Awọn Onidajọ 7:1-8

Lesson 193 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Kò si ẹniti njàgun ti ifi ohun aiye yi dí ara rẹ lọwọ, ki o le mu inu ẹniti o yàn a li ọmọ-ogun dùn”
Cross References
(2 Timoteu 2:4).

I Ẹgbẹ-Ogun ti a kọ Silẹ

1. Gideoni ati gbogbo awọn eniyan dide ni kutukutu owurọ lati mura fun ogun naa, Awọn Onidajọ 7:1; Joṣua 3:1; 6:12

2. Ọlorun kọ pupọ ninu awọn ọmọ-ogun Gideoni silẹ ki wọn má baa gberaga, Awọn Onidajọ 7:2; l Samuẹli 14:6; 2 Kronika 14:11; l Kọrinti 1: 27-29; 2 Kọrinti 4:7

3. Gbogbo awọn ti ẹru n bà ati ojo pada sile, Awọn Onidajọ 7:3; Deuteronomi 20:8; Ifihan 21:8

II Ẹgbẹ-Ogun ti Ọlọrun Yàn

1. Oluwa wi pe ẹgbaa marun un (10,000) ọmọ-ogun ti o kù silẹ ṣi pọ ju sibẹ, Awọn Onidajọ 7:4; l Samuẹli 16:7; Orin Dafidi 33:16

2. Oluwa dín awọn ọmọ-ogun naa kù, Awọn Onidajọ 7:5, 6

3. A ṣe ileri iṣẹgun lati ọwọ ọọdunrun (300) ọkunrin, Awọn Onidajọ 7:7; Isaiah 41:14-16

4. Ẹgbẹ-ogun ọọdunrun (300) mura silẹ fun ogun, Awọn Onidajọ 7:8; Numeri 10:9

Notes
ALAYÉ

Ẹgbaa Mẹrindinlogun (32,000) Ọkunrin

Ẹmi Ọlọrun bà lé Gideoni, o si funpè ogun lati kó Israẹli jọ pọ pẹlu rẹ lati bá awọn Midiani jà. Awọn Ọmọ Israẹli ti jiya pupọ lọwọ awọn ọta yii, o si dabi ẹni pe ọpọ ti ṣetan lati jẹ ipe Gideoni. Awọn ẹgbaa mẹrindinlogun (32,000) ọmọ-ogun ti pé jọ pọ sọdọ balogun wọn, wọn si dó si tosi kanga Harodu, eyi mu ki wọn wà ni ibi giga, wọn si n woo gun awọn ara Midiani ti ó dó si afonifoji. Ṣugbọn abuku kan wà ni ibudo Gideoni. Ọlọrun mọ lẹsẹkẹsẹ, lai si aniani, Gideoni paapaa mọ pẹlu: ẹrù nla wà ninu ọkàn ọpọlọpọ ninu awọn eniyan yii, Oluwa mọ pe pupọ ninu awọn ọmọ-ogun yii yoo gberaga si Oun. Boya a sọ kanga Harodu, itumọ eyi ti i ṣe ẹrù tabi jinnijinni, ni orukọ yii nitori ohun ti o ṣẹlẹ nipa ẹrù ti o wà lọkàn awọn Ọmọ Israẹli.

Ko si ayè fun ẹru lati fi ọkàn awọn ti o n pe ara wọn ni ọmọ-ogun Ọlọrun ṣe ibugbe. Iṣẹ Ọlọrun n beere igbọran ati igbagbọ ninu Rẹ. Igbagbọ ninu Ọlọrun niyelori fun ọkàn ọmọ-eniyan ju ọrọ, okiki, imọ tabi agbara ti ayé le fi fun ni lọ. Ibẹrù lodi si igbagbọ, nitori naa a ni lati mú ibẹru kuro lọna. Bi ẹnikan ko bá lé ẹrù kuro lọkan rẹ nipa iranlọwọ Ọlọrun, oluwa rẹ yoo ri i pe a o yọ oun kuro ninu iṣẹ isin Ọlọrun. Ẹru a maa sé ilẹkun ọkàn eniyan to bẹẹ nigba ti Ọlọrun ba fẹ ṣiṣẹ, Oun yoo ri i pe a ti sé ilẹkun mọ Ọn sode ni ọna kan ṣoṣo ti O le gbà ṣiṣẹ ninu ọmọ-eniyan. Bi ẹrù ba ti pọ to ninu ọkàn ni ilẹkun igbagbọ yoo ṣe tì mọ Ọlọrun gbọningbọnin to.

