Awọn Onidajọ 6:1-40

Lesson 192 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹ mu gbogbo idamẹwa wá si ile iṣura, ki onjẹ ba le wà ni ile mi, ẹ si fi eyi dán mi wò nisisiyi, bi emi ki yio ba ṣi awọn ferese ọrun fun nyin, ki nsi tú ibukún jade fun nyin, tobẹẹ ti ki yio si aye to lati gbà a” (Malaki 3:10).
Cross References

I Ipo Oṣi ti Awọn ẹlẹṣe wa

1. Israẹli dẹṣẹ; awọn Midiani ṣẹgun wọn, wọn si fi wọn sinu ipọnju, Awọn Onidajọ 6:1-6; Orin Dafidi 106:41-43

2. Awọn Ọmọ Israẹli kigbe si Ọlọrun, O si rán wolii kan lati ran wọn leti ẹṣẹ wọn, Awọn Onidajọ 6:7-10; Orin Dadidi 106:44; Hosea 5:15

II Ọrọ Angẹli si Gideoni

1. Bi Gideoni ti n pakà, angẹli naa fara hàn pẹlu ọrọ lati ọdọ Ọlọrun, Awọn Onidajọ 6:11, 12

2. Ẹnu ya Gideoni si ipe Ọrun naa, Awọn Onidajọ 6:13-16; Ẹksodu 3:11; 2 Samuẹli 7:18-20; Jeremiah 1:6-9

3. A fi ami jẹri si aṣẹ angẹli naa, Awọn Onidajọ 6:17-24; Lẹfitiku 9:24; 1 Awọn Ọba 18:38; 2 Kronika 7:1

III Iparun Baali lati Ọwọ Gideoni

1. Aṣẹ kin-in-ni ti Ọlọrun pa fun Gideoni ni pe ki ó pa oriṣa run, ki ó si kọ pẹpẹ kan fun Ọlọrun, Awọn Onidajọ 6:25-27; Matteu 6:24; 2 Kọrinti 6:15-17

2. Awọn ọkunrin ilu naa fẹ lati pa Gideoni, Awọn Onidajọ 6:28-30; Jeremiah 26:11; Johannu 16:2; Iṣe Awọn Aposteli 9:1, 2; 26:9-11

3. Baba Gideoni gba Gideoni silẹ lọwọ awọn ọkunrin ilu naa, Awọn Onidajọ 6:31, 32; 2 Timoteu 4:16, 17

4. Ẹmi Oluwa ba le Gideoni bi awọn Midiani ti gbara jọ fun ogun, Awọn Onidajọ 6:33-35; 15:14-16; Efesu 6:10-12

IV Ijolootọ Ọlọrun

1. Gideoni beere ami lati jẹri si pipe rẹ lati ṣe akoso Israẹli, Awọn Onidajọ 6:36-38; Ẹksodu 4:1-9

2. Gideoni fẹ ami lẹrinkeji, Ọlọrun si da a lohun, Awọn Onidajọ 6:39, 40.

Notes
ALAYE

Ọjọ Wahala

Ẹni ti o ba dẹṣẹ ni lati maa reti lati ri ère ẹṣẹ gbà. Israẹli ṣe eyi ṣe eyi ti o buru ni oju Oluwa, kò pẹ lẹyin naa ti aabo ká kuro lori wọn ati ilẹ wọn. Ni akoko yii, Ọlọrun gba awọn ara Midiani layè, awọn ti Israẹli ti ṣẹgun wọn tẹlẹ ri, lati dó ti Israẹli ati lati maa pọn wọn loju. Aṣẹgun titún di ẹni ti wọn ṣẹgun rẹ. Ẹṣẹ ti gba agbara ati ifẹ lati jà kuro lọwọ awọn ọmọ-ogun Israẹli, a ni wọn yàn ni akoko yii lati sá niwaju ọta ju ati bá wọn jà lọ. Iho oke ati apata wá di ibi isadi awọn Ọmọ Israẹli. Awọn ara Midiani a maa wá lọpọlọpọ bi eeṣú, wọn a si ba eso ilẹ wọn jẹ titi Israẹli fi di talaka lai ni ounjẹ.

