nitori Kristi rán wa leti pe “agbo kekere” ni Ọlọrun n pese Ile ayeraye fún -- ṣugbọn lati ayebaye titi di isisiyi ni a ti n ri i ti ẹni kọọkan n fi tọkantọkan tẹle Ọlọrun. Ododo ti Ọlọrun fi ta awọn eniyan mimọ ti igbà laelae lọrẹ nilaari, o si pé, iyanu ni iwa-mimọ Ọlọrun ti o gbin sọkàn wọn, to bẹẹ ti Ẹmi Mimọ tẹnu mọ ọn fun ni pe awa di ajigbese lati tọ ipasẹ awọn “ẹlẹri pupọ” wọnyii.

Ọkunrin – tabi Obinrin?

Ni akoko iṣoro ati ipọnju Israẹli, awọn eniyan diẹ wà sibẹ ti wọn yàn lati bá Ọlọrun duro ti wọn si n jà fun ogo Rẹ. Ọlọrun ki i diwọn ọkunrin ati obinrin pẹlu odiwọn ti awọn ẹda n lò lati fi diwọn ipá ati agbara eniyan. Ni akoko iṣoro yii, boya àyà awọn ọkunrin domi nitori ẹrù ati ibanujẹ ti o yi wọn ká. Ṣugbọn Ọlọrun ni ohun gbogbo, ani ohun gbogbo ninu ohun gbogbo! Ohun-elo ni awa jẹ lọwọ Ọlọrun. Ẹni kọọkan wa, a ni gbogbo wa jẹ alailere ninu ara wa. Ọlọrun ni o n fun wa ni gbogbo ipá ti a ní. A kò ni ohun kan lẹyin eyi ti a ri gbà lọwọ Rẹ. O rọrun fun Ọlọrun lati lo obinrin tabi ọkunrin gẹgẹ bi O ti ṣe ni akoko yii. Kò si iyatọ lọdọ Rẹ.

Igba pupọ ni o wà ninu itan igbesi-aye eniyan nigba ti àyà awọn ọkunrin domi ṣugbọn ti obinrin akin kan si ti dide lati di aafo ti o ṣí silẹ lati gbe Iná Otitọ ati Ominira soke fun ayé ti o n táràrà ninu okunkun ati ainireti nipa ti ẹmi. Ihinrere yii jẹ ti wa lonii nitori ọkàn akin ti ọpọlọpọ awọn obinrin ẹni iwa-bi-Ọlọrun ni, awọn ẹni ti o duro ṣinṣin, ti wọn si ṣe oloootọ si eyi ti a fi lé wọn lọwọ lati ṣe. Ayè kò ni gbà wa to nihin lati sọ pupọ nipa wọn, awọn ẹni bi Susanna Wesley, iya John ati Charles Wesley, Evangeline Booth, Frances Havergal, Fanny J. Crosby, Mary Slessor ati awọn bẹẹ bẹẹ ti wọn jẹ oloootọ ninu iṣẹ iranṣẹ wọn si Ọlọrun. Awa ti Ijọ Igbagbọ Aposteli mọ daju pe Ọlọrun a maa lo obinrin ninu iṣẹ Rẹ niwọn igbà ti awa paapaa ti fi oju wa ri igbesi-aye ati iṣẹ-iranṣẹ eniyan Ọlọrun ti i ṣe oludasilẹ ijọ wa, Ẹni-ọwọ Florence L. Crawford. Nipa ijolootọ si Ọlọrun ti iya wa Crawford, ati nipa itọni rẹ laaarin ogunlọgọ awọn Onigbagbọ, ẹkọ isọdimimọ patapata gẹgẹ bi iṣẹ oore-ọfẹ ti o yanju, lẹyin ti a ba ni idalare ati ṣiwaju ifiwọni agbara Ẹmi Mimọ ati ina ṣi wà ninu aye sibẹ lonii. Ati nipa eyi, a le ri agbara Ẹmi Mimọ ati iná tootọ gbà lonii, bi o tilẹ jẹ pe ọtá wa ẹmi ti gbe ayederu ẹmi lé ọpọlọpọ eniyan lọwọ.