Awọn Ọmọ-Ogun ti A Kọ Silẹ

Kò ya ni lẹnu nigba naa pe Ọlọrun sọ fun Gideoni lati kede leti awọn eniyan naa pe, “Ẹnikẹni ti o ba nfòya ti ẹru ba si mbà, ki o pada lati òke Gileadi ki o si lọ.” Ikede yii ṣe deedee pẹlu ofin Mose: “Ki awọn olori-ogun ki o si sọ fun awọn enia na si i, ki nwọn ki o si wipe, Ọkọnrin wo li o wà ti o bẹru ti o si nṣojo? jẹ ki o pada lọ si ile rẹ, ki àiya awọn arakọnrin rẹ ki o má ba ṣojo pẹlu bi àiya tirẹ” (Deuteronomi 20:8). Ẹrù, ìjàyà ati ojo a maa gbeeràn ninu ẹgbẹ ọmọ-ogun Onigbagbọ bi ni aarin awọn eniyan miiran gbogbo; nitori idi eyi, Ọlọrun yoo fà wọn tu danu. Ọmọ-ogun Kristi, má ṣe fi ara silẹ fun awọn ohun ti n pa ẹmi run wọnyii.

Idi miiran ti Ọlọrun fi lé awọn eniyan wọnyii pada ni pe ki wọn má baa gba ogo iṣẹgun ti Oluwa fi fun wọn fun ara wọn. Awọn eniyan ti kò lọkàn akin lati le dojuja kọ ọta kò ni fi ọkan pe meji ki wọn to maa funnu pe awọn ni ó ṣẹ ogun naa lẹyin ti ogun ba ti pari tán. Ọlọrun n fẹ ki ọlá ogun yii jẹ ti Rẹ nikan ṣoṣo, ki ayé ki o le mọ Ọn ki wọn si bu ọlá fun Un; nitori naa, O yọ awọn ti kò ni fi ọlá fun Un kuro ninu ẹgbẹ ogun. Igberaga ati ijọ-ara-ẹni-loju jẹ irira niwaju Ọlọrun, Oun kò le lo ẹni ti o bá gberaga tabi ti o jọ ara rẹ loju, Oun kò tilẹ jẹ lo iru ẹni bẹẹ.

Iṣẹgun nipa Igbagbọ

Lati igbà pipẹ sẹyin ni awọn ọta Onigbagbọ ti i maa lo idayafo lati bi igbagbọ ti o wà ninu igbesi-ayé awọn ọmọ Ọlọrun ṣubu, wọn a si maa ṣe bẹẹ titi di oni-oloni. Ọpọlọpọ ọmọ-ogun Kristi ni o ti ṣubu nitori ẹrù, ṣugbọn ọpọ oju iwe itan awọn Onigbagbọ ni o kún fun iṣẹgun ologo ti o jẹ ti awọn wọnni ti o duro ti ijẹwọ igbagbọ wọn ninu Ọlọrun. Onigbagbọ ni Balogun kan ti kò ba ogun kan tì rí nibikibi nigba kan rí; ati pe Oun a si maa dori ọnà awọn eniyan buburu kodò niwaju awọn eniyan Rẹ.

O gbà pe ki ẹni kọọkan ni igbagbọ ki o to le ṣẹ ogun ti o wà ninu igbesi-aye rẹ. Ṣugbọn Ọlọrun n fẹ lati gbin igbagbọ yii si ọkan rẹ ki O si maa fun un ni agbara si i siwaju ati siwaju. A sọ fun ni pe o tó bi aadọta ọkẹ lọna aadọta (50 million) eniyan ni o ti kú ikú ajẹriku fun Kristi kaka ki wọn sẹ igbagbọ wọn ninu Ọlọrun. Igbagbọ wọn jẹ ẹri ti o daju nipa ijolootọ ti Ihinrere le fi si ọkàn eniyan, o si ti jẹ ẹri ti o daju si itiju ti o jẹ ti awọn wọnni ti wọn ti fi ibudo awọn Ẹni Irapada silẹ ki ogun to bẹrẹ tabi ki ariwo ogun to de eti wọn. Má ṣe sá, ṣugbon jà; nitori ọna kan yii ni a le gbà ṣẹgun. Wá sọdọ Ọlọrun fun ikiya, agbara, ireti ati igbagbọ ọtun. O ti ṣeleri pe Oun kò ni ta awọn ti ebi n pa nù lai yó wọn.