“Kepè mi li ọjọ ipọnju: emi o gbà ọ, iwọ o si ma yìn mi logo” (Orin Dafidi 50:15). Israẹli ké pe Ọlọrun, lẹyin ti awọn ara Midiani pọn wọn loju fun ọdun meje tọtọ. O ya ni lẹnu pe awọn eniyan le duro pẹ to bayii ki wọn to ke pe Ẹnikan ṣoṣo ti o le yọ wọn kuro ninu ipọnju. Ọlọrun fihan pe Oun ṣetan Oun si ni ifẹ lati gbọ adura awọn eniyan Rẹ; ṣugbọn ki O to rán oludande si wọn, O kọ rán wolii kan lati rán awọn eniyan leti ẹṣẹ wọn ati pe wọn ni lati ronu piwada. Lai si aniani, iṣẹ wolii yii mú ire jade, nitori gẹrẹ lẹyin eyi ni angẹli Ọlọrun fi ara han ẹni naa ti Ọlọrun yàn lati jẹ balogun awọn akọni eniyan diẹ lati bá ọta jà.

Ọkunrin Alagbara

Angẹli Oluwa ba Gideoni nibi ti o gbé n pakà nibi ifunti - nibi ti awọn ara Midiani kò ni ireti lati ri ọkà rara. Angẹli ki i bayii pe, “OLUWA wà pẹlu rẹ, iwọ ọkọnrin alagbara.” Gideoni si dahun pe, “Ibaṣepe OLUWA wà pẹlu wa, njẹ ẽṣe ti gbogbo eyi fi bá wa?” Gideoni dabi ọpọlọpọ eniyan lọjọ oni – o kùna lati ri i pe Ọlọrun gba ipọnju yii layè lati de ba wọn, fun idi pataki yii pe ki Oun le mú wọn pada sọdọ Oun tikara Rẹ. Onisaamu wi pe, “O dara fun mi ti a pọn mi loju; ki emi ki o le kọ ilana rẹ” (Orin Dafidi 119:71). Iná ipọnju ni o saba maa n yọ ipẹpẹ ati idarọ kuro lara awọn ọmọ Ọlọrun.

Nigba ti Gideoni gbọ ipe Ọlọrun lati gba awọn Ọmọ Israẹli silẹ kuro lọwọ awọn ara Midiani, o hu iru iwa kan naa ti o n fi awọn eniyan ti Ọlọrun n lò hàn. Gideoni jẹ onirẹlẹ ni tootọ. Ni idahun si ipe pé ki o gba Israẹli là, o wi pe, “ọna wo li emi o fi gbà Israẹli là? kiyesi i, talakà ni idile mi ni Manasse, emi li o si jẹ ẹni ikẹhin ni ile baba mi” (Awọn Onidajọ 6:15). Irẹlẹ tootọ jẹ ohun-elo atata ni ọwọ Ọlọrun. A tilẹ sọ fun ni pe irẹlẹ ni àkàbà kan ṣoṣo si ọlá ni Ijọba Ọlọrun. Meloo-meloo ninu awọn eniyan Ọlọrun ni o ti sọ ti ailagbara lọna kan tabi lọna miiran nigba ti Ọlọrun pè wọn si iṣẹ Rẹ. Mose wi pe “Tali emi? Nigba ti Ọlọrun sọ fun un lati lọ si Egipti lati gba awọn Ọmọ Israẹli la kuro lọwọ igbekun awọn ti o n ni wọn lara. Mose sin Ọlọrun ni irẹlẹ ni gbogbo ọjọ aye rẹ, to bẹẹ ti Bibeli sọ nipa rẹ pe, “Ṣugbọn ọkọnrin na Mose, o ṣe ọlọkàn tutù jù gbogbo enia lọ ti mbẹ lori ilẹ” (Numeri 12:3). Igbesi-ayé ati iṣẹ iranṣẹ Mose duro bi apẹẹrẹ ti ko le parun titi di oni-oloni. Ohun pataki ju lọ ti o ṣọwọn ninu ayé lonii ni awọn wọnni ti wọn ṣetan lati wi pe, “Tali emi?” ti wọn ṣetan lati jẹ ki Ọlọrun lò wọn gẹgẹ bi O ba ti fẹ.