Lọna iyanu ti o ga rekọja ni Ọlọrun gbà pe Florence Crawford, o fi ẹgbẹ ati ẹkọ awọn alaiwa-bi-Ọlọrun silẹ, o si di ojulowo Onigbagbọ. Gẹrẹ lẹyin naa, o fẹ ṣiṣẹ fun Ọlọrun ti o fẹran lọpọlọpọ, aafo yii ṣi silẹ lakọkọ lati maa ṣe awọn ohun ti kò jọ ni loju nitosi ile rẹ. O sọ fun ni pe oun a maa mu awọn ọmọ kekere lati igboro lọ si ile rẹ lati wẹ ẹsẹ ti wọn fi pa ti o si n ṣẹjẹ, o n ṣe eyi ni orukọ Oluwa rẹ. O bẹrẹ si ṣe ibẹwo si ile tubu, o n gba ni niyanju, o si n ba awọn eniyan gbadura ni awọn ile tubu. Ọlọrun ti ipasẹ rẹ yí ọpọlọpọ pada lọna bayii, lẹyin naa, lọna ti kò yé e nigba ni, a mú un kuro ni ẹnu ṣẹ ti o mu eso wá si iye ainipẹkun yii, a si pè é lati jẹ alakoso ninu iṣẹ iranṣẹ ti Ihinrere.

O bẹrẹ iṣẹ yii nipa igbagbọ ni igbọran si ipe Ọlọrun. Ọlọrun sọ iṣẹ rẹ di nla, bi o si ti n gbadura, ti o n kọ ni, ti o n waasu, ti o si n gba awọn ti o wà ni ayika rẹ niyanju, Ọlọrun fun ni iti pupọ fun ikore Rẹ. Inunibini dide, nitori awọn kan wà lati ibẹrẹ ti wọn bẹrẹ si rẹ òdiwọn igbagbọ silẹ -- wọn n fi ohun miiran ti o rọrun dipo -- si iparun ẹmi ara wọn ati ogunlọgọ awọn ti n tẹle wọn. Ṣugbọn o duro ṣinṣin, obìnrinbìnrìn doju kọ ọpọlọpọ ọkunrin ti aarẹ ti mu ọkàn wọn nitori ti wọn yà kuro ninu “ọna igbani.” O gbé iṣẹ Ijọ Igbagbọ Apọsteli kalẹ lori ẹkọ Bibeli nikan, o si fi ipilẹ kan lelẹ ti o duro ṣinṣin titi di oni-oloni, yoo si duro gbọningbọnin bẹẹ titi Jesu yoo fi dé. Bawo ni ọkàn wa ti kún fun ọpẹ to fun awọn eniyan bi ti Debora lati igba ni titi di isisiyii!

Ọlọrun ni iṣẹ fun gbogbo wa -- lọkunrin ati lobinrin, ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin ati awọn ọmọ keekeekee lọkunrin ati lobinrin. Awọn eniyan rò pe awọn miiran kò lagbara wọn ko si nilaari, nipa odiwọn eniyan, ṣugbọn Ọlọrun kò ni iru ero bayii si awọn ti wọn ba jọwọ ara wọn fun Un patapata. O le ṣiṣẹ rẹpẹtẹ pẹlu ohun-elo ti kò ni laari, bi wọn ba jọwọ ara wọn fun ifẹ ati ilana Rẹ. Bi eyi ko ba ri bẹẹ, bawo ni a ṣe le gbe Eto Rẹ yọ rara! Kò si ẹnikan ninu wa, ati awọn akọni ninu igbagbọ ti igba ni, ti o to tan. Alailere ọmọ-ọdọ ni gbogbo wa i ṣe – ohun-elo ti ko nilaari – ti ko lagbara kan lẹyin Rẹ.

