Lesson 191 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI:“Emi, ani emi, o kọrin si OLUWA; emi o kọrin iyin si OLUWA, Ọlọrun Israẹli” (Awọn Onidajọ 5:3).Cross References
I Ọrọ ti o Ṣiwaju Orin Debora ati Baraki
1. A fi iyin fun Ọlọrun fun idasilẹ Rẹ, Awọn Onidajọ 5:1-3
2. A sọ lẹsẹẹsẹ ti ogo, ọla nla, ati agbara Ọlọrun ti a ti fi hàn nipa Israeli, Awọn Onidajọ 5:4, 5; Deuteronomi 33:2; Orin Dafidi 68:7, 8; Habakkuku 3:3, 4
3. A sọ ti ipo itiju Israẹli nitori bọriṣa, Awọn Onidajọ 5:6-8
4. A yin awọn oloootọ alakoso Israẹli, Awọn Onidajọ 5:9
5. A fi hàn ni ti alaafia, ododo ati ijọba otitọ ti Israẹli ni ọjọ iwaju -- boya eyi tun n sọ nipa Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun, Awọn Onidajọ 5:10, 11; Isaiah 2:1-4, 10-21
II Iyin fun Isin Atọkanwa; Ibawi fun Ilọra
1. A tẹnu mọ ipe si ipo aṣiwaju ati ojuṣe, Awọn Onidajọ 5:12,13
2. A yin Efraimu, Bẹnjamini, Manasse (Makiri), Sebuluni, Issakari ati Naftali fun isin atọkanwa, Awọn Onidajọ 5:14, 15, 18
3. A bá Reubẹni, Gadi (Gileadi), Dani ati Aṣeri wí fun imọtara-ẹni¬-nikan ati aifẹ iṣẹ ṣe wọn, Awọn Onidajọ 5:15-17; Gẹnẹsisi 49:3, 4
4. Ọlọrun fi awọn eniyan Merosi bú fun iwa aibikita ati imẹlẹ wọn, Awọn Onidajọ 5:23
III ọna Ogun ati Abayọrisi Rẹ 1. A sọ fun Israẹli pe awọn ẹya ti wọn jẹ ipe ṣe bẹẹ nipa ifẹ inu wọn, lai si ero fun ère owó, Awọn Onidajọ 5:19 2. A si tun rán wọn leti pe Ọlọrun jà, O si ṣẹgun fun wọn, Awọn Onidajọ 5:20-22; 4:9, 14, 15, 23 3. A yin iwa otitọ Jaẹli si ipa ti Ọlọrun lai ka iṣepọ ti o ni pẹlu awọn alaiwa-bi-Ọlọrun sí, Awọn Onidajọ 5:24-27; 4:11, 12, 17-21 4. A fi han Israẹli, igbẹkẹle aabo ẹlẹran ara tí awọn alaiwa-bi-Ọlọrun ní, ati bi o ti n já wọn tilẹ, Awọn Onidajọ 5:28-30 5. A sure fun wọn gidigidi, Awọn Onidajọ 5:31; Heberu 11:32-34, 39.
Notes
ALAYEOrin Iyin
O fẹrẹ jẹ pe gbogbo ori karun un Iwe Awọn Onidajọ ni a yà sọtọ fun orin tí Debora ati Baraki kọ lẹyin ti ogun ti wọn ba awọn ara Kenaani jà ti pari tan. Awọn ọrọ ti o ṣiwaju fi awọn otitọ ti o jinlẹ ti i ṣe iwadi ọkàn hàn, ti o wulo fun igbesi-aye ẹni kọọkan titi di oni oloni, bi o tilẹ jẹ pe nipa imisi ni a ti kọ orin yii lati nnkan bi ẹgbẹẹdogun (3,000) ọdun sẹyin.
Nigba ti a ba fi orin yii wé awọn miiran gbogbo ninu Bibeli, a le ri i bi ibẹrẹ wọn ti fara jọ ara wọn tabi ibẹrẹ awọn orin iyin. Orin Mose ti a kọ lẹyin lila Okun Pupa já (Ẹksodu 15:1-21), ati orin ikẹyin ni opin igbesi-aye rẹ (Deuteronomi 32:1-43), bẹrẹ pẹlu fifi iyin fun Ọlọrun ati ẹri nipa titobi Rẹ. Orin idupẹ Hannah (l Samuẹli 2:1-10), ọpọlọpọ ninu awọn Saamu, orin idupẹ Isaiah (Isaiah 12:1-6), Iyin-Ọlọrun-logo Maria, iya Jesu (Luku 1:46-55), asọtẹlẹ Sekariah baba Johannu Baptisi (Luku 1:67-79), ati orin awọn ẹni irapada yika Itẹ Ọlọrun (Ifihan 5:9-14; 7:12-17; 15:3, 4), ni wọn bẹrẹ pẹlu fifi titobi Ọlọrun hàn ati iyin si Olodumare. Adura ti Jesu fi kọ ni, ti a n pè ni Adura Oluwa, bẹrẹ lọna kan naa (Matteu 6:9-13). Nitori naa, ẹkọ kin-in-ni ti a ri kọ ninu orin Debora yii ni bi o ti ṣe dandan fun wa to lati tọ Ọlọrun wá pẹlu ọkàn ti o tọ -- pẹlu irẹlẹ ati iyin.