O Pọju Sibẹ

Nigba ti Gideoni rí ti ẹgbaa mọkanla (22,000) ọmọ-ogun da ohun ija wọn silẹ ti wọn si mú ọna ile pọn, boya o ro pe awọn ẹgbaa marun un (10,000) ti o kù ti kere jù. Ṣugbọn kò sọ ireti nù. Baraki ati Debora kò ha gba Israẹli là kuro lọwọ Sisera pẹlu iwọn iba eniyan diẹ? (Awọn Onidaju 4:14). Bi Gideoni ti n woye iran naa, Oluwa sọ fun un pe awọn eniyan naa pọ ju sibẹ. Ọlọrun paṣẹ fun Gideoni lati kó awọn ọmọ ogun naa wá si eti odò, ki Oun le yan awọn ti yoo lọ si ogun. Odiwọn Ọlọrun ga pupọ.

Ami ti Ọlọrun fi fun Gideoni lati mọ awọn ti yoo lọ ati awọn ti yoo pada sile ki i ṣe ami lasan. “Olukuluku ẹniti o ba fi ahọn rẹ lá omi, bi ajá ti ma lá omi, on na ni ki iwọ ki o fi si apakan fun ara rẹ; bẹẹ si li olukuluku ẹniti o kunlẹ li ẽkun rẹ lati mu omi” (Awọn Onidajọ 7:5). Iye awọn ti wọn fi ahọn lá omi, ti wọn fi ọwọ wọn bu omi si ẹnu jẹ ọọdunrun (300) ọkunrin. Oluwa sọ fun Gideoni pe lati ọwọ awọn ọọdunrin ọkunrin wọnyii ni Oun yoo gbà fi Midiani lé Israẹli lọwọ.

Iwọnba Diẹ

Nigba pupọ ni o ṣe pe nipa ohun kekere ni a fi n mọ iyatọ laaarin awọn eniyan. Paulu Aposteli sọ fun awọn ara Efesu pe: “Ẹ kiyesi lati mã rìn ni iwa pipé, ki iṣe bi awọn alailọgbọn, ṣugbọn bi awọn ọlọgbọn; ẹ mã ra igba pada, nitori buburu li awọn ọjọ” (Efesu 5:15, 16) Ọlọrun ki i saaba lo ọpọ eniyan fun iṣẹ Rẹ, ohun kan yii ni O n beere, pe ki awọn ti o n ṣiṣẹ fun Un ni amuyẹ ti ẹmi. John Wesley sọ pe: “Ẹ ba mi wá ọgọrun (100) oniwaasu ti kò bẹru ohunkohun afi ẹṣẹ, ti kò fẹ ohunkohun afi Ọlọrun, n kò fẹ mọ bi alufaa ni wọn tabi ọmọ ijọ; iru wọn ni yoo mi ilẹkun ọrun apaadi ti wọn yoo si fi idi Ijọba Ọlọrun kalẹ ninu ayé.

Ki i ṣe ohun nla kan ni a fi mọ iyatọ laaarin awọn ọọdunrun ọkunrin wọnyii ati ẹgbaarun-o-din-ọọdunrun (9,700) ọkunrin ti a kọ wọnyii. Iyatọ nla nla ni o wà laaarin awọn ẹgbaa mọkanla (22,000) ọkunrin ti ẹru n bà ati awọn ẹgbaarun ọkunrin ti o duro lẹyin idanwo àkọkọ. O le dabi ẹni pe Ọlọrun ṣakoso ọkàn ọmọ-eniyan nipa yíyan awọn ọọdunrun wọnyii laarin ẹgbaarun (10,000) eniyan, ṣugbọn nigba ti a ba wo o finnifinni a o ri i pe o wà lọwọ ẹnikọọkan wọn sibẹ. Igba pupọ wà ti ohun kekere kan ti o dabi ẹni pe ko to nnkan, kò ni jẹ ki a ka eniyan mọ awọn ti Ọlọrun yàn. A kò le kiyesara ju nipa iwà ati iṣe wa niwaju Ọlọrun.