Pẹpẹ Gideoni

Bi Gideoni ti n bá angẹli ti o mu ihin ti ọdọ Ọlọrun wá sọrọ, otitọ bẹrẹ si fara hàn diẹdiẹ pe eyi ki i ṣe onṣẹ kan lasan. Gideoni kò fẹ ki onṣẹ naa lọ titi oun yoo fi mu ọrẹ wa. Angẹli naa sọ pe oun yoo duro. Nigba ti ó mu ọrẹ naa wá, angẹli naa paṣẹ fun un pe ki o fi i silẹ lori apata. Angẹli naa fi ori ọpa ti o wà lọwọ rẹ kan ẹbọ naa, iná si jade lati inu apata naa, o si sun gbogbo ẹbọ naa patapata. Angẹli naa si pada lọ lẹsẹ kan naa.

Gideoni ti n gbọ ohun pupọ nipa Ọlọrun Israẹli, ṣugbọn o dabi ẹni pe igba kin-in-ni ti a ni akọsilẹ rẹ ni yii pe Gideoni bá Ọlọrun padé. Ohun ti o kọ sọ si i lọkán ni pe oun yoo kú. Gẹrẹ ti ero yii wọ inu rẹ ni ohùn kan ti fọ si i lati Ọrun wá lati fi ọkàn rẹ balẹ pe: “Alafia fun ọ; má ṣe bẹru: iwọ ki yio kú.”

Gideoni ni alaafia gidi pẹlu Ọlọrun ni wakati kan naa, nitori a kà á pé Gideoni tẹ pẹpẹ nibẹ fun Oluwa. Orukọ ti o sọ pẹpẹ yii ṣe pataki: “Jehofa-ṣalomu”, itumọ eyi ti i ṣe, “Oluwa ni i ṣe alaafia.” Ogun ti o le ju lọ ni Ọlọrun n pe Gideoni si, sibẹ Gideoni tẹ pẹpẹ eyi ti itumọ rẹ i ṣe “Oluwa ni i ṣe alaafia.” Ki i ha ṣe alaafia pẹlu Ọlọrun nipasẹ Jesu Kristi Oluwa wa ni o n fun ni lagbara lati ja “ija rere ti igbagbọ?” Lati kọ oju ija si arekere eṣu, ati awọn alaṣẹ ibi okunkun ati awọn ẹmi buburu oju ọrun, o ṣe danindanin fun ni lati ni imọ Ọlọrun, nipaṣẹ iriri pẹlu Ọlọrun, pe Oluwa ni i ṣe alaafia. Iriri yii wà lọwọ Ọlọrun fun gbogbo awọn ti wọn mọ pe o ṣe dandan fun wọn ti wọn yoo si tọ Ọ wá pẹlu adura gbigbona.

Pipa Baali Run

Aṣẹ kin-in-ni ti Ọlọrun pa fun Gideoni ni pe ki o wó pẹpẹ Baali lulẹ, ki o si gé igbo oriṣa ti o wà lẹba rẹ lulẹ, ki ó si tẹ pẹpẹ fun Ọlọrun. Ki i ṣe iṣẹ kekere ni eyi, nitori gbogbo ara ilu naa ni o n sin Baali. Gideoni kò ba Ọlọrun jiyan ọrọ yii, ni oru ọjọ naa gan an ni o mú ọkunrin mẹwaa ninu awọn iranṣẹ rẹ, o si ṣe ohun ti Ọlọrun palaṣẹ fun un. Eyi yii jẹ aṣiri kan nipa bi a ti le ṣe iṣẹ aṣeyọri fun Ọlọrun -- lati ṣe ohunkohun ti o ba palaṣẹ lai jafara. Ki a maa gbó Ọlọrun lẹnu tabi ki a maa fi igbọran si aṣẹ Rẹ falẹ, yoo mu ki iṣẹ naa ni wá lara lati ṣe. Bi a ba ṣe ohunkohun ti Ọlọrun palaṣẹ fun ni nigba ti O ba pè wá, oore-ọfẹ Rẹ yoo tó fun wa lati mu ki iṣẹ naa yọri si rere.