Awọn Idasilẹ Ọlọrun
Fifun-ni ni Ofin ni Oke Sinai jẹ ohun pataki ni igbesi-aye awọn Ọmọ Israẹli. Nibẹ ni Ọlọrun gbé bá Israẹli dá Majẹmu kan pato -- ti o si yatọ si Majẹmu ti o bá Abrahamu, Isaaki ati Jakọbu dá. Nibẹ ni awọn Ọmọ Israẹli gbé fà sẹyin ti wọn si kọ ojuṣe ti a fi le wọn lọwọ nipa Majẹmu yii silẹ. Ọlọrun, ninu ogo ati agbara Rẹ fara hàn wọn ni Oke Sinai, bi wọn ti gbọ ohùn Rẹ ti O n sọ awọn Ofin ati ipinhun majẹmu naa fun wọn. Gbogbo ohun ti o si ṣẹlẹ ni igbesi-aye wọn bi ẹni kọọkan, tabi orilẹ-ède, ti o fi idide Ọlọrun lati gbè wọn nija hàn, n ran wọn leti Oke Sinai ati ogo ati agbara ti wọn ri nibẹ.
Oluwa jà fun Israẹli ni didoju kọ ogun Jabini, ọba Kenaani. Ki i ṣe agbara ogun jija awọn Ọmọ Israẹli ni o fun wọn ni iṣẹgun, nitori laaarin awọn ọkẹ meji (40,000) Ọmọ Israẹli, a ko ri ẹyọ apata tabi ọkọ kan ṣoṣo. Ninu ẹkọ wa ti o kọja, a ti mọ pe a jẹ wọn niya fun nnkan bi ogun ọdun. Ṣugbọn nigba ti wọn ke pe Ọlọrun, O gbọ ti wọn, O si gbà wọn.
A kò sọ fun ni pato, ohun ti Ọlọrun lò lati fi lé awọn ara Kenaani ati lati pa wọn run, bi ko ṣe eyi pe, omi gbé ọpọlọpọ wọn lọ, wọn si kú, ati pe ọrun lọhun para pọ mọ awọn nnkan ti ayé lati dojuja kọ awọn Keferi. Nipa ọwọ Ọlọrun ni a fun wọn ni iṣẹgun, nitori Israẹli pa aṣẹ Ọlọrun mọ, wọn si fi tọkantọkan yọọda ara wọn fun ipa ti Ọlọrun. Nitori iṣẹgun yii, ayọ ati inu-didun ti n tẹle iṣẹgun kún ọkàn Debora.
Ọlọrun kan naa ti o fọhùn ni oke Sinai, ni o bá Sisera ati ogun Kenaani jà. Ọlọrun kan naa ni o gbá omi Okun Pupa ati odo Jordani jọ bi oke, ti awọn Ọmọ Israẹli si kọja ni iyangbẹ ilẹ. Ọlọrun kan naa ni o rán aparo si wọn lati jẹ, ti o pese manna pẹlu, ni ọjọ mẹfa ninu ọjọ meje, fun ogoji ọdun. Ọlọrun naa ni o mú omi jade ninu apata lile bi ọta ibọn, ti o sọ imọ awọn ọta di asán, ti o rán agbọn lati gbà wọn: ti o fi ọwọn awọsannma ṣiji bò wọn ni ọsan kuro ninu ooru ati oorun aṣálẹ: ti o si fi ọwọn iná ṣamọna wọn ni oru. Ọlọrun kan naa ni o fara hàn lori Itẹ Aanu ni Ibi Mimọ Julọ, ti o mu ki ilẹ la ẹnu rẹ lati gbé awọn ọlọtẹ ti wọn tapa si aṣẹ Mimọ Rẹ mì; ti o bi odi Jẹriko wó: ti o rán arun si awọn ara Egipti ti kò si jẹ ki arun naa fọwọ kan awọn Ọmọ Israẹli.