Debora ati Baraki

Debora jẹ ohun-elo Ọlọrun. Wolii ni oun i ṣe, eyi ni pe o n sọrọ Ọlọrun fun awọn eniyan. Ipe rẹ daju, gbogbo awọn ti o mọ ọn si mọ bẹẹ, nitori gbogbo wọn – lọkunrin ati lóbinrin ni o n tọ ọ wá. A kò gbọdọ foya pe awa jẹ alailagbara niwọn igba ti a ba n rin ninu ifẹ Ọlọrun. Nitori a jẹ ọkan ninu awọn ti a rò pé kò le ṣe ojiṣẹ Ọlọrun, nipa iro-inu eniyan, ko fihan pe Ọlọrun kò le lo wa bi a ba jọwọ ara wa fun Un patapata.

Ọlọrun n fẹ awọn ọdọmọkunrin! O n fẹ awọn ọdọmọbinrin pẹlu! Iṣẹ wà ninu ọgbà ajara Rẹ fun gbogbo wa; nitori a bí ẹnikan lobinrin kò din iwulo rẹ fun Ọlọrun kù lọnakọna. Ọpọlọpọ ti a pè lati jẹ iranṣẹ Ọlọrun ni o n sin eniyan dipo – nigba pupọ wọn n sin ifẹ ọkàn awọn tikara wọn! Bi Ọlọrun ba pè wá lati jẹ iranṣẹ Rẹ, a ko gbọdọ jó ajórẹyin lati lọ jọba! Lati ṣe iṣẹ ti o rẹlẹ julọ ninu ọgbà ajara Ọlọrun ga ju ipò ti o ga ju lọ ti eniyan, orilẹ-ède tabi agbajọpọ orilẹ-ẹde le fi fun ni.

Baraki mọ pe Ọlọrun ni o pe Debora. Kò wá aye tabi igbega fun ara rẹ lọnakọna. Loju ara rẹ, o ro ara rẹ si ẹni ti o rẹlẹ si ohunkohun lati ọwọ Ọlọrun wá tabi eyi ti Oun fi ọwọ si. Gẹgẹ bi Mose, ẹni ti o kọ lati maa kó awọn Ọmọ Israẹli lọ si Ilẹ Ileri afi bi Oju Ọlọrun ba n ba wọn lọ nigba gbogbo, Baraki kọ lati kó awọn Ọmọ Israẹli lọ si ogun lati bá awọn ara Kenaani jà, afi bi iranṣẹ Ọlọrun ba wà pẹlu wọn lati maa fi ọna hàn wọn nigba gbogbo.

Ọpọ ẹkọ ni a le ri kọ lara eniyan Ọlọrun yii! O rẹ ara rẹ silẹ, eyi ko fihàn pe kò gbọn tabi pe ko le dá ipinnu ṣe fun ara rẹ. O ni igboya. O ni agbara. Awọn ẹgbẹ ọmọ-ogun Israẹli fi ti rẹ pè. Ṣugbọn o ni ohun ti ju eyi lọ. O mọ ni ookan aya rẹ pe gbogbo iriri oun kò já mọ nnkan rara. O ni lati ni iranwọ Ọlọrun, oun paapaa si mọ bẹẹ. O ni ẹmi ti kò lọra lati gbà pe oun jẹ alailagbara ninu ipá ara rẹ, ki o si maa ṣafẹri agbara Ọlọrun, ki o si gba a nigba ti o ba de, lọnakọna ti o wu ki Ọlọrun yàn lati gba fi fun un.

Boya bi awọn ara Kenaani ba gbọ ọrọ ti wọn sọ, wọn yoo rò pe ọpọlọ rẹ kò pé tó lati kó awọn eniyan lọ soju ogun, nibi ti ẹjẹ ọmọ eniyan yoo maa ṣàn bi isun omi, ti alagbara paapaa yoo wariri nigba ti o ba ri ẹyọ kan pere ninu awọn iṣẹlẹ ibanujẹ ti yoo wọpọ lẹyin opin ọjọ kin-in-ni fun ogun jija. Ki ni obinrin le ṣe ni iru akoko bayii?