Ẹgbaarun din ọọdunrun (9,700) ọkunrin wá sódò, wọn si kunlẹ lori eekun wọn lati mu omi. Ọta ni o dó ti Israẹli gbọngbọn yii, awọn ọmọ-ogun wọnyii gbagbe ohun gbogbo ti o yí wọn ká fun iwọn igba diẹ lati tu ara wọn lara. Awọn ọọdunrun ti o fi ahọn la omi yatọ si awọn wọnyii. Wọn ranti ọpọlọpọ ọdun ti wọn ti fi n jiya lọwọ awọn ará Midiani. Akoko ti wọn le ni idande ni yii, wọn si ṣetan lati gbaju mọ iṣẹ yii. Kò si àyè lati mu omi amuyo pẹlu irọra: wọn fi ọwọ bu omi si ẹnu, wọn si mu iwọnba ti wọn le mu bayii, ni gbogbo igba yii, ojú ati ọkàn wọn wà ninu ohun ti wọn ba wá. Ọlọrun wi pe, lati ọwọ awọn ọọdunrun (300) ọkunrin ti wọn mú ṣáṣá, onipinnu ati ẹni diduro ṣinṣin wọnyii ni Oun yoo ti gba Israẹli là.

Kiko Ara Nijanu

Ohun pupọ ni o wà ninu ayé ti a kò kọ fun ọmọ Ọlọrun lati lò, ṣugbọn aṣeju ninu ohunkohun yoo fa ibinu Ọlọrun. Ẹkọ yii farahàn gbangba ninu igbesi-ayé awọn ọmọ-ogun Gideoni. Ta ni jẹ wi pe ẹṣẹ wà ninu omi mimu, ṣugbọn ọna ti awọn ọọdunrun-din-ni ẹgbaarun (9,700) ọkunrin wọnyii gbà fi irọra ati akoko wọn mu omi fi ipò ti wọn wà ninu ẹmi hàn, eyi si mu ki a lé wọn kuro laaarin awọn ẹni aṣayàn Ọlọrun.

Nipa iṣẹ ti ara, ẹni ti awọn eniyan le jẹri rẹ pé o ṣe aṣẹyọri ni ẹni naa ti o ba fi gbogbo akoko, ọgbọn ati agbara rẹ ṣe gbogbo iṣẹ rẹ. O gbà pe ẹni ti ko ṣiṣẹ ko yẹ ki o jẹun, nitori naa ẹkọọkan ni o n sinmi. Nigba gbogbo ni o n ro bi iṣẹ tabi ìpè oun yoo ṣe ni ilọsiwaju, bi ero bayii si ti wà ni ọkàn rẹ, iṣẹ rẹ yoo maa lọ deedee.

Ohun kan naa ti a kà silẹ nipa aṣeyọri ni ti iṣẹ oojọ yii ni a tun le sọ nipa ti ọmọ-ogun Kristi. Iru ẹni bẹẹ ni lati fi iṣẹ siwaju afẹ, eyi si ni iwa awọn ti o n sin Ọlọrun tinutinu. Ninu ṣiṣe ifẹ Balogun rẹ ni idunnu rẹ wa. Bakan naa ni itura ati iṣẹ jẹ fun ọmọ Ọlọrun. Bi ọkunrin tabi obinrin ba ti sin Ọlọrun pẹ to ni otitọ yii yoo tubọ fi ara hàn tó. “Ohunkohun ti ẹnyin ba nṣe, ẹ mã ṣe gbogbo wọn fun ogo Ọlọrun” (l Kọrinti 10:31).

Wọn Kere Niye Ṣugbọn Wọn Jẹ Alagbara

Ọlọrun kò fẹ ọpọ eniyan lati fi ṣe iṣẹ Rẹ. O le lo ọpọlọpọ eniyan fun iṣẹ Rẹ lọna iyanu bi ọkàn wọn ba ṣe deedee niwaju Rẹ, ti awọn eniyan naa si fẹ ṣe ohun ti Ọlọrun wí. Ohun ti o ba ni ninu jẹ ni pe iru awọn eniyan bẹẹ ti wọn jọwọ ara wọn fun Ọlọrun kò wọpọ. Ṣugbọn ọpọ yanturu kọ ni Ọlọrun n fẹ lati ṣiṣẹ ninu ọgba ajara Rẹ, bi ko ṣe awọn ti o ni ohun wọnni ti Oun le mú lò ninu wọn. Aṣeyọri ninu ọpọlọpọ idawọle ni o n beere pe ki awọn ti o dawọ le e ni imọ ti o tọ nipa iṣẹ naa, ki i si i ṣe bi wọn ti pọ to ni iye. Bakan naa ni o ri ninu iṣẹ Oluwa.