Ohun ti o dara ni lati boju wo ẹyin wo idasilẹ Ọlọrun fun wa kuro ninu iyọnu, ẹṣẹ ati ibi. O dara lati maa ṣe eyi lakoko iṣoro. O dara ju lati maa ṣe bẹẹ nigba ti ọkàn wa kún fun ayọ iṣẹgun ti Ọlọrun fi fun wa. “Ohun rere ni lati ma fi ọpẹ fun OLUWA, ati lati ma kọrin si orukọ rẹ, Ọga-ogo” (Orin Dafidi 92:1).
Ipè, pẹlu Iyin ati Ibawi
Ẹkọ wa ti o kọja fi iwa Debora ati Baraki hàn fun wa, gẹgẹ bi itara wọn lati jẹ ipè Ọlọrun ati ijolootọ wọn si I ti fi han fun ni. Ṣugbọn o ṣe ni laanu pe, gbogbo Israẹli kò dabi awọn iranṣẹ Ọlọrun meji wọnyii.
Awọn ẹya mẹwaa pere ni a mẹnu kàn ninu orin yii. A kò darukọ Simeoni ati Juda. Boya agbegbe ilẹ Simeoni ati Juda ti jinna si ibi ti ogun yii gbé wà ni ko jẹ ki wọn wá jagun pẹlu awọn Ọmọ Israẹli iyokù. Aabọ Manasse, ti o dó si ihà ila-oorùn Jordani wà lara awọn ti o wà ni Gileadi ti a ba wi, nitori nigba ti a ba sọ pe “Gileadi”, eyi kó gbogbo awọn ti o n gbé ilẹ ti awọn eniyan wọnyii dó si papọ.
Baraki kó awọn ẹgbaarun (10,000) ọmọ-ogun rẹ jọ si tosi ilu rẹ, ni agbegbe ilẹ tí awọn ẹya Sebuluni ati Naftali wà. Wọn rìn lọ si iha guusu lọ si oke Tabori, lai pẹ wọn si kọlu awọn ọta, nitori Heberi ẹni ti Jabini ti bá ṣe ipihun alaafia, ti sọ fun awọn ara Kenaani pe awọn Ọmọ Israẹli wà nibi oke yii. Ni agbegbe ilẹ ti Issakari ati ti aabọ ẹya Manasse ti o bá awọn Ọmọ Israẹli kọja si odikeji Jọrdani lati gba ilẹ-ini wọn ni ilẹ Kenaani ni a gbé ja ogun yii. Ni ihà isalẹ ibi ti ogun yii gbé dó sí ni Efraimu ati Bẹnjamini gbé wà, wọn si dide lati bá wọn jagun yii, boya nipa yiyọ si oju ogun lati ọna ẹyin ibi ti ogun dó si.
Ọna awọn ẹya meji aabọ ti ó wà ni iha ila-oorun Jordani kò jinna ju bi o ti yẹ si ibi ti ogun dó sí, lati ni ipin ninu ija naa. Bi wọn ba tilẹ fẹ ṣẹ awawi pe ọna wọn jìn jù, awọn tikara wọn ni wọn fi ọwọ ara wọn yan an, o yẹ ki wọn ti gbaradi lati fara da inira fun iwọn igba diẹ lati dapọ mọ Israẹli ni ogun pataki yii fun anfaani orilẹ-ede wọn yii. Bi ọkàn wọn ba ṣe deedee pẹlu Ọlọrun, wọn i ba ti dide lai si awawi tabi iyan jija.
Ṣugbọn Reubẹni duro ti agbo-ẹran, nitori itọju ohun-ini wọn ṣe pataki loju wọn ju iṣẹ Ọlọrun lọ. O fi hàn pe wọn kò ṣafẹri ohun ti n bẹ loke, ṣugbọn ọkàn wọn wà ninu ohun igba isisiyii. Awọn ọmọ Gadi pẹlu, duro si iha ọhún Jordani pẹlu aabọ ẹya Manasse ti wọn kùna lati lọ si ilẹ Ileri ni ọdún pupọ ṣiwaju eyi si tun fi han bi ifẹ wọn si Ọlọrun ti tutu to.