Ni oru ni Gideoni ṣe iṣẹ yii nitori ẹru awọn ara ilu naa bà á, ṣugbọn ẹrù wọn kò ba a de àye ti kò ni ṣiṣẹ naa rara. Iyatọ nla ni o wà ninu eyi. Ọta wa ẹmi yoo sa ipá rẹ lati fi ẹru si ọkàn awọn ọmọ-ogun Ọlọrun ni ibẹrẹ ipe wọn si iṣẹ pataki ninu Ihinrere, de àye pe ki wọn le fi iṣẹ Ọlọrun silẹ, ki wọn si pada si ọna wọn atijọ. Ẹ jẹ ki a duro bi ọmọ ogun fun Ọlọrun, bi o tilẹ ṣe pe ohun ti abayọrisi rẹ yoo jẹ le ba ni lẹrù. Titẹra mọ iṣẹ wa yoo mu ki aarẹ mu iranṣẹ eṣu ti o buru ju lọ. Nigba ti Gideoni fi rẹyìn awọn Midiani tán, àyà kò fò ó mọ. Ileri Ọlọrun ni eyi pe “Ifẹ ti o pé nlé ibẹru jade” (l Johannu 4:18). Nigba ti Ọlọrun ba sọ ifẹ Rẹ di pipe ninu ọkàn wa, gbogbo ibẹru eniyan ati ki ni ero wọn si wa yoo fò lọ.

Mimu Iduro

Lati igba ti aye ti ṣẹ ni awọn ọmọ ayé ti n gbogun ti awọn ọmọ Ọlọrun. Ko pẹ ki Gideoni to ni iriri yii ni igbesi-aye rẹ. Nigba ti awọn eniyan jí ni owurọ ọjọ keji lẹyin ti a ti wó pẹpẹ Baali lulẹ tán, ọkàn wọn darú. Kò pẹ ki wọn to mọ ẹni ti o ṣe iṣẹ yii. Ayé mọ awọn ti o n sin Ọlọrun bi o tilẹ jẹ pe ko ti i pẹ ti wọn di ọmọ Ọlọrun. Awọn ara ilu pinnu pe ori Gideoni ni lati kuro lọrun rẹ lẹsẹkẹsẹ nitori ohun ti o ṣe si oriṣa wọn.

Iduro ṣinṣin fun Ọlọrun yoo mu ki awọn ẹlomiran pinnu lati bá ọ duro. Baba Gideoni ti fara mọ ọmọ rẹ kiakia, lati doju ija kọ awọn ara ilu. “Ẹnyin o gbèja Baali bi? tabi ẹnyin o gbà a là bi?......bi on ba ṣe ọlọrun, ẹ jẹ ki o gbèja ara rẹ, nitoriti ẹnikan wó pẹpẹ rẹ lulẹ” (Awọn Onidajọ 6:31). Joasi kò ri i ki Baali ṣe rere kan rí. Dajudaju, nisisiyii ó mura tán lati gbẹkẹle Ọlọrun Israẹli lati ri ohun ti yoo ṣe. Iduro ti awọn meji yii mú ṣiṣẹ ribiribi, nitori nigba ti Gideoni fun ipe lati gbá ẹgbẹ ogun jọ ninu awọn eniyan Israẹli, awọn eniyan Abieseri, ilu ti a bi Gideoni, jade pẹlu rẹ.

Irun Agutan Gideoni

Gideoni beere ami, ki i ṣe gẹgẹ bi iran buburu ati panṣaga ti igba ayé Jesu ti o n beere ami, ṣugbọn Gideoni beere ki a ba le fidi igbagbọ rẹ mulẹ ki o si tubọ lagbara si i ninu Oluwa. Alakoso ti a ṣẹṣẹ yàn ti kò si mọ nnkan kan nipa ogun jija. Awọn Midiani pọ niye ni afonifoji bi eeṣù. Kò yà wá lẹnu nigba naa pe Gideoni ri i pe oun ni lati tubọ ni igbagbọ ti o gbona janjan ninu Ọlọrun.