Lakoko iṣẹ-iranṣẹ Jesu ninu aye, Ọmọ Ọlọrun ri awọn mọkanla ti O le fi ọkàn tán ti O si le fun ni aṣẹ lati lọ si gbogbo ayé lati waasu Ihinrere fun gbogbo eniyan. Ki ọkunrin mọkanla pere dojukọ gbogbo agbaye ki i ṣe iṣẹ ti o rọrun, ṣugbọn Jesu ṣeleri pe Oun yoo wà pẹlu wọn nigba gbogbo ani titi de opin aye. Njẹ iṣẹ Ihinrere ni ifasẹyin nitori awọn oṣiṣẹ kò pọ? Rara o. O tankalẹ lọna iyanu ni akoko awọn Aposteli ti igba ni, bẹẹ naa ni o ri sibẹ titi di oni-oloni. Ohun ti Ihinrere n ṣe kò ṣe e fẹnu sọ tan, ṣugbọn a sọ fun ni pe agbara rẹ ni o dawọ ibinu ati idajọ Ọlọrun duro. Ajadopin ni ogun ti ọmọ-ogun Kristi, awọn ọta rẹ pataki si ni “awọn alaṣẹ ibi òkunkun aiye yi,” ati “awọn ẹmí buburu ni oju ọrun” (Efesu 6:12). Satani n sa gbogbo ipá rẹ lati gbé ijọba ti rẹ kalẹ nipasẹ Aṣodi-si-Kristi, ṣugbọn ẹmi Ọlọrun ti ó wà ninu awọn eniyan Rẹ ni o n ṣe idena Rẹ. Lọjọ kan a o gba ijọ soke Ọrun, nigba naa aye yoo wà labẹ alakoso onroro ti o buru ju lọ.

Ẹgbẹ Awọn Aṣayan Ọlọrun

Ọpọ ẹgbẹ ẹlẹsin ni o wà ninu ayé lọjọ oni, gbogbo wọn ni o si n wi pe wọn wà ninu ogun Ọlọrun. Bawo ni i ba ti dara to bi gbogbo awọn ti o jẹwọ pe ọmọ-ogun Kristi ni awọn i ṣe ba ni iru ẹmi ti awọn ẹgbẹ-ogun Gideoni ni! Ṣugbọn ohun ti o ba ni ninu jẹ ni pe, iye awọn ti i ṣe ọmọ-ogun tootọ, ti o fẹ ti o si ṣetan lati runpa-runsẹ si ohun ti i ṣe ti Kristi kere niye si awọn ojo ati abẹru tabi awọn wọnni ti wọn fẹ lati ṣe faaji bi ọta tilẹ wà nitosi, gẹgẹ bi o ti ri ni akoko Gideoni. Ẹyọ ẹni kan ninu ọgọrun eniyan ni o yege idanwo ti Ọlọrun mu wọn là já. Eyi ba ni lẹru gidigidi! “Tali o ha le là?” eyi ni ibeere ti awọn ọmọ-ẹhin fi siwaju jesu nigba ti wọn gbọ awọn ohun ti o ṣe gunmọ ti wọn ni lati ṣe ki wọn to wọ Ijọba Ọrun. Ọran ati ri igbala jẹ ohun ti ẹni kọọkan ni lati pinnu fun ara rẹ. A ti ṣe ipese oore-ọfẹ ati ogo ti kò loṣuwọn fun ero kọọkan ti o bá n rin lọna giga ti iwa mimọ. “Iwọ le ṣe e bi o ba pinnu” ni ọrọ akọle ti awọn Onigbagbọ fẹ lati maa lò lati ọdun pupọ sẹyin, bi o ti ri ni igbesi-aye ẹni ti ọrọ yii kọ jade si ni o si le ri fun iwọ naa pẹlu lonii. “Má bẹru, agbo kekere; nitori didùn inu Baba nyin ni lati fi ijọba fun nyin” (Luku 12:32).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Eniyan meloo ni o jẹ ipe Gideoni lati bá awọn ará Midiani jà?
  2. Ki ni ṣe ti Ọlọrun sọ fun Gideoni pe awọn eniyan naa pọ ju?
  3. Ki ni idanwo kin-in-ni ti a fi siwaju awọn ọmọ-ogun wọnyii? Eniyan meloo ni o pada sẹyin?
  4. Ta ni wá tún dán awọn ọmọ-ogun wọnyii wo? Ki ni idanwo naa?
  5. Eniyan meloo ni o yege ninu idanwo keji?
  6. Ẹkọ pataki wo ni a ri kọ nipa idanwo ti Ọlọrun mu awọn ọmọ-ogun Gideoni la kọja?
  7. Bawo ni Ọlọrun ṣe n dán awọn ọmọ-ogun ti Rẹ wò lonii?