Baraki mọ ailera rẹ -- ailagbara gbogbo ẹda. O mọ ibi ti a gbe le ri agbara Ọlọrun pẹlu: o si mọ ẹni ti Ọlọrun pe lati jẹ alakaso ninu ohun ti ṣe ti Ọrun. O mọ pe a kò le ṣe ohunkohun deedee a fi bi o ba jẹ pe Ọlọrun ni Olupilẹṣẹ ati Olupese ohun naa. O pinnu, o si sọ iduro rẹ. Nitori ipinnu yii tọna, Debora fara mọ ọn lẹsẹ kan naa, o si bá ogun Israẹli jade – ohun ti o lodi si ọkàn rirọ obinrin, ọkan aanu rẹ ati ailagbara rẹ gẹgẹ bi obinrin ju bi a ti le fẹnu sọ lọ.

Ọna ti o Nira, tabi ọna ti O Rọrun?

Awọn ẹlomiran a maa sọ pe wọn kò le ṣe iru awọn iṣẹ kan fun Ọlọrun nitori wọn ki i ṣe ọkunrin; tabi nitori wọn ko ni ẹbun yii tabi eyi ni, bi wọn tilẹ jẹ ọkunrin paapaa. Debora fi ibi aabo ati itura rẹ labẹ igbi ọpẹ silẹ, ati iṣẹ rẹ gẹgẹ bi wolii ati onidajọ, lati ṣe ifẹ Ọlọrun. O pa igbesi-aye ti awọn obinrin ti igbà ti rẹ n gbé tì, ani titi de apa kan iṣẹ ti rẹ nipa ti ẹmi fun iṣẹ Ọlọrun ti o tobi ju eyi lọ. Awọn ibi ti ó lọ ki i ṣe ibi ti o rọrun. Awọn ohun ti ó ri kò fun ni imisi rara. Ṣugbọn ó tọ Ọlọrun lẹyin, o si gbà ọna ti o nira -- ọna ti o lodi si gbogbo ero ọkàn obinrin – o si ri ayọ ati ere ti kò lẹgbẹ gbà lati ọdọ Ọlọrun wá, eyi ti o fẹrẹ jẹ pe ko si iru rẹ ri ninu itàn agbaye. Ihó ọpẹ rẹ fun iyin ati ayọ ti o ti inu igbọran ati igbẹkẹle ninu Ọlọrun jade larinrin, ó kún fún ẹkọ to bẹẹ ti a ṣe akọsilẹ rẹ sinu Bibeli, ọpọlọpọ awọn eniyan Ọlọrun ni o si ti fi ọrọ wọnyii waasu ninu ọkẹ aimoye igbà, nipasẹ eyi ti ogunlọgọ eniyan ti ri idagbasoke gbà ti wọn si ni anfaani lati tubọ sunmọ Ọlọrun.

Debora tilẹ le sọ pe abẹ igi ọpẹ ti idajọ ki i ṣe ayè obinrin. O yẹ ki o ro pe Baraki kò tọ lati jẹ balogun niwaju ogun, bi o ba ṣe pe bi inu rẹ ti ri gan ni o ṣe sọrọ nì, nitori eyi fihàn pe kò ni igboya ati ipinnu. Baraki pẹlu ti le ri awọn ohun ti Debora ti le maa fọkan ṣe aṣaro lori ọrọ yii.