Ọlọrun dahun adura Gideoni, bi Oun yoo ṣe dahun adura gbogbo awọn ti o ba wa A lẹmi ati lotitọ. Gideoni fi irun agutan lelẹ, o si gbadura pe ki iri sẹ si ara rẹ nikan ni oru ọjọ naa, ṣugbọn ki iri ki o má ṣe sẹ silẹ rara ni ayika irun agutan yii. Bi Oluwa bá mu ibeere yii ṣẹ, nigba naa ni Gideoni yoo mọ pe Ọlọrun pinnu lati gba Israẹli là lati ọwọ oun. Ọlọrun ṣe ohun ti Gideoni beere gan an -- ilẹ ti o wà ni ayika irun naa gbẹ, ṣugbọn Gideoni fún iri naa kuro lara irun, ọpọn kan si kún. Lai si aniani, adánniwo ni wà nitosi lati sọ fun Gideoni pe ohun ti o rọrun ni fun irun lati fa omi sara lati inu atẹgun ni oru.

Idahun Meji

Ni oru ọjọ keji Gideoni beere pe ki iri ki o sẹ si ilẹ ki ara irun agutan ki o gbẹ. Lati pa iyemeji run kuro ninu ọkàn Gideoni nipa ipè rẹ lati gba Israẹli là lati ọwọ rẹ, Ọlọrun gbà lati dahun ẹbẹ rẹ keji yii. Nigba ti Gideoni jí ni owurọ ọjọ keji, irun agutan gbẹ furúfurú, ṣugbọn iri sẹ si ilẹ, o si tutu. Ni ọjọ wọnni, awọn eniyan ni lati ri ifarahan Ọlọrun taara ni ọpọlọpọ igba ki ibalo Ọlọrun le yé wọn.

Ni ọjọ oni, a n jẹ anfaani imọlẹ Ihinrere ni kikun bi a ti fihan nipasẹ Oluwa wa Jesu Kristi ninu irapada ati isọdimimọ, ati fun awọn ti o wa A, ni a fun ni Ẹmi Mimọ lati tọ wọn si ọna otitọ gbogbo. “Nigbati on, ani Ẹmi otitọ ni ba de, yio tọ nyin si ọna otitọ gbogbo; nitori ki yio sọ ti ara rẹ; ṣugbọn ohunkohun ti o ba gbọ, on ni yio ma sọ: yio si sọ ohun ti mbọ fun nyin. On o ma yìn mi logo: nitoriti yio gbà ninu ti emi, yio si ma sọ ọ fun nyin” (Johannu 16:13, 14). Sibẹ, titi di oni-oloni ni Ọlọrun n gbọ adura lọna kan pato lati fihan awọn eniyan Rẹ pe Oun ti gbọ adura wọn. O n fẹ ki awọn eniyan Rẹ dan An wò, ki o le fi agbara Rẹ hàn nipa ti wọn. A ha ni iṣoro lọjọ oni bi? Ẹ jẹ ki a mu wọn tọ Ọlọrun lọ ninu ẹbẹ ati adura pẹlu ọkàn yii pe, “Ifẹ tirẹ ni ṣiṣe,” ki a si maa wo ohun ti Oun yoo ṣe.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Lọna pataki wo ni ipo ti awọn Ọmọ Israẹli wà fi buru ni akoko yii?
  2. Bawo ni o ti pẹ to ki awọn Ọmọ Israẹli to mọ pe ọnà àbàyọ wà?
  3. Ta ni angẹli Oluwa yọ si? Bawo ni o ṣe ki i?
  4. Bawo ni Oluwa ṣe mọ iru eniyan ti Gideoni jẹ?
  5. Ki ni ero Gideoni lẹyin ti o mọ pe angẹli Oluwa ni oun n bá sọrọ?
  6. Ki ni iṣẹ kin-in-ni ti Ọlọrun fi le Gideoni lọwọ? Bawo ni o ti pẹ to ki o to ṣe iṣe naa?
  7. Ihà wo ni awọn ara ilu kọ si iṣẹ naa?
  8. Ọna meji wo ni Gideoni gbà beere ami lati le mọ daju pe Ọlọrun ni o yan oun lati gba Israẹli là kuro lọwọ awọn ara Midiani?