Aṣeri duro leti ebute – jinna réré si oju ogun bi wọn ti lè rìn jinna to laaarin agbegbe ilẹ wọn. Wọn duro ninu odi wọn. Ki ṣe ainaani ipe Ọlọrun nikan ni ẹbi wọn, ṣugbọn wọn jẹbi ainaani alaafia awọn arakunrin wọn. Wọn kò fẹ mọ bi a tilẹ kó awọn ẹya iyoku lẹrú tabi bi a pa wọn run. Wọn rò pe ohun ti o kàn wọn ni lati boju to odi wọn, ki wọn si duro ni ẹkùn wọn. Bawo ni wọn ti jẹ aboṣi to ni kikuna ipe Ọlọrun Israẹli ti o fẹ ki wọn jẹ iranṣẹ Majẹmu ni si gbogbo araye lati mú ihin alaafia, aabo pipe, ati igbala ati awọn Majẹmu ibukun miiran gbogbo tọ eniyan gbogbo lọ! Ki i ṣe pe awọn ẹya Aṣeri jẹbi lati ṣe ojuṣe ti a fi lé wọn lọwọ nipasẹ Majẹmu wọnni si awọn orilẹ-ède Keferi nikan, ṣugbọn wọn tun jẹbi ainaani ati aibikita fun eniyan ara wọn paapaa -- Israẹli, orilẹ-ède ti a yanfẹ! Iru ipo ti ẹnikẹni ti o ba to iṣura rẹ jọ si ayé dipo Ọrun wà ni yii.
Awọn ẹya Dani pẹlu jẹ amọ-ti-ara-ẹni-nikan. Wọn wà ninu ọkọ oju omi wọn, wọn n bá òwò wọn lọ pẹrẹwu pẹlu orilẹ-ède miiran. Wọn kò ro ti ẹyin ọla; nitori anfaani ki ni awọn ilu wọn ti o wà leti ebute ati òwo wọn le mu wá bi awọn aladugbo ti o yi wọn kaakiri kò bá bá wọn rẹ? Bi a ba pa awọn Israẹli yoku run, aanu ati òwo aṣejere wo ni awọn ẹya Dani rò pe awọn yoo ba pade lati ọdọ awọn ti n pọn wọn loju ti wọn si n bori wọn bayi? Wọn dabi ọpọ ti kò naani ipadabọwa Oluwa wa, wọn n gbokegbodo lati tẹ ara lọrun, lati pese irọra ati ọrọ fun ọjọ ogbó wọn, ati lati maa sin ifẹ ọkàn ara wọn.
Ṣugbọn awọn olugbe Merosi ni ibawi wọn le jù lọ. Angẹli Oluwa gegun fun wọn, nitori wọn ṣe alainaani, wọn si jẹ ki anfaani lati ṣiṣẹ fun Ọlọrun ré wọn kọja. Wọn kò kuku ṣọtẹ gan an si awọn Ọmọ Israẹli. A kò sọ fun ni pe idi rẹ ti wọn kò fi wá ni pe itọju ohun ti ara wọn ni o gbà wọn layè patapata bi ti awọn ẹya Reubẹni, Aṣeri ati Dani. Awọn olugbe Merosi kàn kawọ gbenu lasan ṣá ni; ẹṣẹ aimu ohunkohun ṣe fa ibawi ti o gbona ju ti awọn miiran lọ wá sori wọn.
Merosi ha wà ni àye pataki tabi wọn ṣe gunmọ to bẹẹ ninu eto ogun jija yii, to bẹẹ ti a kò le ṣẹgun lai si iranwọ wọn? Rara o! Nitori Ọlọrun le mú eto ti Rẹ ṣẹ dopin lai si wa gẹgẹ bi ẹni kọọkan. Lai si wa iṣẹ Oluwa yoo maa lọ lai fọta pè. A kò mọ bi awọn ara Merosi wa nitosi ibi ti a gbé jagun, tabi wọn wà ni ibi ti awọn ọta le maa gbà sá asala, boya nipa bẹẹ wọn iba le ṣe iranwọ pataki fun awọn Ọmọ Israẹli iyoku. Ohun ti a mọ ni pe wọn wà nibi ti wọn gbe le ṣiṣẹ fun Ọlọrun, ṣugbọn wọn kò ṣe e. Wọn kò ṣe ohunkohun!
Egún ti a fi Merosi gún ṣẹ tán patapata to bẹẹ ti kò si iranti wọn mọ, awọn eniyan tabi ahoro ibi ti wọn gbé wà kò kù mọ rara. A ti pa a run patapata. Ẹkọ pataki ti a ri kọ nipa iparun ti o de ba wọn yii ni pe a fi ré nitori awọn eniyan rẹ kàn kawọ gbenu ṣa laí ṣe ohun kan, eyi si mu ọrọ Oluwa wa si iranti wa pe: “Ọmọ-ọdọ na, ti o mọ ifẹ oluwa rẹ, ti kò si mura silẹ ti kò si ṣe gẹgẹ bi ifẹ rẹ, on li a o nà pipọ” (Luku 12:47).