O yẹ ki Debora kọ lati lọ si ogun lati foju ri oku lẹgbẹ ọdọ rẹ, lati maa gbọ igbe oró wọn bi wọn ti n bẹbẹ pe ki ikú wá mu wọn dipo irora iku ti wọn n jẹ. O yẹ ki o ro pe igbesi-aye pakanleke ọmọ ogun kò yẹ obinrin ti iṣe alailagbara. Ṣugbọn Debora kò tẹle aṣa. O tọ Ọlọrun lẹyin! Nitori ipinnu rẹ, ati ohun ti o ṣe lẹyin naa, ẹgbẹẹgbẹrun eniyan ni o wà ni Ile-ogo loke lọjọ oni.

Diẹ ninu Awọn Erè Ẹṣẹ

Idasilẹ awọn Ọmọ Israẹli de lọna airotẹlẹ. Iwe Mimọ sọ fun ni pe, “awọn irawọ ni ipa wọn bá Sisera jà”; “OLUWA si fi oju idà ṣegun Sisera, ati gbogbo kẹkẹ rẹ, ati gbogbo ogun rẹ”, ati pe “odò Kiṣoni gbá wọn lọ.” Jaeli, aya Heberi, ṣe iranwọ nipa lilo anfaani ti o ṣí silẹ lati pa Sisera ọta awọn Ọmọ Israẹli ẹni ti a ti yàn fun iparun.

Awọn ara Kenaani ni anfaani lati yi pada si Ọlọrun gẹgẹ bi Rahabu ti ṣe. Awọn pẹlu ni ipin ninu ibukun ti a ṣeleri fun gbogbo idile aye ninu Majẹmu Ayeraye. Kaka bẹẹ, wọn kọ igbala Ọlọrun wọn si doju ija kọ Ọ. Olori wọn fi ipinhun alaafia ti o ti ṣe, ṣe aabo fun ara rẹ dipo Aabo ti o daju ti a ti pese fun eniyan. A pa awọn ọmọ-ogun Jabini, ọba Kenaani, run. A pa Sisera, olori-ogun awọn keferi run pẹlu. A pa ọba wọn pẹlu.

A sọ fun ni pe nigba ti Ọlọrun ba dide lati jà, ko si ẹni ti o le duro; nigba ti O bá n lepa, ko si ẹni ti o le sá asala; nigba ti O ba dawọ le ohunkohun, Oun yoo ṣe e ni aṣeyọri. “Ikú li ère ẹṣẹ.” Awọn wọnni ti wọn doju kọ Ọlọrun ti wọn ṣọtẹ si I ati akoso ododo Rẹ, jiya iru eyi ti o n bọ wa ba awọn wọnni ti wọn fẹ ẹṣẹ ju ododo, aiwa-bi-Ọlọrun ju iwa-mimọ, ati ikú ayeraye ju iyè ainipẹkun. Kò si ajabọ kuro ninu idajọ otitọ Ọlọrun ayeraye!

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni wa buburu ti o tẹlẹ ọkàn awọn Ọmọ Israẹli nigba ti wọn fi n rìn kiri ni aginju?
  2. Ki ni iwa buburu ti o pilẹ ọkàn wọn nigba ti wọn de ilẹ Kenaani?
  3. Ofin wo ni wọn rú nipa ẹṣẹ wọn? Awọn Ofin wo ni wọn jẹbi rẹ?
  4. Lọna wo ni Ọlọrun gbà lo awọn ara Kenaani ninu eto Rẹ? Bi ohun-elo ki ni a lò wọn?
  5. Ka Romu 6:23 lati ori wa.
  6. Nipasẹ ta ni Ọlọrun sọrọ, lati fi ifẹ Rẹ hàn fun awọn Ọmọ Israẹli lakoko yii?
  7. Darukọ awọn ẹlomiran ti awọn eniyan le maa pè ni ohun-elo alailagbara ti Ọlọrun lò gidigidi.
  8. Iru iwa wo ni Baraki hù nigba ti a ké si i lati di ipò pataki mú?
  9. O ha ṣe ohun ti o tọ lati huwa bẹẹ? Ki ni ohun ti o wọpọ ti ọran ti o fara jọ eyi?
  10. Bawo ni a ṣe fi iṣẹgun fun Israẹli?