Ibukun Ọlọrun wá sori awọn ẹya mẹfa ti wọn bá ọta jà pẹlu gbogbo ọkàn ati agbara wọn. Wọn wá wọn si jà, wọn kò gba owó tabi èrè kan fun ara wọn fun akoko ti wọn kò fi ṣe iṣẹ oojọ wọn. “Kò si ẹniti o fi ile, tabi aya, tabi ará, tabi obi, tabi ọmọ silẹ, nitori ijọba Ọlọrun. Ti ki yio gba ilọpo pipọ si i li aiye yi, ati li aiye ti mbọ iye ainipẹkun” (Luku 18:29, 30). O rọrun lati mọ ère ti a n tò jọ fun awọn ti wọn fi tọkantọkan sin Ọlọrun ti wọn si gbọran si gbogbo aṣẹ Rẹ. Wọn “fi ẹmi wọn wewu titi de oju ikú nibi giga gbogbo loju ija.” Ṣugbọn wọn gba ere ainipẹkun ni ṣiṣe bẹẹ!
Awọn odiwọn ti a n beere lọwọ wa ni akoko Majẹmu Titun yii kò kere lọnakọna si eyi ti a beere lọwọ awọn Ọmọ Israẹli. Awọn iranṣẹ Ọlọrun onigboya meji ti akoko Majẹmu Titun ni a tọka si lọna kan naa. Akọwe ohun mimọ yii sọ fun ni pe wọn jẹ awọn ọkunrin ti o fi ẹmí wọn wewu nitori orukọ Oluwa wa Jesu Kristi” (Iṣe Awọn Aposteli 15:26). Ohun ti Jesu pẹlu fi lelẹ ga, nigba ti O wi pe, “Bi ẹnikan ba tọ mi wá, ti ko si korira (ifẹ ti o rẹlẹ) baba rẹ, ati iya, ati aya, ati ọmọ, ati arakunrin, ati arabirin, ani ati ẹmí ara rẹ pẹlu, kò le ṣe ọmọ-ẹhin mi. Ẹnikẹni ti kò ba rù agbelebu rẹ, ki o si ma tọ mi lẹhin, kò le ṣe ọmọ-ẹhin mi.” “Gẹgẹ bẹẹni, ẹnikẹni ti o wù ki o ṣe ninu nyin, ti kò ba kọ ohun gbogbo ti o ni silẹ, kò le ṣe ọmọ-ẹhin mi” (Luku 14:26, 27, 33).
Erè ti ko ṣe e fẹnu sọ wà ni ipamọ fun ẹnikẹni ti o ba le gbe agbelebu rẹ lati maa tọ Jesu lẹyin, ki wọn si fi ẹmi wọn wewu “nibi giga gbogbo loju ija,” awọn ẹni ti wọn fi ẹmi wọn wewu nitori orukọ Rẹ. Ibawi kikoro ati adanu ayeraye wà fun awọn ti wọn kùna lati ṣe e ti wọn si “duro ninu ọkọ,” ti ọkàn wọn si balẹ ninu “agbo-ẹran” ohun ti ayé yii, ti wọn si duro labẹ aabo imọ-ti-ara-ẹni-nikan, ti wọn si kuna lati pa majẹmu wọn mọ, tabi awọn ti kò tilẹ naani lati dide fun iranwọ Oluwa – kaka bẹẹ, ti wọn kawọ gbenu lai ṣe ohunkohun!
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni kókó ibẹrẹ orin Debora ati Baraki?
- Darukọ awọn orin pataki miiran ninu Bibeli ki o si sọ fun ni eredi rẹ ti a fi kọ wọn.
- Iru ipò wo ni Israẹli wà nigba ti a gbé Debora dide bi wolii obirin?
- Ki ni ṣe ti a fi yin awọn ẹya Sebuluni ati Naftali?
- Ki ni ṣe ti a bá awọn ẹya Gadi ati Reubẹni wi?
- Ka ẹsẹ kan lati ori ninu Majẹmu Titun ti o sọ fun ni irú iha ti a ni lati kọ si iṣẹ Ọlọrun.
- Ki ni ṣe ti a fi awọn olugbe Merosi ré?
- Bawo ni egun yii ṣe ṣẹ tó?
- A le sọ pe iya Sisera gbagbọ de ayè kan pe ọmọ oun wà lai lewu. Ki ni o fara jọ eyi nipa ti ẹmi?
- A sure fun Jaẹli, aya Heberi lọna ti o wú ni lori. Darukọ obirin miiran ti a sure fun lọna bayii.